Orí Kejì
Bàbá Kan Àtàwọn Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ Rẹ̀
1, 2. Ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe dẹni tó ní àwọn ọlọ̀tẹ̀ ọmọ.
BÍ GBOGBO òbí onífẹ̀ẹ́ ti ń pèsè nǹkan dáadáa fún ọmọ wọn lòun náà ṣe pèsè fáwọn tirẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó ń rí i dájú pé wọ́n jẹun, wọ́n wọṣọ, wọ́n sì ní ibùgbé. Ó máa ń fún wọn ní ìbáwí nígbà tó bá yẹ. Ṣùgbọ́n ìyà wọn kì í kọjá bó ti yẹ; ó sábà máa ń jẹ́ ní “ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 30:11) Ẹ wá fojú inú wo bí yóò ṣe dun baba yìí tó nígbà tí gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí fi jáde lẹ́nu rẹ̀ pé: “Èmi ti tọ́ àwọn ọmọ, mo sì ti tọ́jú wọn dàgbà, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti dìtẹ̀ sí mi.”—Aísáyà 1:2b.
2 Àwọn èèyàn Júdà làwọn ọmọ tí ibí yìí ń tọ́ka sí, Jèhófà Ọlọ́run sì ni baba tó ń kẹ́dùn náà. Ó mà kúkú burú o! Jèhófà ṣìkẹ́ àwọn ará Júdà, ó sì gbé wọn lékè láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ó tipasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì rán wọn létí lẹ́yìn náà pé: “Mo . . . tẹ̀ síwájú láti fi ẹ̀wù tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára wọ̀ ọ́, mo sì fi awọ séálì wọ̀ ọ́ ní bàtà, mo sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wé ọ, mo sì fi aṣọ olówó iyebíye bò ọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 16:10) Síbẹ̀, ká sáà kúkú sọ pé àwọn ènìyàn Júdà ò mọrírì ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn rárá ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣọ̀tẹ̀, tàbí wọ́n dìtẹ̀.
3. Èé ṣe tí Jèhófà fi ké sí ọ̀run àti ayé láti wá jẹ́rìí sí ìṣọ̀tẹ̀ Júdà?
3 Ó tọ́ bí Jèhófà ṣe fi gbólóhùn yìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọ̀run, sì fi etí sílẹ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé, nítorí Jèhófà tìkára rẹ̀ ti [sọ̀rọ̀].” (Aísáyà 1:2a) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, ọ̀run àti ayé kúkú gbọ́ ni ká wí, nítorí gbọnmọgbọnmọ ni ìkìlọ̀ ró létígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àbájáde àìgbọràn ṣíṣe. Mósè sọ pé: “Mo fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé wéréwéré ni ẹ̀yin yóò ṣègbé dájúdájú kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ ó sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà.” (Diutarónómì 4:26) Wàyí o, lọ́jọ́ Aísáyà, Jèhófà wá ń ké sí ọ̀run tí a kò lè fojú rí àti ayé tí a lè fojú rí láti wá jẹ́rìí sí ìṣọ̀tẹ̀ Júdà.
4. Ọwọ́ wo ni Jèhófà ṣì fi mú Júdà?
4 Bọ́ràn náà ṣe burú tó, ńṣe ló yẹ kó fọ̀rọ̀ gún wọn lójú. Ṣùgbọ́n níbi tọ́ràn tilẹ̀ le dé yìí pàápàá, ó gbàfiyèsí—ó tún dùn mọ́ni pẹ̀lú—pé ọwọ́ òbí onífẹ̀ẹ́ ṣì ni Jèhófà fi mú Júdà kì í ṣọwọ́ pé èmi ni mo fowó mi rà yín. Ìyẹn fi hàn pé ńṣe ni Jèhófà ń rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọ́n fojúu pé òun jẹ́ baba tọ́kàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn ọmọ rẹ̀ wo ọ̀ràn náà. Bóyá irú ìṣòro yìí lè má ṣàjèjì sí àwọn òbí kan ní Júdà pàápàá, kí àpèjúwe yẹn sì mú wọn ronú. Àmọ́ ṣá, Jèhófà ti ṣe tán láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ tí Júdà ṣẹ̀ ẹ́.
