Ẹ Fi Ẹ̀mí Ìdúródeni Hàn!
“Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.”—MÍKÀ 7:7.
1, 2. (a) Báwo ni ẹ̀mí tí kò dára ṣe pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára nínú aginjù? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan tí kò bá ní ẹ̀mí tó dára?
Ọ̀PỌ̀ nǹkan nínú ìgbésí ayé la lè fojú tó dáa tàbí ojú tí kò dáa wò, ó sinmi lórí irú ẹ̀mí tí a bá fi gbà á. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, ọ̀nà ìyanu là fi pèsè mánà fún wọn. Ṣe ló yẹ kí wọ́n wò yí ká aṣálẹ̀ tó lọ salalu, kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà fún pípèsè ohun tó ń gbẹ́mìí wọn ró. Ìyẹn ì bá ti fi ẹ̀mí tó dára hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n rántí ni onírúurú oúnjẹ tó wà ní Íjíbítì, wọ́n sì ṣàròyé pé mánà náà ò lọ lẹ́nu rárá. Ẹ̀mí òdì gbáà lèyí!—Númérì 11:4-6.
2 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, irú ẹ̀mí tí Kristẹni kan ní lónìí lè mú kí àwọn nǹkan dà bí èyí tó fún un láyọ̀ tàbí èyí tó ń bà á nínú jẹ́. Bí Kristẹni kan kò bá ní ẹ̀mí tó dára, kò ní pẹ́ pàdánù àyọ̀ rẹ̀, ìyẹn á sì burú gan-an nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà ti sọ: “Ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára [wa].” (Nehemáyà 8:10) Ẹ̀mí tó dára tó sì jẹ́ aláyọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ alágbára, ó sì ń gbé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ lárugẹ.—Róòmù 15:13; Fílípì 1:25.
3. Báwo ni ẹ̀mí tó dára ṣe ran Jeremáyà lọ́wọ́ láwọn àkókò ìṣòro?
3 Jeremáyà fi ẹ̀mí tó dára hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbé ní àkókò tó le koko. Kódà nígbà tó rí àwọn nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣubú Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó ṣì tún rí i pé nǹkan ṣì lè dára. Jèhófà kò ní gbàgbé Ísírẹ́lì, orílẹ̀-èdè náà yóò là á já. Jeremáyà kọ ọ́ sínú ìwé Ìdárò pé: “Àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni kò jẹ́ kí a wá sí òpin wa, nítorí ó dájú pé àánú rẹ̀ kì yóò wá sí òpin. Tuntun ni wọ́n ní òròòwúrọ̀. Ìṣòtítọ́ rẹ pọ̀ yanturu.” (Ìdárò 3:22, 23) Jálẹ̀ ìtàn ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti máa ń wá bí àwọn ṣe máa ní ẹ̀mí tó dára, àní ẹ̀mí tó kún fún ayọ̀ pàápàá nínú ipò tó burú jù lọ.—2 Kọ́ríńtì 7:4; 1 Tẹsalóníkà 1:6; Jákọ́bù 1:2.
4. Irú ẹ̀mí wo ni Jésù ní, báwo ló sì ṣe ràn án lọ́wọ́?
4 Ẹgbẹ̀ta ọdún lẹ́yìn Jeremáyà, ẹ̀mí tó dára tí Jésù ní ló ran òun náà lọ́wọ́ láti ní ìfaradà. A kà á pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú [Jésù], ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 12:2) Lójú gbogbo àtakò tàbí inúnibíni tí Jésù dojú kọ—títí kan ìjẹ̀rora lórí òpó igi oró pàápàá—ibi tí ó fi ọkàn rẹ̀ sí ni “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.” Ìdùnnú yẹn ni àǹfààní láti dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre àti láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ títí kan ìrètí náà láti mú ìbùkún ńlá wá fún ìran ènìyàn onígbọràn lọ́jọ́ iwájú.
Ní Ẹ̀mí Ìdúródeni
5. Kí ni ipò kan táa lè lò bí àpẹẹrẹ nínú èyí tí ẹ̀mí ìdúródeni ti lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dára nípa àwọn ọ̀ràn?
