Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá!
“Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, . . . kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé.”—ONÍWÀÁSÙ 12:1
1. Báwo làwọn ọ̀dọ́ tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run ṣe ń fẹ́ lo ìgbà ọ̀dọ́ àti okun wọn?
JÈHÓFÀ máa ń fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Aísáyà 40:28-31) Tọmọdé tàgbà wa ló ń fún lágbára náà. Ṣùgbọ́n o, ní pàtàkì jù lọ, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run lè lo ìgbà ọ̀dọ́ wọn àti okun wọn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ìgbà yẹn ni wọ́n á tó lè sọ pé àwọn ń fi ìmọ̀ràn “akónijọ,” ìyẹn Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un, sọ́kàn. Ìmọ̀ràn rẹ̀ náà nìyí: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—Oníwàásù 1:1; 12:1.
2. Kí ló yẹ kí ọmọ àwọn Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ ṣe?
2 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Ísírẹ́lì ni Sólómọ́nì kọ́kọ́ darí ìmọ̀ràn rẹ̀ sí, pé kí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́. A bí wọn sínú orílẹ̀-èdè kan táa ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Àwọn ọmọ Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ lóde ìwòyí ńkọ́? Kò sí àní-àní, àwọn náà ò gbọ́dọ̀ gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá. Bí wọn kò bá gbàgbé rẹ̀, wọ́n á máa bọlá fún un, wọ́n á sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣera wọn láǹfààní.—Aísáyà 48:17, 18.
Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Láyé Ọjọ́un
3. Àpẹẹrẹ wo ni Jósẹ́fù, Sámúẹ́lì, àti Dáfídì fi lélẹ̀?
3 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà nígbà táa kọ Bíbélì ló fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá. Láti kékeré ni Jósẹ́fù, ọmọ Jékọ́bù, ti rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Nígbà tí aya Pọ́tífárì fìlọ̀kulọ̀ lọ Jósẹ́fù, tó ní kó wá bóun ṣe, Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀, ó ní: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Sámúẹ́lì, ọmọ Léfì, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, kì í ṣe nígbà tó wà lọ́mọdé nìkan o, àmọ́ ó rántí rẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 1:22-28; 2:18; 3:1-5) Ẹ̀rí tún fi hàn pé Dáfídì ọ̀dọ́mọkùnrin tó wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kò gbàgbé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ rárá. Ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Ọlọ́run hàn gbangba nígbà tó dojú ìjà kọ Gòláyátì, òmìrán Filísínì, tó sì wí pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá. Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ọ balẹ̀, èmi yóò sì mú orí rẹ kúrò lára rẹ; . . . àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì. Gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là, nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà, òun yóò sì fi yín lé wa lọ́wọ́.” Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Gòláyátì ti kú, làwọn Filísínì bá bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀.—1 Sámúẹ́lì 17:45-51.
4. (a) Kí ló fi hàn pé ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan tó wà ní oko ẹrú ní Síríà àti Jòsáyà ọ̀dọ́mọdé Ọba rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá? (b) Báwo ni Jésù ọmọ ọdún méjìlá ṣe fi hàn pé òun rántí Ẹlẹ́dàá òun?
4 Ọ̀dọ́mọdé mìíràn tó rántí Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá náà ni ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan tó wà ní oko ẹrú. Ó jẹ́rìí tó jíire fún aya Náámánì, olórí ogun Síríà, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkùnrin náà fi tọ wòlíì Ọlọ́run lọ, tí wòlíì náà wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn, tó sì di olùjọsìn Jèhófà. (2 Àwọn Ọba 5:1-19) Jòsáyà Ọba tóun pẹ̀lú jẹ́ ọ̀dọ́ fìgboyà gbé ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ga. (2 Àwọn Ọba 22:1–23:25) Àmọ́ ṣá o, ẹni ti àpẹẹrẹ tiẹ̀ dára jù lọ nínú àwọn tó rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá nígbà tí wọ́n ṣì kéré ni Jésù ará Násárétì. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méjìlá yẹ̀ wò. Àwọn òbí rẹ̀ ló mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù fún Àjọ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n ń darí bọ̀ wálé, ni wọ́n bá wọ̀tún-wòsì, ni wọn ò rí Jésù mọ́; kíá ni wọ́n padà, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri. Ọjọ́ kẹta ni wọ́n tó rí i, níbi tó ti ń jíròrò àwọn ìbéèrè láti inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ ní tẹ́ńpìlì. Nígbà tí Jésù ń dá màmá rẹ̀ tó ti ń ṣàníyàn lóhùn, ó wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” (Lúùkù 2:49) Jésù jàǹfààní nínú ìsọfúnni tó níye lórí nípa tẹ̀mí tó gbà nínú tẹ́ńpìlì, ìyẹn ‘ilé Baba rẹ̀.’ Lóde òní, Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ibi tó dára jù lọ táa ti lè gba ìmọ̀ pípéye nípa Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.
