Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
“Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo.”—AÍSÁ. 26:4.
1. Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi yàtọ̀ sáwọn èèyàn tó wà nínú ayé?
À Ń GBÉ nínú ayé kan tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ò ti mọ ẹni tí wọ́n lè gbẹ́kẹ̀ lé mọ́ tí wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè kà sí òótọ́. Èyí sì lè jẹ́ torí pé ẹnì kan ti ṣèpalára fún wọn tàbí kí wọ́n ti já wọn kulẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n tàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ o! Torí pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí wọn, wọ́n mọ̀ pé kò yẹ káwọn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ayé yìí tàbí nínú “àwọn ọ̀tọ̀kùlú.” (Sm. 146:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà lè pa ìwàláàyè àwọn mọ́ ó sì lè mú kí ọjọ́ ọ̀la àwọn dára, torí pé wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn àti pé gbogbo ìgbà ló máa ń mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.—Róòmù 3:4; 8:38, 39.
2. Báwo ni Jóṣúà ṣe jẹ́ ká rí i pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?
2 Ọ̀rọ̀ tí Jóṣúà ìgbàanì sọ jẹ́ ká rí i pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Nígbà tí Jóṣúà ti di arúgbó, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.”—Jóṣ. 23:14.
3. Kí ni orúkọ Ọlọ́run fi hàn nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́?
3 Jèhófà máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti pàápàá jù lọ nítorí orúkọ rẹ̀. (Ẹ́kís. 3:14; 1 Sám. 12:22) Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Bíbélì The Emphasized Bible, látọwọ́ J. B. Rotherham sọ nípa orúkọ Ọlọ́run pé: “[Ó] dúró fún ìlérí tó fi inúure Ọlọ́run hàn; ẹ̀rí tó dájú pé ipò yòówù kó yọjú, ìṣòro tàbí ohun àìròtẹ́lẹ̀ èyíkéyìí tí ì báà wáyé, agbára Ọlọ́run ká a . . . [Orúkọ náà] jẹ́ ìlérí, . . . ìṣípayá, ìrántí àti ẹ̀jẹ́. Ọlọ́run kò sì ní í ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí Orúkọ náà dúró fún láé; bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run kò ní tijú orúkọ rẹ̀.”
4. (a) Kí ni Aísáyà 26:4 gbà wá níyànjú láti ṣe? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo mọ Jèhófà dunjú débi tí mo fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú rẹ̀? Ǹjẹ́ mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sí ohun tó kọjá agbára Ọlọ́run?’ Ìwé Aísáyà 26:4 sọ pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin wà.” Òótọ́ ni pé, ní báyìí, Ọlọ́run kì í dá sí ọ̀ràn ìgbésí ayé àwọn èèyàn mọ́ bó ti ṣe láwọn ìgbà kan ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Síbẹ̀, torí pé ó jẹ́ “Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin” a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ “ní ìgbà gbogbo.” Báwo ni Ọlọ́run wa tó ṣeé gbára lé ṣe ń ran àwọn tó ń fòótọ́ sìn ín lọ́wọ́ lónìí? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀: Ó máa ń fún wa lókun nígbà tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú ìdẹwò, ó máa ń tì wá lẹ́yìn bá a bá ní láti fara da ẹ̀mí ìdágunlá tàbí àtakò ní tààràtà, ó sì máa ń gbé wa ró nígbà tá a bá ń ṣàníyàn. Bá a ṣe ń gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò, máa ronú lórí ọ̀nà tó o lè gbà mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní nínú Jèhófà lágbára.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Bó O Bá Dojú Kọ Ìdẹwò Láti Ṣe Ohun Tí Kò Tọ́
5. Kí ló lè dán bí ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Ọlọ́run ṣe lágbára tó wò?
5 Ohun kan ni pé kéèyàn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà látàrí ìlérí tó ṣe nípa Párádísè tàbí àjíǹde, èyí tó jẹ́ àwọn nǹkan tí gbogbo wa ń yán hànhàn fún. Àmọ́, ohun míì tó yàtọ̀ pátápátá ló jẹ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlànà tó gbé kalẹ̀ nípa irú ìwà tó yẹ ká máa hù, ìyẹn ni pé ká gbà nínú ọkàn wa pé rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ ni ohun tó tọ́ àti ohun tó máa mú ká ní ayọ̀ tó ga jù lọ. Sólómọ́nì Ọba ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìṣílétí yìí pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Kíyè sí i pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “ọ̀nà” àti “ipa ọ̀nà.” Èyí fi hàn pé kì í wulẹ̀ ṣe tó bá dọ̀ràn ìrètí tá a ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni nìkan la gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, a tún gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e nínú gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ ìwàláàyè wa. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e nígbà ìdẹwò?
6. Báwo la ṣe lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu tá a bá ṣe pé a kò ní fàyè gba èrò búburú?
6 Bá a bá fẹ́ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú àfi ká kọ́kọ́ yí ìrònú wa pa dà. (Ka Róòmù 8:5; Éfésù 2:3.) Nígbà náà, báwo lo ṣe lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu tó o ṣe pé o kò ní fàyè gba èrò búburú? Ronú lórí àwọn ọ̀nà márùn-ún yìí: 1. Wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà. (Mát. 6:9, 13) 2. Ṣe àṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó dá lórí àwọn tó kùnà láti fetí sí Jèhófà àtàwọn tó fetí sí i. Lẹ́yìn náà, kíyè sí ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí fún wọn.a (1 Kọ́r. 10:8-11) 3. Ronú lórí ìpalára ti ọpọlọ àti ti ìmí ẹ̀dùn tí ẹ̀ṣẹ̀ lè fà fún ẹ àtàwọn tó sún mọ́ ẹ. 4. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára Ọlọ́run bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. (Ka Sáàmù 78:40, 41.) 5. Ronú nípa bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó bá rí i pé ẹnì kan tó ń sin òun láìyẹsẹ̀ kọ ohun búburú sílẹ̀ tó sì ṣe ohun tó dára, yálà ní gbangba tàbí ní ìkọ̀kọ̀. (Sm. 15:1, 2; Òwe 27:11) Ìwọ náà lè fi hàn pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Bó O Bá Ní Láti Fara Da Ẹ̀mí Ìdágunlá àti Àtakò
7. Àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ wo ni Jeremáyà dojú kọ, báwo ló sì ṣe máa ń rí lára rẹ̀ nígbà míì?
7 Ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń sìn ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó ti pọn dandan pé kí wọ́n lo ìfaradà. Wòlíì Jeremáyà náà sìn lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, ìyẹn ní àwọn ọjọ́ oníyánpọnyánrin tó gbẹ̀yìn ìjọba Júdà. Ojoojúmọ́ ló ń dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́ torí pé ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run nípa kíkéde ìdájọ́ Rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Bárúkù, tó jẹ́ adúróṣinṣin àti akọ̀wé Jeremáyà pàápàá ṣàròyé pé agara ti dá òun. (Jer. 45:2, 3) Ǹjẹ́ Jeremáyà wá tìtorí ìyẹn rẹ̀wẹ̀sì? Òun náà máa ń sorí kọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ké jáde pé: “Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi! . . . Èé ti ṣe tí mo fi jáde wá láti inú ilé ọlẹ̀ náà láti rí iṣẹ́ àṣekára àti ẹ̀dùn-ọkàn, kí àwọn ọjọ́ mi sì wá sí òpin wọn nínú ìtìjú lásán-làsàn?”—Jer. 20:14, 15, 18.
8, 9. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Jeremáyà 17:7, 8 àti Sáàmù 1:1-3, kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa so èso rere?
8 Síbẹ̀, Jeremáyà kò juwọ́ sílẹ̀. Ó ń bá a nìṣó láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Nítorí èyí, wòlíì olóòótọ́ yìí rí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Jeremáyà 17:7, 8, pé: “Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀ tààrà lọ sẹ́bàá ipadò; òun kì yóò sì rí i nígbà tí ooru bá dé, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé yóò di èyí tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ti gidi. Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, òun kì yóò sì ṣàníyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò dẹ́kun mímú èso jáde.”
