Àìsáyà
53 Ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?*+
Ní ti apá Jèhófà,+ ta la ti fi hàn?+
2 Ó máa jáde wá bí ẹ̀ka igi+ níwájú rẹ̀,* bíi gbòǹgbò látinú ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.
3 Àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un,+
Ọkùnrin tó mọ bí ìrora ṣe ń rí,* tó sì mọ àìsàn dunjú.
Ó dà bí ẹni pé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wa.*
Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.+
Àmọ́ a kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọ lù, tó sì ń jìyà.
6 Gbogbo wa ti rìn gbéregbère bí àgùntàn,+
Kálukú ti yíjú sí ọ̀nà tirẹ̀,
Jèhófà sì ti mú kó ru ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa.+
Wọ́n mú un wá bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,+
Bí abo àgùntàn tó dákẹ́ níwájú àwọn tó ń rẹ́ irun rẹ̀,
Kò sì la ẹnu rẹ̀.+
9 Wọ́n sin ín* pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú+
Àti àwọn ọlọ́rọ̀,* nígbà tó kú,+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe ohunkóhun tí kò dáa,*
Kò sì sí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu rẹ̀.+
10 Àmọ́ ó wu Jèhófà* láti tẹ̀ ẹ́ rẹ́, ó sì jẹ́ kó ṣàìsàn.
Tí o bá máa fi ẹ̀mí* rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀bi,+
Ó máa rí ọmọ* rẹ̀, ó máa mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ gùn,+
Ohun tí inú Jèhófà dùn sí* sì máa yọrí sí rere nípasẹ̀ rẹ̀.+