Orí Kẹtàlélógún
Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
1, 2. (a) Kí ló wà nínú Aísáyà orí ọgbọ̀n? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
NÍNÚ Aísáyà orí ọgbọ̀n, a kà nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run kéde síwájú sí i sórí àwọn olubi. Àmọ́, ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí tún gbé mélòó kan nínú àwọn ànímọ́ àmọ́kànyọ̀ tí Jèhófà ní yọ. Ọ̀nà tó gbà ṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ Jèhófà ṣe kedere tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, àfi bíi ká kúkú sọ pé Jèhófà ọ̀hún dúró tì wá ni, tó ń tù wá nínú, táa ń gbóhùn rẹ̀ bó ṣe ń tọ́ wa sọ́nà, táa sì ń mọ̀ ọ́n lára pé ó ń fọwọ́ bà wá láti mú wa lára dá.—Aísáyà 30:20, 21, 26.
2 Síbẹ̀ náà, àwọn apẹ̀yìndà ará Júdà, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà pẹ̀lú Aísáyà, kọ̀ láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, èèyàn làwọn gbẹ́kẹ̀ lé ní tiwọn. Irú ojú wo ni Jèhófà fi wo ìyẹn? Báwo sì ni ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ṣe ran àwọn Kristẹni òde òní lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti fojú sọ́nà fún Jèhófà? (Aísáyà 30:18) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìyẹn.
Ìwà Òmùgọ̀ àti Ewu
3. Kí ni wọ́n ń pète, tí Jèhófà sì tú àṣírí rẹ̀?
3 Ó pẹ́ díẹ̀ táwọn aṣáájú Júdà ti ń pète ní bòókẹ́lẹ́ lórí ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa bọ́ sábẹ́ àjàgà Ásíríà. Jèhófà sì fọwọ́ lẹ́rán ó ń wò wọ́n. Nísinsìnyí, ó wá tú àṣírí ohun tí wọ́n ń pète, ó ní: “‘Ègbé ni fún àwọn alágídí ọmọ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn tí ó ti ṣe tán láti mú ète ṣẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá; àti láti da ẹbọ ìtasílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí mi, kí wọ́n lè fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀; àwọn tí ó mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì.’”—Aísáyà 30:1, 2a.
4. Báwo làwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn Ọlọ́run ṣe sọ Íjíbítì di Ọlọ́run?
4 Àyà àwọn aṣáájú tó ń pète wọ̀nyẹn á mà já o láti gbọ́ bí wọ́n ṣe ń tú àṣírí ohun tí wọ́n ń wéwèé! Ìwà tí wọ́n hù nípa lílọ ti wọ́n lọ sí Íjíbítì láti lọ bá a mulẹ̀ yìí ré kọjá títọwọ́ bọ Ásíríà lójú; Jèhófà Ọlọ́run ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí. Láyé ìgbà Dáfídì Ọba, Jèhófà ni orílẹ̀-èdè yẹn gbójú lé gẹ́gẹ́ bí odi agbára, wọ́n sì sá di “abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá” rẹ̀. (Sáàmù 27:1; 36:7) Àmọ́ ní báyìí, ṣe ni wọ́n ń “wá ibi ààbò nínú ibi odi agbára Fáráò” tí wọ́n sì “sá di òjìji Íjíbítì.” (Aísáyà 30:2b) Áà, wọ́n kúkú sọ Íjíbítì di Ọlọ́run! Ìṣọ̀tẹ̀ gbáà!—Ka Aísáyà 30:3-5.
5, 6. (a) Èé ṣe tó fi jẹ́ pé àṣìṣe eléwu gbáà ni wọ́n ṣe láti lọ bá Íjíbítì mulẹ̀? (b) Ìrìn àjò wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run rìn níṣàájú tó jẹ́ kó hàn kedere pé ìwà òmùgọ̀ gidi ni gbígbéra tí wọ́n gbéra lọ sí Íjíbítì lọ́tẹ̀ yìí?
