Igbeyawo Ha ni Kọkọrọ Kanṣoṣo naa Si Ayọ Bi?
“Oun di ominira lati bá ẹni ti ó fẹ́ gbeyawo, kìkì ninu Oluwa. Ṣugbọn oun jẹ́ alayọ ju bi o bá duro bi o ti wà.”—1 KỌRINTI 7:39, 40, NW.
1. Bawo ni Iwe Mimọ ṣe ṣapejuwe Jehofa, ki ni ó sì ti ṣe fun awọn ẹ̀dá rẹ̀?
JEHOFA jẹ́ “Ọlọrun alayọ.” (1 Timoti 1:11, NW) Gẹgẹ bi Olupese Ọpọ yanturu “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pípé,” oun mú wà larọọwọto fun gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀—eniyan ati ẹmi—ohun ti wọn nilo gan-an lati layọ ninu iṣẹ-isin rẹ̀. (Jakobu 1:17) Fun idi yẹn, ẹyẹ kan ti o ti ẹnu bọ orin, ọmọ ọ̀lọ́ǹbọ̀ òkun ti ń yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, tabi ẹja lámùsóò òkun ti o kúndùn eré ṣiṣe gbogbo wọn jẹrii sii pe Jehofa dá awọn ẹranko lati gbadun iwalaaye ninu awọn ibugbe wọn lọkọọkan. Onisaamu naa tilẹ lọ jinna debi sisọ lọna ewì pe “awọn igi Jehofa nitẹẹlọrun, awọn kédárì Lebanoni ti oun ti gbìn.”—Saamu 104:16, NW.
2. (a) Ki ni ó fihan pe Jesu ri ayọ ninu ṣiṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀? (b) Awọn idi wo fun ayọ ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni?
2 Jesu ni ‘aworan Jehofa tikaraarẹ.’ (Heberu 1:3) Kò yanilẹnu nigba naa, pe Jesu ni a nilati pe ni “alayọ ati Ọba Alagbara-giga kanṣoṣo.” (1 Timoti 6:15, NW) Oun pese apẹẹrẹ agbayanu fun wa nipa bi ṣiṣe ifẹ-inu Jehofa ti lè tẹnilọrun ju ounjẹ lọ, ni pipese inudidun alailabula. Jesu tun fihan wa pe igbadun lè wà nigba ti a bá ń huwa ninu ibẹru Ọlọrun, iyẹn ni pe, pẹlu ọ̀wọ̀ jijinlẹ ati ìfòyà pípéye lati maṣe mú Un binu. (Saamu 40:8; Aisaya 11:3; Johanu 4:34) Nigba ti 70 awọn ọmọ-ẹhin “fi ayọ” pada lẹhin irin-ajo iwaasu Ijọba kan, Jesu fúnraarẹ̀ “kún fun ayọ gidigidi ninu ẹmi mimọ.” Lẹhin sisọ ayọ rẹ̀ fun Baba rẹ̀ ninu adura, ó yiju pada si awọn ọmọ-ẹhin ó sì wi pe: “[Alayọ ni] oju ti ń rí ohun ti ẹyin ń ri: nitori mo wi fun yin, wolii ati ọba pupọ ni o ń fẹ́ lati ri ohun ti ẹyin ń rí, wọn kò sì rí wọn, ati lati gbọ́ ohun ti ẹyin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”—Luuku 10:17-24.
Awọn Idi Fun Jíjẹ́ Aláyọ̀
3. Ki ni awọn idi diẹ fun ayọ?
3 Kò ha yẹ ki awọn oju wa layọ lati ri awọn ohun ti a rí ni imuṣẹ Ọrọ ati awọn ète Jehofa ni akoko opin yii bi? Kò ha yẹ kí a kún fun ayọ lati loye awọn asọtẹlẹ ti iru awọn wolii oluṣotitọ ati ọba bii Aisaya, Daniẹli, ati Dafidi kò lè lóye bi? Kò ha dun mọ́ wa lati ṣiṣẹsin Ọlọrun alayọ naa, Jehofa, labẹ ipo aṣaaju alayọ Ọba Alagbara-giga, Ọba wa Jesu Kristi bi? Dajudaju ó dùn mọ́ wa!
4, 5. (a) Lati wà ni alayọ titilọ ninu iṣẹ-isin Jehofa, ki ni a gbọdọ yẹra fun? (b) Ki ni awọn ohun diẹ ti o dákún ayọ, ibeere wo sì ni eyi gbé dide?
4 Bi o ti wu ki o ri, bi a bá fẹ́ wà ní alayọ titilọ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun, a kò gbọdọ gbé ohun ti ó pọndandan fun ayọ wa ka ori awọn èrò ti ayé. Iwọnyi lè fi tirọruntirọrun ṣíji bo ironu wa nitori pe wọn ni ọrọ̀ nipa ti ara, ọ̀nà igbesi-aye aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, ati ohun ti o jọ bẹẹ ninu. “Ayọ” ti a sì gbekari iru awọn nǹkan bẹẹ kì yoo tọ́jọ́, nitori pe ayé yii ń kọja lọ.—1 Johanu 2:15-17.
5 Ọpọ julọ ninu awọn iranṣẹ Jehofa ti o ti ṣeyasimimọ mọ̀ pe lílé awọn gongo ti ayé bá kì yoo mú ayọ tootọ wa. Baba wa ọ̀run nikanṣoṣo ní ń pese awọn ohun tẹmi ati ti ara ti ń pakun ojulowo ayọ awọn iranṣẹ rẹ̀. A ti kún fun ọpẹ́ tó fun ounjẹ tẹmi ti ó ń fun wa nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu”! (Matiu 24:45-47, NW) A tun kún fun imoore fun ounjẹ ti ara ati awọn ohun ti ara miiran ti a ń rígbà lati ọwọ onifẹẹ ti Ọlọrun. Lẹhin naa, pẹlu, ẹbun agbayanu ti igbeyawo wà ati awọn ayọ ti o tan mọ igbesi-aye idile. Abajọ ti a fi sọ idaniyanfẹ atọkanwa Naomi fun awọn iyawo ọmọkunrin rẹ ti wọn jẹ́ opo pẹlu awọn ọrọ wọnyi: “Ǹjẹ́ ki Jehofa fun yin ni ẹbun kan, ki ẹyin sì rí ibi isinmi lẹnikọọkan ninu ile ọkọ rẹ̀.” (Ruutu 1:9, NW) Nitori naa igbeyawo jẹ́ kọkọrọ kan ti ó lè ṣí ilẹkun si ayọ ńlá. Ṣugbọn igbeyawo ha ni kìkì kọkọrọ tí ń ṣí oju-ọna si igbesi-aye alayọ bi? Awọn ọdọ eniyan ni pataki nilati fi ironu jinlẹ ṣayẹwo yala eyi jẹ́ bẹẹ.
6. Ni ibamu pẹlu Jẹnẹsisi, ki ni ète ipilẹṣẹ fun eto igbeyawo?
6 Ni rirohin ìtàn ipilẹṣẹ igbeyawo, Bibeli sọ pe: “Bẹẹ ni Ọlọrun dá eniyan ni aworan rẹ̀, ni aworan Ọlọrun ni ó dá a; ati akọ ati abo ni ó dá wọn. Ọlọrun sì súre fun wọn. Ọlọrun sì wí fun wọn pe, ẹ maa bí sii, ki ẹ sì maa rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ, ki ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹnẹsisi 1:27, 28) Nipa dídá ti Jehofa dá igbeyawo silẹ, Adamu ni a lo lati mú ẹ̀dá eniyan pupọ sii wá si ìyè, ti ó sì tipa bayii mú kí ìran eniyan maa gbooro sii. Ṣugbọn igbeyawo ni ohun ti ó pọ sii ju eyi lọ.
