“Ọgbọ́n Jẹ́ Fún Ìdáàbòbò”
ÒWE 16:16 sọ pé: “Níní ọgbọ́n, ó mà kúkú sàn ju wúrà o! Níní òye sì ni kí a yàn ju fàdákà.” Kí nìdí tí ọgbọ́n fi ṣe kókó tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Ọ̀nà wo ni ọgbọ́n gbà ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè?
Bá a bá ní ọgbọ́n tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ìyẹn ni pé tá a bá ní ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ náà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́. (Òwe 2:10-12) Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Òpópó àwọn adúróṣánṣán ni láti yí padà kúrò nínú ohun búburú. Ẹni tí ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́.” (Òwe 16:17) Bó ṣe rí nìyẹn o, ọgbọ́n a máa dá àwọn tó ní in nídè kúrò nínú ohun búburú, a sì máa pa wọ́n mọ́ láàyè! Ọ̀rọ̀ ṣókí tó bọ́gbọ́n mu tó wà nínú Òwe 16:16-33 jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu lè jẹ́ ká ní èrò tó dáa lọ́kàn, ká máa sọ̀rọ̀ tó dáa jáde lẹ́nu, ó sì tún lè jẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́.a
“Jẹ́ Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ẹ̀mí”
Jésù tí ìwé Òwe pè ní ọgbọ́n sọ pé: “Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn.” (Òwe 8:13) Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín ìgbéraga àti ọgbọ́n. A gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n hùwà ká sì ṣọ́ra ká má bàa dẹni tí ń yangàn tàbí ẹni tí ń ṣe fọ́ńté. Àgàgà bá a bá ti rọ́wọ́ mú nígbèésí ayé tàbí tá a bá ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ.
Òwe 16:18 kìlọ̀ fún wa pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” Wàá rántí ìfọ́yángá tó pabanbarì jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ rí, ìyẹn ni ìṣubú ọ̀kan lára àwọn ẹni ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, àmọ́ tó sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9) Ǹjẹ́ o rántí pé ó di onígbèéraga kó tó fọ́ yángá? Ohun tí Bíbélì ń sọ gan-an nìyẹn nígbà tó sọ pé ká má ṣe yan ẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn padà sípò alábòójútó nínú ìjọ nítorí “ìbẹ̀rù pé ó lè wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, kí ó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.” (1 Tímótì 3:1, 2, 6) Ẹ ò wá rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti rí i pé a ò ṣe ohunkóhun tó máa mú káwọn ẹlòmíì di agbéraga, káwa fúnra wa sì rí i pé a ò gba ẹ̀mí ìgbéraga láyè!
Òwe 16:19 sọ pé: “Ó sàn láti jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọlọ́kàn tútù ju láti pín ohun ìfiṣèjẹ pẹ̀lú àwọn tí ń gbé ara wọn ga.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì ìgbàanì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí bọ́gbọ́n mu. Ẹ̀mí ìgbéraga sún un láti gbé ère ràgàjì kan kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé òun alára ni ère yẹn dúró fún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló gbé ère yẹn sórí ibi gíga débi pé, ní ìnàró, ó ga tó mítà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tàbí ilé alájà mẹ́jọ. (Dáníẹ́lì 3:1) Ńṣe ni wọ́n fẹ́ kí ère gogoro yìí wà gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí àti àpẹẹrẹ ilẹ̀ Ọba Bábílónì táwọn èèyàn á máa wárí fún. Lóòótọ́ làwọn ohun àwòyanu bí irú ère yẹn, àtàwọn nǹkan bí òpó ìrántí, ilé gogoro tí wọ́n kọ́ sórí ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ilé àwòṣífìlà lè máa jọ àwọn èèyàn lójú, àmọ́ wọn ò jẹ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Onísáàmù kọrin pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” (Sáàmù 138:6) Ní tòdodo, “ohun tí ó ga fíofío láàárín àwọn ènìyàn jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.” (Lúùkù 16:15) Ó sàn kí Ọlọ́run “ṣamọ̀nà” wa “lọ pẹ̀lú àwọn ohun rírẹlẹ̀,” dípò ká jẹ́ kí “àwọn ohun gíga fíofío” gbà wá lọ́kàn.—Róòmù 12:16.
Máa Fi “Ìjìnlẹ̀ Òye” àti “Ìyíniléròpadà” Sọ̀rọ̀
Báwo ló ṣe yẹ kí ọgbọ́n tá a ní máa hàn nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ? Ọlọ́gbọ́n ọba náà dáhùn, ó ní: “Ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú ọ̀ràn yóò rí ire, aláyọ̀ sì ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà ni a ó pè ní olóye, ẹni tí ètè rẹ̀ sì dùn ń fi ìyíniléròpadà kún un. Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tí ó ni ín; ìbáwí àwọn òmùgọ̀ sì ni ìwà òmùgọ̀. Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”—Òwe 16:20-23.