5 Bí a bá ní irú ẹ̀mí ìrònú tí Jésù ní, a ò ní pàdánù ìdùnnú Jèhófà kódà bí àwọn nǹkan ò tiẹ̀ fi gbogbo ìgbà rí báa ṣe fẹ́ kó rí, tí wọn ò sì ṣẹlẹ̀ lákòókò táa fẹ́ kí wọ́n ṣẹlẹ̀. Wòlíì náà Míkà sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Míkà 7:7; Ìdárò 3:21) Àwa náà lè fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn. Lọ́nà wo? Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Lọ́nà kan, a lè rò pé arákùnrin kan tó wà ní ipò àṣẹ ti ṣe àṣìṣe kan, ó sì yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ ní kíá mọ́sá láti tún ọ̀ràn náà ṣe. Ẹ̀mí ìdúródeni yóò jẹ́ kí a ronú pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ló ṣe àṣìṣe ni, àbí ojú mi lọ̀ràn náà ti rí bẹ́ẹ̀? Tó bá ṣe àṣìṣe, ó ha lè jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà ń fẹ́ kí nǹkan ṣì máa lọ bẹ́ẹ̀ ná nítorí ó gbà pé ẹni náà yóò ṣàtúnṣe, àti pé ìbáwí mímúná janjan kankan kò pọndandan?’
6. Báwo ni ẹ̀mí ìdúródeni ṣe lè ran ẹnì kan tó ní ìṣòro ara ẹni lọ́wọ́?
6 Ẹ̀mí ìdúródeni á pọndandan bí a bá ní ìṣòro ara ẹni tó ń bá wa fínra tàbí tí a bá ń tiraka láti borí àìlera kan. Ká ní a béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, síbẹ̀ tí ìṣòro náà ò lọ. Kí wá ni ká ṣe? A gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní ṣíṣe ohunkóhun tí agbára wa bá ká láti yanjú ìṣòro náà, kí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” (Lúùkù 11:9) Máa gbàdúrà, kí o sì dúró de Jèhófà. Àkókò tó dára jù lọ ni Jèhófà yóò dáhùn àdúrà rẹ, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀nà tirẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 5:17.
7. Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí ìdúródeni fi lè ṣèrànwọ́ fún ojú ìwòye wa nípa òye Bíbélì tó ń dé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?
7 Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ní ìmúṣẹ ni òye wa lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ túbọ̀ ń ṣe kedere sí i. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà mìíràn wà táa lè ronú pé ó ti yẹ kí ìlàlóye ti dé tipẹ́tipẹ́ nípa kókó kan. Bí kò bá dé lákòókò tó wù wá kó dé, ǹjẹ́ a múra tán láti dúró? Rántí pé, Jèhófà rí i pé ó dára láti ṣí “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Kristi” payá díẹ̀díẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún. (Éfésù 3:3-6) Ǹjẹ́ a wá ní ìdí kankan láti máa kánjú? Ṣé kò dá wa lójú pé a ti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fún àwọn ènìyàn Jèhófà “ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” ni? (Mátíù 24:45) Èé ṣe tí a óò máa fi ìdùnnú tí ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá du ara wa nítorí pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la lóye tán pátá? Rántí pé Jèhófà ló ń pinnu ìgbà tí òun yóò ṣí ‘àwọn ọ̀ràn àṣírí rẹ̀’ payá, àti bí òun ṣe máa ṣí wọn payá.— Ámósì 3:7.
8. Báwo ni sùúrù Jèhófà ṣe ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ ènìyàn?
8 Àwọn kan lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí wọ́n ronú pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn ti fi òtítọ́ sìn, àwọn lè máà rí “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” (Jóẹ́lì 2:30, 31) Síbẹ̀, wọ́n ṣì lè rí ìṣírí nígbà tí wọ́n bá gba ibi tó dáa wò ó. Pétérù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pétérù 3:15) Sùúrù Jèhófà ti gba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olódodo mìíràn láyè láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Èyí kì í ha í ṣe nǹkan àgbàyanu bí? Síwájú sí i, bí Jèhófà bá ṣe ní sùúrù tó, bẹ́ẹ̀ náà ni àkókò ṣe máa wà fún wa tó láti “máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílípì 2:12; 2 Pétérù 3:11, 12.
9. Bí a kò bá lè ṣe tó bí a ṣe fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, báwo ni ẹ̀mí ìdúródeni ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ipò náà?
9 Ẹ̀mí ìdúródeni ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí àtakò, àìsàn, ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn bá ń dí wa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà. Jèhófà retí pé kí a máa fi tọkàntọkàn sin òun. (Róòmù 12:1) Àmọ́ ṣá o, Ọmọ Ọlọ́run, tó ń “káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì,” kò retí pé kí a ṣe ju ibi tí agbára wa mọ; bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà kò retí ìyẹn. (Sáàmù 72:13) Nítorí náà, a rọ̀ wá láti ṣe ohun tí a bá lè ṣe, kí a máa fi sùúrù dúró títí ipò nǹkan yóò fi yí padà—yálà nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tàbí nínú èyí tó ń bọ̀. Rántí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.
10. Kí ni ìwà tí Ọlọ́run kórìíra, tí ẹnì kan tó ní ẹ̀mí ìdúródeni lè yẹra fún? Ṣàlàyé.
10 Ẹ̀mí ìdúródeni tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìkùgbù. Àwọn kan ti di apẹ̀yìndà nítorí pé wọn ò fẹ́ dúró. Wọ́n ti lè ronú pé ó yẹ kí a ṣe àwọn àtúnṣe kan, yálà nínú òye Bíbélì tàbí nínú àwọn ọ̀ràn ìṣètò. Ṣùgbọ́n, wọ́n kùnà láti mọ̀ pé ẹ̀mí Jèhófà ló ń sún ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe àwọn àtúnṣe ní àkókò tí ó tọ́ lójú Rẹ̀, kì í ṣe nígbà táa rò pé ó yẹ ní ṣíṣe. Àtúnṣe èyíkéyìí sì ní láti wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú èrò tiwa. Àwọn apẹ̀yìndà jẹ́ kí ìkùgbù sọ èrò inú wọn dìdàkudà, kí ó sì mú wọn kọsẹ̀. Àmọ́ ká ní wọ́n ní ẹ̀mí ìrònú Kristi ni, ayọ̀ wọn ì bá má yingin, àti pé wọn ì bá ṣì wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà báyìí.—Fílípì 2:5-8.
11. Báwo la ṣe lè lo àkókò táa fi ń dúró lọ́nà tó mérè wá, ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn wo?
11 Àmọ́ ṣá o, níní ẹ̀mí ìdúródeni kò túmọ̀ sí pé ká di ọ̀lẹ tàbí aláìṣiṣẹ́ mọ́. Iṣẹ́ pọ̀ lọ́rùn wa. Fún àpẹẹrẹ, ó yẹ kí a máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra wa, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì olóòótọ́ àti àwọn áńgẹ́lì pàápàá ti ṣe. Nígbà tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìfẹ́ tó jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ní ti ìgbàlà yìí gan-an, ìwádìí aláápọn àti ìwákáàkiri àfẹ̀sọ̀ṣe ni àwọn wòlíì ṣe . . . Nǹkan wọ̀nyí gan-an ni àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.” (1 Pétérù 1:10-12) Kì í ṣe orí dídákẹ́kọ̀ọ́ lọ̀rọ̀ parí sí o, lílọ sípàdé déédéé àti àdúrà tún pọndandan. (Jákọ́bù 4:8) Àwọn tó ń fi hàn pé àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ wọ́n lọ́kàn nípa jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé àti nípa dídara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ń fi hàn gbangba pé àwọn ní ẹ̀mí ìrònú tí Kristi ní.—Mátíù 5:3.
Ní Èrò Tí Ó Tọ́
12. (a) Òmìnira wo ní Ádámù àti Éfà fẹ́? (b) Kí ló sì ti jẹ́ àbájáde títẹ̀lé tí àwọn ènìyàn ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà Ádámù àti Éfà?
