Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún
Ọ̀rọ̀ Àgàn Náà Dayọ̀
1. Kí nìdí tí Sárà fi ń wá ọmọ lójú méjèèjì, kí sì lọ̀ràn ti rí fún un?
SÁRÀ ń wá ọmọ lójú méjèèjì. Ṣùgbọ́n, ó mà ṣe o, Sárà yàgàn, ìyẹn sì dùn ún gidigidi. Láyé ìgbà tiwọn, ẹ̀gàn ló jẹ́ tí obìnrin bá yàgàn, ṣùgbọ́n ohun tó ń dun Sárà tilẹ̀ ju ìyẹn lọ. Ó ń hára gàgà láti rí i pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún ọkọ òun ṣẹ. Ìlérí yẹn ni pé Ábúráhámù á bí irú ọmọ kan tí yóò jẹ́ ìbùkún fún gbogbo ìdílé ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún kọjá lọ lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣe ìlérí yẹn, wọn ò sì rí ọmọ bí rárá. Sárà wá di arúgbó láìrí ọmọ bí. Ó lè ti máa rò ó nígbà mìíràn pé bóyá ni ìrètí òun kò ti já sí òfo. Àfi bó ṣe di ọjọ́ kan, tíbànújẹ́ rẹ̀ dayọ̀!
2. Ìdí wo ló fi yẹ kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìnléláàádọ́ta wù wá?
2 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sárà yìí jẹ́ kí òye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìnléláàádọ́ta yé wa. Níbẹ̀, Jèhófà bá Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ bíi pé ó jẹ́ àgàn kan tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà di ayọ̀ ńlá ní ti pé ó di ìyá ọlọ́mọ yọyọ. Bí Jèhófà sì ṣe ṣàpèjúwe àwọn èèyàn rẹ̀ àtijọ́ lápapọ̀ pé wọ́n jẹ́ aya òun, ńṣe ló ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó fi mú wọn hàn. Ẹ̀wẹ̀, orí ìwé Aísáyà yìí jẹ́ ká rí ojútùú apá kan tó ṣe pàtàkì gan-an nínú ohun tí Bíbélì pè ní “àṣírí ọlọ́wọ̀.” (Róòmù 16:25, 26) Mímọ ẹni tí “obìnrin” yìí jẹ́ àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe wí, á túbọ̀ là wá lóye gan-an nípa ìsìn mímọ́ lóde òní.
A Sọ Ẹni Tí “Obìnrin” Yẹn Jẹ́
3. Kí ni ìdí tí àgàn yìí yóò fi dẹni tó ń yọ̀?
3 Ọ̀rọ̀ ìdùnnú ni orí kẹrìnléláàádọ́ta fi bẹ̀rẹ̀, ó ní: “‘Fi ìdùnnú ké jáde, ìwọ àgàn tí kò bímọ! Fi igbe ìdùnnú tújú ká, kí o sì ké lọ́nà híhan gan-an-ran, ìwọ tí kò ní ìrora ìbímọ, nítorí àwọn ọmọ ẹni tí ó ti di ahoro pọ̀ níye ju àwọn ọmọ obìnrin tí ó ní ọkọ tí í ṣe olówó orí rẹ̀,’ ni Jèhófà wí.” (Aísáyà 54:1) Áà, yóò dùn mọ́ Aísáyà gan-an ni bó ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ yìí! Ìtùnú ńlá mà ni ìmúṣẹ rẹ̀ yóò sì jẹ́ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì o! Ní àsìkò yẹn, ahoro ni Jerúsálẹ́mù yóò ṣì wà. Lójú ọmọ aráyé, yóò jọ pé kò sí ìrètí kankan pé àwọn èèyàn yóò tún padà máa gbébẹ̀, àní bí àgàn tó ti darúgbó kò ṣe ní retí pé òun yóò tún bímọ. Ṣùgbọ́n o, ìbùkún ńláǹlà ń bẹ fún “obìnrin” yìí lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ni pé, yóò di abiyamọ. Ayọ̀ Jerúsálẹ́mù á sì pọ̀ jọjọ. “Àwọn ọmọ” tàbí aráàlú yóò tún padà kún ibẹ̀ fọ́fọ́.
4. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé Aísáyà orí kẹrìnléláàádọ́ta yóò ní láti ṣẹ lọ́nà kan tó ju èyí tó ṣẹ lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa? (b) Kí ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè”?
4 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ yìí yóò ṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun pàápàá lè má mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú orí kẹrìnléláàádọ́ta ìwe Aísáyà, ó wá ṣàlàyé pé “obìnrin” yìí tọ́ka sí ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ìlú Jerúsálẹ́mù ti ilẹ̀ ayé lọ. Ó kọ̀wé pé: “Jerúsálẹ́mù ti òkè jẹ́ òmìnira, òun sì ni ìyá wa.” (Gálátíà 4:26) Kí ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè” yìí? Ó dájú pé kì í ṣe ìlú Jerúsálẹ́mù tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí. Nítorí pé ayé yìí ni ìlú yẹn wà ní tiẹ̀, kì í ṣe “òkè” ọ̀run lọ́hùn-ún. “Jerúsálẹ́mù ti òkè” jẹ́ “obìnrin” Ọlọ́run tó wà ní ọ̀run, ìyẹn ètò àjọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tí Ọlọ́run ní.
5. Nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ tó wà nínú Gálátíà 4:22-31, ta ló dúró fún (a) Ábúráhámù? (b) Sárà? (d) Ísákì? (e) Hágárì? (ẹ) Íṣímáẹ́lì?
5 Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe lè ní obìnrin ìṣàpẹẹrẹ méjì, kí ọ̀kan jẹ́ ti ọ̀run kí èkejì sì jẹ́ ti ayé? Ṣé ọ̀ràn ibí yìí kò ta kora báyìí? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé inú ìdílé Ábúráhámù tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ wí la ó ti rí ìdáhùn sí i. (Gálátíà 4:22-31; wo “Ìdílé Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀,” lójú ewé 218.) Sárà aya Ábúráhámù, tó jẹ́ “òmìnira obìnrin,” dúró fún ètò àjọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó dà bí aya fún Jèhófà. Hágárì tó jẹ́ ìránṣẹ́bìnrin, tí í ṣe aya onípò kejì, tàbí wáhàrì Ábúráhámù, dúró fún Jerúsálẹ́mù ti ilẹ̀ ayé.
6. Ọ̀nà wo ni ètò àjọ Ọlọ́run ní ọ̀run gbà yàgàn fún ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ?
6 Òye ìtàn àtẹ̀yìnwá yìí ń jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí rí bí Aísáyà 54:1 ti ṣe pàtàkì gidigidi tó. Lẹ́yìn tí Sárà ti yàgàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó padà wá bí Ísákì nígbà tó dẹni àádọ́rùn-ún ọdún. Lọ́nà kan náà, sáà gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run fi yàgàn. Édẹ́nì lọ́hùn-ún ni Jèhófà ti ṣèlérí pé “obìnrin” òun yóò bí “irú ọmọ” náà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú nípa Irú Ọmọ ìlérí yìí. Àmọ́ “obìnrin” Ọlọ́run ti ọ̀run yìí yóò ní láti dúró di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún sí i kí ó tó bí Irú Ọmọ yẹn. Síbẹ̀, àkókò dé tí àwọn ọmọ “àgàn” ìgbà kan rí yìí wá pọ̀ ju ti Ísírẹ́lì nípa ti ara lọ. Àkàwé àgàn yìí jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn áńgẹ́lì fi ń hára gàgà láti rí i kí Irú Ọmọ tí àsọtẹ́lẹ̀ ń wí yìí dé. (1 Pétérù 1:12) Ìgbà wo ló sì wá dé níkẹyìn?
7. Ìgbà wo ni àkókò ìdùnnú dé fún “Jerúsálẹ́mù ti òkè” gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 54:1 ṣe wí, kí sì nìdí tóo fi dáhùn bẹ́ẹ̀?
7 Dájúdájú, ìgbà ìbí Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ èèyàn jẹ́ àkókò ìdùnnú fún àwọn áńgẹ́lì. (Lúùkù 2:9-14) Àmọ́, ìyẹn kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí Aísáyà 54:1 sọ tẹ́lẹ̀. Ìgbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé Jésù lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ nípa tẹ̀mí fún “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sí sọ fáyé gbọ́ pé ó jẹ́ “Ọmọ” òun “olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Máàkù 1:10, 11; Hébérù 1:5; 5:4, 5) Ìgbà yẹn ni “obìnrin” Ọlọ́run ní ọ̀run wá rí ìdí tó fi lè bú sí ayọ̀, ní ìmúṣẹ Aísáyà 54:1. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó bí Mèsáyà, Irú Ọmọ táa ṣèlérí náà! Ni ipò àgàn tó ti wà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún bá dópin. Àmọ́ ṣá, ibẹ̀ yẹn nìkan kọ́ ni ìdùnnú rẹ̀ mọ.
Àgàn Di Ọlọ́mọ Yọyọ
8. Kí nìdí tí ìdùnnú fi lè bá “obìnrin” Ọlọ́run ní ọ̀run lẹ́yìn tó bí Irú Ọmọ táa ṣèlérí náà?
8 Ìdùnnú bá “obìnrin” Ọlọ́run tó wà ní ọ̀run yìí lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì tún jíǹde, nítorí pé ó rí ààyò Ọmọ yìí gbà padà gẹ́gẹ́ bí “àkọ́bí láti inú òkú.” (Kólósè 1:18) Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá bẹ̀rẹ̀ sí bí àwọn ọmọ tẹ̀mí púpọ̀ sí i. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọgọ́fà ọmọlẹ́yìn Jésù la fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ sí i lọ́jọ́ tí à ń wí yìí, ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000 ] èèyàn tún kún wọn. (Jòhánù 1:12; Ìṣe 1:13-15; 2:1-4, 41; Róòmù 8:14-16) Ló bá di pé àwùjọ àwọn ọmọ yìí bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i. Àmọ́ ṣá, ní àwọn ọ̀rúndún tó wà lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìpẹ̀yìndà Kirisẹ́ńdọ̀mù, ení tere èjì tere ni wọ́n ń wá. Ṣùgbọ́n nígbà tó di ọ̀rúndún ogún, ìyẹn yí padà.
