Ẹ Wà Lójúfò Bíi Ti Jeremáyà
“[Èmi Jèhófà] wà lójúfò nípa ọ̀rọ̀ mi láti mú un ṣẹ.”—JER. 1:12.
1, 2. Kí nìdí tí Bíbélì fi fi ‘wíwà lójúfò’ Jèhófà wé igi álímọ́ńdì?
LÓRÍ àwọn òkè ní ilẹ̀ Lẹ́bánónì àti ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ojú ọjọ́ máa ń tutù nini nínú oṣù January àti February. Kò sí igi tó ń yọ òdòdó láàárín ìgbà yẹn. Àmọ́ igi álímọ́ńdì máa ń yọ òdòdó ní tirẹ̀. Òdòdó náà máa ń ní àwọ̀ osùn àti àwọ̀ funfun. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi tó kọ́kọ́ máa ń yọ òdòdó kí ojú ọjọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbóná. Nítorí náà, ní olówuuru, orúkọ igi náà lédè Hébérù túmọ̀ sí “òjíkùtù.”
2 Nígbà tí Jèhófà yan Jeremáyà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì rẹ̀, Ọlọ́run fi bí igi álímọ́ńdì ṣe tètè máa ń mú òdòdó jáde yìí ṣàkàwé ohun pàtàkì kan. Nígbà tí wòlíì Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Ọlọ́run fi èéhù igi náà hàn án nínú ìran. Kí ló túmọ̀ sí? Jèhófà ṣàlàyé pé: “Mo wà lójúfò nípa ọ̀rọ̀ mi láti mú un ṣẹ.” (Jer. 1:11, 12) Bí igi álímọ́ńdì ṣe tètè máa ń mú òdòdó jáde ní kùtùkùtù tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe tètè máa ń sọ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́ kí wọ́n lè kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn bí wọ́n bá ṣàìgbọràn. (Jer. 7:25) Kò sì ní sinmi, ó máa “wà lójúfò,” títí tí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fi máa nímùúṣẹ. Ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní àkókò náà gan-an tí Jèhófà ti pinnu, ó mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí orílẹ̀-èdè Júdà tó ti di apẹ̀yìndà.
3. Ìdánilójú wo la lè ní nípa Jèhófà?
3 Bákan náà, lónìí, Jèhófà wà lójúfò, ó sì ṣe tán láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Kò sí bí kò ṣe ní mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Báwo ni ìmúratán Jèhófà yìí ṣe kàn ẹ́? Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé nínú ọdún 2011 tá a wà yìí, Jèhófà ṣì “wà lójúfò” láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Bá a bá ń ṣiyè méjì nípa àwọn ìlérí Jèhófà tí kì í kùnà, tá a sì ti ń tòògbé nípa tẹ̀mí, àkókò nìyí fún wa láti wà lójúfò. (Róòmù 13:11) Gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jèhófà, Jeremáyà rí i pé òun wà lójúfò. Bá a bá ṣàyẹ̀wò bí Jeremáyà ṣe wà lójúfò lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ àti ìdí tó fi wà lójúfò, èyí á mú kí àwa náà mọ bá a ṣe lè máa bá a nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́.
Iṣẹ́ Kánjúkánjú
4. Àwọn ìpèníjà wo ni Jeremáyà dojú kọ nígbà tó ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, kí ló sì mú kí iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú?
