Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Jẹ́ “Ìbáwí Síhà Ọgbọ́n”
ỌGBỌ́N tòótọ́ ti pe àpèjẹ ńlá kan. Ó ti “rán àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ obìnrin jáde, kí ó lè ké jáde ní orí àwọn ibi gíga ìlú pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí, kí ó yà síhìn-ín.’ Ẹnì yòówù tí ọkàn-àyà bá kù fún—ó wí fún un pé: ‘Ẹ wá, ẹ fi oúnjẹ mi bọ́ ara yín, kí ẹ sì ṣàjọpín nínú mímu wáìnì tí mo ti dà lù. Ẹ fi àwọn aláìní ìrírí sílẹ̀, kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ sì máa rìn tààrà ní ọ̀nà òye.’”—Òwe 9:1-6.
Béèyàn bá ń jẹun lórí tábìlì ọgbọ́n, kì í yọrí sí ohun búburú bẹ́ẹ̀ ni kì í pani lára. Ńṣe ni fífetí sí ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú àwọn òwe tí Ọlọ́run mí sí, àti títẹ́wọ́ gba ìbáwí tó wà nínú rẹ̀ máa ń jẹ́ kó dára fúnni. Bó sì ṣe rí nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Òwe 15:16-33 nìyẹn.a Fífi ìmọ̀ràn inú àwọn gbólóhùn tó ṣe ṣókí wọ̀nyí sílò á jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ máa tẹ́ wa lọ́rùn, á jẹ́ ká máa tẹ̀ síwájú, á sì jẹ́ ká máa láyọ̀ nígbèésí ayé wa. Bákan náà, á jẹ́ ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dára, á sì jẹ́ ká lè máa wà lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.
Níní Ohun Ìní Níwọ̀nba Ló Dára Jù
Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Díẹ̀ ní inú ìbẹ̀rù Jèhófà sàn ju ọ̀pọ̀ ìpèsè yanturu tòun ti ìdàrúdàpọ̀.” (Òwe 15:16) Ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn ṣàìka Ẹlẹ́dàá sí kó sì máa fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lé ohun ìní tara. Ńṣe ni irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ máa ń mú kéèyàn máa bá kòókòó-jàn-án-jàn-án kiri láìsí ìsinmi, bẹ́ẹ̀ lèèyàn ò sì ní ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ẹ ò rí i pé kò ní bójú mu rárá bó bá jẹ́ pé ọjọ́ ogbó lèèyàn tó wá rí i pé asán àti ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo ohun tóun ti fi ìgbésí ayé òun ṣe! Ó dájú pé kíkó ọ̀pọ̀ ohun ìní jọ tòun ti “ìdàrúdàpọ̀” kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu rárá. Kéèyàn kọ́ láti ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn àti kéèyàn jẹ́ kéyìí máa darí ìgbésí ayé òun mà dára gan-an o! Kì í ṣe inú àwọn ohun ìní lèèyàn ti ń rí ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn bí kò ṣe nínú ìbẹ̀rù Jèhófà, ìyẹn àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀.—1 Tímótì 6:6-8.
Sólómọ́nì tẹnu mọ́ ọn pé kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn ní èrè tó pọ̀ nínú ju ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun ìní lọ. Ó ní: “Oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.” (Òwe 15:17) Òótọ́ ni o, kí ìfẹ́ wà nínú ìdílé kan sàn ju ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ dídọ́ṣọ̀ lọ. Nínú ìdílé olóbìí kan, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sówó. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó lè jẹ́ oúnjẹ tí kò gbówó lórí ni apá ẹnì kan máa ká láti rà. Àmọ́ nínú ìdílé tí ìfẹ́ àti aájò bá wà, àwọn tó wa níbẹ̀ máa ń láyọ̀.
Kódà nínú àwọn ìdílé tí wọ́n ti máa ń fìfẹ́ hàn síra wọn nígbà gbogbo, ìṣòro lè ṣẹlẹ̀. Ẹnì kan lára wọn lè sọ nǹkan kan tàbí ṣe ohun kan tó máa bí òmíràn nínú. Kí ni ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ ní láti ṣe? Òwe 15:18 sọ pé: “Ènìyàn tí ó kún fún ìhónú ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lọ́ra láti bínú ń mú aáwọ̀ rọlẹ̀.” Dídáhùn padà lóhùn pẹ̀lẹ́, láìfi ìbínú fèsì, yóò jẹ́ kí àlááfíà wà. A tún lè fi ìmọ̀ràn inú òwe yìí sílò nínú àwọn ipò mìíràn, títí kan nínú ìgbòkègbodò ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
“Ọ̀nà Tí A Gbé Sókè”
Òwe tó kàn báyìí jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni tí kò fetí sí ọgbọ́n àtàwọn tó ń fetí sí i. Ọlọ́gbọ́n ọba náà sọ pé: “Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí ọgbà ẹ̀gún ọ̀gàn, ṣùgbọ́n ipa ọ̀nà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ọ̀nà tí a gbé sókè.”—Òwe 15:19.
