Jehofa Ṣe Ojúrere sí I Lọ́nà Gíga
“KÚ DÉÉDÉÉ ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojúrere sí lọ́nà gíga, Jehofa wà pẹlu rẹ.” Irú ìkíni yìí mà tún ga o! Ẹni tí ó sọ̀rọ̀ yìí kò yẹ̀ ní áńgẹ́lì Gabrieli. Ó ń bá ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀ kan sọ̀rọ̀—Maria, ọmọbìnrin ọkùnrin kan tí a ń pè ní Eli. Ní ọdún 3 B.C.E. ni, ó sì jẹ́ ní ìlú-ńlá Nasareti.—Luku 1:26-28, NW.
Ọjọ́ ti wà lọ́nà fún gbígbé Maria níyàwó fún Josefu gbẹ́nàgbẹ́nà. Ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti àṣà àwọn Juu, a ti ń wò ó gẹ́gẹ́ bí aya tí ó ti fẹ́ sílé. (Matteu 1:18) Bíi ti aya rẹ̀, ó jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ kan níti ipò ìgbésí-ayé. Nígbà náà, èéṣe ti áńgẹ́lì náà fi kí i gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ṣe ojúrere sí lọ́nà gíga?
Àǹfààní Àgbàyanu Rẹ̀
Gabrieli fikún un pé: “Má bẹ̀rù, Maria, nitori iwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun; sì wò ó! iwọ yoo lóyún ninu ilé ọlẹ̀ rẹ iwọ yoo sì bí ọmọkùnrin kan, iwọ yoo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. Ẹni yii yoo jẹ́ ẹni ńlá a óò sì pè é ní Ọmọkùnrin Ẹni Gíga Jùlọ; Jehofa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún un, oun yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jekọbu títí láé, kì yoo sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Luku 1:29-33, NW.
Bí ẹ̀rù ti bà á tí ìdààmú sì bá a, Maria béèrè pé: “Bawo ni èyí yoo ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí emi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹlu ọkùnrin?” Gabrieli dáhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yoo bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jùlọ yoo sì ṣíjibò ọ́. Nitori ìdí èyí pẹlu ohun tí a bí ni a óò pè ní mímọ́, Ọmọkùnrin Ọlọrun.” Láti mú iyèméjì èyíkéyìí kúrò, áńgẹ́lì náà fikún un pé: “Wò ó! Elisabeti ẹbí rẹ fúnra rẹ̀ pẹlu ti lóyún ọmọkùnrin kan, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún oun ẹni tí gbogbo ènìyàn ń pè ní àgàn; nitori pé lọ́dọ̀ Ọlọrun kò sí ìpolongo kankan tí yoo jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Luku 1:34-37, NW.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Maria tẹ́wọ́gba àǹfààní iṣẹ́-ìsìn àgbàyanu yìí. Tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, ó fèsì pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jehofa! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹlu ìpolongo rẹ.” Bí ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀ tán, Gabrieli lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Maria yára kánkán lọ sí ìlú-ńlá kan tí ó wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ olókè-ńlá ti Judah. Bí ó ti dé ilé àlùfáà Sekariah àti aya rẹ̀, Elisabeti, bí áńgẹ́lì náà ti ṣàpèjúwe ipò àwọn nǹkan gẹ́lẹ́ ló rí. Ẹ wo bí ayọ̀ ti kún ọkàn Maria tó! Ètè rẹ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn jáde sí Jehofa.—Luku 1:38-55, NW.
Ó Di Aya Josefu
Wúńdíá kan ni yóò pèsè ara Jesu, nítorí pè a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú ìbí bẹ́ẹ̀. (Isaiah 7:14; Matteu 1:22, 23) Ṣùgbọ́n èéṣe tí a fi béèrè fún wúńdíá kan tí a ti bá ṣe àdéhùn ìgbéyàwó? Kí a baà lè pèsè bàbá tí yóò jẹ́ alágbàtọ́ tí ó lè fi ẹ̀tọ́ òfin fún gígorí ìtẹ́ Ọba Dafidi lé ọmọ náà lọ́wọ́. Josefu àti Maria wá láti inú ẹ̀yà Juda wọ́n sì jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dafidi. Nítorí náà ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ajogún tí Jesu ní ni a óò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ìlọ́po méjì. (Matteu 1:2-16; Luku 3:23-33) Ìdí rẹ̀ nìyí tí áńgẹ́lì náà fi sọ fún Josefu lẹ́yìn náà pé kò níláti kọ̀ láti mú Maria mọ́ra gẹ́gẹ́ bí aya rẹ̀ lábẹ́ òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lóyún.—Matteu 1:19-25.a
Òfin agbẹ́rù-iṣẹ́-kani-lórí tí Kesari Augustu gbé kalẹ̀ sọ ọ́ di dandan fún Josefu àti Maria láti fi orúkọ sílẹ̀ ní Betlehemu. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ó bí ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí. Àwọn olùṣọ́ àgùtàn wá láti rí ọmọ-ọwọ́ náà, wọ́n sì fi ìyìn fún Bàbá rẹ̀, Jehofa. Lẹ́yìn 40 ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mose, Maria lọ sí tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerusalemu láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Lefitiku 12:1-8; Luku 2:22-24) Bẹ́ẹ̀ni, níwọ̀n bí ohun kò ti ní oyún tí ń sọ ìyá di aláìlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀, àwọn àìpé ti ẹ̀dá rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ fi ẹbọ ètùtù bò mọ́lẹ̀.—Orin Dafidi 51:5.
