Bí o Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́
“OHUN ŃLÁ LO NÍ BÓO BÁ LỌ́RẸ̀Ẹ́ GIDI KAN JÁLẸ̀ ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ; AGBÁRA KÁKÁ LO FI LÈ NÍ MÉJÌ; Ó ṢÒRO KÓO TÓ NÍ MẸ́TA.”—Henry Brooks Adams.
IRÚ gbólóhùn báyìí ń fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣọ̀wọ́n. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mi ò lẹ́ni tí mo lè yíjú sí,” “Kò sẹ́ni tí mo lè finú tán,” tàbí “Ajá mi lọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi” la sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu àwọn èèyàn tó dá nìkan wà, tí wọ́n ń wá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ lójú méjèèjì.
Kì í ṣe ohun tó rọrùn láti lọ́rẹ̀ẹ́, kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ọ̀hún sì wà pẹ́ títí. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórí ọ̀ràn yìí fi hàn pé “ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára àwọn àgbàlagbà ni ìṣòro ‘ìdánìkanwà tó burú gidigidi’ ń bá jà, ní . . . ilẹ̀ Faransé sì rèé, ìdajì àwọn tó ń gbébẹ̀ ló ń kojú ìdánìkanwà tó burú jáì.” Bí àwọn ẹgbẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú dídá ọjọ́ àjọròde àti iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí kọ̀ǹpútà ti ń pọ̀ sí i, àti bí ìkéde àwọn tó ń fẹ́ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ṣe ń gba inú àwọn ìwé ìròyìn kan, jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn èèyàn ń yán hànhàn fún àjọṣe ẹ̀dá.
Dókítà David Weeks, tó jẹ́ onímọ̀ nípa àjọṣe ìhùwà, ọpọlọ àti ìrònú, sọ pé kì í ṣe ìrònú èèyàn nìkan ni dídá nìkan wà máa ń nípa lé lórí, ó tún ń nípa lórí ìlera ara pẹ̀lú. “Ọ̀pọ̀ jaburata àwọn aláìsàn tí mò ń tọ́jú nítorí àníyàn ọkàn àti ìsoríkọ́ ni mo lè sọ pé dídá nìkan wà ni ohun náà gan-an tó ń dà wọ́n láàmú. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìsoríkọ́ lílekoko fi jọra pẹ̀lú kéèyàn máà ní alábàárò kankan.”
Ìkọ̀sílẹ̀ àti bí ìdílé ṣe ń túká ń fi tipátipá mú kí àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i máa dá nìkan gbé ìgbésí ayé wọn. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kádìí ọ̀rọ̀ náà pé, tó bá fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, nǹkan bí ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè náà ló máa dẹni tó ń dá nìkan gbé.
Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan á gbayé kan. (2 Tímótì 3:1-5) Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé àwọn nǹkan ìní tara bí ilé tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ló jẹ́ góńgó lórí ẹ̀mí wọn, ju kí wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn lọ. Òǹkọ̀wé Anthony Storr sọ pé: “Dípò káwọn èèyàn pọkàn wọn pọ̀ sọ́dọ̀ ọkọ wọn tàbí aya wọn àti sórí àwọn ọmọ wọn, ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ni ọkàn wọn máa ń wà.”
Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ ṢEYEBÍYE
Bí o bá ṣe báni dọ́rẹ̀ẹ́ tó ni ìgbésí ayé rẹ ṣe máa nítumọ̀ tó. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ kì í láyọ̀ nítorí pé wọn ò lọ́rẹ̀ẹ́ tí wọ́n lè bá ṣàjọpín àwọn ohun tí wọn ní tàbí àwọn èrò ọkàn wọn. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, George Byron tún ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́ yìí sọ, ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹni bá fẹ́ ní ayọ̀, gbọ́dọ̀ fúnni láyọ̀.”
Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rẹ́? Ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣàlàyé ọ̀rẹ́ pé ó jẹ́ “àwọn tí ìfẹ́ so pọ̀ tímọ́tímọ́, tí èkíní sì ń buyì fún èkejì.” Ọ̀rẹ́ tòótọ́ lè ṣèrànwọ́ láti darí ìrònú rẹ sórí àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ó lè fún ẹ níṣìírí, kó tún gbé ẹ ró lákòókò tóo bá níṣòro. Ó tiẹ̀ tún lè bá ẹ pín nínú ìbànújẹ́ rẹ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ohun ìní tara kì í wúlò mọ́ bọ́jọ́ bá ti ń lọ lórí wọn, ńṣe lọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń lókun sí i tó sì máa ń gbèrú bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́.