Ẹranko Lásánlàsàn Mọ̀ Jù Wọ́n Lọ
5. Ní ìyàtọ̀ sí ìwà Ísírẹ́lì, ọ̀nà wo ni akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi lẹ́mìí àrótì?
5 Nípasẹ̀ Aísáyà, Jèhófà sọ pé: “Akọ màlúù mọ ẹni tí ó ra òun dunjú, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ ẹran olúwa rẹ̀; Ísírẹ́lì alára kò mọ̀, àwọn ènìyàn mi kò hùwà lọ́nà òye.” (Aísáyà 1:3)a Akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹranko arẹrù tí àwọn tí ń gbé Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé mọ̀ dáadáa. Ní tòótọ́, àwọn ènìyàn Júdà wọ̀nyẹn kò ní jiyàn rárá pé àwọn ẹranko lásánlàsàn wọ̀nyẹn pàápàá lẹ́mìí àrótì, wọ́n mọ̀ dájú pé àwọn lólúwa. Láti kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, fetí sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣojú ọ̀gbẹ́ni kan tí ń ṣèwádìí lórí Bíbélì, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní ìlú kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé: “Gbàrà tí agbo ẹran náà wọnú ìlú ni wọ́n tú ká. Akọ màlúù kọ̀ọ̀kan mọ olúwa rẹ̀ dunjú, àti ọ̀nà ilé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ tó gba inú kọ̀rọ̀ já sí gbangba látinú horo já sí horo kò dàrú mọ́ ọn lójú rárá ni. Ní ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹnu ọ̀nà ilé ló gbà lọ tààrà, ó sì wọnú ‘ibùjẹran ti ọ̀gá rẹ̀.’”
6. Báwo ni àwọn ènìyàn Júdà kò ṣe fòye hùwà?
6 Níwọ̀n bí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ti wọ́pọ̀ gan-an lọ́jọ́ Aísáyà, ohun tí Jèhófà ń sọ yéni, pé: Bí ẹranko lásánlàsàn bá lè dá ọ̀gá rẹ̀ mọ̀, tó sì mọ ibùjẹ òun fúnra rẹ̀, kí wá ni àwíjàre àwọn ènìyàn Júdà fún fífi tí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀? Lóòótọ́, wọn “kò hùwà lọ́nà òye.” Àfi bíi pé wọn kò mọ̀ rárá pé ọwọ́ Jèhófà ni aásìkí àti ìwàláàyè àwọn wà. Ní tòótọ́, àánú ló sún Jèhófà tó ṣì fi ń pe àwọn ará Júdà wọ̀nyẹn ní “àwọn ènìyàn mi”!
7. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fi hàn pé a mọrírì àwọn ìpèsè Jèhófà?
7 Ẹ má ṣe jẹ́ ká hu ìwà àìlóye láé, nípa kíkùnà láti fi ìmọrírì hàn fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká ṣàfarawé olórin náà, Dáfídì, tó sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà; èmi yóò máa polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sáàmù 9:1) Bíbá tí a bá ń bá a lọ láti gba ìmọ̀ Jèhófà sínú ni yóò fún wa níṣìírí láti ṣe èyí, nítorí Bíbélì sọ pé “ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” (Òwe 9:10) Bí a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún Jèhófà lójoojúmọ́, ìyẹn ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kún fún ọpẹ́, kí á má sì rí Baba wa ọ̀run fín. (Kólósè 3:15) Jèhófà sọ pé: “Ẹni tí ń rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ ni ó ń yìn mí lógo; àti ní ti ẹni tí ń pa ọ̀nà tí a là sílẹ̀ mọ́, dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí ó rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run.”—Sáàmù 50:23.
Wọ́n Hùwà Àfojúdi Gbáà sí “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì”
8. Èé ṣe tí a fi lè pe orílẹ̀-èdè Júdà ní “orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀”?
