Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣàìsàn Tó Báyìí?
JASON jẹ́ ọmọ ọdún 18 péré, àmọ́ ńṣe ló wá jọ pé gbogbo góńgó rẹ̀ nínú ìgbésí ayé ni ọwọ́ rẹ̀ kò lè tẹ̀. Ó ti retí láti ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristẹni kan, ṣùgbọ́n nígbà náà ni ó wá mọ̀ pé òun ní àrùn Crohn—ìṣiṣẹ́gbòdì aronilára kan tí kì í dẹwọ́, nínú ìfun. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, Jason ń ṣàṣeyọrí ní mímú ọ̀ràn rẹ̀ mọ́ra.
Bóyá ìwọ pẹ̀lú ń kojú àrùn lílekoko kan. Nínú ìtẹ̀jáde kan tí ó ṣáájú, Jí! ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìpèníjà tí àwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ dojú kọ.a Ní báyìí, jẹ́ kí a wá ṣàyẹ̀wò bí o ṣe lè ṣàṣeyọrí ní kíkojú ipò rẹ.
Ìmọ̀lára Èrò Orí Pé Nǹkan Yóò Dára
Ṣíṣàṣeyọrí nínú kíkojú àìlera èyíkéyìí kan níní ìmọ̀lára èrò orí pé nǹkan yóò dára. Bíbélì wí pé: “Ẹ̀mí ènìyàn lè fara da àrùn rẹ̀; ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí tí ìdààmú bá, ta ní lè mú un mọ́ra?” (Òwe 18:14, NW) Àwọn èrò àti ìmọ̀lára onísoríkọ́, àti elérò àìdára ń mú kí ìkọ́fẹpadà túbọ̀ ṣòro. Jason rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́.
Lákọ̀ọ́kọ́, Jason ní láti bá àwọn ìmọ̀lára òdì, bí ìbínú, tí ń mú un sorí kọ́, gbógun. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! nípa ìsoríkọ́ ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti máa ní ìmọ̀lára pé nǹkan yóò dára. Ní báyìí, mo ń gbìyànjú láti kojú ọjọ́ kan lẹ́ẹ̀kan.”b
Bákan náà ni Carmen, ọmọ ọdún 17, kọ́ láti máa ronú nípa apá dídára inú ipò rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àrùn fòníkúfọ̀larùn, ó ń ronú lórí àwọn ohun amúniláyọ̀ tí ó ní. Ó sọ pé: “Mo ronú nípa àwọn tí ipò wọn burú ju tèmi lọ, tí wọn kò sì lè ṣe àwọn ohun tí mo lè ṣe. Mo sì máa ń kún fún ìmoore, tí n kì í banú jẹ́ púpọ̀ nítorí ipò mi.”
Òwe 17:22 (NW) sọ pé: “Ọkàn àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” Àwọn kan lè ronú pé ẹ̀rín kò bágbà mu lójú àìlera lílekoko. Àwọn ìpanilẹ́rìn-ín gbígbámúṣé àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin ń tu ọkàn rẹ lára, ó sì ń ṣàlékún ìfẹ́ inú rẹ láti wà láàyè. Ní gidi, ayọ̀ jẹ́ ànímọ́ ìwà-bí-Ọlọ́run, ọ̀kan lára àwọn èso ẹ̀mí Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22) Ẹ̀mí yẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ayọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ń bá àìlera kan wọ̀jà.—Orin Dáfídì 41:3.
Rírí Dókítà Kan Tó Lóye
Ó ṣèrànwọ́ gidigidi láti ní dókítà kan tí ó lóye àwọn ọ̀dọ́. Àwọn àìní ti èrò orí àti ti ìmọ̀lára ọ̀dọ́ kan sábà máa ń yàtọ̀ sí ti àgbàlagbà kan. Ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni Ashley nígbà tí ó lọ sílé ìwòsàn fún ìtọ́jú kókó ọlọ́yún aṣèpalára kan nínú ọpọlọ. Dókítà tí ó tọ́jú Ashley ṣe bẹ́ẹ̀ tìyọ́nútìyọ́nú lọ́nà tí ó lè lóye. Ó sọ bí àìsàn tí ó ṣe òun náà nígbà ọmọdé ṣe sún òun láti di dókítà. Ní pẹ̀lẹ́tù, ṣùgbọ́n lọ́nà ṣíṣekedere, ó ṣàlàyé ọ̀nà ìṣètọ́jú tí wọ́n fẹ́ lò fún un, nítorí náà, ó mọ ohun tí ó ní láti máa retí.
Ìwọ àti àwọn òbí rẹ yóò fẹ́ láti ṣàwárí onímọ̀ ìṣègùn tí yóò buyì fún ọ, tí yóò sì lóye àìní rẹ. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé, nítorí ìdí kan, ìtọ́jú tí o ń rí gbà kò tù ọ́ lára tó, má fòyà láti sọ àníyàn rẹ fún àwọn òbí rẹ.
