Orí Kẹrin
“Ẹ̀yin Ni Ẹlẹ́rìí Mi”!
1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àsọtẹ́lẹ̀, ìhà wo sì ni àwọn èèyàn rẹ̀ ní láti kọ sí àsọtẹ́lẹ̀ tó bá ti ṣẹ?
AGBÁRA láti lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni ohun kan tó fi Ọlọ́run tòótọ́ hàn yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, ìdí tó fi sọ ọ́ ré kọjá pé ó wulẹ̀ ń fi jíjẹ́ tí ó jẹ́ Ọlọ́run hàn. Bí Aísáyà orí kẹtàlélógójì ṣe fi hàn, Jèhófà máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti fi ẹ̀rí jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí ó ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ tí ó bá dá májẹ̀mú hàn. Ní ti àwọn èèyàn rẹ̀ ní tiwọn, wọn kò gbọ́dọ̀ rí òye ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì tún wá ṣẹnu mẹ́rẹ́n; wọ́n ní láti jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n rí. Dájúdájú, wọ́n ní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí Jèhófà!
2. (a) Kí ni ipò tí Ísírẹ́lì wà nípa tẹ̀mí nígbà ayé Aísáyà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe la àwọn èèyàn rẹ̀ lójú?
2 Ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà ayé Aísáyà, ipò tí Ísírẹ́lì wà burú gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà fi ka àwọn èèyàn yẹn sí abirùn nípa tẹ̀mí. Ó ní: “Mú àwọn ènìyàn tí ó fọ́jú wá, bí ojú tilẹ̀ ń bẹ, àti àwọn adití, bí wọ́n tilẹ̀ ní etí.” (Aísáyà 43:8) Báwo làwọn èèyàn tó fọ́jú tó sì dití nípa tẹ̀mí ṣe lè wá jẹ́ alààyè ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? Ọ̀nà kan ṣoṣo ló lè gbà rí bẹ́ẹ̀. Ojú wọn ní láti là kí etí wọn sì ṣí lọ́nà ìyanu. Ohun tí Jèhófà sì ṣe gan-an nìyẹn o! Báwo ló ṣe ṣe é? Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà fi dẹndẹ ìyà jẹ wọ́n, ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá dèrò ìgbèkùn lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, tí àwọn ará Júdà sì dèrò ìgbèkùn lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn náà, Jèhófà fi agbára gbé ìgbésẹ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ̀ nípa dídá wọn nídè, tí ó sì mú àwọn àṣẹ́kù tí okun wọn nípa tẹ̀mí ti sọjí padà wá sí ìlú ìbílẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àní, ó dá Jèhófà lójú gan-an ni pé kò sóhun tó lè ké ète òun yìí nígbèrí, ìyẹn ló fi jẹ́ pé nǹkan bí igba ọdún ṣáájú ló ti sọ̀rọ̀ ìdáǹdè Ísírẹ́lì bíi pé ó tilẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.
3. Ìṣírí wo ni Jèhófà fún àwọn tí yóò dèrò ìgbèkùn lẹ́yìnwá ọ̀la?
3 Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá rẹ, ìwọ Jékọ́bù, àti Aṣẹ̀dá rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì: ‘Má fòyà, nítorí pé mo ti tún ọ rà. Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́. Tèmi ni ọ́. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o gba inú omi kọjá, èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ dájúdájú; bí o bá sì gba inú àwọn odò kọjá, wọn kì yóò kún bò ọ́. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o rin inú iná kọjá, kì yóò jó ọ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ iná pàápàá kì yóò wì ọ́. Nítorí pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí í ṣe Olùgbàlà rẹ.’”—Aísáyà 43:1-3a.
4. Báwo ló ṣe jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ló sì fún àwọn èèyàn rẹ̀ nípa pípadà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn?
4 Jèhófà ní ìfẹ́ àkànṣe sí Ísírẹ́lì nítorí pé tirẹ̀ ni orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́. Òun fúnra rẹ̀ ló gbé orílẹ̀ èdè yẹn kalẹ̀ ní ìmúṣẹ májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3) Ìyẹn ni Sáàmù 100:3 fi sọ pé: “Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa. Àwa ni ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀.” Bí Jèhófà ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Olùràpadà Ísírẹ́lì, yóò kó àwọn èèyàn rẹ̀ padà délé koko ni. Àwọn ohun ìdènà bí omi, àwọn odò tó kún àkúnya àtàwọn aṣálẹ̀ oníná kò ní ṣèdíwọ́ fún wọn, kò tilẹ̀ ní pa wọ́n lára, gan-an bí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣe dí àwọn baba ńlá wọn lọ́wọ́ lẹ́nu ìrìn wọn lọ́nà Ilẹ̀ Ìlérí ní ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.
5. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe jẹ́ ìtùnú fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí? (b) Àwọn wo ni alábàákẹ́gbẹ́ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, àwọn wo ló sì ṣàpẹẹrẹ wọn?
5 Ọ̀rọ̀ Jèhófà tún jẹ́ ìtùnú fún àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí lóde òní, àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “ìṣẹ̀dá tuntun” tí a fi ẹ̀mí bí. (2 Kọ́ríńtì 5:17) Bí wọ́n ṣe fi ìgboyà jáde wá síwájú “omi” ìran ènìyàn, Ọlọ́run fi ààbò onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bò wọ́n la inú àwọn ìkún omi ìṣàpẹẹrẹ já. Iná tó ń ṣẹ́ yọ látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá wọn kò ṣe wọ́n léṣe rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló tilẹ̀ tún yọ́ wọn mọ́ pàápàá. (Sekaráyà 13:9; Ìṣípayá 12:15-17) Jèhófà sì tún nawọ́ ìpamọ́ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” pẹ̀lú, àwọn tí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àwọn wọ̀nyí ni “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì àti àwọn tí kì í ṣe Júù tó bá àwọn ìgbèkùn tó dòmìnira padà wá láti Bábílónì ń ṣàpẹẹrẹ.—Ẹ́kísódù 12:38; Ẹ́sírà 2:1, 43, 55, 58.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo lòun ní ti ọ̀ràn ìràpadà (a) Ísírẹ́lì nípa ti ara? (b) Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
6 Ìlérí Jèhófà ni pé òun yóò lo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà láti fi dá àwọn èèyàn òun nídè kúrò ní Bábílónì. (Aísáyà 13:17-19; 21:2, 9; 44:28; Dáníẹ́lì 5:28) Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, Jèhófà yóò fi ìràpadà tí ó tọ́ san èrè fún “òṣìṣẹ́” rẹ̀, Mídíà òun Páṣíà, dípò Ísírẹ́lì. Ó ní: “Mo ti fi Íjíbítì fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà rẹ, Etiópíà àti Sébà dípò rẹ. Nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ṣe iyebíye ní ojú mi, a kà ọ́ sí ẹni tí ó ní ọlá, èmi fúnra mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Èmi yóò sì fi àwọn ènìyàn fúnni dípò rẹ, àti àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè dípò ọkàn rẹ.” (Aísáyà 43:3b, 4) Ìtàn jẹ́rìí sí i pé Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ṣẹ́gun Íjíbítì, Etiópíà, àti Sébà ìtòsí wọn lóòótọ́, bí Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Òwe 21:18) Lọ́dún 1919, bákan náà ni Jèhófà ṣe lo Jésù Kristi láti fi dá àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí nídè kúrò nígbèkùn. Àmọ́ ṣá o, ní ti Jésù, kò sí pé a ń san èrè fún un nítorí iṣẹ́ tí ó ṣe. Kèfèrí alákòóso kọ́ lòun. Àti pé, àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí ló dá nídè. Yàtọ̀ síyẹn, lọ́dún 1914, Jèhófà ti “fi àwọn orílẹ̀-èdè fún [un] gẹ́gẹ́ bí ogún [rẹ̀] àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní [rẹ̀].”—Sáàmù 2:8.
7. Kí ni ìṣarasíhùwà Jèhófà sí àwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ àti lóde òní?
7 Ẹ ṣàkíyèsí pé Jèhófà kò fi ìyọ́nú tó ní sí àwọn ìgbèkùn tí ó rà padà bò. Ó sọ fún wọn pé wọ́n ṣe “iyebíye” pé wọ́n sì ní “ọlá” lójú òun, àti pé òun “nífẹ̀ẹ́” wọn. (Jeremáyà 31:3) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ náà ni ọ̀ràn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin lóde òní ṣe rí lára rẹ̀, àní ó tilẹ̀ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Àbímọ́ni kọ́ ni àjọṣe tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá Ọlọ́run ní, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló mú wọn wọ àjọṣe yẹn lẹ́yìn tí wọ́n ti fúnra wọn ya ara wọn sí mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá wọn. Jèhófà ló fà wọ́n mọ́ Ọmọ rẹ̀ àti òun tìkára rẹ̀, tó sì wá kọ àwọn òfin rẹ̀ àti ìlànà rẹ̀ sínú ọkàn-àyà ìgbàṣe wọn.—Jeremáyà 31:31-34; Jòhánù 6:44.
8. Ìfinilọ́kànbalẹ̀ wo ni Jèhófà fún àwọn ìgbèkùn, báwo ni ìdáǹdè wọn yóò sì ṣe rí lójú wọn?
8 Jèhófà túbọ̀ fi àwọn ìgbèkùn lọ́kàn balẹ̀, nípa sísọ̀rọ̀ síwájú sí i pé: “Má fòyà, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ. Láti yíyọ oòrùn ni èmi yóò ti mú irú-ọmọ rẹ wá, láti wíwọ̀-oòrùn ni èmi yóò sì ti kó ọ jọpọ̀. Èmi yóò wí fún àríwá pé, ‘Dá sílẹ̀!’ àti fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá dúró. Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ibi jíjìnnàréré, àti àwọn ọmọbìnrin mi láti ìkángun ilẹ̀ ayé, olúkúlùkù ẹni tí a ń fi orúkọ mi pè, tí mo sì dá fún ògo mi, tí mo ṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ ni, tí mo ṣe.’” (Aísáyà 43:5-7) Bó bá ti tó àkókò lójú Jèhófà láti tú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti dá wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ọ̀wọ́n, kódà ibi jíjìnnàréré jù lọ láyé yìí kò ní jìnnà jù fún Jèhófà láti dé. (Jeremáyà 30:10, 11) Láìsí àní-àní, lójú tiwọn, ìdáǹdè tí orílẹ̀-èdè wọn gbà kúrò ní Íjíbítì látijọ́ kò ní tó nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí.—Jeremáyà 16:14, 15.
9. Ọ̀nà méjì wo ni Jèhófà gbà wé iṣẹ́ ìdáǹdè tí ó ṣe pọ̀ mọ́ orúkọ rẹ̀?
9 Nípa rírán tí Jèhófà ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé orúkọ òun ni wọ́n fi ń pè wọ́n, ńṣe ló túbọ̀ ń mú kí ìlérí rẹ̀ láti dá Ísírẹ́lì nídè dájú. (Aísáyà 54:5, 6) Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà tún so orúkọ rẹ̀ mọ́ àwọn ìlérí ìdáǹdè tí ó ṣe. Ó ń ṣe ìyẹn láti mú kí ó dájú ṣáká pé ti òun ni ògo rẹ̀ máa jẹ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ òun bá ṣẹ. Kódà ẹni tó ṣẹ́gun Bábílónì kò lè lẹ́tọ̀ọ́ sí ọlá tó tọ́ sí ẹnì kan ṣoṣo tí í ṣe Ọlọ́run alààyè.
Àwọn Òrìṣà Ń Jẹ́jọ́
10. Ìpèníjà wo ni Jèhófà gbé ka iwájú àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn?
10 Jèhófà wá fi ìlérí ìdáǹdè tó ṣe fún Ísírẹ́lì ṣe ìdí ìpìlẹ̀ ẹjọ́ rẹ̀ nínú ìpẹ̀jọ́ àgbáyé kan tó ti mú kí àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè wá jẹ́jọ́. A kà á pé: “Kí a kó orílẹ̀-èdè gbogbo jọpọ̀ sí ibì kan, kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì kóra jọpọ̀. Ta ní ń bẹ nínú [àwọn òrìṣà] wọn tí ó lè sọ èyí? Tàbí kẹ̀, wọ́n ha lè mú kí a gbọ́ àní àwọn ohun àkọ́kọ́? Kí wọ́n [àwọn òrìṣà wọn] mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn jáde wá, kí a lè polongo wọn ní olódodo, tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì wí pé, ‘Òtítọ́ ni!’” (Aísáyà 43:9) Jèhófà gbé gbankọgbì ìpèníjà kalẹ̀ síwájú àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Lọ́rọ̀ kan ṣá ohun tó sọ ni pé: ‘Kí àwọn òrìṣà yín wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí kò ní yingin nípa ọjọ́ ọ̀la láti fi hàn pé ọlọ́run ni wọ́n.’ Nígbà tó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ló lè sọ tẹ́lẹ̀ kó má yẹ̀, ìdánwò yìí máa táṣìírí gbogbo ọlọ́run ẹ̀tàn ni. (Aísáyà 48:5) Ṣùgbọ́n, Olódùmarè tún fi àṣẹ béèrè ohun mìíràn síwájú sí i, ìyẹn ni pé: Gbogbo àwọn tó bá sọ pé ọlọ́run tòótọ́ làwọn ní láti kó ẹlẹ́rìí wá, ẹlẹ́rìí tí yóò jẹ́rìí pé wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀, àti ẹlẹ́rìí tí yóò sọ pé ó ṣẹ lóòótọ́. Láìsí àní-àní, Jèhófà kò yọ ara rẹ̀ sílẹ̀ nínú ohun tó fàṣẹ béèrè yìí.
11. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, kí ni Jèhófà sì ṣí payá nípa jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run?
11 Níwọ̀n bí àwọn òrìṣà kò ti lè dá ohunkóhun ṣe, wọn kò rí ẹlẹ́rìí mú jáde rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ìtìjú gbáà ló jẹ́, pé, páropáro ni àyè tó yẹ kí àwọn ẹlẹ́rìí wọn dúró sí dá. Wàyí o, ọpọ́n wá sún kan Jèhófà láti fi ẹ̀rí jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run múlẹ̀. Ni ó bá kọjú sí àwọn èèyàn rẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn, kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, àti pé kí ẹ lè lóye pé Ẹnì kan náà ni mí. Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó. Èmi—èmi ni Jèhófà, yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan. Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀ jáde, mo sì ti gbà là, mo sì ti mú kí a gbọ́ ọ, nígbà tí kò sí àjèjì ọlọ́run kankan láàárín yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . èmi sì ni Ọlọ́run. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní gbogbo ìgbà, Ẹnì kan náà ni mí; kò sì sí ẹni tí ń dáni nídè kúrò ní ọwọ́ mi. Èmi yóò gbé kánkán ṣiṣẹ́, ta sì ni ó lè yí [ọwọ́ mi] padà?”—Aísáyà 43:10-13.
12, 13. (a) Ẹ̀rí púpọ̀ yanturu wo ni àwọn èèyàn Jèhófà tò kalẹ̀? (b) Báwo ni orúkọ Jèhófà ṣe gba iwájú láyé òde òní?
12 Ní ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, kíákíá ni ògìdìgbó àwọn ẹlẹ́rìí ti ya bo àyè ìdúró tó wà fún àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀, tí ibẹ̀ sì kún àkúnfàya. Ẹ̀rí wọn yéni yékéyéké, kò sì ṣeé já ní koro. Bíi Jóṣúà àtijọ́ ni wọ́n ṣe jẹ́rìí pé ‘gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ló ti ṣẹ. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.’ (Jóṣúà 23:14) Àwọn èèyàn Jèhófà kò ì tí ì gbàgbé ọ̀rọ̀ Aísáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì, àti àwọn wòlíì mìíràn, tó jẹ́ pé wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà, ní ti pé, Júdà yóò lọ sí ìgbèkùn àti pé wọn yóò gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn lọ́nà ìyanu. (Jeremáyà 25:11, 12) Wọ́n ti dárúkọ ẹni tí yóò dá Júdà nídè, ìyẹn Kírúsì, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí i pàápàá!—Aísáyà 44:26-45:1.
13 Lójú ẹ̀rí tó ga bí òkè ńlá yìí, ta ní lè ṣàìgbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà? Jèhófà yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà Kèfèrí yòókù ní ti pé, òun nìkan ṣoṣo ni kò sẹ́ni tó dá a; òun nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́.a Nítorí náà, àwọn èèyàn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀, èyí tó ń mórí yá gágá, ìyẹn ni láti sọ ìṣe àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ìran ẹ̀yìn ọ̀la, àti àwọn mìíràn tó bá ń ṣèwádìí nípa rẹ̀. (Sáàmù 78:5-7) Lọ́nà kan náà, ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní, wọ́n láǹfààní láti kéde orúkọ Jèhófà ní gbogbo ayé. Ní àwọn ọdún 1920, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì túbọ̀ wá ń mọ bí ìjẹ́pàtàkì Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, ṣe jinlẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ní July 26, 1931, nígbà ìpàdé kan ní ìlú Columbus, Ohio, ààrẹ Society náà, Joseph F. Rutherford, gbé ìpinnu kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Orúkọ Tuntun” jáde fáwọn èèyàn láti tẹ́wọ́ gbà. Gbólóhùn náà, “Orúkọ tí a ń fẹ́ kí àwọn èèyàn fi mọ̀ wá kí wọ́n sì máa fi pè wá, láti ìsinsìnyí lọ ni, Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” wú àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ yẹn lórí gan-an ni, tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìpinnu yẹn nípa fífi ohùn rara sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni!” Láti ìgbà yẹn wá ni orúkọ Jèhófà ti di mímọ̀ nílé lóko.—Sáàmù 83:18.