5 Aísáyà wá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé síwájú sí i bí ẹni pé ó ń fi ìyẹn fèsì àwíjàre tí wọ́n lè fẹ́ wí, pé àwọn ońṣẹ́ tó lọ sí Íjíbítì kàn lọ ṣèbẹ̀wò lásán ni. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù: La ilẹ̀ wàhálà àti àwọn ipò ìnira kọjá, ti kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn tí ń kùn hùn-ùn, ti paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tí ń fò, èjìká àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán ni wọ́n fi ru àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn, iké àwọn ràkúnmí sì ni wọ́n fi ru àwọn ìpèsè wọn.” (Aísáyà 30:6a) Ó dájú pé ṣe ni wọ́n dìídì wéwèé ìrìn àjò yẹn. Àwọn aṣojú wọ̀nyẹn to àwọn ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ̀ọ̀wọ́, wọ́n di àwọn ẹrù iyebíye rù wọ́n, wọ́n sì dà wọ́n gba inú aginjù aṣálẹ̀ tí àwọn kìnnìún tí ń kùn hùn-ùn àti ejò olóró pọ̀ sí, lọ sí Íjíbítì. Níkẹyìn, àwọn aṣojú wọ̀nyí dé Íjíbítì níbi tí wọ́n ń lọ, wọ́n sì kó ìṣúra wọn fún àwọn ará ibẹ̀. Lójú tiwọn, ṣe ni wọ́n ti fowó ra ààbò. Ṣùgbọ́n, Jèhófà sọ pé: “Wọn kì yóò já sí àǹfààní kankan fún àwọn ènìyàn náà. Asán gbáà sì ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì yóò sì ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan. Nítorí náà, mo ti pe ẹni yìí ní: ‘Ráhábù—wọ́n wà fún jíjókòó jẹ́ẹ́.’” (Aísáyà 30:6b, 7) “Ráhábù,” tí i ṣe “ẹran ńlá abàmì inú òkun,” ló ṣàpẹẹrẹ Íjíbítì. (Aísáyà 51:9, 10) Kò sóhun tí Íjíbítì ò ṣèlérí pé òun máa ṣe, bẹ́ẹ̀ kò ṣe ohunkóhun. Àṣìṣe tó léwu gbáà ni Júdà ṣe tó fi lọ bá a mulẹ̀.
6 Bí Aísáyà ṣe ń ṣàlàyé ìrìn àjò àwọn aṣojú wọ̀nyẹn, ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ń gbọ́ ọ rántí irú ìrìn àjò kan náà tó wáyé nígbà ayé Mósè. Inú “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù” yẹn náà làwọn baba ńlá wọ́n gbà kọjá. (Diutarónómì 8:14-16) Àmọ́, nígbà ayé Mósè, ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. Lọ́tẹ̀ yìí, ṣe làwọn aṣojú wọ̀nyí gbéra lọ sí Íjíbítì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn dẹni àmúsìn. Wọ́n mà kúkú hùwà òmùgọ̀ o! Ǹjẹ́ kí àwa náà má lọ ṣe irú ìpinnu omùgọ̀ yẹn láé, nípa sísọ ara wa dẹrú dípò wíwà lómìnira nípa tẹ̀mí!—Fi wé Gálátíà 5:1.
Àtakò Dé sí Iṣẹ́ Tí Wòlíì Náà Ń Jẹ́
7. Èé ṣe tí Jèhófà fi ní kí Aísáyà kọ ìkìlọ̀ tóun fún Júdà sílẹ̀?
7 Jèhófà sọ fún Aísáyà pé kó kọ ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yẹn sílẹ̀ kí “ó lè jẹ́ fún ọjọ́ ọ̀la, láti ṣe ẹ̀rí fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 30:8) Fún àǹfààní àwọn ìran tí ń bọ̀, àní títí kan ìran tiwa lóde òní, ó ní láti wà lákọọ́lẹ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà bíbá ènìyàn mulẹ̀ dípò gbígbẹ́kẹ̀ lé Òun. (2 Pétérù 3:1-4) Àmọ́, wọ́n ṣì nílò àkọọ́lẹ̀ kan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. “Ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n, àwọn aláìlóòótọ́ ọmọ, àwọn ọmọ tí kò fẹ́ gbọ́ òfin Jèhófà.” (Aísáyà 30:9) Ńṣe làwọn èèyàn wọ̀nyẹn kọ ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílẹ̀. Nítorí náà, dandan ni kó wà lákọọ́lẹ̀ kí wọ́n má bàa sọ lẹ́yìn wá ọ̀la pé àwọn ò rí ìkìlọ̀ tó yẹ gbà.—Òwe 28:9; Aísáyà 8:1, 2.
8, 9. (a) Báwo làwọn aṣáájú Júdà ṣe gbìyànjú láti sọ àwọn wòlíì Jèhófà dìbàjẹ́? (b) Báwo ni Aísáyà ṣe fi hàn pé ìhàlẹ̀ kankan ò lè pa òun lẹ́nu mọ́?
8 Aísáyà wá sọ àpẹẹrẹ ìwà ìṣọ̀tẹ̀ táwọn èèyàn yẹn hù. Ó ní wọ́n “sọ fún àwọn tí ń rí pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ rí,’ àti fún àwọn tí ń rí ìran pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ rí ìran ohunkóhun tí ó jẹ́ títọ́ sí wa. Ẹ máa sọ àwọn ohun dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in fún wa; ẹ máa rí ìran àwọn ohun ìtannijẹ.’” (Aísáyà 30:10) Nígbà tí àwọn aṣáájú Júdà pàṣẹ pé kí àwọn wòlíì olóòótọ́ ṣíwọ́ sísọ ọ̀rọ̀ tó “jẹ́ títọ́,” tàbí ọ̀rọ̀ òótọ́, kí wọ́n sì máa bá àwọn sọ ohun “dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in” àti ọ̀rọ̀ “ìtannijẹ,” tàbí ọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń fi hàn pé ẹni tí yóò máa rin àwọn létí làwọn ń fẹ́. Sàdáńkátà ni wọ́n ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe fáwọn dípò bíbẹnu àtẹ́ lu àwọn. Lójú tiwọn, kí wòlíì èyíkéyìí tí kò bá fẹ́ sọ tẹ́lẹ̀ bí àwọn ṣe fẹ́, tètè “yà kúrò lójú ọ̀nà” kó sì “yapa kúrò ní ipa ọ̀nà” ni o. (Aísáyà 30:11a) Bí kò bá ti lè wàásù ohun tó báni létí mu kó kúkú gbẹ́nu dákẹ́!
9 Àwọn alátakò Aísáyà fi dandan lé e pé: “Mú kí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wá sí òpin kìkì ní tìtorí wa.” (Aísáyà 30:11b) Kí Aísáyà yéé sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà, “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì” mọ́! Àpèlé yẹn pàápàá ń bí wọn nínú nítorí pé ìlànà ìwà híhù gíga tí Jèhófà ń lò ń tú àṣírí ìwàkiwà wọn. Kí ni Aísáyà wá ṣe? Ó kéde pé: “Èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí.” (Aísáyà 30:12a) Aísáyà ò lọ́ tìkọ̀ tó fi tún sọ gbólóhùn tí àwọn alátakò rẹ̀ láwọn ò fẹ́ máa gbọ́ rárá. Ìhàlẹ̀ kankan ò ní pa á lẹ́nu mọ́. Àpẹẹrẹ rere lèyí mà jẹ́ fún wa o! Tọ́rọ̀ bá dórí kíkéde iṣẹ́ Ọlọ́run, àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ láé. (Ìṣe 5:27-29) Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà, ńṣe ni wọn óò máa bá a lọ láti polongo pé: ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí’!
Ohun Tí Ìṣọ̀tẹ̀ Ń Fà Báni
10, 11. Kí ni ìṣọ̀tẹ̀ Júdà yóò yọrí sí?
10 Júdà kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n fọkàn tán irọ́, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé “ohun békebèke.” (Aísáyà 30:12b) Kí ni yóò fà bá wọn? Kàkà kí Jèhófà fi orílẹ̀-èdè yẹn sílẹ̀, kí wọ́n máa ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́, yóò kúkú mú kí orílẹ̀-èdè yẹn pa rẹ́ ni o! Bí àpèjúwe tí Aísáyà lò láti fi tẹnu mọ́ ọn ṣe fi hàn, òjijì ni yóò já lù wọ́n, yóò sì run wọ́n pátápátá ni. Ìṣọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè yẹn dà bí “abala tí ó ti là, tí ó máa tó wó lulẹ̀, ìwúsíta lára ògiri gíga sókè, ìwópalẹ̀ èyí tí ó lè dé lójijì, ní ìṣẹ́jú akàn.” (Aísáyà 30:13) Bí ibi tó ń wú síta lára ògiri ṣe máa jẹ́ kí ògiri yẹn wó lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bẹ́ẹ̀ náà ni pípọ̀ tí ìṣọ̀tẹ̀ àwọn èèyàn ìgbà ayé Aísáyà ń pọ̀ sí i ṣe máa fa ìṣubú orílẹ̀-èdè yẹn.
11 Aísáyà wá lo àpèjúwe mìíràn láti fi sọ bí ìparun tó ń bọ̀ yẹn ṣe máa jẹ́ ìparun ráúráú, ó ní: “Ṣe ni ẹnì kan yóò fọ́ ọ bí ìgbà tí a bá fọ́ ìṣà títóbi ti àwọn amọ̀kòkò, èyí tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́ láìsí pé ẹni náà dá a sí, tí yóò fi jẹ́ pé, lára ìfọ́síwẹ́wẹ́ rẹ̀, a kì yóò rí àpáàdì tí a ó fi wa iná láti ibi ìdáná tàbí láti fi ré omi láti àbàtà.” (Aísáyà 30:14) Júdà yóò rún wómúwómú dépò tí kò fi ní sí ohunkóhun tó wúlò lára rẹ̀ mọ́, àní kò tiẹ̀ ní ku àpáàdì tó fẹ̀ tó láti fi họ eérú gbóná kúrò ní ààrò, tàbí tó ṣeé fi ré omi lábàtà. Ibi tí ọ̀ràn wọ́n parí sí mà tini lójú o! Bí ìparun sì ṣe máa já lu àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí ìsìn tòótọ́ lónìí lójijì nìyẹn, tí yóò sì run wọ́n pátápátá.—Hébérù 6:4-8; 2 Pétérù 2:1.
Wọ́n Kọ Ohun Tí Jèhófà Nawọ́ Rẹ̀ sí Wọn
12. Kí ló lè jẹ́ kí ìparun yẹ̀ lórí àwọn ará Júdà?
12 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé kò sọ́nà tí ìparun fi lè yẹ̀ lórí àwọn tí Aísáyà ń bá sọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀nà àjàbọ́ wà fún wọn. Wòlíì yìí ṣàlàyé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, wí: ‘Nípa pípadà wá àti sísinmi ni a ó fi gbà yín là. Agbára ńlá yín yóò sì wà nínú àìní ìyọlẹ́nu rárá àti nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé.’” (Aísáyà 30:15a) Jèhófà ṣe tán láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nípa “sísinmi” tàbí kí wọ́n má gbìyànjú láti wá ìgbàlà látinú ìmùlẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn, àti bí wọ́n bá “wà nínú àìní ìyọlẹ́nu rárá,” ìyẹn kí wọ́n fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé agbára ààbò Ọlọ́run nípa ṣíṣàìbẹ̀rù. Aísáyà wá sọ fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́.”—Aísáyà 30:15b.
13. Kí làwọn aṣáájú Júdà gbẹ́kẹ̀ lé, ṣe irú ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn sì gbè wọ́n?
13 Aísáyà wá ṣe àlàyé síwájú sí i pé: “Ẹ sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: ‘Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò sá lọ lórí ẹṣin!’ Ìdí nìyẹn tí ẹ ó fi sá lọ. ‘Ẹṣin yíyára sì ni àwa yóò gùn!’ Ìdí nìyẹn tí àwọn tí ń lépa yín yóò fi ara wọn hàn ní ẹni yíyára.” (Aísáyà 30:16) Àwọn ará Jùdíà rò pé àwọn ẹṣin yíyára ni yóò gba àwọn là, kì í ṣe Jèhófà. (Diutarónómì 17:16; Òwe 21:31) Àmọ́ wòlíì yìí tètè fi yé wọn pé ìmúlẹ̀mófo ni ìgbẹ́kẹ̀lé wọn yóò já sí nítorí pé àwọn ọ̀tá wọn yóò lé wọn bá. Kódà wọn ì báà pọ̀, ìyẹn ò ní ṣàǹfààní kankan fún wọn. Ó ní: “Ẹgbẹ̀rún yóò wárìrì ní tìtorí ìbáwí mímúná ẹnì kan; ní tìtorí ìbáwí mímúná ẹni márùn-ún ẹ óò sá lọ.” (Aísáyà 30:17a) Igbe ìwọ̀nba kéréje àwọn ọ̀tá ni yóò lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Júdà sá kìjokìjo.a Níkẹyìn, yóò wá ku kìkì àṣẹ́kù tó dá wà “bí òpó kan ní orí òkè ńlá àti bí àmì àfiyèsí kan lórí òkè kékeré.” (Aísáyà 30:17b) Lóòótọ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ, kìkì àṣẹ́kù ló la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Jeremáyà 25:8-11.
Ìtùnú Lásìkò Ìbáwí
14, 15. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Aísáyà 30:18 sọ fún àwọn ará Júdà láyé àtijọ́ àti àwọn Kristẹni òde òní?
14 Àgbà ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣì ń ró kì lọ́kàn àwọn tí Aísáyà ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ohùn tó fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ bá yí padà. Ohùn ìkìlọ̀ nípa ìjábá yí padà di èyí tó ń ṣèlérí àwọn ìbùkún. Ó ní: “Nítorí náà, Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.” (Aísáyà 30:18) Ọ̀rọ̀ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Bàbá oníyọ̀ọ́nú tó ń fẹ́ láti ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ ni Jèhófà jẹ́. Ìdùnnú ló máa ń jẹ́ fún un láti ṣàánú fúnni.—Sáàmù 103:13; Aísáyà 55:7.