4 Ó ṣeé ṣe kí Jeremáyà ti tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] nígbà tí Jèhófà yàn án gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. (Jer. 1:1, 2) Ṣùgbọ́n, ó ronú pé ọmọdé ni òun, ó sì rí ara rẹ̀ bí ẹni tí kò tóótun rárá láti bá àwọn àgbààgbà tó wà lórílẹ̀-èdè náà sọ̀rọ̀, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jù ú lọ lọ́jọ́ orí tí wọ́n sì wà nípò àṣẹ. (Jer. 1:6) Ó gbọ́dọ̀ polongo ìbáwí kíkankíkan kó sì kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lé àwọn èèyàn náà lórí, pàápàá jù lọ àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì èké, àwọn alákòóso àti àwọn tí wọ́n ń tọ “ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀” tí wọ́n sì ti ń hùwà ‘àìṣòótọ́ láti ọjọ́ tó ti pẹ́.’ (Jer. 6:13; 8:5, 6) Tẹ́ńpìlì ológo tí Sólómọ́nì Ọba kọ́, èyí tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin, ni a ó pa run. Jerúsálẹ́mù àti Júdà yóò di ahoro, a ó sì kó àwọn olùgbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. Lọ́nà tó ṣe kedere, iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán Jeremáyà jẹ́ iṣẹ́ kánjúkánjú!
5, 6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹgbẹ́ Jeremáyà lónìí? (b) Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ wa máa dá lé lórí?
5 Lóde òní, Jèhófà ti fi ìfẹ́ pèsè àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fún aráyé kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ ìṣàpẹẹrẹ tí yóò máa kìlọ̀ fún wọn nípa ìdájọ́ rẹ̀ tí ń bọ̀ wá sórí aráyé. Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ẹgbẹ́ Jeremáyà yìí ti ń rọ àwọn èèyàn láti máa fiyè sí àkókò tá à ń gbé. (Jer. 6:17) Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà, tó jẹ́ Olùpa Àkókò Mọ́ Títóbi Jù náà, kì í fi nǹkan falẹ̀. Ọjọ́ rẹ̀ máa dé ní àkókò náà gan-an tó fẹ́ kó dé, ní wákàtí tí àwọn èèyàn kò retí.—Sef. 3:8; Máàkù 13:33; 2 Pét. 3:9, 10.
6 Fi sọ́kàn pé Jèhófà wà lójúfò àti pé ó máa mú ayé tuntun òdodo rẹ̀ wá ní àkókò tó ti pinnu. Ó yẹ kí mímọ̀ tí ẹgbẹ́ Jeremáyà mọ èyí mú kí wọ́n má ṣe dá iṣẹ́ dúró kó sì ran àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ lọ́wọ́ láti wà lójúfò bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe túbọ̀ ń di kánjúkánjú. Ọ̀nà wo ni ìyẹn gbà kàn ẹ́? Jésù fi hàn pé ó pọn dandan kí gbogbo wa fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run la fara mọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó ran Jeremáyà lọ́wọ́ láti wà lójúfò sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un èyí tó máa ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè wà lójúfò.
Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
7. Ṣàlàyé bí ìfẹ́ ṣe sún Jeremáyà láti wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dojú kọ àwọn ipò tó le koko.
7 Kí ló sún Jeremáyà láti wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dojú kọ àwọn ipò tó le koko? Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Jeremáyà mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn èké ló ń fa ọ̀pọ̀ lára ìṣòro tí àwọn èèyàn dojú kọ. (Jer. 23:1, 2) Èyí mú kó fi ìfẹ́ àti àánú ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ó fẹ́ kí àwọn aráàlú rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì yè. Ọ̀rọ̀ náà jẹ ẹ́ lógún débi pé ó sunkún nítorí àjálù ibi tó ń bọ̀ wá sórí wọn. (Ka Jeremáyà 8:21; 9:1.) Ìwé Ìdárò ṣàlàyé kedere nípa ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti àníyàn tí Jeremáyà ní fún orúkọ Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀. (Ìdárò 4:6, 9) Lónìí, tó o bá rí àwọn èèyàn tí ‘a bó láwọ tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,’ ǹjẹ́ kì í wù ẹ́ pé kó o mú ìròyìn tí ń tuni lára nípa Ìjọba Ọlọ́run tọ̀ wọ́n lọ?—Mát. 9:36.