Ìwé Mímọ́ gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ni wọn. (2 Kọ́ríńtì 6:13) Ọgbọ́n wà nínú kéèyàn sún mọ́ àwọn ẹlòmíràn. A kà nínú Oníwàásù 11:1, 2 pé: “Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i. Fi ìpín fún àwọn méje, tàbí fún àwọn mẹ́jọ pàápàá, nítorí ìwọ kò mọ ìyọnu àjálù tí yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” Báwo ni a ṣe lè lo ìlànà yìí nínú dídọ́rẹ̀ẹ́? Tóo bá ti bá ọ̀pọ̀ èèyàn dọ́rẹ̀ẹ́, díẹ̀ lára wọn lè wá ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tóo bá wà nínú ìṣòro.
Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tún jẹ́ ààbò fún ọ lọ́nà mìíràn. Òwe 27:6 sọ pé: “Àwọn ọgbẹ́ tí olùfẹ́ dá síni lára jẹ́ ti ìṣòtítọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìmọye èèyàn lè máa sọ̀rọ̀ ìyìn nípa rẹ lójú ẹ, ọ̀rẹ́ tòótọ́ nìkan ló lè mọyì ẹ débi tó máa lè sọ nípa àṣìṣe ńlá tóo ṣe fún ọ, tí yóò sì fún ọ ní ìmọ̀ràn tó lè mú ọ sunwọ̀n sí i pẹ̀lú ìfẹ́.—Òwe 28:23.
Àwọn ọ̀rẹ́ gidi, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ wà lára àwọn ẹ̀bùn tó ṣọ̀wọ́n, tí wọ́n lè nípa tó dára lórí rẹ. Nínú Ìṣe orí kẹwàá, a kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí ayé Kọ̀nílíù, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù, ẹni tí áńgẹ́lì kan sọ fún pé àwọn àdúrà rẹ̀ ni a ti gbọ́. Bí Kọ̀nílíù ti ń retí ìbẹ̀wò àpọ́sítélì Pétérù, ó “pe àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jọ.” Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí Kọ̀nílíù ní yẹn wà lára àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tó kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tí a sì fi ẹ̀mí yàn wọ́n, tí wọ́n sì ń fojú sọ́nà láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé ìbùkún lèyí jẹ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí Kọ̀nílíù ní!—Ìṣe 10:24, 44.
Àmọ́, báwo lo ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́? Bíbélì, ìwé tó sọ púpọ̀ nípa dídọ́rẹ̀ẹ́, fi àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ dáhùn ìbéèrè yìí. (Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.)
IBI TÓO TI LÈ YAN OJÚLÓWÓ Ọ̀RẸ́
Ibi tó dára jù lọ láti yan ojúlówó ọ̀rẹ́ ni inú ìjọ Kristẹni. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o lè lo àǹfààní tóo ní láti dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá rẹ àti Bàbá rẹ ọ̀run Jèhófà, àti pẹ̀lú Jésù Kristi tí í ṣe Olùgbàlà rẹ. Jésù, ẹni tó ń ké sí ọ láti wá di ọ̀rẹ́ òun sọ pé: “kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13, 15) Nípa dídọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù Kristi, wàá ní ìdánilójú pé wọn yóò ‘gbà ọ́ sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.’ Dájúdájú, dídọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Lúùkù 16:9; Jòhánù 17:3.
Báwo lo ṣe lè jèrè ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn onífẹ̀ẹ́? Àwọn ohun tí a ń béèrè láti jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú Sáàmù kẹẹ̀ẹ́dógún. Wò ó nínú Bíbélì, kóo sì ka ẹsẹ márààrún tí sáàmù yẹn ní. Ní àfikún sí i, Jésù Kristi sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.”—Jòhánù 15:14.
Dájúdájú, nípa fífi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí o sì ń fi ohun tóo ń kọ́ sílò, ńṣe lò ń fi hàn pé o fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà àti Jésù. Kí èyí tó lè rí bẹ́ẹ̀, o tún gbọ́dọ̀ máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, níbi táa ti ń fi ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run fúnni. Fi òótọ́ inú fetí sílẹ̀ sí Jèhófà, wàá rí i pé wàá túbọ̀ sún mọ́ òun àti Ọmọ rẹ̀ sí i.