Nígbà tí Maria àti Josefu ṣì wà ní tẹ́ḿpìlì, ó jẹ́ àǹfààní Simeoni àgbàlagbà àti wòlíì obìnrin Anna arúgbó láti rí Ọmọkùnrin Ọlọrun. Kìí ṣe Maria ni àfiyèsí wọn dá lé lórí. (Luku 2:25-38) Lẹ́yìn náà, àwọn amòye awòràwọ̀ tẹríba kìí ṣe fún un bíkòṣe fún Jesu.—Matteu 2:1-12.
Lẹ́yìn sísá lọ sí Egipti àti wíwà níbẹ̀ títí tí Herodu búburú fi kú, àwọn òbí Jesu padà wọ́n sì fìdí kalẹ̀ sí abúlé kékeré Nasareti. (Matteu 2:13-23; Luku 2:39) Níbẹ̀ ni Josefu àti Maria ti tọ́ Jesu dàgbà lábẹ́ ipò tí ó jẹ́ ti ìdílé olùṣèfẹ́ Ọlọrun.
Maria Bí Àwọn Ọmọ Mìíràn
Nígbà tí ó ṣe, Maria àti Josefu bí àwọn àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin lé Jesu. Nígbà tí iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu gbé e dé ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Nasareti, àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ní ìgbà ọmọdé dá a mọ̀. Wọ́n béèrè pé: “Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà naa? Kì í ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ń pè ní Maria, ati awọn arákùnrin rẹ̀ Jakọbu ati Josefu ati Simoni ati Judasi? Ati awọn arábìnrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹlu wa?” (Matteu 13:55, 56, NW) Àwọn ará Nasareti ń tọ́ka sí ìdílé Josefu àti Maria nípa ti ara, títíkan àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin Jesu nípa ti àjọbí.
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí kìí ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí Jesu. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kìí ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tàbí àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tẹ̀mí, nítorí Johannu 2:12 (NW) fi ìyàtọ̀ kedere hàn láàárín àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì náà nípa sísọ pé: “Oun [Jesu] ati ìyá ati awọn arákùnrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu.” Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ní Jerusalemu, aposteli Paulu rí Kefa, tàbí Peteru, ó sì fikún un pé: “Èmi kò rí èyíkéyìí nínú àwọn aposteli yòókù; Jakọbu nìkan ṣoṣo ni mo rí, arákùnrin Oluwa.” (Galatia 1:19, The Jerusalem Bible) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gbólóhùn náà pé Josefu “kò ní ìbádàpọ̀ kankan pẹlu [Maria] títí ó fi bí ọmọkùnrin kan” fihàn pé bàbá tí ó jẹ́ alágbàtọ́ Jesu ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìnwá ìgbà náà ó sì jẹ́ bàbá fún àwọn ọmọ rẹ̀ mìíràn. (Matteu 1:25, NW) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Luku 2:7 pe Jesu ní “àkọ́bí” ọmọkùnrin rẹ̀.
Ìyá tí Ó Jẹ́ Olùbẹ̀rù Ọlọrun
Gẹ́gẹ́ bí ìyá tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun, Maria fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Josefu ní kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní òdodo. (Owe 22:6) Pé òun jẹ́ akíkanjú akẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ni a rí láti inú gbólóhùn dídọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí tí ó lò nígbà tí Elisabeti kí i. Ní àkókò yẹn ìyá Jesu ṣe àsọtúnsọ àwọn èrò ìmọ̀lára inú orin Hanna ó sì fihàn pé òun ní òye àwọn psalmu, àwọn ìwé ìtàn àti ti àsọtẹ́lẹ̀, àti àwọn ìwé Mose. (Genesisi 30:13; 1 Samueli 2:1-10; Owe 31:28; Malaki 3:12; Luku 1:46-55) Maria ti há àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ sórí, ó ti tọ́jú wọn bí ìṣúra sínú ọkàn-àyà rẹ̀, ó sì ti sinmẹ̀dọ̀ ronú lé wọn lórí nínú ọkàn rẹ̀. Nítorí náà ó ti gbaradì dáradára láti kópa nínú fífi ìtọ́ni ti òbí fún ọmọkùnrin náà Jesu.—Luku 2:19, 33.
