‘Afọgbọ́nhùwà Ni Ẹni Tó Ń ka Ìbáwí Sí’
ÒWE orí kẹtàlélógún ẹsẹ kejìlá sọ pé: “Mú ọkàn-àyà rẹ wá fún ìbáwí àti etí rẹ fún àwọn àsọjáde ìmọ̀.” Nínú ẹsẹ yìí, “ìbáwí,” tàbí ẹ̀kọ́ nípa ìwà rere ní í ṣe pẹ̀lú bíbá ara ẹni wí tàbí gbígba ìbáwí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ gba kéèyàn mọ irú ìtọ́ni téèyàn nílò àti ọ̀nà téèyàn máa gbà mú ìtọ́ni náà lò. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn ní “àwọn àsọjáde ìmọ̀” tó wá láti orísun tó ṣeé gbára lé.
Ìwé Òwe inú Bíbélì jẹ́ orísun tó dára gan-an téèyàn ti lè rí àwọn àsọjáde ọgbọ́n. Àwọn òwe inú rẹ̀ wà “fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí, . . . láti gba ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye, òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán.” (Òwe 1:1-3) Ọlọ́gbọ́n la jẹ́ tá a bá fi ‘etí wa’ sí wọn. Òwe orí kẹẹ̀ẹ́dógún fúnni ní ìtọ́ni tó yè kooro lórí bá a ṣe lè kápá ìbínú, bó ṣe yẹ ká máa lo ahọ́n wa, àti bá a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹsẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò nínú orí náà.
Kí Ló “Máà Ń Yí Ìhónú Padà”?
Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ń sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ọ̀rọ̀ ẹnu máa ń ní lórí ìbínú tàbí ìhónú, ó sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) “Ìbínú” ni ọ̀rọ̀ tá a fi ń ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe máa ń rí lára èèyàn nígbà tí wọ́n bá sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ síni. “Ìhónú” sì ni kéèyàn bínú gan-an kó sì ṣòro gan-an láti ṣàkóso ìbínú náà. Báwo ni òwe yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe nígbà tí ẹnì kan bá bínú sí wa tàbí tínú bá ń bí àwa fúnra wa?
Ọ̀rọ̀ tí kò bára dé tó ń dunni wọra lè mú kẹ́ni tínú ń bí tẹ́lẹ̀ wá bínú kọjá ààlà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe ni ìdáhùn pẹ̀lẹ́ sábà máa ń jẹ́ kára tuni. Síbẹ̀, kì í sábà rọrùn láti dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́ nígbà tí ẹnì kan bá fìbínú sọ̀rọ̀. Àmọ́, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbìyànjú láti mọ ohun tó ń bí onítọ̀hún nínú. Bíbélì sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni onítọ̀hún kò dá ara rẹ̀ lójú ni inú ṣe ń bí i tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ káwọn èèyàn ka òun sí? Ohun tó ń múnú bí i gan-an lè má ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tá a sọ tàbí ohun tá a ṣe. Nígbà tí ẹnì kan bá bínú sí wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí ohun tí kò jóòótọ́ tí ẹni náà ti gbọ́ nípa ohun tá a gbà gbọ́ ló sábà máa ń fà á tàbí kó jẹ́ pé ẹ̀tanú tó ní nítorí àwọn àṣìlóye kan ló fà á? Ṣé ó wá yẹ ká gba ọ̀rọ̀ náà bíi pé àwa gan-an ni onítọ̀hún kórìíra, ká sì wá fìbínú dá a lóhùn? Kódà nígbà tá ò bá mọ ohun tó ń bí ẹnì kan nínú pàápàá, fífi ọ̀rọ̀ tó ń gúnni lára dá a lóhun lè fi hàn pé a ò lè kora wa níjàánu. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú èsì bẹ́ẹ̀.
Ìmọ̀ràn pé ká máa fèsì lọ́nà tó ṣe pẹ̀lẹ́ tún ṣe pàtàkì gan-an nígbà táwa fúnra wa bá ń bínú. A lè fi ìmọ̀ràn yẹn sílò nípa kíkọ́ láti máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa lọ́nà tí kò ní múnú bí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀. Nígbà tọ́rọ̀ bá da àwa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìdílé wa pọ̀, dípò ká máa fìbínú sọ̀rọ̀ tàbí ká máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, ńṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti fi sùúrù jẹ́ kí wọ́n mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wa. Ńṣe ni kòbákùngbé ọ̀rọ̀ máa ń mú kẹ́ni tá a sọ ọ́ sí fẹ́ gbẹ̀san. Fífi sùúrù sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa fún ẹnì kan kò ní jẹ́ kó sọ pé a ń fẹ̀sùn kan òun, ó sì lè mú kí onítọ̀hún tọrọ àforíjì.
‘Ahọ́n Àwọn Ọlọ́gbọ́n Máa Ń Ṣe Rere’
A gbọ́dọ̀ máa kóra wa níjàánu nínú ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ àti ohun tá à ń sọ pẹ̀lú. Sólómọ́nì sọ pé: “Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn arìndìn máa ń tú ìwà òmùgọ̀ jáde.” (Òwe 15:2) Nígbà tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tá a sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe àtàwọn ohun àgbàyanu tó ń pèsè fún wa, ǹjẹ́ kì í ṣe pé à “ń lò ìmọ̀ lọ́nà rere” nìyẹn? Arìndìn èèyàn ò lè ṣe èyí nítorí pé kò ní ìmọ̀.
Kó tó di pé Sólómọ́nì fúnni ní ìtọ́ni síwájú sí i lórí bó ṣe yẹ ká máa lo ahọ́n wa, ó sọ ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ kan. Ó ní: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” (Òwe 15:3) Èyí lè múnú wa dùn gan-an nítorí ó dá wa lójú pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Tá a bá ń ṣe nǹkan tó dára, Ọlọ́run mọ̀. Ó tún máa ń wo àwọn tó ń ṣe ohun búburú, á sì mú kí wọ́n dáhùn fún ohun tí wọ́n ṣe.
Sólómọ́nì tún sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì ahọ́n tó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó ní: “Ìparọ́rọ́ ahọ́n jẹ́ igi ìyè, ṣùgbọ́n ìfèrúyípo nínú rẹ̀ túmọ̀ sí ìrẹ̀wẹ̀sì nínú ẹ̀mí.” (Òwe 15:4) Gbólóhùn náà “igi ìyè” ń sọ nípa ìwòsàn àtàwọn ohun tó ń fúnni lókun. (Ìṣípayá 22:2) Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ látẹnu ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n máa ń tu àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lára. Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fi ànímọ́ rere tí wọ́n ní hàn. Àmọ́, ahọ́n ẹ̀tàn tàbí èyí tó ń sọ ọ̀rọ̀ àyídáyidà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
Gbígba Ìbáwí àti “Títan Ìmọ̀ Kálẹ̀”
Ọba ọlọ́gbọ́n náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ òmùgọ̀ ń ṣàìbọ̀wọ̀ fún ìbáwí baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń ka ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sí jẹ́ afọgbọ́nhùwà.” (Òwe 15:5) Báwo lẹnì kan ṣe lè “ka ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sí” tí kì í bá ṣe pé a kọ́kọ́ fún un ní ìbáwí náà? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ pé a gbọ́dọ̀ fúnni ní ìbáwí nígbà tó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Nínú ìdílé, ojúṣe àwọn òbí ni láti fún ọmọ ní ìbáwí, àgàgà bàbá, ojúṣe àwọn ọmọ sì ni kí wọ́n gba ìbáwí náà. (Éfésù 6:1-3) Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa ń gba ìbáwí lọ́nà kan tàbí òmíràn. Hébérù 12:6 sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.” Ọwọ́ tá a bá fi mú ìbáwí tí wọ́n fún wa ló máa fi hàn bóyá a jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀.
Sólómọ́nì tún mẹ́nu kan àfiwé mìíràn, ó ní: “Ètè ọlọ́gbọ́n ń bá a nìṣó ní títan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà àwọn arìndìn kò rí bẹ́ẹ̀.” (Òwe 15:7) Títan ìmọ̀ kálẹ̀ dà bíi fífọ́n irúgbìn. Láyé àtijọ́, àwọn àgbẹ̀ kì í gbin irúgbìn wọn sójú kan ṣoṣo. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa bu irúgbìn náà díẹ̀díẹ̀, wọ́n á sì máa fọ́n ọn ká gbogbo pápá náà. Bó ṣe rí gẹ́ẹ́ pẹ̀lú títan ìmọ̀ kálẹ̀ nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá bá ẹnì kan pàdé lóde ẹ̀rí, kò ní bọ́gbọ́n mu ká sọ gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa Bíbélì fún un lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n máa ń kó ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ níjàánu. Á máa ‘tan ìmọ̀ kálẹ̀’ bó ṣe rọra ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì kan lẹ́ẹ̀kan tó sì ń fi kún un díẹ̀díẹ̀, á sì máa kíyè sí ọ̀nà tí ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ ń gbà dáhùn padà. Jésù Kristi tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ wa ṣe èyí nígbà tó ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀.—Jòhánù 4:7-26.
Ríran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ gba pé kéèyàn máa sọ ọ̀rọ̀ tó máa tọ́ onítọ̀hún sọ́nà tá á sì ṣe é láǹfààní. Èèyàn gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ dáadáa kó tó lè sọ̀rọ̀ táwọn èèyàn máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀ táá sì fún wọn níṣìírí. Abájọ tí “Ọkàn-àyà olódodo [fi] máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí ọ̀rọ̀ wa dà bí òjò tó rọra ń rọ̀, tó rin ilẹ̀ dáadáa tó sì ṣe ilẹ̀ láǹfààní, kó má jẹ́ ọ̀gbàrá òjò tó ń ṣàn gbùúgbùú tó sì ń gbá gbogbo nǹkan lọ!
‘Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Ní Ìwà’
Títan ìmọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé kálẹ̀, ká sì máa rú “èso ètè” wa sí i gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ ìyìn” jẹ́ ìgbésẹ̀ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́. (Hébérù 13:15) Àmọ́, kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa.’ (1 Pétérù 1:14-16) Sólómọ́nì lo òwe méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti mú ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí wá sí àfiyèsí wa. Ó ní: “Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. Ọ̀nà ẹni burúkú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ń lépa òdodo.”—Òwe 15:8, 9.
Ojú wo làwọn tó ń fi ọ̀nà ìyè sílẹ̀ fi máa ń wo ìbáwí tó ń tọ́ni sọ́nà, kí ló sì máa yọrí sí fún wọn? (Mátíù 7:13, 14) “Ìbáwí burú fún ẹni tí ó fi ipa ọ̀nà sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà yóò kú.” (Òwe 15:10) Dípò káwọn kan tó ń ṣe ohun tí ò dáa fara mọ́ ìmọ̀ràn tá a fi ń tọ́ni sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni kí wọ́n sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ńṣe ni wọ́n máa ń fi ọ̀nà òdodo sílẹ̀ pátápátá. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà nìyẹn!
Bí ẹnì kan bá wá ṣe bíi pé òun fara mọ́ ìbáwí nígbà tó sì jẹ́ pé ó kórìíra rẹ̀ ní ti gidi ńkọ́? Èyí náà ò bọ́gbọ́n mu. Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Ṣìọ́ọ̀lù àti ibi ìparun ń bẹ ní iwájú Jèhófà. Mélòómélòó wá ni ọkàn-àyà àwọn ọmọ aráyé!” (Òwe 15:11) Tá a bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kò síbi tó tún lè jìnnà sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè tó bí Ṣìọ́ọ̀lù ṣe jìnnà sí i, ìyẹn ipò àwọn òkú. Síbẹ̀, Ṣìọ́ọ̀lù wà níwájú rẹ̀. Ó mọ gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, ó mọ bí ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n ṣe rí, ó sì lágbára láti jí wọn dìde. (Sáàmù 139:8; Jòhánù 5:28, 29) Ẹ ò rí i pé kò ṣòro rárá fún Jèhófà láti mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Ọmọ èèyàn la lè tàn jẹ, a kò lè tan Ọlọ́run jẹ.
Kì í ṣe pé ẹni tó ń kọ ìbáwí máa ń kórìíra ìbáwí tí wọ́n ń fi tọ́ ọ sọ́nà nìkan ni, àmọ́ ó tún kórìíra àwọn tó ń fún un ní ìbáwí ọ̀hún. Sólómọ́nì sọ pé: “Olùyọṣùtì kò nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ń fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà.” Kí Sólómọ́nì lè túbọ̀ ṣàlàyé ohun tó ń sọ yìí, ó tún sọ èrò mìíràn tó fara pẹ́ ẹ, ó ní: “Kì yóò tọ àwọn ọlọ́gbọ́n lọ.” (Òwe 15:12) Ẹ ò rí i pé bóyá ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ fi lè ṣàtúnṣe!
Ẹ Máa Láyọ̀
Ọ̀rọ̀ nípa “ọkàn-àyà” ni Sólómọ́nì sọ nínú àwọn òwe rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó tẹ̀ lé e. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n ọba náà ń sọ bí ohun tó ń lọ nínú ọkàn ṣe máa ń hàn lójú èèyàn, ó sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú máa ń ní ipa rere lórí ìrísí, ṣùgbọ́n nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.”—Òwe 15:13.