9 Bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ èyí tá a gbìn “sẹ́bàá ipadò” tàbí inú ọgbà ọ̀gbìn tí wọ́n ń bomi rin, Jeremáyà kò ‘dẹ́kun láti máa mú èso jáde.’ Kò fàyè gba àwọn afiniṣẹ̀sín ọ̀bàyéjẹ́ tó yí i ká láti nípa lórí rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹra mọ́ jíjọ́sìn Jèhófà tó jẹ́ Orísun “omi” tó ń gbé ìwàláàyè ró, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó bá sọ fún un. (Ka Sáàmù 1:1-3; Jer. 20:9) Àpẹẹrẹ rere mà ni Jeremáyà jẹ́ fún wa o, pàápàá jù lọ àwa tá à ń sin Ọlọ́run ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó nira! Bó bá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn, máa bá a nìṣó láti gbára lé Jèhófà pátápátá. Òun ló máa mú kó o lè fara dà á bó o ṣe ń “ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.”—Héb. 13:15.
10. Àwọn ìbùkún wo là ń rí gbà, kí ló sì yẹ ká bi ara wa?
10 Ká bàa lè kojú àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ti fún wa ní ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lódindi, èyí tá à ń túmọ̀ lọ́nà tó péye sí èdè tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ó tún ń lo ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti fún wa ní ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò. Ó sì tún ń mú ká ní ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró pẹ̀lú ògìdìgbó àwọn olùjọsìn bíi tiwa láwọn ìpàdé ìjọ àti láwọn àpéjọ. Ǹjẹ́ ò ń fi gbogbo àwọn ìpèsè yìí sílò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Gbogbo àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ “yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” Àmọ́, àwọn tó bá kùnà láti tẹ́tí sí Ọlọ́run “yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà” wọn yóò sì “hu nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.”—Aísá. 65:13, 14.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Bó O Bá Ń Ṣàníyàn
11, 12. Nítorí àwọn ìṣòro tó kún inú ayé, kí ló bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe?
11 Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ńṣe ni ìṣòro túbọ̀ ń ya lu aráyé bí àkúnya omi. (Mát. 24:6-8; Ìṣí. 12:12) Bí àkúnya omi gidi bá ṣẹlẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn sábà máa ń sáré lọ sí ibi tó ga tàbí kí wọ́n gun orí òrùlé lọ, tàbí kí wọ́n sá lọ sí ibi gíga èyíkéyìí. Bákan náà, bí ìṣòro ayé yìí ṣe ń peléke sí i, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń wá ààbò lọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó dà bí ibi gíga, èyí tó lè jẹ́ ti ìṣòwò, ti òṣèlú tàbí ti ìsìn, wọ́n sì tún máa ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí lára àwọn àjọ yìí tó lè fúnni ní ojúlówó ààbò. (Jer. 17:5, 6) Àmọ́, ó dájú pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ààbò tó dájú, ààbò yẹn ni Bíbélì pè ní “Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísá. 26:4) Onísáàmù náà sọ pé: “[Jèhófà] ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi.” (Ka Sáàmù 62:6-9.) Báwo la ṣe lè fi Àpáta yìí ṣe ààbò wa?
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jèhófà bá sọ máa ń sábàá ta ko ọgbọ́n èèyàn, ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló máa fi hàn pé a rọ̀ mọ́ ọn. (Sm. 73:23, 24) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ọgbọ́n èèyàn ń darí lè sọ pé: ‘O kò lè gbé ayé lẹ́ẹ̀mejì; kúkú jayé orí ẹ kó o tó máa lọ.’ ‘Wá iṣẹ́ tó dáa ṣe.’ ‘Kó owó jọ rẹpẹtẹ.’ ‘Ra tibí, ra tọ̀hún.’ ‘Máa gbafẹ́ kiri; jayé bó ṣe wù ẹ́.’ Àmọ́, ìmọ̀ràn tó fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn sọ pé: “[Kí] àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́r. 7:31) Bákan náà, Jésù gbà wá níyànjú pé ká fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní ká sì tipa bẹ́ẹ̀ to “ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara [wa] ní ọ̀run,” níbi tó dájú pé kò sí ohunkóhun tó lè bà á jẹ́.—Mát. 6:19, 20.
13. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí 1 Jòhánù 2:15-17 sọ, kí la gbọ́dọ̀ bi ara wa?
13 Ǹjẹ́ ojú tó o fi ń wo “ayé” àti “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” fi hàn pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run? (1 Jòh. 2:15-17) Ṣé ọrọ̀ tẹ̀mí àti àwọn àǹfààní tó rọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run ló máa ń wù ẹ́ jù, ṣé wọ́n sì ṣe pàtàkì lójú rẹ ju àwọn nǹkan tí ayé lè fúnni lọ? (Fílí. 3:8) Ṣé ò ń sapá láti máa ní ‘ojú tó mú ọ̀nà kan’? (Mát. 6:22) Ọlọ́run kò fẹ́ kó o hùwà òmùgọ̀ tàbí kó o máa ṣe bí ẹni tí kò mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, pàápàá jù lọ bí ìdílé bá wà tí o ní láti bójú tó. (1 Tím. 5:8) Síbẹ̀, ó fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun gbẹ́kẹ̀ lé òun ní kíkún kí wọ́n má sì ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ayé Sátánì tó ń kú lọ yìí.—Héb. 13:5.
14-16. Àǹfààní wo làwọn kan ti rí nínú jíjẹ́ kí ‘ojú wọ́n mú ọ̀nà kan’ àti fífi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní?
14 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Richard àti Ruth, tí wọ́n ní ọmọ mẹ́ta. Richard sọ pé: “Ọkàn mi ń sọ fún mi pé mo lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mo rí towó ṣe, àmọ́ ńṣe ló dà bíi pé iṣẹ́ ìsìn gbà-máà-póò-rọ́wọ́ mi ni mò ń ṣe. Lẹ́yìn tí mo ti fi ọ̀rọ̀ náà sínú àdúrà tí mo sì gbéṣirò lé e, èmi àti Ruth gbà pé kí n kúkú sọ fún ọ̀gá mi níbi iṣẹ́ pé kó dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù sí ọjọ́ mẹ́rin lọ́sẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò ìṣúnná owó orílẹ̀-èdè náà kò lọ déédéé. Ọ̀gá mi gbà fún mi. Láàárín oṣù kan mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́sẹ̀.” Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Richard?
15 Richard sọ pé: “Owó oṣù mi dín sí iye tí mò ń gbà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí àádọ́ta [50] ọjọ́ ló ṣí sílẹ̀ fún mi lọ́dún tí mo fi ń wà pẹ̀lú ìdílé mi tí mo sì fi ń kọ́ àwọn ọmọ mi. Ní báyìí, àkókò tí mò ń lò lóde ẹ̀rí ti di ìlọ́po méjì, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi ti di ìlọ́po mẹ́ta, mo sì ti ń múpò iwájú sí i jù ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú ìjọ. Níwọ̀n bí mo sì ti máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti bójú tó àwọn ọmọ nínú ilé, Ruth máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòrèkóòrè. Tí mo bá ṣì ní àǹfààní rẹ̀, mo ti pinnu láti máa ṣiṣẹ́ nìṣó lọ́nà yìí.”
16 Ó ti ṣeé ṣe fún Roy àti Petina tí wọ́n ṣì ń tọ́mọ lọ́wọ́ láti dín àkókò tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù kí wọ́n lè máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Roy sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni mo máa ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀, Petina sì ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀mejì.” Bákan náà, a kó lọ sínú ilé tó kéré sí èyí tá à ń gbé tẹ́lẹ̀ tó sì túbọ̀ rọrùn fún wa láti bójú tó. A ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ká tó bí ọmọ wa ọkùnrin àti obìnrin, síbẹ̀ a ṣì nífẹ̀ẹ́ láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó. Torí náà, nígbà tí àwọn ọmọ wa dàgbà, a pa dà sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Kò sí iye owó tá a lè fi wé ìbùkún tá a ti rí gbà.”