8. Kí ló fi hàn pé Jeremáyà kò bínú torí pé wọ́n fìyà jẹ ẹ́?
8 Àwọn èèyàn tí Jeremáyà fẹ́ láti ràn lọ́wọ́ gangan ni wọ́n fìyà jẹ ẹ́, síbẹ̀ kò gbẹ̀san tàbí kó bínú. Ó lo ìpamọ́ra àti inú rere fún Sedekáyà Ọba tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ pàápàá! Lẹ́yìn tí Sedekáyà ti fa Jeremáyà lé wọn lọ́wọ́ pé kí wọ́n lọ pa á, ó ṣì bẹ ọba náà pé kó fetí sí ohùn Jèhófà. (Jer. 38:4, 5, 19, 20) Ṣé ìfẹ́ tí àwa náà ní fún àwọn èèyàn lágbára bíi ti Jeremáyà?
Ọlọ́run Fún Un Ní Ìgboyà
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ló fún Jeremáyà ní ìgboyà?
9 Nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó gbìyànjú láti ṣe àwáwí. Èyí wá jẹ́ ká rí i pé ìgboyà àti àìyẹsẹ̀ rẹ̀ kì í ṣe ànímọ́ tí Ọlọ́run dá mọ́ ọn. Ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún tí Jeremáyà ní nínú Ọlọ́run ló mú kó ní agbára àrà ọ̀tọ̀ tó fi ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó sì dájú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wòlíì náà gẹ́gẹ́ bí “alágbára ńlá tí ń jáni láyà” ní ti pé ó ti Jeremáyà lẹ́yìn ó sì fún un lókun láti bójú tó iṣẹ́ tó yàn fún un. (Jer. 20:11) Àwọn èèyàn mọ̀ nípa ìwà àìṣojo àti ìgboyà Jeremáyà débi pé nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àwọn kan rò pé Jeremáyà ló pa dà wá sáyé!—Mát. 16:13, 14.
10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àṣẹ́kù ẹni àmì òróró wà “lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba”?
10 Gẹ́gẹ́ bí “Ọba àwọn orílẹ̀-èdè,” Jèhófà gbé iṣẹ́ lé Jeremáyà lọ́wọ́ pé kó lọ kéde ìdájọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba. (Jer. 10:6, 7) Àmọ́, ọ̀nà wo ni àṣẹ́kù ẹni àmì òróró gbà wà “lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba”? (Jer. 1:10) Bíi ti àwọn wòlíì ìgbà àtijọ́, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ti gbé iṣẹ́ lé ẹgbẹ́ Jeremáyà lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run ní àṣẹ láti kéde àwọn àsọjáde Ọlọ́run lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba kárí ayé. Níwọ̀n bí Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ ti gbé àṣẹ lé ẹgbẹ́ Jeremáyà lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń lo èdè tó rọrùn láti yéni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, wọ́n ń polongo pé àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn ìjọba tó wà lóde òní ni a ó fà tu tí a ó sì pa run bí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run àti ní ọ̀nà tí Ọlọ́run yàn. (Jer. 18:7-10; Ìṣí. 11:18) Ẹgbẹ́ Jeremáyà ti pinnu pé òun kò ní dẹ́kun láti máa bójú tó iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́ láti polongo ìdájọ́ Jèhófà kárí ayé.
11. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù láìdábọ̀ nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ipò tó ṣòro?
11 Ó wọ́pọ̀ pé ká rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì bá a bá dojú kọ àtakò, ìdágunlá tàbí àwọn ipò tó ṣòro. (2 Kọ́r. 1:8) Àmọ́, bíi ti Jeremáyà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó. Ẹ má ṣe jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì. Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa bá a nìṣó láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run, ká gbára lé e, ká sì “máyàle” bá a ti ń wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. (1 Tẹs. 2:2) Torí pé a jẹ́ olùjọsìn tòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti wà lójúfò bá a ti ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́. A gbọ́dọ̀ pinnu láti máa wàásù láìdábọ̀ nípa ìparun tó ń bọ̀ wá sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, èyí tí ìparun Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́ ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Kì í ṣe “ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà” nìkan ni ẹgbẹ́ Jeremáyà máa kéde rẹ̀, àmọ́ ó tún máa kéde “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa.”—Aísá. 61:1, 2; 2 Kọ́r. 6:2.
