Kọ́kọ́rọ́ kan Sí Ìgbésí-ayé Ìdílé Aláṣeyọrísírere
“ANÍ ẹ̀ka ìdílé tí ń díbàjẹ́,” ni ẹnìkan tí ń jà fún ipò ààrẹ United States sọ ní ọdún tí ó kọjá. Nítòótọ́, ibi tí ìdílé díbàjẹ́ dé ń dáyàfoni. “Àwọn ìyípadà gígadabú bí èyí nínú àkọsílẹ̀ ìṣúnná-owó tàbí ti ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ la sáà àkókò kan-náà já,” ni ìwé-ìròyìn Fortune sọ, “yóò mú wa kọ háà fún ìyanu.”
Àní àwọn ìdílé tí wọ́n gbìyànjú láti tẹ̀lé àwọn ìlànà Bibeli pàápàá ni a sábà máa ń nípa lé lórí lọ́nà tí ó léwu. Ní ẹnu ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, bàbá àwọn ọmọ mẹ́fà kan tí ọjọ́-orí wọn kò tíì tó ọdún mẹ́tàlá ni Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó ní ọkàn rere sọ fún pé: “Ìwọ lè retí láti pàdánù mẹ́rin nínú àwọn ọmọ rẹ sínú ayé.” Síbẹ̀, bàbá yìí kò gbàgbọ́ pé èyí níláti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ òun pàápàá. Ó ṣàlàyé ìdí rẹ̀.
“Àwọn ọmọ wa kìí ṣe tiwa níti gidi,” ni ó sọ. “Jehofa Ọlọrun ni ó fi wọ́n sí ìkáwọ́ èmi àti aya mi, ‘ìní’ kan, tàbí ẹ̀bùn kan, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ó sì sọ pé bí a bá tọ́ wọn dàgbà ní ọ̀nà yíyẹ, ‘wọn kì yóò kúrò nínú rẹ̀.’ Nítorí náà a ti sábà máa ń gbìyànjú láti bójútó wọn bí ẹni pé Jehofa ni ó ni wọ́n.”—Orin Dafidi 127:3; Owe 22:6.
Bàbá yìí tọ́ka sí kọ́kọ́rọ́ kan sí ìgbésí-ayé ìdílé aláṣeyọrísírere níhìn-ín—àwọn òbí níláti bójútó àwọn ọmọ wọn bí ẹni pé wọ́n ń bójútó ohun-ìní Ọlọrun. Nígbà tí èyí kò túmọ̀sí pé àwọn ọmọ yóò kọbiara sí ìdarí rere rẹ nínú gbogbo ọ̀ràn, ìwọ ní ẹrù-iṣẹ́ náà láti bójútó àwọn ọmọ tí Ọlọrun ti fi sí ìkáwọ́ rẹ.
Ẹrù-Iṣẹ́ Wíwúwo Kan
Ìwọ ń pèsè àbójútó yìí lọ́nà yíyẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìdàníyàn jíjinlẹ̀, kìí ṣe pẹ̀lú ọwọ́ dẹngbẹrẹ tàbí ìdágunlá. Ìwọ ń ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú ìmọ̀dájú náà pé ìwọ yóò jíhìn fún Ọlọrun fún ogún-ìní, tàbí ẹ̀bùn rẹ̀, fún ọ. Kò pọndandan láti dán onírúurú ọ̀nà ìgbàtọ́mọ wò. Kìkì àwọn ìtọ́ni Ọlọrun nìkan ni àwọn òbí nílò gẹ́gẹ́ bí a ti pèsè rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, wọ́n sì níláti tẹ̀lé èyí tìṣọ́ra-tìṣọ́ra.