Rántí Jèhófà Nísinsìnyí!
5. Lọ́rọ̀ tìrẹ, báwo ni wàá ṣe ṣàlàyé ohun tí akónijọ sọ táa kọ sínú Oníwàásù 12:1?
5 Ẹni tó bá ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà máa ń fẹ́ tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀, ó sì máa ń fẹ́ sin Ọlọ́run ni gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, báwo ni ọjọ́ ọ̀la ẹni tó fi ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ṣòfò torí pé kò rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ yóò ṣe rí? Lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá, akónijọ wí pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—Oníwàásù 12:1.
6. Ẹ̀rí wo ló wà pé Síméónì àti Ánà tí wọ́n ti darúgbó rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá?
6 Kò sẹ́ni tó ń gbàdúrà pé kóun rí “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tí ọjọ́ ogbó ń mú wá. Ṣùgbọ́n àwọn àgbàlagbà tí kò gbàgbé Ọlọ́run máa ń láyọ̀ tí ọjọ́ ogbó bá dé. Fún àpẹẹrẹ, bàbá arúgbó nì, Síméónì, gbé Jésù ọmọ kékeré jòjòló sọ́wọ́ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì fi tayọ̀tayọ̀ kéde pé: “Nísinsìnyí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ lómìnira ní àlàáfíà ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ; nítorí ojú mi ti rí ohun àmúlò rẹ fún gbígbanilà tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ lójú gbogbo ènìyàn, ìmọ́lẹ̀ fún mímú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ògo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì.” (Lúùkù 2:25-32) Obìnrin náà, Ánà, tóun pẹ̀lú jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin mà rántí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Ìyá yìí kì í wọ́n ní tẹ́ńpìlì, ìṣojú rẹ̀ la sì ṣe gbé Jésù, ọmọdé jòjòló wá síbẹ̀. “Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá sí tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.”—Lúùkù 2:36-38.
7. Báwo ni ipò àwọn tó ti darúgbó nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ti rí?
7 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti darúgbó nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lóde ìwòyí lè máa jẹ̀rora tí ọjọ́ ogbó ń fà, ó sì lè dín ohun tí wọn ì bá ṣe kù. Síbẹ̀, ẹ ò rí i bí wọ́n ti ń láyọ̀ tó, ẹ sì wo báwa náà ṣe ń fi ìmọrírì hàn tó fún iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ti fòtítọ́ ṣe! Wọ́n ní “ìdùnnú Jèhófà,” nítorí wọ́n mọ̀ pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí lo agbára rẹ̀ tí kò ṣeé ṣẹ́gun fún àǹfààní ilẹ̀ ayé yìí, ó sì ti gbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run, Ọba tó ju ọba lọ. (Nehemáyà 8:10) Àkókò táa wà yìí ló yẹ kí tọmọdé tàgbà ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹ̀yin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin. Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé. Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.”—Sáàmù 148:12, 13.
8, 9. (a) Àwọn wo ni “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” kò lérè kankan fún, èé sì ti ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ló ṣe lè ṣàlàyé Oníwàásù 12:2?
8 “Àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tí ọjọ́ ogbó ń mú wá kò lérè kankan—ó tiẹ̀ lè fa ìdààmú—fún àwọn tí kò ronú nípa Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá, àwọn tí kò lóye kankan nípa àwọn ète rẹ̀ ológo. Wọn kò ní òye tẹ̀mí kankan tó lè dín àdánwò ọjọ́ ogbó kù àti èyí tó lè pẹ̀rọ̀ sí ègbé tó ti dé sórí aráyé láti ìgbà táa ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run. (Ìṣípayá 12:7-12) Abájọ tí akónijọ fi rọ̀ wá pé ká rántí Ẹlẹ́dàá wa “kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, tí àwọn àwọsánmà sì ti padà, lẹ́yìn èyí tí eji wọwọ yóò rọ̀.” (Oníwàásù 12:2) Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí?
