Lẹ́tà Jémíìsì
2 Ẹ̀yin ará mi, bí ẹ ṣe di ìgbàgbọ́ Jésù Kristi, Olúwa wa ológo mú, ṣé kì í ṣe pé ẹ tún ń ṣe ojúsàájú?+ 2 Tí ẹnì kan bá wá sí ìpàdé yín, tó wọ àwọn òrùka wúrà sí ìka rẹ̀, tó sì wọ aṣọ tó dáa gan-an, àmọ́ tí tálákà kan tó wọ aṣọ tó dọ̀tí náà wọlé wá, 3 ṣé ẹ máa fi ojúure wo ẹni tó wọ aṣọ tó dáa gan-an, tí ẹ máa sọ pé, “Jókòó síbi tó dáa yìí,” tí ẹ sì máa wá sọ fún tálákà náà pé, “Ìwọ wà lórí ìdúró” tàbí, “Jókòó síbẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi”?+ 4 Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe pé kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti wà láàárín yín nìyẹn,+ tí ẹ sì ti di adájọ́ tó ń dá ẹjọ́ burúkú?+
5 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n. Ṣebí àwọn tí aráyé kà sí tálákà ni Ọlọ́run yàn pé kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́+ àti ajogún Ìjọba náà, èyí tó ṣèlérí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?+ 6 Síbẹ̀, ẹ ti tàbùkù sí tálákà. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ ló ń ni yín lára,+ tí wọ́n sì ń fà yín lọ sí ilé ẹjọ́? 7 Ṣebí wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere tí ẹ̀ ń jẹ́? 8 Tí ẹ bá ń mú ọba òfin ṣẹ bó ṣe wà nínú ìwé mímọ́ pé, “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ,”+ ẹ̀ ń ṣe dáadáa gan-an ni. 9 Àmọ́ tí ẹ bá ṣì ń ṣe ojúsàájú,+ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ̀ ń dá, òfin sì ti dá yín lẹ́bi* pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.+
10 Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń pa gbogbo Òfin mọ́ àmọ́ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé nínú ọ̀kan, ó ti rú gbogbo òfin.+ 11 Torí ẹni tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,”+ ló tún sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.”+ Nígbà náà, tí o ò bá ṣe àgbèrè àmọ́ tí o pààyàn, o ti di arúfin. 12 Ẹ máa sọ̀rọ̀ kí ẹ sì máa hùwà bí àwọn tí a máa fi òfin àwọn tó wà lómìnira* dá lẹ́jọ́.+ 13 Torí ẹni tí kì í ṣàánú kò ní rí àánú gbà nígbà ìdájọ́.+ Àánú máa ń borí ìdájọ́.
14 Ẹ̀yin ará mi, kí ni àǹfààní rẹ̀, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ àmọ́ tí kò ní àwọn iṣẹ́?+ Ìgbàgbọ́ yẹn ò lè gbà á là, àbí ó lè gbà á?+ 15 Tí arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí ò bá láṣọ,* tí wọn ò sì ní oúnjẹ tó máa tó wọn jẹ lóòjọ́, 16 síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà; kí ẹ rí aṣọ fi bora, kí ẹ sì yó dáadáa,” àmọ́ tí ẹ ò fún wọn ní ohun tí ara wọn nílò, àǹfààní kí ló jẹ́?+ 17 Bákan náà, ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+
18 Àmọ́ ẹnì kan lè sọ pé: “Ìwọ́ ní ìgbàgbọ́, èmí sì ní àwọn iṣẹ́. Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, màá sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” 19 O gbà pé Ọlọ́run kan ló wà, àbí? O ṣe dáadáa gan-an ni. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.+ 20 Àmọ́ ṣé o tiẹ̀ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ kò wúlò láìsí iṣẹ́, ìwọ èèyàn lásánlàsàn? 21 Ṣebí a ka Ábúráhámù bàbá wa sí olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tó mú Ísákì ọmọ rẹ̀ lọ sórí pẹpẹ?+ 22 Ẹ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn kedere nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé,+ 23 a sì mú ìwé mímọ́ náà ṣẹ tó sọ pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* a sì kà á sí òdodo fún un,”+ a sì wá ń pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà.*+
24 Ṣé ẹ wá rí i pé àwọn iṣẹ́ la fi ń ka èèyàn sí olódodo, kì í ṣe ìgbàgbọ́ nìkan. 25 Bákan náà, ṣebí àwọn iṣẹ́ ló mú kí á ka Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú sí olódodo, lẹ́yìn tó gba àwọn òjíṣẹ́ lálejò, tó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà míì jáde?+ 26 Lóòótọ́, bí ara láìsí ẹ̀mí* ṣe jẹ́ òkú,+ bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+