Orí Kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
Àdúrà Ìrònúpìwàdà
1, 2. (a) Kí ni ète ìbáwí Ọlọ́run? (b) Kí ni àwọn Júù lè yàn láti ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà bá wọn wí?
ÌPARUN Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa jẹ́ ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó fi hàn pé ó bínú sí wọn gidigidi. Ìyà ńlá tó jẹ orílẹ̀-èdè Júdà aláìgbọràn sì tọ́ sí wọn gan-an ni. Síbẹ̀, Jèhófà kò pète pé kí àwọn Júù kúkú pa rẹ́ ráúráú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yán ète tí Jèhófà fi ń báni wí fẹ́rẹ́ nígbà tó sọ pé: “Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.”—Hébérù 12:11.
2 Ìhà wo làwọn Júù yóò wá kọ sí ìyà ńlá tó jẹ wọ́n yìí? Ṣé wọ́n á wá kórìíra ìbáwí Jèhófà ni? (Sáàmù 50:16, 17) Tàbí wọ́n á tẹ́wọ́ gbà á láti fi ṣàríkọ́gbọ́n? Ṣé wọ́n á ronú pìwà dà kí wọ́n sì gba ìmúláradá? (Aísáyà 57:18; Ìsíkíẹ́lì 18:23) Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn pé ó kéré tán, àwọn kan lára àwọn ará Júdà yóò fi ìbáwí yẹn ṣàríkọ́gbọ́n. Láti àwọn ẹsẹ 15-19 tó kẹ́yìn Aísáyà orí kẹtàlélọ́gọ́ta títí lọ dé orí kẹrìnlélọ́gọ́ta, a fi orílẹ̀-èdè Júdà hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn oníròbìnújẹ́ tó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà tọkàntọkàn. Wòlíì Aísáyà wá ṣojú fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ tó máa wà nígbèkùn lọ́jọ́ iwájú láti gbàdúrà ìrònúpìwàdà. Bó ṣe ń gbàdúrà yẹn, ó ń sọ̀rọ̀ àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ bíi pé ó ń rí i tí wọ́n ń ṣẹlẹ̀.
Bàbá Oníyọ̀ọ́nú
3. (a) Báwo ni àdúrà Aísáyà tí ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ṣe gbé Jèhófà ga? (b) Báwo ni àdúrà Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé àdúrà Aísáyà tí ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ bá èrò ọkàn àwọn Júù tó ronú pìwà dà ní Bábílónì mu? (Wo àpótí ojú ewé 362.)
3 Aísáyà gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Wò láti ọ̀run, kí o sì rí láti ibùjókòó rẹ gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà.” Ọ̀run ti ẹ̀mí, níbi tí Jèhófà àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀ tí a kò lè fojú rí ń gbé, ni wòlíì yìí ń sọ o. Aísáyà wá tẹ̀ síwájú láti sọ èrò ọkàn àwọn Júù tó wà nígbèkùn, ó ní: “Ìtara rẹ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá rẹ, rírugùdù ìhà inú rẹ, àti àwọn àánú rẹ dà? Wọ́n ti ká ara wọn lọ́wọ́ kò sí mi.” (Aísáyà 63:15) Jèhófà fawọ́ agbára rẹ̀ sẹ́yìn, kò sì jẹ́ kí inú rẹ̀, ìyẹn “rírugùdù ìhà inú [rẹ̀], àti àwọn àánú [rẹ̀],” yọ́ sí àwọn èèyàn rẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà ni “Baba” orílẹ̀-èdè àwọn Júù. Ábúráhámù àti Ísírẹ́lì (Jékọ́bù) ni baba ńlá wọn ní ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí àwọn wọ̀nyẹn bá tiẹ̀ jí sáyé padà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn apẹ̀yìndà yìí lọ́mọ. Àmọ́, ìyọ́nú Jèhófà ju tiwọn lọ. (Sáàmù 27:10) Ẹ̀mí ìmoore wá sún Aísáyà láti sọ pé: “Ìwọ, Jèhófà, ni Baba wa. Olùtúnnirà wa láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni orúkọ rẹ.”—Aísáyà 63:16.
