Ìyàsímímọ́ àti Òmìnira Ṣíṣe Yíyàn
“Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira.”—GÁLÁTÍÀ 5:1.
1. Kí ni a lo ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí a tú sí “ìyàsímímọ́,” ‘ayẹyẹ ṣíṣílé,’ tàbí ‘ìyàsọ́tọ̀,’ fún ní pàtàkì?
ÀWỌN tí ó kọ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì mélòó kan láti gbé èrò yíyà sọ́tọ̀ fún ète ọlọ́wọ̀ yọ. Nínú àwọn Bíbélì èdè Yorùbá, a lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìyàsímímọ́,” ‘ayẹyẹ ṣíṣílé,’ tàbí ‘ìyàsọ́tọ̀,’ láti tú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Nígbà mìíràn, a lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ilé—lọ́pọ̀ ìgbà nípa tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì àti ìjọsìn tí a ń ṣe níbẹ̀. A kì í sábà lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti tọ́ka sí àwọn ohun tí kò jẹ mọ́ ti ìsìn.
Ìyàsímímọ́ fún “Ọlọ́run Ísírẹ́lì”
2. Èé ṣe tí ó fi tọ́ láti pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Ísírẹ́lì”?
2 Ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè ní oko ẹrú àwọn ará Íjíbítì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ̀ àrà ọ̀tọ̀, ó mú wọn wọnú ìbátan onímájẹ̀mú. Ó sọ fún wọn pé: “Wàyí o, bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi.” (Ẹ́kísódù 19:5; Sáàmù 135:4) Níwọ̀n bí ó ti sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di àkànṣe dúkìá rẹ̀, ó tọ́ láti pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”—Jóṣúà 24:23.
3. Èé ṣe tí a kò fi lè sọ pé Jèhófà ṣe ojúsàájú ní yíyàn tí ó yan Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ̀?
3 Jèhófà kò ṣe ojúsàájú ní sísọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di àwọn ènìyàn tí a yà sí mímọ́ fún un, nítorí pé ó ní àníyàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú. Ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé: “Bí ó bá . . . ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọ́dọ̀ fojú rẹ̀ gbolẹ̀. Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” (Léfítíkù 19:33, 34) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, a tẹ ojú ìwòye Ọlọ́run mọ́ àpọ́sítélì Pétérù lọ́kàn, tí ó sọ gbangba gbàǹgbà pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
4. Àwọn ipò wo ni ìbátan tí ó wà láàárín Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì sinmi lé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ha sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn bí?
4 Ṣàkíyèsí pẹ̀lú pé, jíjẹ́ ènìyàn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run sinmi lórí àwọn ipò kan. Kìkì bí wọ́n bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ ni wọn yóò tó jẹ́ “àkànṣe dúkìá” rẹ̀. Ó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè fún wọ̀nyí. Lẹ́yìn tí wọ́n kọ Mèsáyà tí Ọlọ́run rán wá ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, wọ́n pàdánù ipò àǹfààní tí wọ́n ní. Jèhófà kò jẹ́ “Ọlọ́run Ísírẹ́lì” mọ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí pẹ̀lú kò jẹ́ àwọn ènìyàn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run mọ́.—Fi wé Mátíù 23:23.
Ìyàsímímọ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”
5, 6. (a) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí a kọ sínú Mátíù 21:42, 43? (b) Nígbà wo ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wá sójú táyé, lọ́nà wo sì ni?
5 Èyí ha túmọ̀ sí pé Jèhófà wà láìní àwọn ènìyàn tí a yà sí mímọ́ fún un nísinsìnyí bí? Rárá o. Ní fífa ọ̀rọ̀ onísáàmù yọ, Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ṣé ẹ kò tíì kà nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ni èyí tí ó ti di olórí òkúta igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ohun ìyanu ní ojú wa’? Ìdí nìyí tí mo fi wí fún yín pé, A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.”—Mátíù 21:42, 43.
