Orí Kejìdínlógún
Jèhófà Mú Ẹ̀mí Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀ Sọ Jí
1. Ọ̀rọ̀ afinilọ́kànbalẹ̀ wo ni Jèhófà sọ, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀?
“ÈYÍ ni ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Gíga Fíofío, tí ń gbé títí láé àti ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ mímọ́, wí: ‘Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni ibi tí mo ń gbé, àti pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí, láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.’” (Aísáyà 57:15) Ohun tí wòlíì Aísáyà kọ sílẹ̀ nìyẹn ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Júdà tó mú kí ọ̀rọ̀ yìí wúni lórí gidigidi? Báwo ni ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí yìí ṣe ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ lóde òní? Àgbéyẹ̀wò orí kẹtàdínlọ́gọ́ta ìwé Aísáyà yóò jẹ́ ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyẹn.
“Ẹ Sún Mọ́ Ìhín”
2. (a) Ìgbà wo ló jọ pé ọ̀rọ̀ Aísáyà orí kẹtàdínlọ́gọ́ta tọ́ka sí? (b) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àwọn olódodo nígbà ayé Aísáyà?
2 Ó jọ pé ìgbà ayé Aísáyà gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó wà ní apá ibí yìí ń tọ́ka sí. Ẹ wo bí ìwà ibi ṣe wọ̀ wọ́n lára tó, ó ní: “Olódodo pàápàá ti ṣègbé, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi èyí sí ọkàn-àyà. Àwọn ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni a ń kó jọ sọ́dọ̀ àwọn òkú, nígbà tí kò sí ẹni tí ó fi òye mọ̀ pé nítorí ìyọnu àjálù ni a fi kó olódodo lọ. Ó wọnú àlàáfíà; wọ́n ń sinmi lórí ibùsùn wọn, olúkúlùkù tí ń rìn lọ́nà títọ́.” (Aísáyà 57:1, 2) Bí olódodo bá ṣubú, kò sẹ́ni tó ń bìkítà. Ì báà ṣẹ́kú, kò sẹ́ni tó ń fiyè sí i. Sísùn tó sùn nínú ikú á mú kó rí àlàáfíà, kí ó bọ́ nínú ìyà tí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run fi ń jẹ ẹ́, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ àjálù. Orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn bà jẹ́, ó sì bàlùmọ̀. Àmọ́ ìṣírí ńlá gbáà ló jẹ́ fún àwọn tó ń bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ láti mọ̀ pé yàtọ̀ sí rírí tí Jèhófà rí gbogbo ohun tó ń lọ, yóò tún ti àwọn lẹ́yìn!
3. Báwo ni Jèhófà ṣe sọ̀rọ̀ sí ìran burúkú ní Júdà, èé sì ti ṣe?
3 Jèhófà ké sí ìran burúkú tó wà ní Júdà, ó ní: “Ní tiyín, ẹ sún mọ́ ìhín, ẹ̀yin ọmọ obìnrin oníṣẹ́ àfọ̀ṣẹ, ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti ti obìnrin tí ń ṣe kárùwà.” (Aísáyà 57:3) Àpèjúwe tó tini lójú yìí, pé wọ́n jẹ́ ọmọ oníṣẹ́ àfọ̀ṣẹ àti irú ọmọ panṣágà àti ti obìnrin tí ń ṣe kárùwà yẹ wọ́n gan-an ni. Àwọn ìṣe onírìíra ti ìbọ̀rìṣà àti ìbẹ́mìílò àti onírúurú ìṣekúṣe gbogbo tilẹ̀ wà lára ìjọsìn èké tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà bi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí léèrè pé: “Ta ni ẹ̀yin ń gbádùn àkókò onímùkẹ́ẹ̀kẹ̀ lé lórí? Ta ni ẹ̀yin ń la ẹnu gbàù sí, tí ẹ ń yọ ahọ́n síta sí? Ọmọ ìrélànàkọjá ha kọ́ ni yín, àní irú-ọmọ èké, ẹ̀yin tí ń ru ìfẹ́ onígbòónára sókè láàárín àwọn igi ńlá, lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, ẹ̀yin tí ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta gàǹgà?”—Aísáyà 57:4, 5.
4. Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹni burúkú tó wà ní Júdà?