“Kìkì Ninu Oluwa”
7. Ohun wo ti a beere fun igbeyawo ni babanla oluṣotitọ kan ṣe isapa ńláǹlà lati muṣẹ?
7 Niwọn bi Jehofa Ọlọrun ti jẹ́ Olupilẹṣẹ igbeyawo, a gbọdọ reti rẹ̀ lati gbé awọn ọ̀pá idiwọn fun ìdè igbeyawo ti yoo yọrisi ayọ awọn iranṣẹ rẹ̀ kalẹ. Ni akoko awọn babanla, igbeyawo pẹlu awọn wọnni ti wọn kì í ṣe olujọsin Jehofa ni a kò fun niṣiiri rárá. Aburahamu jẹ́ ki iranṣẹ rẹ̀ Eliasari fi Jehofa bura pe oun kì yoo mú aya laaarin awọn ará Kenaani fun Isaaki ọmọkunrin babanla naa. Eliasari rin irin-ajo gigun ó sì tẹle awọn itọni Aburahamu kínníkínní ki o baa lè ri ‘obinrin ti Jehofa, ti yàn fun ọmọ oluwa rẹ̀.’ (Jẹnẹsisi 24:3, 44) Nitori naa Isaaki gbé Rebeka niyawo. Nigba ti ọmọkunrin wọn Esau yan awọn aya lati inu awọn ọmọ Hiti abọriṣa, awọn obinrin wọnyi jẹ́ orisun “ibinujẹ fun Isaaki ati fun Rebeka.”—Jẹnẹsisi 26:34, 35; 27:46; 28:1, 8.
8. Ìkálọ́wọ́kò wo ni a gbekari igbeyawo labẹ majẹmu Ofin, eesitiṣe?
8 Labẹ majẹmu Ofin, fifẹ awọn ọkunrin tabi obinrin ti wọn jẹ́ ti awọn orilẹ-ede Kenaani kan pato ni a kàléèwọ̀. Jehofa fun awọn eniyan rẹ̀ nitọọni pe: “Bẹẹni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá àna; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ. Nitori pe wọn ó yí ọmọkunrin rẹ pada lati maa tọ̀ mi lẹhin, ki wọn ki o lè maa sin ọlọrun miiran: ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo sì ru si yin, oun a sì run ọ́ lojiji.”—Deutaronomi 7:3, 4.
9. Imọran wo lori igbeyawo ni Bibeli fifun awọn Kristẹni?
9 Kò yanilẹnu pe awọn ìkálọ́wọ́kò kan naa lori gbígbé awọn wọnni ti wọn ki i jọsin Jehofa niyawo ni a gbọdọ fisilo ninu ìjọ Kristẹni. Apọsiteli Pọọlu rọ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ẹ maṣe fi aidọgba tọrunbọ àjàgà pẹlu awọn alaigbagbọ. Nitori ajọṣe wo ni ododo atí ìwà ailofin ni? Tabi ajọpin wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹlu okunkun? Siwaju sii, ibamu wo ni ń bẹ laaarin Kristi ati Beliali? Tabi ipin wo ni oloootọ eniyan ni pẹlu alaigbagbọ?” (2 Kọrinti 6:14, 15, NW) Imọran yẹn ṣee fisilo ni oniruuru ọ̀nà ó sì daju pe ó kan igbeyawo. Itọni yékéyéké Pọọlu fun gbogbo awọn iranṣẹ oluṣeyasimimọ ti Jehofa ni pe wọn gbọdọ gba gbígbé ẹnikan niyawo rò “kìkì bi ó bá wà ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa.”—1 Kọrinti 7:39, alaye ẹsẹ̀-ìwé NW.
Wọn Kò Lè Gbeyawo “Ninu Oluwa”