6 Ẹ̀rí fi hàn pé ìjọ Kristẹni ni “orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde” náà. Nígbà tí ó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, Jésù yan àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ mẹ́ńbà orílẹ̀-èdè náà. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ nípa títú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ àkọ́kọ́, tí iye wọ́n tó 120. (Ìṣe 1:15; 2:1-4) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́yìn náà, ìjọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yìí wá di “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” Èé ṣe tí a fi yàn wọ́n? Pé kí wọ́n lè “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:9) Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, tí a fi ẹ̀mí Ọlọ́run yàn, wá di orílẹ̀-èdè tí a yà sí mímọ́, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:16.
7. Kí ni àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run yóò gbádùn, nítorí náà, kí ni a ní kí wọ́n yẹra fún?
7 Bí àwọn mẹ́ńbà orílẹ̀-èdè mímọ́ náà tilẹ̀ jẹ́ “àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní,” wọn kò sí lábẹ́ ìsìnrú. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, wọn máa gbádùn òmìnira tí ó pọ̀ ju èyí tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àbínibí tí a yà sí mímọ́, gbádùn lọ. Jésù ṣèlérí fún àwọn tí yóò jẹ́ mẹ́ńbà orílẹ̀-èdè tuntun yìí pé: “Ẹ ó . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a dá àwọn Kristẹni sílẹ̀ lómìnira lọ́wọ́ àwọn ohun tí májẹ̀mú Òfin ń béèrè. Ní ti èyí, ó ṣí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó wà ní Gálátíà létí pé: “Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ kí a tún há yín mọ́ inú àjàgà ìsìnrú.”—Gálátíà 5:1.
8. Ní ọ̀nà wo ni ètò Kristẹni gbà fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan lómìnira tí ó ju èyí ti a gbádùn lábẹ́ májẹ̀mú Òfin?
8 Láìdàbí Ísírẹ́lì àbínibí ìgbàanì, Ísírẹ́lì Ọlọ́run ń ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí àwọn ohun tí ìyàsímímọ́ rẹ̀ béèrè fún, títí di òní olónìí. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí pé tinútinú ni àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ yàn láti ṣègbọràn. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì àbínibí di ẹni tí a yà sí mímọ́ nípasẹ̀ ìbí, àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run di bẹ́ẹ̀ nípa yíyàn tí wọ́n ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ètò Kristẹni yàtọ̀ pátápátá sí májẹ̀mú Òfin àwọn Júù, tí ó fagbára mú olúkúlùkù ṣe ìyàsímímọ́, láìfún wọn lómìnira láti ṣe yíyàn.
9, 10. (a) Báwo ni Jeremáyà ṣe fi hàn pé ìyípadà kan yóò wà ní ti ìyàsímímọ́? (b) Èé ṣe tí ìwọ yóò fi sọ pé kì í ṣe gbogbo Kristẹni tí ó ti ṣèyàsímímọ́ lónìí ni ó jẹ́ mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run?
9 Wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìyípadà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìyàsímímọ́, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe èyí tí ó rí bí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, “májẹ̀mú mi èyí tí àwọn fúnra wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni ọkọ olówó orí wọn,” ni àsọjáde Jèhófà.’ ‘Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.’”—Jeremáyà 31:31-33.
10 Nítorí tí wọ́n ní òfin Ọlọ́run ‘nínú wọn,’ tí a kọ ọ́ sí “inú ọkàn-àyà wọn,” kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, a sún àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn. Ìsúnniṣe wọ́n lágbára ju ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí, tí a yà sí mímọ́ nípa ìbí, tí kì í ṣe nípa yíyàn. Lónìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù márùn-ún, tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run kárí ayé ní irú ìsúnniṣe lílágbára láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tí Ísírẹ́lì Ọlọ́run fi hàn. Àwọn pẹ̀lú ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bí àwọn ẹni wọ̀nyí kò tilẹ̀ ní ìrètí wíwàláàyè ní ọ̀run, tí àwọn tí ó para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní, wọ́n dunnú nínú ìrètí wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. Wọ́n fi ìmọrírì hàn fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí nípa fífi taápọntaápọn ṣètìlẹ́yìn fún ìwọ̀nba mẹ́ńbà rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù, ní mímú iṣẹ́ àyànfúnni wọn ṣe láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”
