Àìsáyà
30 “Àwọn alágídí ọmọ gbé,”+ ni Jèhófà wí,
“Àwọn tó ń ṣe ohun tí mi ò ní lọ́kàn,+
Tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀,* àmọ́ tí kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,
Kí wọ́n lè dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+
Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*
Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!
3 Àmọ́ ibi ààbò Fáráò máa dójú tì yín,
Òjìji Íjíbítì tí ẹ sì fi ṣe ibi ìsádi máa rẹ̀ yín wálẹ̀.+
4 Torí àwọn ìjòyè rẹ̀ wà ní Sóánì,+
Àwọn aṣojú rẹ̀ sì ti dé Hánésì.
5 Àwọn èèyàn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan
Máa dójú ti gbogbo wọn,
Àwọn tí kò ṣèrànwọ́ kankan, tí wọn ò sì ṣeni láǹfààní kankan,
Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ nìkan ni wọ́n ń mú wá.”+
6 Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù:
Wọ́n gba ilẹ̀ wàhálà àti ìnira kọjá,
Ilẹ̀ kìnnìún, kìnnìún tó ń ké ramúramù,
Paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tó ń fò,*
Wọ́n gbé ọrọ̀ wọn sí ẹ̀yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
Àtàwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lò sórí iké àwọn ràkúnmí.
Àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò ní ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní.
7 Torí ìrànlọ́wọ́ Íjíbítì ò wúlò rárá.+
Torí náà, mo pe ẹni yìí ní: “Ráhábù,+ tó jókòó jẹ́ẹ́.”
8 “Ó yá, lọ, kọ ọ́ sára wàláà níṣojú wọn,
Kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé,+
Kó lè wúlò lọ́jọ́ ọ̀la,
Láti jẹ́ ẹ̀rí tó máa wà títí láé.+
10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’
Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+
Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+
11 Ẹ yà kúrò lọ́nà; ẹ fọ̀nà sílẹ̀.
Ẹ má fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì síwájú wa mọ́.’”+
12 Torí náà, ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sọ nìyí:
“Torí pé ẹ ò gba ọ̀rọ̀ yìí,+
Tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì àti ẹ̀tàn,
Tí ẹ sì gbára lé àwọn nǹkan yìí,+
13 Ẹ̀ṣẹ̀ yìí máa dà bí ògiri tó ti sán fún yín,
Bí ògiri gíga tó wú, tó máa tó wó,
Ó máa wó lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.
14 Ó máa fọ́ bí ìṣà ńlá tó jẹ́ ti amọ̀kòkò,
Ó máa fọ́ túútúú débi pé kò ní sí àfọ́kù kankan,
Láti fi wa iná láti ibi ìdáná
Tàbí láti fi bu omi nínú adágún.”*
15 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí:
“Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;
Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+
Àmọ́ kò wù yín.+
16 Dípò ìyẹn, ẹ sọ pé: “Rárá, a máa gun ẹṣin sá lọ!”
Ẹ sì máa sá lọ lóòótọ́.
“A máa gun àwọn ẹṣin tó ń yára kánkán!”+
Àwọn tó ń lépa yín sì máa yára kánkán.+
17 Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) máa gbọ̀n rìrì nítorí ìhàlẹ̀ ẹnì kan;+
Ìhàlẹ̀ ẹni márùn-ún máa mú kí ẹ sá,
Títí ohun tó ṣẹ́ kù nínú yín fi máa dà bí òpó lórí òkè ńlá,
Bí òpó tí wọ́n fi ṣe àmì lórí òkè kékeré.+
Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.+
Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.*+
19 Tí àwọn èèyàn bá ń gbé ní Síónì, ní Jerúsálẹ́mù,+ o ò ní sunkún rárá.+ Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́; ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.+ 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa fi wàhálà ṣe oúnjẹ fún yín, tó sì máa fi ìyà ṣe omi fún yín,+ Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá ò ní fi ara rẹ̀ pa mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.+ 21 Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+
22 Ẹ ó sọ fàdákà tí ẹ fi bo àwọn ère gbígbẹ́ yín àti wúrà tí ẹ fi bo àwọn ère onírin*+ yín di aláìmọ́. Ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí wọ́n fi ṣe nǹkan oṣù, ẹ ó sì sọ fún wọn pé: “A ò fẹ́ mọ́!”*+ 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+ 24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ máa jẹ oúnjẹ ẹran tí wọ́n fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí wọ́n fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́. 25 Odò àti ipadò máa wà lórí gbogbo òkè ńlá tó rí gogoro àti gbogbo òkè kéékèèké tó ga,+ ní ọjọ́ tí a pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú. 26 Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú máa dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì máa lágbára sí i ní ìlọ́po méje,+ bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà bá di àfọ́kù àwọn èèyàn rẹ̀,*+ tó sì wo ọgbẹ́ ńlá tó dá sí wọn lára nígbà tó kọ lù wọ́n sàn.+
27 Wò ó! Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,
Inú ń bí i gan-an, ó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* tó ṣú bolẹ̀.
Ìbínú kún ètè rẹ̀,
Ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tó ń jẹni run.+
28 Ẹ̀mí* rẹ̀ dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tó muni dé ọrùn,
Láti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nínú ajọ̀ ìparun;*
Ìjánu sì máa wà ní páárì àwọn èèyàn+ náà láti kó wọn ṣìnà.
29 Àmọ́ orin yín máa dà bí èyí tí wọ́n kọ ní òru
Nígbà tí ẹ̀ ń múra sílẹ̀* fún àjọyọ̀,+
Inú yín sì máa dùn bíi ti ẹni
Tó ń rìn tòun ti fèrè*
Bó ṣe ń lọ sí òkè Jèhófà, sọ́dọ̀ Àpáta Ísírẹ́lì.+
30 Jèhófà máa mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀ tó gbayì,+
Ó sì máa fi apá rẹ̀ hàn+ bó ṣe ń fi ìbínú tó le sọ̀ kalẹ̀ bọ̀,+
Pẹ̀lú ọwọ́ iná tó ń jẹni run,+
Òjò líle tó bẹ̀rẹ̀ lójijì,+ ìjì tó ń sán ààrá àti àwọn òkúta yìnyín.+
32 Gbogbo bó ṣe ń fi ọ̀pá rẹ̀ tó fi ń jẹni níyà,
Èyí tí Jèhófà máa mú wá sórí Ásíríà,
Máa jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti háàpù,+
Bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ sí wọn lójú ogun.+
Ó ti to igi jọ pelemọ, ó sì fẹ̀,
Pẹ̀lú iná tó ń jó lala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi.
Èémí Jèhófà, tó dà bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́,
Máa dáná sí i.