4, 5. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ̀? (b) Irú ìjọsìn wo ni Jèhófà ń fẹ́?
4 Aísáyà wá ń sọ̀rọ̀ látọkànwá pé: “Jèhófà, èé ṣe tí o fi ń mú kí a máa rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ? Èé ṣe tí o fi sé ọkàn-àyà wa le sí bíbẹ̀rù rẹ? Padà wá nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà ohun ìní àjogúnbá rẹ.” (Aísáyà 63:17) Ní tòótọ́, Aísáyà gbàdúrà pé kí Jèhófà padà yí àfiyèsí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́, ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú kí àwọn Júù rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ̀? Ṣé Jèhófà ló sé ọkàn-àyà wọn le ni, tí wọn ò fi bẹ̀rù rẹ̀? Ó tì o, ńṣe ló kàn gbà á láyè kí ó le, nígbà tó sì di pé ìpòrúùru ọkàn bá àwọn Júù, wọ́n wá ń kábàámọ̀ pé Jèhófà fún àwọn ní irú òmìnira tí àwọn ní. (Ẹ́kísódù 4:21; Nehemáyà 9:16) Wọ́n ní Jèhófà ì bá ti fúnra rẹ̀ dá sí ọ̀ràn àwọn kó má jẹ́ kí àwọn ṣi ẹsẹ̀ gbé.
5 A mọ̀ pé Ọlọ́run kì í dá sí ọ̀ràn ọmọ aráyé lọ́nà bẹ́ẹ̀ ṣá o. Ẹ̀dá tó lómìnira ìwà híhù ni wá, Jèhófà sì fún wa láyè láti fúnra wa pinnu bóyá a óò gbọ́ràn sí i lẹ́nu tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 30:15-19) Ìjọsìn àtọkànwá, tí ojúlówó ìfẹ́ ń súnni ṣe, ni Jèhófà ń fẹ́. Ìyẹn ni Jèhófà fi gba àwọn Júù láyè láti lo òmìnira ìwà híhù tí wọ́n ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí mú kí àyè gbà wọ́n láti ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ọ̀nà tó gbà sé ọkàn-àyà wọn le nìyẹn.—2 Kíróníkà 36:14-21.
6, 7. (a) Kí ni àbájáde fífi tí àwọn Júù fi ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀? (b) Kí làwọn Júù ń retí lórí asán, ṣùgbọ́n kí ni wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti retí?
6 Kí ni àbájáde rẹ̀? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nítorí pé ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ fi ní ohun ìní. Àwọn elénìní wa ti fi ẹsẹ̀ tẹ ibùjọsìn rẹ mọ́lẹ̀. Tipẹ́tipẹ́ ni a ti dà bí àwọn tí ìwọ kò ṣàkóso lé lórí, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.” (Aísáyà 63:18, 19) Ìgbà díẹ̀ ni ibùjọsìn Jèhófà fi jẹ́ ti àwọn èèyàn rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbà kí a pa á run kí orílẹ̀-èdè rẹ̀ sì dèrò ìgbèkùn. Nígbà tí ìyẹn ṣẹlẹ̀, ńṣe ló dà bí pé kò sí májẹ̀mú kankan láàárín òun àti àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, àti bí ẹni pé a kò fi orúkọ rẹ̀ pè wọ́n rí. Àwọn Júù wá di ìgbèkùn ní Bábílónì wàyí, wọ́n wá kébòòsí nínú ipò àìnírètí, wọ́n ní: “Ìwọ ì bá jẹ́ gbọn ọ̀run ya, kí o sọ̀ kalẹ̀, kí àwọn òkè ńlá pàápàá mì tìtì ní tìtorí rẹ, bí ìgbà tí iná ran igbó igi wíwẹ́, tí iná sì mú kí omi gan-an hó yaya, kí o bàa lè sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn elénìní rẹ, kí ṣìbáṣìbo bá àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí rẹ!” (Aísáyà 64:1, 2) Jèhófà kúkú lágbára láti gbani là. Dájúdájú, ì bá ti sọ̀ kalẹ̀ wá gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, kí ó gbọn àwọn onírúurú ìjọba tó dà bí ọ̀run ya, kí ó sì fọ́ àwọn ilẹ̀ ọba tó dà bí òkè. Jèhófà ì bá ti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ nípa lílo ìtara rẹ̀ tí ń jó bí iná nítorí àwọn èèyàn rẹ̀.
7 Jèhófà ti ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn rí. Aísáyà mú un wá sí ìrántí pé: “Nígbà tí o ṣe àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù, èyí tí àwa kò lè retí, ìwọ sọ̀ kalẹ̀. Ní tìtorí rẹ, àwọn òkè ńlá pàápàá mì tìtì.” (Aísáyà 64:3) Ńṣe ni irú àwọn ohun àrà bẹ́ẹ̀ fi agbára Jèhófà hàn, ó sì tún fi hàn pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Ṣùgbọ́n, àwọn Júù aláìṣòótọ́ ti ìgbà ayé Aísáyà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti retí pé kí Jèhófà ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fún àǹfààní wọn.
Jèhófà Nìkan Ló Lè Gbani Là
8. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè? (b) Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè gbé ìgbésẹ̀ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là, kí nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? (d) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 64:4 yọ, báwo ló sì ṣe lò ó? (Wo àpótí tó wà lójú ewé 366.)
8 Àwọn òrìṣà kò lè ṣe ohun àrà kankan láti fi gba àwọn tó ń sìn wọ́n là. Aísáyà kọ̀wé pé: “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, kò sí ẹni tí ó tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi etí sí i, bẹ́ẹ̀ ni ojú kò tíì rí Ọlọ́run kan, bí kò ṣe ìwọ, tí ń gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un. Ìwọ ti bá ẹni tí ń yọ ayọ̀ ńláǹlà pàdé tí ó sì ń ṣe òdodo, àwọn tí ń rántí rẹ ní àwọn ọ̀nà rẹ.” (Aísáyà 64:4, 5a) Jèhófà nìkan ṣoṣo ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ó máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti dáàbò bo àwọn tí ń ṣe òdodo àti àwọn tí ń rántí rẹ̀. (Aísáyà 30:18) Ṣé ìwà tí àwọn Júù sì hù nìyẹn? Rárá o. Aísáyà sọ fún Jèhófà pé: “Wò ó! Ìkannú tìrẹ ru, nígbà tí a ń dẹ́ṣẹ̀ ṣáá—a sì pẹ́ gan-an nínú wọn, a ó ha sì gbà wá là?” (Aísáyà 64:5b) Nítorí pé ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti di ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku, kò sídìí kankan tí Jèhófà yóò fi fawọ́ ìbínú òdodo rẹ̀ sẹ́yìn, kó wá gbé ìgbésẹ̀ láti gbà wọ́n là.
9. Kí ni àwọn Júù tó bá ronú pìwà dà lè máa retí, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú èyí?
9 Àwọn Júù kò lè ṣàtúnṣe ohun tí wọ́n ti bà jẹ́ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìsìn mímọ́, wọ́n lè máa retí pé àwọn á rí ìdáríjì àti àwọn ìbùkún gbà lọ́jọ́ iwájú. Bí àkókò bá tó lójú Jèhófà, yóò san èrè fún àwọn tó bá ronú pìwà dà nípa dídá wọn nídè kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì. Síbẹ̀, sùúrù ló ṣì gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ronú pìwà dà, Jèhófà kò ní yí ìṣètò àkókò rẹ̀ padà. Àmọ́, bí wọ́n bá wà lójúfò, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó dájú pé wọ́n á gba ìdáǹdè níkẹyìn. Bákan náà, àwọn Kristẹni lóde òní ń fi sùúrù bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún Jèhófà. (2 Pétérù 3:11, 12) A fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gálátíà 6:9.
10. Kí ni Aísáyà jẹ́wọ́ gbangba gbàǹgbà nínú àdúrà rẹ̀ pé àwọn ò lè ṣe?
10 Àdúrà Aísáyà tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ju jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nìkan lọ. Ó sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé orílẹ̀-èdè yẹn kò lè gba ara rẹ̀ là. Wòlíì yìí sọ pé: “A sì wá dà bí aláìmọ́, gbogbo wa, gbogbo ìṣe òdodo wa sì dà bí aṣọ fún sáà ṣíṣe nǹkan oṣù; àwa yóò sì rẹ̀ dànù bí ewé, gbogbo wa, àwọn ìṣìnà wa ni yóò sì kó wa lọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù.” (Aísáyà 64:6) Ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó ronú pìwà dà ti ṣíwọ́ ìwà apẹ̀yìndà nígbà tí yóò bá fi di òpin ìgbà ìgbèkùn wọn. Wọ́n lè ti yíjú sí Jèhófà nípa ṣíṣe àwọn ìṣe òdodo. Síbẹ̀ aláìpé ni wọ́n. Àwọn iṣẹ́ rere wọn lè tó ohun táa lè yìn wọ́n fún lóòótọ́, ṣùgbọ́n iṣẹ́ wọ̀nyẹn kò sàn ju aṣọ eléèérí lọ tó bá di pé ká lò wọ́n fún ètùtù àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Ìdáríjì Jèhófà jẹ́ ẹ̀bùn àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí à ń rí gbà nítorí àánú rẹ̀. Kì í ṣe ohun táa lè rí gbà nípasẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́ ẹni.—Róòmù 3:23, 24.
11. (a) Ipò tó burú wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù tó wà nígbèkùn wà nípa tẹ̀mí, kí sì nìdí tí ìyẹn fi lè rí bẹ́ẹ̀? (b) Àwọn wo ló jẹ́ àpẹẹrẹ ẹni ìgbàgbọ́ gidi nígbà ìgbèkùn?
11 Bí Aísáyà ṣe wo ọjọ́ iwájú, kí ló rí ná? Wòlíì yìí gbàdúrà pé: “Kò sì sí ẹni tí ń ké pe orúkọ rẹ, kò sí ẹni tí ń ta ara rẹ̀ jí láti dì ọ́ mú; nítorí pé ìwọ ti fi ojú rẹ pa mọ́ fún wa, o sì mú kí a yọ́ nípasẹ̀ agbára ìṣìnà wa.” (Aísáyà 64:7) Ipò tí orílẹ̀-èdè yẹn wà nípa tẹ̀mí burú gidigidi. Wọn kì í gbàdúrà láti ké pe orúkọ Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé wọn kò dá ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà, tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì mọ́, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé wọn kò kọbi ara sí ìjọsìn ṣíṣe mọ́, kò sì sí ‘ẹni tí ń ta ara rẹ̀ jí láti di Jèhófà mú’ mọ́. Ó dájú pé kò sí àjọṣe tó dán mọ́rán láàárín àwọn àti Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan tiẹ̀ sì rò pé àwọn ò tẹ́ni tó ń gbàdúrà sí Jèhófà. Àwọn mìíràn sì lè máa bá ìgbòkègbodò ayé wọn lọ láìfi Ọlọ́run pè rárá. Dájúdájú, àwọn èèyàn bíi Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì, Asaráyà, àti Ìsíkíẹ́lì wà lára àwọn ìgbèkùn wọ̀nyẹn, àmọ́ àpẹẹrẹ ẹni ìgbàgbọ́ gidi ni wọ́n jẹ́. (Hébérù 11:33, 34) Bí àádọ́rin ọdún ìgbèkùn yẹn sì ṣe ń parí lọ, àwọn èèyàn bíi Hágáì, Sekaráyà, Serubábélì, àti Jóṣúà Àlùfáà Àgbà kò kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu mímú ipò iwájú nínú kíké pe orúkọ Jèhófà. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé ipò èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà nígbèkùn ni àdúrà Aísáyà tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ń ṣàpèjúwe.