8 Aísáyà ń bá iṣẹ́ tó ń jẹ́ lọ, ó sọ ọ̀rọ̀ líle sí orílẹ̀-èdè Júdà, pé: “Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ìṣìnà ti wọ̀ lọ́rùn, irú-ọmọ tí ń ṣebi, àwọn apanirun ọmọ! Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n ti hùwà àìlọ́wọ̀ sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọ́n ti yí padà sẹ́yìn.” (Aísáyà 1:4) Ìwà burúkú lè ṣẹ́jọ dépò pé yóò dà bí ẹrù tó lè kánni lọ́rùn. Láyé Ábúráhámù, Jèhófà sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ Sódómù àti Gòmórà “rinlẹ̀ gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20) Ohun tó jọ ìyẹn náà ló wá hàn kedere nínú ọ̀ràn àwọn ènìyàn Júdà báyìí, nítorí Aísáyà sọ pé “ìṣìnà ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn.” Síwájú sí i, ó tún pè wọ́n ní “irú-ọmọ tí ń ṣebi, àwọn apanirun ọmọ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ará Júdà dà bí ọmọ tó ti ya pòkíì. Wọ́n ti “yí padà sẹ́yìn,” tàbí bí Bíbélì New Revised Standard Version ṣe sọ ọ́, wọ́n ti “dàjèjì pátápátá” sí Baba wọn.
9. Kí ni ìjẹ́pàtàkì gbólóhùn náà, “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì”?
9 Nípa ìwà aṣetinú-ẹni tí àwọn ènìyàn Júdà ń hù, ṣe ni wọ́n ń fojú tín-ínrín “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” Kí ni ìjẹ́pàtàkì gbólóhùn yìí, tó fara hàn nígbà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ìwé Aísáyà? Láti jẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní, láti dá ṣáká. Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní ìwọ̀n tó ga jù lọ. (Ìṣípayá 4:8) Gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá sì ti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fín sára àwo wúrà tí ń bẹ lára láwàní àlùfáà àgbà, pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà,” kókó yìí ló ń rán wọn létí. (Ẹ́kísódù 39:30) Nítorí náà, bí Aísáyà ṣe pe Jèhófà ní “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,” ńṣe ló ń pe àfiyèsí sí bí ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ṣe wúwo tó. Áà, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí kúkú wá ń rú òfin tí wọ́n fún àwọn baba ńlá wọn pé: “Kí ẹ sì sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́”!—Léfítíkù 11:44.
10. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ṣíṣàìbọ̀wọ̀ fún “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì”?
10 Lọ́nàkọnà, àwọn Kristẹni lónìí gbọ́dọ̀ yẹra fún títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn èèyàn Júdà ní ti bí wọ́n ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” Ìjẹ́mímọ́ Jèhófà ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣàfarawé. (1 Pétérù 1:15, 16) Wọ́n sì ní láti “kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Àwọn ìwà àìmọ́ bíi ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà, àti ìmutípara lè ba ìjọ Kristẹni jẹ́. Ìdí nìyẹn tí a fi ń yọ àwọn tí wọ́n bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú nǹkan wọ̀nyẹn kúrò nínú ìjọ. Paríparì rẹ̀ ni pé, àwọn tí wọ́n bá ń forí kunkun hu ìwà àìmọ́ lọ láìdẹ̀yìn kò ní sí lára àwọn tí yóò gbádùn àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá. Ní tòdodo, gbogbo irú àwọn iṣẹ́ burúkú bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà àfojúdi gbáà sí “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Róòmù 1:26, 27; 1 Kọ́ríńtì 5:6-11; 6:9, 10.
Àìsàn Bò Ó Láti Orí Dé Àtẹ́lẹsẹ̀
11, 12. (a) Ṣàlàyé ipò burúkú tí Júdà wà. (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àánú Júdà ṣe wá?