15 Àṣẹ́kù àwọn Júù tí wọ́n ṣojú àánú sí láti jẹ́ kí wọ́n la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, àti àwọn kéréje tó padà wá sí Ilẹ̀ Ìlérí lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, làwọn ọ̀rọ̀ afinilọ́kàn-balẹ̀ yìí kàn. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ wòlíì yìí tún tu àwọn Kristẹni òde òní nínú pẹ̀lú. Ó ń rán wa létí pé Jèhófà yóò “dìde” nítorí tiwa, yóò sì mú ayé burúkú yìí wá sópin. Kí ó dá àwọn olóòótọ́ olùjọsìn lójú pé Jèhófà, tó jẹ́ “Ọlọ́run ìdájọ́,” kò ní gbà kí ayé Sátánì fi ọjọ́ kan ṣoṣo gùn ré kọjá ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Nítorí náà, kí “àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un” ṣáà máa yọ̀ ni o.
Jèhófà Ń Tu Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nínú Nípa Dídáhùn Àdúrà Wọn
16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń tu àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì nínú?
16 Àmọ́ ṣá, àwọn kan lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ìdáǹdè wọn kò dé kíákíá bí wọ́n ṣe retí pé kó dé. (Òwe 13:12; 2 Pétérù 3:9) Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ Aísáyà tó tẹ̀ lé e, tó tẹnu mọ́ ẹ̀ka pàtàkì nínú ànímọ́ Jèhófà, tù wọ́n nínú o. Ó ní: “Nígbà tí àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Síónì yóò máa gbé ní Jerúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò sunkún rárá. Láìkùnà, òun yóò fi ojú rere hàn sí ọ ní gbígbọ́ ìró igbe ẹkún rẹ; gbàrà tí ó bá gbọ́ ọ, yóò dá ọ lóhùn ní tòótọ́.” (Aísáyà 30:19) Aísáyà fi ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yìí nípa lílo “ìwọ” ni ẹsẹ kọkàndínlógún, ìyẹn ọ̀rọ̀ tó tọ́ka sí ẹnì kọ̀ọ̀kan, dípò “yín,” tó lò ní ẹsẹ kejìdínlógún láti fi tọ́ka sí ẹni púpọ̀. Jèhófà a máa tu àwọn tí wàhálà bá nínú lọ́nà tó bá olúkúlùkù mu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tirẹ̀. Òun gẹ́gẹ́ bí Bàbá, kì í bi ẹni tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá pé, ‘Ṣèbí èèyàn bí tìẹ làwọn yòókù, kí ní ṣe tóò ṣara gírí bíi tiwọn?’ (Gálátíà 6:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àní “gbàrà tí ó bá gbọ́ ọ, yóò dá ọ lóhùn ní tòótọ́.” Gbólóhùn yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì lè rí okun ńláǹlà gbà bí wọ́n bá gbàdúrà sí Jèhófà.—Sáàmù 65:2.
Gbọ́ Ohùn Ọlọ́run Tó Ń Tọ́ni Sọ́nà Nípa Kíka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀
17, 18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà, àní nígbà ìṣòro pàápàá?
17 Bí Aísáyà ṣe ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ, ó rán àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ létí pé wàhálà ń bọ̀ o. Àwọn èèyàn yẹn yóò gba “oúnjẹ tí í ṣe wàhálà àti omi tí í ṣe ìnilára.” (Aísáyà 30:20a) Bí oúnjẹ àti omi kò ṣe ṣàjèjì síni ni wàhálà àti ìnira yóò ṣe wọ́pọ̀ nígbà tí wọ́n bá sàga tì wọ́n. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ṣe tán láti kó àwọn ọlọ́kàn títọ́ yọ. Ó ní: “Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá kì yóò tún fi ara rẹ̀ pa mọ́, ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá. Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”—Aísáyà 30:20b, 21.b
18 Jèhófà ni ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá.’ Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní ti ká kọ́ni. Àmọ́, báwo làwọn èèyàn ṣe lè “rí” i, kí wọ́n sì “gbọ́” ọ̀rọ̀ rẹ̀? Jèhófà máa ń fi ara rẹ̀ hàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn sì wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. (Ámósì 3:6, 7) Lóde òní, bí àwọn olóòótọ́ olùjọsìn bá ń ka Bíbélì, ṣe lo máa ń dà bí ìgbà tí wọ́n ń gbọ́ tí Ọlọ́run ń sọ fún wọn, bí bàbá ṣe ń bọ́mọ sọ̀rọ̀, pé ọ̀nà báyìí ni kí ẹ gbà, tó sì ń rọ̀ wọ́n láti yíwà padà láti lè máa tọ ọ̀nà yẹn. Kí olúkúlùkù Kristẹni tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ ni o, bí Jèhófà ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ láti ojú ewé Bíbélì àti nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé karí Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mátíù 24:45-47) Kí olúkúlùkù sì jára mọ́ Bíbélì kíkà ni o, nítorí “ó túmọ̀ sí ìwàláàyè.”—Diutarónómì 32:46, 47; Aísáyà 48:17.
Ronú Lórí Àwọn Ìbùkún Tí Ń Bẹ Níwájú
19, 20. Àwọn ìbùkún wo ló wà nípamọ́ fún àwọn tó bá kọbi ara sí ohùn Olùkọ́ni Atóbilọ́lá?
19 Ńṣe làwọn tó bá kọbi ara sí ohùn Olùkọ́ni Atóbilọ́lá máa kó ère fífín wọn dànù, wọn a kà wọ́n sí ohun ìríra. (Ka Aísáyà 30:22.) Lẹ́yìn náà làwọn tó létí ìgbọ́ yìí yóò wá rí ìbùkún àgbàyanu gbà. Aísáyà ṣàpèjúwe ìwọ̀nyí nínú àkọsílẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 30:23-26, èyí tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò tó dùn mọ́ni, tó kọ́kọ́ ṣẹ nígbà tí àṣẹ́kù àwọn Júù padà bọ̀ láti ìgbèkùn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lóde òní, àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí irú ìbùkún àgbàyanu tí Mèsáyà mú kó wáyé nínú Párádísè tẹ̀mí nísinsìnyí, tí yóò sì wáyé nínú Párádísè táa lè fojú rí tí ń bọ̀.
20 Ó ní: “Dájúdájú, òun yóò sì rọ òjò sí irúgbìn rẹ, èyí tí o fún sí ilẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí èso ilẹ̀, èyíinì ni oúnjẹ, tí yóò di sísanra àti olóròóró. Ní ọjọ́ yẹn, ohun ọ̀sìn rẹ yóò máa jẹko ní pápá ìjẹko aláyè gbígbòòrò. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán, tí wọ́n ń ro ilẹ̀ yóò sì máa jẹ oúnjẹ ẹran tí a fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí a fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́.” (Aísáyà 30:23, 24) Oúnjẹ “sísanra àti olóròóró,” ìyẹn oúnjẹ tó ń ṣara lóore gidigidi, ni yóò wọ́pọ̀ jù lọ nínú oúnjẹ téèyàn ó máa jẹ lójoojúmọ́. Ilẹ̀ yóò méso wá rẹpẹtẹ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó jẹ́ pé àwọn ẹranko pàápàá yóò jàǹfààní. “Oúnjẹ ẹran tí a fi ewéko olómi-kíkan sí,” ìyẹn oúnjẹ àdídùn tí wọn kì í dédé fún ẹran ọ̀sìn láìsí ìdí pàtàkì, ni wọn ó máa fún àwọn ẹran ọ̀sìn jẹ. Àní wọ́n tiẹ̀ tún “fẹ́” oúnjẹ yìí, bẹ́ẹ̀ ọkà téèyàn bá máa jẹ nìkan ni wọ́n sábà máa ń fẹ́. Kúlẹ̀kúlẹ̀ tí Aísáyà mẹ́nu kàn níhìn-ín láti fi ṣàpèjúwe irú ìbùkún jìngbìnnì tí Jèhófà máa fún àwọn olóòótọ́ nínú aráyé mà kọ yọyọ o!
21. Ṣàpèjúwe bí àwọn ìbùkún tí ń bọ̀ yóò ṣe jẹ́ èyí tó délé dóko.
21 Ó ní: “Lórí gbogbo òkè ńlá gíga àti lórí gbogbo òkè kékeré tí ó ga ni àwọn ìṣàn . . . omi yóò wà.” (Aísáyà 30:25a)c Àpèjúwe tó gún régé ni Aísáyà lò láti fi túbọ̀ ṣàlàyé bí ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà yóò ṣe délé dóko. Kò ní sí ọ̀wọ́n omi, nítorí pé pẹ̀tẹ́lẹ̀ nìkan kọ́ ni ohun kò-ṣeé-má-nìí yìí yóò ti máa ṣàn bí kò ṣe lórí gbogbo òkè ńlá, àní “lórí gbogbo òkè ńlá gíga àti gbogbo òkè kékeré tí ó ga” pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni o, ebi yóò dàwátì. (Sáàmù 72:16) Síwájú sí i, wòlíì yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó tiẹ̀ tún ga ju àwọn òkè lọ. Ó ní: “Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń ràn yòò; àní ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń ràn yòò yóò sì di ìlọ́po méje rẹ̀, bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà di ìwópalẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, àní tí ó ṣe ìwòsàn ọgbẹ́ ríronilára gógó tí ó wáyé nítorí ẹgba tí ó nani.” (Aísáyà 30:26) Paríparì ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ga lọ́lá yìí mà wúni lórí o! Ńṣe ni ògo Ọlọ́run yóò máa fi gbogbo ọlá ńlá rẹ̀ tàn yanran. Ní ti àwọn ìbùkún tí ń bẹ nípamọ́ fún àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run, jàn-ànràn jan-anran ló fi ré kọjá ohunkóhun yòówù tí wọ́n tí ì gbádùn rí, àní ní ìlọ́po méje pàápàá.
Ìdájọ́ àti Ayọ̀
22. Ní ìyàtọ̀ sí ìbùkún tí àwọn olóòótọ́ yóò rí gbà, kí ni Jèhófà yóò mú bá àwọn ẹni burúkú?
22 Ohùn tí Aísáyà fi ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tún wá yí padà wàyí. Ó sọ pé, “Wò ó!,” bí ẹni pé ó fẹ́ kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ tẹ́tí sílẹ̀. “Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ibi jíjìnnàréré, ó ń jó pẹ̀lú ìbínú rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọsánmà ṣíṣúdùdù. Ní ti ètè rẹ̀, ó kún fún ìdálẹ́bi, ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tí ń jẹni run.” (Aísáyà 30:27) Ní gbogbo bí àwọn tí ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ ṣọ̀tá ti ń ṣe bó ṣe wù wọ́n, ṣe ni Jèhófà fọwọ́ lẹ́rán tó ń wò wọ́n. Nísinsìnyí, ó wá sún mọ́ tòsí bí ìgbà tí ìjì ààrá bá ń jà bọ̀, láti dá wọn lẹ́jọ́. Ó ní: “Ẹ̀mí rẹ̀ sì dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tí ó dé ọrùn, láti fi ajọ̀ ohun àìníláárí fi àwọn orílẹ̀-èdè làkàlàkà síwá-sẹ́yìn; ìjánu tí ń mú kí ènìyàn rìn gbéregbère yóò sì wà ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn ènìyàn náà.” (Aísáyà 30:28) Ṣe ni “àkúnya ọ̀gbàrá” máa yí àwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run ká, àní yóò “fi ajọ̀” fì wọ́n “làkàlàkà,” yóò sì fi “ìjánu” mú wọn so. Wọn yóò sì pa run.
23. Kí ló ń mú “ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà” bá àwọn Kristẹni lóde òní?
23 Bẹ́ẹ̀ lohùn Aísáyà sì tún yí padà bó ṣe ń ṣàpèjúwe ipò aláyọ̀ tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò wà nígbà tí wọ́n bá padà sí ilẹ̀ wọn lọ́jọ́ kan ṣáá. Ó ní: “Ẹ óò wá ní orin kan bí èyí tí a ń kọ ní òru tí ènìyàn sọ ara rẹ̀ di mímọ́ fún àjọyọ̀, àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà bí ti ẹni tí ń rìn tòun ti fèrè láti dé orí òkè ńlá Jèhófà, àní dé orí Àpáta Ísírẹ́lì.” (Aísáyà 30:29) Irú “ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn àyà” yìí ló máa ń bá àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní bí wọ́n bá ti ń ronú nípa ìdájọ́ tí yóò bá ayé Sátánì yìí; nípa ààbò tí Jèhófà, “Àpáta ìgbàlà,” fi ń bò wọ́n; àti ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá.—Sáàmù 95:1.
24, 25. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe túbọ̀ ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni ìdájọ́ ń bọ̀ wá sórí Ásíríà?
24 Lẹ́yìn gbólóhùn ayọ̀ yìí, Aísáyà tún padà sórí kókó ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ó sì sọ ẹni tí ìrunú Ọlọ́run fẹ́ wá sórí rẹ̀. Ó ní: “Dájúdájú, Jèhófà yóò sì mú kí a gbọ́ iyì ohùn rẹ̀, yóò sì mú kí a rí ìsọ̀kalẹ̀ apá rẹ̀, nínú híhó ìbínú àti ọwọ́ iná tí ń jẹni run àti òjò òjijì apọnmùúmùú àti ìjì òjò àti àwọn òkúta yìnyín. Nítorí pé ní tìtorí ohùn Jèhófà, Ásíríà ni a óò kó ìpayà bá; àní òun yóò fi ọ̀gọ lù ú.” (Aísáyà 30:30, 31) Aísáyà lo àpèjúwe yìí, tó fi bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ gan-an hàn, láti fi tẹnu mọ́ ọn pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀ lórí Ásíríà dájúdájú. Àfi bí ẹni pé Ásíríà dúró níwájú Ọlọ́run, tí jìnnìjìnnì sì bá a bó ṣe rí i pé “apá” ìdájọ́ Ọlọ́run ‘ń sọ̀ kalẹ̀’ bọ̀ wá sórí òun.
25 Wòlíì yìí ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Gbogbo ìfìlàkàlàkà ọ̀pá ìfinani rẹ̀, èyí tí Jèhófà yóò mú kí ó sọ̀ kalẹ̀ sára Ásíríà yóò sì jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti àwọn háàpù dájúdájú; àwọn ìjà ogun tí a ti ń ju àwọn ohun ìjà fìrìfìrì sì ni òun yóò fi bá wọn jà ní ti tòótọ́. Nítorí pé a ti ṣètò Tófétì rẹ̀ ní àkókò àìpẹ́ yìí; a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú fún ọba tìkára rẹ̀. Ó ti mú kí ìtòjọpelemọ rẹ̀ jinlẹ̀. Iná àti igi pọ̀ yanturu. Èémí Jèhófà, bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́, ń jó o.” (Aísáyà 30:32, 33) Níhìn-ín, ṣe ló fi Tófétì, tó wà ní Àfonífojì Hínómù, ṣàpẹẹrẹ ibi tí iná ti ń jó. Ìparun tí yóò dé bá Ásíríà lójijì, tí yóò sì pa á rẹ́ ráúráú ni Aísáyà túbọ̀ ń ṣàlàyé rẹ̀ nígbà tó sọ pé inú àfonífojì yẹn ni orílẹ̀-èdè yẹn yóò parí sí.—Fi wé 2 Àwọn Ọba 23:10.
26. (a) Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà kéde sórí Ásíríà ṣe kan ọ̀ràn òde òní? (b) Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún Jèhófà?
26 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí Ásíríà ni ọ̀rọ̀ ìdájọ́ yìí dá lé, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń sọ ní pàtàkì ré kọjá ìyẹn. (Róòmù 15:4) Lẹ́ẹ̀kan sí i, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Jèhófà yóò ṣì ya lu àwọn tó ń ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára, bí àkúnya omi, yóò sì fì wọ́n làkàlàkà, yóò sì fi ìjánu mú wọn so. (Ìsíkíẹ́lì 38:18-23; 2 Pétérù 3:7; Ìṣípayá 19:11-21) Kí ọjọ́ yẹn mà jọ̀ọ́ tètè dé o! Ní báyìí ná, ṣe làwọn Kristẹni ń fi ìháragàgà retí ọjọ́ ìdáǹdè. Wọ́n ń rí okun gbà bí wọ́n ṣe ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tó yéni yékéyéké tó wà nínú Aísáyà orí ọgbọ̀n. Ṣe lọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níṣìírí pé kí wọ́n ka àǹfààní àdúrà gbígbà sí ohun iyebíye, kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì, kí wọ́n sì máa ronú nípa àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Sáàmù 42:1, 2; Òwe 2:1-6; Róòmù 12:12) Nípa báyìí, ńṣe lọ̀rọ̀ Aísáyà ń ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún Jèhófà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣàkíyèsí pé, ká ní Júdà ṣe olóòótọ́ ni, igbe ìwọ̀n kéréje lára wọn ni ì bá lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀tá sá.—Léfítíkù 26:7, 8.
b Ibí nìkan ṣoṣo ni wọ́n ti pe Jèhófà ní ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá’ nínú Bíbélì.
c Apá tó kẹ́yìn nínú Aísáyà 30:25 kà báyìí pé: “Ní ọjọ́ ìfikúpa tìrìgàngàn nígbà tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú.” Ní ti ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kó tọ́ka sí ìṣubú Bábílónì, èyí tó jẹ́ kí Ísírẹ́lì rí àwọn ìbùkún tí Aísáyà 30:18-26 sọ tẹ́lẹ̀ gbà. (Wo ìpínrọ̀ kọkàndínlógún.) Ó sì tún lè máa sọ nípa ìparun tí yóò wáyé ní Amágẹ́dọ́nì, èyí tí yóò jẹ́ kí àwọn ìbùkún yìí ṣẹ lọ́nà tó ga lọ́lá jù lọ nínú ayé tuntun.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 305]
Nígbà ayé Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ Íjíbítì. Nígbà ayé Aísáyà, Júdà tọ Íjíbítì lọ fún ìrànlọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 311]
“Lórí gbogbo òkè kékeré tí ó ga ni àwọn ìṣàn . . . omi yóò wà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 312]
Jèhófà ń bọ̀ tòun ti “ìbínú rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọsánmà ṣíṣúdùdù”