Àìsáyà
66 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+
3 Ẹni tó ń pa akọ màlúù dà bí ẹni tó ń ṣá èèyàn balẹ̀.+
Ẹni tó ń fi àgùntàn rúbọ dà bí ẹni tó ń ṣẹ́ ọrùn ajá.+
Ẹni tó ń mú ẹ̀bùn wá dà bí ẹni tó ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ!+
Ẹni tó ń mú oje igi tùràrí wá láti fi ṣe ọrẹ ìrántí+ dà bí ẹni tó ń fi ọfọ̀ súre.*+
Wọ́n ti yan ọ̀nà tiwọn,
Ohun ìríra ló sì ń múnú wọn dùn.*
4 Torí náà, màá yan ọ̀nà tí màá fi jẹ wọ́n níyà,+
Àwọn ohun tí wọ́n sì ń bẹ̀rù gan-an ni màá mú kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.
Torí nígbà tí mo pè, kò sẹ́ni tó dáhùn;
Nígbà tí mo sọ̀rọ̀, kò sẹ́ni tó fetí sílẹ̀.+
Wọ́n ń ṣe ohun tó burú lójú mi ṣáá,
Ohun tí inú mi ò dùn sí ni wọ́n sì yàn pé àwọn fẹ́ ṣe.”+
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ̀n rìrì* torí ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn arákùnrin yín tó kórìíra yín, tí wọ́n sì ta yín nù nítorí orúkọ mi sọ pé, ‘Ká yin Jèhófà lógo!’+
Àmọ́ Ó máa fara hàn, ó sì máa mú ayọ̀ wá fún yín,
Àwọn sì ni ojú máa tì.”+
6 À ń gbọ́ ariwo látinú ìlú, ìró kan látinú tẹ́ńpìlì!
Ìró Jèhófà ni, ó ń san ohun tó yẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún wọn.
7 Kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bímọ.+
Kí ìrora ìbímọ tó mú un, ó bí ọmọ ọkùnrin.
8 Ta ló ti gbọ́ irú rẹ̀ rí?
Ta ló ti rí irú rẹ̀ rí?
Ṣé a lè bí ilẹ̀ kan ní ọjọ́ kan ni?
Àbí a lè bí gbogbo orílẹ̀-èdè kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo?
Síbẹ̀, gbàrà tí Síónì bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.
9 “Ṣé màá mú kó rọbí, tí kò sì ní bímọ ni?” ni Jèhófà wí.
“Àbí máa mú kó bímọ, kí n wá ti ilé ọlẹ̀ rẹ̀ pa?” ni Ọlọ́run rẹ wí.
10 Ẹ bá Jerúsálẹ́mù yọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín dùn sí i,+ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+
Ẹ bá a yọ̀ gidigidi, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀,
11 Ẹ máa mu ọmú rẹ̀ tó ń tuni nínú, ó sì máa tẹ́ yín lọ́rùn gidigidi,
Ẹ máa mu ún dáadáa, inú yín sì máa dùn sí ògo rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.
12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
Ẹ máa mu ọmú, a máa gbé yín sí ẹ̀gbẹ́,
Wọ́n á sì máa bá yín ṣeré lórí orúnkún.
14 Ẹ máa rí èyí, inú yín sì máa dùn,
Egungun yín máa yọ dáadáa bíi koríko tútù.
15 “Torí pé Jèhófà máa wá bí iná,+
Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ìjì líle,+
Láti fi ìbínú líle san ẹ̀san,
Kó sì fi ọwọ́ iná báni wí.+
16 Torí pé iná ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́,
Àní, ó máa fi idà rẹ̀ bá gbogbo ẹran ara* jà;
Àwọn tí Jèhófà pa sì máa pọ̀ rẹpẹtẹ.
17 Àwọn tó ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn láti wọnú àwọn ọgbà,*+ tí wọ́n ń tẹ̀ lé ẹni tó wà ní àárín, àwọn tó ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+ àwọn ohun ìríra àti eku,+ gbogbo wọn jọ máa wá sí òpin wọn,” ni Jèhófà wí. 18 “Torí mo mọ iṣẹ́ wọn àti ìrònú wọn, mò ń bọ̀ wá kó èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti èdè jọ, wọ́n sì máa wá rí ògo mi.”
19 “Màá fi àmì kan sáàárín wọn, màá sì rán lára àwọn tó yè bọ́ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè, sí Táṣíṣì,+ Púlì àti Lúdì,+ àwọn tó ń ta ọfà, sí Túbálì àti Jáfánì,+ títí kan àwọn erékùṣù tó wà lọ́nà jíjìn, tí wọn ò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi, tí wọn ò sì tíì rí ògo mi; wọ́n sì máa kéde ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 20 Wọ́n máa kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọ́n á fi wọ́n ṣe ẹ̀bùn fún Jèhófà, lórí ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ tí wọ́n bo orí rẹ̀, lórí àwọn ìbaaka àti lórí àwọn ràkúnmí tó ń yára kánkán, wọ́n á kó wọn wá sórí òkè mímọ́ mi, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,” ni Jèhófà wí, “bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tó mọ́ gbé ẹ̀bùn wọn wá sínú ilé Jèhófà.”
21 “Mo tún máa mú lára wọn láti ṣe àlùfáà, màá sì fi àwọn kan ṣe ọmọ Léfì,” ni Jèhófà wí.
22 “Bí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun+ tí mò ń dá ṣe máa dúró níwájú mi,” ni Jèhófà wí, “bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ* yín àti orúkọ yín ṣe máa dúró.”+