11 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà wá gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ tó lè mú kí àwọn ènìyàn Júdà ronú nípa sísọ irú àìsàn tó ń ṣe wọ́n fún wọn. Ó sọ pé: “Ibo ni ó tún kù tí a ó ti lù yín, ní ti pé ẹ túbọ̀ ń dìtẹ̀ sí i?” Ohun tí Aísáyà ń fi èyí béèrè ni pé: ‘Ṣé ìyà ò tíì jẹ yín tó ni? Kí lẹ ṣe tún fẹ́ máa fìyà jẹ ara yín sí i nípa bíbá ìṣọ̀tẹ̀ yín nìṣó?’ Aísáyà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gbogbo orí wà ní ipò àìsàn, gbogbo ọkàn-àyà sì jẹ́ ahẹrẹpẹ. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ àní dé orí, kò sí ibì kankan nínú rẹ̀ tí ó dá ṣáṣá.” (Aísáyà 1:5, 6a) Júdà ti di ẹni ìríra, ó di olókùnrùn—ó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Àrùn tó ń ṣe é mà kúkú burú o!
12 Ǹjẹ́ ó yẹ kí àánú Júdà ṣe wá? Àgbẹdọ̀! Wọ́n kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fún gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, nípa ohun tí àìgbọràn yóò kó bá wọn. Apá kan ìkìlọ̀ ọ̀hún sọ pé: “Jèhófà yóò fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlù ọ́ lórí eékún méjèèjì àti ojúgun méjèèjì, láti inú èyí tí a kì yóò lè mú ọ lára dá, láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ títí dé àtàrí rẹ.” (Diutarónómì 28:35) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìyà oríkunkun Júdà ló ń jẹ ẹ́ báyìí. Gbogbo ìyà wọ̀nyí ì bá sì má jẹ àwọn ènìyàn Júdà ká ní wọ́n sáà ṣègbọràn sí Jèhófà ni.
13, 14. (a) Àwọn ọgbẹ́ wo ni wọ́n ti dá sí Júdà lára? (b) Ǹjẹ́ ìyà tó jẹ Júdà mú kó túnnú rò lórí ìwà ìṣọ̀tẹ̀ tó ń hù?
13 Aísáyà ń bá àlàyé lọ lórí ipò aṣeniláàánú tí Júdà wà pé: “Àwọn ọgbẹ́ àti ara bíbó àti ojú ibi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ nà—a kò mọ́ wọn tàbí kí a dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi òróró tù wọ́n lójú.” (Aísáyà 1:6b) Oríṣi ìpalára mẹ́ta ni wòlíì náà mẹ́nu kàn níhìn-ín: àwọn ọgbẹ́ (ojúu gígé, bíi kí idà tàbí ọ̀bẹ géni), ara bíbó (kí ara dáranjẹ̀ nítorí nínà), àti ojú ibi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ nà (ojú ọgbẹ́ yánnayànna, tó jọ pé kò ní lè jiná). Èrò tí ibí yìí ń gbé yọ ni tẹnì kan tí wọ́n ti fi ìyà pá lórí, tí kò síbi tí nǹkan ò bà lára rẹ̀. Júdà ti wó sára lóòótọ́.
14 Ǹjẹ́ Júdà tìtorí bójú rẹ̀ ṣe rí màbo yìí padà sọ́dọ̀ Jèhófà bí? Ó tì o! Júdà dà bí ọlọ̀tẹ̀ tí Òwe 29:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, pé: “Ènìyàn tí a fi ìbáwí tọ́ sọ́nà léraléra, ṣùgbọ́n tí ó mú ọrùn rẹ̀ le, yóò ṣẹ́ lójijì, kì yóò sì ṣeé mú lára dá.” Ó jọ pé orílẹ̀-èdè yẹn kò ṣeé wò sàn mọ́. Bí Aísáyà ṣe sọ ọ́, àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, “a kò mọ́ wọn tàbí kí a dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi òróró tù wọ́n lójú.”b Lọ́rọ̀ kan ṣá, Júdà rí bí egbò àdáàjinná, tí wọn kò dì, tí ó tóbi yànmànkàn.
15. Àwọn ọ̀nà wo la fi lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àìsàn tẹ̀mí?
15 Kí a fi ti Júdà ṣàríkọ́gbọ́n o, pé àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àìsàn tẹ̀mí. Bí àìsàn gidi ṣe lè kọluni lòun náà ṣe lè kọlu ẹnikẹ́ni nínú wa. Àbí, ta ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara kò lè bá jà? Ìwọra àti afẹ́ ṣíṣe lè gbà wá lọ́kàn. Nítorí náà, a ní láti tọ́ ara wa láti “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú” kí a sì “rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Bákan náà ló yẹ ká máa fi èso ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwà hù lójoojúmọ́. (Gálátíà 5:22, 23) Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó yẹra fún ìyọnu tí Júdà kó sí, ìyẹn dídi ẹni tí àìsàn tẹ̀mí bò láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀.
Ilẹ̀ Tó Dahoro
16. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ojú ilẹ̀ Júdà? (b) Èé ṣe tí àwọn kan fi sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìjọba Áhásì ló sọ gbólóhùn yìí, ṣùgbọ́n kí la lè lóye wọn sí?
16 Aísáyà wá mẹ́nu kúrò lórí fífi tó ń fi wọ́n wé aláìsàn, ó wá bọ́ sórí ipò tí ojú ilẹ̀ Júdà wà. Bíi pé ó ń wo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọ súà tí ogun ti sọ di págunpàgun, ó ní: “Ilẹ̀ yín jẹ́ ahoro, a fi iná sun àwọn ìlú ńlá yín; ilẹ̀ yín—àwọn àjèjì ń jẹ ẹ́ ní iwájú yín gan-an, ahoro náà sì dà bí ìbìṣubú láti ọwọ́ àwọn àjèjì.” (Aísáyà 1:7) Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé apá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Aísáyà ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá ìgbẹ̀yìn iṣẹ́ wòlíì náà ló sọ wọ́n, bóyá nígbà ìṣàkóso Áhásì Ọba burúkú. Wọ́n sọ pé aásìkí wà gan-an nígbà ìjọba Ùsáyà tí nǹkan kò fi lè burú tó bó ṣe sọ ọ́. Lóòótọ́, kò sí ẹ̀rí ìdánilójú pé bóyá báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Aísáyà ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra ni wọ́n ṣe tò ó síbẹ̀ báyìí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ ni Aísáyà ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ìsọdahoro sọ. Bí Aísáyà ṣe sọ gbólóhùn tó wà lókè yìí, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń lo ọ̀nà kan náà tí wọ́n lò níbòmíràn nínú Bíbélì, ìyẹn ni, ṣíṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú kan bíi pé ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ní títipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé yóò ṣẹlẹ̀ dandan ni.—Fi wé Ìṣípayá 11:15.
17. Èé ṣe tí kò fi yẹ kó ya àwọn ènìyàn Júdà lẹ́nu láti gbọ́ bó ṣe ń fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe ìsọdahoro wọn?
17 Bó ti wù kó jẹ́, kò yẹ kó ya àwọn olóríkunkun àti aláìgbọràn wọ̀nyí lẹ́nu láti gbọ́ bó ṣe ń fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe ìsọdahoro Júdà. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ni Jèhófà ti kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi, ní tèmi, yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, àwọn ọ̀tá yín tí ń gbé inú rẹ̀ yóò wulẹ̀ wò ó sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì. Èmi yóò sì tú yín ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fa idà yọ láti inú àkọ̀ tọ̀ yín lẹ́yìn; ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú ńlá yín yóò sì di ìparundahoro.”—Léfítíkù 26:32, 33; 1 Àwọn Ọba 9:6-8.
18-20. Ìgbà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 1:7, 8 ní ìmúṣẹ, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà ‘ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀’ lákòókò yẹn?