Ọgbọ́n máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìjìnlẹ̀ òye àti ìyíniléròpadà sọ̀rọ̀. Lọ́nà wo? Ìdí ni pé ẹni tó bá gbọ́n á gbìyànjú láti máa wá “ohun tó dára” nínú ọ̀ràn, á sì “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Bó bá jẹ́ ibi táwọn ẹlòmíì dáa sí là ń wò, kò sí bá ò ṣe ní máa rí nǹkan rere sọ nípa wọn. Dípò tá a ó fi jẹ́ òǹrorò àti aríjàgbá, ńṣe ni ọ̀rọ̀ wa á máa dùn létí àwọn tó ń gbọ́ ọ, á sì máa yí wọn lérò padà. Bá a bá lè máa fi òye tó jinlẹ̀ mọ ipò tó yí àwọn míì ká, á máa ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n ṣe le tó àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbé e gbà kí wọ́n lè fara dà á.
Ọ̀rọ̀ tó fa ọgbọ́n yọ tún ṣe kókó bá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kì í ṣe nítorí ká kàn lè kó ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ sáwọn èèyàn lágbárí la ṣe ń kọ́ wọn. Àfojúsùn wa ni pé kí ohun tá à ń kọ́ wọn wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà táá yí wọn lérò padà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé kó máa bá a lọ nínú àwọn ohun tá a ti yí i “lérò padà láti gbà gbọ́.”—2 Tímótì 3:14, 15.
Ìwé An Expository Dictionary of New Testament Words, látọwọ́ W. E. Vine sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó dúró fún “yí lérò padà” túmọ̀ sí “mímú kí ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kan yí padà nípasẹ̀ ìfèròwérò tàbí nípa gbígbé ohun tó jẹ mọ́ ìwà ọmọlúwàbí yẹ̀ wò.” Ká tó lè ṣàlàyé tó máa yé ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ débi tó fi máa yí ọkàn rẹ̀ padà, a gbọ́dọ̀ fi òye tó jinlẹ̀ mọ bí olùgbọ́ wa ṣe ń ronú, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, ipò rẹ̀ àti irú ẹni tó jẹ́ látilẹ̀ wá. Báwo la ṣe lè nírú òye tó jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀? Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù dáhùn, ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Bá a bá bi ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa láwọn ìbéèrè kan, tá a sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó bá sọ, a ó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.
Ọ̀gá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó bá dọ̀rọ̀ ká yíni lérò padà. (Ìṣe 18:4) Kódà Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń ta kò ó gbà pé: “Kì í ṣe ní Éfésù nìkan, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo àgbègbè Éṣíà, [ni] Pọ́ọ̀lù yìí ti yí ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ lérò padà, tí ó sì ti yí wọn padà sí èrò mìíràn.” (Ìṣe 19:26) Ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù gbé ògo fún ara rẹ̀ nítorí pó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Kò ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ńṣe ló rí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe bí “ìfihàn ẹ̀mí àti agbára [Ọlọ́run].” (1 Kọ́ríńtì 2:4, 5) Ẹ̀mí Jèhófà máa ń ran àwa náà lọ́wọ́. Nítorí pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé, ó dá wa lójú pé á ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń sapá láti fi ìjìnlẹ̀ òye àti ìyíniléròpadà sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Abájọ tí wọ́n ṣe máa ń pe “ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà” ní “amòye”! (Òwe 16:21, Bibeli Mimọ) Láìṣe àní-àní, “kànga ìyè” ni ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ fáwọn tó ní in. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn arìndìn tí wọ́n máa ń ‘tẹ́ńbẹ́lú ọgbọ́n àti ìbáwí?’ (Òwe 1:7) Kí ni àbájáde kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gba ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i lẹ́ẹ̀kan, Sólómọ́nì sọ pé: “Ìbáwí àwọn òmùgọ̀ sì ni ìwà òmùgọ̀.” (Òwe 16:22) Wọ́n tún ń gba ìbáwí lọ́nà míì o, ó sì sábà máa ń jẹ́ nípa jíjẹ ìyà tó tó ìyà. Àwọn arìndìn tiẹ̀ tún lè fọwọ́ ara wọn ṣe ohun tó máa fa ìnira, ìtìjú, àìsàn tàbí ikú àìtọ́jọ́.
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì yìí ń sọ̀rọ̀ síwájú sí i nípa bí ọgbọ́n ṣe lè máa nípa lórí ohun tá à ń sọ, ó sọ pé: “Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.” (Òwe 16:24) Bí oyin ṣe máa ń dùn, tó sì máa ń ṣeé pebi kíákíá, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀rọ̀ dídùn ṣe lè fúnni níṣìírí kí wọ́n sì tuni lára. Oyin tún wúlò fún ìtọ́jú ara, ó ṣeé wo àwọn àrùn kan, ó sì dáa lára. Bákan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ dídùn; wọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.—Òwe 24:13, 14.
Ṣọ́ra fún ‘Ọ̀nà Tó Dà bíi Pé Ó Dúró Ṣánṣán’
Sólómọ́nì sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 16:25) Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún wa ká má bàa dẹni tó ń ro ìròkurò lọ́kàn, ká má sì ṣe máa ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run. A lè máa tọ ipa ọ̀nà kan tó dà bíi pé ó tọ̀nà lójú àwa aláìpé àmọ́ tó jẹ́ pé kò fibì kankan bá ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Síwájú sí i, Sátánì lè ṣagbátẹrù àwọn ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ débi pé èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé ikú lòpin rẹ̀.
Kò sí ọ̀nà míì tá a fi lè gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀tàn ju pé ká jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye, ká sì jẹ́ kí ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí ẹ̀rí ọkàn wa. Bó bá di pé kéèyàn ṣe ìpinnu nígbèésí ayé, ì báà jẹ́ nínú ọ̀ràn ìwà rere tàbí ọ̀ràn ìjọsìn tàbí àwọn ọ̀ràn mìíràn, àfi kẹ́ni tí ò bá fẹ́ máa gbé ara rẹ̀ gẹṣin aáyán yáa jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run nípa ohun rere àti búburú máa tọ́ òun sọ́nà.
‘Ẹnu Òṣìṣẹ́ Kára Ló Ń Sún Un Ṣiṣẹ́’
Ọlọ́gbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọkàn òṣìṣẹ́ kára ti ṣiṣẹ́ kára fún un, nítorí pé ẹnu rẹ̀ ti sún un tipátipá.” (Òwe 16:26) Ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé ebi tó ń pa òṣìṣẹ́ kan á mú kó ‘ṣiṣẹ́ kára’ láti rí oúnjẹ torí pé ebi á ‘sún un tipátipá,’ tàbí kó lé e léré láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá. Ìtumọ̀ Bibeli Mimọ kà pé: “Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e.” A lè torí oúnjẹ jára mọ́ṣẹ́, nítorí a ò fẹ́ kí ebi pa wá. Irú ìfẹ́ tá a ń ní fún oúnjẹ yìí ṣàǹfààní. Àmọ́ o, bó bá wá di pé àṣejù wọ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, tónítọ̀hún wá di oníwọra ńkọ́? Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹ̀ṣẹ́ná kékeré kan bọ́ sílẹ̀ tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ran igbó ńlá, tó wá déyìí tí apá ò ká mọ́. Bí àṣejù bá ti wọ ìfẹ́ téèyàn ní sí nǹkan, ó ti di ìwọra nìyẹn, aburú ló sì máa ń yọrí sí. Nípa báyìí, ṣe ni ọlọ́gbọ́n èèyàn á fiyè dénú láti lè máa kó ara rẹ̀ níjàánu lórí ohun tó dáa tó ń wù ú yẹn.
Má Ṣe “Rin Ọ̀nà Tí Kò Dára”
Ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde lè ba nǹkan jẹ́ bí iná ìléru. Nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàpèjúwe aburú tó wà nínú kéèyàn máa wá àṣìṣe àwọn ẹlòmíì kó sì máa wá sọ ọ́ kiri, ó sọ pé: “Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun ń hú ohun tí ó burú jáde, àti ní ètè rẹ̀, ohun kan wà tí a lè pè ní iná tí ń jóni gbẹ. Ènìyàn tí ń so ìpàǹpá ń rán asọ̀ jáde ṣáá, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ sì ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.”—Òwe 16:27, 28.
“Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun” ni ẹnikẹ́ni tó bá ń wá bó ṣe máa ba arákùnrin rẹ̀ lórúkọ jẹ́. Ńṣe la gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti máa wá ibi táwọn ẹlòmíì dáa sí, ká sì máa sọ ohun tó máa jẹ́ káwọn tó mọ̀ wọ́n máa wò wọ́n bí ẹni iyì. Ìhà wo ló wá yẹ ká kọ sáwọn tó ń sọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ láìdáa? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí fura sáwọn ẹlòmíì láìnídìí, ó lè da àárín ọ̀rẹ́ méjì rú, ó sì lè fa ìpínyà nínú ìjọ. Bá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a ò ní fetí sírú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.
Béèyàn bá fetí sí ọ̀rọ̀ ìtànjẹ, ó lè mú kéèyàn dẹni tó ń ṣe ohun tí kò tọ́. Sólómọ́nì sọ nípa irú ọ̀rọ̀ ìtànjẹ bẹ́ẹ̀ pé: “Ènìyàn tí ń hu ìwà ipá yóò sún ọmọnìkejì rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ó rin ọ̀nà tí kò dára. Ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò láti pète-pèrò àwọn ìpàǹpá. Ní kíká ètè rẹ̀ sínú, ṣe ni ó ń ṣe ibi ní àṣeparí.”—Òwe 16:29, 30.
Ǹjẹ́ ìwà ipá lè rá pálá wọnú ayé olùjọsìn tòótọ́? Wọ́n ti tan ọ̀pọ̀ lára àwọn olùjọsìn tòótọ́ jẹ lónìí láti dẹni tó ń “pète-pèrò àwọn ìpàǹpá.” Àwọn tá à ń sọ yìí ń ṣagbátẹrù ìwà ipá tàbí ká kúkú sọ pé àwọn fúnra wọn ń hùwà ipá. Bóyá la fi máa rí ẹnikẹ́ni láàárín wa tó máa fẹ́ hùwà ipá ní tààràtà. Bí wọ́n bá fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú wa lọ́wọ́ sí i ńkọ́? Ṣebí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni wọ́n ti tàn jẹ́ láti dẹni tó ń wo àwọn eré ìnàjú tàbí eré ìdárayá tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ. Kedere ni Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Bẹ́ẹ̀ ni o, ògidì ààbò ni ọgbọ́n tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu jẹ́ fún wa!
Kí la wá lè sọ nípa ẹni tó jẹ́ pé ọgbọ́n àti òye ló fi lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, tí kò sì “rìn ọ̀nà tí kò dára”? Kò sóhun tó dà bíi kéèyàn fi òdodo lo ilé ayé ẹ̀, ẹni iyì ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ á sì jẹ́ lójú Ọlọ́run. Òwe 16:31 sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”
Bá a bá tún fojú míì wò ó, kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí láti bínú sódì. Ìbínú Kéènì àkọ́bí Ádámù àti Éfà “gbóná gidigidi” sí àbúrò rẹ̀ Ébẹ́lì, ó sì ‘fipá kọlù ú, ó sì pa á.’ (Jẹ́nẹ́sísì 4:1, 2, 5, 8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan lè máa mú wa bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ rí i pé à ń kóra wa níjàánu. Òwe 16:32 sọ kedere pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.” Ọ̀lẹ lẹni tí ò bá lè kápá ìbínú rẹ̀, ó sì dájú pé ẹni náà kì í ṣe ọmọlúwàbí. Àléébù tó lè ‘sọ èèyàn dẹni tó ń rìn lọ́nà tí kò dára ni.’
Nígbà Tí ‘Gbogbo Ìpinnu Bá Wá Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà’
Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Orí itan ni a ń ṣẹ́ kèké lé, ṣùgbọ́n gbogbo ìpinnu tí a ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Òwe 16:33) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà gba ṣíṣẹ́ kèké láyè káwọn èèyàn bàa lè mọ ohun tó ń fẹ́. Wọ́n máa ń lo òkúta rogodo tàbí wàláà tí wọ́n fi igi gbẹ́ tàbí èyí tí wọ́n fi òkúta ṣe láti fi ṣẹ́ kèké. Wọ́n máa ń kọ́kọ́ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn mọ ohun tó fẹ́ lórí ọ̀ràn náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n á wá ju kèké náà sínu aṣọ tí wọ́n ṣẹ́ po, wọ́n á wá mú un jáde. Ohun tí èyí tí wọ́n mú jáde bá túmọ̀ sí ni wọ́n á gbà pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn ṣe.
Ní báyìí, Jèhófà kì í tipasẹ̀ kèké sọ ohun tó fẹ́ fáwọn èèyàn mọ́. Ohun tó fẹ́ ká máa ṣe ti wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, àfi ká yáa ní ìmọ̀ pípéye nípa ohun tó wà nínú Bíbélì. Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìjẹ́ pé a ka Ìwé Mímọ́.—Sáàmù 1:1, 2; Mátíù 4:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti jíròrò Òwe 16:1-15 nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2007, ní ojú ìwé 17 sí 20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kí nìdí tí ọgbọ́n fi sàn dáadáa ju wúra lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bó o bá wà lóde ẹ̀rí, kí ló máa mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ lè yíni lérò padà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun ń hú ohun tí ó burú jáde”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Béèyàn ò bá lè kápá ìbínú, ó lè mú kéèyàn dẹni tó n “rìn ọ̀nà tí kò dára”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìwà ipá lè tanni jẹ