9, 10. Kí ni ìtọ́ni tí obìnrin kan tó ń gbé inú àgọ́ láyé àtijọ́ gbà pé kí ó ‘mú kí ibi àgọ́ rẹ̀ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò’ yóò túmọ̀ sí fún un, kí sì nìdí tí yóò fi jẹ́ àkókò ìdùnnú fún obìnrin yẹn?
9 Aísáyà wá gbẹ́nu lé àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí ìbísí kíkàmàmà yóò dé, ó ní: “Mú kí ibi àgọ́ rẹ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò. Kí wọ́n sì na àwọn aṣọ àgọ́ ibùgbé rẹ títóbilọ́lá. Má fawọ́ sẹ́yìn. Mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i, kí o sì mú àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ tìrẹ wọ̀nyẹn le. Nítorí pé ìwọ yóò ya sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn ọmọ tìrẹ yóò sì gba àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá, wọn yóò sì máa gbé àwọn ìlú ńlá tí ó ti di ahoro pàápàá. Má fòyà, nítorí pé a kì yóò kó ìtìjú bá ọ; má sì jẹ́ kí ìtẹ́lógo bá ọ, nítorí pé a kì yóò já ọ kulẹ̀. Nítorí pé ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ pàápàá, ẹ̀gàn ìgbà opó rẹ tí ń bá a nìṣó ni ìwọ kì yóò sì rántí mọ́.”—Aísáyà 54:2-4.
10 Níhìn-ín, Ọlọ́run bá Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ bíi pé ó jẹ́ aya àti ìyá ọlọ́mọ tó ń gbé inú àgọ́, bíi ti Sárà gẹ́lẹ́. Bó bá ti di pé ìdílé rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó di dandan pé kí irú ìyá bẹ́ẹ̀ wá bí yóò ṣe mú kí ilé rẹ̀ gbòòrò sí i. Ó ń béèrè pé kí ó ta àwọn aṣọ àgọ́ àti àwọn okùn tó túbọ̀ gùn sí i, kí ó sì kan àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ síbi tuntun. Iṣẹ́ tí yóò yá a lórí láti ṣe ni, àti pé, ní irú àsìkò tí ọwọ́ rẹ̀ dí gidi yẹn, kíákíá ló lè gbàgbé àwọn ọdún tí ọkàn rẹ̀ kò fi balẹ̀ nítorí ìrònú bóyá òun máa lè bí àwọn ọmọ kí ìlà ìdílé òun má bàa pa rẹ́.
11. (a) Báwo ni ìbùkún ṣe dé bá “obìnrin” Ọlọ́run ní ọ̀run lọ́dún 1914? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Láti ọdún 1919 síwájú, irú ìbùkún wo ló ti bá àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé?
11 Irú ìgbà àmúdọ̀tun bẹ́ẹ̀ la wá fi jíǹkí Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn tí ìgbèkùn wọn ní Bábílónì dópin. “Jerúsálẹ́mù ti òkè” sì tilẹ̀ tún gba ìbùkún tó ju ìyẹn lọ.a Láti ọdún 1919 ní pàtàkì ni “àwọn ọmọ” rẹ̀ ẹni àmì òróró ti ń gbilẹ̀ nínú ipò ìmúbọ̀sípò nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà. (Aísáyà 61:4; 66:8) Wọ́n “gba àwọn orílẹ̀-èdè” ní ti pé wọ́n tàn ká lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ láti wá àwọn tó máa dara pọ̀ mọ́ ìdílé wọn nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ló fi di pé àwọn ọmọ tó jẹ́ ẹni àmì òróró yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ wọlé wìtìwìtì. Ó jọ pé láàárín ọdún 1930 sí 1939 ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye wọn, tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ti pé. (Ìṣípayá 14:3) Ní àsìkò tí à ń wí yìí, wọn kò fi kíkó àwọn ẹni àmì òróró jọ ṣe ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń wàásù mọ́. Síbẹ̀, ìbísí yìí kò mọ sórí àwọn ẹni àmì òróró nìkan.
12. Láfikún sí àwọn ẹni àmì òróró, àwọn wo la tún ti ń kó jọ sínú ìjọ Kristẹni láti ọdún 1930 wá?
12 Jésù fúnra rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé, yàtọ̀ sí “agbo kékeré” ti àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin òun, òun yóò tún ní “àwọn àgùntàn mìíràn” tí a óò ní láti mú wọlé wá sínú agbo àgùntàn ti àwọn Kristẹni tòótọ́. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí, tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró yìí, kì í ṣe ara àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” wọ́n ń kó ipa pàtàkì kan tí àsọtẹ́lẹ̀ ti sọ tipẹ́tipẹ́. (Sekaráyà 8:23) Ìkójọpọ̀ wọn láti ọdún 1930 títí dòní, ti mú kí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” wọn wọlé wá, tó fi jẹ́ pé kò sígbà tí ìjọ Kristẹni tíì gbilẹ̀ tó báyìí rí. (Ìṣípayá 7:9, 10) Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹn ti wá di àràádọ́ta ọ̀kẹ́. Gbogbo ìbísí yìí wá ń béèrè pé kí á bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àti àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ púpọ̀ sí i ní kánjúkánjú. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ Aísáyà túbọ̀ wá bá a mu gan-an ni lásìkò yìí. Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ fún wa láti kópa nínú ìmúgbòòrò tí a sọ tẹ́lẹ̀ yìí o!