4 Ojútáyé ni àwọn ẹni burúkú inú Júdà ti kúkú ń ṣe ìbọ̀rìṣà wọn ẹlẹ́gbin, tí wọ́n “ń gbádùn àkókò onímùkẹ́ẹ̀kẹ̀.” Wọ́n ń fi àwọn wòlíì tí Ọlọ́run rán sí wọn láti tọ́ wọn sọ́nà ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á tilẹ̀ yọ ahọ́n wọn síta bí aròbó tó ń ṣe ọ̀-ọ́-bì láti fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ábúráhámù ni wọ́n, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn ti sọ wọ́n di ọmọ ìrélànàkọjá àti irú ọmọ èké. (Aísáyà 1:4; 30:9; Jòhánù 8:39, 44) Wọn a máa ṣe ohun tí yóò mú kí orí àwọn èèyàn yá gágá sí ìbọ̀rìṣà láti àárín àwọn igi ńlá inú igbó wọn. Ìbọ̀rìṣà wọn sì kún fún ìwà ìkà tó burú jáì! Àní wọ́n ń pa ọmọ àwọn tìkára wọn pàápàá, bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò ní ilẹ̀ yẹn nítorí àwọn ìwà ìríra wọn!—1 Àwọn Ọba 14:23; 2 Àwọn Ọba 16:3, 4; Aísáyà 1:29.
Ó Da Ọrẹ Ẹbọ Ohun Mímu sí Àwọn Òkúta
5, 6. (a) Kí ni àwọn ará Júdà yàn láti ṣe dípò tí wọn ì bá fi sin Jèhófà? (b) Báwo ni Júdà kò ṣe fi ìbọ̀rìṣà rẹ̀ bò, báwo ló sì ṣe gbilẹ̀ tó?
5 Ẹ wo bí àwọn ará Júdà ṣe rì wọnú ìbọ̀rìṣà tó: “Ìpín rẹ wà pẹ̀lú àwọn òkúta jíjọ̀lọ̀ tí ó wà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá. Àwọn—àwọn ni ìpín rẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ni ìwọ da ọrẹ ẹbọ ohun mímu sí, tí o fi ẹ̀bùn rúbọ sí. Èmi yóò ha tu ara mi nínú nítorí nǹkan wọ̀nyí?” (Aísáyà 57:6) Àwọn Júù jẹ́ àwọn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, síbẹ̀, dípò tí wọn ó fi máa sìn ín, òkúta ìsàlẹ̀ odò ni wọ́n ṣà jọ tí wọ́n sì sọ di àkúnlẹ̀bọ. Jèhófà ni Dáfídì sọ pé ó jẹ́ ìpín òun, ṣùgbọ́n àwọn òrìṣà òkúta aláìlẹ́mìí ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyí fi ṣe ìpín tiwọn, àwọn ni wọ́n sì ń da ẹbọ ohun mímu sí. (Sáàmù 16:5; Hábákúkù 2:19) Báwo wá ni ìbàjẹ́ tí àwọn èèyàn tí Jèhófà pè mọ́ ara rẹ̀ yìí ń ṣe nínú ìjọsìn ṣe fẹ́ tu Jèhófà nínú?
6 Ibi gbogbo ni Júdà ti ń bọ̀rìṣà, ì báà ṣabẹ́ igi, ì báà ṣàfonífojì, ì báà ṣorí àwọn òkè, tàbí nínú ìlú wọn. Àmọ́ gbogbo rẹ̀ pátá ni Jèhófà rí, tó sì gbẹnu Aísáyà táṣìírí rẹ̀, ó ní: “Orí òkè ńlá gíga tí ó sì gbé sókè ni o gbé ibùsùn rẹ kalẹ̀ sí. Ibẹ̀ pẹ̀lú ni o gòkè lọ láti rú ẹbọ. Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti òpó ilẹ̀kùn ni o gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí.” (Aísáyà 57:7, 8a) Orí àwọn ibi gíga ni Júdà tẹ́ ibùsùn àìmọ́ nípa tẹ̀mí rẹ̀ sí, ibẹ̀ ló sì ti ń rú àwọn ẹbọ sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ òkèèrè.a Kódà àwọn ilé àdáni pàápàá ní òrìṣà lẹ́yìn àwọn ilẹ̀kùn àti òpó ilẹ̀kùn wọn.
7. Ẹ̀mí wo ni Júdà fi ń ṣe ìbọ̀rìṣà oníṣekúṣe?
