Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
OCTOBER 3-9
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 ojú ìwé 180
Ìmọ̀
Orísun Ìmọ̀. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìmọ̀ ti wá. Òun ló dá gbogbo nǹkan, a kò lè mọ ohunkóhun tí kò bá sí ìwàláàyè. (Sm 36:9; Iṣe 17:25, 28) Síwájú sí i, torí pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, ohun tá a mọ̀ wá látara iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. (Iṣi 4:11; Sm 19:1, 2) Ọlọ́run ló tún mí sí Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ la ti lè kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe. (2Ti 3:16, 17) Torí náà, Jèhófà ni orísun gbogbo ìmọ̀. Ẹni tó bá sì fẹ́ ní ìmọ̀ gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, kó sì máa ṣọ́ra kó má báa ṣe ohun tó máa mú Jèhófà bínú. Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀. (Owe 1:7) Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà yìí, ó máa jẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye. Àmọ́, àwọn tí kò ka Ọlọ́run sí máa ń ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn ohun tí wọ́n ń rí.
OCTOBER 31–NOVEMBER 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 22-26
Títọ́ Àwọn Ọmọlúwàbí Dàgbà Ó Ha Ṣì Ṣeé Ṣe Bí?
ROBERT GLOSSOP ti Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìdílé ti Vanier ní Ottawa, Kánádà, sọ pé: “A ń gbé nínú àwùjọ kan tí ó díjú gidigidi, àwùjọ kan tí ó yàtọ̀ pátápátá, níbi ti ìlànà ìwà híhù kò ti ṣọ̀kan.” Kí ni ó yọrí sí? Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé: “Oyún àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ogún ọdún, ìwà ipá àwọn màjèṣín àti ìṣekúpara-ẹni ti àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ogun ọdún ń peléke sí i.”
Ìṣòro náà kò mọ sí Àríwá Amẹ́ríkà nìkan. Bill Damon, olùdarí Ibùdó fún Ìdàgbàsókè Ẹ̀dá Ènìyàn ní Yunifásítì Brown ní Erékùṣù Rhode, U.S.A., ti ṣèwádìí lórí àwọn ọ̀ràn yí ní Britain àti ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn ní Europe, àti ní Australia, Ísírẹ́lì, àti Japan. Ó tọ́ka sí bí ìtọ́sọ́nà tí ṣọ́ọ̀ṣì, ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn àjọ mìíràn ń pèsè fún àwọn èwe ṣe ń jó rẹ̀yìn. Ó gbà gbọ́ pé àwùjọ wa “kò mọ ohun tí àwọn ọmọ nílò láti ní ìwà ọmọlúwàbí, kí wọ́n sì dáńgájíá.” Ní títọ́ka sí àwọn ògbóǹkangí nínú títọ́ ọmọ, tí wọ́n ń fi kọ́ni pé “ìbáwí léwu fún ìlera àti ire àwọn ọmọ,” Damon tẹnu mọ́ ọn pé èyí jẹ́ “ìlànà fún títọ́ àwọn alágídí àti aláìgbọràn ọmọ dàgbà.”
Kí ni ohun tí àwọn èwe òde òní nílò? Wọ́n nílò ẹ̀kọ́ onífẹ̀ẹ́ tí ń tún èrò inú àti ọkàn àyà ṣe nígbà gbogbo. Èwe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílò ìbáwí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà ti ìfẹ́ bá sún wa, a lè báni wí nípa bíbáni sọ̀rọ̀. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí a fi sọ fún wa nínú Òwe 8:33 (NW) láti “fetí sí ìbáwí.” Ṣùgbọ́n, àwọn kan ń bẹ tí ‘kìkìdá ọ̀rọ̀ kò lè tọ́ sọ́nà láti mú kí wọ́n ṣàtúnṣe.’ Fún wọn, ó lè jẹ́ ìyà tí a fi jẹ wọ́n ní ìwọ̀n tí ó yẹ, tí ó tọ́ sí ìwà àìgbọràn wọn, ni ohun tí wọ́n ń fẹ́. (Òwe 17:10; 23:13, 14; 29:19, NW) Ní dídábàá yìí, kì í ṣe fífi ìbínú nani lẹ́gba tàbí líluni lálùbolẹ̀, tí ó lè dégbò sí ọmọ lára tàbí kí ó ṣe é léṣe, ni Bíbélì ń sọ. (Òwe 16:32) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ọmọ kan mọ ìdí tí a fi ń tọ́ ọ sọ́nà, kí ó sì mọ̀ pé ó jẹ́ nítorí pé òbí náà nífẹ̀ẹ́ òun.—Fi wé Hébérù 12:6, 11.
A tẹnu mọ́ irú ìmọ̀ràn Bíbélì, tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì múná dóko bẹ́ẹ̀ nínú ìwé náà Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
it-2 ojú ìwé 818 ìpínrọ̀ 4
Ọ̀pá Ìbáwí
Àṣẹ Òbí. “Ọ̀pá” tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpẹẹrẹ àṣẹ àwọn òbí lórí ọmọ wọn. Ìwé Òwe sọ púpọ̀ lórí àṣẹ yìí, ó sọ oríṣríṣi ọ̀nà láti gbà bá ọmọ wí, títí kan ọ̀pá tí wọ́n fi ń lu ọmọ. Ọlọ́run ló fún àwọn òbí ní àṣẹ láti lo ọ̀pá yìí, kí wọ́n lè fi darí ọmọ wọn. Òbí tí kò bá ṣe èyí máa mú ìparun àti ikú wá sórí ọmọ rẹ̀, á tún kó ìtìjú bá ara rẹ̀, kò sì ní rí ojúure Ọlọ́run. (Owe 10:1; 15:20; 17:25; 19:13) “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí; ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.” “Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọmọdékùnrin. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o fi ọ̀pá nà án, kì yóò kú. Kí ìwọ fi ọ̀pá nà án, kí o lè dá ọkàn rẹ̀ gan-an nídè kúrò lọ́wọ́ Ṣìọ́ọ̀lù.” (Owe 22:15; 23:13, 14) Kódà, “ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.”—Owe 13:24; 19:18; 29:15; 1Sa 2:27-36.