Fífi Ọgbọ́n Lo Òmìnira tí Ọlọ́run Fúnni
11. Agbára wo ni a dá mọ́ ènìyàn, ọ̀nà wo ni ó sì yẹ kí a gbà lò ó?
11 Ọlọ́run dá ẹ̀dá ènìyàn láti ṣìkẹ́ òmìnira. Ó fún wọn ní agbára láti lo òmìnira ìfẹ́ inú. Tọkọtaya àkọ́kọ́ lo òmìnira ṣíṣe yíyàn tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n, wọ́n fi ìwà òmùgọ̀ àti àìnífẹ̀ẹ́ ṣe yíyàn tí ó yọrí sí ìjábá fún wọn àti fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Síbẹ̀, èyí fi hàn kedere pé Jèhófà kì í fipá mú àwọn ẹ̀dá onílàákàyè láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà kan tí ó lòdì sí ìfẹ́ inú wọn tàbí ìfẹ́-ọkàn wọn. Níwọ̀n bí “Ọlọ́run [ti] nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà,” ìyàsímímọ́ kan ṣoṣo tí ó tẹ́wọ́ gbà jẹ́ èyí tí a gbé karí ìfẹ́, èyí tí a ṣe tinútinú pẹ̀lú ọ̀yàyà, èyí tí a gbé ka òmìnira ṣíṣe yíyàn. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Òun kò tẹ́wọ́ gba irú mìíràn èyíkéyìí.
12, 13. Báwo ni Tímótì ṣe jẹ́ àwòṣe fún títọ́ ọmọ dàgbà lọ́nà yíyẹ, kí sì ni àpẹẹrẹ rẹ̀ ti sún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láti ṣe?
12 Ní mímọ ohun tí a ń béèrè yìí dáradára, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣalágbàwí yíyara ẹni sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n, wọn kì í fagbára mú ẹnikẹ́ni, àní àwọn ọmọ tiwọn pàápàá, láti ṣe irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe, Àwọn Ẹlẹ́rìí kì í batisí àwọn ọmọ wọn ní ọmọ ọwọ́, bí pé ó ṣeé ṣe láti fipá mú wọn ṣèyàsímímọ́ láìfúnra wọn ṣe yíyàn. Àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ tí ó yẹ kí a tẹ̀ lé ni ti èyí tí ọ̀dọ́kùnrin náà, Tímótì, tẹ̀ lé. Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tímótì 3:14, 15.
13 Ó dára láti kíyè si pé, Tímótì mọ ìwé mímọ́ nítorí a fi wọ́n kọ́ ọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló. Ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà yí i lérò padà—wọn kò fipá mú un—láti gba àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni gbọ́. (2 Tímótì 1:5) Nítorí èyí, Tímótì rí ọgbọ́n tí ń bẹ nínú dídi ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fúnra rẹ̀ yàn láti ṣèyàsímímọ́ Kristẹni. Ní òde òní, ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀dọ́, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí àwọn òbí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí. (Sáàmù 110:3) Àwọn mìíràn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Yíyàn olúkúlùkù ni.
Ẹrú Ta Ni O Yàn Láti Jẹ́?
14. Kí ni Róòmù 6:16 sọ fún wa nípa òmìnira pátápátá?
14 Kò sí ẹ̀dá ènìyàn tí ó lómìnira pátápátá. Àwọn òfin àdánidá, irú bí òfin òòfà ilẹ̀, tí a kò lè gbójú fò láìjìyà rẹ̀, dín òmìnira olúkúlùkù kù. Bákan náà ni ó rí nípa tẹ̀mí, kò sí ẹni tí ó lómìnira pátápátá. Pọ́ọ̀lù ronú lọ́nà yìí, pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i, yálà ti ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ikú níwájú tàbí ti ìgbọràn pẹ̀lú òdodo níwájú?”—Róòmù 6:16.
15. (a) Ojú wo ni àwọn ènìyàn fi ń wo jíjẹ́ ẹrú, ṣùgbọ́n kí ni ọ̀pọ̀ máa ń pàpà ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè tí ó yẹ wo ni a lè bi ara wa?