Ọgbà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ ọgbà ẹlẹ́gùn-ún, ohun ìdènà ló sì jẹ́. Kò sí oríṣiríṣi ohun ìdènà tí ọ̀lẹ èèyàn kì í finú rò tán, á sì wá máa lò wọ́n bí àwáwí pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni kò jẹ́ kóun lè dáwọ́ lé àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Àmọ́, àwọn adúróṣánṣán èèyàn kì í bẹ̀rù àwọn ohun ìdènà tó lè ṣèdíwọ́ fún wọn. Wọ́n máa ń tẹpá mọ́ṣẹ́ wọn, wọ́n sì máa ń gbájú mọ́ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n kì í ní ọ̀pọ̀ ìṣòro tó lè dà bí ẹ̀gún tí ì bá dojú kọ wọ́n ká ní wọ́n jẹ́ ẹni tí kò bìkítà. Ọ̀nà wọn jẹ́ èyí tí “a gbé sókè,” ìyẹn ni pé, ó ń tẹ̀ síwájú. Wọ́n máa ń dáwọ́ lé iṣẹ́ wọn, inú wọ́n sì máa ń dùn bí wọ́n ti ń rí i pé iṣẹ́ náà ń tẹ̀ síwájú.
Wo níní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti dídẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan. Èyí gba ìsapá. Ó rọrùn kí ẹnì kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwáwí pé nítorí pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ lọ sílé ìwé, nítorí pé òun ò mọ̀wé kà dáadáa, tàbí pé òun kì í fi bẹ́ẹ̀ rántí nǹkan ni kò jẹ́ kóun máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ì bá mà dára o, láti má ṣe máa wo irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ṣèdíwọ́ fún níní ìmọ̀! Kódà, bá a bá tiẹ̀ ní àwọn ìṣòro wọ̀nyí, a lè sapá láti dẹni tó mọ̀wé kà dáadáa ká sì sapá láti rí i pé à ń lóye ohun tá a bá kà, a tiẹ̀ lè máa lo ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Níní èrò tó tọ́ máa ń ranni lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ó sì ń jẹ́ ká lè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
Ohun Tó Ń Mú Kí “Baba Yọ̀”
Ọba Ísírẹ́lì yìí sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ọmọ ní ń mú kí baba yọ̀, ṣùgbọ́n arìndìn ń tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ̀.” (Òwe 15:20) Ǹjẹ́ inú àwọn òbí kì í dùn nígbà táwọn ọmọ wọn bá hùwà ọlọ́gbọ́n. Òótọ́ ni pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa fún wọn ní ìbáwí káwọn ọmọ náà lè jẹ́ ọmọ tó máa fún wọn láyọ̀. (Òwe 22:6) Kò sí àní-àní pé tọ́mọ kan bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, yóò máa fún àwọn òbí rẹ̀ láyọ̀! Àmọ́ ńṣe ni arìndìn ọmọ máa ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn òbí rẹ̀ nígbà gbogbo.
Ọlọ́gbọ́n ọba yìí tún lo “ayọ̀ yíyọ̀” lọ́nà mìíràn, ó ní: “Ìwà òmùgọ̀ jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀ lójú ẹni tí ọkàn-àyà kù fún, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni ẹni tí ń lọ tààrà.” (Òwe 15:21) Ẹ̀rín tí kò ní láárí ló máa ń pa àwọn tí ọkàn-àyà kù fún, fàájì tí kì í fúnni ní ojúlówó ayọ̀ ló sì máa ń múnú wọn dùn. Àmọ́, ẹni tó lóye mọ̀ pé dídi “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run” kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. (2 Tímótì 3:1, 4) Rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run ń ràn án lọ́wọ́ láti máa jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì ń mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Ṣe “Àṣeparí”
Fífi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò máa ń mú àǹfààní wá nínú àwọn ohun mìíràn tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa. Òwe 15:22 sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”
Ọ̀rọ̀ ìfinúkonú túmọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìdákọ́ńkọ́ táwọn kan jọ sọ tí wọn ò sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún ara wọn. Nínú Sáàmù 89:7, “àwùjọ tímọ́tímọ́” ni wọ́n pe ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ táwọn kan bára wọn sọ tinútinú. Ọ̀rọ̀ ìfinúkonú kì í ṣe kéèyàn kàn máa tàkurọ̀sọ, ó túmọ̀ sí pé kí tọ̀túntòsì bá ara wọn sọ ohun tó wà nínú ọkàn wọn gangan kí wọ́n sì sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gẹ́lẹ́. Tí ọkọ àti aya bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, tí àwọn òbí àtàwọn ọmọ náà sì ń ṣe bẹ́ẹ̀, àlááfíà àti ìṣọ̀kan á wà láàárín wọn. Àmọ́ tí kò bá sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ìbànújẹ́ àti ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa ń yọrí sí nínú ìdílé.
Nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó bọ́gbọ́n mu pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó sọ pé, “àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ yan irú ìtọ́jú tá a máa gbà, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu ká wádìí wò lẹ́nu dókítà méjì tàbí mẹ́tà, pàápàá tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn tó gbẹgẹ́?
A ò lè ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ bí níní ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn láti bójú tó àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Táwọn alàgbà bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ń mú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ gbogbo wọn lápapọ̀ lò, ‘àṣeparí máa ń wà.’ Kò tán síbẹ̀ o, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò alábòójútó kò gbọ́dọ̀ lọ́ra láti lọ bá àwọn alàgbà tó dàgbà jù wọ́n tí wọ́n sì nírìírí jù wọ́n lọ fún ìmọ̀ràn, àgàgà tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ bójú tó le díẹ̀.
Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn ‘Láyọ̀ Nínú Ìdáhùn Rẹ̀’
Àbájáde rere wo ló lè wá látinú ọ̀rọ̀ téèyàn ronú dáadáa kó tó sọ? Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ènìyàn ń yọ̀ nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23) Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn nígbà táwọn kan bá fi ìdáhùn wa tàbí ìmọ̀ràn wa sílò tí ohun tó dára sì tibẹ̀ yọ? Àmọ́ kí ìmọ̀ràn wa tó lè wúlò, ó gbọ́dọ̀ dá lórí ohun méjì kan.
Èkíní, ìmọ̀ràn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ìyẹn Bíbélì. (Sáàmù 119:105; 2 Tímótì 3:16, 17) Èkejì, àkókò tó tọ́ ló sì yẹ ká sọ ọ́. Kódà bí ọ̀rọ̀ kan bá tiẹ̀ jóòótọ́, tá a bá lọ sọ ọ́ lákòókò tí kò tọ́, ó lè ṣàkóbá. Bí àpẹẹrẹ, fífún ẹnì kan nímọ̀ràn láìtíì gbọ́ gbogbo ohun tí ẹni náà ní í sọ kò bọ́gbọ́n mu, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè ṣèrànwọ́. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, [ká sì] lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ”!—Jákọ́bù 1:19.
“Ipa Ọ̀nà Ìyè Wà Lókè”
Òwe 15:24 sọ pé: “Ipa ọ̀nà ìyè wà lókè fún ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, kí ó bàa lè yí padà kúrò nínú Ṣìọ́ọ̀lù nísàlẹ̀.” Ẹni tó ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà yóò jìnnà sí ọ̀nà tó lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ipò òkú. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ lọ́wọ́ sáwọn ìwà abèṣe bíi ṣíṣe ìṣekúṣe, lílo oògùn olóró, àti mímú ọtí ní àmupara, á sì tipa báyìí bọ́ lọ́wọ́ ikú àìtọ́jọ́. Ìyè ni ipa ọ̀nà rẹ̀ forí lé.
Àmọ́, wo bí ọ̀nà àwọn tí kò ní ìjìnlẹ̀ òye ṣe yàtọ̀ síyẹn: “Jèhófà yóò ya ilé àwọn tí ń gbé ara wọn ga lulẹ̀, ṣùgbọ́n yóò fi ààlà opó múlẹ̀. Àwọn ìpètepèrò ẹni búburú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn àsọjáde dídùn mọ́ni jẹ́ èyí tí ó mọ́. Ẹni tí ń jẹ èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ilé ara rẹ̀, ṣùgbọ́n olùkórìíra àwọn ẹ̀bùn [àbẹ̀tẹ́lẹ̀] ni yóò máa wà láàyè nìṣó.”—Òwe 15:25-27.
Ọba Ísírẹ́lì fi ọ̀nà tá a lè gbà yàgò fún ìdẹkùn kan tó wọ́pọ̀ hàn wá, ó ní: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn ẹni burúkú máa ń tú àwọn ohun búburú jáde.” (Òwe 15:28) Ìmọ̀ràn tí òwe yìí fún wa mà wúlò gan-an o! Àwọn ìdáhùn òpònú àti aláìnírònú téèyàn sọ jáde láìronú jinlẹ̀ kì í sábà yọrí sí nǹkan tó dára. Àmọ́ tá a bá gbé gbogbo ohun tó ṣeé ṣe kó wé mọ́ ọ̀ràn kan yẹ̀ wò, títí kan ipò àti èrò àwọn ẹlòmíràn, kò dájú pé a ó sọ ohun tá a máa padà wá kábàámọ̀ rẹ̀.