10. Ki ni ọpọlọpọ awọn Kristẹni ti wọn kò ṣegbeyawo ń ṣe, awọn ibeere wo ni ó sì dide?
10 Ọpọlọpọ awọn Kristẹni àpọ́n ti yàn lati tẹle apẹẹrẹ Jesu Kristi nipa mímú ẹbun àìṣègbéyàwó dagba. Ati pẹlu, nitori jíjẹ́ ẹni ti kò lè ri olùbáṣègbéyàwó oniwa-bi-Ọlọrun ni lọ́ọ́lọ́ọ́ ki wọn sì tipa bayii gbeyawo “ninu Oluwa,” ọpọlọpọ awọn Kristẹni aduroṣinṣin ti fi igbẹkẹle wọn sinu Jehofa wọn sì ti wà ni àpọ́n dipo ki wọn fẹ́ alaigbagbọ. Ẹmi Ọlọrun ń mú iru awọn eso bii ayọ, alaafia, igbagbọ, ati ikora-ẹni-nijaanu jade ninu wọn, ti ń mú ki o ṣeeṣe fun wọn lati maa ba wíwà ni àpọ́n oniwa mímọ́ lọ titi. (Galatia 5:22, 23) Lara awọn wọnni ti wọn ń koju idanwo ifọkansin si Ọlọrun yii lọna aṣeyọri ni iye kan lara awọn Kristẹni arabinrin wa, awọn ti a ni ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun. Ni oniruuru awọn ilẹ, wọn tayọ iye awọn arakunrin ati nitori naa wọn ni ipin titobi ju ninu iṣẹ iwaasu. Nitooto, “Jehofa fúnraarẹ̀ ti funni ni ọrọ naa; awọn obinrin ti ń sọ ihinrere jẹ́ ọmọ-ogun ńlá.” (Saamu 68:11, NW) Niti tootọ, ọpọlọpọ ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn kò tii ṣegbeyawo ni tọkunrin tobinrin ń pa iwatitọ mọ nitori pe wọn ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wọn gbẹkẹle Jehofa, ó sì ń mú ki ipa-ọna wọn tọ́.’ (Owe 3:5, 6) Ṣugbọn ó ha daju pe awọn wọnni ti wọn kò lè gbeyawo “ninu Oluwa” ni lọ́ọ́lọ́ọ́ kò ní layọ bi?
11. Nipa ki ni awọn Kristẹni ti wọn wà ni àpọ́n titilọ nitori ọ̀wọ̀ fun awọn ilana Bibeli lè ni idaniloju?
11 Ẹ jẹ ki a ranti pe a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Ọlọrun alayọ naa, Jehofa, ti ń ṣiṣẹsin labẹ alayọ Ọba Alagbara-giga, Jesu Kristi. Nitori naa bi ọ̀wọ̀ wa fun awọn ìkálọ́wọ́kò ti a fi kalẹ ni kedere ninu Bibeli bá nilati sun wa lati wà ni àpọ́n titilọ nitori jíjẹ́ ẹni ti kò lè rí olùbáṣègbéyàwó kan “ninu Oluwa,” ó ha bọgbọnmu lati ronu pe Ọlọrun ati Kristi yoo fi wa silẹ lailayọ bi? Dajudaju bẹẹkọ. Fun idi yii, a gbọdọ pari èrò si pe ó ṣeeṣe lati jẹ́ alayọ gẹgẹ bii Kristẹni nigba ti a si wà ni ipo aiṣegbeyawo. Jehofa lè mú wa layọ nitootọ yala a gbeyawo tabi a wà ni àpọ́n.
Kọkọrọ Naa si Ayọ Tootọ
12. Ki ni ọ̀ràn awọn angẹli alaigbọran fihan niti igbeyawo?
12 Igbeyawo kì í ṣe kọkọrọ kanṣoṣo naa si ayọ fun gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, wo awọn angẹli. Ṣaaju Ìkún-omi, awọn angẹli kan mu ifẹ-ọkan ti kò bá iwa ẹ̀dá mu fun awọn ẹ̀dá ẹmi dagba, wọn di alainitẹẹlọrun pe awọn kò lè gbeyawo, wọn sì gbe ẹran ara eniyan wọ̀ ki wọn baa lè mú awọn obinrin ni aya. Nitori pe awọn angẹli wọnyi tipa bẹẹ “fi ipo wọn silẹ,” Ọlọrun ‘ti pa [wọn] mọ ninu ẹwọn ainipẹkun nisalẹ okunkun de idajọ ọjọ ńlá nì.’ (Juuda 6; Jẹnẹsisi 6:1, 2) Ni kedere, Ọlọrun ko ṣeto rí fun awọn angẹli lati gbeyawo. Nitori naa igbeyawo ko wulẹ lè jẹ́ kọkọrọ naa si ayọ wọn.