14. Kí ni Jèhófà rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí, kí sì nìdí tí ìránnilétí yẹn fi bọ́ sí àkókò?
14 Jèhófà ń bójú tó àwọn tó ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́ orúkọ mọ́ ọn, ó sì kà wọ́n sí “ọmọlójú ojú rẹ̀.” Ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí èyí, ìyẹn ló fi sọ fún wọn nípa bí òun ṣe dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, tí òun sì ṣamọ̀nà wọn láìséwu gba inú aginjù kọjá. (Diutarónómì 32:10, 12) Ní ìgbà yẹn, kò sí àjèjì ọlọ́run kankan láàárín wọn, nítorí wọ́n fojú ara wọn rí bí ẹ̀tẹ́ ṣe bá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo àgbájọ òrìṣà àwọn ará Íjíbítì kò lè dáàbò bo Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì lè dènà Ísírẹ́lì kí wọ́n má lè lọ. (Ẹ́kísódù 12:12) Bákan náà, Bábílónì alágbára, tó jẹ́ pé ó kéré tán àádọ́ta tẹ́ńpìlì gàgàrà-gàgàrà tí wọ́n kọ́ fún àwọn òrìṣà ló wà káàkiri inú ìlú ńlá rẹ̀, kò lè dènà Olódùmarè nígbà tó dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú, “kò sí olùgbàlà kankan” yàtọ̀ sí Jèhófà.
Àwọn Ẹṣin Ogun Ṣubú, Ilẹ̀kùn Ẹ̀wọ̀n Ṣí
15. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì?
15 Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà yín, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì: ‘Nítorí yín, ṣe ni èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì, èmi yóò sì mú kí àwọn ọ̀pá ìdábùú ẹ̀wọ̀n kí ó wálẹ̀, àti àwọn ará Kálídíà tí ó wà nínú àwọn ọkọ̀ òkun pẹ̀lú kíké tẹ̀dùntẹ̀dùn níhà ọ̀dọ̀ wọn. Èmi ni Jèhófà Ẹni Mímọ́ yín, Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, Ọba yín.’ Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹni tí ń la ọ̀nà gba inú òkun pàápàá kọjá àti òpópónà àní gba inú omi lílágbára kọjá, Ẹni tí ń mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹṣin jáde wá, ẹgbẹ́ ológun àti àwọn alágbára lẹ́ẹ̀kan náà: ‘Wọn yóò dùbúlẹ̀. Wọn kì yóò dìde. Ṣe ni a óò fẹ́ wọn pa. Gẹ́gẹ́ bí òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe ni a óò fẹ́ wọn pa.’”—Aísáyà 43:14-17.
16. Àjálù wo ni yóò bá Bábílónì, àti àwọn oníṣòwò ará Kálídíà, àti ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ dáàbò bo Bábílónì?
16 Ẹ̀wọ̀n ni Bábílónì jẹ́ lójú àwọn ìgbèkùn nítorí pé kò jẹ́ kí wọ́n padà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun tí Bábílónì fi dáàbò bo ara rẹ̀ kò lè dènà Olódùmarè, Ẹni tó jẹ́ pé, nígbà ìṣáájú, ó ti “la ọ̀nà gba inú [Òkun Pupa] pàápàá kọjá àti òpópónà àní gba inú omi lílágbára kọjá,” ìyẹn sì ṣeé ṣe kó jẹ́ odò Jọ́dánì. (Ẹ́kísódù 14:16; Jóṣúà 3:13) Bákan náà, Kírúsì, ońṣẹ́ Jèhófà, yóò mú kí alagbalúgbú odò Yúfírétì fà, kí àwọn jagunjagun rẹ̀ lè ráyè wọ ìlú ńlá náà. Ńṣe ni àwọn oníṣòwò tó ń gba àwọn ipadò Bábílónì, ìyẹn àwọn ojú omi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò àti ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù tó kó àwọn òrìṣà àwọn ará Bábílónì ń gbà, yóò ké tẹ̀dùntẹ̀dùn nígbà tí olú ìlú wọn alágbára bá ṣubú. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ayára-bí-àṣá àwọn ará Bábílónì kò ní lè gbé ohunkóhun ṣe, bíi ti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Fáráò nínú Òkun Pupa ni ọ̀ràn wọn yóò ṣe rí. Wọn kò ní gbà á sílẹ̀. Bí ẹní fẹ́ná òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe pa ni àwọn tó wá gbógun jà wọ́n yóò ṣe gbẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbèjà rẹ̀.
Jèhófà Ṣamọ̀nà Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Délé Koko
17, 18. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ ohun “tuntun” wo ni Jèhófà sọ? (b) Ọ̀nà wo làwọn èèyàn yẹn ò fi ní rántí àwọn nǹkan àtijọ́, èé sì ti ṣe?