9 Sólómọ́nì fi ìgbà ọ̀dọ́ wé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ilẹ̀ Palẹ́sìnì, nígbà tí oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ máa ń mọ́lẹ̀ yòò, nígbà tí kùrukùru kì í gbojú ọjọ́. Gbogbo nǹkan ló máa ń dán gbinrin lákòókò yẹn. Àmọ́ ṣá o, nígbà tọ́jọ́ ogbó bá ti dé tán, ìgbésí ayé ẹni á wá dà bíi ìgbà òtútù, ìgbà ọ̀gìn-nìtìn olójò wẹliwẹli, ìgbà tí wàhálà yóò má gorí ara wọn bí àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò. (Jóòbù 14:1) Áà, ẹ wo bí yóò ti burú tó, kéèyàn láǹfààní àtimọ Ẹlẹ́dàá nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ayé rẹ̀, ìyẹn láàárọ̀ ọjọ́, kó sì wá kọ̀ láti sìn ín! Tí ìgbà ọ̀gìn-nìtìn ayé ẹni bá wọlé wẹ́rẹ́, ìyẹn tọ́jọ́ ogbó bá dé, gbogbo nǹkan á wá pòkúdu, pàápàá jù lọ àwọn tó ti gbé àǹfààní sísin Jèhófà nígbà ọ̀dọ́ wọn jùnù nítorí lílépa ohun tí kò ní láárí. Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ẹ jẹ́ á ‘tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún,’ gẹ́gẹ́ bí Kálébù olóòótọ́ ti ṣe, ẹni tó bá wòlíì Mósè ṣiṣẹ́, tó sì dúró tì í gbágbáágbá.—Jóṣúà 14:6-9.
Ipa Tí Ọjọ́ Ogbó Ń Ní
10. Kí làwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí (a) “àwọn olùtọ́jú ilé”? (b) “àwọn ọkùnrin tí ó ní ìmí”?
10 Sólómọ́nì wá mẹ́nu kan àwọn ìṣòro tó máa ń jẹyọ “ní ọjọ́ tí àwọn olùtọ́jú ilé ń wárìrì, tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ìmí sì tẹ ara wọn ba, tí àwọn obìnrin tí ń lọ nǹkan sì ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí pé wọ́n ti kéré níye, tí àwọn ọmọge tí ń wòde lójú fèrèsé sì rí i pé òkùnkùn ṣú.” (Oníwàásù 12:3) Níhìn-ín, “ilé” ń tọ́ka sí ara ènìyàn. (Mátíù 12:43-45; 2 Kọ́ríńtì 5:1-8) “Àwọn olùtọ́jú” rẹ̀ ni apá àti ọwọ́ wa, táa fi ń tọ́jú ara wa, táa sì fi ń gbé ohun táa bá nílò. Tọ́jọ́ ogbó bá dé, lọ́pọ̀ ìgbà, wọn ò ní ṣe é gbé mọ́, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, wọ́n á sì rọ jọwọlọ. “Àwọn ọkùnrin tí ó ní ìmí”—ìyẹn làwọn ẹsẹ̀—wọn ò ní dúró ṣámúṣámú nílẹ̀ mọ́, wọ́n á ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, wọ́n a sì ti tẹ̀ wọ́rọ́kọ́, débi pé wíwọ́ la ó máa wọ́ wọn nílẹ̀. Síbẹ̀, ǹjẹ́ inú rẹ̀ kì í dùn nígbà tóo bá rí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ tó jẹ́ pé wọ́n ti dàgbà, ṣùgbọ́n tí wọ́n kì í fi wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni ṣeré?
11. Kí ló dúró fún “àwọn obìnrin tí ń lọ nǹkan” àti “àwọn ọmọge ti ń wòde lójú fèrèsé”?
11 “Àwọn obìnrin tí ń lọ nǹkan si ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí pé wọ́n ti kéré níye”—ọ̀nà wo lèyí ń gbà ṣẹlẹ̀? Eyín ti lè jẹrà tàbí kó ti ká, kó jẹ́ pé ẹ̀tahóró ló kù. Atifi jẹ oúnjẹ líle a wá diṣẹ́ tàbí kó má tiẹ̀ ṣe é fi jẹun rára. “Àwọn ọmọge tí ń wòde lójú fèrèsé”—ìyẹn ni ẹyinjú wa àtàwọn nǹkan tó wà nínú ọpọlọ wa, tí ń jẹ́ ká ríran—á wá di bàìbàì, tàbí ká má tiẹ̀ ríran mọ́.
12. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “a . . . ti àwọn ilẹ̀kùn tí ó jáde sí ojú pópó”? (b) Kí lèrò rẹ nípa àwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run?
12 Akónijọ ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tí a sì ti ti àwọn ilẹ̀kùn tí ó jáde sí ojú pópó, nígbà tí ìró ọlọ ìlọ-nǹkan ti rẹlẹ̀, tí ènìyàn sì dìde nígbà ìró ẹyẹ, tí gbogbo àwọn ọmọbìnrin orin ń dún lọ́nà rírẹlẹ̀.” (Oníwàásù 12:4) Ilẹ̀kùn méjì—ìyẹn ni ète òkè àti tìsàlẹ̀—tí ń bẹ lẹ́nu àwọn àgbàlagbà tí kò sin Ọlọ́run kò ní lè ṣí dáadáa mọ́ tàbí kò má tiẹ̀ lè ṣí rárá láti sọ ohun tó wà nínú “ilé,” ìyẹn, inú àgọ́ ara. Wọn ò rí nǹkan kan sọ fáwọn èèyàn tó wà ní “ojú pópó.” Ṣùgbọ́n, àwọn àgbàlagbà onítara tí wọ́n jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba náà ńkọ́? (Jóòbù 41:14) Lóòótọ́, ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí wọ́n ti ń lọ láti ojúlé kan síkejì, kó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni àtisọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ fún àwọn míì nínú wọn, àmọ́, kò sí àní-àní pé wọ́n ń yin Jáà!—Sáàmù 113:1.
13. Báwo ni akónijọ ṣe ṣàlàyé àwọn ìṣòro mìíràn táwọn arúgbó ń dojú kọ, àmọ́ kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó ti darúgbó?
13 Ìgbà tó kúkú jẹ́ pé èrìgì ló kù láti fi jẹun, ìró ọlọ ti rẹlẹ̀ pátápátá. Tárúgbó bá wà lórí bẹ́ẹ̀dì, kì í sàsùnwọra. Kódà bẹ́yẹ bá súfèé lásán, oorun a dá lójú ẹ̀. Orin tó lè kọ́ ò pọ̀ mọ́, bó bá sì ń kọrin ọ̀hún pàápàá, ohùn rẹ̀ kò ní jákè. “Gbogbo àwọn ọmọbìnrin orin”—àwọn ohùn tí ń mórin dùn yùngbà—‘ti bẹ̀rẹ̀ sí dún lọ́nà rírẹlẹ̀.’ Báa bá tún ní kí àgbàlagbà tẹ́tí sí orin táwọn ẹlòmíràn ń kọ́, àtigbọ́ràn dáadáa á tún dogun. Àmọ́ ṣá o, àwọn ẹni àmì òróró tó ti dàgbàlagbà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú wọn náà ti ń dàgbà, ń gbé ohùn wọn sókè láti kọrin ìyìn sí Ọlọ́run ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Ẹ wo bínú wa ti máa ń dùn tó, nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa, táwọn náà ń yin Jèhófà nínú ìjọ!—Sáàmù 149:1
14. Kí ló máa ń ba àwọn arúgbó lẹ́rù?
14 Ìṣòro àwọn arúgbó mà bani nínú jẹ́ gan-an o, pàápàá jù lọ àwọn arúgbó tó pa Ẹlẹ́dàá wọn tì! Akónijọ sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ti fòyà ohun tí ó ga, àwọn ohun ìpayà sì wà ní ọ̀nà. Igi álímọ́ńdì sì yọ àwọn ìtànná, tata sì ń wọ́ ara rẹ̀ lọ, àgbáyun kápérì sì bẹ́, nítorí pé ènìyàn ń rìn lọ sí ilé rẹ̀ pípẹ́ títí, àwọn apohùnréré ẹkún sì ti rìn yí ká ní ojú pópó.” (Oníwàásù 12:5) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn arúgbó gorí àtẹ̀gùn tó ga, púpọ̀ nínú wọn ló máa ń bẹ̀rù pé àwọn máa ṣubú. Àní ṣíṣíjú wo nǹkan tó wà lókè lásán lè jẹ́ kí òòyì kọ́ wọ́n. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ní láti lọ sójú pópó tí èrò máa ń gbà lọ gbà bọ̀, ojora pé wọ́n lè ṣe wọ́n léṣe tàbí káwọn olè jáwó wọn gbà kì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn.
15. Báwo ló ṣe jẹ́ pé “igi álímọ́ńdì . . . yọ ìtànná,” báwo sì ni tata ‘ṣe ń wọ́ ara rẹ̀ lọ’?
15 Ní ti baba arúgbó kan, “igi álímọ́ńdì sì yọ àwọn ìtànná,” ìyẹn ń tọ́ka sí i lọ́nà tó ṣe kedere pé, irun rẹ̀ ti di ewú, ó ti di funfun kin-ni-win. Ewú yìí yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí re, bí ìgbà tí ìtànná funfun igi álímọ́ńdì bá ń bọ́ sílẹ̀. Bí baba yìí ti ‘ń wọ́ ara rẹ̀ lọ,’ bóyá ó tẹ̀, tó da ọwọ́ sílẹ̀ tàbí tó dáwọ́ tẹ̀bàdí, tí ìgúnpá rẹ̀ sì ta gọngọ sẹ́yìn, yóò jọ tata gan-an ni. Ṣùgbọ́n, bẹ́nikẹ́ni nínú wa bá rí bẹ́ẹ̀, káwọn tó kù mọ̀ pé, a wà nínú agbo eéṣú Jèhófà, tí ń sáré bíi mànàmáná, tí agbára rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ!—Wo Ilé Ìṣọ́, May 1, 1998, ojú ìwé 8 sí 13.
16. (a) Kí ni ‘àgbáyun kápérì tó bẹ́’ túmọ̀ sí? (b) Ibo ni ‘ilé tí ènìyàn máa wà pẹ́ títí,’ àwọn àmì wo ló sì ń fi hàn pé ikú onítọ̀hún ti ń sún mọ́lé?
16 Oúnjẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ wu arúgbó jẹ, kódà bó jẹ́ oúnjẹ tó dùn bí àgbáyun kápérì la gbé síwájú ẹ̀. Látayébáyé la ti ń lo àgbáyun yìí láti mú kí oúnjẹ wu èèyàn jẹ. ‘Bíbẹ́ tí àgbáyun kápérì bẹ́’ ń tọ́ka sí àkókò tí oúnjẹ kò fi bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́nu àgbàlagbà mọ́, kódà èso yìí kò lè mú kí oúnjẹ náà wù ú jẹ. Irú nǹkan báwọ̀nyí ń fi hàn pé ó ti ń sún mọ́ “ilé rẹ pípẹ́,” ìyẹn ni sàréè. Bó bá lọ jẹ́ pé ó gbàgbé Ẹlẹ́dàá rẹ̀, tó jẹ́ pé ìwà ibi ṣáá ló ń hù débi tí Ọlọ́run kò fi rántí rẹ̀ nínú àjíǹde, àbùjá ò sí lọ́rùn ọ̀pẹ, sàréè ni yóò jẹ́ ilé rẹ̀ títí láé. Àmì pé ikú ti dé tán ń hàn gbangba nínú ohùn arò àti àròyé ìkérora tó ń jáde lẹ́nu àwọn arúgbó.
17. Báwo la ṣe já “okùn fàdákà” kúrò, kí sì ni “àwokòtò wúrà” lè dúró fún?
17 A rọ̀ wá láti rántí Ẹlẹ́dàá wa “kí a tó mú okùn fàdákà kúrò, kí àwokòtò wúrà tó fọ́, kí ìṣà tí ó wà níbi ìsun tó fọ́, kí àgbá kẹ̀kẹ́ àfifami nídìí ìkùdu tó fọ́.” (Oníwàásù 12:6) “Okùn fàdákà” yìí lè jẹ́ ọ̀pá ẹ̀yìn. Tí ọ̀nà ìyanu tí ìsọfúnni ń gbà lọ sínú ọpọlọ yìí bá lọ bà jẹ́ débi tí kò fi ṣeé tún ṣe, tóò, ikú dé nìyẹn. “Àwokòtò wúrà” lè dúró fún ọpọlọ, torí inú ohun kan tí ó jọ àwokòtò ló wà, èyí táa ń pè ní agbárí, ibẹ̀ la so ọ̀pá ẹ̀yìn mọ́. Bí ọpọlọ ṣe ṣeyebíye tó ló jẹ́ ká fi wé wúrà, bó bá sì lọ fọ́, tóò, ikú lòpin ẹ̀.
18. Kí ni “ìṣà tí ó wà níbi ìsun” ṣàpẹẹrẹ, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá fọ́?
18 “Ìṣà tí ó wà níbi ìsun,” ni ọkàn-àyà, èyí ló ń gba ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn nínú ara wọlé, tó sì tún ń tú u jáde, kó lè yí gbogbo ara po. Téèyàn bá ti kú, ọkàn-àyà a wá dà bí ìṣà tó ti fọ́, tí kò ṣeé ṣà jọ mọ́, nítorí bí ẹ̀jẹ̀ bá ṣàn débẹ̀ ńṣe ni yóò máa jò ṣùùrùṣù, kò sì ní lè tú ẹ̀jẹ̀ jáde sínú ara mọ́, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ṣe pàtàkì, kí ara lè lókun, kó sì lè ṣiṣẹ́ dáadáa. ‘Àgbá kẹ̀kẹ́ àfifami tó ti fọ́’ kò lè yí mọ́, ẹ̀jẹ̀ tó so ẹ̀mí ró, tí ń lọ káàkiri ara ti ṣíwọ́ iṣẹ́ nìyẹn. Báyìí ni Jèhófà ṣe fi ọ̀nà tí ẹ̀jẹ̀ gbà ń yí ara po han Sólómọ́nì tipẹ́tipẹ́ kí oníṣègùn ọ̀rúndún kẹtàdínlógún nì, William Harvey, tó ṣàlàyé bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń yí ara po.
19. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ Oníwàásù 12:7 ṣe ń nímùúṣẹ nígbà tí èèyàn bá kú?
19 Akónijọ fi kún un pé: “Nígbà náà ni ekuru yóò padà sí ilẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀, àní ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.” (Oníwàásù 12:7) Níwọ̀n bí “àgbá kẹ̀kẹ́ àfifami” ti fọ́, ara ènìyàn, tó jẹ́ pé inú ekuru la ti mú un wá, yóò tún padà sínú ekuru. (Jẹ́nẹ́sísì 2;7; 3:19) Ọkàn náà kú nítorí pé ẹ̀mí, tàbí agbára ìwàláàyè, tí Ọlọ́run fún un ti padà sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá.—Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20; Jákọ́bù 2:26.
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ló Ń Dúró De Àwọn Tó Rántí Ẹlẹ́dàá?
20. Nínú àdúrà Mósè táa kọ sínú Sáàmù 90:12, kí ló ń bẹ̀bẹ̀ fún?
20 Lọ́nà tó gbéṣẹ́ gan-an, Sólómọ́nì fi ìjẹ́pàtàkì rírántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá hàn. Dájúdájú, kì í ṣe ìgbésí ayé kúkúrú, tó kún fún hílàhílo yìí náà lòpin gbogbo ìwàláàyè àwọn tó bá rántí Jèhófà, tí wọ́n sì fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Yálà ọmọdé ni wọ́n tàbí àgbàlagbà, wọ́n ní irú ẹ̀mí tí Mósè ní, tó fi gbàdúrà pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” Wòlíì Ọlọ́run yìí tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ fi tọkàntọkàn béèrè pé kí Jèhófà fi han òun, tàbí kó kọ́ òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí àwọn yóò ṣe máa fi ọgbọ́n ka ‘ọjọ́ àwọn ọdún wọn,’ àti bí àwọn yóò ṣe lò ó lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.—Sáàmù 90:10, 12.
21. Báa bá fẹ́ máa ka ọjọ́ wa lọ́nà tí yóò fògo fún Jèhófà, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
21 Pàápàá jù lọ, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni pinnu láti máa kọbi ara sí ìmọ̀ràn akónijọ náà pé, kí wọ́n máa rántí Ẹlẹ́dàá wọn. Àní àǹfààní tí wọ́n ní láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní! Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, báa bá kọ́ láti máa ka ọjọ́ wa lọ́nà tí yóò fògo fún Jèhófà ní “àkókò òpin” yìí, yóò lè ṣeé ṣe fún wa láti máa kà á lọ títí láé fáàbàdà. (Dáníẹ́lì 12:4; Jòhánù 17:3) Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé, a gbọ́dọ̀ rántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá. A sì gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú Ọlọ́run.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe táa fi rọ àwọn ọ̀dọ́ láti rántí Ẹlẹ́dàá wọn?
◻ Kí làwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn tó rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá?
◻ Kí ni díẹ̀ lára ipa tí ọjọ́ ogbó ń ní lórí ẹni gẹ́gẹ́ bí àlàyé Sólómọ́nì?
◻ Ọjọ́ ọ̀la wo ló ń dúró de àwọn tí kò gbàgbé Jèhófà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Dáfídì, ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì tó wà ní oko ẹrú, Ánà, àti Síméónì, gbogbo wọ́n rántí Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá