ORÍ 22
Ìjọba Náà Mú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ ní Ayé
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa nígbà míì láti rántí pé ìgbà ń bọ̀ tí a máa wà nínú Párádísè? (b) Kí ló máa mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run túbọ̀ lágbára?
ARÁKÙNRIN olóòótọ́ kan tó ti rẹ̀ wá sípàdé lẹ́yìn kòókòó jàn-ánjàn-án ọjọ́ náà. Ọ̀gá rẹ̀ tó lè fiṣẹ́ páni lórí ti fojú rẹ̀ rí màbo, àníyàn bó ṣe máa bójú tó ìdílé rẹ̀ mu ún lómi, ìrònú àìsàn tó ń ṣe aya rẹ̀ sì kà á láyà. Ṣùgbọ́n bí orin tí wọ́n fẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ṣe ń dún, ara tù ú ó sì mí kanlẹ̀, torí inú rẹ̀ dùn pé òun wà nípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú àwọn ará. Orin náà dá lórí ìrètí wíwà nínú Párádísè, ọ̀rọ̀ orin náà sì ní kó fojú inú wo bí ìgbà yẹn ṣe máa rí, pé kó wò ó bíi pé òun tiẹ̀ ti wà nínú Párádísè náà. Orin tó fẹ́ràn gan-an ni. Bí òun àti ìdílé rẹ̀ sì ṣe ń kọ́ ọ, ìrètí ọjọ́ iwájú náà tù ú nínú gidigidi.
2 Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí? Ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára wa rí o. Àmọ́ ká sòótọ́, bí nǹkan ṣe rí nínú ètò ògbólógbòó yìí lè jẹ́ kó ṣòro fún wa láti máa rántí pé ìgbà ń bọ̀ tí a máa wà nínú Párádísè lóòótọ́. “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà, ayé tí a sì ń gbé báyìí ò fibì kankan jọ Párádísè rárá. (2 Tím. 3:1) Kí ló máa wá jẹ́ kí ìrètí Párádísè tá a ní dá wa lójú? Ó dára ná, báwo la tiẹ̀ ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso gbogbo aráyé lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ tí àwọn èèyàn rẹ̀ rí pé wọ́n ṣẹ láyé ìgbàanì. Lẹ́yìn náà, a ó wá sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ ṣe ń ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí lọ́nà tó ń mórí ẹni yá gágá. Paríparí rẹ̀, nǹkan wọ̀nyí á mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, a ó sì wá wo bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yóò ṣe ṣẹ fún wa lọ́jọ́ iwájú.
Bí Jèhófà Ṣe Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Nígbà Àtijọ́
3. Ìlérí Ọlọ́run wo ló ń tu àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn Bábílónì nínú?
3 Fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí fún àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn Bábílónì nígbà yẹn, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìgbèkùn ni ọ̀pọ̀ lára wọn dàgbà sí bíi tàwọn òbí wọn, nǹkan ò sì rọrùn fún wọn rárá. Àwọn ará Bábílónì máa ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà. (Sm. 137:1-3) Ní gbogbo ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ yẹn, ìrètí kan ṣoṣo tó dájú tí àwọn Júù olóòótọ́ fi ń gbé ara wọn ró ni pé: Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò kó àwọn èèyàn òun jọ pọ̀ pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Jèhófà sọ pé ibẹ̀ máa lárinrin gan-an ni. Kódà ó tiẹ̀ fi ilẹ̀ Júdà tó máa mú pa dà bọ̀ sípò wé ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn Párádísè! (Ka Aísáyà 51:3.) Ńṣe ni Jèhófà dìídì ṣe àwọn ìlérí yìí láti lè fi àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, kó sì fi paná iyè méjì tó bá fẹ́ máa dà wọ́n lọ́kàn rú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan ní pàtó.
4. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kó dá àwọn Júù lójú pé ààbò yóò wà fún wọn ní ìlú ìbílẹ̀ wọn?
4 Ààbò. Tí àwọn tó wà nígbèkùn yẹn bá pa dà sílé, inú Párádísè kọ́ ni wọ́n máa pa dà sí, ilẹ̀ tó wà lọ́nà jíjìn réré tó sì ti wà láhoro láti àádọ́rin [70] ọdún ni, kódà díẹ̀ péré lára wọn ló tíì débẹ̀ rí. Láyé ìgbà yẹn, àwọn kìnnìún wọ́pọ̀ láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹranko aṣọdẹ bí ìkookò, àmọ̀tẹ́kùn àtàwọn ẹranko míì. Baálé ilé kan lè máa wá rò ó pé, ‘Báwo ni màá ṣe dáàbò bo aya mi àtàwọn ọmọ mi ná? Àwọn àgùntàn àti màlúù mi ńkọ́, báwo ni màá ṣe dáàbò bò wọ́n?’ Irú àníyàn bẹ́ẹ̀ máa wá síni lọ́kàn lóòótọ́. Wá ronú nípa ìlérí Ọlọ́run tó wà ní Aísáyà 11:6-9, kó o sì wo bó ṣe máa fọkàn wọn balẹ̀ tó. (Kà á.) Jèhófà lo ọ̀rọ̀ tó wúni lórí gan-an wọ̀nyẹn láti mú kó dá àwọn ìgbèkùn náà lójú pé ààbò yóò wà fún àwọn àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Kìnnìún yóò jẹ èérún pòròpórò ní ti pé kò ní pa màlúù àwọn Júù jẹ. Ọkàn àwọn olóòótọ́ yẹn á balẹ̀ pé àwọn ẹranko aṣọdẹ yìí kò ní ṣèpalára kankan fún àwọn. Jèhófà ṣèlérí pé kò ní séwu fáwọn èèyàn òun ní ilẹ̀ Júdà tí a mú pa dà bọ̀ sípò náà, àní tí wọ́n bá wà nínú aginjù àti igbó pàápàá.—Ìsík. 34:25.
5. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló fi àwọn ìgbèkùn tó ń pa dà sílé lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò lọ́pọ̀ yanturu?
5 Ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. Àwọn àníyàn míì tún lè wà. Wọ́n lè máa rò ó pé, ‘Ǹjẹ́ màá lè bọ́ ìdílé mi ní ilẹ̀ tí a mú pa dà bọ̀ sípò náà? Ibo la ó máa gbé? Ṣé iṣẹ́ á wà láti ṣe, ṣé ó sì máa sàn ju gbogbo làálàá tí à ń ṣe nígbèkùn lábẹ́ àṣẹ àwọn tó kó wa lẹ́rú?’ Jèhófà fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò lo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó mí sí láti fi dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Jèhófà ṣèlérí pé àwọn èèyàn òun tó jẹ́ onígbọràn yóò rí i pé òjò á máa rọ̀ bó ṣe yẹ; èyí táá jẹ́ kí ilẹ̀ mú oúnjẹ “sísanra àti olóròóró,” ìyẹn ọ̀pọ̀ yanturu èso, jáde wá. (Aísá. 30:23) Ní ti ọ̀rọ̀ ibùgbé àti iṣẹ́ tí ń tẹ́ni lọ́rùn, Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.” (Aísá. 65:21, 22) Àní sẹ́, ìgbé ayé wọn á lárinrin lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ìyàtọ̀ sí bó ṣe rí nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn àwọn ará Bábílónì abọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n o, olórí ìṣòro wọn wá ńkọ́, èyí tó jẹ́ pé ìyẹn gan-an ló sọ wọ́n dèrò ìgbèkùn?
6. Àìsàn wo ló ti ń ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́? Kí ni Jèhófà mú kó dá àwọn ìgbèkùn tó ń pa dà sílé lójú?