Ìyá Tó Ń Tọ́jú Àwọn Ọmọ Rẹ̀
13, 14. (a) Ìṣòro wo ló jọ pé ó yọjú ní ti àwọn gbólóhùn kan táa lò nípa “obìnrin” Ọlọ́run ní ọ̀run? (b) Òye tó jinlẹ̀ wo ni a lè ní látinú bí Ọlọ́run ṣe lo àpèjúwe ìbátan inú agbo ìdílé?
13 A ti rí i pé ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run ni “obìnrin” inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí dúró fún ní ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ lọ́nà títóbi jù. Ṣùgbọ́n bí a bá ka Aísáyà 54:4, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa bí ìtìjú tàbí ẹ̀gàn ṣe lè bá irú ètò àjọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yẹn. Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ pé Ọlọ́run yóò fi “obìnrin” rẹ̀ sílẹ̀, a ó ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́, a ó sì kọlù ú. Yóò tilẹ̀ mú inú bí Ọlọ́run. Báwo wá ni irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀ sí ètò àjọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ẹni pípé tí kò ṣẹ̀ rí? Bí ìdílé ṣe rí jẹ́ ká lè mọ ìdáhùn rẹ̀.
14 Jèhófà máa ń lo àpèjúwe ìbátan inú agbo ìdílé, bí ọkọ àti aya, ìyá àti ọmọ, láti fi ṣàlàyé àwọn òtítọ́ pàtàkì-pàtàkì nípa tẹ̀mí nítorí pé irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tètè yé ọmọ aráyé. Ohun yòówù tí ì báà máa ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé tiwa, ó kéré, ó pọ̀ ni o, a óò ṣáà ní òye díẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí àárín tọkọtaya rere, tàbí àárín òbí àti ọmọ tó dán mọ́rán ṣe rí. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi hàn pé àjọṣe aládùn, tó ṣe tímọ́tímọ́, tí ìfọkàntánni sì wà níbẹ̀ ló ń bẹ láàárín òun àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ìránṣẹ́ òun mà yéni yékéyéké o! Ọ̀nà tó sì gbà kọ́ wa pé ètò àjọ òun ní ọ̀run ń bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ táa fi ẹ̀mí yàn, tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé, mà sì wúni lórí o! Bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ènìyàn bá ń jìyà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ọ̀run, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè” a jìyà pẹ̀lú. Bákan náà, Jésù sọ pé: “Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi [tí a fi ẹ̀mí yàn] wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.”—Mátíù 25:40.
15, 16. Kí ni ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí Aísáyà 54:5, 6 ní, kí sì ni ìmúṣẹ títóbi jù tó ní?
15 Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí Jèhófà sọ fún “obìnrin” rẹ̀ ní ọ̀run ló jẹ́ àfihàn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò: “‘Olùṣẹ̀dá rẹ Atóbilọ́lá ni ọkọ olówó orí rẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀; Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni Olùtúnnirà rẹ. Ọlọ́run gbogbo ilẹ̀ ayé ni a óò máa pè é. Nítorí pé Jèhófà pè ọ́ bí ẹni pé ìwọ jẹ́ aya tí a fi sílẹ̀ pátápátá, tí a sì pa ẹ̀mí rẹ̀ lára, àti gẹ́gẹ́ bí aya ìgbà èwe tí a wá já sílẹ̀,’ ni Ọlọ́run rẹ wí.”—Aísáyà 54:5, 6.
16 Ta ni aya tí ibí yìí ń wí ná? Jerúsálẹ́mù tó dúró fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ni nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ. Nígbà àádọ́rin ọdún tí wọ́n fi wà nígbèkùn Bábílónì, wọn yóò máa rò ó pé Jèhófà ti já àwọn sílẹ̀, pé ó ti fi àwọn sílẹ̀ pátápátá. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ṣẹ lọ́nà títóbi jù, ọ̀rọ̀ ibí yìí ń tọ́ka sí “Jerúsálẹ́mù ti òkè” àti bí ó ṣe bí “irú ọmọ” yìí níkẹyìn ní ìmúṣẹ ohun tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 wí.
Ìbáwí Ìṣẹ́jú Mélòó Kan, Ìbùkún Ayérayé
17. (a) Báwo ni “àkúnya” ìkannú Ọlọ́run yóò ṣe bo Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀? (b) “Àkúnya” wo ló bo àwọn ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” mọ́lẹ̀?
17 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá a lọ pé: “‘Ìṣẹ́jú díẹ̀ ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá, ṣùgbọ́n àánú ńláǹlà ni èmi yóò fi kó ọ jọpọ̀. Nínú àkúnya ìkannú ni mo fi ojú mi pa mọ́ fún ọ fún kìkì ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fi ṣàánú fún ọ dájúdájú,’ ni Jèhófà, Olùtúnnirà rẹ, wí.” (Aísáyà 54:7, 8) “Àkúnya” ìbínú Ọlọ́run bo Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé nígbà tí agbo ọmọ ogun Bábílónì kọlù ú lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àádọ́rin ọdún tí yóò lò nígbèkùn lè dà bí èyí tó gùn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ. Síbẹ̀, irú àdánwò bẹ́ẹ̀ kò gùn ju “kìkì ìṣẹ́jú kan” lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìbùkún ayérayé tó wà níwájú fún àwọn tó bá kọbi ara sí ìbáwí yìí dáadáa. Bákan náà ni nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹni àmì òróró, ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ńṣe ló dà bíi pé “àkúnya” ìkannú Ọlọ́run bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ kí àwọn ìjọba ayé gbógun tì wọ́n gẹ́gẹ́ bí Bábílónì Ńlá ti kó sí wọn nínú láti ṣe. Àmọ́, àsìkò tí wọ́n fi gba ìbáwí yẹn kò gùn tó nǹkan kan rárá lójú wọn táa bá fi wé àkókò àwọn ìbùkún nípa tẹ̀mí tó ti wọlé dé láti ọdún 1919!