17 Jèhófà wá fi àwọn ìdáǹdè tí òun ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí wéra pẹ̀lú èyí tí òun máa tó ṣe, ó ní: “Ẹ má ṣe rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́, ẹ má sì yí ìrònú yín padà sí àwọn nǹkan àtijọ́. Wò ó! Èmi yóò ṣe ohun tuntun kan. Ìsinsìnyí ni yóò rú yọ. Ẹ ó mọ̀ ọ́n, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ní ti tòótọ́, èmi yóò la ọ̀nà kan gba inú aginjù, gba inú àwọn odò aṣálẹ̀. Ẹranko ìgbẹ́ yóò yìn mí lógo, àwọn akátá àti ògòǹgò; nítorí pé èmi yóò ti pèsè omi ní aginjù, àwọn odò ní aṣálẹ̀, láti mú kí àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, kí ó mu, àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.”—Aísáyà 43:18-21.
18 Nígbà tí Jèhófà sọ pé “ẹ má ṣe rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́,” kì í ṣe pé ó ń dá a lábàá pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun pa àwọn ìdáǹdè tí òun ti ṣe rẹ́ kúrò nínú ọkàn wọn. Kódà, púpọ̀ lára àwọn ìdáǹdè wọ̀nyí jẹ́ apá kan ìtàn Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run mí sí, Jèhófà sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣèrántí àjàbọ́ wọn kúrò ní Íjíbítì lọ́dọọdún nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá. (Léfítíkù 23:5; Diutarónómì 16:1-4) Àmọ́, ní báyìí, Jèhófà ń fẹ́ kí yíyìn tí àwọn èèyàn òun yóò yin òun lógo jẹ́ lórí ìpìlẹ̀ “ohun tuntun,” ìyẹn ni ohun tí wọn yóò fojú ara wọn rí kòrókòró. Èyí kò sì mọ sórí ìdáǹdè wọn kúrò ní Bábílónì, ó tún kan ìrìn àjò ìyanu tí wọn yóò rìn délé, bóyá nípa gbígba ọ̀nà aṣálẹ̀ tó túbọ̀ ṣe tààrà. Jèhófà yóò la “ọ̀nà kan” fún wọn nínú aṣálẹ̀ yẹn, yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ àrà tó jọ èyí tó ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè, àní, yóò bọ́ àwọn tó ń padà lọ sílé yìí nínú aginjù, yóò sì fi àwọn odò tó ń ṣàn gbùúgbùú pa òùngbẹ wọn. Àwọn ìpèsè Jèhófà yóò pọ̀ yanturu débi pé àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá yóò yin Ọlọ́run lógo, wọn kò sì ní pa ẹnikẹ́ni lára.
19. Báwo ni àṣẹ́kù Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe ń rìn lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” náà?
19 Bákan náà, lọ́dún 1919, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí gba ìdáǹdè kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbéra ìrìn àjò lójú ọ̀nà tí Jèhófà ti là kalẹ̀ fún wọn, ìyẹn “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” (Aísáyà 35:8) Ìrìn àjò tiwọn kò dà bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì o, torí kò sí ti pé wọ́n ń la inú aṣálẹ̀ oníná kọjá láti ìlú kan pàtó sí òmíràn, wọn kò sì parí ìrìn àjò wọn sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn oṣù mélòó kan. Àmọ́, “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn gbé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dé inú párádísè tẹ̀mí. Ní tiwọn, wọn kò ṣíwọ́ ìrìn lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́,” nítorí pé wọ́n ṣì ní láti rin ìrìn àjò la inú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já. Bí wọn kò bá sì ti yà kúrò lójú òpópónà yẹn, ìyẹn, bí wọ́n bá ṣáà ti ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà mímọ́ àti ìjẹ́mímọ́ ti Ọlọ́run, wọn yóò máa bá a lọ láti wà nínú párádísè tẹ̀mí ni. Ayọ̀ ńláǹlà mà ló sì jẹ́ fún wọn o pé ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n jẹ́ “àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì” wá dara pọ̀ mọ́ wọn láti bá wọn kẹ́gbẹ́! Ọ̀ràn àwọn àṣẹ́kù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò rí bíi ti àwọn tó gbára lé ètò àwọn nǹkan ti Sátánì, ńṣe ni wọ́n ń jẹ àkànṣe àsè nípa tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Aísáyà 25:6; 65:13, 14) Bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹhànnà èèyàn ṣe wá róye bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ yìí, ni wọ́n bá yíwà padà, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run tòótọ́ lógo.—Aísáyà 11:6-9.