12 Nígbà tí Ọlọ́run dá tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, kò fún wọn ní ẹ̀tọ́ láti pinnu rere àti búburú, òun fúnra rẹ̀ ló ni ẹ̀tọ́ yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ádámù àti Éfà fẹ́ òmìnira kúrò lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, èyí sì wá yọrí sí bí nǹkan ṣe rí nínú ayé tó yí wa ká lónìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ẹgbàata [6,000] ọdún ìtàn ìran ènìyàn láti ìgbà Ádámù ti fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Gbígbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Jeremáyà kò túmọ̀ sí pé a ti jọ̀gọ̀ nù. A gbà nítorí pé òótọ́ pọ́ńbélé ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ ohun tó fà á láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wọ̀nyí wá tí “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀” nítorí pé àwọn ènìyàn ń ṣàkóso láìfi Ọlọ́run pè.—Oníwàásù 8:9.
13. Èrò tí ó tọ́ wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nípa ohun tí àwọn ènìyàn lè ṣe yọrí?
13 Lójú bí ipò ìran ènìyàn ṣe rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé ìwọ̀nba díẹ̀ ní ohun táa lè gbé ṣe nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ẹ̀mí tó dára lè ràn wá lọ́wọ́ láti má pàdánù ayọ̀ wa, àmọ́ ìyẹn kọ́ ni ojútùú sí gbogbo nǹkan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, àlùfáà kan tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà tẹ ìwé kan jáde, tó jẹ́ pé òun ló tà jù lọ nígbà yẹn, ó pe orúkọ rẹ̀ ní The Power of Positive Thinking. Ìwé náà dámọ̀ràn pé ọ̀pọ̀ jù lọ ìdènà la lè borí bí a bá fi ẹ̀mí tó dára wò wọ́n. Dájúdájú ohun tó dára gan-an ni kéèyàn ní ẹ̀mí rere. Ṣùgbọ́n ìrírí ti fi hàn pé ìmọ̀, òye iṣẹ́, ohun ìní ti ara, àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn lè jẹ́ kí ohun tí àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan lè ṣe mọ níwọ̀n. Táa bá sì wò yí ká ayé, a óò rí i pé àwọn ìṣòro náà ti pọ̀ kọjá ohun táwọn èèyàn lè rí ojútùú sí—bó ti wù kí ìrònú wọn dára tó!
14. Ṣé ẹ̀mí tí kò dára ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ni? Ṣàlàyé.
14 Nítorí èrò tí ó tọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nípa irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn máa ń fẹ̀sùn kàn wọ́n nígbà mìíràn pé wọn ò ní ẹ̀mí tó dára. Dípò ìyẹn, ṣe ni wọ́n ń hára gàgà láti sọ fún àwọn ènìyàn nípa Ẹnì kan ṣoṣo tó lè tún ọ̀ràn aráyé ṣe pátápátá. Ṣíṣe èyí pẹ̀lú fi hàn pé wọ́n ní ẹ̀mí ìrònú Kristi. (Róòmù 15:2) Ọwọ́ wọ́n sì dí ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ìbátan tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n mọ̀ pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, èyí ló máa ṣàǹfààní tó dára jù lọ.—Mátíù 28:19, 20; 1 Tímótì 4:16.
15. Báwo ni iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe?
15 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fojú pa àwọn ìṣòro tó yí wọn ká láwùjọ rẹ́—àgàgà àwọn àṣà ẹlẹ́gbin tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Kó tó di pé olùfìfẹ́hàn kan di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìyípadà kan, lọ́pọ̀ ìgbà ó ní láti ṣẹ́pá àwọn ìwàkiwà tó ti di mọ́ọ́lí sí i lára, èyí tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran àwọn tó ní etí ìgbọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ọtí àmupara, ìjoògùnyó, ìṣekúṣe, àti tẹ́tẹ́ títa tó ti di bárakú. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tó ti yí padà ti wá mọ bí wọ́n á ṣe máa pèsè fún ìdílé wọn lọ́nà tó bójú mu, tí kì í sì í ṣe ti onímàgòmágó. (1 Tímótì 5:8) Nígbà táa bá ran àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn ìdílé lọ́wọ́ nírú ọ̀nà yìí, àwọn ìṣòro máa ń dín kù láwùjọ—àwọn ajoògùnyó á dín kù, ìwà ipá á dín kù nínú ìdílé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fúnra wọn jẹ́ ọmọlúwàbí tí ń pa òfin mọ́, tí wọ́n sì tún ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn padà sí rere, wọ́n ń dín iṣẹ́ àwọn àjọ tó ń bójú tó àwọn ìṣòro tí ń bẹ láwùjọ kù.
16. Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ sí iṣẹ́ tí àwọn àjọ alátùn-únṣe inú ayé ń ṣe?
16 Ṣé ká wá tìtorí bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yí ìwà tó gbòde kan nínú ayé padà ni? Tóò, ní ẹ̀wádún tó kọjá, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣiṣẹ́ déédéé lọ sókè láti iye àwọn tó kù díẹ̀ kó tó mílíọ̀nù mẹ́ta àti ogójì ọ̀kẹ́ [3,800,000] dé iye àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000]. Ìyẹn jẹ́ ìbísí tó ń lọ sí nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [2,200,000], tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì jẹ́ àwọn tó fi ìwà àìṣòdodo sílẹ̀ nígbà tí wọ́n di Kristẹni. Ọ̀pọ̀ èèyàn la mà ti tún ayé wọn ṣe! Àmọ́, iye yìí kéré gan-an táa bá fi wé báwọn èèyàn ṣe pọ̀ sí i tó lórí ilẹ̀ ayé láàárín àkókò kan náà—ìyẹn mílíọ̀nù ẹgbẹ̀rin ó lé márùndínlọ́gọ́rin [875,000,000] ènìyàn! Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti ran àwọn tó ní etí ìgbọ́ lọ́wọ́, bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn èèyàn tó máa gba ọ̀nà tó lọ sí ìyè. (Mátíù 7:13, 14) Nígbà tó jẹ́ pé ìyípadà sí rere tí Ọlọ́run nìkan lè ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dúró dè, wọ́n kì í lọ́wọ́ sí iṣẹ́ tí àwọn àjọ alátùn-únṣe inú ayé ń ṣe, èyí tó sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èrò tó dára ṣùgbọ́n tó máa ń parí pẹ̀lú àìnírètí àti ìwà ipá pàápàá.—2 Pétérù 3:13.
17. Kí ni Jésù ṣe láti ran àwọn tó yí i ká lọ́wọ́, àmọ́ kí ni kò ṣe?
17 Nípa títẹ̀lé ipa ọ̀nà yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi hàn pé a ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé kan náà tí Jésù ní nínú Jèhófà nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu mímú àwọn ènìyàn lára dá. (Lúùkù 6:17-19) Ó tilẹ̀ jí òkú dìde pàápàá. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-56) Àmọ́ kò mú ìṣòro àìsàn kúrò, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣẹ́gun ọ̀tá náà tí í ṣe ikú. Ó mọ̀ pé kò tíì tó àkókò fún ṣíṣe èyí lójú Ọlọ́run. Nítorí agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ tí Jésù ní, ì bá ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan láti yanjú àwọn ìṣòro ìṣèlú àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Ó dà bí pé àwọn kan lára àwọn alájọgbáyé rẹ̀ fẹ́ kó gbàjọba, kó sì ṣe ohun táa wí yìí, ṣùgbọ́n Jésù kọ̀ jálẹ̀. A kà á pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn rí àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Dájúdájú, èyí ni wòlíì tí ń bọ̀ wá sí ayé.’ Nítorí náà, Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.”—Jòhánù 6:14, 15.
18. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn ní gbogbo ìgbà? (b) Báwo ni ìgbòkègbodò Jésù ṣe yí padà láti ọdún 1914?