7 Àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tó tilẹ̀ mú kí Júdà kira bọ ìsìn àìmọ́ tó bẹ́ẹ̀. Àbí alágbára kan tó jù ú lọ ló mú kó pa Jèhófà tì tipátipá ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá o. Ó fínnú-fíndọ̀ ṣe é pẹ̀lú ìháragàgà ni. Jèhófà sọ pé: “O tú ara rẹ sí ìhòòhò fún àwọn ẹlòmíràn dípò mi, o sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ; o sọ ibùsùn rẹ di aláyè gbígbòòrò. O sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn dá májẹ̀mú fún ara rẹ. Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ibùsùn pẹ̀lú wọn. Ẹ̀yà ara akọ ni ìwọ rí.” (Aísáyà 57:8b) Júdà bá àwọn òrìṣà rẹ̀ dá májẹ̀mú, ó sì fẹ́ràn àjọṣe oníṣekúṣe tí wọ́n jọ ń ṣe pọ̀. Ní pàtàkì, ó fẹ́ràn ìwà ìṣekúṣe tó wé mọ́ bíbọ àwọn òrìṣà wọ̀nyí gan-an ni, tó jọ pé ó kan ìlò àwọn òkúta tí a gbẹ́ ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ akọ!
8. Ìgbà ìṣàkóso ọba wo ní pàtó ni ìbọ̀rìṣà gbilẹ̀ ní Júdà?
8 Àpèjúwe ìbọ̀rìṣà oníṣekúṣe àti oníwà ìkà tó burú jáì bá ohun tí a mọ̀ nípa ọ̀pọ̀ ìkà ọba tó jẹ ní Júdà mu gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, Mánásè kọ́ àwọn ibi gíga, ó mọ àwọn pẹpẹ fún òrìṣà Báálì, ó sì gbé àwọn pẹpẹ ìsìn èké kalẹ̀ sí àgbàlá méjì nínú tẹ́ńpìlì. Ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ la iná já, ó ń ṣe iṣẹ́ òkùnkùn, ó lọ ń woṣẹ́, ó sì mú kí ìbẹ́mìílò gbilẹ̀. Mánásè Ọba tún gbé ère òpó ọlọ́wọ̀ fínfín tí ó ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà.b Ó sún Júdà láti dẹ́ṣẹ̀, àní láti ṣe “ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú.” (2 Àwọn Ọba 21:2-9) Àwọn kan gbà gbọ́ pé Mánásè ló ní kí wọ́n pa Aísáyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Mánásè kò fara hàn nínú Aísáyà orí kìíní ẹsẹ kìíní.
‘O Ń Bá A Lọ Ní Rírán Àwọn Aṣojú Rẹ’
9. Kí nìdí tí Júdà fi rán àwọn aṣojú rẹ̀ “sí ibi jíjìnnàréré”?
9 Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà kò mọ sí àwọn òrìṣà bíbọ nìkan. Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Mélékì ti ìwọ ti òróró, o sì ń mú kí àwọn òróró ìkunra rẹ pọ̀ yanturu. O sì ń bá a lọ ní rírán àwọn aṣojú rẹ sí ibi jíjìnnàréré, tí ìwọ fi rẹ àwọn ọ̀ràn wálẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù.” (Aísáyà 57:9) Ìjọba Júdà aláìṣòótọ́ sọ̀ kalẹ̀ tọ “Mélékì” lọ, èyí tó túmọ̀ sí “ọba” lédè Hébérù, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ọba ilẹ̀ òkèèrè alágbára kan, wọ́n wá ń fún un ní àwọn ẹ̀bùn olówó gọbọi tó jọjú, tí òróró àti àwọn òróró ìkunra olóòórùn dídùn ṣàpẹẹrẹ. Júdà rán àwọn ońṣẹ́ lọ sí àwọn ọ̀nà jíjìn réré. Fún kí ni? Láti lọ rọ àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí pé kí wọ́n wá bá òun wọ àjọṣe pa pọ̀. Bó ṣe kẹ̀yìn sí Jèhófà, àwọn ọba ilẹ̀ òkèèrè ló lọ gbẹ́kẹ̀ lé.
10. (a) Báwo ni Áhásì Ọba ṣe wọ àjọṣe pẹ̀lú ọba Ásíríà? (b) Ọ̀nà wo ni Júdà gbà “rẹ àwọn ọ̀ràn wálẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù”?
10 Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ wáyé nígbà ayé Áhásì Ọba. Bí ọkàn aláìṣòótọ́ ọba Júdà yìí kò ti balẹ̀ nítorí àjọṣe tó wà láàárín Ísírẹ́lì àti Síríà, ló bá rán àwọn ońṣẹ́ sí Tigilati-pílésà Kẹta ti Ásíríà, ó ní: “Ìránṣẹ́ rẹ àti ọmọkùnrin rẹ ni mí. Gòkè wá gbà mí là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Síríà àti kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ísírẹ́lì, àwọn tí ó dìde sí mi.” Áhásì wá fi fàdákà àti wúrà ránṣẹ́ láti fi bẹ ọba Ásíríà lọ́wẹ̀, ọba yẹn sì wá ṣe ohun tí ó bẹ̀ ẹ́, ó ṣígun ti Síríà, ó sì ṣe wọ́n ṣúkaṣùka. (2 Àwọn Ọba 16:7-9) Bí Júdà ṣe ń bá àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí wọ àjọṣe, ńṣe ló rẹ ara rẹ̀ “wálẹ̀ sí Ṣìọ́ọ̀lù.” Nítorí àwọn àjọṣe yẹn sì ni yóò ṣe kú, tàbí pé kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira tí ó ní ọba mọ́.
11. Báwo ni Júdà ṣe tan ara rẹ̀ pé kò séwu fún òun?
11 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Júdà lọ, ó ní: “O ti ṣe làálàá nínú ògìdìgbó àwọn ọ̀nà rẹ. Ìwọ kò wí pé, ‘Ìrètí kò sí!’ Ìwọ ti rí ìmúsọjí láti inú agbára rẹ. Ìdí nìyẹn tí ìwọ kò tíì fi ṣàìsàn.” (Aísáyà 57:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, orílẹ̀-èdè yẹn ti ṣe làálàá gan-an ni lẹ́nu àwọn ọ̀nà ìpẹ̀yìndà rẹ̀, kò sì jẹ́ rí i pé kò sí ìrètí kankan nínú àwọn ohun tí òun ń ṣòpò lé lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ń ṣe ló ń tan ara rẹ̀ jẹ nípa gbígbàgbọ́ pé ìsapá òun yóò mú òun ṣe àṣeyọrí. Ó gbà pé kébékébé lara òun ṣì ń ta. Áà, ó mà kúkú gọ̀ o!
12. Àwọn ipò wo nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jọ ti Júdà?
12 Ètò àjọ kan wà lónìí tí ìṣe rẹ̀ jọ ti Júdà ìgbà ayé Aísáyà gan-an ni. Kirisẹ́ńdọ̀mù ń lo orúkọ Jésù, àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni ó ń bá wọ àjọṣe káàkiri, ó sì kó ère kún àwọn ibi ìjọsìn rẹ̀ fọ́fọ́. Àní àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní àwọn ère òrìṣà nínú ilé tiwọn pàápàá. Kirisẹ́ńdọ̀mù tún fi àwọn ọ̀dọ́ èèyàn rẹ̀ rúbọ nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè. Ìríra gbáà ni gbogbo èyí yóò jẹ́ lójú Ọlọ́run tòótọ́ tó pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà”! (1 Kọ́ríńtì 10:14) Bí Kirisẹ́ńdọ̀mù sì ṣe tọrùn bọ ìṣèlú, ó ti bá ‘àwọn ọba ilẹ̀ ayé ṣe àgbèrè’ nìyẹn. (Ìṣípayá 17:1, 2) Ká sòótọ́, ọ̀kan lára alátìlẹyìn pàtàkì fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni. Kí ló máa tó dé bá aṣẹ́wó onísìn yìí? Ó dára, kí ni Jèhófà sọ fún Júdà aláìṣòótọ́ tó dà bíi tirẹ̀ níṣàájú, pàápàá fún Jerúsálẹ́mù olú ìlú rẹ̀ tó ń ṣojú fún un?
“Àwọn Nǹkan Tí O Kó Jọ Kì Yóò Dá Ọ Nídè”
13. ‘Irọ́’ wo ni Júdà bẹ̀rẹ̀ sí pa, kí sì ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí sùúrù Jèhófà?