18. Ìlànà pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bínú sí àwọn èèyàn rẹ̀, ipa wo ni èyí sì lè ní lórí olúkúlùkù wa?
18 Àwọn ẹsẹ yìí tún sọ òtítọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé, ìkannú Ọlọ́run kì í wà pẹ́ lọ títí, ṣùgbọ́n pé àánú rẹ̀ a máa wà títí láé. Ọlọ́run máa ń bínú gidigidi sí ẹni tó ṣe àṣemáṣe, ṣùgbọ́n kì í bínú sódì rárá, a sì máa ní ohun tó pète kó tó bínú. Bí a bá sì ti fara mọ́ ìbáwí Jèhófà, ìbínú rẹ̀ yóò kàn wà “fún kìkì ìṣẹ́jú kan” ni, yóò sì rọlẹ̀. “Àánú ńláǹlà” rẹ̀, ìyẹn ìdáríjì rẹ̀ àti inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò wá rọ́pò rẹ̀. Ìwọ̀nyẹn a sì máa wà “fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Nítorí náà, bí a bá dẹ́ṣẹ̀, kí á má ṣe lọ́ tìkọ̀ rárá láti ronú pìwà dà kí á sì tètè tún àárín àwa àti Ọlọ́run ṣe padà. Bó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, kí á tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Jákọ́bù 5:14) Lóòótọ́, ó lè mú ká gba ìbáwí o, èyí sì lè má rọrùn. (Hébérù 12:11) Ṣùgbọ́n bí ìgbà kúkúrú báyìí mà ni yóò jẹ́ o tí a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ìbùkún ayérayé tí a óò rí gbà nípa pé Jèhófà Ọlọ́run dárí jì wá!
19, 20. (a) Kí ni májẹ̀mú òṣùmàrè, báwo ló sì ṣe kan àwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì? (b) Ìdánilójú wo ni “májẹ̀mú àlàáfíà” jẹ́ kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní lóde òní?
19 Jèhófà wá sọ̀rọ̀ ìtùnú láti fọkàn àwọn èèyàn rẹ̀ balẹ̀, ó ní: “‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ Nóà ni èyí rí sí mi. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti búra pé omi Nóà kì yóò tún kọjá lórí ilẹ̀ ayé mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra pé dájúdájú, ìkannú mi kì yóò ru sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí lọ́nà mímúná. Nítorí pé a lè ṣí àwọn òkè ńláńlá pàápàá kúrò, àní àwọn òkè kéékèèké sì lè ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, ṣùgbọ́n inú rere mi onífẹ̀ẹ́ ni a kì yóò mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àlàáfíà mi kì yóò ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,’ ni Jèhófà, Ẹni tí ó ṣàánú fún ọ, wí.” (Aísáyà 54:9, 10) Lẹ́yìn Àkúnya omi, Ọlọ́run bá Nóà àti gbogbo alààyè ọkàn yòókù dá májẹ̀mú kan, èyí tí àwọn kan máa ń pè ní májẹ̀mú òṣùmàrè nígbà mìíràn. Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní fi ìkún omi kárí ayé pa ilẹ̀ ayé run mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 9:8-17) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún Aísáyà àti àwọn èèyàn rẹ̀?
20 Ìtùnú ló jẹ́ fún wọn láti mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni àwọn yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mọ, ìyẹn ìgbèkùn àádọ́rin ọdún ní Bábílónì. Bí ìyẹn bá sì ti wá tán, ọ̀rọ̀ yẹn parí nìyẹn. Lẹ́yìn náà, “májẹ̀mú àlàáfíà” Ọlọ́run yóò wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “àlàáfíà” lédè Hébérù ní ìtumọ̀ tó ré kọjá pé ogun kò sí, ó kan pé ohun gbogbo ń lọ ní gbẹdẹmukẹ pẹ̀lú. Títí gbére ni Ọlọ́run fẹ́ kí májẹ̀mú yẹn jẹ́. Kódà ó rọrùn pé kí àwọn òkè kéékèèké àti òkè ńláńlá dàwátì ju pé kí inú rere onífẹ̀ẹ́ tó ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ dópin. Ó báni nínú jẹ́ pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, orílẹ̀ èdè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yóò da májẹ̀mú yẹn, wọn yóò sì lé àlàáfíà jìnnà sí ara wọn nípa kíkọ̀ tí wọ́n á kọ Mèsáyà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n o, ohun tí àwọn ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” ṣe sàn ju tiwọn lọ. Gbàrà tí wàhálà tiwọn ti dópin ni wọ́n ti gba ìdánilójú pé ààbò Ọlọ́run ń bẹ fún wọn ní tiwọn.