Láwọn ìpàdé yẹn, o tún lè dojúlùmọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń fi àwọn èso tẹ̀mí bí—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu—hàn nínú ìgbésí ayé wọn. (Gálátíà 5:22, 23) Tó bá jẹ́ òótọ́ ló wà lọ́kàn ẹ láti dọ́rẹ̀ẹ́, tóo sì fẹ́ kí dídá nìkan wà wábi gbà, máa wá sáwọn ìpàdé Kristẹni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ńṣe ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kóo wà níbi tó tọ́ ní àsìkò tó tọ́ láti lè ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó ń wà pẹ́ títí pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run tí a bù kún.
ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÓ MÁA WÀ TÍTÍ AYÉ
Níní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ jẹ́ àgbàyanu ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Ó wá látinú àkópọ̀ ìwà rẹ̀ àti àwọn ànímọ́ rẹ̀. Nítorí ẹ̀mí ìfẹ́ àti ọ̀làwọ́ tó ní, ó fi àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tóo lè bá dọ́rẹ̀ẹ́ kún inú ayé fọ́fọ́. Máa bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ kẹ́gbẹ́. Fún wọn níṣìírí. Bá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Máa gbàdúrà pẹ̀lú wọn, kóo sì máa gbàdúrà fún wọn déédéé. Wàá tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣàfarawé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn kan tí gbogbo ènìyàn lè fúnni kí wọ́n sì tún rí gbà. Lọ́jọ́ iwájú tí ò ní pẹ́ mọ́, wàá láǹfààní láti mú káwọn ọ̀rẹ́ rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i. Wàá lè dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tó wà láàyè nísinsìnyí, àti àwọn ìràn tó ti wà nígbà kan rí, tí wọ́n sùn nínú ikú, tí wọ́n sì ń retí àjíǹde nígbà tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4; Jòhánù 5:28, 29) Sapá nísinsìnyí láti jẹ́ ẹni tára ẹ̀ yọ̀ méèyàn, kóo sì dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Máa wá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi nípa fífetí sí Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, o ò tún ní dá nìkan wà mọ́ títí láé.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
OHUN MẸ́FÀ TÓ Ń RANNI LỌ́WỌ́ LÁTI DỌ́RẸ̀Ẹ́ TÓ MÁA WÀ PẸ́ TÍTÍ
1. ÌWỌ FÚNRA RẸ Á JẸ́ Ọ̀RẸ́. Ábúráhámù ni a pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà” nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. (Jákọ́bù 2:23) Àmọ́ ìdí mìíràn tún wà. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù fi ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run hàn. (2 Kíróníkà 20:7) Ó lo àtinúdá rẹ̀ láti jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ nípa bí nǹkan ti rí lára òun. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20-33) Bẹ́ẹ̀ ni o, o ní láti lo ìdánúṣe láti fi ẹ̀rí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ hàn. Jésù wí pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.” (Lúùkù 6:38) Ọ̀rọ̀ ìṣírí kan táa sọ tàbí ìrànwọ́ kan táa ṣe lè jẹ́ ibi kékeré kan tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó lágbára ti máa bẹ̀rẹ̀. Aláròkọ ọmọ Amẹ́ríkà náà Ralph Waldo Emerson, sọ nígbà kan pé: “Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o fi lè ní ọ̀rẹ́ ni pé kí ìwọ náà jẹ́ ọ̀rẹ́.”
2. WÁ ÀKÓKÒ LÁTI DỌ́RẸ̀Ẹ́. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ló máa ń nífẹ̀ẹ́ sí àǹfààní tó wà nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́. Síbẹ̀, ọwọ́ wọn dí kọjá kí wọ́n rí àyè tí wọ́n máa fi ṣe bẹ́ẹ̀. Róòmù 12:15, 16 rọ̀ wá pé ká bá àwọn ẹlòmíràn pín nínú ayọ̀ àti àṣeyọrí wọn, ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀ wọn. Ó sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún. Irú èrò inú kan náà tí ẹ ní sí ara yín ni kí ẹ ní sí àwọn ẹlòmíràn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù Kristi jẹ́ ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ dí, ìgbà gbogbo ló ń rí àkókò fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Máàkù 6:31-34) Rántí o, pé ńṣe ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ dà bí ewéko tó máa ń yọ òdòdó, èyí táa gbọ́dọ̀ máa bomi rin ká sì máa tọ́jú rẹ̀ kó lè rú dáadáa—ìyẹn sì máa ń gba àkókò.