13 Jèhófà bi í pé: “Ta ni jìnnìjìnnì bá ọ nítorí rẹ̀, tí o sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù, tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí purọ́?” Ìbéèrè yẹn tọ́ jàre! Dájúdájú, Júdà kò bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tí ó tọ́ tí ó sì yẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀-èdè yẹn ì bá má ti jẹ́ òpùrọ́ àti abọ̀rìṣà látòkè délẹ̀. Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Èmi kọ́ ni ẹni tí ìwọ rántí. Ìwọ kò fi nǹkan kan sí ọkàn-àyà. Èmi kò ha dákẹ́, tí mo sì fi àwọn ọ̀ràn pa mọ́? Nítorí náà ni ìwọ kò ṣe bẹ̀rù èmi pàápàá.” (Aísáyà 57:11) Jèhófà dákẹ́ ní ti pé kò jẹ Júdà níyà lójú ẹsẹ̀. Ǹjẹ́ Júdà mọrírì èyí bí? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ka sùúrù Ọlọ́run yìí sí àìbìkítà. Kò bẹ̀rù Ọlọ́run mọ́ rárá.
14, 15. Kí ni Jèhófà sọ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Júdà àti ‘àwọn nǹkan tí ó kó jọ’?
14 Àmọ́, àkókò tí Ọlọ́run fi ní sùúrù máa tó dópin. Ìgbà yẹn ni Jèhófà ń wò tó fi kéde pé: “Èmi fúnra mi yóò sọ nípa òdodo rẹ àti iṣẹ́ rẹ, tí wọn kì yóò fi ṣe ọ́ láǹfààní. Nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àwọn nǹkan tí o kó jọ kì yóò dá ọ nídè, ṣùgbọ́n ẹ̀fúùfù yóò gbé gbogbo wọn pàápàá lọ. Èémí àmíjáde yóò gbé wọn lọ.” (Aísáyà 57:12, 13a) Jèhófà máa táṣìírí òdodo ẹ̀tàn tí Júdà ń ṣe. Iṣẹ́ àgàbàgebè rẹ̀ kò ní ṣe é láǹfààní rárá. ‘Àwọn nǹkan tó kó jọ,’ ìyẹn àwọn òrìṣà tó tò jọ, kò ní gbà á sílẹ̀. Bí àjálù bá dé, èémí tó fẹ́ yẹ́ẹ́ lásán ni yóò fẹ́ àwọn òrìṣà tí ó gbẹ́kẹ̀ lé dà nù.
15 Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìgbà yẹn ni Nebukadinésárì ọba Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, tí ó jó tẹ́ńpìlì, tí ó sì kó ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ibẹ̀ nígbèkùn. “Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.”—2 Àwọn Ọba 25:1-21.
16. Kí ló ń dúró de Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ìyókù “Bábílónì Ńlá”?
16 Bákan náà, àwọn òrìṣà tí Kirisẹ́ńdọ̀mù kó jọ pelemọ kò ní gbà á sílẹ̀ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà. (Aísáyà 2:19-22; 2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò pa rẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìyókù “Bábílónì Ńlá” tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ni. Ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ, aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò, àti ìwo mẹ́wàá rẹ̀ ni “yóò . . . sọ [Bábílónì Ńlá] di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:3, 16, 17) A mà dúpẹ́ o, pé a ṣègbọràn sí àṣẹ náà tó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀”! (Ìṣípayá 18:4, 5) Ǹjẹ́ kí a má ṣe padà sínú rẹ̀ tàbí sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ mọ́ láé.
“Ẹni Tí Ó Bá Sá Di Mí Ni Yóò Jogún Ilẹ̀ Náà”
17. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún ‘ẹni tó bá sá di í,’ ìgbà wo ni ìlérí yẹn sì ṣẹ?
17 Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé èyí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá ńkọ́ o? Ó ní: “Ẹni tí ó bá sá di mí ni yóò jogún ilẹ̀ náà, tí yóò sì gba òkè ńlá mímọ́ mi.” (Aísáyà 57:13b) Ta ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ nísinsìnyí? Ńṣe ni Jèhófà ń wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àjálù tí ń bọ̀, tí ó sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn rẹ̀ yóò ṣe gba ìdáǹdè kúrò ní Bábílónì tí wọn yóò sì mú ìjọsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù, òkè mímọ́ rẹ̀. (Aísáyà 66:20; Dáníẹ́lì 9:16) Èyí á mà fún àwọn Júù tó bá ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ níṣìírí gan-an o! Jèhófà sọ̀rọ̀ síwájú sí i, ó ní: “Dájúdájú, ẹnì kan yóò sì wí pé, ‘Ẹ kọ bèbè, ẹ kọ bèbè! Ẹ tún ọ̀nà ṣe. Ẹ mú ohun ìdìgbòlù èyíkéyìí kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.’” (Aísáyà 57:14) Tí àkókò bá tó tí Ọlọ́run yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, ọ̀nà yóò là gbọnrangandan, tí gbogbo ohun ìdìgbòlù yóò sì kúrò lọ́nà.—2 Kíróníkà 36:22, 23.