Jèhófà Fi Ìbínú Rẹ̀ Hàn
20. Báwo ni Ísírẹ́lì ìgbà ayé Aísáyà ṣe já Jèhófà kulẹ̀?
20 Láyé àtijọ́, ìwà àṣẹ́kù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó padà bọ̀ ti yí padà pátápátá, wọ́n ti yàtọ̀ sí ìràn burúkú ti ìgbà ayé Aísáyà. Àwọn ìran burúkú yẹn ni Jèhófà sọ fún pé: “Ìwọ kò pe èmi pàápàá, ìwọ Jékọ́bù, nítorí tí agara mi ti dá ọ, ìwọ Ísírẹ́lì. Ìwọ kò mú àgùntàn àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ wá fún mi, o kò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo. Èmi kò ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ọ pé kí o fi ẹ̀bùn sìn mí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi oje igi tùràrí dá ọ lágara. Ìwọ kò fi owó kankan ra ewéko dídùn onípòròpórò wá fún mi; ìwọ kò sì fi ọ̀rá àwọn ẹbọ rẹ rin mí gbingbin. Ní ti gidi, ìwọ ti sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún mi láti sìn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ; o ti fi àwọn ìṣìnà rẹ dá mi lágara.”—Aísáyà 43:22-24.
21, 22. (a) Kí ni ìdí tí a fi lè sọ pé àwọn ohun tí Jèhófà béèrè kì í ṣe ẹrù ìnira? (b) Báwo ni àwọn èèyàn yìí ṣe dà bíi pé wọ́n kúkú ń mú kí Jèhófà máa ṣiṣẹ́ fún wọn?
21 Sísọ tí Jèhófà sọ pé, “Èmi kò ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ọ pé kí o fi ẹ̀bùn sìn mí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi oje igi tùràrí dá ọ lágara,” kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń sọ pé òun kò béèrè ẹbọ àti oje igi tùràrí (ara èròjà tùràrí mímọ́). Ní tòdodo, àpá pàtàkì lára ìsìn tòótọ́ ló jẹ́ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ sì ni ọ̀ràn ti ‘ewéko onípòròpórò’ pẹ̀lú, tó tọ́ka sí ewéko kálámọ́sì olóòórùn dídùn, èyí tó jẹ́ ara èròjà olóòórùn dídùn tó wà nínú òróró àfiyanni mímọ́. Ńṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa wọ́n tì, láìlò wọ́n mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n, ṣé ẹrù ìnira wá ni irú àwọn nǹkan tí Jèhófà béèrè wọ̀nyí ni? Rárá o! Àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè fúyẹ́ gẹgẹ tí a bá fi wéra pẹ̀lú èyí tí àwọn òrìṣà ń gbà. Bí àpẹẹrẹ, ẹbọ tí wọ́n fi ọmọ rú ni òrìṣà Mólékì máa ń gbà, ohun tó jẹ́ pé Jèhófà kò béèrè rí!—Diutarónómì 30:11; Míkà 6:3, 4, 8.
22 Ká ní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òye tẹ̀mí ni, ‘agara Jèhófà’ kì bá máà ‘dá wọn’ láéláé. Bí wọ́n bá wo inú Òfin rẹ̀ wọn ì bá rí i pé ó fẹ́ràn wọn dénúdénú, wọn ì bá sì ti fi ìdùnnú fi “ọ̀rá” rúbọ sí i, ìyẹn, èyí tó dára jù lọ lára àwọn ẹbọ wọn. Ṣùgbọ́n, ara wọn ni wọ́n ń fi ìwọra tọ́jú ọ̀rá yẹn fún. (Léfítíkù 3:9-11, 16) Áà, orílẹ̀-èdè burúkú yẹn mà kúkú fi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọn wàhálà Jèhófà o, àfi bíi pé wọ́n mú kí Jèhófà kúkú máa ṣiṣẹ́ fún wọn!—Nehemáyà 9:28-30.
Ìbáwí Yọrí sí Rere
23. (a) Kí ni ìdí tí ìbáwí tí Jèhófà fi fún wọn fi tọ́ sí wọn? (b) Kí ló wé mọ́ ìbáwí tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì?