3. MÁA TẸ́TÍ SÍLẸ̀ NÍGBÀ TÁWỌN ẸLÒMÍRÀN BÁ Ń SỌ̀RỌ̀. Ọ̀rẹ́ níní sábà máa ń rọrùn fáwọn tó bá ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé, “kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Nígbà tóo bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, máa lọ́kàn ìfẹ́ sí bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. Fún wọn ní ìṣírí láti sọ̀rọ̀ nípa ara wọn. Ìwọ ni kóo kọ́kọ́ máa bọlá fún wọn. (Róòmù 12:10) Wàá rí i pé wọ́n á fẹ́ máa wà lọ́dọ̀ ẹ. Lọ́nà kejì ẹ̀wẹ̀, tó bá jẹ́ pé ìwọ nìkan lò ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀, tàbí kẹ̀ tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ara ẹ lo máa ń sọ ṣáá, á pẹ́ kóo tó rí ẹni tó máa ṣe tán láti tẹ́tí gbọ́ ẹ tàbí tó máa bìkítà nípa bí nǹkan ti rí lára ẹ àti nípa àwọn ìṣòrò rẹ.
4. MÁA DÁRÍ JINI. Jésù sọ fún Pétérù nígbà kan rí pé kó múra tán láti dárí jini “títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mátíù 18:21, 22) Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń tètè gbójú fo àwọn àṣìṣe kéékèèké dá. Fún àpẹẹrẹ: Àwọn kan kì í fẹ́ jẹ èso góbà nítorí àwọn kóró inú ẹ̀. Àmọ́ àwọn tó gbádùn jíjẹ èso yìí kì í tiẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn kóró náà. Àwọn ànímọ́ tó dára, èyí táwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ní la fi máa ń fẹ́ràn wọn; a sì máa ń gbójú fo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn dá. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kólósè 3:13) Àwọn tó mọ báa ti ń dárí jini kì í pàdánù àwọn ọ̀rẹ́ wọn.
5. FỌ̀WỌ̀ HÀN FÚN ÀKÓKÒ TÍ ÀWỌN MÌÍRÀN MÁA Ń FẸ́ LÁTI DÁ WÀ. Kò sẹ́ni tí kì í ní àwọn àkókò tó máa fẹ́ láti dá wà, títí kan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ náà. Òwe 25:17 ṣàlàyé tó bọ́gbọ́n mu pé: “Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣọ̀wọ́n ní ilé ọmọnìkejì rẹ, kí ọ̀ràn rẹ má bàa sú u, òun a sì kórìíra rẹ dájúdájú.” Nípa bẹ́ẹ̀, jẹ́ ọlọgbọ́n pẹ̀lú bóo ṣe ń ṣe lemọ́lemọ́ sí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti bí àkókò tóo fi ń bẹ̀ wọ́n wò ti gùn tó. Má rakaka lé wọn lórí, èyí tó lè yọrí sí owú jíjẹ. Lo òye nígbà tóo bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tóo fẹ́ràn àtàwọn èrò rẹ nípa àwọn kókó ọ̀ràn kan. Èyí máa ń fi kún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ń tuni lára tó sì gbádùn mọ́ni.
6. JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́. A máa ń ní ọ̀rẹ́ nípa jíjẹ́ ọ̀làwọ́. Ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni pé ká ‘jẹ́ aláìṣahun, ká múra tán láti ṣe àjọpín.’ (1 Tímótì 6:18) Fún àpẹẹrẹ, máa ṣàjọpín ọ̀rọ̀ tí ń fúnni níṣìírí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Òwe 11:25) Máa sọ ọ̀rọ̀ ìyìn tó tọkàn wá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró fàlàlà. Nígbà tóo bá fi ojúlówó ọkàn ìfẹ́ hàn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn, wọ́n á fà sún mọ́ ọ. Máa ronú nípa ohun tóo lè ṣe fún wọn dípò fífọkàn sí ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ.