Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àsọtẹ́lẹ̀ lílókìkí kan nípa Mèsáyà wà nínú Aísáyà orí kẹtàléláàádọ́ta. Ẹsẹ ìkẹwàá sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́; ó mú kí ó ṣàìsàn.” Kí ni èyí túmọ̀ sí?
Ó rọrùn láti rí ìdí tí ìbéèrè fi lè dìde lórí Aísáyà 53:10. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ronú pé Ọlọ́run wa oníyọ̀ọ́nú àti olójú àánú yóò ní inú dídùn sí títẹ ẹnikẹ́ni rẹ́ tàbí mímú kí ó ṣàìsàn. Bíbélì fún wa ní ìdí táa fi lè ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run kì í ní inú dídùn nínú dídá àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lóró. (Diutarónómì 32:4; Jeremáyà 7:30, 31) Láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá, Jèhófà ti lè fàyè gba ìjìyà láwọn àkókò kan nítorí àwọn ìdí kan tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́, ó dájú pé òun kọ́ ló mú kí Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jìyà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni àyọkà yìí wá ń sọ ní ti gidi?
Ó dára, a lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye kókó náà bí a bá gbé gbogbo ẹsẹ táà ń sọ yìí yẹ̀ wò, kí a kíyè sí ìgbà méjì tí ọ̀rọ̀ náà, “inú dídùn,” jẹ yọ. Aísáyà 53:10 kà pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́; ó mú kí ó ṣàìsàn. Bí ìwọ yóò bá fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, òun yóò rí àwọn ọmọ rẹ̀, yóò mú ọjọ́ rẹ̀ gùn, ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí yóò sì kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀.”
Àkópọ̀ gbogbo ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé “ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí,” tí a mẹ́nu kàn ní òpin ẹsẹ náà dá lórí mímú ète rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba náà. Ṣíṣe tí Jèhófà bá ṣe èyí yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre, yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe láti mú ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá kúrò lára àwọn ènìyàn onígbọràn—ìyẹn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Kíróníkà 29:11; Sáàmù 83:18; Ìṣe 4:24; Hébérù 2:14, 15; 1 Jòhánù 3:8) Kókó pàtàkì kan nínú gbogbo èyí ni pé Ọmọ Ọlọ́run ní láti di ẹ̀dá ènìyàn kí ó sì pèsè ẹbọ ìràpadà náà. Báa ṣe mọ̀, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Jésù jìyà. Bíbélì sọ fún wa pé ó “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” Nítorí náà, Jésù jàǹfààní láti inú ìjìyà yẹn.—Hébérù 5:7-9.
Jésù mọ̀ ṣáájú pé ọ̀nà akíkanjú tí òun fẹ́ tọ̀ yóò ní ìrora nínú. Ìyẹn hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú àkọsílẹ̀ Jòhánù 12:23, 24, níbi tí a ti kà á pé: “Wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé hóró àlìkámà bọ́ sínú ilẹ̀, kí ó sì kú, ó ṣì wà ní ẹyọ hóró kan ṣoṣo; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, nígbà náà ni yóò so èso púpọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù mọ̀ pé òun ní láti pa ìwà títọ́ òun mọ́ kódà títí dójú ikú pàápàá. Àkọsílẹ̀ náà tẹ̀ síwájú pé: “‘Wàyí o, ọkàn mi dààmú, kí ni èmi yóò sì sọ? Baba, gbà mí là kúrò nínú wákàtí yìí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi wá sí wákàtí yìí. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.’ Nítorí náà, ohùn kan jáde wá láti ọ̀run pé: ‘Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.’”—Jòhánù 12:27, 28; Mátíù 26:38, 39.
Inú àyíká ọ̀rọ̀ yìí la ti lè lóye Aísáyà 53:10. Jèhófà mọ̀ dájú pé ohun tí yóò ṣe ọmọ òun yóò ní títẹ̀ ẹ́ rẹ́ nínú láwọn ọ̀nà kan. Síbẹ̀, níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ̀ nípa ògo àti ire gíga lọ́lá tí yóò tibẹ̀ jáde, ó ní inú dídùn sí ohun tí Jésù yóò fàyà rán. Lọ́nà yẹn, Jèhófà “ní inú dídùn sí títẹ” Mèsáyà náà “rẹ́.” Jésù pẹ̀lú ní inú dídùn sí ohun tí òun alára lè ṣàṣeparí rẹ̀ tí ó sì ṣe. Ní ti tòótọ́, bí Aísáyà 53:10 ṣe dé ọ̀rọ̀ náà ládé, ‘ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀.’