Ààbò Tẹ̀mí Tí Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ní
21, 22. (a) Kí nìdí tí àsọtẹ́lẹ̀ fi sọ pé wọ́n ṣẹ́ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” níṣẹ̀ẹ́ àti pé ìjì líle bì í síwá-sẹ́yìn? (b) Kí ni ipò ìbùkún tí “obìnrin” Ọlọ́run ní ọ̀run wà máa ń fi hàn nípa ipò “àwọn ọmọ” rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
21 Jèhófà wá gbẹ́nu lé àsọtẹ́lẹ̀ pé ààbò ń bọ̀ wá fún àwọn èèyàn òun olóòótọ́, ó ní: “Ìwọ obìnrin tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ìjì líle ń bì síwá-sẹ́yìn, tí a kò tù nínú, kíyè sí i, èmi yóò fi àpòrọ́ erùpẹ̀ líle mọ àwọn òkúta rẹ, èmi yóò sì fi sàfáyà fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀ dájúdájú. Òkúta rúbì ni èmi yóò sì fi ṣe odi orí òrùlé rẹ, òkúta oníná pípọ́nyòò ni èmi yóò sì fi ṣe àwọn ẹnubodè rẹ, àwọn òkúta mèremère ni èmi yóò sì fi ṣe gbogbo ààlà rẹ. Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu. A ó fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òdodo. Ìwọ yóò jìnnà réré sí ìnilára—nítorí tí ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìkankan—àti sí ohunkóhun tí ń jáni láyà, nítorí pé kì yóò sún mọ́ ọ. Bí ẹnikẹ́ni bá gbéjà kò ọ́ pẹ́nrẹ́n, kí yóò jẹ́ nípasẹ̀ àwọn àṣẹ ìtọ́ni mi. Ẹnì yòówù tí ó bá gbéjà kò ọ́ yóò ṣubú àní ní tìtorí rẹ.”—Aísáyà 54:11-15.
22 Lóòótọ́ o, kò tíì sígbà kan rí tí wọ́n ṣẹ́ “obìnrin” Jèhófà ní ọ̀run níṣẹ̀ẹ́ tàbí kí ìjì líle bì í síwá-sẹ́yìn ní tààràtà. Àmọ́, ó jìyà nígbà tí “àwọn ọmọ” rẹ̀ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé jìyà, pàápàá nígbà tí wọ́n fi wà nígbèkùn nípa tẹ̀mí lọ́dún 1918 sí 1919. Bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe jẹ́ pé, nígbà tí wọ́n gbé “obìnrin” ọ̀run yìí ga, ńṣe ló ń fi irú ipò kan náà tó wà láàárín àwọn ọmọ rẹ̀ hàn. Nígbà náà, wo ọ̀nà tó gbayì tí Jèhófà gbà ṣàpèjúwe “Jerúsálẹ́mù ti òkè” ná. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìwádìí kan ṣe wí, àwọn ẹnubodè rẹ̀ olókùúta iyebíye, àwọn “àpòrọ́ erùpẹ̀ líle” olówó gọbọi, ìpìlẹ̀ rẹ̀, àní ojú ààlà rẹ̀ pàápàá fúnni ní òye pé ó jẹ́ “ẹlẹ́wà, pé ó jẹ́ ọlọ́lá ńlá, pé ó jẹ́ mímọ́, pé ó jẹ́ alágbára, àti pé ó dúró gbọn-in gbọn-in.” Kí ni yóò gbé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dé irú ipò ààbò àti oníbùkún bẹ́ẹ̀?
23. (a) Ipa wo ni jíjẹ́ tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” ní lórí wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run gbà rí ìbùkún fífi tí wọ́n fi ‘àwọn òkúta mèremère ṣe gbogbo ààlà rẹ̀’?
23 Aísáyà 54:13 pèsè ìdáhùn rẹ̀, ìyẹn ni pé gbogbo wọn yóò jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Jésù fúnra rẹ̀ lo àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró. (Jòhánù 6:45) Wòlíì Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àkókò òpin” yìí, a ó fi ìmọ̀ tòótọ́ púpọ̀ yanturu àti ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí jíǹkí àwọn ẹni àmì òróró. (Dáníẹ́lì 12:3, 4) Irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó ga jù lọ nínú ìtàn ìran ènìyàn, tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kọ́ni káàkiri gbogbo ayé. (Mátíù 24:14) Lẹ́sẹ̀ kan náà, irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké. Aísáyà 54:12 mẹ́nu kan fífi ‘àwọn òkúta mèremère ṣe gbogbo ààlà rẹ̀.’ Láti ọdún 1919 wá ni Jèhófà ti ń fún àwọn ẹni àmì òróró ní òye tó túbọ̀ ń ṣe kedere sí i nípa àwọn ààlà, ìyẹn ojú ààlà tẹ̀mí, tó yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára ìsìn èké àti àwọn àjọ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nínú ayé. (Ìsíkíẹ́lì 44:23; Jòhánù 17:14; Jákọ́bù 1:27) Báyìí ni wọ́n ṣe dẹni táa yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run.—1 Pétérù 2:9.
