Jíjẹ́ Onídùnnú-ayọ̀ Nísinsìnyí àti Títí Láé
“Ẹ yọ ayọ̀ àṣeyọrí, ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì jẹ́ onídùnnú-ayọ̀ títí láé nínú ohun tí èmi ń dà. Nítorí èmi ń dá Jerusalemu bí orísun ìdùnnú-ayọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bí orísun ayọ̀ àṣeyọrí.”—ISAIAH 65:18, NW.
1. Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ ṣe nípa lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún?
JÁLẸ̀ àwọn ọ̀rúndún, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ti rí ìdùnnú-ayọ̀ púpọ̀ nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọrun tòótọ́ náà, Jehofa. Dafidi jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìdùnnú-ayọ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́. Bibeli ròyìn pé, nígbà tí a gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerusalemu, “Dafidi àti gbogbo ilé Israeli sì gbé àpótí ẹ̀rí Oluwa gòkè wá, ti àwọn ti ìhó ayọ̀.” (2 Samueli 6:15) Irú ìdùnnú-ayọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa, kì í ṣe ohun àtijọ́ lásán. O lè nípìn-ín nínú rẹ̀. Àwọn apá tuntun nínú ìdùnnú-ayọ̀ pàápàá sì lè jẹ́ tìrẹ láìpẹ́!
2. Yàtọ̀ sí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti Isaiah orí 35 lórí àwọn Júù tí wọ́n padà, àwọn wo ni ìmúṣẹ mìíràn kàn lónìí?
2 Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a ṣàgbéyẹ̀wò ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ arùmọ̀lárasókè tí a kọ sínú Isaiah orí 35. A lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ sọ pé èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò nítorí pé, ohun tí ó yọrí sí fún àwọn Júù ìgbàanì nìyẹn. Ó ní ìmúṣẹ tí ó fara jọ ọ́ ní àkókò wa. Báwo? Tóò, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aposteli Jesu àti àwọn mìíràn ní Pentekosti ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jehofa ti ń bá àwọn ọmọ Israeli tẹ̀mí lò. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí a fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun yàn, tí wọ́n di apá kan ohun tí aposteli Paulu pè ní “Israeli Ọlọrun.” (Galatia 6:16; Romu 8:15-17) Rántí pẹ̀lú pé, ní 1 Peteru 2:9, a pe àwọn Kristian wọ̀nyí ní “ẹ̀yà-ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” Peteru ń bá a lọ láti sọ iṣẹ́ àyànfúnni tí a fún Israeli tẹ̀mí pé: “‘Kí ẹ̀yin lè polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè yín jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”
Ìmúṣẹ ní Àkókò Wa
3, 4. Báwo ni ipò náà ṣe rí nígbà tí Isaiah orí 34 ní ìmúṣẹ ní àkókò òde òní?
3 Àkókò kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, nígbà tí àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé kò ṣe déédéé ní ti fífi taápọntaápọn polongo ìhìn iṣẹ́ náà. Wọn kò kún fún ayọ̀ ní kíkún nínú àgbàyanu ìmọ́lẹ̀ Ọlọrun. Ní ti gàsíkíá, wọ́n wà nínú òkùnkùn dé ìwọ̀n àyè tí ó ga. Nígbà wo nìyẹn? Kí sì ni Jehofa Ọlọrun ṣe nípa rẹ̀?
4 Ní àkókò Ogun Àgbáyé Kìíní ni, kété lẹ́yìn tí a gbé Ìjọba Messia Ọlọrun kalẹ̀ ní ọ̀run ní 1914. Àwọn orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú ìtìlẹyìn àwùjọ àlùfáà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ní onírúurú ilẹ̀, bínú sí ara wọn lẹ́nì kíní kejì. (Ìṣípayá 11:17, 18) Ní ti gidi, Ọlọrun lòdì sí Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà pẹ̀lú àwùjọ àlùfáà rẹ̀ tí a gbé ga, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí orílẹ̀-èdè Edomu ọlọ́kàn gíga. Nítorí náà, ó bá a mu pé kí Kirisẹ́ńdọ̀mù, Edomu amápẹẹrẹṣẹ náà, nímọ̀lára ìmúṣẹ òde òní ti Isaiah orí 34. Ìmúṣẹ yìí nípasẹ̀ ìparun pátápátá dájú ṣáká gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí nínú ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ lòdì sí Edomu ìgbàanì.—Ìṣípayá 18:4-8, 19-21.
