Àìsáyà
“Má bẹ̀rù, torí mo ti tún ọ rà.+
Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́.
Tèmi ni ọ́.
Tí o bá rin inú iná kọjá, kò ní jó ọ,
Ọwọ́ iná ò sì ní rà ọ́.
3 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, Olùgbàlà rẹ.
Mo ti fi Íjíbítì ṣe ìràpadà fún ọ,
Mo sì ti fi Etiópíà àti Sébà dípò rẹ.
Torí náà, màá fi àwọn èèyàn rọ́pò rẹ,
Màá sì fi àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí* rẹ.
5 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+
6 Màá sọ fún àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀!’+
Màá sì sọ fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá wọn dúró.
Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ọ̀nà jíjìn àti àwọn ọmọbìnrin mi láti àwọn ìkángun ayé,+
7 Gbogbo ẹni tí wọ́n ń fi orúkọ mi pè,+
Tí mo sì dá fún ògo mi,
Tí mo ṣẹ̀dá, tí mo sì ṣe.’+
Èwo nínú wọn ló lè sọ èyí?
Àbí wọ́n lè mú ká gbọ́ àwọn ohun àkọ́kọ́?*+
Kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wá, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn jàre,
Tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì sọ pé, ‘Òótọ́ ni!’”+
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni Jèhófà wí,
“Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+
Kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,*
Kó sì yé yín pé Ẹnì kan náà ni mí.+
Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run tí a dá,
Lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan.+
11 Èmi, àní èmi ni Jèhófà,+ kò sí olùgbàlà kankan yàtọ̀ sí mi.”+
12 “Èmi ni Ẹni tó kéde, tó gbani là, tó sì mú kó di mímọ̀,
Nígbà tí kò sí ọlọ́run àjèjì kankan láàárín yín.+
Torí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Jèhófà wí, “èmi sì ni Ọlọ́run.+
Tí mo bá ń ṣe nǹkan kan, ta ló lè dá mi dúró?”+
14 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+
“Nítorí yín, màá ránṣẹ́ sí Bábílónì, màá sì gé gbogbo ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè lulẹ̀,+
Àwọn ará Kálídíà sì máa ké jáde nínú ìdààmú, nínú àwọn ọkọ̀ òkun wọn.+
15 Èmi ni Jèhófà, Ẹni Mímọ́ yín,+ Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì+ àti Ọba yín.”+
16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
Ẹni tó ń la ọ̀nà gba inú òkun,
Tó sì ń la ọ̀nà gba inú omi tó ń ru gùdù,+
17 Ẹni tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹṣin jáde,+
Àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú:
“Wọ́n máa dùbúlẹ̀, wọn ò sì ní dìde.+
A máa fẹ́ wọn pa, a máa pa wọ́n bí òwú àtùpà tó ń jó.”
18 “Ẹ má ṣe rántí àwọn ohun àtijọ́,
Ẹ má sì máa ronú nípa ohun tó ti kọjá.
Ṣé ẹ ò mọ̀ ọ́n ni?
20 Ẹran igbó máa bọlá fún mi,
Àwọn ajáko* àti ògòǹgò,
Torí mo pèsè omi ní aginjù,
Odò ní aṣálẹ̀,+
Fún àwọn èèyàn mi, àwọn àyànfẹ́ mi,+ kí wọ́n lè mu,
21 Àwọn èèyàn tí mo dá fún ara mi,
Kí wọ́n lè kéde ìyìn mi.+
23 O ò mú àgùntàn wá fún mi láti fi rú àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ,
O ò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo.
Mi ò fi dandan mú ọ pé kí o mú ẹ̀bùn wá fún mi,
Mi ò sì fi oje igi tùràrí tí mo ní kí o mú wá dá ọ lágara.+
Dípò ìyẹn, ṣe lo fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ di ẹrù wọ̀ mí lọ́rùn,
O sì fi àwọn àṣìṣe rẹ tán mi lókun.+
26 Rán mi létí; jẹ́ ká gbé ẹjọ́ wa wá;
Ro ẹjọ́ rẹ, kí o lè fi hàn pé o jàre.