Àìsáyà
1 Ìran tí Àìsáyà*+ ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù láyé ìgbà Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ àwọn ọba Júdà:+
“Mo ti tọ́ àwọn ọmọ,+ mo sì ti tọ́jú wọn dàgbà,
Àmọ́ wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+
3 Akọ màlúù mọ ẹni tó ra òun dunjú,
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ ẹran olówó rẹ̀;
Àwọn èèyàn mi ò fi òye hùwà.”
4 O gbé! Ìwọ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,+
Àwọn èèyàn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn,
Ìran àwọn èèyàn burúkú, àwọn ọmọ oníwà ìbàjẹ́!
5 Ibo la tún lè lù lára yín nígbà tí ẹ kò jáwọ́ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ yín?+
Gbogbo orí yín ló ń ṣàìsàn
Àrùn sì ti kọ lu gbogbo ọkàn yín.+
6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí, kò sí ibi tó gbádùn.
7 Ilẹ̀ yín ti di ahoro.
Wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.
Àwọn àjèjì jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.+
Ó dà bí ilẹ̀ tó di ahoro tí àwọn àjèjì gbà.+
8 Ó wá ku ọmọbìnrin Síónì nìkan, bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
Bí ahéré nínú oko kùkúńbà,*
Bí ìlú tí wọ́n gbógun tì.+
9 Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ nínú wa sí,
À bá ti dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,
À bá sì ti jọ Gòmórà.+
10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin apàṣẹwàá* Sódómù.+
Ẹ fetí sí òfin* Ọlọ́run wa, ẹ̀yin èèyàn Gòmórà.+
11 “Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ẹbọ yín ń ṣe mí?”+ ni Jèhófà wí.
“Àwọn ẹbọ sísun yín tí ẹ fi àgbò+ ṣe àti ọ̀rá àwọn ẹran tí ẹ bọ́ dáadáa + ti sú mi,
Inú mi ò dùn sí ẹ̀jẹ̀+ àwọn akọ ọmọ màlúù,+ ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́.+
13 Ẹ má ṣe mú àwọn ọrẹ ọkà tí kò ní láárí wá mọ́.
Tùràrí yín ń rí mi lára.+
Àwọn òṣùpá tuntun,+ sábáàtì+ àti pípe àpéjọ,+
Mi ò lè fara da bí ẹ ṣe ń pidán,+ tí ẹ sì tún ń ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀.
14 Mo* kórìíra àwọn òṣùpá tuntun yín àtàwọn àjọyọ̀ yín.
Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi;
Mi ò lè gbé e mọ́.
17 Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere, ẹ wá ìdájọ́ òdodo,+
Ẹ tọ́ àwọn aninilára sọ́nà;
Ẹ gbèjà àwọn ọmọ aláìníbaba,*
Kí ẹ sì gba ẹjọ́ opó rò.”+
18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+
“Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,
Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+
Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,
Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.
21 Ẹ wo bí ìlú olóòótọ́+ ṣe di aṣẹ́wó!+
Ìdájọ́ òdodo kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+
Òdodo ń gbé inú rẹ̀ nígbà kan,+
Àmọ́ ní báyìí, àwọn apààyàn ló wà níbẹ̀.+
23 Alágídí ni àwọn ìjòyè rẹ, àwọn àtàwọn olè jọ ń ṣiṣẹ́.+
Gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.+
24 Torí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Alágbára Ísírẹ́lì, kéde pé:
“Ó tó gẹ́ẹ́! Mi ò ní fàyè gba àwọn elénìní mi mọ́,
Màá sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.+
25 Màá yí ọwọ́ mi pa dà sí ọ,
Màá yọ́ ìdàrọ́ rẹ dà nù bíi pé mo fi ọṣẹ fọ ìdọ̀tí,
Màá sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.+
26 Màá dá àwọn adájọ́ rẹ pa dà sí bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀rẹ̀,
Àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ á sì rí bíi ti ìbẹ̀rẹ̀.+
Lẹ́yìn èyí, wọ́n máa pè ọ́ ní Ìlú Òdodo, Ìlú Olóòótọ́.+
28 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ máa fọ́ sí wẹ́wẹ́,+
Òpin sì máa dé bá àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀.+
30 Torí ẹ máa dà bí igi ńlá tí àwọn ewé rẹ̀ rọ+
Àti bí ọgbà tí kò lómi.