5. Irú ìmúṣẹ wo ni Isaiah orí 35 ní ní àkókò wa?
5 Orí 35 ti àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah pẹ̀lú ìtẹnumọ́ rẹ̀ lórí ìdùnnú-ayọ̀ ńkọ́? Ìyẹn pẹ̀lú ti ní ìmúṣẹ ní àkókò wa. Báwo ni ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó ti ní ìmúṣẹ nínú ìmúpadàbọ̀sípò Israeli tẹ̀mí láti inú irú ìgbèkùn kan. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn òkodoro òtítọ́ náà yẹ̀ wò nínú ohun tí ó jẹ́ ìtàn àìpẹ́ yìí nípa ìṣàkóso Ọlọrun, tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò ìgbésí ayé àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ṣì ń bẹ láàyè.
6. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé, àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí kó sínú ipò ìgbèkùn?
6 Fún sáà kúkúrú, ní ìfiwéra, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí kò tí ì pa ara rẹ̀ mọ́ tónítóní látòkèdélẹ̀, kò sì wà ní ìṣọ̀kan pátápátá pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọrun. Ẹ̀kọ́ ìsìn èké ti kó àbàwọ́n bá àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì fi ipò wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́ nípa ṣíṣàìjẹ́ kí ìdúró wọn fún Jehofa ṣe kedere nígbà tí a fipá mú wọn láti ṣètìlẹyìn fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jagun. Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn tí ogun fi jà, wọ́n jìyà oríṣiríṣi inúnibíni, a tilẹ̀ ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn léèwọ̀ ní ibi púpọ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a dá díẹ̀ nínú àwọn arákùnrin tí ń mú ipò iwájú lẹ́bi, a sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn èké. Bí a bá ronú lórí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, kò ṣòro láti rí i pé, lọ́nà kan, àwọn ènìyàn Ọlọrun wà ní ipò ìgbèkùn, dípò kí wọ́n wà lómìnira. (Fi wé Johannu 8:31, 32.) Wọ́n kò ní ojú ìríran tẹ̀mí rárá. (Efesu 1:16-18) Wọ́n fi hàn pé àwọ́n ya odi dé ìwọ̀n àyè kan ní ti yíyin Ọlọrun, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, wọn kò méso jáde nípa tẹ̀mí. (Isaiah 32:3, 4; Romu 14:11; Filippi 2:11) O ha rí bí èyí ṣe bá ipò àwọn Júù ìgbàanì tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni mu bí?
7, 8. Irú ìmúpadàbọ̀sípò wo ni àṣẹ́kù ti òde òní nírìírí rẹ̀?
7 Ṣùgbọ́n, Ọlọrun yóò ha fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní sílẹ̀ nínú ipò yẹn bí? Rárá, ó ti pinnu láti mú wọn padà bọ̀ sípò, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ nípasẹ̀ Isaiah. Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yìí ní orí 35 ní ìmúṣẹ tí ó yàtọ̀ gédégbé ní àkókò wa, pẹ̀lú ìmúpadàbọ̀sípò àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí sí aásìkí àti ìlera nínú paradise tẹ̀mí kan. Ní Heberu 12:12, Paulu lo Isaiah 35:3 lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ní kíkín ìpéye bí a ṣe lo apá yìí nípa tẹ̀mí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah lẹ́yìn.
8 Ní àwọn ọdún ẹ̀yìn ogun, àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró ti Israeli tẹ̀mí jáde wá láti ìgbèkùn, gẹ́gẹ́ bí a ti lè pè é. Jehofa Ọlọrun lo Jesu Kristi, Kirusi Títóbi Jù, láti dá wọn nídè. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún àṣẹ́kù náà láti ṣiṣẹ́ àtúnkọ́, èyí tí a lè fi wé iṣẹ́ tí àṣẹ́kù àwọn Júù ìgbàanì ṣe, àwọn tí wọ́n padà sí ilẹ̀ wọn láti ṣe àtúnkọ́ tẹ́ḿpìlì gidi náà tí ó wà ní Jerusalemu. Síwájú sí i, àwọn ọmọ Israeli tẹ̀mí yìí ní àkókò òde òní lè bẹ̀rẹ̀ sí í roko, kí wọ́n sì mú paradise tẹ̀mí títutù yọ̀yọ̀, ọgbà Edeni ìṣàpẹẹrẹ jáde.