Kí wá ni èrè kéèyàn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run kó sì máa gba ìbáwí? Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà dáhùn, ó ní: “Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú, ṣùgbọ́n àdúrà àwọn olódodo ni ó máa ń gbọ́.” (Òwe 15:29) Ọlọ́run tòótọ́ kì í sún mọ́ àwọn èèyàn burúkú. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yí etí rẹ̀ kúrò nínú gbígbọ́ òfin, àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.” (Òwe 28:9) Àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́ lójú rẹ̀ lè bá a sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, tí ọkàn wọn á sì balẹ̀ gan-an pé yóò fetí sí àwọn.
Ohun Tó ‘Ń Mú Ọkàn Yọ̀’
Sólómọ́nì lo àfiwé kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ gan-an, ó ní: “Ìtànyòò ojú a máa mú kí ọkàn-àyà yọ̀; ìròyìn tí ó dára a máa mú àwọn egungun sanra.” (Òwe 15:30) Tí mùdùnmúdùn bá kún inú egungun, egungun á “sanra.” Èyí máa ń fún gbogbo ara pátá lókun ó sì ń mú ọkàn yọ̀. Bí ọkàn bá sì láyọ̀, á hàn lójú èèyàn. Irú àbájáde tí ìròyìn rere máa ń ní nìyẹn!
Ǹjẹ́ àwọn ìròyìn nípa bí ìjọsìn Jèhófà ṣe ń tàn kálẹ̀ yíká ayé kì í fún wa ní ìṣírí gan-an? Kò sí àní-àní pé mímọ̀ nípa gbogbo ohun tá à ń gbé ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn máa ń mú ká túbọ̀ fẹ́ kópa tó pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ìrírí àwọn tó fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run wọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn tòótọ́ máa ń mú ọkàn wa láyọ̀ gan-an. Níwọ̀n bí “ìròyìn rere láti ilẹ̀ jíjìnnà” ti ń fúnni láyọ̀ tó pọ̀ tó báyìí, ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa kọ ìròyìn tó pé pérépéré nípa ohun tá a ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká sì máa fi ìròyìn náà sílẹ̀!—Òwe 25:25.
‘Ìrẹ̀lẹ̀ Ló Ń Ṣáájú Ògo’
Ọba ọlọ́gbọ́n náà tún tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká máa gba ìbáwí ní onírúurú ọ̀nà tó bá gbà wá, ó sọ pé: “Etí tí ń fetí sí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ìyè a máa gbé láàárín àwọn ọlọ́gbọ́n. Ẹnikẹ́ni tí ń yẹ ìbáwí sílẹ̀ ń kọ ọkàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fetí sí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ń jèrè ọkàn-àyà.” (Òwe 15:31, 32) Ìbáwí tá a fi ń tọ́ni sọ́nà máa ń wọnú ọkàn ó sì máa ń ṣàtúnṣe ọkàn èèyàn, á jẹ́ kéèyàn dẹni tó ní làákàyè. Abájọ tó fi jẹ́ pé “ọ̀pá ìbáwí” ló ń mú ‘ìwà òmùgọ̀ tó dì sí ọkàn ọmọdékùnrin kúrò’! (Òwe 22:15) Ẹni tó bá ń tẹ́tí sí ìbáwí tún máa ń jèrè ọkàn tó dáa, ìyẹn ni pé èrò rere ló máa ń ní lọ́kàn tó fi ń ṣe nǹkan. Àmọ́ téèyàn bá ń kọ ìbáwí, ìyè ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń kọ̀ yẹn.
Ká sòótọ́, nínífẹ̀ẹ́ sí ìbáwí tí ọgbọ́n ń fúnni àti títẹ́wọ́ gbà á tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ máa ń ṣeni láǹfààní. Kì í ṣe ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtẹ̀síwájú, ayọ̀, àti àṣeyọrí nìkan lèyí máa fúnni, á tún fúnni ní ògo àti ìyè. Ọ̀rọ̀ tí Òwe 15:33 wá fi kádìí gbogbo rẹ̀ ni pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ ìbáwí síhà ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ògo.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí Òwe 15:1-15, wo Ilé Ìṣọ́ July 1, 2006, ojú ìwé 13 sí 16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Kí ìfẹ́ wà nínú ìdílé kan sàn ju kí ilé kún fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ aládùn lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bá ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lọ sílé ìwé, tá a bá ní èrò tó dára, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ọ̀rọ̀ ìfinúkonú túmọ̀ sí pé kí tọ̀túntòsì bá ara wọn sọ ohun tó wà nínú ọkàn wọn gangan kí wọ́n sì sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gẹ́lẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ǹjẹ́ o mọ bí ‘ìròyìn tó dára ṣe máa ń mú àwọn egungun sanra’?