24. Báwo lá ṣe lè rí i dájú pé a di ẹni tí Jèhófà kọ́?
24 Nípa báyìí, ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Ṣé Jèhófà ń kọ́ mi?’ A ò lè káwọ́ lẹ́rán kí á sì dédé rí ẹ̀kọ́ yẹn gbà. A ní láti ṣakitiyan láti lè rí i gbà. Bí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tí a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, bí a bá sì ń gba ìtọ́ni nípa kíka àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé karí Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde, tí a sì ń gba ìtọ́ni nípa mímúra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀ tí a kò sì ń pa ìpàdé jẹ, Jèhófà yóò máa kọ́ wa ní ti tòótọ́. (Mátíù 24:45-47) Bí a bá ń ṣakitiyan láti fi àwọn ohun tí a kọ́ sílò, tí a wà lójúfò nípa tẹ̀mí tí a sì ń kíyè sára, ẹ̀kọ́ Ọlọ́run yóò mú wa yàtọ̀ pátápátá sí àwọn èèyàn ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí. (1 Pétérù 5:8, 9) Èyí tó tilẹ̀ tún dára jù ni pé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Jákọ́bù 1:22-25; 4:8.
25. Kí ni ìlérí àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣe túmọ̀ sí fún àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní?
25 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tún fi hàn pé àwọn ẹni àmì òróró tún gba ìbùkún àlàáfíà púpọ̀ yanturu. Ṣé èyí wá fi hàn pé kò sí ẹnikẹ́ni tó ń gbéjà kò wọ́n ni? Ó tì o, àmọ́ Ọlọ́run mú kó dá wọn lójú pé òun ò ní sọ pé kí ẹnikẹ́ni wá gbéjà kò wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni òun ò ní jẹ́ kí ìgbéjàkò èyíkéyìí ṣàṣeyọrí. A kà á pé: “‘Wò ó! Èmi fúnra mi ni ó dá oníṣẹ́ ọnà, ẹni tí ń fẹ́ atẹ́gùn sí iná èédú, tí ó sì ń mú ohun ìjà jáde wá gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà rẹ̀. Èmi fúnra mi, pẹ̀lú, ni ó dá apanirun fún iṣẹ́ ìfọ́bàjẹ́. Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—Aísáyà 54:16, 17.
26. Báwo ni mímọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá gbogbo aráyé ṣe ń fini lọ́kàn balẹ̀?
26 Ẹ̀ẹ̀kejì nìyí tí Jèhófà máa rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ létí nínú orí ìwé Aísáyà yìí pé òun ni Ẹlẹ́dàá. Níṣàájú, ó ti kọ́kọ́ sọ fún aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ pé òun ní ‘Olùṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá.’ Wàyí o, ó ní òun ni Ẹlẹ́dàá gbogbo aráyé. Ẹsẹ kẹrìndínlógún ṣe àpèjúwe alágbẹ̀dẹ kan tó ń fẹ́ná ẹwìrì sí irin tí ó ń rọ láti ṣe ohun ọṣẹ́, ó sì tún mẹ́nu kan jagunjagun kan, ìyẹn “apanirun fún iṣẹ́ ìfọ́bàjẹ́.” Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè mú ìpayà bá àwọn ọmọ aráyé bíi tiwọn o, ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n tiẹ̀ ṣe rò pé àwọn yóò lè borí ẹni tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn ná? Lóde òní bákan náà, àní nígbà tí agbo ọmọ ogun tó jẹ́ alágbára jù lọ láyé yìí bá gbéjà ko àwọn èèyàn Jèhófà, wọn ò ní lè ṣe àṣeyọrí rárá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
27, 28. Kí ni ìfọ̀kànbalẹ̀ táa ní lásìkò làásìgbò yìí, kí sì nìdí tí a fi mọ̀ pé òtúbáńtẹ́ ni ìjà tí Sátánì ń gbé kò wá yóò já sí?
27 Ìgbà gbígbéjàko àwọn èèyàn Ọlọ́run láti pa àwọn àti ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́ run ti kọjá. (Jòhánù 4:23, 24) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Jèhófà gbà kí Bábílónì Ńlá gbéjà kò wọ́n kí ó sì ṣàṣeyọrí fúngbà díẹ̀. Fún ìgbà kúkúrú kan, “Jerúsálẹ́mù ti òkè” rí i tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́nu mọ́ nígbà tó di pé iṣẹ́ ìwàásù lórí ilẹ̀ ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró. Àmọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ wáyé mọ́ láé! Ayọ̀ ló kù tó ń yọ̀ lórí àwọn ọmọ rẹ̀ wàyí, nítorí pé, wọ́n ti di àràbà nípa tẹ̀mí, apá ẹnikẹ́ni ò lè ká wọn mọ́. (Jòhánù 16:33; 1 Jòhánù 5:4) Lóòótọ́ o, wọ́n ti kó ọ̀pọ̀ ohun ìjà jọ láti fi gbéjà kò wọ́n rí, bẹ́ẹ̀ wọ́n ṣì tún máa kó púpọ̀ sí i jọ. (Ìṣípayá 12:17) Àmọ́, kò sí ìkankan tó tíì ṣàṣeyọrí kò sì sí èyí tí yóò ṣàṣeyọrí. Sátánì kò ní ohun ìjà kankan tó lè paná ìgbàgbọ́ àti ìtara àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. “Ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà” ni àlàáfíà nípa tẹ̀mí jẹ́, nítorí náà, ẹnikẹ́ni ò lè já a gbà mọ́ wọn lọ́wọ́ rárá.—Sáàmù 118:6; Róòmù 8:38, 39.