Jesu ọmọ ọdún 12 tí a ti kọ́ dáradára fi ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ hàn èyí tí ó mú kí àwọn ọkùnrin onímọ̀ ṣe kàyéfì nínú tẹ́ḿpìlì. Nítorí pé ó ti fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ ní àkókò Ìrékọjá yẹn, ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ọmọ, èéṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yii? Wò ó bayii baba rẹ ati emi ti ń wá ọ ninu wàhálà èrò-orí.” Jesu fèsì pé: “Èéṣe tí ẹ fi níláti máa wá mi? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé emi gbọ́dọ̀ wà ninu ilé Baba mi ni?” Níwọ̀n bí kò ti ṣeéṣe fún un láti lóye ìjẹ́pàtàkì èsì yìí, Maria pa á mọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ̀. Ní pípadà sí Nasareti, Jesu ń bá a nìṣó “ní títẹ̀síwájú ninu ọgbọ́n ati ninu ìdàgbàsókè ti ara-ìyára ati ninu ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun ati ènìyàn.”—Luku 2:42-52.
Maria Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-Ẹ̀yìn Jesu
Ẹ wo bí ó ti bá a mu gẹ́ẹ́ tó pé Maria níláti di olùfọkànsìn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní àṣẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀! Ó jẹ́ onínútútù kò sì ní ìlépa àṣeyọrí láti jẹ́ ẹni àrà-ọ̀tọ̀ láìka iṣẹ́ àyànfúnni aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọrun fifún un sí. Maria mọ Ìwé Mímọ́. Bí ìwọ fúnraàrẹ bá yẹ̀ wọ́n wò, ìwọ kì yóò rí ibi tí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ògo, tí a gbé e jókòó sórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí “ìyá-òun-ọbabìnrin” tí ògo tí ń ti ọ̀dọ̀ Kristi tàn wá wẹ̀ kanlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò rí i ní apá ẹ̀yìn, níbi tí a kò ti pe àfiyèsí sí i.—Matteu 13:53-56; Johannu 2:12.
Jesu bẹ́gidí ohunkóhun tí ó jọ Ìjọsìn Maria láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní àkókò kan báyìí, “obìnrin kan lati inú ogunlọ́gọ̀ naa gbé ohùn rẹ̀ sókè pé, ‘Ìbùkún ni fún ilé ọlẹ̀ naa tí ó bí ọ ati ọmú tí iwọ mu!’ Ó fèsì pé: ‘Kàkà bẹ́ẹ̀ ìbùkún ni fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí wọ́n sì ń pa á mọ́.’” (Luku 11:27, 28, The New American Bible, tí a túmọ̀ láti ọwọ́ àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ Catholic Biblical Association of America) Níbi àsè ìgbéyàwó kan, Jesu sọ fún Maria pé: “Kí ni pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin? Wákàtí mi kò tí ì dé síbẹ̀.” (Johannu 2:4, NW) Àwọn ìtumọ̀ mìíràn kà pé: “Jọ̀wọ́ ọ̀ràn náà sí mi lọ́wọ́.” (Weymouth) “Máṣe gbìyànjú láti darí mi.” (An American Translation) Bẹ́ẹ̀ni, Jesu bọ̀wọ̀ fún ìyá rẹ̀, ṣùgbọ́n kò jọ́sìn fún un.
Àwọn Àǹfààní Ayérayé
Ẹ wo àwọn àǹfààní tí Maria gbádùn! Ó bí Jesu. Lẹ́yìn náà ó ṣe ìyá fún ọmọ kékeré náà ó sì fún un ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ní àkótán, ó lo ìgbàgbọ́, ní dídi ọmọ-ẹ̀yìn àti arábìnrin tẹ̀mí fún Kristi. Nígbà tí a gbúròó Maria kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́, a rí i nínú iyàrá òkè ní Jerusalemu. Ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn aposteli Jesu, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mìíràn, àti àwọn obìnrin olùṣòtítọ́ mélòókan—tí gbogbo wọn jẹ́ olùjọ́sìn Jehofa.—Iṣe 1:13, 14.
Nígbà tí ó ṣe, Maria kú ara rẹ̀ sì padà di erùpẹ̀. Bíi ti àwọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹ́yìn ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ìgbà ìjímìjí, ó sùn nínú ikú títí di àkókò tí ó tọ́ ní ojú Ọlọrun láti jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí pẹ̀lú ìwàláàyè àìlèkú nínú ọ̀run. (1 Korinti 15:44, 50; 2 Timoteu 4:8) Ẹ wo bí inú “ẹni tí a ṣe ojúrere sí lọ́nà gíga” yìí yóò ti dùn tó nísinsìnyí níwájú Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí Maria kìí bá ṣe wúńdíá ni, ta ni ìbá jẹ́ fẹ́ ẹ? Àwọn Juu a máa rinkinkin mọ́ ọn pé kí obìnrin kan jẹ́ wúńdíá.—Deuteronomi 22:13-19; fiwé Genesisi 38:24-26.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Gẹ́gẹ́ bí ìyá Jesu a ṣe ojúrere sí Maria lọ́nà gíga