13. Eeṣe ti awọn angẹli mímọ́ fi layọ, ki sì ni eyi fihan fun gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun?
13 Sibẹ, awọn angẹli oluṣotitọ layọ. Jehofa fi awọn ipilẹ ayé lélẹ̀ “si ijumọ kọrin pọ alayọ ti awọn irawọ owurọ ati ijumọ hó ìhó ayọ awọn angẹli ọmọ Ọlọrun.” (Joobu 38:7, The New Jerusalem Bible [Gẹẹsi]) Eeṣe ti awọn angẹli mimọ fi layọ? Nitori pe wọn ń ṣeranṣẹ fun Jehofa Ọlọrun nigba gbogbo, ‘ni fifeti si ohùn ọrọ rẹ̀’ ki wọn baa lè mu ṣẹ. Wọn ni inudidun ninu ‘ṣiṣe ifẹ rẹ̀.’ (Saamu 103:20, 21, alaye ẹsẹ̀-ìwé) Bẹẹni, ayọ awọn angẹli wá lati inu ṣiṣiṣẹsin Jehofa pẹlu iṣotitọ. Iyẹn ni kọkọrọ naa si ayọ tootọ fun awọn eniyan pẹlu. Fun idi yẹn, awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti wọn gbeyawo ti wọn ń fi tayọtayọ ṣiṣẹsin Ọlọrun nisinsinyi ki yoo gbeyawo nigba ti a bá ji wọn dide sí ìyè ti ọrun, ṣugbọn wọn yoo layọ gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi ti ń ṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Yala wọn jẹ́ ẹni ti o ti gbeyawo tabi ti o wà ni àpọ́n, nigba naa, gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin lè layọ nitori pe ipilẹ fun ayọ tootọ ni iṣẹ-isin oloootọ si Ẹlẹdaa.
“Ohun Kan Ti Ó Sàn Ju Awọn Ọmọkunrin ati Ọmọbinrin”
14. Ileri alasọtẹlẹ wo ni a fi fun awọn iwẹfa oniwa-bi-Ọlọrun ni Isirẹli igbaani, eesitiṣeti eyi fi lè jọ bi ẹni pe ó ṣajeji?
14 Ani bi Kristẹni aduroṣinṣin kan kò bá gbeyawo paapaa, Ọlọrun lè mú ayọ ẹni yẹn daju. Iṣiri ni a lè rí fayọ lati inu awọn ọrọ alasọtẹlẹ yii ti a dari si awọn iwẹfa ni Isirẹli igbaani pe: “Eyi ni ohun ti Jehofa ti sọ fun awọn iwẹfa ti ń pa awọn ọjọ isinmi mi mọ́ ti wọn sì ti yan ohun ti mo ni inudidun ninu [rẹ̀] ti wọn sì ń gbá majẹmu mi mú: ‘Emi yoo fi fun wọn ninu ile mi ati laaarin awọn ogiri mi ohun irannileti kan ati orukọ kan, ohun kan ti ó sàn ju awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Orukọ kan titi akoko titi lọ gbére ni emi yoo fi fun wọn, ọ̀kan ti a ki yoo ké kuro.’” (Aisaya 56:4, 5, NW) Ẹnikan ti lè reti pe awọn ẹnikọọkan wọnyi ni a o ṣeleri aya ati awọn ọmọ fun lati mú orukọ wọn wà titi. Ṣugbọn a ṣeleri “ohun kan ti ó sàn ju awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin” fun wọn—orukọ pipẹtiti ninu ile Jehofa.
15. Ki ni a lè sọ nipa imuṣẹ Aisaya 56:4, 5?
15 Bi a bá ka awọn iwẹfa wọnyi sí aworan alasọtẹlẹ ti o wémọ́ “Isirẹli Ọlọrun,” wọn duro fun awọn ẹni ami ororo ti wọn gba ibi wíwà pẹtiti ninu ile tẹmi, tabi tẹmpili Jehofa. (Galatia 6:16) Laiṣiyemeji, asọtẹlẹ yii yoo ni ifisilo olówuuru fun awọn iwẹfa oniwa-bi-Ọlọrun ti Isirẹli igbaani ti a ji dide. Bi wọn bá tẹwọgba ẹbọ irapada Kristi ti wọn sì ń ba a lọ lati yan ohun ti Jehofa ni inu didun ninu rẹ̀, wọn yoo gba “orukọ kan titi akoko titilọ gbére” ninu ayé titun ti Ọlọrun. Eyi pẹlu tun ṣee fisilo fun awọn wọnni ti wọn jẹ́ “agutan miiran” ni akoko opin yii ti wọn yáfì igbeyawo ati jíjẹ́ òbí ki wọn baa lè lo araawọn ni kikun fun iṣẹ-isin Jehofa. (Johanu 10:16) Diẹ ninu wọn lè kú laigbeyawo ati lailọmọ. Ṣugbọn bi wọn bá jẹ́ oloootọ, ni ajinde wọn yoo gba “ohun kan ti ó sàn ju awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin”—orukọ kan “ti a kì yoo ké kuro” ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan titun.
