Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáwọ́ Dídámilẹ́bi Nígbà Gbogbo Dúró?
“Wọ́n sábà máa ń dá mi lẹ́bi ohun gbogbo. Bí a kò bá tilẹ̀kùn ilé tàbí tí a kò paná àdògán, tàbí tí a gbé ohun kan síbi tí kò yẹ, tàbí tí a fi ohun kan sílẹ̀ láìṣe, ẹ̀bi Ramon ni!”—Ramon.
NÍGBÀ tí o wà ní ọ̀dọ́langba, ó lè fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bíi pé ìwọ ni a máa ń dá lẹ́bi ohun gbogbo tí kò bá tọ́. Nínú àpilẹ̀kọ kan tí a kọ tẹ́lẹ̀, a gbà pé àwọn òbí máa ń yára jù nígbà míràn láti dá àwọn ọmọ wọn lẹ́bi.a Àwọn ohun tí ń fa èyí lè bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbìkítà òbí lọ́nà títọ́ dé orí wàhálà ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí òbí ní. Ohun yòó wù kí ó fà á, dídá ọ lẹ́bi nítorí àwọn ohun tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ lè dùn ọ́, kí ó sì tẹ́ ọ lógo.
Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, ìwọ yóò máa ṣe àṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Róòmù 3:23) Láfikún sí i, nítorí tí o jẹ́ ọ̀dọ́, o kò nírìírí púpọ̀ tó. (Òwe 1:4) Ó ṣeé ṣe kí o máa ṣe àṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nínú ìpinnu rẹ. Nítorí náà, nígbà tí o bá ṣe àṣìṣe, ó wulẹ̀ tọ́, ó sì bọ́gbọ́n mu pé kí a dá ọ lẹ́bi.—Oníwàásù 11:9.
Nígbà náà, báwo ni ó ṣe yẹ kí o hùwà pa dà nígbà tí a bá dá ọ lẹ́bi nítorí ohun kan tí o ṣe ní gidi? Àwọn èwe kan ń gbìyànjú láti ṣe bíi pé a wulẹ̀ ń fi ìyà ńlá kan jẹ wọ́n láìtọ́ ni. Wọ́n ń kígbe, wọ́n sì ń fẹ̀fun gbòò pé nígbà gbogbo ni àwọn òbí àwọn máa ń dá àwọn lẹ́bi lórí gbogbo nǹkan. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àwọn òbí tí a já kulẹ̀ ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó túbọ̀ le sí i láti jẹ́ kí àwọn ọmọ náà lóye. Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn yí pé: “Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú. Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:7, 8, NW) Nígbà tí o bá ń jẹ́wọ́ àwọn ìṣìnà rẹ, tí o sì ń ṣe àwọn ìyípadà yíyẹ, o lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe rẹ.—Hébérù 12:11.
Bíbá Àwọn Òbí Sọ “Ọ̀rọ̀ Ìfinúkonú”
Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀ràn míràn pátápátá ni bí a bá ń dá ọ lẹ́bi lórí àwọn ohun tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ tàbí tí ìdálẹ́bi náà kò dẹwọ́. Lọ́nà tí ó lè yéni, o lè bínú, kí o sì máa fìbínú hàn. O tilẹ̀ lè ní ìdẹwò láti ṣìwà hù, ní ríronú pé kò kúkú sí èyí tí o ṣe tí a kò ní dá ọ lẹ́bi. (Oníwàásù 7:7) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìwà ìpẹ̀gàn ń pa ẹni gbogbo lára. (Fi wé Jóòbù 36:18.) Òwe 15:22 (NW) tọ́ka sí ọ̀nà tí ó sàn jù láti gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn, ní wíwí pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀nà kan láti yí bí àwọn òbí rẹ ṣe ń hùwà sí ọ pa dà ni láti jẹ́ kí wọ́n mọ ìmọ̀lára rẹ.
Lákọ̀ọ́kọ́, wá ohun tí Bíbélì pè ní “àkókò yíyẹ.” (Òwe 15:23, NW) Òǹkọ̀wé Clayton Barbeau dámọ̀ràn pé: “Yan àkókò kan àti ibì kan tí ara tu kálukú, tí ọkàn gbogbo yín sì balẹ̀.” Síwájú sí i, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1, NW) Nítorí náà, gbìyànjú láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti abọ̀wọ̀fúnni nínú ọ̀nà tí o ń gbà sọ̀rọ̀, má ṣe jẹ́ aríjàgbá. Yẹra fún bíbínú. (Òwe 29:11) Dípò gbígbéjà ko àwọn òbí rẹ (‘Nígbà gbogbo ni ẹ máa ń dá mi lẹ́bi fún gbogbo nǹkan!’), gbìyànjú láti ṣàlàyé bí dídá tí wọ́n ń dá ọ lẹ́bi léraléra ṣe máa ń rí lára rẹ. (‘Ó máa ń bà mí nínú jẹ́ nígbà tí ẹ bá ń dá mi lẹ́bi nítorí àwọn nǹkan tí kì í ṣe ẹ̀bi mi.’)—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 30:1, 2.