28 Kò tilẹ̀ sí ohunkóhun tí ayé Sátánì lè ṣe tí yóò lè fòpin sí iṣẹ́ àti ìjọsìn mímọ́ tí kò dáwọ́ dúró tí àwọn ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ ń ṣe fún Ọlọ́run. Ìtùnú gbáà ni ìfinilọ́kànbalẹ̀ yẹn sì jẹ́ fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ ìtùnú fún àwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú. Bí a bá ṣe ní ìmọ̀ nípa ètò àjọ Jèhófà ti ọ̀run àti àjọse rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé tó, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa yóò ṣe lágbára tó. Bí ìgbàgbọ́ wa bá sì ti jẹ́ alágbára, ó tán, asán ni gbogbo ohun ìjà yòówù kí Sátánì fi gbéjà kò wá yóò já sí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 12:1-17 ṣe fi hàn, “obìnrin” Ọlọ́run yìí rí ìbùkún ńlá gbà ní ti bíbí tó bí “ọmọ” tó ṣe pàtàkì jù lọ, àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí pàtó kan kọ́ ni ọmọ yìí o, Ìjọba Mèsáyà ní ọ̀run ni. Ọdún 1914 ló bí i. (Wo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, ojú ewé 177 sí 186.) Ayọ̀ tó bá a nítorí bí Ọlọ́run ṣe ń bù kún àwọn ọmọ rẹ̀ ẹni àmì òróró tó wà ní orí ilẹ̀ ayé ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tẹnu mọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 218, 219]
Ìdílé Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ìdílé Ábúráhámù jẹ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn àpẹẹrẹ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa irú àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ní ọ̀run àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ májẹ̀mú Òfin Mósè.—Gálátíà 4:22-31.
Ábúráhámù, tó jẹ́ olórí ìdílé, dúró fún Jèhófà Ọlọ́run. Bí Ábúráhámù ṣe múra tán láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ jẹ́ àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe múra tán láti fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-13; Jòhánù 3:16.
Sárà ṣàpẹẹrẹ “aya” Ọlọ́run ní ọ̀run, ìyẹn ètò àjọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí ó ní. Ṣíṣàpèjúwe ètò àjọ ti ọ̀run yẹn gẹ́gẹ́ bí aya Jèhófà bá a mu wẹ́kú gan-an ni, nítorí pé àjọṣe tímọ́tímọ́ ló ní pẹ̀lú Jèhófà, ó ń fi ìtẹríba ṣègbọràn sí ipò orí rẹ̀, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Wọ́n tún pè é ní “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” (Gálátíà 4:26) “Obìnrin” yìí kan náà ni wọ́n mẹ́nu kàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, òun ni wọ́n sì ń ṣàpèjúwe nínú ìran tó wà nínú Ìṣípayá 12:1-6, 13-17.
Ísákì ṣàpẹẹrẹ Irú Ọmọ nípa tẹ̀mí ti obìnrin Ọlọ́run. Ní pàtàkì jù lọ Jésù Kristi ni irú ọmọ náà. Àmọ́, àwọn arákùnrin Kristi tó jẹ́ ẹni àmì òróró tún wá di ara irú ọmọ yìí pẹ̀lú, wọ́n wá di àwọn tí Ọlọ́run gbà ṣe ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, wọ́n sì di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.—Róòmù 8:15-17; Gálátíà 3:16, 29.
Hágárì, tó jẹ́ aya onípò kejì, tàbí wáhàrì fún Ábúráhámù, jẹ́ ẹrú. Ó bá Jerúsálẹ́mù ti orí ilẹ̀ ayé mu lọ́nà tó ṣe wẹ́kú, níbi tí Òfin Mósè ti ń darí àwọn tó wà níbẹ̀, tó sì tú gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ òfin yẹn fó pé wọ́n jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Hágárì yìí túmọ̀ sí Sínáì, òkè ńlá kan ní Arébíà,” nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti fìdí májẹ̀mú Òfin múlẹ̀.—Gálátíà 3:10, 13; 4:25.
Íṣímáẹ́lì, ọmọ Hágárì, dúró fún àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù tó ṣì ń sìnrú lábẹ́ Òfin Mósè. Bí Íṣímáẹ́lì ṣe ṣenúnibíni sí Ísákì náà ni àwọn Júù wọ̀nyẹn ṣe ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni, àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọmọ Sárà ìṣàpẹẹrẹ, tí í ṣe “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” Gẹ́lẹ́ bí Ábúráhámù sì ṣe lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ náà ni Jèhófà ṣe ta Jerúsálẹ́mù àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ọmọ rẹ̀ nù nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.—Mátíù 23:37, 38.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 220]
Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, Jèhófà fẹ̀mí mímọ́ yàn án, Aísáyà 54:1 sì wà bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 225]
“Kìkì ìṣẹ́jú kan” ni Jèhófà fi pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò lára Jerúsálẹ́mù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 231]
Ǹjẹ́ jagunjagun àti alágbẹ̀dẹ lè borí Ẹlẹ́dàá wọn bí?