18. Báwo la ṣe ṣàpèjúwe gíga tí Jèhófà ga fíofío, síbẹ̀ ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ wo ló gbà ń ṣàníyàn nípa ẹni?
18 Ìgbà yìí ni wòlíì Aísáyà wá sọ ọ̀rọ̀ tí a fà yọ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yẹn, tó sọ pé: “Èyí ni ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Gíga Fíofío, tí ń gbé títí láé àti ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ mímọ́, wí: ‘Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni ibi tí mo ń gbé, àti pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí, láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.’” (Aísáyà 57:15) Ibi tó ga jù lọ ní ọ̀run ni ìtẹ́ Jèhófà wà. Kò tún sí ibòmíràn tó ròkè tàbí tó ga ju ibẹ̀ lọ. Ó mà tuni nínú gan-an o láti mọ̀ pé, láti ibẹ̀, ó ń rí gbogbo ohun tó ń lọ, àti pé yàtọ̀ sí pé ó ń rí ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ẹni burúkú ń dá, ó tún ń rí iṣẹ́ òdodo tí àwọn tó ń ṣakitiyan láti sìn ín ń ṣe! (Sáàmù 102:19; 103:6) Ẹ̀wẹ̀, ó ń gbọ́ bí àwọn tí wọ́n ń ni lára ṣe ń kérora, ó sì ń mú ọkàn àyà àwọn ẹni tí a tẹ̀ rẹ́ sọjí. Ọ̀rọ̀ yìí ti ní láti wọ àwọn tó ronú pìwà dà lára àwọn Júù ayé àtijọ́ lọ́kàn gan-an ni. Ó dájú pé ó wọ àwa náà lọ́kàn lóde òní pẹ̀lú.
19. Ìgbà wo ni ìkannú Jèhófà máa ń rọlẹ̀?
19 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ síwájú sí i tún tuni nínú gan-an pẹ̀lú, ó ní: “Kì í ṣe fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò máa báni fà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe títí lọ fáàbàdà ni èmi yóò kún fún ìkannú; nítorí pé ẹ̀mí pàápàá yóò di ahẹrẹpẹ nítorí mi, àní àwọn ẹ̀dá eléèémí tí èmi fúnra mi ṣẹ̀dá.” (Aísáyà 57:16) Ká ní pé ìkannú Jèhófà máa ń wà títí lọ fáàbàdà ni, láìlópin, kò sí ìkankan nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí ì bá lè là á. Àmọ́, ó dùn mọ́ni pé kìkì ìgbà kúkúrú ni ìkannú Ọlọ́run máa fi ń wà. Bí ìkannú rẹ̀ bá ti ṣe iṣẹ́ tó fẹ́ ṣe, ìkannú yẹn a sì rọlẹ̀. Ìjìnlẹ̀ òye tí ó ní ìmísí yìí ń mú ká ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún ìfẹ́ tí Jèhófà fẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀.
20. (a) Ọwọ́ wo ni Jèhófà fi ń mú ẹni tó ṣe àṣemáṣe tí kò sì ronú pìwà dà? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń tu oníròbìnújẹ́ nínú?
20 A rí ìjìnlẹ̀ òye síwájú sí i bí Jèhófà ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Ó kọ́kọ́ sọ pé: “Nítorí ìṣìnà èrè rẹ̀ aláìbá ìdájọ́ òdodo mu ni ìkannú mi ṣe ru, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, nígbà tí ìkannú mi ru. Ṣùgbọ́n ó ń rìn ṣáá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dàlẹ̀ ní ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ̀.” (Aísáyà 57:17) Ó dájú pé bí èèyàn bá fi ìwà ìwọra ṣe àṣemáṣe, onítọ̀hún á rí ìbínú Ọlọ́run. Bí èèyàn bá sì ti ń bá a lọ láti jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ ní ọkàn àyà rẹ̀, Jèhófà kò ní dáwọ́ ìkannú rẹ̀ dúró. Ṣùgbọ́n bí ọ̀dàlẹ̀ náà bá kọbi ara sí ìbáwí yẹn ńkọ́? Jèhófà sọ ohun tí ìfẹ́ àti àánú rẹ̀ yóò sún un láti ṣe, ó ní: “Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀ gan-an; mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú un lára dá, mo sì darí rẹ̀, mo sì fi ìtùnú san àsanfidípò fún un àti fún àwọn tirẹ̀ tí ń ṣọ̀fọ̀.” (Aísáyà 57:18) Bí Jèhófà bá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ èèyàn tán, ó máa ń mú ẹni tó bá jẹ́ oníròbìnújẹ́ lára dá, a sì tu onítọ̀hún àtàwọn tó ń bá a ṣọ̀fọ̀ nínú. Ìyẹn ló fi ṣeé ṣe fún àwọn Júù láti padà sílé lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lóòótọ́ o, Júdà kò padà di ìjọba olómìnira tí ọba láti ìlà ìdílé Dáfídì ń ṣàkóso mọ́. Síbẹ̀, wọ́n tún tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù kọ́, wọ́n sì mú kí ìjọsìn mímọ́ tún máa bá a lọ níbẹ̀.
21. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ẹ̀mí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sọjí lọ́dún 1919? (b) Ànímọ́ wo ló yẹ kí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi kọ́ra?
21 Lọ́dún 1919, Jèhófà “Ẹni Gíga àti Ẹni Gíga Fíofío” fi hàn pé òun bìkítà nípa ire àwọn ẹni àmì òróró pẹ̀lú. Nítorí ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní, Jèhófà, Ọlọ́run gíga jù lọ fi inú rere kíyè sí ìpọ́njú wọn, ó sì gbà wọ́n kúrò nígbèkùn Bábílónì. Ó mú gbogbo ohun ìdìgbòlù kúrò lọ́nà, ó ṣamọ̀nà wọn tí wọ́n fi gba òmìnira kí wọ́n lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́ sí i. Bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ṣe ṣẹ nígbà yẹn nìyẹn. Àwọn ìlànà tí yóò wà títí ayérayé, tí ó kan olúkúlùkù wa sì ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Ìjọsìn àwọn tí ó bá ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ni Jèhófà máa ń tẹ́wọ́ gbà. Bí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá sì dẹ́ṣẹ̀, kí onítọ̀hún tètè mọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀ṣẹ̀, kí ó gba ìbáwí, kí ó sì tún àwọn ọ̀nà rẹ̀ ṣe. Ǹjẹ́ kí á má ṣe gbàgbé láé pé Jèhófà a máa mú àwọn onírẹ̀lẹ̀ lára dá, a sì máa tù wọ́n nínú, àmọ́ a máa “kọ ojú ìjà sí àwọn onírera.”—Jákọ́bù 4:6.
‘Àlàáfíà fún Àwọn Tó Jìnnà àti Àwọn Tó Wà Nítòsí’
22. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé ó ń bẹ níwájú fún (a) àwọn tó ronú pìwà dà? (b) àwọn ẹni ibi?
22 Jèhófà wá ń fi ìyàtọ̀ hàn nípa ohun tí ń bẹ níwájú fún àwọn tó ronú pìwà dà àti fún àwọn tó ń bá àwọn ọ̀nà burúkú wọn lọ, ó ní: “Èmi yóò dá èso ètè. Àlàáfíà tí ń bá a lọ ni yóò wà fún ẹni tí ó jìnnà réré àti fún ẹni tí ó wà nítòsí, . . . èmi yóò sì mú un lára dá dájúdájú. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tí a ń bì síwá bì sẹ́yìn, nígbà tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀, èyí tí omi rẹ̀ ń sọ èpò òkun àti ẹrẹ̀ sókè. Àlàáfíà kò sí fún àwọn ẹni burúkú.”—Aísáyà 57:19-21.
23. Kí ni èso ètè, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà “dá” èso ètè yìí?
23 Èso ètè ni ẹbọ ìyìn tí a ń rú sí Ọlọ́run, ìyẹn pípolongo orúkọ rẹ̀ ní gbangba. (Hébérù 13:15) Báwo ni Jèhófà ṣe ń “dá” ìpolongo ní gbangba yẹn? Láti lè rú ẹbọ ìyìn, èèyàn ní láti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí ó sì gbà á gbọ́. Ìgbàgbọ́ tí í ṣe ara èso ẹ̀mí Ọlọ́run ni yóò wá sún onítọ̀hún láti máa sọ ohun tí ó gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó ń polongo ní gbangba nìyẹn. (Róòmù 10:13-15; Gálátíà 5:22) Kí á sì tún rántí pé Jèhófà gan-an ló yan iṣẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n lọ máa kéde ìyìn òun. Jèhófà sì ni ó dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti lè rú irú ẹbọ ìyìn yẹn. (1 Pétérù 2:9) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ ọ́ dájúdájú pé Jèhófà ló dá èso ètè yìí.