A lè sọ ohun kan náà nípa àwọn àkókò tí àwọn òbí rẹ ń bínú nítorí àwọn èdè àìyédè kan. Àwọn òbí Jésù ọ̀dọ́ bínú nígbà kan tí wọn kò mọ bí ó ṣe rìn. Ṣùgbọ́n Jésù kò kùn, kò sì ṣàwáwí. Ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ipò náà. (Lúùkù 2:49) Èé ṣe tí o kò gbìyànjú láti hùwà bí àgbàlagbà sí àwọn òbí rẹ nígbà tí o bá ní ìṣòro? Mọ̀ pé inú ń bí wọn nítorí pé wọ́n bìkítà nípa rẹ! Fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Òwe 4:1) Fara balẹ̀ títí tí ìbínú wọn yóò fi rọlẹ̀ kí o tó ṣàlàyé ìhà tìrẹ nínú ọ̀ràn náà.
‘Fífi Ohun Tí Iṣẹ́ Rẹ Jẹ́ Hàn’
Ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwọn òbí kan fi máa ń yára dé orí ìpinnu tí kò tọ̀nà nípa àwọn ọmọ wọn? Ká sọ òótọ́, àwọn ọ̀dọ́ máa ń fún àwọn òbí wọn ní ìdí láti méfò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Òwe 20:11 (NW) sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Irú ìfùsì wo ni o ti ní lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ? Àwọn “ìṣe” rẹ ha fi ọ́ hàn bí ẹni tó “dúró ṣánṣán,” tí ó sì ní ìwà àgbà, tàbí aláìbìkítà, tí kò ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ bí? Bí ó bá jẹ́ èyí tí a sọ kẹ́yìn ni, máà jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bí wọ́n bá ń yára dórí ìpinnu tí kò tọ̀nà nípa rẹ. Nígbà tí Ramon, ọ̀dọ́kùnrin tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, ń sọ̀rọ̀ nípa àríwísí tí àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe, ó sọ pé: “Mo ní láti fúnra mi gbà láìṣàbòsí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òtítọ́ díẹ̀díẹ̀ máa ń wà nínú ìméfò wọn.”
Bí irú rẹ̀ bá jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ, ohun kan ṣoṣo tí o lè ṣe ni kí o ṣàtúnṣe tí a óò fi gbàgbé àwọn ohun búburú tí o ti ṣe sẹ́yìn. Nípa gbígbé ọ̀nà ìhùwà ẹni tí ó ṣeé fọkàn tán, tí ó sì ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ kalẹ̀, o lè mú un dá àwọn òbí rẹ lójú ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé o ti yí pa dà, o sì ṣeé fọkàn tán.
Ọ̀ràn ti Ramon ṣàpèjúwe kókó yìí. Lọ́nà àwàdà, àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ̀ fún un lórúkọ ìnagijẹ náà, ọ̀jọ̀gbọ́n aláìláfọkàn-sí, nítorí tí ó máa ń gbàgbé nǹkan. Ṣé àwọn òbí rẹ ti fún ọ lórúkọkórúkọ bí “aláìdàgbà-dénú” tàbí “aláìṣeé-fọkàn-tán”? Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Kathleen McCoy ṣe sọ, àwọn òbí lè rò pé irú orúkọ bẹ́ẹ̀ ń “tọ́ka ohun tí kò tọ́ jáde, kí ọ̀dọ́langba náà lè rí i, kí ó sì yí pa dà.” Ṣùgbọ́n, ní gidi, irú orúkọ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fa ìkórìíra jíjinlẹ̀ ni. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ramon wá mọ̀ pé orúkọ ìnagijẹ yẹn sọ kókó kan tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ó sọ pé: “Ọkàn mi ń wà lórí ohun kan nígbà gbogbo, tí mo ń sọ àwọn nǹkan bíi kọ́kọ́rọ́ tàbí iṣẹ́ àṣetiléwá mi nù, tí mo sì ń gbàgbé àwọn iṣẹ́ ilé.”
Nítorí náà, Ramon bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nípa ẹrù iṣẹ́ àti iṣẹ́ àkọ́múṣe. Mo ṣe ìwéwèé kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọwọ́ ìjẹ́pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ara ẹni. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fojú pàtàkì wo àwọn nǹkan kéékèèké bí ó ti ń wo àwọn nǹkan ńláńlá.” (Lúùkù 16:10) Nípa lílo àwọn ìlànà Bíbélì, Ramon ju ìfùsì gbígbàgbé nǹkan sílẹ̀ níkẹyìn. O kò ṣe gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà? Bí orúkọ tàbí orúkọ ìnagijẹ kan bá sì ń bí ọ nínú ní gidi, bá àwọn òbí rẹ jíròrò nípa rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n lóye bí ó ṣe ń nípa lórí rẹ.