Ìtọ́ni Jehofa Ọlọrun nìyí: “Kí ìwọ kí ó sì máa fi [àwọn ọ̀rọ̀ mi] kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde. Kí ìwọ kí ó sì so wọ́n mọ́ ọwọ́ rẹ fún àmì, kí wọn kí ó sì máa ṣe ọ̀já-ìgbàjú níwájú rẹ. Kí ìwọ kí ó sì kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ, àti sára ilẹ̀kùn ọ̀nà-òde rẹ.” Bibeli tún rọni pé: “Ẹ̀yin baba, . . . ẹ máa tọ́ [àwọn ọmọ yín] nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.”—Deuteronomi 6:7-9; Efesu 6:4.
Nítorí náà bíbójútó àwọn ọmọ béèrè fún àfiyèsí ojoojúmọ́; bẹ́ẹ̀ni, ó túmọ̀sí fífún wọn ní àkókò rẹ ní fàlàlà àti ní pàtàkì ìfẹ́ àti ìdàníyàn rẹ jíjinlẹ̀. Àwọn òbí tí wọ́n bá fún àwọn ọmọ wọn ní àwọn ohun kòṣeémánìí wọ̀nyí ń ṣe ohun tí Ọlọrun sọ pé ó pọndandan kí wọ́n baà lè gbádùn ìgbésí-ayé ìdílé aláṣeyọrísírere.
Ìwọ ha gbàgbọ́ pé èyí jẹ́ bíbéèrè ohun púpọ̀ jù bí? Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ń fihàn nípa ìṣesí wọn pé àwọn nímọ̀lára pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Síbẹ̀, àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun—àwọn ọmọ rẹ—lẹ́tọ̀ọ́sí àkànṣe-àfikún àfiyèsí níti gidi.
Bí A Ṣe Lè Bójútó Wọn
Pẹ̀lú ọgbọ́n, ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn wọnnì tí wọ́n ti gbádùn àṣeyọrísírere nínú títọ́ ọmọ. Ìwé-ìròyìn kan, nínú ìtàn àkọlé ẹ̀yìn rẹ̀ “Àwọn Ìdílé Àgbàyanu,” ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan mẹ́rin tí ó ṣe pàtàkì nínú títọ́ àwọn ògo-wẹẹrẹ ní ọ̀nà tí ó yanjú: “[1] Ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àkókò oúnjẹ tí ń ru èrò-inú sókè, [2] kíka àwọn ìwé tí ó jíire, [3] agbára ìsúnniṣe àwọn àwòfiṣàpẹẹrẹ ọlọ́gbọ́n àtinúdá, [4] òye ìmọ̀lára náà pé àṣà ìdílé tí a níláti ṣètìlẹ́yìn fún wà.”—U.S.News & World Report, December 12, 1988.
Nípa “ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àkókò oúnjẹ,” rántí pé Ọlọrun pàṣẹ fún àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé. Ìdílé rẹ ha ń jókòó papọ̀ déédéé ní àkókò oúnjẹ bí, ní títipa báyìí pèsè àwọn àǹfààní fún ìfararora àti ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ń runisókè? Irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ ṣekókó wọ́n sì jẹ́ mánigbàgbé fún àwọn ọmọ, ní fífún wọn ní ìmọ̀lára ìwàdéédéé àti ààbò. Ọmọ ọlọ́dún mẹ́fà kan sọ pé òun fẹ́ràn àkókò oúnjẹ “nítorí pé ìwọ kò níláti ṣàníyàn nípa ẹnìkínní kejì,” níwọ̀n bí gbogbo wa ti wà papọ̀.
Kí ni nípa ti ìjójúlówó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àkókò oúnjẹ rẹ? Ó ha máa ń fìgbà gbogbo dá lórí àwọn ohun tí ó wà nínú “àwọn ìwé tí ó jíire,” tí ó ní nínú Bibeli àti àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ tí a gbékarí Bibeli tí ń jíròrò iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun tàbí àwọn ọ̀ràn tí o tanmọ́ ìṣẹ̀dá Ọlọrun bí? Ní àfikún sí ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àkókò oúnjẹ bí irú èyí, nípasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àwọn òbí níláti mú ìfẹ́ fún Jehofa àti àwọn òfin òdodo rẹ̀ dàgbà nínú àwọn ọmọ wọn.
“Jíjẹun papọ̀ déédéé kìí ṣe ìṣòro,” ni bàbá àwọn ọmọ mẹ́fà tí a mẹ́nukàn ṣáájú ṣàlàyé. “Èyí máa ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ́, ó sì ṣiṣẹ́ láti so wá pọ̀ ṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé ṣòro.” Nítorí àárẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára òòjọ́ lásán, òun nígbà mìíràn máa ń sùn ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Síbẹ̀, òun kò ṣíwọ́ láé láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé kan pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ó sì máa ń tẹ́tísílẹ̀ sí wọn fún sáà àkókò gígùn.
Yàtọ̀ sí mímú ipò iwájú nínú ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ àkókò oúnjẹ àti ṣíṣètò fún kíka àwọn ìwé tí ó jíire, ìwọ ha ń rí sí i pé àwọn ọmọ rẹ rí “agbára ìsúnniṣe àwọn àwòfiṣàpẹẹrẹ ọlọ́gbọ́n àtinúdá” gbà bí? Òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀ ni pé, ṣíṣètò fún àwọn ọmọ rẹ láti darapọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ń ṣàfarawé ọkùnrin títóbilọ́lá jùlọ tí ó tíì gbé ayé rí náà, Jesu Kristi, ṣekókó bí wọ́n bá níláti di àgbàlagbà tí ó ṣe àṣeyọrísírere.
Níkẹyìn, kí ni nípa ti “òye ìmọ̀lára náà pé àṣà ìdílé tí a níláti ṣètìlẹ́yìn fún wà”? Àwọn ọmọ rẹ níláti lóye pé àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìdílé wà tí a retí pé kí wọn ṣètìlẹ́yìn fún—pé irú àwọn ìwà, èdè, ìwọṣọ, ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kan, ni a kò tẹ́wọ́gbà tí wọ́n sì lòdìsí àṣà ìdílé. Wọ́n níláti mọ̀ dájú pé láti tẹ àṣà ìdílé lójú jẹ́ ọ̀ràn wíwúwo kan—pé inú yín yóò bàjẹ́ gidigidi, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú Jakobu baba àwọn Heberu ìgbàanì, tí àwọn ọmọdékùnrin rẹ̀ mú un di “òórùn nínú àwọn onílẹ̀” nípa ìwà adójútini wọn.—Genesisi 34:30.
Bàbá àwọn ọmọ mẹ́fà náà tí ó ka àwọn ọmọ rẹ̀ sí ohun-ìní Ọlọrun tẹnumọ́ “àṣà ìdílé” ní pàtàkì. Ó ń ronú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ déédéé lórí bí ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìdílé nípa ìwọṣọ, ìmúra, àti yíyàsọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ọ̀nà ayé ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí àti ìdarí Ẹlẹ́dàá náà, Jehofa Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìwọ̀n àkókò púpọ̀, ìfẹ́, àti ìdàníyàn tí a fifún wọn—ní dídi ẹni tí a tọ́ ní ọ̀nà tí wọn yóò tọ̀—àwọn ọmọ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà ti dáhùnpadà nípa ‘ṣíṣàì kúrò ní ojú ọ̀nà wọn.’—Owe 22:6.
Kárí-ayé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú àwọn ẹ̀ka ìdílé lílágbára bẹ́ẹ̀ ni ó wà. Ẹ wo irú ìyìn tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ sí Ẹlẹ́dàá wọn, ẹ sì wo irú èrè tí wọ́n jẹ́ fún àwọn òbí wọn aláìnímọtara-ẹni-nìkan, àti onífẹ̀ẹ́! Bí ọdún ti ń gorí ọdún, irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti jàǹfààní láti inú ìsapá wọn túbọ̀ ń mọrírì púpọ̀ púpọ̀ síi. Jọ̀wọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn tí ó tẹ̀lé e ti obìnrin kan tí àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run tọ́ dàgbà, kí o sì ṣàkíyèsí àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye tí a lè kọ́ láti inú rẹ̀.