Kí ló lè fa ìbànújẹ́ ọkàn? Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba [pẹ̀lú ìbànújẹ́].” (Òwe 12:25) Ọ̀nà wo la ò fi ní jẹ́ káwọn ohun tó ń bà wá nínú jẹ́ nígbèésí ayé wa máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa? Dípò tá a ó máa fi gbogbo ìgbà ronú lórí àwọn ìṣòro tá ò lè yanjú fúnra wa, a lè máa ronú lórí àwọn ìbùkún tẹ̀mí rẹpẹtẹ tí Jèhófà ń fún wa nísinsìnyí àtàwọn ohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Èyí yóò mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Láìsí àní-àní, ó dájú pé sísúnmọ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” kò ní ṣàìfún ọkàn ìbànújẹ́ wa láyọ̀.—1 Tímótì 1:11.
Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń tuni nínú ó sì máa ń fúnni láyọ̀ gan-an. Onísáàmù sọ pé aláyọ̀ ni ẹni tí ‘inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, tó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.’ (Sáàmù 1:1, 2) Kódà, nígbà tí ohun kan bá ń bà wá lọ́kàn jẹ́, kíka Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó sọ yóò fún wa ní ìṣírí. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Bíbélì mú un dá wa lójú pé “àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.”—Sáàmù 126:5.
Sólómọ́nì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní òye ni ń wá ìmọ̀ kiri, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn arìndìn ní ń nàgà sí ìwà òmùgọ̀.” (Òwe 15:14) Òwe yìí jẹ́ ká rí i pé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n yàtọ̀ pátápátá sí ti òmùgọ̀. Kí olóye èèyàn tó fúnni ní ìmọ̀ràn, á kọ́kọ́ wá ìmọ̀ kiri. Á fetí sílẹ̀ dáadáa, a sì rí i pé òun mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí dáadáa. Á wá inú Ìwé Mímọ́ láti mọ àwọn òfin àti ìlànà téèyàn lè tẹ̀ lé nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa gbé gbogbo ìmọ̀ràn rẹ̀ kà. Àmọ́, òmùgọ̀ èèyàn kò ní wádìí ọ̀rọ̀ náà rárá, á kàn sọ ohunkóhun tó bá wá sọ́kàn rẹ̀ jáde gbàù ni. Nítorí náà, tá a bá fẹ́ gba ìmọ̀ràn, ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni pé ká lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ìmọ̀ wọn kún tí wọ́n sì dàgbà dáadáa nípa tẹ̀mí dípò tá a ó fi lọ sọ́dọ̀ àwọn tó lè jẹ́ pé ohun tá a fẹ́ gbọ́ ni wọ́n máa sọ fún wa. Ó mà dára gan-an o, bá a ṣe ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” nínú ìjọ Kristẹni, ìyẹn àwọn tí wọ́n máa “ń wá ìmọ̀ kiri” kí wọ́n tó fúnni nímọ̀ràn!—Éfésù 4:8.
Òwe tó tẹ̀ lé èyí sọ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa jẹ́ aláyọ̀. Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Ìgbésí ayé wa máa ń ní àkókò ìbùkún àti àkókò àjálù, bẹ́ẹ̀ náà ló tún máa ń ní àkókò ayọ̀ àti àkókò ẹkún. Tó bá jẹ́ pé apá tí kò dùn mọ́ wa níbẹ̀ la máa ń rò ní gbogbo ìgbà, ìbànújẹ́ á gba gbogbo ọkàn wa, gbogbo ọjọ́ ayé wa yóò sì kan gógó. Àmọ́ tá a bá jẹ́ kí gbogbo ìrònú wa dá lórí àwọn ìbùkún tá a ti rí gbà àti lórí ìrètí tí Ọlọ́run fún wa, a ó rí i pé a ò ní ka àwọn ohun tó ń kó ìbànújẹ́ báni sí bàbàrà mọ́, a ó sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Jíjẹ́ aláyọ̀ yóò mú kó dà bíi pé à ń jẹ “àsè nígbà gbogbo.”
Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìbáwí. Kó má ṣe jẹ́ pé inú ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa nìkan ló ti máa hàn, àmọ́ kó tún hàn lójú wa pẹ̀lú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
“Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ojúṣe àwọn òbí ló jẹ́ láti bá àwọn ọmọ wọn wí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
“Ètè ọlọ́gbọ́n ń bá a nìṣó ní títan ìmọ̀ kálẹ̀”