18 Ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 1:7, 8 jọ pé ó ní ìmúṣẹ nígbà tí Ásíríà gbógun wọ ibẹ̀, tó fa ìparun Ísírẹ́lì, tó sì fa ìparun òun ìjìyà ní ibi púpọ̀ ní Júdà. (2 Àwọn Ọba 17:5, 18; 18:11, 13; 2 Kíróníkà 29:8, 9) Àmọ́ ṣá, Júdà kò pa rẹ́ pátápátá. Aísáyà sọ pé: “Ọmọbìnrin Síónì ni a sì fi sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà, bí ahéré alóre inú àwọn pápá apálá, bí ìlú ńlá tí a sénà rẹ̀.”—Aísáyà 1:8.
19 Nínú gbogbo ìparun yìí, “ọmọbìnrin Síónì,” ìyẹn Jerúsálẹ́mù yóò ṣì wà. Àmọ́ hẹ́gẹhẹ̀gẹ ni yóò rí—bí ahéré inú ọgbà àjàrà tàbí àtíbàbà olùṣọ́ oko apálá. Bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣe rí irú àwọn àtíbàbà bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń gba ojú odò Náílì lọ, ọ̀rọ̀ Aísáyà ló rántí, ó ṣàpèjúwe wọn pé “díẹ̀ ni wọ́n fi yàtọ̀ sí ọgbà téèyàn sọ láti fi dènà ẹ̀fúùfù ìhà àríwá.” Bí ìkórè bá ti parí nílẹ̀ Júdà, ṣe ni wọ́n máa ń fi irú àtíbàbà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ kí ó wó dànù. Síbẹ̀ náà, bó ti wù kí Jerúsálẹ́mù rí hẹ́gẹhẹ̀gẹ tó níwájú agbo ọmọ ogun Ásíríà tó jẹ́ ajagunṣẹ́gun, yóò là á já.
20 Aísáyà parí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí pé: “Bí kò ṣe pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ṣẹ́ kìkì àwọn olùlàájá díẹ̀ kù sílẹ̀ fún wa, àwa ì bá ti dà bí Sódómù gan-an, à bá ti jọ Gòmórà pàápàá.” (Aísáyà 1:9)c Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jèhófà yóò wá gba Júdà sílẹ̀ lọ́wọ́ Ásíríà alágbára. Júdà kò ní pa rẹ́ ráúráú bí ti Sódómù àti Gòmórà. Yóò máa wà títí lọ ni.
21. Lẹ́yìn tí Bábílónì ti pa Jerúsálẹ́mù run, èé ṣe tí Jèhófà fi ‘ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀’?
21 Lóhun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Júdà tún wà nínú ewu. Ìyà tí a tipasẹ̀ Ásíríà fi jẹ wọ́n kò tíì kọ́ àwọn èèyàn náà lọ́gbọ́n. “Wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà.” Nítorí náà, “ìhónú Jèhófà . . . jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Nebukadinésárì ọba Bábílónì ṣẹ́gun Júdà, lọ́tẹ̀ yìí, kò ṣẹ́ ku ohunkóhun tó dà “bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà.” Kódà Jerúsálẹ́mù pàápàá pa run. (2 Kíróníkà 36:17-21) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ‘ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àádọ́rin ọdún ni Júdà fi wà nígbèkùn, Jèhófà rí i dájú pé orílẹ̀-èdè náà kò pa rẹ́, pàápàá ìlà ìdílé Dáfídì, níbi tí Mèsáyà tí a ṣèlérí yóò ti jáde wá.
22, 23. Ní ọ̀rúndún kìíní, èé ṣe tí Jèhófà fi ‘ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀’?
22 Ní ọ̀rúndún kìíní, àgbákò ìkẹyìn dé bá Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú. Nígbà tí Jésù wá gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tí a ṣèlérí, orílẹ̀-èdè náà kọ̀ ọ́, nítorí èyí, Jèhófà kọ̀ wọ́n. (Mátíù 21:43; 23:37-39; Jòhánù 1:11) Ṣé ibi tí níní tí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ kan lórí ilẹ̀ ayé máa wá dópin sí nìyí? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Aísáyà 1:9 ṣì tún ní ìmúṣẹ mìíràn. Bó ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìtumọ̀ Bíbélì ti Septuagint, ó kọ̀wé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti wí ní ìgbà ìṣáájú pé: ‘Bí kì í bá ṣe pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ṣẹ́ irú-ọmọ kù sílẹ̀ fún wa, àwa ì bá ti dà bí Sódómù gan-an, à bá sì ti ṣe wá gẹ́gẹ́ bí Gòmórà gan-an.’”—Róòmù 9:29.