Igbeyawo Kì í Ṣe Kọkọrọ Kanṣoṣo si Ayọ
16. Eeṣe ti a fi lè sọ pe igbeyawo ki i figba gbogbo mu ayọ wá?
16 Awọn eniyan kan nimọlara pe ayọ tanmọ igbeyawo lọna ti kò ṣee yà kuro. Bi o ti wu ki o ri, a gbọdọ gbà pe, laaarin awọn iranṣẹ Jehofa lonii paapaa, igbeyawo kò figba gbogbo mú ayọ wá. Ó yanju awọn iṣoro kan ṣugbọn niye ìgbà ó ń ṣokunfa awọn miiran ti wọn lè tubọ ṣoro lati dojukọ ju awọn wọnni ti awọn eniyan ti wọn wà àpọ́n ń nírìírí rẹ̀ lọ. Pọọlu sọ pe igbeyawo ń mú ‘ipọnju ninu ẹran ara’ wa. (1 Kọrinti 7:28) Awọn akoko wà nigba ti ẹnikan ti o ti ṣegbeyawo “ń ṣaniyan” ti o sì ń “pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ.” Oun lọkunrin tabi lobinrin niye ìgbà ń rí i pe ó ṣoro lati “ṣiṣẹsin Oluwa nigba gbogbo laisi ìpínyà-ọkàn.”—1 Kọrinti 7:33-35, NW.
17, 18. (a) Ki ni awọn alaboojuto arinrin-ajo kan ti rohin? (b) Amọran wo ni Pọọlu fi funni, eesitiṣe ti o fi ṣanfaani lati fi í silo?
17 Ati igbeyawo ati wíwà ni àpọ́n jẹ́ ẹ̀bùn lati ọdọ Ọlọrun. (Ruutu 1:9; Matiu 19:10-12) Bi o ti wu ki o ri, lati ṣaṣeyọri ninu ipo eyikeyii ninu mejeeji, ironu ti ó kún fun adura ṣe kókó. Awọn alaboojuto arinrin-ajo rohin pe ọpọlọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí ń gbeyawo nigba ti wọn ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ gan-an, niye ìgbà ti wọn ń di òbí ṣaaju ki wọn tó ṣetan lati gbé ẹru-iṣẹ ti ó ń yọrisi. Diẹ ninu awọn igbeyawo wọnyi ń túká. Awọn tọkọtaya miiran koju awọn iṣoro wọn, ṣugbọn igbeyawo wọn kò tii mu ayọ wá fun wọn. Gẹgẹ bi Oyinbo eléré ori ìtàgé kan William Congreve ti kọwe, awọn wọnni ti wọnbá fi ìwárapàpà gbeyawo “lè farabalẹ kabaamọ.”
18 Awọn alaboojuto ayika tun rohin pe awọn ọ̀dọ́ arakunrin kan fà sẹhin kuro ninu fifọwọ si iṣẹ-isin Bẹtẹli tabi yiyọnda araawọn fun Ile-Ẹkọ Idanilẹkọọ Iṣẹ-Ojiṣẹ nitori ohun abeere fun lati wà ni àpọ́n fun akoko kan. Ṣugbọn Pọọlu funni ni amọran lati maṣe gbeyawo ṣaaju ìgbà ti ẹnikan ba tó “rekọja ìgbà ìtanná èwe,” iyẹn ni, lati duro titi di ìgbà ti ìrugùdù akọkọ ti agbara òòfà-ọkàn si ibalopọ takọtabo bá tó lọ silẹ. (1 Kọrinti 7:36-38) Awọn ọdun ti a lò ni gbígbé gẹgẹ bi agbalagba àpọ́n kan pese iriri ati oye inu ṣiṣeyebiye fun ẹnikan, ni fifi ẹni naa lọkunrin tabi lobinrin si ipo didara ju lati yan ẹnikeji ninu igbeyawo tabi fi tiṣọratiṣọra gbe ipinnu lati wà ni àpọ́n titilọ yẹwo.
