Oníwàásù
12 Nítorí náà, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ,+ kí àwọn ọjọ́ wàhálà* tó dé,+ kí àwọn ọdún náà tó dé nígbà tí wàá sọ pé: “Wọn ò mú inú mi dùn”; 2 kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,+ tí ojú ọ̀run á sì tún ṣú lẹ́yìn tí òjò ti rọ̀;* 3 ní ọjọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́* ilé ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,* tí àwọn ọkùnrin alágbára sì tẹ̀, tí àwọn obìnrin tó ń lọ nǹkan dáwọ́ dúró nítorí pé wọn ò pọ̀ mọ́, tí àwọn ọmọge tó ń wo ìta lójú fèrèsé* sì rí i pé òkùnkùn ṣú;+ 4 nígbà tí àwọn ilẹ̀kùn tó jáde sí ojú ọ̀nà ti wà ní títì, nígbà tí ìró ọlọ ti lọ sílẹ̀, nígbà tí èèyàn á jí nítorí ìró ẹyẹ, tí ohùn gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó ń kọrin kò sì dún sókè mọ́.+ 5 Bákan náà, èèyàn á máa bẹ̀rù ibi tó ga, ẹ̀rù á sì wà lójú ọ̀nà. Igi álímọ́ńdì ń yọ ìtànná,+ tata ń wọ́ ara rẹ̀ lọ, àgbáyun kápérì sì bẹ́, torí pé èèyàn ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé,+ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ sì ń rìn kiri ní ojú ọ̀nà;+ 6 kí okùn fàdákà tó yọ, kí àwo wúrà tó fọ́ sí wẹ́wẹ́, kí ìṣà tó wà níbi ìsun omi tó fọ́, kí kẹ̀kẹ́ ìfami tó wà níbi kòtò omi tó kán. 7 Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+
8 “Asán* pátápátá gbáà!” ni akónijọ+ wí. “Asán ni gbogbo rẹ̀.”+
9 Kì í ṣe pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n nìkan ni, ó tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó mọ̀,+ ó ronú jinlẹ̀, ó sì wádìí fínnífínní, kí ó lè kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ.*+ 10 Akónijọ wá bó ṣe máa rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára,+ kó sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́.
11 Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù,+ àkójọ ọ̀rọ̀ wọn sì dà bí ìṣó tó wọlé ṣinṣin; ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni wọ́n ti wá. 12 Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan yìí, ọmọ mi, ṣọ́ra: Kò sí òpin nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, fífi àkókò tó pọ̀ jù kà wọ́n sì ń kó àárẹ̀ bá ara.+
13 Òpin ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,+ kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe èèyàn.+ 14 Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lórí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, títí kan gbogbo ohun tó fara pa mọ́, bóyá ó dára tàbí ó burú.+