Sapá Gidigidi Nítorí Ìlera Rẹ!
Ó tún ṣe kókó pé kí o bá àìlera rẹ gbógun ní gbogbo ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe fún ọ. Bí àpẹẹrẹ, kọ́ nípa gbogbo ohun tí o bá lè mọ̀ nípa ipò rẹ. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ . . . ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.” (Òwe 24:5, NW) Ìmọ̀ ń mú ìbẹ̀rù nípa ohun tí a kò mọ̀ kúrò.
Láfikún sí i, ọ̀dọ́ tí ó nímọ̀ lè túbọ̀ kópa nínú ìtọ́jú ara rẹ̀, ó sì wà ní ipò sísànjù láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ṣíṣe é. Bí àpẹẹrẹ, ó lè kẹ́kọ̀ọ́ pé òun kò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ lílo egbòogi tí a kọ fún òun láìjẹ́ pé dókítà sọ bẹ́ẹ̀. Carmen, tí a mẹ́nu bà lókè, ka àwọn ìwé lórí àrùn fòníkúfọ̀larùn, àwọn òbí rẹ̀ pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí wọ́n kọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba ìtọ́jú tí ó ṣàǹfààní jù lọ fún Carmen.
Béèrè àwọn ìbéèrè pàtó lọ́wọ́ dókítà rẹ—bí ó bá pọn dandan, béèrè ju ẹ̀ẹ̀kan lọ—bí ọ̀ràn kankan kò bá yé ọ. Kàkà kí o máa sọ ohun tí o rò pé dókítà ń fẹ́ gbọ́, ṣàlàyé èrò rẹ àti ìmọ̀lára rẹ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, “àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.”—Òwe 15:22, NW.
Ní àárín kan, ó jọ pé Ashley kì í jíròrò àìlera rẹ̀. Ìyá rẹ̀ nìkan ló ń bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ọlọgbọ́n òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan bi í níkọ̀kọ̀ pé: “Ǹjẹ́ o rò pé bóyá wọ́n ń fi ohun kan pa mọ́ fún ọ?” Ashley finú hàn án pé òun rò bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, obìnrin náà fi àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìlera Ashley hàn án, ó sì ṣàlàyé wọn fún un. Ó tún rọ àwọn dókítà náà pé kí wọ́n máa bá Ashley sọ̀rọ̀ ní tààrà dípò wíwulẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún Ashley láti rí ìrànlọ́wọ́ tí ó nílò gbà nípa sísọ ti ọkàn rẹ̀ jáde níkẹyìn.
Ìtìlẹ́yìn Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Tó Yí Ọ Ká
Nígbà tí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé bá ń ṣàìsàn gidigidi, ó ń di bùkátà ìdílé, tí ń gba ìsapá àjùmọ̀ṣe. Àwọn ẹbí Ashley àti ìjọ Kristẹni gbárùkù tì í. A ń rán ìjọ náà létí látìgbàdégbà pé ó wà ní ilé ìwòsàn. Àwọn mẹ́ńbà ìjọ ń bẹ̀ ẹ́ wò déédéé, wọ́n sì ń bá ìdílé náà ṣe iṣẹ́ ilé àti ìgbọ́únjẹ títí dìgbà tí ìdílé náà lè pa dà máa ṣe àwọn nǹkan déédéé. Àwọn ọmọdé nínú ìjọ bẹ Ashley wò nílé ìwòsàn, nígbà tí àìsàn rẹ̀ kò burú jù láti ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́. Ashley nìkan kọ́ ni èyí dára fún, ó dára fún àwọn ọ̀dọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú.
Bí o ti wù kí ó rí, kí àwọn mìíràn tó lè ṣèrànwọ́ fún ọ, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé o nílò rẹ̀. Carmen fojú sọ́nà fún ìtìlẹ́yìn ní ti ìmọ̀lára àti tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ àti àwọn alàgbà ìjọ. Ó tún fojú sọ́nà pé àwọn tí wọ́n bá a ṣàjọpín àwọn ìgbàgbọ́ Kristẹni kan náà nílé ẹ̀kọ́ yóò ṣètìlẹ́yìn. Carmen wí pé: “Wọ́n ṣàníyàn nípa mi, mo sì nímọ̀lára pé a bìkítà nípa mi.”