18 Jésù kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ìṣèlú tàbí iṣẹ́ tó wulẹ̀ jẹ́ ti afẹ́nifẹ́re lásán nítorí ó mọ̀ pé àkókò kò tíì tó fún òun láti gba agbára gẹ́gẹ́ bí ọba àti láti ṣe iṣẹ́ ìmúláradá fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo. Kódà lẹ́yìn tó gòkè lọ sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́, ó ṣe tán láti dúró de àkókò tí Jèhófà yàn kalẹ̀ kó tó gbégbèésẹ̀. (Sáàmù 110:1; Ìṣe 2:34, 35) Àmọ́ ṣá, àtìgbà tó ti gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọdún 1914 ló ti ń jáde lọ “ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣípayá 6:2; 12:10) Ẹ wo bí a ṣe kún fún ìmoore tó láti tẹrí ba fún ipò ọba rẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn tí wọ́n ń pe ara wọn ní Kristẹni yàn láti wà láìmọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ìjọba náà!
Dídúró De Nǹkan —Ṣé Orísun Àìnírètí Ni Àbí Ti Ayọ̀?
19. Ìgbà wo ní dídúró ń ‘mú ọkàn-àyà ṣàárẹ̀,’ ìgbà wo ló sì ń fúnni láyọ̀?
19 Sólómọ́nì mọ̀ pé dídúró de nǹkan lè tánni ní sùúrù. Ó kọ̀wé pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Dájúdájú, bí ẹnì kan bá ń retí ohun tó jẹ́ àléèbá, ìjákulẹ̀ lè mú kí ọkàn-àyà rẹ̀ ṣàìsàn. Àmọ́ ṣá, dídúró de nǹkan ayọ̀ tó fẹ́ ṣẹlẹ̀—bí ìgbéyàwó, ọmọ bíbí, tàbí pípadà rí àwọn ènìyàn tí a fẹ́ràn—lè jẹ́ ká ti máa yọ̀ sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kí ọjọ́ náà tó dé. Ayọ̀ yẹn yóò túbọ̀ kún tí a bá fọgbọ́n lo àkókò táa fi ń dúró náà, tí a ń múra de ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ náà.
20. (a) Kí ni àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀lẹ̀ tó dá wa lójú pé yóò ṣẹlẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè láyọ̀ báa ti ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ète Jèhófà?
20 Nígbà tí a bá ní ìgbọ́kànlé tó dájú pé ohun tí a ń retí yóò dé—kódà bí a kò tilẹ̀ mọ ìgbà tí yóò dé—àkókò tí a fi ń dúró náà kò ní láti ‘mú ọkàn-àyà ṣàárẹ̀.’ Àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run mọ̀ pé Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi ti sún mọ́lé. Ó dá wọn lójú pé wọn óò rí òpin ikú àti àìsàn. Pẹ̀lú ìháragàgà ni wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ dúró de àkókò náà nígbà tí wọn óò kí àìmọye bílíọ̀nù òkú káàbọ̀, títí kan àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú. (Ìṣípayá 20:1-3, 6; 21:3, 4) Ní àwọn àkókò tí àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ti ko ìṣòro yìí, wọ́n ní ìrètí dídánilójú ti rírí Párádísè tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 35:1, 2, 7) Ẹ wo bó ṣe mọ́gbọ́n dání tó nígbà náà láti lo àkókò tí a fi ń dúró yìí dáradára, ‘kí a máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa’! (1 Kọ́ríńtì 15:58) Máa bá a lọ ní jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí. Máa mú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà gún régé sí i. Wá àwọn ẹlòmíràn tí ọkàn-àyà wọn ń sún wọn láti sin Jèhófà rí. Máa fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ níṣìírí. Lo àkókò èyíkéyìí tí Jèhófà ṣì yọ̀ǹda dáadáa. Nígbà náà, dídúró de Jèhófà kò ní mú ‘ọkàn-àyà rẹ ṣàárẹ̀’ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò mú ayọ̀ rẹ kún!
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn?
• Lábẹ́ àwọn ipò wo làwọn Kristẹni ti nílò ẹ̀mí ìdúródeni?
• Èé ṣe tó fi tẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́rùn láti dúró de Jèhófà?
• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí dídúró de Jèhófà fún wa láyọ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jésù lo ìfaradà nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti ń sìn, a ṣì lè máa ní ayọ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti mú kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i nípa dídi Ẹlẹ́rìí Jèhófà