Lẹ́tà sí Àwọn Ará Kólósè
2 Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí ìsapá mi ṣe pọ̀ tó lórí yín, lórí àwọn tó wà ní Laodíkíà+ àti lórí gbogbo àwọn tí kò tíì rí mi lójúkojú.* 2 Èyí jẹ́ kí a lè tu ọkàn wọn lára,+ kí a lè so wọ́n pọ̀ di ọ̀kan nínú ìfẹ́,+ kí wọ́n sì lè ní gbogbo ọrọ̀ tó ń wá látinú òye wọn tó dájú hán-ún, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tó péye nípa àṣírí mímọ́ Ọlọ́run, ìyẹn Kristi.+ 3 Inú rẹ̀ ni a fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.+ 4 Mò ń sọ èyí kí ẹnì kankan má bàa fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. 5 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nínú ara, mo wà pẹ̀lú yín nínú ẹ̀mí, inú mi ń dùn bí mo ṣe ń rí i pé ẹ wà létòlétò,+ ìgbàgbọ́ yín sì fìdí múlẹ̀ nínú Kristi.+
6 Nítorí náà, bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa rìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, 7 kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì máa dàgbà nínú rẹ̀,+ kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,+ bí a ṣe kọ́ yín, kí ẹ sì máa kún fún ọpẹ́.+
8 Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán+ mú yín lẹ́rú* látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn, nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kì í ṣe nínú Kristi; 9 torí pé inú rẹ̀ ni gbogbo ànímọ́* Ọlọ́run pé sí.+ 10 Torí náà, ẹ ti ní ohun gbogbo nípasẹ̀ rẹ̀, ẹni tó jẹ́ orí gbogbo ìjọba àti àṣẹ.+ 11 Àjọṣe tí ẹ ní pẹ̀lú rẹ̀ ti mú kí a dádọ̀dọ́* ẹ̀yin náà pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́* tí a kò fi ọwọ́ ṣe nípa bíbọ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+ ìyẹn ìdádọ̀dọ́ tó jẹ́ ti Kristi.+ 12 A sin yín pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìbatisí rẹ̀,+ àjọṣe tí ẹ sì ní pẹ̀lú rẹ̀ mú kí a gbé ẹ̀yin náà dìde+ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú iṣẹ́ agbára Ọlọ́run, ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú.+
13 Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́* ẹran ara yín, Ọlọ́run mú kí ẹ wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú,+ 14 ó pa ìwé àfọwọ́kọ rẹ́,*+ èyí tí àwọn àṣẹ wà nínú rẹ̀,+ tó sì lòdì sí wa.+ Ó mú un kúrò lọ́nà bí ó ṣe kàn án mọ́ òpó igi oró.*+ 15 Ó ti tú àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ sí borokoto, ó fi wọ́n hàn ní gbangba pé a ti ṣẹ́gun wọn,+ ó ń fi òpó igi oró* darí wọn lọ nínú ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun.
16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan dá yín lẹ́jọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń mu+ tàbí lórí àjọyọ̀ kan tí ẹ ṣe tàbí òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.+ 17 Àwọn nǹkan yẹn jẹ́ òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀,+ àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.+ 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mú kí ẹ̀bùn náà bọ́ mọ́ yín lọ́wọ́,+ ẹni tó fẹ́ràn ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀tàn àti ọ̀nà ìjọsìn àwọn áńgẹ́lì, “tó dúró lórí”* àwọn ohun tó ti rí. Ní tòótọ́, kò sídìí tó fi yẹ kó gbéra ga, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó ń ronú lọ́nà ti ara, 19 kò sì di orí náà mú ṣinṣin,+ ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ara fi ń rí ohun tó nílò, tó sì so gbogbo rẹ̀ pọ̀ di ọ̀kan nípasẹ̀ àwọn oríkèé àti àwọn iṣan tó de eegun pọ̀, tó ń mú kó máa dàgbà sókè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.+
20 Bí ẹ bá ti kú pẹ̀lú Kristi nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé,+ kí ló dé tí ẹ̀ ń gbé ìgbé ayé yín bíi pé ẹ ṣì jẹ́ apá kan ayé bí ẹ ṣe ń fi ara yín sábẹ́ àwọn àṣẹ tó sọ pé:+ 21 “Má dì í mú, má tọ́ ọ wò, má fọwọ́ kàn án,” 22 ní ti gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣègbé lẹ́yìn lílò, gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látọwọ́ èèyàn ṣe sọ?+ 23 Bó tiẹ̀ dà bíi pé àwọn nǹkan yẹn bọ́gbọ́n mu, ṣe ni àwọn tó ń ṣe wọ́n yan ọ̀nà ìjọsìn tiwọn fúnra wọn. Wọ́n ń fìyà jẹ ara wọn+ torí wọ́n fẹ́ kí àwọn èèyàn máa rò pé àwọn nírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yẹn kò ní àǹfààní kankan téèyàn bá fẹ́ borí ìfẹ́ ti ara.