24. (a) Àwọn wo ló wá mọ àlàáfíà Ọlọ́run, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀? (b) Ta ni kò wá mọ àlàáfíà rárá, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀ fún wọn?
24 Ẹbọ èso ètè tí àwọn Júù sì rú nígbà tí wọ́n padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ti àwọn ti orin ìyìn sí Jèhófà á mà sì pọ̀ gan-an o! Wọn ì báà wà níbi tó “jìnnà réré,” ìyẹn ọ̀nà jíjìn sí Júdà, kí wọ́n máa dúró de ìgbà tí wọn yóò padà sílé, tàbí kí wọ́n wà “nítòsí,” ìyẹn ni pé kí wọ́n ti wà nínú ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìdùnnú ńlá ni yóò jẹ́ fún wọn láti mọ bí àlàáfíà Ọlọ́run ṣe máa ń rí. Ipò àwọn ẹni burúkú yàtọ̀ pátápátá gbáà sí tiwọn! Ẹnikẹ́ni tó bá kùnà láti kọbi ara sí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà fi bá wọn wí, ìyẹn àwọn ẹni burúkú, àní ẹni yòówù kí wọ́n jẹ́ àti ibikíbi tí wọn ì báà wà, kò lè sí àlàáfíà fún wọn rárá. Nítorí ńṣe ni wọ́n ń ru gùdù bí òkun tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀, èkìdá “èpò òkun àti ẹrẹ̀” tó jẹ́ ohun àìmọ́ gbogbo, ni wọ́n ń mú jáde ṣáá, wọn kò mú èso ètè jáde rárá.
25. Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lọ́nà jíjìn àti nítòsí ṣe ń di ẹni tó mọ àlàáfíà?
25 Lónìí pẹ̀lú, àwọn olùjọsìn Jèhófà níbi gbogbo ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni tó wà lọ́nà jíjìn àti àwọn tó wà nítòsí, ní orílẹ̀-èdè tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ, ń rú ẹbọ èso ètè wọn, tí wọ́n sì ń kókìkí ìyìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. “Láti ìkángun ilẹ̀ ayé” pàápàá ni àwọn èèyàn ti ń gbóhùn orin ìyìn tí wọ́n ń kọ. (Aísáyà 42:10-12) Àwọn tó ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń wí tí wọ́n sì kọbi ara sí i ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí í ṣe Bíbélì. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá ń mọ àlàáfíà, èyí tí wọ́n ń rí látinú sísìn tí wọ́n ń sin “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà.”—Róòmù 16:20.
26. (a) Kí ní bẹ níwájú fún àwọn ẹni burúkú? (b) Ìlérí àgbàyanu wo ni Ọlọ́run ṣe fún àwọn ọlọ́kàn tútù, kí ló sì yẹ kí ó jẹ́ ìpinnu wa?
26 Òótọ́ ni pé àwọn ẹni burúkú kò kọbi ara sí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, kò ní sí àyè fún wọn láti máa dí àlàáfíà àwọn olódodo lọ́wọ́ mọ́. Jèhófà ṣèlérí pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” Àwọn tó bá sá di Jèhófà yóò jogún ilẹ̀ ayé lọ́nà àgbàyanu. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11, 29) Áà, ilẹ̀ ayé wa yìí yóò mà dùn gan-an nígbà yẹn o! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti má ṣe pàdánù àlàáfíà Ọlọ́run láé, kí a lè máa kọ orin ìyìn Ọlọ́run títí ayérayé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí ohun tí a pè ní “ibùsùn” níhìn-ín máa tọ́ka sí pẹpẹ tàbí sí ojúbọ. Pípè é ní ibùsùn jẹ́ ìránnilétí pé irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà aṣẹ́wó nípa tẹ̀mí.
b Ó ṣeé ṣe kí àwọn òpó ọlọ́wọ̀ dúró fún ohun tó jẹ mọ́ ti abo, kí àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ sì jẹ́ àwọn òkúta tí a gbẹ́ ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ akọ. Méjèèjì sì ni àwọn ará Júdà aláìṣòótọ́ lò.—2 Àwọn Ọba 18:4; 23:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 263]
Júdà ń ṣe ìjọsìn oníwà ìbàjẹ́ lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 267]
Júdà kọ́ àwọn pẹpẹ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 275]
“Èmi yóò dá èso ètè”