Ojú Ìwòye Bíbélì
A Ha Lè Máa Bá Ìgbéyàwó Kan Lọ Lẹ́yìn Ìhùwà Àìtọ́ Bí?
“Mo wí fún yín pé ẹni yòó wù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò bá ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà.”—MÁTÍÙ 19:9.
PẸ̀LÚ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Jésù Kristi fún Kristẹni kan láǹfààní láti yàn láti kọ alájọgbéyàwó kan tí ó jẹ́ aláìṣòótọ́ sílẹ̀.a Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí ẹnì kejì tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ náà bá yàn láti jẹ́ kí ìgbéyàwó náà máa bá a lọ, tí tọkọtaya náà sì pinnu láti tún àárín wọn ṣe ńkọ́? Àwọn ìṣòro wo ni tọkọtaya náà lè pàdé, báwo ni wọ́n sì ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà lọ́nà tí ó yọrí sí rere? Ẹ jẹ́ kí a wo bí Bíbélì ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Ilé Tí A Wó Palẹ̀
A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lóye bí ìhùwà àìtọ́ náà ti ṣe ìbàjẹ́ tó. Bí Jésù Kristi ti ṣàlàyé, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó pète pé kí ọkọ àti aya má ṣe jẹ́ “méjì mọ́, bí kò ṣe ẹran ara kan.” Ó fi kún un pé: “Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀ sábẹ́ àjàgà kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, a pète ìgbéyàwó láti so àwọn ẹ̀dá ènìyàn pọ̀ lọ́nà tí kò ṣeé yà sọ́tọ̀. Nígbà tí ẹnì kan bá tẹ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó lójú nípa ṣíṣe panṣágà, àwọn àbájáde aronilára gógó yóò tẹ̀ lé e.—Mátíù 19:6; Gálátíà 6:7.
Ìrora ọkàn tí ó ṣẹlẹ̀ sí alájọgbéyàwó tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ náà ń jẹ́rìí sí èyí. A lè fi àbáyọrí ìhùwà panṣágà wé ti ìjì líle kan tí ó fọ́ àwọn ibùgbé yángá. Ọ̀mọ̀wé Shirley P. Glass sọ pé: “Àwọn bíi mélòó kan tí mo ti tọ́jú sọ fún mi pé, ì bá túbọ̀ rọrùn fún àwọn ká ní alájọgbéyàwó wọ́n kú ni.” Lótìítọ́, àwọn kan tí alájọgbéyàwó wọ́n ti kú lè má fara mọ́ ọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé panṣágà máa ń dunni gan-an. Àwọn ènìyàn kan kò lè gbọ́kàn kúrò pátápátá nínú dídà tí a dà wọ́n náà.
Lójú irú làásìgbò bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Ìhùwà panṣágà ha gbọ́dọ̀ fòpin sí ìgbéyàwó kan bí?’ Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa panṣágà fi hàn pé alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ ní yíyàn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu láti ṣe ìkọ̀sílẹ̀, àmọ́, kò sí lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tọkọtaya kan pinnu láti ṣàtúntò ohun tí ó ti fọ́, kí wọ́n sì fún un lókun, nípa ṣíṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tí ó gbe ìwà panṣágà lẹ́yìn.
Dájúdájú, ó sàn jù láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan nínú ipò ìbátan lọ́kọláya tí tọkọtaya náà bá jẹ́ olùṣòtítọ́ sí ara wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kódà nígbà tí ìwà àìtọ́ bá ṣẹlẹ̀, àwọn alájọgbéyàwó kan tí wọn kò mọwọ́mẹsẹ̀ yàn láti máa bá ìgbéyàwó náà lọ. Dípò kí wọ́n gbé irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ karí èrò ìdàníyàn pé nǹkan yóò dára, alájọgbéyàwó tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ náà gbọ́dọ̀ gbé àwọn àbájáde rẹ̀ yẹ̀ wò. Ó ṣeé ṣe kí ó ronú nípa àwọn àìní àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn àìní tirẹ̀ nípa tẹ̀mí, èrò ìmọ̀lára, ara ìyára, àti ti ọ̀ràn ìnáwó. Yóò tún lo ọgbọ́n nípa ríronú lórí bóyá a lè yọ ìgbéyàwó rẹ̀ nínú ewu.