9. Báwo ni irú ohun tí a ṣàpèjúwe ni Isaiah 35:1, 2, 5-7 ṣe jẹ yọ ní àkókò wa?
9 Pẹ̀lú ohun tí a mẹ́nu kàn lókè yìí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ kí a gbé Isaiah orí 35 yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i, kí a sì wo ẹsẹ 1 àti 2. Ohun tí ó ti jọ ilẹ̀ gbígbẹ tẹ́lẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í di ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú ní tòótọ́, tí ó sì ti ń mú èso jáde bíi pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣaroni ìgbàanì. Nígbà náà, wo ẹsẹ 5 sí 7. Àṣẹ́kù náà, tí díẹ̀ nínú wọ́n ṣì wà láàyè, tí wọ́n sì jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa, ni a ti la ojú ìlóye wọn. Wọ́n lè túbọ̀ lóye ìtumọ̀ àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1914 àti lẹ́yìn náà. Ìyẹn pẹ̀lú ti ní ipa lórí púpọ̀ nínú wa tí a para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí a ń ṣiṣẹ́ sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àṣẹ́kù náà nísinsìnyí.—Ìṣípayá 7:9.
Ìwọ́ Ha Jẹ́ Apá Kan Ìmúṣẹ Náà Bí?
10, 11. (a) Báwo ni ìmúṣẹ Isaiah 35:5-7 ṣe kàn ọ́? (b) Kí ni ìmọ̀lára ìwọ fúnra rẹ nípa àwọn ìyípadà wọ̀nyí?
10 Fi ara rẹ ṣe àpẹẹrẹ. Ṣáájú kí o tó mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, o ha máa ń ka Bibeli déédéé bí? Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ni òye rẹ ti tó? Fún àpẹẹrẹ, nísinsìnyí, o ti wá mọ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà. Bóyá o lè tọ́ka ẹnì kan tí ó lọ́kàn ìfẹ́ nínú ọ̀ràn náà sí àwọn ẹsẹ tí ó ṣe wẹ́kú nínú Genesisi orí 2, Oniwasu orí 9, àti Esekieli orí 18, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹsẹ ìwé mímọ́ mìíràn. Àní, ó ṣeé ṣe kí o lóye ohun tí Bibeli kọ́ni lórí ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́ tàbí ọ̀rọ̀ míràn. Ní ṣókí, Bibeli ní ìtumọ̀ sí ọ, o sì lè ṣàlàyé ohun púpọ̀ nínú rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí o ti ń ṣe dájúdájú.
11 Ṣùgbọ́n, ó dára kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe kọ́ gbogbo ohun tí mo mọ̀ nípa òtítọ́ Bibeli? Ṣáájú kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jehofa, mo ha mọ ibi tí gbogbo ẹsẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn wọ̀nyẹn wà bí? Mo ha lóye wọn, tí mo sì ti dé orí ìparí èrò títọ́, ní ti ohun tí wọ́n túmọ̀ sí bí?’ Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn tí kò fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò yẹ kí ẹnì kan bínú nítorí irú gbólóhùn yẹn, ṣùgbọ́n, a lè sọ pé ní ti gidi ojú rẹ fọ́ sí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí àti ìtumọ̀ wọn. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Wọ́n wà níbẹ̀ nínú Bibeli, ṣùgbọ́n, kò ṣeé ṣe fún ọ láti rí wọn tàbí láti lóye ìjẹ́pàtàkì wọn. Nígbà náà, báwo ni a ṣe la ojú rẹ nípa tẹ̀mí? Ó jẹ́ nípa ohun tí Jehofa ti ṣe, ní mímú Isaiah 35:5 ṣẹ sórí àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, a la ojú rẹ. O kò sí nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí mọ́. O ń ríran.—Fi wé Ìṣípayá 3:17, 18.
12. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àkókò yìí kì í ṣe àkókò fún iṣẹ́ ìyanu oníwòsàn nípa ti ara? (b) Báwo ni ọ̀ràn Arákùnrin F. W. Franz ṣe ṣàkàwé ọ̀nà tí Isaiah 35:5 fi ń ní ìmúṣẹ ní àkókò wa?
12 Àwọn ọ̀jáfáfá akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò ìbálò Ọlọrun jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, mọ̀ pé àkókò kọ́ nìyí nínú ìtàn, fún iṣẹ́ ìyanu oníwòsàn nípa ti ara. (1 Korinti 13:8-10) Nítorí náà, a kò retí pé kí Jesu Kristi máa la àwọn ojú tí ó ti fọ́, láti lè fi ẹ̀rí hàn pé òun ni Messia náà, Wòlíì Ọlọrun. (Johannu 9:1-7, 30-33) Bẹ́ẹ̀ sì ni òun kò mú kí gbogbo adití tún gbọ́ran. Bí Frederick W. Franz, ọ̀kan lára àwọn ẹni-àmì-òróró, tí ó sì jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society tẹ́lẹ̀ rí, ṣe ń sún mọ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í dùn ún, ó sì ní láti lo ẹ̀rọ ìgbọ́ràn. Fún àwọn ọdún díẹ̀, òun kò ríran kàwé mọ́; síbẹ̀, ta ni ó lè kà á sí afọ́jú tàbí adití ní èrò ohun tí ó túmọ̀ sí níhìn-ín ní Isaiah 35:5? Ojú ìríran tẹ̀mí rẹ̀ tí ó dá ṣáká, jẹ́ ìbùkún fún àwọn ènìyàn Ọlọrun kárí ayé.
13. Ìyípadà tàbí ìmúpadàbọ̀sípò wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun lóde òní nírìírí rẹ̀?
13 Ahọ́n rẹ ńkọ́? Àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọrun lè ti ya odi nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, gbàrà tí Ọlọrun yí ipò náà padà, ahọ́n wọn bẹ̀rẹ̀ sì í ké jáde fún ayọ̀ nípa ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, àti àwọn ìlérí rẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. Wọ́n ti lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tú ahọ́n rẹ pẹ̀lú. Báwo ni o ti ń sọ òtítọ́ Bibeli fún àwọn ẹlòmíràn tó ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá? Bóyá ní sáà kan, o ronú pé, ‘Mo gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n n kò ní jáde lọ bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ láé.’ Ṣùgbọ́n, kò ha jẹ́ òtítọ́ pé “ahọ́n odi” ‘ń kọrin’ nísinsìnyí ‘fún ayọ̀’ bí?—Isaiah 35:6.
14, 15. Báwo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ṣe rìn ní “Ọ̀nà ìwà mímọ́” ní àkókò wa?
14 Àwọn Júù ìgbàanì, tí a dá nídè kúrò ní Babiloni, rin ọ̀nà jíjìn padà sí ilẹ̀ wọn. Kí ni ìyẹn bá dọ́gba ní àkókò wa? Tóò, wo Isaiah 35:8: “Òpópó kan yóò sì wà níbẹ̀, àti ọ̀nà kan, a óò sì máa pè é ní, Ọ̀nà ìwà mímọ́; aláìmọ́ kì yóò kọjá níbẹ̀.”
15 Láti ìgbà tí a ti dá wọn sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn míràn ń tẹ̀ lé nísinsìnyí, ti jáde kúrò nínú Babiloni Ńlá sí ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ kan, ọ̀nà mímọ́ tónítóní tí ń sinni lọ sí paradise tẹ̀mí. A ń sa gbogbo ipá wa láti tóótun, kí a sì wà ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́ yìí. Ronú nípa ara rẹ ná. Àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù rẹ àti àwọn ìlànà tí o dì mú kò ha ga nísinsìnyí ju ti ìgbà tí o wà nínú ayé lọ bí? Ìwọ kò ha túbọ̀ ń sapá gidigidi láti mú ìrònú àti ìwà rẹ bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun mu bí?—Romu 8: 12, 13; Efesu 4:22-24.