6 Àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó lọ sígbèkùn ni wọ́n ti ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Ohun tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ nípa àwọn èèyàn rẹ̀ ni pé: “Gbogbo orí wà ní ipò àìsàn, gbogbo ọkàn-àyà sì jẹ́ ahẹrẹpẹ.” (Aísá. 1:5) Wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití nípa tẹ̀mí torí pé wọ́n ń di etí wọn sí ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wọn, wọ́n sì ń di ojú wọn sí ìlàlóye tó ń fún wọn. (Aísá. 6:10; Jer. 5:21; Ìsík. 12:2) Tí àwọn tó pa dà sílé láti ìgbèkùn bá tún lọ ní ìṣòro yìí, báwo ni wọ́n ṣe máa wá rí ààbò? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n á kàn tún pàdánù ojúure Jèhófà? Ẹ wo irú ìtùnú tí wọ́n máa rí gbà látinú ìlérí Jèhófà yìí, pé: “Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé náà dájúdájú, ojú àwọn afọ́jú pàápàá yóò sì ríran nínú ìṣúdùdù àti nínú òkùnkùn.” (Aísá. 29:18) Àní sẹ́, Jèhófà yóò wo àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ti gba ìbáwí, tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà, sàn nípa tẹ̀mí. Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti ń kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn, Jèhófà yóò fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tí yóò yọrí sí ìyè àti ìlàlóye fún wọn.
7. Báwo ni àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn ṣe ṣẹ? Kí nìdí tó fi yẹ kí ìmúṣẹ àwọn ìlérí yẹn fún ìgbàgbọ́ wa lágbára?
7 Ǹjẹ́ Jèhófà mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Ohun tí ìtàn sọ fi hàn pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó bù kún àwọn Júù tó pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn, ààbò wà fún wọn, wọ́n ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan àti àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tí wọ́n lágbára jù wọ́n lọ, tí wọ́n sì tún pọ̀ jù wọ́n lọ dáadáa. Àwọn ẹranko aṣọdẹ kò pa ẹran ọ̀sìn àwọn Júù run. Lóòótọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ ló ṣẹ sí àwọn Júù yẹn lára nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Párádísè tí àwọn wòlíì bí Aísáyà, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì kọ sílẹ̀, àmọ́ èyí tó ṣẹ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run yẹn lára mórí wọn yá gágá, ó sì jẹ́ ohun tí wọ́n nílò gẹ́lẹ́ nígbà yẹn. Bí a ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì, ìgbàgbọ́ wa yóò túbọ̀ máa lágbára. Tí ìwọ̀nba ìmúṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ní bá sì mórí ẹni yá gágá, báwo wá ni ìmúṣẹ tó tóbi jù yóò ṣe rí ná? Ìwọ wo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wa lóde òní.
Bí Jèhófà Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Nígbà Tiwa
8. Irú “ilẹ̀” wo ni àwa èèyàn Ọlọ́run wà lóde òní?
8 Ní báyìí, àwa èèyàn Jèhófà tòde òní kò di orílẹ̀-èdè ayé kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni gbogbo wa ń gbé pa pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí kan, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) “Àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn sì wà pẹ̀lú wọn nínú “ilẹ̀” tẹ̀mí kan, ìyẹn ètò Jèhófà tó dà bí orílẹ̀-èdè kan, níbi tí wọ́n ti jọ ń sìn Jèhófà Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan. Ìjọsìn yẹn gan-an ló ń darí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn. (Jòh 10:16; Aísá. 66:8) Irú “ilẹ̀” wo wá ni Jèhófà fún wa yìí? Párádísè tẹ̀mí ni o. Àwọn ìlérí Ọlọ́run pé nǹkan máa rí bíi ti Édẹ́nì ti ń ní ìmúṣẹ àgbàyanu nípa tẹ̀mí nínú Párádísè tẹ̀mí yìí. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
9, 10. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 11:6-9 ṣe ń ṣẹ lónìí? (b) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé àlàáfíà wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run?
9 Ààbò. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 11:6-9, a rí àpẹẹrẹ kan tó dùn mọ́ni gan-an pé ìṣọ̀kan àti àlàáfíà yóò wà, ìyẹn láàárín gbogbo àwọn ẹranko ẹhànnà, yóò sì tún wà láàárín àwọn èèyàn àtàwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn. Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ní ìmúṣẹ nínú Párádísè tẹ̀mí tí a wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ní ẹsẹ 9, a rí ìdí tí irú àwọn ẹranko yìí ò fi ní ṣe ìpalára tàbí fa ìparun, ó ní: “Nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Ṣé “ìmọ̀ Jèhófà” máa ń yí ìwà àwọn ẹranko pa dà ni? Rárá o, àwọn èèyàn ló máa ń yíwà pa dà tí wọ́n bá dẹni tó mọ Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo tí wọ́n sì ń kọ́ béèyàn ṣe ń tẹ̀ lé ọ̀nà àlàáfíà Ọlọ́run. Abájọ tí a fi ń rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ lọ́nà tó dùn mọ́ni gan-an nínú Párádísè tẹ̀mí tá a wà lóde òní. Lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ń kọ́ béèyàn ṣe ń jáwọ́ nínú àwọn ìwà òǹrorò àti ìwà bí ẹranko, wọ́n wá ń dèèyàn àlàáfíà tó ń wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará nínú ètò Ọlọ́run.
10 Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé yìí a ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwa Kristẹni kì í ṣeé dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti ogun. A sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ àti inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí àwa èèyàn Ọlọ́run torí pé a kò dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti ogun. Ǹjẹ́ kò wúni lórí pé nínú ayé oníwà ipá yìí, àwùjọ èèyàn tó dà bí “orílẹ̀-èdè” ńlá kan wà tó ń kọ̀ láti kópa nínú ìwà ipá èyíkéyìí, kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ fẹ́ torí ìyẹn pa wọ́n? Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó wúni lórí gan-an nìyẹn jẹ́ pé àwọn ọmọ abẹ́ Mèsáyà Ọba ti ń gbádùn irú àlàáfíà tí Aísáyà sọ yẹn gan-an lóòótọ́! Jésù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bá ní láàárín ara wọn ni àwọn èèyàn á fi mọ̀ wọ́n. (Jòh 13:34, 35) Nínú ìjọ, Kristi ń fi sùúrù lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” rẹ̀ láti kọ́ gbogbo Kristẹni tòótọ́ pátá kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ẹni tó ń nífẹ̀ẹ́ àti oníwà pẹ̀lẹ́.—Mát. 24:45-47.
11, 12. Ìyàn wo ló ń han aráyé léèmọ̀ lónìí? Báwo ni Jèhófà ṣe ti ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan fáwọn èèyàn rẹ̀?
11 Ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. Ìyàn nípa tẹ̀mí ń han aráyé léèmọ̀. Bíbélì sọ èyí tẹ́lẹ̀, ó ní: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’” (Ámósì 8:11) Ǹjẹ́ ìyàn ń han àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà léèmọ̀? Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ àtàwọn ọ̀tá rẹ̀, ó ní: “Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin.” (Aísá. 65:13) Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ yìí ń ṣẹ?
12 À ń gba ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ìpèsè tẹ̀mí bí ìgbà tí omi odò tó túbọ̀ ń fẹ̀ tó sì ń jìn ń ṣàn wá sọ́dọ̀ wa. Àwọn ìtẹ̀jáde wa tó dá lórí Bíbélì, títí kan àwọn ohùn àtẹ́tísí àti fídíò, àwọn ìpàdé àti àpéjọ àgbègbè wa àtàwọn ohun tí à ń gbé jáde lórí Ìkànnì wa, para pọ̀ jẹ́ ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè tẹ̀mí tó ń rọ́ wá gbùúgbùú bí ibú omi tó ń ṣàn, nínú ayé tí ìyàn tẹ̀mí ti ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ yìí. (Ìsík. 47:1-12; Jóẹ́lì 3:18) Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn gan-an bó o ṣe ń rí i tí àwọn ìlérí Jèhófà pé òun máa pèsè ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan ṣe ń ṣẹ sí ọ lára lójoojúmọ́ ayé? Ǹjẹ́ ò ń rí i dájú pé ò ń jẹun déédéé lórí tábìlì Jèhófà?
13. Báwo lo ṣe ń rí ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà pé ojú àwọn afọ́jú ń ríran, etí àwọn adití sì ń gbọ́rọ̀?
13 Àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù nínú aráyé ló jẹ́ afọ́jú àti adití nípa tẹ̀mí. (2 Kọ́r. 4:4) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Kristi ń ṣèwòsàn àwọn àìlera àti àìsàn kárí ayé. Ǹjẹ́ o ti ń rí i pé ojú àwọn afọ́jú ń ríran, etí àwọn adití sì ń gbọ́rọ̀? Tó o bá ti rí àwọn èèyàn tó ń ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n ń jáwọ́ nínú àwọn irọ́ tí ìsìn pa èyí tó jẹ́ kí wọ́n fọ́jú kí wọ́n sì dití sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, o ti rí bí ìlérí Ọlọ́run yìí ṣe ṣẹ nìyẹn, ó ní: “Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé náà dájúdájú, ojú àwọn afọ́jú pàápàá yóò sì ríran nínú ìṣúdùdù àti nínú òkùnkùn.” (Aísá. 29:18) Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kárí ayé ló ń rí irú ìwòsàn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ gbà. Olúkúlùkù ẹni tó bá jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá tó sì dara pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn nínú Párádísè wa nípa tẹ̀mí ló jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fójú rí pé àwọn ìlérí Jèhófà ti ṣẹ!
14. Àwọn ẹ̀rí wo ló máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára tá a bá ṣàṣàrò lé wọn lórí?
14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí ìwé yìí ló ní ẹ̀rí tó lágbára tó fi hàn pé Kristi ti kó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wọnú ojúlówó Párádísè tẹ̀mí ní àkókò òpin yìí. Ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí Ọlọ́run ti bù kún wa nínú Párádísè tẹ̀mí yẹn lóde òní. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú yóò máa lágbára sí i.
“Kí Ìjọba Rẹ Dé”
15. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ayé yóò di Párádísè?
15 Tipẹ́tipẹ́ ló ti jẹ́ ète Jèhófà pé kí gbogbo ayé di Párádísè. Ó dá Ádámù àti Éfà sínú ọgbà Párádísè, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n fi irú ọmọ wọn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì máa bójú tó gbogbo ẹ̀dá inú ayé pátá. (Jẹ́n. 1:28) Ṣùgbọ́n Ádámù àti Éfà bá Sátánì lẹ̀dí àpò pọ̀ láti ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì ri gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn sínú àìpé, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Síbẹ̀, ète Ọlọ́run ò yí pa dà. Ọ̀rọ̀ tó bá sọ máa ń ṣẹ láìkù síbì kan. (Ka Aísáyà 55:10, 11.) Torí náà, ó dá wa lójú pé àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà yóò ṣì kún ilẹ̀ ayé, wọ́n á ṣèkáwọ́ rẹ̀, wọ́n á sì máa bójú tó gbogbo ìṣẹ̀dá Jèhófà nínú ayé tó ti di Párádísè. Nígbà yẹn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn látijọ́, nípa ìgbé ayé nínú Párádísè yóò wá ṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́! Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí ná.
16. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ààbò tá a máa gbádùn nínú Párádísè?
16 Ààbò. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà 11:6-9 ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà tó dùn mọ́ni gan-an, yóò wá ṣẹ ní ti gidi àti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ààbò yóò wà fún tọkùnrin tobìnrin àtàwọn ọmọdé níbikíbi tí wọ́n bá lọ láyé. Kò ní sí ẹ̀dá kankan, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko tó máa wu wọ́n léwu rárá. Fójú inú wo ìgbà tí wàá rí i pé gbogbo ilé ayé yìí ló jẹ́ ibùgbé rẹ, níbi tí wàá ti lè lúwẹ̀ẹ́ nínú àwọn odò, nínú àwọn adágún omi àti òkun; níbi tí wàá ti máa rìn gba orí àwọn òkè kọjá, tí wàá sì lè máa rìn káàkiri nínú pápá láìséwu kankan. Ìdààmú ò ní bá ọ tí ilẹ̀ bá ṣú bá ọ níbikíbi. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 34:25 yóò ṣẹ, àní débi pé á ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láti “gbé ní ààbò ní aginjù ní ti tòótọ́, wọn yóò sì sùn nínú igbó.”
17. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò pèsè àwọn nǹkan tí a nílò lọ́pọ̀ yanturu tí Ìjọba náà bá ti ń ṣàkóso gbogbo ayé?
17 Ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. Fojú inú wo ìgbà tí kò ní sí ipò òṣì, àìjẹunrekánú, ìyàn àti onírúurú ètò afẹ́nifẹ́re mọ́ rárá. Ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn lónìí jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Mèsáyà Ọba wa yóò bọ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn lọ́nà ráńpẹ́ pé òun lè mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ, torí ó fi kìkì ìwọ̀nba ìṣù búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tí ebi ń pa. (Mát. 14:17, 18; 15:34-36; Máàkù 8:19, 20) Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo ayé pátá, irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí èyí tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ máa ṣẹ ní ti gidi, ó ní: “Òun yóò sì rọ òjò sí irúgbìn rẹ, èyí tí o fún sí ilẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí èso ilẹ̀, èyíinì ni oúnjẹ, tí yóò di sísanra àti olóròóró. Ní ọjọ́ yẹn, ohun ọ̀sìn rẹ yóò máa jẹko ní pápá ìjẹko aláyè gbígbòòrò.”—Aísá. 30:23.
18, 19. (a) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 65:20-22 bá ń ṣẹ? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé “bí ọjọ́ igi” ni ọjọ́ wa yóò rí?
18 Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ò tiẹ̀ lè ronú rẹ̀ rárá ni pé àwọn á ní ibùgbé tó dára tàbí iṣẹ́ tó lérè tó sì tẹ́ wọn lọ́rùn. Nínú ètò àwọn nǹkan tó kún fún ìwà ìbàjẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ń rí i pé ṣe làwọn kàn ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó láìfi bẹ́ẹ̀ sí àǹfààní kankan níbẹ̀ fún àwọn tàbí ìdílé àwọn, tó sì jẹ́ pé àwọn olówó oníwọra ló ń jẹ èrè gbogbo làálàá àwọn. Fojú inú wo bó ṣe máa rí nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ yìí bá ṣẹ kárí ayé, ó ní: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísá. 65:20-22.
19 Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé “bí ọjọ́ igi” ni ọjọ́ wa yóò rí? Tó o bá dúró sídìí igi ńlá ràbàtà kan, ǹjẹ́ ẹnu kì í yà ọ́ tó o bá ronú lórí bó ṣe pẹ́ tó tí igi náà ti wà níbẹ̀, bóyá ó tiẹ̀ ti wà níbẹ̀ kí ìran-ìran àwọn òbí rẹ tó dáyé pàápàá? O lè máa wá rò ó pé tó o bá ṣì wà láyé nínú ẹran ara àìpé yìí, bópẹ́ bóyá ikú á dé, tí igi yìí á máa wà nìṣó láìsí ìyọnu, nígbà tí ìwọ lè ti dẹni tí àwọn èèyàn á kàn máa rántí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹ ò rí bí inúure Jèhófà ṣe tó bó ṣe mú kó dá wa lójú pé ẹ̀mí wa yóò gùn, a ó sì wà lálàáfíà nínú Párádísè tó ń bọ̀! (Sm. 37:11, 29) Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ọjọ́ orí àwọn igi tó tiẹ̀ pẹ́ gan-an láyé pàápàá yóò kúrú bíi tàwọn koríko tó ń kọjá lọ wẹ́rẹ́ lójú wa, nígbà tí àwa yóò máa wà láàyè lọ títí láé!
20. Báwo ni àwọn adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe ní ìlera pípé?
20 Ìlera pípé. Lóde òní, ń ṣe ni àìsàn àti ikú ń han gbogbo èèyàn pátá léèmọ̀. A tiẹ̀ kúkú lè sọ pé gbogbo wa là ń ṣàìsàn, àìsàn kan tó ń yọrí sí ikú ni o. Orúkọ rẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀. Ẹbọ ìràpadà Kristi nìkan ṣoṣo ni ìwòsàn rẹ̀. (Róòmù 3:23; 6:23) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, Jésù àtàwọn tó máa bá a jọba yóò mú kí gbogbo èèyàn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà yẹn lẹ́kún-únrẹ́rẹ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn kúrò pátápátá. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí yóò wá ṣẹ ní kíkùn, ó ní: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” (Aísá. 33:24) Fojú inú wo ìgbà tí kò ní sẹ́ni tó máa jẹ́ afọ́jú, adití tàbí arọ mọ́. (Ka Aísáyà 35:5, 6.) Yálà àìsàn nípa tara ni o, ti ọpọlọ tàbí ti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni, gbogbo wọn pátá ni agbára Jésù ká, tó sì máa wò sàn. Àwọn adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò wá ní ìlera pípé!
21. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ikú? Kí nìdí tí ìlérí yìí fi ń tù ọ́ nínú?
21 Ṣùgbọ́n ohun tí àìsàn sábà máa ń yọrí sí ńkọ́, tó jẹ́ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ fà, ìyẹn ikú? Òun náà ni “ọ̀tá ìkẹyìn,” ọ̀tá kan tó jẹ́ pé ó máa ń ṣá gbogbo èèyàn aláìpé balẹ̀ bópẹ́ bóyá. (1 Kọ́r. 15:26) Ṣùgbọ́n, ṣé ikú wá ju ohun tí Jèhófà lè borí? Wo àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ, ó ní: “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Ǹjẹ́ o lè fojú inú rí bí ìgbà yẹn ṣe máa rí? Kò ní sí ètò ìsìnkú, itẹ́ òkú àti ẹkún ìbànújẹ́ mọ́ rárá! Kàkà bẹ́ẹ̀, omijé ayọ̀ la ó máa rí bí Jèhófà ṣe ń jí àwọn òkú dìde ní ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ tó mórí ẹni yá gágá! (Ka Aísáyà 26:19.) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, àìmọye ọgbẹ́ oró tí ikú ti dá yóò sàn pátá.
22. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ìjọba Mèsáyà bá ti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé?
22 Tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, Ìjọba náà yóò ti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ pátápátá ní ayé, Kristi yóò sì wá gbé ìṣàkóso pa dà fún Baba rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:25-28) Aráyé tó ti di pípé nígbẹ̀yìn gbẹ́yín yóò ti wà nípò tí wọ́n á fi lè kojú ìdánwò ìkẹyìn nígbà tí Ọlọ́run bá tú Sátánì sílẹ̀ nínú ọ̀gbun tí kò ti lè ta pútú tó wà. Lẹ́yìn ìyẹn, Kristi yóò pa ejò olubi yẹn rẹ́ pátápátá àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀. (Jẹ́n. 3:15; Ìṣí. 20:3, 7-10) Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tó jẹ́ pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni wọ́n ní sí Jèhófà yóò ní ìrètí alárinrin. Bóyá ni ọ̀rọ̀ míì tún wà tó lè ṣàkàwé ìrètí yẹn bí èyí tá a rí nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú Bíbélì. Òun ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àwọn olóòótọ́ yóò ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
23, 24. (a) Kí nìdí tó fi dájú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ? (b) Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?
23 Àwọn ìlérí yẹn kì í ṣe ìrètí asán, ohun téèyàn kàn ń rò lọ́kàn lásán, tàbí àlá tí kò lè ṣẹ o. Àwọn ìlérí Jèhófà dájú! Kí nìdí? Rántí ọ̀rọ̀ Jésù tá a ṣàlàyé rẹ̀ ní orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:9, 10) Ìjọba Ọlọ́run kì í kàn ṣe ohun àròsọ lásán. Ìjọba tó wà lóòótọ́ ni! Ó ń ṣàkóso ní ọ̀run lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ó ti tó ọgọ́rùn-ún ọdún kan báyìí tí Ìjọba náà ti ń mú àwọn ìlérí Jèhófà ṣẹ ní onírúurú ọ̀nà tá a lè fojú rí kedere nínú ìjọ Kristẹni. Torí náà, kí ó dá wa lójú pé gbogbo àwọn ìlérí Jèhófà yóò ṣẹ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé láti wá fi agbára rẹ̀ ṣàkóso ayé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́!
24 A mọ̀ dájú pé Ìjọba Ọlọ́run yóò dé. A mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ yóò ṣẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TI Ń ṢÀKÓSO! Ìbéèrè kan tó yẹ kí olúkálukú wa máa bi ara rẹ̀ ni pé, ‘Ǹjẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso mi?’ Ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ Ìjọba yẹn nísinsìnyí, ká lè jàǹfààní ìṣàkóso òdodo rẹ̀ pípé, títí láé!