Ayọ̀ Àtọkànwá
12. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ayọ̀ Jeremáyà kò pẹ̀dín, kí sì ní ohun pàtàkì tó ràn án lọ́wọ́?
12 Jeremáyà láyọ̀ nídìí iṣẹ́ rẹ̀. Ó sọ fún Jèhófà pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run.” (Jer. 15:16) Àǹfààní ló jẹ́ fún Jeremáyà láti ṣojú fún Ọlọ́run kó sì máa wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kíyè sí i pé nígbà tí Jeremáyà ń ronú ṣáá nípa báwọn èèyàn ṣe ń fòun ṣe yẹ̀yẹ́, ńṣe ni inú rẹ̀ ń bà jẹ́. Àmọ́ nígbà tó wá ń ronú nípa bí iṣẹ́ náà ṣe dára tó àti bó ti ṣe pàtàkì tó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ pa dà.—Jer. 20:8, 9.
13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tó túbọ̀ jinlẹ̀ ká lè máa láyọ̀?
13 Ká lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lónìí, a gbọ́dọ̀ máa fi “oúnjẹ líle,” ìyẹn òtítọ́ jíjinlẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara wa. (Héb. 5:14) Kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ máa ń gbé ìgbàgbọ́ ró. (Kól. 2:6, 7) Ó máa ń mú kí bí ìṣesí wa ṣe máa ń rí lára Jèhófà túbọ̀ ṣe kedere sí wa. Bó bá ń ṣòro fún wa láti wá àkókò fún kíka Bíbélì ká sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ tún ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa gbé yẹ̀ wò. Kódà, ìṣẹ́jú díẹ̀ tá a bá fi ń kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì fi ń ṣe àṣàrò lójoojúmọ́ máa mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ó sì máa pa kún “ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà” wa, bó ṣe rí fún Jeremáyà.
14, 15. (a) Kí ni àbájáde bí Jeremáyà ṣe fi ìṣòtítọ́ tẹra mọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un? (b) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run mọrírì rẹ̀ lónìí nípa iṣẹ́ ìwàásù?
14 Jeremáyà polongo ìkìlọ̀ àti ìdájọ́ Jèhófà láìdábọ̀, síbẹ̀ kò mọ́kàn kúrò lórí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un “láti kọ́ àti láti gbìn.” (Jer. 1:10) Iṣẹ́ tó ṣe láti kọ́ àti láti gbìn sì sèso rere. Àwọn Júù kan àtàwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. A mọ̀ nípa àwọn ọmọ Rékábù, Ebedi-mélékì àti Bárúkù. (Jer. 35:19; 39:15-18; 43:5-7) Àwọn ọ̀rẹ́ Jeremáyà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọ́run yìí ló ṣàpẹẹrẹ àwọn tó ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé lónìí tí wọ́n ń bá ẹgbẹ́ Jeremáyà ṣọ̀rẹ́. Inú ẹgbẹ́ Jeremáyà sì ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń gbé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí ró nípa tẹ̀mí. (Ìṣí. 7:9) Bákan náà, àwọn adúróṣinṣin tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró yìí ń rí ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà nínú ríran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.
15 Àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ pé ìwàásù ìhìn rere kì í wulẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe gbogbo àwọn tó bá gbọ́ ọ láǹfààní nìkan àmọ́, ó tún jẹ́ apá kan ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Yálà a rí àwọn èèyàn tó fẹ́ gbọ́ tàbí a kò rí, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà nípasẹ̀ ìwàásù wa ń mú ká ní ayọ̀ tó pọ̀.—Sm. 71:23; ka Róòmù 1:9.
‘Wà Lójúfò’ Bó O Ṣe Ń Ṣe Iṣẹ́ Rẹ!
16, 17. Báwo ni Ìṣípayá 17:10 àti Hábákúkù 2:3 ṣe fi hàn pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí?