A Ha Lè Yọ Ìgbéyàwó Náà Nínú Ewu Bí?
Kí a tó gbìyànjú láti ṣàtúnkọ́ ilé kan tí ìjì líle wó, mọlémọlé kan gbọ́dọ̀ pinnu bóyá a lè mú un pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà, kí wọ́n tó gbìyànjú láti ṣàtúnṣe ipò ìbátan kan tí ìwà àìtọ́ ti fọ́ yángá, tọkọtaya kan—ní pàtàkì alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀—yóò fẹ́ láti ṣe ojúlówó ìdíyelé nípa bí ó ti ṣeé ṣe tó láti mú ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pa dà bọ̀ sípò nínú ìgbéyàwó náà.
Kókó kan tí ó ní láti gbé yẹ̀ wò ni bóyá alájọgbéyàwó tí ó jẹ̀bi náà fi ìrònúpìwàdà aláìṣẹ̀tàn hàn tàbí, dípò bẹ́ẹ̀, ó ṣì ń ṣe panṣágà “nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:27, 28) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣèlérí láti yí pa dà, ó ha lọ́ra láti fòpin sí àjọṣe oníwà pálapàla rẹ̀ lọ́gán bí? (Ẹ́kísódù 20:14; Léfítíkù 20:10; Diutarónómì 5:18) Ojú rẹ̀ ha ṣì ń ṣe kámi-kàmì-kámi bí? Ó ha ń ti ẹ̀bi ìwà panṣágà rẹ̀ sórí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìsapá láti mú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ pa dà bọ̀ sípò nínú ìgbéyàwó náà lè má yọrí sí rere. Ní ọwọ́ kejì, bí ó bá fòpin sí àjọṣe aláìbófinmu náà, tí ó sì gba ẹ̀bi fún ìwà àìtọ́ rẹ̀, tí ó sì fi hàn pé òun mú ṣíṣàtúnṣe ìgbéyàwó náà bí iṣẹ́ pátápátá, ẹnì kejì rẹ̀ lè rí ìpìlẹ̀ fún ríretí pé a lè mú ojúlówó ìgbẹ́kẹ̀lé pa dà bọ̀ sípò lọ́jọ́ kan.—Mátíù 5:29.
Bákan náà, alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ náà ha lè dárí jì bí? Èyí kò túmọ̀ sí pé kò gbọ́dọ̀ sọ ìmọ̀lára ìpalára jíjinlẹ̀ tí ó ní jáde nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tàbí pé kí ó díbọ́n pé ohunkóhun kò yí pa dà. Ó túmọ̀ sí pé yóò gbìyànjú, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, láti má ṣe gbin ìbínú jíjinlẹ̀ sínú. Irú ìdáríjì bẹ́ẹ̀ ń gba àkókò àmọ́, ó lè ṣèrànwọ́ láti fìdí ìpìlẹ̀ tí ó lágbára, tí a lè ṣàtúnṣe ìgbéyàwó náà lè, múlẹ̀.