23 Lọ́tẹ̀ yìí o, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó gba Jésù Kristi gbọ́ làwọn tó là á já. Àwọn Júù tó gbà gbọ́ nìkan ni lákọ̀ọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, àwọn Kèfèrí tó gbà gbọ́ wá di ara wọn. Àpapọ̀ wọn ló di Ísírẹ́lì tuntun, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Róòmù 2:29) “Irú-ọmọ” yìí ló la ìparun ètò àwọn nǹkan Júù já lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Ní tòótọ́, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ṣì wà pẹ̀lú wa lónìí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn onígbàgbọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” ló ti dara pọ̀ mọ́ wọn báyìí.—Ìṣípayá 7:9.
24. Kí ló yẹ kí gbogbo ènìyàn ṣàkíyèsí bí wọ́n bá fẹ́ la yánpọnyánrin tí ń bọ̀ wá bá aráyé já?
24 Láìpẹ́, ayé yìí yóò dojú kọ ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Yánpọnyánrin yìí yóò tayọ ogun tí Ásíríà tàbí Bábílónì gbé ja Júdà, kódà yóò tayọ pípa tí Róòmù pa Jùdíà run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, àmọ́ àwọn kan yóò là á já. (Ìṣípayá 7:14) Ó mà ṣe pàtàkì o, pé kí gbogbo wa fẹ̀sọ̀ gbé ọ̀rọ̀ tí Aísáyà bá Júdà sọ yẹ̀ wò! Ìyẹn làwọn olùṣòtítọ́ fi là á já nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ó sì tún lè jẹ́ ìyẹn làwọn tó gbà gbọ́ lónìí yóò fi là á já.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ọ̀ràn yìí, ìjọba Júdà tó jẹ́ ẹ̀yà méjì ni a pè ní “Ísírẹ́lì.”
b Àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà fi hàn bí ìṣègùn ṣe rí nígbà ayé tirẹ̀. E. H. Plumptre tó jẹ́ aṣèwádìí lórí Bíbélì sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń gbìyànjú láti ‘fún’ tàbí ‘tẹ’ ojú egbò kíkẹ̀ láti mú kí ọyún rẹ̀ jáde; lẹ́yìn náà, wọn a wá fi àpòpọ̀ egbòogi gbígbóná ‘dì í,’ gẹ́gẹ́ bíi ti Hesekáyà (orí xxxviii. 21 [Ais 38:21]), lẹ́yìn náà, wọn a wá fi òróró atániyẹ́ẹ́ tàbí ìwọ́ra pa á, bóyá wọ́n tún ń lo epo tàbí wáìnì láti fi fọ egbò náà, bó ṣe ṣẹlẹ̀ nínú Lúùkù x. 34 [10:34].”
c Ìwé Commentary on the Old Testament, tí C. F. Keil àti F. Delitzsch ṣe, sọ pé: “Apá kan àsọyé wòlíì yìí parí síbí. Àlàfo tí wọ́n fi sáàárín ọ̀rọ̀ Ais 1 ẹsẹ kẹsàn-án àti ìkẹwàá fi hàn pé wọ́n pín in sí apá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níhìn-ín lóòótọ́. Lílo àṣà fífi àlàfo sílẹ̀ tàbí gígé ìlà kúrò yìí láti fi ìyàtọ̀ sí apá tó gùn tàbí apá kéékèèké, ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ìlò àmì ìdánudúró tàbí àmì ohùn tó yẹ láti fi pe ọ̀rọ̀ tó wà, ó sì bá bí wọ́n ti ń ṣe é bọ̀ látayébáyé mu.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Júdà kò ní dà bí Sódómù àti Gòmórà, kò ní wà láhoro títí láé