16 Bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó wà nínú Ìṣípayá 17:10, a máa rí bó ṣe mú kó ṣe kedere pé à ń gbé ní àkókò kánjúkánjú. Ọba keje, ìyẹn Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti dé. A kà nípa rẹ̀ pé: “Nígbà tí [agbára ayé keje] bá dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.” Ní báyìí, “ìgbà kúkúrú” rẹ̀ á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Wòlíì Hábákúkù mú kó dá wa lójú nípa òpin ètò búburú yìí pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀ . . . Máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—Háb. 2:3.
17 Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo mọ̀ pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí? Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé mi fi hàn pé mò ń retí pé òpin máa dé láìpẹ́? Àbí ńṣe làwọn ìpinnu mi ń fi hàn pé mò ń retí pé ó máa pẹ́ kí òpin tó dé tàbí kò dá mi lójú bóyá ó tiẹ̀ máa dé rárá?’
18, 19. Kì nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ dẹwọ́ ní àkókò tá a wà yìí?
18 Iṣẹ́ ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà kò tíì parí. (Ka Jeremáyà 1:17-19.) Ẹ wo bó ti ń fúnni láyọ̀ tó pé àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ń dúró láìyẹsẹ̀, bí “ọwọ̀n irin” àti “ìlú ńlá olódi”! Wọ́n fi ‘òtítọ́ di abẹ́nú wọn lámùrè’ ní ti pé wọ́n ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn lókun títí tí wọ́n á fi parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn. (Éfé. 6:14) Pẹ̀lú irú ìpinnu kan náà yìí, àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ń fi taápọntaápọn kọ́wọ́ ti ẹgbẹ́ Jeremáyà lẹ́yìn láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.
19 Kì í ṣe àkókò tá a wà yìí ló yẹ ká dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run bí kò ṣe pé ká máa gbé kókó pàtàkì tó wà nínú Jeremáyà 12:5 yẹ̀ wò. (Kà á.) Gbogbo wa la ní àdánwò tá à ń fara dà. Àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò yìí la lè fi wé “àwọn ẹlẹ́sẹ̀” tá a gbọ́dọ̀ máa bá sáré. Síbẹ̀, bí “ìpọ́njú ńlá” ṣe ń wọlé bọ̀, a lè retí pé kí ìnira máa pọ̀ sí i. (Mát. 24:21) Bá a ṣe ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn ìṣòro tó ń muni lómi yìí la lè fi wé ‘bíbá àwọn ẹṣin sá eré ìje.’ Ẹnì kan gbọ́dọ̀ ní ìfaradà ńláǹlà kó tó lè bá ẹṣin tó ń sáré kútúpà-kútúpà sáré. Torí náà, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá fara da àwọn àdánwò tó ń dojú kọ wá nísinsìnyí. Ó sì lè jẹ́ àwọn àdánwò náà ló máa múra wa sílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
20. Kí lo pinnu láti ṣe?
20 Gbogbo wa la lè fara wé Jeremáyà ká sì kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá a gbé lé wa lọ́wọ́! Àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìgboyà àti ìdùnnú ló mú kí Jeremáyà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] ní àṣeyọrí. Igi álímọ́ńdì tó máa ń yọ òdòdó rírẹwà rán wa létí pé Jèhófà á máa “wà lójúfò” nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè mú un ṣẹ. Torí náà, àwa pẹ̀lú ní ìdí rere láti ṣe bíi ti Jèhófà. Jeremáyà “wà lójúfò,” àwa náà sì lè wà lójúfò bíi tirẹ̀.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni ìfẹ́ ṣe ran Jeremáyà lọ́wọ́ láti “wà lójúfò” lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un?
• Kí nìdí tá a fi nílò ìgboyà tí Ọlọ́run ń fúnni?
• Kí ló mú kí Jeremáyà máa láyọ̀?
• Kí nìdí tí wàá fi fẹ́ láti “wà lójúfò”?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ṣé wàá máa wàásù nìṣó láìka àtakò sí?