19. Oju wo ni a lè fi wo awọn ọ̀ràn bi a kò bá ni aini gidi fun igbeyawo?
19 Diẹ ninu wa ti rekọja ìgbà ìtànná èwe, pẹlu ifẹ alagbara rẹ̀ fun àjọṣepọ̀ timọtimọ onibaalopọ takọtabo. A lè ronu síwá-sẹ́hìn lori awọn ibukun igbeyawo lóòrèkóòrè ṣugbọn si a ni ẹ̀bùn wíwà ni àpọ́n niti gidi. Jehofa lè rí i pe a ṣiṣẹsin oun lọna gbigbeṣẹ ni ipo àpọ́n pe a kò sì ni aini gidi naa fun igbeyawo, eyi ti ó lè beere pe ki a fi awọn anfaani kan bayii ninu iṣẹ-isin rẹ̀ silẹ. Bi igbeyawo ki i bá ṣe aini ara-ẹni ti a kò sì bukun wa pẹlu olùbáṣègbéyàwó kan, Ọlọrun lè ni ohun miiran kan ni ipamọ fun wa. Nitori naa ẹ jẹ ki a lo igbagbọ pe oun yoo pese ohun ti a nilo. Ayọ titobi julọ ń jẹ jade lati inu fifi tirẹlẹtirẹlẹ tẹwọgba ohun ti o bá jẹ́ ifẹ-inu Ọlọrun fun wa, ani gẹgẹ bi awọn arakunrin Juu ṣe ‘gbà laijanpata ti wọn sì yin Ọlọrun logo’ lori mímọ̀ pe ó ti yọọda ironupiwada fun awọn Keferi ki wọn baa lè ni ìyè.—Iṣe 11:1-18.
20. (a) Imọran wo lori wíwà ni àpọ́n ni a fi fun awọn Kristẹni ọ̀dọ́ nihin-in? (b) Kókó ipilẹ wo nipa ayọ ni ó ṣì jẹ́ otitọ?
20 Wayi o, nigba naa, igbeyawo lè jẹ́ kọkọrọ kan si ayọ, bi o tilẹ jẹ pe ó tun lè ṣí ọ̀nà silẹ fun awọn iṣoro. Ohun kan daju: Igbeyawo kì í ṣe ọ̀nà kanṣoṣo lati ri ayọ. Bi a ti gbe ohun gbogbo yẹwo, yoo bá ọgbọn mu nigba naa, fun awọn Kristẹni ọ̀dọ́ ni pataki, lati gbiyanju lati wá ààyè fun awọn ọdun melookan ti wíwà ni àpọ́n. Awọn ọdun diẹ ni a lè lo daradara lati ṣiṣẹsin Jehofa ki a sì tẹsiwaju ninu ipo tẹmi. Laika ọjọ-ori tabi ipo tẹmi si, bi o ti wu ki o ri, kókó ipilẹ yii ṣì jẹ́ otitọ fun gbogbo awọn wọnni ti wọn ti ṣeyasimimọ si Ọlọrun láìṣẹ́kùsíbìkankan pe: Ayọ tootọ ni a ń rí ninu iṣẹ-isin oloootọ si Jehofa.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahunpada?
◻ Eeṣe ti awọn iranṣẹ Jehofa fi layọ?
◻ Eeṣe ti igbeyawo ki i ṣe kọkọrọ naa si ayọ titobi julọ?
◻ Ninu ọ̀ràn yíyan olubaṣegbeyawo, ki ni a beere fun lọdọ awọn eniyan Jehofa?
◻ Eeṣe ti ó fi bá ọgbọn mu lati gbagbọ pe awọn Kristẹni ti wọn wà ni àpọ́n titilọ le layọ?
◻ Ki ni a gbọdọ gbà nipa igbeyawo ati ayọ?