Bí Ó Bá Jọ Pé Ojúsàájú Wà Níbẹ̀
Nígbà míràn, ó máa ń jọ pé ojúsàájú ló fa ìdálẹ́bi náà. Ramon sọ pé: “Àwọn ẹ̀gbọ́n mi lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń pẹ́ kí wọ́n tó wọlé, wọ́n sì ń mú un jẹ. Bí èmi bá pẹ́ kí n tó wọlé, mo dáràn.” Ọkùnrin ará Guyana kan tí ń jẹ́ Albert rántí pé òun ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nígbà tí òun ń dàgbà. Ó jọ lójú rẹ̀ pé màmá rẹ̀ máa ń bá a wí ju bí ó ti máa ń bá arákùnrin rẹ̀ wí lọ.
Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan kì í fìgbà gbogbo jẹ́ bí ó ti jọ. Àwọn òbí sábà máa ń fún àwọn ọmọ tó ti dàgbà ní ìwọ̀n òmìnira púpọ̀ sí i, kì í ṣe nítorí ojúsàájú, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí tí wọ́n rò pé àwọn ọmọ náà yóò hùwà àgbà. Tàbí ipò àrà ọ̀tọ̀ kan lè wà níbẹ̀. Albert gbà pé wọn kì í na arákùnrin òun nítorí pé ó “kéré, ara rẹ̀ kò sì dá.” Ó ha jẹ́ ìwà ojúsàájú fún àwọn òbí láti mọ àwọn àìní àrà ọ̀tọ̀ tí ọmọ kan ní tàbí ibi tí agbára rẹ̀ mọ lámọ̀jẹ́wọ́ bí?
Dájúdájú, àwọn òbí máa ń ní àwọn ààyò ọmọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 37:3.) Albert sọ nípa arákùnrin rẹ̀ tí ara rẹ̀ kò dá pé: “Mọ́mì ní ìfẹ́ni àrà ọ̀tọ̀ fún un.” Lọ́nà àrìnnàkore, ìfẹ́ Kristẹni ṣeé mú gbòòrò. (Kọ́ríńtì Kejì 6:11-13) Nítorí náà, ká tilẹ̀ ní àwọn òbí rẹ “ní ìfẹ́ni àrà ọ̀tọ̀” fún ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ, kò túmọ̀ sí pé kò ku ìfẹ́ kankan sílẹ̀ fún ìwọ. Ọ̀ràn náà ní gidi ni pé, Wọ́n ha ń ṣègbè nínú bí wọ́n ṣe ń hùwà sí ọ, tí wọ́n ń dá ọ lẹ́bi nítorí ìfẹ́ni aláìláàlà tí wọ́n ní fún ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ kan bí? Bí ó bá jọ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí, ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ kí wọ́n mọ èrò rẹ. Lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, tí ń fi ìgbatẹnirò hàn, fún wọn ní àwọn àpẹẹrẹ pàtó nípa bí o ṣe rò pé wọ́n ṣe ojúsàájú. Bóyá wọn yóò fetí sí ọ.
Àwọn Ìdílé Tó Níṣòro
A gbà pé kì í ṣe gbogbo ọ̀ràn ló rọrùn láti yí pa dà. Dídójútini àti dídánilẹ́bi ti di ara fún àwọn òbí kan. Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì láàárín àwọn òbí tí wọ́n ní ìṣòro ní ti ìmọ̀lára tàbí tí wọ́n ń bá àṣà bárakú kan jìjàkadì. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbìyànjú láti fi ìjíròrò yanjú ọ̀ràn lè má ṣàǹfààní púpọ̀. Bí ó bá jọ pé báyìí ni ọ̀ràn tìrẹ rí, mọ̀ pé ìṣòro àwọn òbí rẹ kọjá ohun tí apá rẹ ká, ó sì lè jẹ́ pé ìrànwọ́ láti ẹ̀yìn òde ìdílé ni yóò yanjú rẹ̀. Ohun dídára jù lọ tí o lè ṣe ni pé kí o máa fún wọn ní ọlá àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ wọ́n, kí o sì máà gbìyànjú láti yẹra fún ìforígbárí aláìnídìí. (Éfésù 6:1, 2) Òwe 22:3 (NW) sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”b
Nígbà kan náà, gba ìrànwọ́ díẹ̀ láti ẹ̀yìn òde ìdílé. Bá àgbàlagbà tó dàgbà dénú kan, bóyá tí ó jẹ́ Kristẹni alàgbà kan, sọ̀rọ̀. Àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe púpọ̀ láti kojú èrò náà pé àwọn nǹkan máa ń jẹ́ ẹ̀bi rẹ nígbà gbogbo. Nígbà kan náà, “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:8) Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn lè máa dá ọ lẹ́bi láìtọ́, “[Ọlọ́run] kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin. . . . Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Orin Dáfídì 103:9, 14) Mímọ̀ pé o ṣe iyebíye lójú Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti forí ti ìdálẹ́bi láìtọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Ó Fi Ń Jẹ́ Ẹ̀bi Mi Nígbà Gbogbo?” tí ó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti July 22, 1997.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Awọn Ọ́dọ́ Beere Pe . . . Bawo Ni Mo Ṣe Lè Kojúkápá Èébú Ẹnu?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti December 8, 1989. Tún wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, October 22, 1996.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Gbígba àwọn ìṣìnà wa ń jẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àṣìṣe wa