Ori 21
A Mú Ọgbà Edeni Padàbọ̀sípò—Yíká-Ayé
1. (a) Ní ero itumọ wo ni a o gbà fi mu ọgbà Edeni padabọsipo, eeṣe ti ko fi ní nasẹ de kiki agbegbe kereje kan lori ilẹ̀-ayé? (b) Ki ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu si oluṣe buburu naa fihan?
ỌGBÀ Edeni jẹ́ “paradise igbadun kan,” ati ní ero itumọ yẹn yoo di eyi ti a mupadabọsipo. (Genesisi 2:8, Douay Version) Paradise ipilẹṣẹ naa kari agbegbe ilẹ kereje kan lori ilẹ̀-ayé. Ṣugbọn Jehofa pete pe awọn aala rẹ̀ ni idile eniyan ti ń pọ̀ sii yoo maa mu gbooro siwaju sii, kaakiri, titi Paradise yoo fi kari gbogbo ilẹ̀-ayé ti yoo si fi ẹwà adanida kíkọyọyọ bò ó bi aṣọ. (Genesisi 1:26-28; 2:8, 9, 15) Awọn ọ̀rọ̀ Jesu si oluṣe buburu abanikẹdun naa ti ó ku lẹgbẹẹ rẹ̀ ní Kalfari mu un da ọkunrin naa loju pe a o ji i dide nigba ti imupadabọsipo Paradise ba ti lọ jìnnà, ti oun yoo si ṣakiyesi iyipada amunilọkanyọ ninu irisi ori ilẹ̀-ayé nigba naa. (Luku 23:43) Ki ni Paradise naa ti a mupadabọsipo kárí-ayé yoo farajọ? Bawo ni yoo ṣe yatọ si ọgbà Edeni ipilẹṣẹ naa?
2. (a) Ki ni ohun ti ó wà ninu ọgbà Edeni ipilẹṣẹ ti yoo di àwátì ninu Paradise kárí-ayé naa? (b) Eeṣe ti ó fi bọgbọnmu pe Ọlọrun ki yoo dan igbọran iran eniyan wo nipasẹ igi kanṣoṣo?
2 Ninu awọn asọtẹlẹ yiyanilẹnu amuni-ninudun nipa awọn ohun ologo ti ó wà niwaju laipẹ, awa ri ohun kan ti ó di àwátì ninu Paradise kárí-ayé ti a mupadabọsipo naa. Ki ni iyẹn? Oun ni “igi imọ rere ati buburu” eyi ti ó wà “laaarin ọgbà.” (Genesisi 2:17; 3:3) Dajudaju eyi jẹ igi kanṣoṣo. Yoo ha bọgbọnmu lati ronu pe laaarin ọgbà Edeni ti a mupadabọsipo kárí-ayé naa, iru igi kanṣoṣo bẹẹ nilati wà lori eyi ti a o gbé ikalọwọko atọrunwa lé bi? Bẹẹkọ. Yoo beere fun ririn irin-ajo gbọọrọgbọọrọ kan ki awọn eniyan ti wọn wà ni awọn ipẹkun ilẹ̀-ayé to lè lọ si ọgangan ibi ti igi bẹẹ wà ni Aarin Gbungbun Ila-Oorun Ayé boya lati baa lè jẹ ninu eso naa ní ṣiṣaigbọran si Ọlọrun Ọga Ogo.
3. Ki ni ohun miiran ti yoo tun di àwátì ninu Paradise ti a mupadabọsipo naa?
3 Siwaju sii, ki yoo si ejo kan ti “ń sọrọ” ní iru ọgangan ibẹ̀ lati kesi awọn ti wọn ba rin sunmọ igi naa lati jẹ ninu eso fifanimọra rẹ̀ lati inu idagunla si awọn aṣẹ Ọlọrun. Bakan naa ni ki yoo si ẹmi airi buburu eyikeyii lati dọgbọn dari ejo kan ki o si mu ki o farahan bi eyi ti ń sọrọ ki o si kesi ẹni ti ń wo eso naa lati ṣọtẹ si Ọlọrun nipa titọ ipa ọna aigbọran kan si Ẹlẹ́dàá naa, pẹlu awọn abajade aṣekupani.
4. Eeṣe ti Satani Eṣu kò fi ní si larọọwọto laaarin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa?
4 Bẹẹkọ, ẹ̀dá ẹmi airi naa ti ó wà lẹhin ejo ti “ń sọrọ” naa lẹhin lọhun-un ninu ọgbà Edeni ki yoo si larọọwọto laaarin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa, Kristi Jesu. Ẹni buburu yẹn, Satani Eṣu, ni a o fi sabẹ ikalọwọko patapata lẹhin Armageddoni. Ìfihàn 20:2, 3 sọ fun wa pe “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa yoo gbá “ejo atijọ nì, tii ṣe Eṣu, ati Satani” mú, yoo si dè é yoo si gbe e jù sinu ọgbun ainisalẹ fun ẹgbẹrun ọdun.
Alaafia ati Àìléwu Tootọ Ninu Paradise Ti A Mu Padabọsipo Naa
5. Ninu Paradise ti a mupadabọsipo naa, eeṣe ti alaafia ati àìléwu tootọ yoo fi gbalẹ̀ kárí-ayé?
5 Ẹ wo iru alaafia ati àìléwu ti yoo tẹ̀lé e! Agbara ati ijẹgaba Satani lori iran eniyan gẹgẹ bi “aládé ayé yii” yoo ti poora! (Johannu 14:30) Pẹlu ẹgbaagbeje awọn ẹmi buburu Satani ti a gbe ju sinu ọgbun, ilẹ̀-ayé nigbẹhin-gbẹhin yoo dominira kuro lọwọ oniruuru ibẹmiilo, iṣẹ awo, ati fifi agbara ẹmi eṣu ṣebi—bẹẹni, gbogbo apa eyikeyii ti biba ẹmi eṣu lò, eyi ti Jehofa koriira.—Deuteronomi 18:10-12.
6, 7. (a) Eeṣe ti ẹ̀dá ẹranko ki yoo fi jẹ́ idayafoni eyikeyii fun awọn eniyan? (b) Asọtẹlẹ wo niti eyi ni yoo ní imuṣẹ ní gidi?
6 Ẹ̀dá ẹranko ki yoo ṣe ipalara tabi jẹ́ idayafoni eyikeyii fun awọn olugbe inu Paradise ti a mupadabọsipo naa. Ọlọrun yoo dá ìwọ̀n ibẹru eniyan eyikeyii ti wọn ti lè padanu rẹ̀ pada fun awọn ẹ̀dá rirẹlẹ naa. Nipa bayii a lè fojusọna fun iru apejuwe ayé fifanimọra ti awọn ẹranko ti a tò lẹsẹẹsẹ ninu Isaiah 11:6-9 lati ní imuṣẹ niti gidi laaarin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa pe:
7 “Ikooko pẹlu yoo maa ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kinniun yoo si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ maluu ati ọmọ kinniun ati ẹgbọrọ ẹran abọpa yoo maa gbe pọ̀; ọmọ kekere yoo si maa da wọn. Maluu ati beari yoo si maa jẹ pọ̀; ọmọ wọn yoo dubulẹ pọ̀; kinniun yoo si jẹ koriko bii maluu. Ọmọ ẹnu-ọmu yoo si ṣere ní iho paramọlẹ, ati ọmọ ti a ja lẹnu ọmu yoo si fi ọwọ́ rẹ̀ si iho gunte. Wọn ki yoo panilara, bẹẹ ni wọn ki yoo panirun ní gbogbo oke mímọ́ mi: nitori ayé yoo kun fun imọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo okun.”
8. Ki ni ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ naa pe “erupẹ ni yoo jẹ́ ounjẹ ejo” tumọsi?
8 Yoo jẹ́ aiṣedeedee fun Ọlọrun lati misi iru asọtẹlẹ bẹẹ lati ní kiki itumọ tẹmi nikan ki o ma si ṣe afihan iru awọn ohun bẹẹ niti gidi ninu igbesi-aye lori ilẹ̀-ayé. Lọna kan naa, Isaiah 65:25 sọ fun wa pe: “Ikooko ati ọdọ-agutan yoo jumọ jẹ pọ̀, kinniun yoo si jẹ koriko bi akọ maluu: erupẹ ni yoo jẹ́ ounjẹ ejo.” Eyi ha tumọsi pipa idile ejo rẹ́ raurau kuro ninu ọgbà Edeni kárí-ayé bi? Bẹẹkọ, ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ naa pe “erupẹ ni yoo jẹ́ ounjẹ ejo” tumọsi pe awọn mẹmba ti ẹ̀yà ẹranko afàyàfà ki yoo jẹ́ ihalẹmọni fun iwalaaye ati ilera didara awọn ẹ̀dá eniyan mọ́ lae. Wọn yoo nilati mọ̀ daju pe iran eniyan ni ọga wọn ti ó ní agbara iṣakoso lori ohun gbogbo ti ń rako lori ilẹ, gan-an gẹgẹ bi ọran naa ti ri pẹlu Adamu ninu ọgbà Edeni nigba ti ó sọ gbogbo awọn ẹranko lorukọ laisi ifoya.—Genesisi 2:19, 20; Hosea 2:18.
9, 10. Ki ni Orin Dafidi 65 ati Isaiah 25:6 sọtẹlẹ nipa ilẹ̀-ayé labẹ iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia”?
9 Ẹwà ati ọpọ yanturu ọgbà Edeni ti yoo kárí-ayé yẹn rekọja ohun ti awa lè finuwoye. Ṣugbọn Bibeli fun wa ni apejuwe alasọtẹlẹ kan nipa rẹ̀ ninu Orin ikarundin-laadọrin, ti a dari rẹ̀ si Ọlọrun. Lapakan, orin yii sọ pe: “Iwọ bẹ ayé wò, o si bomirin in: iwọ mu un ní ọrọ̀, odo Ọlọrun kun fun omi: iwọ pese ọka wọn, nigba ti iwọ ti pese ilẹ bẹẹ.” Ki yoo si ọ̀dá nigba naa, ṣugbọn, kaka bẹẹ, “ọ̀wọ́ òjò”! (Orin Dafidi 65:1, 9-13) Ọpọ yanturu ounjẹ ni yoo wà fun gbogbo olugbe ilẹ̀-ayé.
10 Ọpọ yanturu yii ni a tun sọ asọtẹlẹ rẹ̀ ní Isaiah 25:6 pe: “Ati ní oke nla yii ni Oluwa awọn ọmọ ogun yoo se ase ohun abọpa fun gbogbo orilẹ-ede, ase ọti waini lori gẹdẹgẹdẹ, ti ohun abọpa ti ó kun fun ọ̀rá, ti ọti waini ti ó tòrò lori gẹdẹgẹdẹ.” Awọn olugbe inu Paradise ti a mupadabọsipo naa yoo jẹ ounjẹ ti ó kun fun ọ̀rá daradara ti yoo gbé ọkan-aya ró ti yoo si mu oju dan. Wọn yoo mu ọti waini, ti ó ti gbó daradara lori gẹdẹgẹdẹ, ti ó si tòrò ti ń mu ọkan-aya wọn yọ̀. (Orin Dafidi 104:14, 15) Ki yoo si ọ̀wọ́n ounjẹ labẹ Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa! Kaka bẹẹ, “akunwọsilẹ” ni yoo wà.—Orin Dafidi 72:16, NW.
Awọn Iyipada Ninu Èdè ati Ninu Oju-Ọjọ
11. Iyipada wo ninu èdè ni yoo ṣẹlẹ, bawo ni eyi yoo si ṣe nipa lori iran eniyan?
11 Njẹ Paradise kárí-ayé naa yoo ha jiya lọwọ idarudapọ nini ọpọlọpọ èdè bi? Bẹẹkọ, nitori “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ni a tun tọkasi bi “Ọlọrun Alagbara.” (Isaiah 9:6) Nipa bayii yoo ṣeeṣe fun un lati yí idarudapọ èdè ti ó bẹrẹ ní Ile-Iṣọ Babeli pada. (Genesisi 11:6-9) Ki ni yoo wa di èdè gbogbogboo fun gbogbo awọn ọmọ ilẹ̀-ayé ti “Baba Ayeraye” naa? Yoo ha jẹ́ èdè ipilẹṣẹ ti Adamu akọkọ, èdè naa ti Jehofa fi jinki rẹ̀ bi? O ṣeeṣe. Bi o ti wu ki o ṣẹlẹ, gbogbo idena èdè ni a o mu kuro. Yoo si ṣeeṣe fun ọ lati rin irin-ajo lọ si ibikibi ki o si bá awọn eniyan sọrọ nibẹ. Iwọ yoo lè loye wọn, wọn yoo si lè loye rẹ. Èdè kanṣoṣo ni yoo wà fun gbogbo iran eniyan, yoo si baamu pe ki odindi Bibeli wà larọọwọto ní èdè kanṣoṣo yẹn. (Fiwe Sefaniah 3:9.) Ní èdè yẹn gbogbo ayé yoo kun fun imọ Jehofa “gẹgẹ bi omi ti bo okun.”—Isaiah 11:9.
12. Bawo ni Sekariah 14:9 yoo ṣe ní imuṣẹ?
12 A o ti mú awọn ọ̀rọ̀ Sekariah 14:9 ṣẹ ti ó wi pe: “Ní ọjọ naa ni [Jehofa, NW] kan yoo wà, orukọ rẹ̀ yoo si jẹ́ ọkan.” Kiki Jehofa ni a o maa jọsin bii Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa. Ní “ọjọ” Ijọba Jehofa nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa, Ọlọrun yoo ṣí bi a ṣe ń pe orukọ rẹ̀ gan-an paya. Nigba naa kiki ọna kanṣoṣo ni yoo wà fun gbogbo eniyan lori ilẹ̀-ayé lati gba pe orukọ mímọ́ yẹn. Orukọ rẹ̀ yoo jẹ́ ọkan.
13. Eeṣe ti oju-ọjọ, awọn ẹfuufu, ati ìgbì kò fi ní jẹ́ ihalẹmọni fun awọn olugbe ilẹ̀-ayé?
13 Iru iyipada oju-ọjọ ati ti ayika ti yoo wà tun jẹ́ ọran tí awọn wọnni tí wọn ń fojusọna si Paradise kárí-ayé ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa lọkan-ifẹ mimuna si. Ohun kan daju: A o sọ gbogbo ilẹ̀-ayé di ibi ẹlẹ́wà kan lati gbé. Paradise naa ni awọn ìjì, àfẹ́yíká-ìjì, ìgbì, ìjì-líle, tabi ìjì-ńlá ti ń pa nǹkan run ki yoo yọlẹnu lae. Ẹfuufu, igbi, ati oju-ọjọ yoo ṣegbọran si “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa. (Marku 4:37-41) Ọgbà Edeni yíká-ayé naa yoo ní oju-ọjọ ti a ṣakoso rẹ̀ lẹkun-unrẹrẹ. Gbogbo ilẹ̀-ayé ni a o sọ di paradise ẹlẹ́wà ti igbadun, nibi ti yoo ti jẹ́ anfaani alayọ gbogbo iran eniyan lati gbé ní àìléwu titi ayé ailopin.
14, 15. (a) Ileri wo ti a kọsilẹ ninu Ìfihàn 21:3, 4 ni yoo ni imuṣẹ? (b) Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe pàgọ́ saaarin iran eniyan? (c) Iru omije wo ni a o nù kuro titilae?
14 Ki yoo si idi kankan fun ẹkun ti irora nigba naa! Ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Jehofa mu un da wa loju pe: “Agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ́ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ní oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Ìfihàn 21:3, 4.
15 Awọn ọ̀run ni itẹ Ọlọrun, ilẹ̀-ayé si ni apoti itisẹ rẹ̀. (Isaiah 66:1) Iyẹn ni pe Ọlọrun kò lè gbé ori ilẹ̀-ayé niti gidi. Ṣugbọn oun yoo pàgọ́ pẹlu iran eniyan. Laaarin Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun naa, Jehofa yoo pagọ saaarin iran eniyan lọna iṣojufunni nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀ ti a ti ṣe logo, Jesu Kristi. Ẹ wo bi ó ti baamu to pe wiwanibẹ Jehofa ni a o ṣoju fun nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” rẹ̀! Eyi mú ọ̀rọ̀ inu Isaiah 7:14 nipa orukọ ti a o lò fun Messia naa wá si ọkàn—Immanueli. Orukọ yẹn tumọsi “Ọlọrun Wà Pẹlu Wa.” (Matteu 1:23) Ẹ wo bi eyi ti munilọkanyọ to pe nipasẹ Ọmọkunrin ọ̀wọ́n julọ, Ọlọrun yoo “gbé” pẹlu iran eniyan! Nigba naa o ṣeeṣe ki omije ayọ̀ maa ṣan silẹ lati oju wa nigba ti a ba ri awọn iṣẹ iyanu meriyiiri tí “Ọlọrun Alagbara” yii yoo ṣe, ní pataki nigba ti a ba mu awọn ololufẹ wa ti o ti kú padabọ si iye ninu ajinde sinu ipo Paradise. (Iṣe 24:15) Iru awọn iṣẹ iyanu bẹẹ yoo jẹ́ awọn ẹri agbayanu pe Ọlọrun wà pẹlu iran eniyan ati pe oun ń nu gbogbo omije ikẹdun nù kuro loju wa laelae.
Ọgangan Ẹwà Ninu Agbaye Salalu
16. A ha nilati dá ajinde awọn oku duro titi di igba ti a bá nasẹ̀ Paradise kaakiri gbogbo ayé bi? Ṣalaye.
16 A sọ fun Adamu akọkọ nipa bi yoo ṣe bẹrẹ iṣẹ idawọle ti mimu Paradise naa gbooro lati inu ọgbà Edeni gan-an. Ṣiṣe aṣepari ète ipilẹṣẹ yẹn lati mu un gbooro kárí-ayé ni a o muṣẹ. Ṣugbọn njẹ ajinde awọn oku yoo ha nilati duro titi a o fi nasẹ Paradise kaakiri gbogbo ayé bi? Rara. Fun apẹẹrẹ, awọn ti wọn padabọ ninu ajinde iṣaaju ni a o ji dide si awọn apa ilẹ̀-ayé nibi ti awọn olula Armageddoni já wà ti wọn si ti sọ iru agbegbe bẹẹ di paradise kan. Bi ajinde iran eniyan ní gbogbogboo ti ń tẹsiwaju, awọn agbegbe Paradise wọnyi yoo maa fẹ̀ sii titi wọn yoo fi já pọ̀ lati di Paradise kárí-ayé kan.
17. Iru apejuwe wo ni a fi funni nipa Paradise kárí-ayé?
17 Paradise ti ń bọ naa yoo tayọ rekọja gbogbo ọgbà tabi ọgbà iṣere ẹlẹ́wà toni. Pẹlu itanṣan, gbogbo ayé yoo tanna bii paradise alalaafia kan, ọkan ti ó fa kii ṣe kiki oju awọn eniyan mọra ṣugbọn oju Ẹlẹ́dàá naa paapaa. Yoo jẹ́ ọgbà Edeni kárí-ayé kan ti a fi eweko ati awọn igi ṣe lọṣọọ—ti wọn dara ní wiwo ti wọn si tun ń pese awọn ounjẹ ti ń gbe iwalaaye awọn ẹda ró ninu ijẹpipe. Ilẹ̀-ayé yoo maa wà titilae bi ibi ọgangan ẹwà ninu gbogbo agbaye salalu ti Jehofa. Pẹlupẹlu gbogbo iran eniyan ti a sopọṣọkan yoo ní iṣẹ aigbọdọmaṣe ati anfaani ayeraye ti pipa ilẹ̀-ayé mọ́ ni jijẹ iru ibi ọgangan ẹlẹ́wà kan bẹẹ.
18. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe gbogbo eniyan, tọkunrin tobinrin, yoo jumọ gbé papọ̀ ní alaafia bi arakunrin ati arabinrin?
18 Gbogbo awọn mẹmba idile eniyan oniwa-bi-Ọlọrun yii yoo jùmọ̀ gbé papọ ní alaafia bi awọn arakunrin ati arabinrin ninu gbogbo ijẹmimọ, nitori wọn yoo jẹ́ awọn ọmọ “Baba Ayeraye,” “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa niti tootọ. Nitori naa ki yoo si ìjẹgàba onigberaga niha ọdọ awọn ọkunrin lori awọn obinrin, awọn arabinrin wọn. Ṣugbọn awọn obinrin ti a ti sọ di pipe naa yoo jẹ́ ohun ti Jehofa Ọlọrun ti pete rẹ̀, gan-an gẹgẹ bi a ti pete Efa lati jẹ́ “oluranlọwọ” fun ọkọ rẹ̀ pipe, Adamu.—Genesisi 2:18; tun wo 1 Peteru 3:7.
19. Paradise ilẹ̀-ayé yoo pese iran wo fun awọn wọnni ti wọn ń gbe ninu awọn ọ̀run ti a kò lè fojuri?
19 Iran tí paradise ilẹ̀-ayé ti ó kun fun awọn ọkunrin ati obinrin pipe naa yoo pese fun awọn wọnni tí wọn wà ninu awọn ọ̀run ti a ko le fojuri yoo tobilọla yoo si wuni ju irisi ilẹ̀-ayé nigba ti a kọkọ dá a lọ, ní akoko eyi ti “awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ń ho iho ayọ̀.” (Jobu 38:7) Nigba naa Ọlọrun Ọga Ogo naa, Jehofa, ni a o ti dalare lẹkun-unrẹrẹ bi Ẹni naa ti a kò lè mu ète ologo rẹ̀ kùnà lae. Gbogbo iyin yẹ fun un!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 172, 173]
Paradise niti gidi kan yoo ṣe gbogbo ilẹ̀-ayé, “apoti itisẹ” Ọlọrun, lọ́ṣọ̀ọ́