Pípalẹ̀ “Àwọn Pàǹtírí” Náà Mọ́
Lẹ́yìn tí alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ náà bá ti pinnu láti máa bá ìgbéyàwó wọn lọ, ìgbésẹ̀ wo ni tọkọtaya kan lè wá gbé? Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́dọ̀ gbá àwọn pàǹtírí tí ó wà láyìíká ibùgbé kan tí ìjì líle kan bà jẹ́ gan-an kúrò, a gbọ́dọ̀ gbá “àwọn pàǹtírí” tí ó yí ìgbéyàwó náà ká kúrò. A lè ṣàṣeparí èyí dé àyè kan bí tọkọtaya náà bá sọ ìmọ̀lára wọn lẹ́nìkíní kejì jáde. Òwe 15:22 (NW) sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀ ìfinúkonú” tọ́ka sí ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́, a sì pè é ní “àwùjọ tímọ́tímọ́” nínú Orin Dáfídì 89:7 (NW). Nítorí náà, kì yóò wulẹ̀ jẹ́ àsọgbà ọ̀rọ̀ lóréfèé lásán kan, àmọ́, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ aláìlábòsí, tí ó tọkàn wá, nínú èyí tí àwọn méjèèjì yóò ti ṣí ìmọ̀lára wọn jíjinlẹ̀ payá.—Òwe 13:10.
Fún àpẹẹrẹ, nínú àwọn ọ̀ràn kan, alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ náà lè ní àwọn ìbéèrè síwájú sí i láti bi ẹnì kejì rẹ̀. Báwo ni ọ̀ràn àjọṣe náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Báwo ni ó ṣe wà pẹ́ tó? Ta ló tún mọ̀ nípa rẹ̀? Lótìítọ́, yóò jẹ́ nǹkan tí ń bani nínú jẹ́ fún tọkọtaya náà láti jíròrò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ náà lè rí irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ bí ohun tí ó pọn dandan láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé pa dà bọ̀ sípò. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dára jù lọ pé kí alájọgbéyàwó tí ó jẹ́ aláìṣòótọ́ náà dáhùn lọ́nà àìlábòsí àti ìgbatẹnirò. Ó gbọ́dọ̀ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ti rí lọ́nà onífẹ̀ẹ́, tí ó sì kún fún inú rere, kí ó fi sọ́kàn pé ète àjọsọ náà jẹ́ láti ṣàtúnṣe, kì í ṣe láti ṣèpalára. (Òwe 12:18; Éfésù 4:25, 26) Àwọn méjèèjì yóò ní láti lo ọgbọ́n inú, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ìtẹ́tísílẹ̀ lọ́nà ìgbatẹnirò, bí wọ́n ti ń fi ìmọ̀lára wọn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ hàn.b—Òwe 18:13; Kọ́ríńtì Kíní 9:25; Pétérù Kejì 1:6.
Àwọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fẹ́ láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà inú ìjọ. Ó dájú pé, ní ti àwọn Kristẹni, a gbọ́dọ̀ lọ lọ́gán láti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bíi panṣágà fún àwọn alàgbà, tí àníyàn nípa ire tẹ̀mí àwọn tọkọtaya náà àti ìjọ ń jẹ lọ́kàn. Ó lè jẹ́ pé nígbà tí onípanṣágà náà pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ó fi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà á láyè láti ṣì wà nínú ìjọ. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà lè máa bá a lọ ní ṣíṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tọkọtaya náà.—Jákọ́bù 5:14, 15.
Ṣíṣàtúnṣe
Lẹ́yìn tí tọkọtaya náà bá ti lè ṣàkóso ìmọ̀lára wọn dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe tó, wọ́n wà ní ipò tí ó dára láti ṣàtúnṣe àwọn apá pàtàkì nínú ìgbéyàwó wọn. Wọ́n ṣì ń nílò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ onífọkànsí. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ, tí wọ́n bá rí àwọn àṣìṣe.