15 Èrò jíjẹ́ ẹrú ẹnì kan kì í dùn mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú. Síbẹ̀, nínú ayé òde òní, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn ènìyàn sábà máa ń jẹ́ kí a tàn wọ́n jẹ́, kí a sì lo agbára lórí wọn, ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọn kò fura sí, débi pé wọ́n máa ń pàpà ṣe àwọn ohun tí àwọn ẹlòmíràn fẹ́ kí wọ́n ṣe láìtinú wọn wá. Fún àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ ìpolówó ọjà àti ayé ohun ìnàjú ń gbìdánwò láti darí ìrònú àti ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn láti máa ṣe ohun kan náà, wọ́n ń gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n kalẹ̀ fún wọn láti tẹ̀ lé. Àwọn ètò ìṣèlú àti ti ìsìn ń mú kí àwọn ènìyàn ti èrò àti góńgó wọn lẹ́yìn, kì í sábà jẹ́ nípa ẹ̀rí tí wọ́n mú dáni lójú, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń jẹ́ nípa ríru ẹ̀mí àjùmọ̀ṣe tàbí ti ìdúróṣinṣin sókè nínú àwọn ènìyàn. Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé, ‘a jẹ́ ẹrú àwọn tí a ń ṣègbọràn sí,’ olúkúlùkù wa yóò ṣe dáradára láti bi ara rẹ̀ pé, ‘Ẹrú ta ni mo ń ṣe? Ta ní ń nípa tí ó ga jù lórí àwọn ìpinnu mi àti ìgbésí ayé mi? Ṣé àwọn àlùfáà ìsìn, àwọn aṣáájú ìṣèlú, àwọn oníṣòwò pàtàkì, tàbí àwọn olókìkí nínú eré ìnàjú ni? Ta ni mo ń ṣègbọràn sí—ṣé Ọlọ́run ni tàbí ènìyàn?’
16. Ní ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni gbà jẹ́ ẹrú Ọlọ́run, ojú wo ni ó sì yẹ kí a fi wo irú ìsìnrú bẹ́ẹ̀?
16 Àwọn Kristẹni kì í wo ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń tẹ òmìnira wọn lójú láìyẹ. Wọ́n ń fínnúfíndọ̀ lo òmìnira wọn ní ọ̀nà tí Àwòkọ́ṣe wọn, Jésù Kristi, gbà lò ó, ní mímú ìfẹ́-ọkàn wọn àti ohun àkọ́múṣe wọn bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Jòhánù 5:30; 6:38) Wọ́n ń mú “èrò inú ti Kristi” dàgbà, wọ́n ń tẹríba fún un gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 2:14-16; Kólósè 1:15-18) Èyí dà bí obìnrin kan tí a gbé níyàwó, tí ó sì fi tinútinú fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, a sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni tí a fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí wúńdíá tí kò lábààwọ́n, tí a ṣèlérí fún Kristi nínú ìgbéyàwó.—2 Kọ́ríńtì 11:2; Éfésù 5:23, 24; Ìṣípayá 19:7, 8.
17. Kí ni gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàn láti dà?
17 Ọ̀kọ̀ọ̀kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yálà ìrètí rẹ̀ jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé, ti ṣe ìyàsímímọ́ ara ẹni fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí Alákòóso. Fún Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan, ìyàsímímọ́ ti jẹ́ yíyàn tí a fúnra ẹni ṣe láti di ẹrú Ọlọ́run, dípò bíbá a lọ gẹ́gẹ́ bí ẹrú ènìyàn. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó wí pé: “A rà yín ní iye kan; ẹ dẹ́kun dídi ẹrú ènìyàn.”—1 Kọ́ríńtì 7:23.
Kíkọ́ Láti Ṣe Ara Wa Láǹfààní
18. Nígbà wo ni ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó di Ẹlẹ́rìí yóò di ẹni tí ó tóótun láti ṣe batisí?
18 Kí ẹnì kan tó lè tóótun láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè. Àwọn alàgbà ń lo ìṣọ́ra láti pinnu bóyá Ẹlẹ́rìí lọ́la kan lóye ohun tí ó wé mọ́ ìyàsímímọ́ Kristẹni ní tòótọ́. Ṣé ó fẹ́ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tòótọ́? Ó ha ti múra tán láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí èyí ní nínú bí? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun kò tóótun láti ṣe batisí.