“Ṣíṣègbọràn Sàn Ju Ẹbọ”
12. Báwo ni Aísáyà ṣe sọ ọ̀rọ̀ fífẹ́ tí àwọn Júù tó ronú pìwà dà fẹ́ láti yíwà padà?
12 Àwọn Júù tó ronú pìwà dà ṣe tán láti yí padà. Aísáyà wá ṣojú fún wọn, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Wàyí o, Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Aísáyà 64:8) Ọ̀rọ̀ yìí tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé Jèhófà ló ni àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Baba, tàbí Olùfúnni-Ní-Ìyè. (Jóòbù 10:9) Ó fi àwọn Júù tó ronú pìwà dà wé amọ̀ tí ó lẹ̀. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn tó bá ṣègbọràn sí ìbáwí Jèhófà lè dẹni tí a tẹ̀, tàbí tí a mọ, sí ọ̀nà tó bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. Ṣùgbọ́n, Jèhófà, tó jẹ́ Amọ̀kòkò, ní láti kọ́kọ́ dárí jì wọ́n ná kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe. Ìyẹn ni Aísáyà fi wá rọ̀ ọ́ lẹ́ẹ̀mejì pé kó rántí pé èèyàn rẹ̀ làwọn Júù jẹ́ o, ó ní: “Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí ìkannú rẹ ru dé góńgó, má sì rántí ìṣìnà wa títí láé. Jọ̀wọ́, wò ó, nísinsìnyí: ènìyàn rẹ ni gbogbo wa jẹ́.”—Aísáyà 64:9.
13. Ipò wo ni ilẹ̀ Ísírẹ́lì wà nígbà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run fi wà nígbèkùn?
13 Ohun tó bá àwọn Júù nígbà ìgbèkùn ju kìkì pé wọ́n jẹ́ ìgbèkùn ní ilẹ̀ àwọn kèfèrí lọ. Ahoro tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà jẹ́ ẹ̀gàn fún àwọn àti Ọlọ́run wọn. Aísáyà mẹ́nu kan díẹ̀ nínú àwọn nǹkan tó fa ẹ̀gàn yìí nínú àdúrà ìrònúpìwàdà tó gbà, ó ní: “Àwọn ìlú ńlá mímọ́ rẹ ti di aginjù. Síónì alára ti di kìkìdá aginjù, Jerúsálẹ́mù ti di ahoro. Ilé wa ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà, inú èyí tí àwọn baba ńlá wa ti yìn ọ́, ti di ohun sísun nínú iná; gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra wa ti di ìparundahoro.”—Aísáyà 64:10, 11.
14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ nípa ipò tí wọ́n wà báyìí? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti ẹbọ tí wọ́n ń rú níbẹ̀, kí ló ṣe pàtàkì jù?
14 Dájúdájú, Jèhófà mọ bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ ní ilẹ̀ baba ńlá àwọn Júù. Ní nǹkan bí okòó lé nírínwó [420] ọdún ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù, ni ó tí kìlọ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé bí wọn ò bá pa àwọn òfin òun mọ́, tí wọ́n sì lọ ń sin àwọn ọlọ́run mìíràn, òun yóò “ké [wọn] kúrò ní orí ilẹ̀,” tí tẹ́ńpìlì ẹlẹ́wà yẹn yóò sì “di òkìtì àwókù.” (1 Àwọn Ọba 9:6-9) Òótọ́ ni pé inú Jèhófà dùn sí ilẹ̀ tó fi fún àwọn èèyàn rẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn sí tẹ́ńpìlì tó gbayì tí wọ́n kọ́ láti fi yẹ́ ẹ sí, àti àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí i. Ṣùgbọ́n, ìdúróṣinṣin àti ìgbọràn ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ti ara lọ, ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì ju ẹbọ rírú lọ pàápàá. Ìyẹn ló fi bá a mu bí wòlíì Sámúẹ́lì ṣe sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò.”—1 Sámúẹ́lì 15:22.
15. (a) Ẹ̀bẹ̀ wo ni Aísáyà bẹ Jèhófà nínú àsọtẹ́lẹ̀, báwo ni Jèhófà sì ṣe dáhùn rẹ̀? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló fa kíkọ̀ tí Jèhófà kọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan sílẹ̀ níkẹyìn?
15 Àmọ́ ṣá, ṣé Ọlọ́run Ísírẹ́lì lè wá máa wo àjálù tó bá àwọn èèyàn rẹ̀ tó ronú pìwà dà kí àánú wọn má sì ṣe é ni? Irú ìbéèrè tí Aísáyà fi parí àdúrà rẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nìyẹn. Ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn Júù ìgbèkùn pé: “Lójú nǹkan wọ̀nyí, ìwọ yóò ha máa bá a nìṣó ní kíkó ara rẹ níjàánu, Jèhófà? Ìwọ yóò ha dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì jẹ́ kí a ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́ dé góńgó?” (Aísáyà 64:12) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jèhófà dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́, ó mú wọn padà wá sí ilẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, kí wọ́n tún lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìjọsìn mímọ́ níbẹ̀. (Jóẹ́lì 2:13) Àmọ́, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, a tún pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lẹ́ẹ̀kan sí i, Ọlọ́run sì kúkú kọ orílẹ̀-èdè tí ó bá dá májẹ̀mú sílẹ̀ pátápátá. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé àwọn èèyàn Jèhófà yà kúrò nínú àwọn òfin rẹ̀, wọ́n sì kọ Mèsáyà sílẹ̀. (Jòhánù 1:11; 3:19, 20) Bí ìyẹn sì ṣe ṣẹlẹ̀, Jèhófà fi orílẹ̀-èdè tuntun kan, orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” dípò Ísírẹ́lì yìí.—Gálátíà 6:16; 1 Pétérù 2:9.
Jèhófà, “Olùgbọ́ Àdúrà”
16. Kí ni Bíbélì kọ́ni nípa ìdáríjì Jèhófà?
16 A lè rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì. A rí i pé “ẹni rere” ni Jèhófà, àti pé ó “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, àánú àti ìdáríjì rẹ̀ nìkan la fi lè rí ìgbàlà. Kò sí àwọn iṣẹ́ rere wa kankan tó lè mú ká rí àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn gbà. Àmọ́, ó lójú àwọn ẹni tó ń rí ìdáríjì gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Kìkì àwọn tó bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n sì yí padà ló lè rí ìdáríjì gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Ìṣe 3:19.
17, 18. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí àwọn èrò wa àti bí àwọn nǹkan ṣe ń rí lára wa ní ti tòótọ́? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ní sùúrù fún àwọn aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀?
17 A sì tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí èrò wa gidigidi àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa nígbà tí a bá ń gbàdúrà sí i. Òun ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2, 3) Àpọ́sítélì Pétérù mú un dá wa lójú pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pétérù 3:12) Síwájú sí i, a tún kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a bá ń gbàdúrà ìrònúpìwàdà. (Òwe 28:13) Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé a lè máa wá hùwà àìbìkítà nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú. Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ‘má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí wọ́n sì tàsé ète rẹ̀.’—2 Kọ́ríńtì 6:1.
18 Paríparì rẹ̀ ni pé, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète tí Ọlọ́run fi ní sùúrù fún àwọn èèyàn rẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé Jèhófà ń mú sùúrù “nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Àmọ́ ṣá o, àwọn tó bá ń bá a lọ láti tẹ́ńbẹ́lú sùúrù Ọlọ́run yóò jìyà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ìyẹn la fi rí i kà pé: “[Jèhófà] yóò sì san án fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀: ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí ń wá ògo àti ọlá àti àìlèdíbàjẹ́ nípasẹ̀ ìfaradà nínú iṣẹ́ rere; bí ó ti wù kí ó rí, fún àwọn tí wọ́n jẹ́ alásọ̀, tí wọ́n sì ń ṣàìgbọràn sí òtítọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣègbọràn sí àìṣòdodo ni ìrunú àti ìbínú yóò wà.”—Róòmù 2:6-8.
19. Àwọn ànímọ́ tí kì í yí padà wo ni Jèhófà ní?
19 Ìwà tí Ọlọ́run hù sí Ísírẹ́lì àtijọ́ nìyẹn. Àwọn ìlànà kan náà ló ṣì ń ṣàkóso àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lóde òní, nítorí Jèhófà kì í yí padà. Lóòótọ́, kò ní ṣàìfìyà jẹ ẹni tó bá tọ́ sí, ṣùgbọ́n nígbà gbogbo, òun ni “Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.”—Ẹ́kísódù 34:6, 7.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 362]
Àdúrà Ìrònúpìwàdà Tí Dáníẹ́lì Gbà
Bábílónì ni wòlíì Dáníẹ́lì wà ní gbogbo àádọ́rin ọdún tí àwọn Júù fi wà nígbèkùn. Lásìkò kan nínú ọdún kejìdínláàádọ́rin ìgbà ìgbèkùn wọn, Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà pé ìgbà àtìpó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. (Jeremáyà 25:11; 29:10; Dáníẹ́lì 9:1, 2) Ni Dáníẹ́lì bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó gbàdúrà ìrònúpìwàdà nítorí orílẹ̀-èdè Júù lápapọ̀. Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo sì ń bá a lọ láti kọjú mi sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, láti lè wá a pẹ̀lú àdúrà àti pẹ̀lú ìpàrọwà, pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́.”—Dáníẹ́lì 9:3, 4.
Nǹkan bí igba ọdún lẹ́yìn tí Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ àdúrà rẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, èyí tó wà nínú Aísáyà orí kẹtàlélọ́gọ́ta àti ìkẹrìnlélọ́gọ́ta, ni Dáníẹ́lì gba àdúrà tirẹ̀. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù olódodo ló gbàdúrà sí Jèhófà ní àwọn ọdún ìgbèkùn tó le koko yẹn. Àmọ́, àdúrà Dáníẹ́lì ni Bíbélì gbé jáde, èyí tó dájú pé ó jẹ́ bí nǹkan ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn Júù olóòótọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àdúrà Dáníẹ́lì fi hàn pé àwọn ohun tí Aísáyà sọ nínú àdúrà rẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ jẹ́ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn Júù olóòótọ́ tó wà nígbèkùn ní Bábílónì.
Ṣàkíyèsí àwọn ohun tó jọra nínú àdúrà Dáníẹ́lì àti ti Aísáyà.
Aísáyà 64:10, 11 Dáníẹ́lì 9:16-18
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 366]
‘Ojú Kò Tíì Rí I’
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Aísáyà nígbà tó kọ̀wé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò tíì rò nínú ọkàn-àyà ènìyàn àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’” (1 Kọ́ríńtì 2:9)a Àti ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù o, àti àlàyé Aísáyà o, kò sí èyí tó sọ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Àwọn ìbùkún tó ti ń tẹ àwọn Kristẹni lọ́wọ́ ní ọ̀rúndún kìíní lọ́hùn-ún ni Pọ́ọ̀lù ń fi ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣàlàyé, ìyẹn àwọn ìbùkún bíi lílóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run àti gbígba ìlàlóye tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.
Ìgbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà láti ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa tẹ̀mí payá nìkan ni a tó lè lóye wọn, a sì ní láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó sún mọ́ Jèhófà dáadáa kí òye yẹn tó tiẹ̀ yé wa pàápàá. Ọ̀rọ̀ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Ojú wọn kò lè rí àwọn òtítọ́ nípa tẹ̀mí, kò sì lè mọ̀ wọ́n, etí wọn kò lè gbọ́ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, kò sì lè yé e. Ìmọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ kò tiẹ̀ wọnú ọkàn irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run bíi ti Pọ́ọ̀lù, ni Ọlọ́run máa ń tipa ẹ̀mí rẹ̀ ṣí àwọn nǹkan wọ̀nyí payá fún.—1 Kọ́ríńtì 2:1-16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe fa ọ̀rọ̀ yìí yọ gẹ́lẹ́ ló ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù o. Ó jọ pé ńṣe ló pa èrò tó wà nínú Aísáyà 52:15; 64:4 àti Aís 65:17 pọ̀ mọ́ra.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 367]
“Ìgbà díẹ̀” ni Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ fi jẹ́ ti àwọn èèyàn Ọlọ́run