Ó ṣeé ṣe kí ilé ẹ̀kọ́ rẹ pèsè ìmọ̀ràn wíwúlò nípa ìṣègùn àti ọ̀ràn ìṣúnná owó, ó sì tilẹ̀ lè fún ọ ní ìtìlẹ́yìn ara ẹni díẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, olùkọ́ Ashley fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ níṣìírí láti kọ̀wé sí Ashley, kí wọ́n sì ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àwọn olùkọ́ rẹ kò bá mọ àwọn ìṣòro tí o dojú kọ, ó lè pọn dandan fún àwọn òbí rẹ láti bá àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà jíròrò ipò rẹ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
Fọgbọ́n Lo Èrò Inú àti Ara
Bí o bá ń ṣàìsàn gidigidi, o lè má lè ṣe ohunkóhun ju kí o pọkàn pọ̀ sórí gbogbo okun tí o nílò láti sàn. Bí kò bá jẹ́ pé ó tán ọ lókun pátápátá, ọ̀pọ̀ ohun níníyelórí wà tí o lè ṣe. Òǹkọ̀wé Jill Krementz sọ nípa ohun tí ó kíyè sí nígbà tí ó ń ṣèwádìí lórí ìwé rẹ̀ náà, How It Feels to Fight for Your Life, pé: “Ó ti bà mí nínú jẹ́ gidigidi láti lo ọdún méjì ní rírìn kiri ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé ìwòsàn, kí n sì máa rí àwọn ọmọdé púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ń ranjú mọ́ tẹlifíṣọ̀n. Ó yẹ kí a fún àwọn èwe wọ̀nyí níṣìírí láti kàwé púpọ̀ sí i. Orí ibùsùn ilé ìwòsàn jẹ́ ibì kan tí ó dára jù lọ láti fún ọpọlọ ẹni níṣẹ́ ṣe.”
Ì báà jẹ́ ilé lo wà tàbí ilé ìwòsàn, lílo agbára èrò orí rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà láti túbọ̀ mú ara yá. Ǹjẹ́ o ti gbìyànjú láti kọ lẹ́tà tàbí ewì bí? Yíyàwòrán tàbí kíkùn wọ́n ń kọ́? Bí ipò rẹ bá fàyè gbà á, kíkọ́ láti lo ohun èlò ìkọrin kan ńkọ́? Kódà, nígbà tí ìlera ẹni bá láàlà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí a lè ṣe. Dájúdájú, ohun dídára jù lọ tí o lè ṣe ni kí o mú àṣà gbígbàdúrà sí Ọlọ́run àti kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, dàgbà.—Orin Dáfídì 63:6.
Bí ipò rẹ bá fàyè gbà á, ìgbòkègbodò ìlokunra yíyẹ pẹ̀lú lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ara yá. Nítorí ìdí yìí ni àwọn ilé ìwòsàn fi máa ń ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwòsàn onídàárayá fún àwọn ọ̀dọ́ olùgbàtọ́jú. Nínú ọ̀ràn púpọ̀, kì í ṣe pé eré ìmárale yíyẹ ń gbé ìwòsàn ara lárugẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń ṣèrànwọ́ láti gbé ẹ̀mí rẹ lárugẹ.
Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!
Lójú ìjìyà gígalọ́lá, Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó gbẹ́kẹ̀ lé E, ó sì pọkàn pọ̀ sórí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ kàkà kí ó jẹ́ lórí ìrora náà. (Hébérù 12:2) Ó kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ipò onírora rẹ̀. (Hébérù 4:15, 16; 5:7-9) Ó tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí. (Lúùkù 22:43) Ó pọkàn pọ̀ sórí ire àwọn ẹlòmíràn, kàkà kí ó jẹ́ lórí àìfararọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀.—Lúùkù 23:39-43; Jòhánù 19:26, 27.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè máa ṣàìsàn gidigidi, ìwọ pẹ̀lú lè jẹ́ agbára ìsúnniṣe kan fún àwọn ẹlòmíràn. Nínú ìròyìn kan tí Abigail, ẹ̀gbọ́n Ashley, kọ nílé ẹ̀kọ́, ó wí pé: “Ẹni tí ó jọ mí lójú jù lọ ni àbúrò mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó máa ń lọ sílé ìwòsàn, ó ń gba egbòogi sára, ó sì ń gbabẹ́rẹ́ púpọ̀, síbẹ̀, tẹ̀ríntẹ̀rín ni!”c
Jason kò tí ì jáwọ́ lára àwọn góńgó rẹ̀, ó wulẹ̀ ṣàtúntò wọn lọ́nà kan ni. Góńgó tí ó ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ fún àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí o má lè ṣe gbogbo ohun tí o fẹ́, bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ti Jason. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé kí o kọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí agbára rẹ mọ, kí o má ṣe kẹ́ra rẹ jù tàbí lora rẹ jù. Gbára lé Jèhófà láti fún ọ ní ọgbọ́n àti okun kí o lè ṣe bí o bá ti lè ṣe dáradára tó. (Kọ́ríńtì Kejì 4:16; Jákọ́bù 1:5) Sì rántí pé, àkókò náà yóò dé, nígbà tí ilẹ̀ ayé yìí yóò jẹ́ párádísè kan, níbi tí “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́jọ́ kan, ìwọ yóò ní ìlera lẹ́ẹ̀kan sí i!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1991, ojú ìwé 15; March 1, 1990, ojú ìwé 3 sí 9; àti Jí!, April 22, 1988, ojú ìwé 2 sí 16; May 8, 1988, ojú ìwé 12 sí 16.
c Tún wo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ojú ìwé 116 sí 127.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìgboyà Ashley jọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Abigail, lójú