19. Èé ṣe tí kò fi sí ìdí láti ṣe lámèyítọ́ ẹnì kan tí ó pinnu láti di ìránṣẹ́ tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run?
19 Ṣùgbọ́n, bí ẹnì kan bá kúnjú ìwọ̀n gbogbo ohun tí a béèrè, èé ṣe tí a óò fi ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ fún fífínnúfíndọ̀ fúnra rẹ̀ pinnu láti jẹ́ kí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí ó mí sí nípa lórí òun? Jíjẹ́ kí ènìyàn nípa lórí ẹni ha ṣètẹ́wọ́gbà ju jíjẹ́ kí Ọlọ́run nípa lórí ẹni lọ? Àbí jíjẹ́ kí Ọlọ́run nípa lórí ẹni kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní ni? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò rò bẹ́ẹ̀. Wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Aísáyà kọ sílẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.
20. Lọ́nà wo ni òtítọ́ Bíbélì gbà dá àwọn ènìyàn sílẹ̀ lómìnira?
20 Òtítọ́ Bíbélì ń gba àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gbígba àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké gbọ́, irú bí oró ayérayé nínú hẹ́ẹ̀lì oníná. (Oníwàásù 9:5, 10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń mú kí ọkàn wọ́n kún fún ìmoore fún ìrètí tòótọ́ fún àwọn òkú—àjíǹde tí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi mú kí ó ṣeé ṣe. (Mátíù 20:28; Ìṣe 24:15; Róòmù 6:23) Òtítọ́ Bíbélì ń gba àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ gbígbáralé ìlérí àwọn òṣèlú, tí kì í ṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń mú kí ọkàn wọn kún fún ayọ̀, ní mímọ̀ pé Ìjọba Jèhófà ti ń ṣàkóso nínú àwọn ọ̀run, yóò sì ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Òtítọ́ Bíbélì ń gba àwọn ènìyàn lọ́wọ́ àwọn àṣà tí kò bọlá fún Ọlọ́run, tí ó sì ń ṣàkóbá gidigidi ní ti ipò ìbátan tí ó forí ṣánpọ́n, àìsàn, àti ikú àìtọ́jọ́, bí wọ́n tilẹ̀ ń fa ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra. Ní kúkurú, jíjẹ́ ẹrú Ọlọ́run ṣàǹfààní gidigidi ju jíjẹ́ ẹrú ènìyàn. Ní tòótọ́, ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ń mú àǹfààní wá “ní sáà àkókò yìí . . . àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.
21. Ojú wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run, kí sì ni ìfẹ́-ọkàn wọn?
21 Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò di ara orílẹ̀-èdè tí a yà sí mímọ́ nípasẹ̀ ìbí, gẹ́gẹ́ bí ti Ísírẹ́lì àtijọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ ara ìjọ àwọn Kristẹni tí a yà sí mímọ́. Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣe batisí ti ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo òmìnira ṣíṣe yíyàn tí ó ní gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan láti ṣe ìpinnu. Ní tòótọ́, fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyàsímímọ́ ń yọrí sí níní ipò ìbátan ara ẹni ọlọ́yàyà pẹ̀lú Ọlọ́run, tí iṣẹ́ ìsìn tí a fi tinútinú ṣe ń sàmì sí. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn fẹ́ láti di ipò ìbátan aláyọ̀ yìí mú, ní dídi òmìnira tí Jésù Kristi sọ wọ́n dì mú ṣinṣin títí láé.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí a kò fi lè sọ pé Ọlọ́run ṣe ojúsàájú ní yíyàn tí ó yan Ísírẹ́lì láti di “àkànṣe ìní” rẹ̀?
◻ Èé ṣe tí ìwọ yóò fi sọ pé ìyàsímímọ́ Kristẹni kò túmọ̀ sí pípàdánù òmìnira wa?
◻ Kí ni àǹfààní yíya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run?
◻ Èé ṣe tí ó fi sàn láti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ju láti jẹ́ ẹrú ènìyàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run jẹ́ ọ̀ràn ìbí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìyàsímímọ́ Kristẹni jẹ́ ọ̀ràn yíyàn