Àìní láti ṣe àwọn ìyípadà yóò já lé èjìká alájọgbéyàwó tí ó jẹ̀bi náà ní pàtàkì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, alájọgbéyàwó tí kò yẹsẹ̀ náà gbọ́dọ̀ ṣe ipa tirẹ̀ ní mímú kí àwọn apá tí ó láṣìṣe nínú ìgbéyàwó náà lókun. Èyí kò túmọ̀ sí pé ẹ̀bi rẹ̀ ni ìwà panṣágà náà tàbí pé a lè yọ̀ǹda rẹ̀—kò sí àwáwí tí ó fìdí múlẹ̀ fún dídá irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 3:12; Jòhánù Kíní 5:3.) Ó wulẹ̀ túmọ̀ sí pé àwọn ìṣòro kan lè ti wà nínú ìgbéyàwó náà tí a ní láti yanjú. Ṣíṣàtúnṣe jẹ́ ìdáwọ́lé àjùmọ̀ṣe kan. Ẹ ha nílò láti mú àwọn ìjẹ́pàtàkì àti góńgó ìlépa tọ̀túntòsì lókun bí? Ẹ ha ti pa àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tì bí? Ìgbésẹ̀ ṣíṣàwárí àwọn àṣìṣe pàtàkì yí, àti ṣíṣe àwọn ìyípadà tí ó pọn dandan wúlò nínú ṣíṣàtúnṣe ìgbéyàwó kan tí ó ti bà jẹ́ gan-an.
Àbójútó
Kódà, ilé tí a kọ́ dáradára kan nílò àbójútó déédéé. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó, nígbà náà, láti pa ipò ìbátan tí a ṣàtúnṣe rẹ̀ mọ́. Tọkọtaya náà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àkókò tí ń kọjá ba ìpinnu wọn láti rọ̀ mọ́ àwọn ìpinnu wọn tuntun jẹ́. Kàkà kí wọ́n ba ọkàn jẹ́ bí àwọn ìfàsẹ́yìn tí kò tó nǹkan bá ṣẹlẹ̀, bíi jíjó rẹ̀yìn sínú àṣà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí kò dára, ó yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti tún fìdí àṣà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídára múlẹ̀, kí wọ́n sì máa bá a lọ ní títẹ̀ síwájú.—Òwe 24:16; Gálátíà 6:9.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọkọ àti ìyàwó gbọ́dọ̀ fi ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn sí ipò tí ó mú iwájú jù lọ, kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí òun, tàbí ìgbéyàwó wọn, mú ipò kejì lẹ́yìn àwọn ìgbòkègbodò míràn. Orin Dáfídì 127:1 sọ pé: “Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà, àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán.” Bákan náà, Jésù kìlọ̀ pé: “Gbogbo ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí tí kò sì ń ṣe wọ́n ni a óò fi wé òmùgọ̀ ọkùnrin kan, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò sì rọ̀ sílẹ̀ ìkún omi sì dé ẹ̀fúùfù sì fẹ́ wọ́n sì kọ lu ilé náà ó sì ya lulẹ̀, ìwólulẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀.”—Mátíù 7:24-27.
Bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá kọ àwọn ìlànà Bíbélì tì nítorí pé wọ́n ṣòro láti fi sílò, ìgbéyàwó náà yóò ṣí sílẹ̀ fún ìkọlù ìdánwò onípákáǹleke tí ìwà àìtọ́ tí ó bá ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e yóò mú wá. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkọ àti ìyàwó bá pa àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì mọ́ nínú gbogbo ọ̀ràn, ìgbéyàwó wọn yóò ní ìbùkún àtọ̀runwá. Wọn óò tún ní ìsúnniṣe tí ó lágbára jù lọ sípa ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó—ìfẹ́ ọkàn láti tẹ́ Ẹlẹ́dàá ìgbéyàwó, Jèhófà Ọlọ́run, lọ́rùn.—Mátíù 22:36-40; Oníwàásù 4:12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìdí tí ó gbéṣẹ́ wà tí ẹnì kan fi lè yàn láti kọ alájọgbéyàwó tí ó jẹ́ panṣágà sílẹ̀. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí ọ̀ràn yí, wo “Ojú-Ìwòye Bíbélì: Panṣágà—Ṣé Kí N Dáríjì Í Tàbí Kí N Máṣe Dáríjì Í?” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde August 8, 1995.
b Fún ìsọfúnni lórí ìtẹ́tísílẹ̀ lọ́nà tí ó dára, wo Jí!, ìtẹ̀jáde January 22, 1994, ojú ìwé 6 sí 9, àti December 8, 1994, ojú ìwé 10 sí 13.