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà bá wọn wí lọ́nà tó le koko, tí ó sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe, ìyẹn ló fi lè wá ṣàánú wọn. Ó ní:“Èmi—èmi ni Ẹni tí ń nu àwọn ìrélànàkọjá rẹ kúrò nítorí tèmi, èmi kì yóò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Rán mi létí; ẹ jẹ́ kí a jọ mú ara wa wọnú ìdájọ́; sọ ìròyìn tìrẹ nípa rẹ̀ kí o lè jàre. Baba tìrẹ, ẹni àkọ́kọ́, ti ṣẹ̀, àwọn agbọ̀rọ̀sọ [“ògbufọ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] rẹ sì ti rélànà mi kọjá. Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn ọmọ aládé ibi mímọ́ di aláìmọ́, ṣe ni èmi yóò sì fi Jékọ́bù léni lọ́wọ́ bí ọkùnrin tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì lé àwọn ọ̀rọ̀ èébú lọ́wọ́.” (Aísáyà 43:25-28) Àtọmọdọ́mọ Ádámù, “ẹni àkọ́kọ́,” ni Ísírẹ́lì jẹ́ bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ọmọ Ísírẹ́lì kankan tó lè rojọ́ tirẹ̀ kí ó “jàre.” Kódà àwọn “agbọ̀rọ̀sọ” fún Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn olùkọ́ni ní Òfin, tàbí ògbufọ̀ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì, pàápàá ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì ti fi èké kọ́ni. Jèhófà ní tirẹ̀ yóò fi gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn léni lọ́wọ́ “fún ìparun,” àti “ọ̀rọ̀ èébú.” Yóò sì tún sọ gbogbo àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ní “ibi mímọ́” tàbí ibùjọsìn rẹ̀ di aláìmọ́.
24. Fún ìdí wo ní pàtàkì ni Jèhófà yóò fi dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ti ayé àtijọ́ àti tòde òní, síbẹ̀, báwo ni ọ̀ràn wọn ṣe rí lára rẹ̀?
24 Àmọ́ ṣá o, ṣàkíyèsí pé, ìròbìnújẹ́ Ísírẹ́lì nìkan kọ́ ló máa mú kí Ọlọ́run ṣàánú wọn; tìtorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ni. Dájúdájú, orúkọ rẹ̀ wé mọ́ ọn. Ká ní pé ó fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ nígbèkùn títí gbére ni, àwọn tó ń wò wọ́n ì bá bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn orúkọ òun gan-an alára. (Sáàmù 79:9; Ìsíkíẹ́lì 20:8-10) Bákan náà ni lóde òní, ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà àti ìdáláre ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ló ṣáájú ìgbàlà ọmọ aráyé. Àmọ́ ṣá, Jèhófà fẹ́ràn àwọn tó bá fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ìbáwí rẹ̀, tí wọ́n sì sìn ín ní ẹ̀mí àti òtítọ́. Ó ń fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn wọ̀nyí nípa pípa ìrélànàkọjá wọn rẹ́ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, wọn ì báà jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn mìíràn.—Jòhánù 3:16; 4:23, 24.
25. Àwọn iṣẹ́ àrà ńlá wo ni Jèhófà yóò ṣe láìpẹ́ láìjìnnà, báwo la sì ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn nísinsìnyí?
25 Síwájú sí i, láìpẹ́, Jèhófà yóò fi hàn pé òun fẹ́ràn ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó jẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ adúróṣinṣin, nígbà tó bá ṣe ohun tuntun nítorí tiwọn nípa gbígbà wọ́n là láti inú “ìpọ́njú ńlá” bọ́ sínú “ayé tuntun” tó mọ́ tónítóní. (Ìṣípayá 7:14; 2 Pétérù 3:13) Wọn yóò fojú ara wọn rí ọ̀nà àgbàyanu jù lọ tí aráyé tí ì rí kí Jèhófà gbà lo agbára rẹ̀ rí. Dídájú tó dájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ ń mú kí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti gbogbo àwọn tí yóò para pọ̀ di ogunlọ́gọ̀ ńlá máa yọ̀, kí wọ́n sì máa gbé ìgbésí ayé ojoojúmọ́ níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ takuntakun tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ yìí, pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi”!—Aísáyà 43:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìwáṣẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè máa ń fi hàn pé “bíbí” ni wọ́n “bí” ọ̀pọ̀ nínú òrìṣà wọn, pé àwọn náà sì “bímọ.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 48, 49]
Jèhófà yóò ti àwọn Júù lẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá ń lọ sílé wọn ní Jerúsálẹ́mù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 52]
Jèhófà pe àwọn orílẹ̀-èdè níjà pé kí wọ́n kó ẹlẹ́rìí jáde ní ìtìlẹyìn àwọn òrìṣà wọn
1. Ère Báálì tí wọ́n fi idẹ ṣe 2. Àwọn ère Áṣítórétì kéékèèké tí wọ́n fi amọ̀ ṣe 3. Mẹ́talọ́kan àwọn ará Íjíbítì, ìyẹn Hórúsì, Ósírísì, àti Ísísì 4. Òrìṣà Átẹ́nà (apá òsì) àti Áfúródáítì ti àwọn Gíríìkì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 58]
“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.”—Aísáyà 43:10