Jẹ́ Kí “Àlàáfíà Ọlọ́run” Máa Ṣọ́ Ọkàn-Àyà Rẹ
17. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé àìdánilójú là ń gbé, ìtùnú wo lo ti rí gbà nínú Ìwé Mímọ́?
17 Kò sí ẹni tó mọ ilẹ̀ tó máa mọ́ ọ̀la nínú wa, torí pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníw. 9:11) Àmọ́, ti pé a kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la kò sọ pé kí ìdààmú bá wa ní báyìí, kí ọ̀rọ̀ wa má bàa dà bíi ti àwọn tí ẹ̀rù máa ń bà torí pé wọn kò ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. (Mát. 6:34) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”—Fílí. 4:6, 7.
18, 19. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ń gbà tù wá nínú? Ṣàpèjúwe.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún máa ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti àlàáfíà tí Jèhófà máa ń fúnni. Arábìnrin kan sọ pé: “Dókítà oníṣẹ́ abẹ kan gbìyànjú léraléra láti dẹ́rù bà mí kí n lè gba ẹ̀jẹ̀. Tó bá ti rí mi, ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ máa ń jáde lẹ́nu rẹ̀ kì í dáa. Á sọ pé, ‘Èwo tiẹ̀ ni gbogbo ìranù kéèyàn máà fẹ́ láti gbẹ̀jẹ̀ yìí?’ Bó bá ti sọ bẹ́ẹ̀ tán àti láwọn ìgbà míì, mo máa ń gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí Jèhófà, àlàáfíà Rẹ̀ á sì mára tù mí. Ọkàn mi á le gbagidi bí àpáta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìtó ẹ̀jẹ̀ ti mú kó rẹ̀ mí, ó máa ń ṣeé ṣe fún mi láti fi Ìwé Mímọ́ ṣe àlàyé kedere nípa ìdí tí mi ò fi ní gba ẹ̀jẹ̀.”
19 Nígbà míì, Ọlọ́run lè fún wa ní ìtìlẹ́yìn tá a nílò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtùnú tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá sọ tàbí nípasẹ̀ oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ó ṣeé ṣe kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti sọ fún ẹ rí pé: “Ohun tí mo nílò gan-an ló wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Torí tèmi gan-an ni wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde!” Láìka ipò yòówù ká bá ara wa sí tàbí ohun yòówù tó jẹ́ àìní wa, ó dájú pé Jèhófà máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé e. Ó ṣe tán, “àgùntàn” rẹ̀ ni wá, a sì ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn.—Sm. 100:3; Jòh. 10:16; Ìṣe 15:14, 17.
20. Kí nìdí tí àwọn èèyàn Jèhófà yóò fi máa gbé nínú ààbò nígbà tí ayé Sátánì bá wá sí òpin rẹ̀?
20 Ní “ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà,” gbogbo nǹkan tí ayé Sátánì gbẹ́kẹ̀ lé pátá ló máa fọ́ yángá. Wúrà, fàdákà àtàwọn ohun iyebíye míì kò ní pèsè ààbò èyíkéyìí fún wọn. (Sef. 1:18; Òwe 11:4) Ààbò kan ṣoṣo tó máa wà ni “Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin” wa. (Aísá. 26:4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn ní báyìí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, nípa jíjẹ́ onígbọràn tí ń rìn nínú àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀, nípa pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bó bá tiẹ̀ gba pé ká fara da ẹ̀mí ìdágunlá tàbí àtakò àti nípa yíyí àwọn àníyàn wa lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bá a ti ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé a ó máa ‘gbé nínú ààbò, a ó sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.’—Òwe 1:33.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
Báwo la ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run
• bí a bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́?
• bí a bá ní láti fara da ẹ̀mí ìdágunlá àti àtakò?
• bí a bá ń ṣàníyàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
A máa láyọ̀ bá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
“Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin”