KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù Sátánì?
Èéfín olóró kan wà tí wọ́n ń pè ní carbon monoxide irú èyí tó máa ń jáde nínú jẹnẹrétọ̀. Májèlé ni èéfín yìí, ó sì ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ibi tó burú sí ni pé kì í fu èèyàn lára rárá títí tá á fi wọni lára, tá a sì ṣọṣẹ́. Kò ṣe fojú rí, kò sì lóòórùn. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà téèyàn lè ṣe láti dáàbò bò ara rẹ̀ lọ́wọ́ èéfín gbẹ̀mígbẹ̀mí yìí. Ọ̀kan lára ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò ni aago ìdágìrì tó ń tani lólobó tí èéfín yìí bá ti wà nínú afẹ́fẹ́, àwọn náà á sì tètè gbéra sọ tó bá ti ké.
Bíi ti èéfín olóró yìí, ewèlè ẹ̀dá tí kò ṣe é fojú rí ni Sátánì, òun náà sì máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́. Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù rẹ̀ torí pé Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà àbáyọ fún wa. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára rẹ̀ yẹ̀ wò, ká sì rí bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa:
Òmìnira láti ṣe ìpinnu. Ìwé Jákọ́bù 4:7 sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Sátánì lágbára lóòótọ́, àmọ́, kò lè fipá mú ẹ ṣe ohun tí kò wù ẹ́. Bóyá tibí ni wàá ṣe tàbí tọ̀hún, ìpinnu yẹn dọwọ́ ẹ. Ìwé 1 Pétérù 5:9 sọ pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” Rántí pé Sátánì fi Jésù sílẹ̀ lẹ́yìn tó dẹ ẹ́ wò lẹ́ẹ̀mẹ́ta, tó sì rí i pé ìpinnu Jésù ṣe ṣàkó. (Mátíù 4:11) Ìwọ náà lè pinnu pé o kò ní gbà fún Sátánì.
Bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́. Ìwé Jákọ́bù 4:8 gbà wá níyànjú pé ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” Jèhófà dìídì nawọ́ àǹfààní yẹn sí ẹ pé kó o bá òun ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ o lè máa rò ó pé báwo lo ṣe fẹ́ ṣe é? Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ kó o ṣe ní pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì. (Jòhánù 17:3) Ohun tó o bá kọ́ nípa Jèhófà máa mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìfẹ́ tó o bá ní fún un ló máa sún ẹ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Jòhánù 5:3) Ìwé Jákọ́bù yẹn fi kún un pé bó o bá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Bàbá rẹ ọ̀run, ‘[Ọlọ́run] yóò sún mọ́ ẹ.’
Ààbò tí Ọlọ́run ń pèsè. Ìwé Òwe 18:10 kà pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé orúkọ Ọlọ́run dà bí oògùn téèyàn ṣe sára fún ààbò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run lè ké pè é nígbàkigbà tí wọ́n bá nílò ààbò rẹ̀.
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ìwé Ìṣe 19:19 sọ ohun kan tó jọni lójú nípa àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni nílùú Éfésù, ó ní: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] ẹyọ fàdákà.”a Gbogbo ohun èlò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò làwọn Kristẹni wọ̀nyẹn dà nù pátápátá láìka iye tó ná wọn sí. Àpẹẹrẹ nìyẹn jẹ́ fún àwa Kristẹni torí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ti wọnú onírúurú ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, wọ́n sì ti jingíri sínú àwọn àṣà ìbẹ́mìílò gbogbo. Kódà àwọn nǹkan téèyàn ò kà kún tẹ́lẹ̀ tàbí tí ò tó nǹkan ti wá léwu báyìí, ó sì lè mú káwọn ẹ̀mí èṣù máa dani láàmú. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká yẹ ara wa wò, ká sì kó àwọn nǹkan yìí dà nù láìka ohun tó lè ná wa sí.—Diutarónómì 18:10-12.
Rogelio tá a mẹ́nu kàn ní àkòrí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí kò kọ́kọ́ gbà pé Sátánì wà, àmọ́ lẹ́yìn àádọ́ta ọdún, ó tún èrò rẹ̀ pa. Òun fúnra rẹ̀ sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo gba Bíbélì kan. Ẹ̀kọ́ tí mo sì kọ́ nínú rẹ̀ jẹ́ kí n rí i pé Èṣù wà lóòótọ́. Ohun tí mo kọ́ ló ń ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi kó sí pańpẹ́ rẹ̀.”
“Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kì n rí i pé Èṣù wà lóòótọ́. Ohun tí mo kọ́ yìí ló ń ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi kó sí pańpẹ́ rẹ̀”
Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ kó o jí lọ́jọ́ kan kó o sì gbọ́ pé Sátánì ò sí mọ́? Ọjọ́ náà dínkan lónìí. Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa fi Èṣù tó ń ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà “sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́.” (Ìṣípayá 20:10) Àmọ́ iná gidi àti imí ọjọ́ kò lè ṣèpalára kankan fún ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣe é fojú rí yìí. Torí náà, adágún iná yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé. Ọjọ́ náà á mà lárinrin o fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run torí pé a ò tún ní gbúròó Sátánì mọ́ láé.
Ní báyìí, túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti àwọn ìlànà rẹ̀.b Fojú inú wo ìgbà yẹn tí gbogbo èèyàn á fi ìdùnnú ké jáde pé, “A dúpẹ́, Sátánì ò sí mọ́!”
a Tó bá jẹ́ pé ẹyọ fàdákà tá à ń sọ yìí jẹ́ owó dínárì Róòmù, a jẹ́ pé owó gọbọi làwọn ìwé tí wọ́n kó dà nù yẹn, torí iye rẹ̀ to owó iṣẹ́ téèyàn máa fi ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] ọjọ́ ṣe!
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Sátánì àti ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbẹ́mìílò, ka orí 10 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè béèrè ẹ̀dá kan lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá rí