16. Àwọn ipò wo ni a lè gbádùn bí a ṣe ń rìn ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́?
16 Bí o ṣe ń bá a lọ lójú Ọ̀nà Ìwà Mímọ́ yìí, ìwọ ní ti gidi kò fòyà nípa àwọn ènìyàn oníwà-bí-ẹranko. Òtítọ́ ni pé, nínú ayé, o ní láti wà lójúfò kí àwọn ènìyàn oníwọra tàbí ẹlẹ́mìí ìkórìíra má baà jẹ ọ́ ní tútù ní èdè ìṣàpẹẹrẹ. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ jẹ́ olójúkòkòrò nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn lò. Wo bí ọ̀ràn náà ti yàtọ̀ pátápátá tó láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun! Níbẹ̀, o wà ní àyíká tí a ti dáàbò bò ọ́. Àmọ́ ṣáá o, àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin rẹ kì í ṣe ẹni pípé; nígbà míràn, ẹnì kan lè ṣe àṣìṣe tàbí mú ọ bínú. Ṣùgbọ́n, o mọ̀ pé àwọn arákùnrin rẹ kì í mọ̀ọ́mọ̀ gbìyànjú láti mú ọ bínú tàbí fẹ́ jẹ ọ́ ní tútù. (Orin Dafidi 57:4; Esekieli 22:25; Luku 20:45-47; Ìṣe 20:29; 2 Korinti 11:19, 20; Galatia 5:15) Dípò èyí, wọ́n ń fi ọkàn ìfẹ́ hàn sí ọ; wọ́n ti ràn ọ́ lọ́wọ́; wọ́n sì fẹ́ ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú rẹ.
17, 18. Ní ọ̀nà wo ni paradise kan fi wà nísinsìnyí, kí sì ni ipa tí èyí ní lórí wa?
17 Nítorí náà, a lè wo Isaiah orí 35, kí a sì ní ìmúṣẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ ti ẹsẹ 1 sí 8 lọ́kàn. Kò ha ṣe kedere pé, a ti rí ohun tí a fi ẹ̀tọ́ pè ní paradise tẹ̀mí bí? Rárá o, kò pé pérépéré—ó ṣì kù díẹ̀. Ṣùgbọ́n paradise ni ní tòótọ́, nítorí pé bí ẹsẹ 2 ti sọ, a lè “rí ògo Oluwa, àti ẹwà Ọlọrun wa” níhìn-ín nísinsìnyí. Kí sì ni àbájáde rẹ̀? Ẹsẹ 10 sọ pé: “Àwọn ẹni ìràpadà Oluwa yóò padà, wọn óò wá sí Sioni ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn: wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí-ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.” Ní tòótọ́, jíjáde tí a jáde kúrò nínú ìsìn èké, tí a sì ń lépa ìjọsìn tòótọ́ lábẹ́ ojú rere Ọlọrun jẹ́ èyí tí ń mú ìdùnnú-ayọ̀ wá.
18 Ìdùnnú-ayọ̀ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ ń bá a lọ láti máa pọ̀ sí i, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? O ń rí àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ń ṣe ìyípadà, tí wọ́n sì ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́ Bibeli. O ń kíyè sí àwọn èwe tí ń dàgbà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Àwọn ìbatisí, tí o ti ń rí àwọn ènìyàn tí o mọ̀, tí ń ṣe batisí máa ń wà. Àwọn wọ̀nyí kì í ha ṣe ìdí fún ìdùnnú-ayọ̀, fún ọ̀pọ̀ jaburata ìdùnnú-ayọ̀ lónìí bí? Àní, ẹ wo ìdùnnú-ayọ̀ ńlá tí ó jẹ́ láti mú kí àwọn mìíràn dara pọ̀ mọ́ wa nínú òmìnira tẹ̀mí àti ipò tí ó dà bíi paradise!
Ìmúṣẹ Kan Ṣì Wà Níwájú!
19. Ìrètí dídájú wo ni Isaiah orí 35 fi kún ọkàn wa?
