Ori 12
Majẹmu Titun Ti Ọlọrun Ń Súnmọ́ Àṣeparí Rẹ̀
1. (a) Ki ni yoo ṣẹlẹ si ilẹ̀-ayé wa bi Ọlọrun kò ba pa majẹmu rẹ̀ mọ́ nipa ọsan ati oru? (b) Niwọn bi Ọlọrun ti fi pẹlu iduroṣinṣin dìrọ̀ mọ́ awọn majẹmu rẹ̀, ki ni eyi lè mú da wa loju?
KI NI ohun ti awa ìbá ṣe bi Ọlọrun kò ba pa majẹmu rẹ̀ mọ́ nipa ọsan ati oru? Kaka ti a ba fi ní ọsan ati oru ti ń paarọ araawọn, ilẹ̀-ayé wa ni a ba ti tanmọlẹ si nipa imọlẹ ti ó ń wà titilọ tabi ki o ṣú dùdù ninu okunkun titilọ. (Genesisi 1:1, 2, 14-19) Ṣugbọn Ọlọrun fi pẹlu iduroṣinṣin dìrọ̀ mọ́ awọn majẹmu rẹ̀. Nitori naa awa lè ní idaniloju alaiyingin pe oṣupa, oorun, awọn iṣupọ irawọ oju ọ̀run ni a ki yoo parun lae; bakan naa si ni planẹti Ilẹ̀-Ayé wa pẹlu.
2. Ki ni ohun ti Jehofa sọ fun awọn Ju ní isopọ pẹlu majẹmu rẹ̀ niti ọsan ati ti oru?
2 Nigba ti ó ń sọrọ nipa majẹmu rẹ̀ niti ọsan ati ti oru, Ọlọrun sọ fun awọn Ju ti wọn wà labẹ ijọba ìlà ọlọba ti ilé Dafidi pe: “Bi ẹyin ba lè ba majẹmu mi ti ọsan jẹ, ati majẹmu mi ti oru, tí ọsan ati oru ko lè si ní akoko wọn; nigba naa ni majẹmu mi pẹlu Dafidi iranṣẹ mi lè bajẹ, pe ki oun ki o ma lè ní ọmọ lati jokoo lori itẹ rẹ̀.”—Jeremiah 33:20, 21.
3. Ki ni awọn ọ̀rọ̀ wọnyi fihan nipa majẹmu rẹ̀ pẹlu Dafidi fun Ijọba ainipẹkun kan?
3 Ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn a ní ẹri ti o dọgbọn tumọsi pe ilẹ̀-ayé wa, papọ pẹlu oorun ati oṣupa, yoo wà titilae. (Oniwasu 1:4) Ilẹ̀-ayé wa ni yoo maa fi igba gbogbo kun fun awọn eniyan olugbe inu rẹ̀, fun wọn lati gbadun awọn ẹwà ọsan ati ti oru labẹ Ọlọrun kan ti ń pa majẹmu mọ́, Ẹlẹ́dàá eniyan. Ati gan-an gẹgẹ bi Jehofa ti di majẹmu rẹ̀ ti ọsan ati ti oru mu ṣinṣin, bakan naa ni ó ti jẹ́ aduroṣinṣin si majẹmu rẹ̀ pẹlu Ọba Dafidi igbaani fun Ijọba ainipẹkun kan ní ìlà idile Dafidi. Eyi jẹ́ otitọ bi o tilẹ jẹ pe ibujokoo Ijọba naa ni a ti nilati ta atare rẹ̀ lati ori ilẹ̀-ayé si inu awọn ọ̀run ti a ko lè fojuri.—Orin Dafidi 110:1-3.
4. (a) Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi fun Ijọba ainipẹkun ni a sopọ pẹlu majẹmu miiran wo? (b) Ki ni ohun ti Jesu Kristi sọ nipa rẹ̀, ati labẹ awọn ayika ipo wo sì ni?
4 Majẹmu Ọlọrun fun Ijọba ainipẹkun ní ìlà atọmọdọmọ ti Dafidi ni a sopọ mọ́ majẹmu miiran, “majẹmu titun” naa. Majẹmu yii ti yoo rọpo majẹmu ogbologboo naa ni Jesu mẹnuba. Eyi jẹ́ lẹhin ti ó ti ṣe ajọdun Irekọja awọn Ju tan pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ oluṣotitọ ní alẹ Nisan 14 ní 33 C.E. O gbé ohun kan ti a wa bẹrẹsii pe ní “ounjẹ alẹ Oluwa” kalẹ̀. O mọ̀ wi pe ní ọjọ Irekọja yẹn gan-an, oun yoo tú ẹjẹ rẹ̀ dà silẹ ní irubọ. Nitori iyẹn, o mu ago ọti waini pupa, ṣugbọn ṣaaju ki ó to fi lé awọn aposteli rẹ̀ oluṣotitọ lọwọ, o wi pe: “Ago yii ni majẹmu titun ní ẹjẹ mi.”—Luku 22:20; 1 Korinti 11:20, 23-26.
5. Ta ni Ọlọrun ṣeleri dida majẹmu titun fun, njẹ Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli ha sọ pe oun wà ninu majẹmu yii bi?
5 Gẹgẹ bii majẹmu ogbologboo naa, majẹmu titun naa ni a dá pẹlu orilẹ-ede kan ṣugbọn kii ṣe pẹlu eyikeyii ninu awọn orilẹ-ede Kristẹndọm. Bi o tilẹ jẹ pe ileri majẹmu titun naa ni a ṣe nipasẹ wolii Jeremiah fun orilẹ-ede Israeli ní eyi ti ó ju 2,500 ọdun sẹhin, Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli ti ode-oni kò sọ pe oun wà ninu majẹmu titun naa. Kaka bẹẹ, Orilẹ-Ede Aláààrẹ ti Israeli di mẹmba UN.
6. Ní ibamu pẹlu Jeremiah ori 31, eeṣe ti Ọlọrun fi rii pe o yẹ lati dá majẹmu titun kan, ki ni yoo si yọrisi?
6 Eeṣe ti Ọlọrun fi fẹ́ majẹmu titun kan? Jeremiah 31:31-34 ṣalaye pe: “Wo o, ọjọ ń bọ, ni Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun. Kii ṣe bi majẹmu naa ti emi ba baba wọn dá ní ọjọ naa ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti wọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ́ alakooso wọn sibẹ, ni Oluwa wi. Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli dá; Lẹhin ọjọ wọnni, ni Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si àyà wọn; emi o si jẹ́ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ́ eniyan mi. Wọn ki yoo si kọni mọ ẹnikinni ẹnikeji rẹ̀, ati ẹgbọn, ati aburo rẹ̀ wi pe, Mọ Oluwa [“Jehofa!” NW]: nitori pe gbogbo wọn ni yoo mọ̀ mi, lati ẹni kekere wọn de ẹni nla wọn, ni Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedeedee wọn jì, emi ki o si ranti ẹṣẹ wọn mọ́.”
Majẹmu kan Ti Ó Dara Ju Pẹlu Alarina kan Ti Ó Dara Ju
7. Majẹmu titun naa ha jẹ́ isọdọtun majẹmu tí awọn ọmọ Israeli dà bi, eesitiṣe ti ó fi dara ju majẹmu Ofin lọ?
7 Majẹmu titun naa kii wulẹ ṣe isọdọtun ṣakala kan ti majẹmu iṣaaju eyi ti awọn ọmọ Israeli ti dà. Bẹẹkọ rara! Nitori ti aposteli Paulu kọwe si awọn Kristian ní Romu wi pe: “Ẹyin ko si labẹ ofin, bikoṣe labẹ oore-ọfẹ.” (Romu 6:14) Ofin titun kan ni ó jẹ́ niti gidi gan-an, a si ni ireti pe yoo jẹ́ eyi ti ó dara ju nitori Jehofa Ọlọrun Olodumare lè mu awọn ọran sunwọn sii niti awọn wọnni ti oun gbà sinu majẹmu titun naa. Fun ohun kan, oun gbé alarina, tabi onilaja, ti o dara ju kan dide lati fi idi majẹmu titun naa mulẹ. Alarina yii kii ṣe ọkunrin alaipe, ti ó ní akoran ẹṣẹ kan bii ti wolii Mose.
8. (a) Ki ni majẹmu titun naa ní ti ó fi dara ju majẹmu Ofin? (b) Ta ni Alarina majẹmu titun didara ju naa? (c) Ki ni Heberu 8:6, 13 wi nipa majẹmu titun naa ati ilọlaju Alarina rẹ̀, ati pẹlu imọlara wo lori majẹmu iṣaaju?
8 Majẹmu Ofin naa ti wolii Mose ṣe alarina rẹ̀ dara ninu araarẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, majẹmu yẹn pese fun irubọ awọn ẹranko ti ẹ̀jẹ̀ wọn kò lè wẹ ẹṣẹ awọn eniyan nù lae. Nitori naa fun Jehofa Ọlọrun lati gbé majẹmu ti ó dara ju kalẹ, alarina didara ju pẹlu irubọ ti ó dara ju nilati wà. Alarina yiyẹ ní gbogbo ọna yii jẹ́ Jesu Kristi. Ní titọka ilọlaju Alarina yii jade ní ifiwera pẹlu wolii Mose, Bibeli fun wa ní alaye ti ó tẹ̀lé e yii: “Ṣugbọn nisinsinyi o [Jesu] ti gba iṣẹ iranṣẹ ti ó ni ọla ju, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti ó dara ju ni iṣe, eyi ti a fi ṣe ofin lori ileri ti ó san ju bẹẹ lọ. . . . Ní eyi ti ó wi pe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaaju di ti laelae [“atijọ,” NW].”—Heberu 8:6, 13.
A Paarọ Majẹmu Ogbologboo “Atijọ”
9. (a) Ní ọjọ wo ni majẹmu ogbologboo naa kọja lọ? (b) Ki ni ṣẹlẹ ní owurọ ọjọ yẹn, eyi si jẹ́ ijẹrii si ki ni?
9 Majẹmu “atijọ,” tabi alaiba igba mu yẹn, kọja lọ ní 50 ọjọ lẹhin ajinde Alarina majẹmu titun naa. Eyi ṣẹlẹ ní ọjọ Pentekosti. Ní owurọ ọjọ yẹn, Ajọdun Ikojọpọ amapẹẹrẹṣẹ ti awọn Ju ti bẹrẹsii ṣẹlẹ. Bawo ni? O dara, 120 awọn oluṣotitọ ọmọ-ẹhin Alarina majẹmu titun naa ko araawọn jọpọ̀ ninu iyara oke kan ní Jerusalemu, wọn si gba ẹmi mímọ́ ti a ṣeleri rẹ̀ ní imuṣẹ asọtẹlẹ Joeli 2:28-32. O jẹrii si ibẹrẹ majẹmu titun naa nipa pipese ẹri ti ó ṣeégbọ́ ati eyi ti ó ṣeeri fun gbogbo awọn onworan.
10. Ní ọjọ Pentekosti, bawo ni a ṣe fi i han kedere pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni a ti fi ẹmi mímọ́ yàn?
10 Nigba ti Jesu jade wa lati inu omi iribọmi ti a si tú ẹmi mímọ́ le e lori, ẹmi naa ni a ṣapẹẹrẹ rẹ̀ lọna iyanu nipasẹ aworan àdàbà ti ń rà bàbà loke ori rẹ̀. Ṣugbọn niti ọran awọn 120 Heberu ọmọ-ẹhin ní ọjọ Pentekosti, bawo ni a ṣe fi fifi ẹmi mímọ́ yàn wọn han kedere? Nipasẹ ifarahan ẹ̀là ahọ́n bii ti ina loke ori wọn ati nipasẹ fifi animọ agbara pipolongo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní awọn ede ajeji ti wọn kò kẹkọọ ri jinki wọn.—Matteu 3:16; Iṣe 2:1-36.
11. (a) Ki ni ó yẹ ki ó hàn kedere si awọn Ju, eesitiṣe? (b) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe awọn Ju ko wi fun ẹnikinni ẹnikeji wọn pe, “Mọ Jehofa!” ki si ni ayọ̀ ti wọn kò ni?
11 O yẹ ki o hàn kedere si awọn Ju ati si awọn rabbi wọn pe majẹmu Ofin Mose kò si lẹnu iṣẹ mọ. Lati igba iparun Jerusalemu lati ọwọ́ ẹgbẹ ogun Romu ní 70 C.E., wọn ko tii ní tẹmpili kankan. Nigba yẹn, akọsilẹ ìlà iran wọn ni a sọnu tabi parun. Nipa bayii lonii wọn kò mọ ta ni ó jẹ́ ti ẹya Lefi tabi ta ni o jẹ́ atọmọdọmọ Aaroni ki o ba lè ṣiṣẹsin ní ipo àyè iṣẹ ti olori alufaa orilẹ-ede Ju. Kaka ti wọn iba fi maa wi ẹnikinni si ẹnikeji rẹ̀ pe, “Mọ Jehofa!” wọn ka pipe orukọ atọrunwa naa si èèwọ̀. Nitori naa wọn ko ṣajọpin ayọ̀ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lori otitọ naa pe majẹmu ogbologboo “atijọ” ni a ti paarọ rẹ̀ pẹlu titun naa.
“Majẹmu Ayeraye” Kan
12. (a) Adura wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè da araawọn pọ̀ mọ́ lati inu ọkan-aya wọn? (b) Pẹlu ki ni a ji Jesu dide lati inu oku?
12 Ní iyatọ gedegbe si bi ipo ti ri pẹlu awọn Ju lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Olori Alufaa alaapọn, ti ń ṣiṣẹsin ní ọwọ́ ọtun Ọlọrun ninu awọn ọ̀run. Oun ni Alarina majẹmu titun naa, alarina kan ti ó tobi ju Mose lọ gbọọrọgbọọrọ. Lati inu ọkan-aya wá, awọn Ẹlẹ́rìí wọnyi fun Jehofa lè da araawọn pọ̀ pẹlu onkọwe naa ninu adura rẹ̀ ninu Heberu 13:20, 21 pe: “Njẹ [ki] Ọlọrun alaafia, ẹni ti ó tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan ti inu oku wá, nipa ẹjẹ majẹmu ayeraye, ani Oluwa wa Jesu, ki ó mu yin pe ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀.” Niwọn bi “oluṣọ-agutan nla” naa ti fi iwalaaye rẹ̀ bi eniyan lélẹ̀ fun “awọn agutan,” a lè ji i dide kuro ninu oku sinu ara ti ẹmi alailẹjẹ ti kò lè ku ṣugbọn pẹlu itoye ẹjẹ majẹmu titun naa ti a ti fi pẹlu iṣotitọ pamọ ti ó si wà fun ayeraye ninu awọn iyọrisi rere rẹ̀.
13. (a) Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń ṣeranti iku Alarina majẹmu titun naa lọdọọdun? (b) Ki ni awọn ohun iṣapẹẹrẹ naa ń duro fun?
13 Iku irubọ ti Alarina majẹmu titun naa, Jesu Kristi, ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣeranti rẹ̀ lọdọọdun ní ayajọ “ounjẹ alẹ Oluwa” naa. Akara alaiwu tí awọn ti wọn wà ninu majẹmu titun naa ń ṣajọpin rẹ̀ nigba “ounjẹ alẹ” yẹn ń ṣapẹẹrẹ ẹran ara pipe ti Alarina naa, ti waini naa si ń ṣapẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ mímọ́, alailabula ti o ní, gẹgẹ bi Iwe Mímọ́ ti wí, itoye iwalaaye ti Alarina naa gan-an ninu.—1 Korinti 11:20-26; Lefitiku 17:11.
14. Nigba ti awọn wọnni ti wọn wà ninu majẹmu titun naa ba ṣajọpin ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ Iranti naa, ki ni wọn ń ṣe, ki a sọ ọ lọna iṣapẹẹrẹ?
14 Nigba ti awọn ti wọn wà ninu majẹmu titun naa ba ṣajọpin ago waini Iranti naa nibi “ounjẹ alẹ Oluwa,” o wulẹ jẹ́ ní ọna iṣapẹẹrẹ ni wọn fi ń mu ẹ̀jẹ̀, ti Alarina majẹmu titun naa. O tun jẹ́ ní ọna iṣapẹẹrẹ ni wọn fi ń jẹ ẹran ara rẹ̀ nigba ti wọn ba ń ṣajọpin ninu iṣu akara Iranti alaiwu naa. Nipa ṣiṣe eyi, ki a sọ ọ lọna iṣapẹẹrẹ, wọn ń ṣaṣefihan igbagbọ wọn ninu ẹbọ irapada Ọmọkunrin Ọlọrun, Olurapada gbogbo iran eniyan.
15. (a) Bawo ni majẹmu titun naa ti wà pẹ́ tó nisinsinyi, bawo ni ó si ti ṣe fi ẹri hàn pe majẹmu ti ó dara ju nii ṣe nitootọ? (b) Eeṣe ti a fi lè tọkasi majẹmu titun naa bi “majẹmu ayeraye” kan?
15 Majẹmu titun naa, ti ó ju 1,950 ọdun lọ nisinsinyi, ń sunmọ aṣepari ète rẹ̀. Nisinsinyi ó ti fi ọpọ ọrundun wà pẹ́ ju majẹmu Ofin Mose lọ. Nitori pe a gbe e ka awọn ileri ti ó dara ju pẹlu ẹbọ didara ju ati Alarina didara ju, o ti fi ẹri han pe majẹmu ti ó dara ju ni o jẹ nitootọ. Nitori pe ko ní si idi fun pípa a tì tabi fifi majẹmu titun didara ju miiran rọpo rẹ̀, majẹmu titun alaṣeyọri naa ni a tọkasi bi “majẹmu ayeraye” kan.—Heberu 13:20.
16. Ki ni a gbọdọ maa dupẹ lọwọ Jehofa Ọlọrun fun?
16 A dupẹ lọwọ Ọlọrun Olodumare, Jehofa, pe oun gbe Alarina kan ti ó dara ju Mose dide, nipasẹ ẹni ti Oun fi lè mu majẹmu Ofin Mose kuro lọna ofin nipa kikan an mọ́ igi oró, ti ó si pese ẹ̀jẹ̀ majẹmu titun ayeraye naa!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 105]
Majẹmu titun naa ti Jesu ṣalarina rẹ̀ tayọlọla pupọpupọ ju majẹmu ogbologboo naa ti Mose ṣalarina rẹ̀ lọ