19 Gbogbo ohun tí a ti gbé yẹ̀ wò títí di ìsinsìnyí nínú Isaiah orí 35, ní í ṣe pẹ̀lú ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ lórí ìpadà àwọn Júù àti ìmúṣẹ tẹ̀mí tí ń lọ lọ́wọ́ lónìí. Ṣùgbọ́n kò pin síbẹ̀. Púpọ̀ sí i ṣì wà. Ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìmúdánilójú tí Bibeli ṣe nípa ìmúpadàbọ̀sípò ipò paradise ní ti gidi lórí ilẹ̀ ayé.—Orin Dafidi 37:10, 11; Ìṣípayá 21:4, 5.
20, 21. Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu, tí ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu láti gbà gbọ́ pé, ìmúṣẹ mìíràn nípa Isaiah orí 35 yóò ṣì tún wà?
20 Kò ní wà déédéé fún Jehofa láti pèsè àwọn àpèjúwe tí ó kún rẹ́rẹ́ nípa paradise kan, síbẹ̀ kí ó wá fi ìmúṣẹ rẹ̀ mọ sí àwọn ohun tẹ̀mí nìkan. Àmọ́ ṣáá o, èyí kò túmọ̀ sí pé, àwọn ìmúṣẹ nípa tẹ̀mí náà kò ṣe pàtàkì. Àní bí a bá gbé paradise kan ní ti gidi kalẹ̀, kò ní tẹ́ wa lọ́rùn bí àwọn ènìyàn oníwà ìbàjẹ́ nípa tẹ̀mí, àwọn ẹ̀dá ènìyàn oníwà-bí-ẹranko ẹhànnà bá yí wa ká nínú ipò ẹlẹ́wà àti láàárín àwọn ẹranko oníwà tútù. (Fi wé Titu 1:12.) Àní, tẹ̀mí gbọ́dọ̀ ṣáájú, nítorí pé òun ni ó ṣe pàtàkì jù lọ.
21 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò fi Paradise tí ń bọ̀ mọ sórí kìkì apá tẹ̀mí tí a ń gbádùn rẹ̀ lọ́wọ́, tí a óò sì túbọ̀ gbádùn síwájú sí i ní ọjọ́ iwájú. A ní ìdí tí ó dára láti retí ìmúṣẹ ní ti gidi ti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ irú èyí tí ó wà ní Isaiah orí 35. Èé ṣe? Tóò, Isaiah sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa awọn “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” kan ní orí 65. Aposteli Peteru lo ẹsẹ ìwé mímọ́ yẹn, nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ohun tí ó tẹ̀ lé ọjọ́ Jehofa. (Isaiah 65:17, 18; 2 Peteru 3:10-13) Peteru ń fi hàn pé àwọn ẹ̀ka tí Isaiah ṣàpèjúwe yóò ní ìmúṣẹ ní ti gidi nígbà tí “ayé tuntun” bá ní ìmúṣẹ. Ìyẹn ní àwọn àpèjúwe tí o mọ̀ dunjú nínú—kíkọ́ ilé àti gbígbé inú wọn; gbígbin ọgbà àjàrà àti jíjẹ èso wọn; jíjẹ adùn iṣẹ́ ọwọ́ ẹni fún ìgbà pípẹ́ títí; rírí ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn tí ń gbé pọ̀; tí ewu kankan kò sì ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ní èdè míràn, ẹ̀mí gígùn, ilé aláàbò, oúnjẹ púpọ̀ jaburata, iṣẹ́ tí ń tẹ́ni lọ́rùn, àti àlááfíà láàárín àwọn ẹranko àti láàárín ẹranko sí ẹ̀dá ènìyàn.
22, 23. Ìdí wo fún ìdùnnú-ayọ̀ ni yóò wà, nínú ìmúṣẹ ọjọ́ iwájú nípa Isaiah orí 35?
22 Ìrètí yẹn kò ha fi ìdùnnú-ayọ̀ kún ọkàn rẹ bí? Ó yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, nítorí bí Ọlọrun ti dá wa kí a máa gbé nìyẹn. (Genesisi 2:7-9) Nítorí náà, kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà ní Isaiah orí 35, tí a ń gbé yẹ̀ wò túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé, a ní ìdí púpọ̀ sí i láti ké jáde fún ìdùnnú-ayọ̀. Àwọn aṣálẹ̀ àti ilẹ̀ gbígbẹ ní ti gidi yóò di ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú, ní fífún wa ní ìdí láti yọ̀. Nígbà náà, yóò ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ẹyinjú aláwọ̀ búlúù tàbí aláwọ̀ ilẹ̀, tàbí àwọn àwọ̀ míràn tí ó dára, ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú nísinsìnyí, láti ríran. Àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n dití tàbí àwọn kan nínú wa pàápàá tí wọn kò gbọ́ràn dáradára, yóò lè gbọ́ràn dáradára. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìdùnnú-ayọ̀ tó láti lo agbára ìgbọ́ràn yẹn láti gbọ́ bí a ti ń kà, tí a sì ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kí wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí ìró afẹ́fẹ́ orí igi, ẹ̀rín ọmọdé, orin ẹyẹ!
23 Yóò tún túmọ̀ sí pé, àwọn arọ, títí kan àwọn tí àrùn oríkèé ríro ń bá jà nísinsìnyí, yóò rìn kiri láìsí ìrora. Ẹ wo irú ìtura tí èyí yóò jẹ́! Nígbà náà, ìṣàn omi ní ti gidi yóò tú jáde ní aṣálẹ̀. Gbogbo wa yóò sì rí omi tí ń ru gùdù, a óò sì gbọ́ ìró híhó rẹ̀. Yóò ṣeé ṣe fún wa láti rìn níbẹ̀, kí a sì fọwọ́ kan àwọn ewéko títutù yọ̀yọ̀ àti àwọn irúgbìn pápírọ́ọ̀sì. Ní tòótọ́, Paradise tí a mú padà bọ̀ sípò ni yóò jẹ́. Ìdùnnú-ayọ̀ tí a óò rí nínú wíwà pẹ̀lú kìnnìún tàbí irú ẹranko bẹ́ẹ̀ láìfòyà ńkọ́? A kò tún gbọ́dọ̀ máa sọ ìyẹn, nítorí pé gbogbo wa ni ó ti fọkàn yàwòrán ìyẹn tẹ́lẹ̀.
24. Èé ṣe tí o fi lè fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó wà ní Isaiah 35:10?
24 Isaiah mú un dá wa lójú pé: “Àwọn ẹni ìràpadà Oluwa yóò padà, wọn óò wá sí Sioni ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn.” Nítorí náà, a lè fohùn ṣọ̀kan pé, a ní ìdí láti ké jáde fún ìdùnnú-ayọ̀. Ìdùnnú-ayọ̀ lórí ohun tí Jehofa ń ṣe nísinsìnyí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú paradise tẹ̀mí tí ó jẹ́ tiwa, àti ìdùnnú-ayọ̀ lórí ohun tí a lè retí nínú Paradise gidi tí ó kù sí dẹ̀dẹ̀. Nípa àwọn onídùnnú-ayọ̀—nípa wa—Isaiah kọ̀wé pé: “Wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí-ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.”—Isaiah 35:10.
Ìwọ́ Ha Ṣàkíyèsí Bí?
◻ Ìmúṣẹ kejì wo ni Isaiah orí 35 ní?
◻ Nípa tẹ̀mí, kí ni ó bá ìyípadà lọ́nà iṣẹ́ ìyanu ti Isaiah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ mu?
◻ Báwo ni o ti ṣe nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí?
◻ Èé ṣe tí a fi lè sọ pé, Isaiah orí 35 fi ìrètí fún ọjọ́ iwájú kún ọkàn wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọgbà ẹ̀wọ̀n Òpópónà Raymond ní Brooklyn, New York, níbi ti a há àwọn arákùnrin méje tí wọ́n yọrí ọlá mọ́ ní June 1918
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í dùn ún nígbà tí ọjọ́ ogbó dé sí i, ojú ìríran Arákùnrin Franz nípa tẹ̀mí ríran kedere
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìdàgbàsókè àti ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí jẹ́ àwọn ìdí fún ìdùnnú-ayọ̀