Orí Kẹtàlá
“Jèhófà Ti Ṣe Ohun Tí ó Ní Lọ́kàn”
1. Nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run, kí ni Jeremáyà sọ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà?
JEREMÁYÀ ń wo bí àwọn ògiri ìlú Jerúsálẹ́mù ṣe ti di àlàpà. Èéfín iná tí àwọn ará Bábílónì tó ṣẹ́gun ìlú náà fi sun ún ṣì ń rú. Jeremáyà wá rántí báwọn tí wọ́n ń fi idà pa ṣe ń figbe oró ta. Ọlọ́run ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún un ṣáájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run wá kédàárò pé: “Jèhófà ti ṣe ohun tí ó ní lọ́kàn.” Áà, àjálù ńlá ni ìparun Jerúsálẹ́mù jẹ́!—Ka Ìdárò 2:17.
2. Àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ti sọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn wo ló ṣẹ níṣojú Jeremáyà?
2 Jeremáyà wá rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ táwọn èèyàn Ọlọ́run ti gbọ́ sétí, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti wà látayébáyé, ṣẹ sí wọn lára lóòótọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Mósè ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé wọ́n lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run kí wọ́n gba “ìbùkún,” tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn, kí wọ́n sì dẹni “ìfiré.” Èyí tó dáa jù, ìyẹn ìbùkún, ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ yàn. Àmọ́ tí wọ́n bá ya aláìgbọràn, ìfiré tó máa wá sórí wọn yóò burú jáì. Mósè kìlọ̀ fún wọn, Jeremáyà sì tún sọ ohun kan náà, pé àwọn tí wọn ò bá ka Jèhófà sí, tí wọ́n tàpá sí i, yóò “jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin wọn àti ẹran ara àwọn ọmọbìnrin wọn” pàápàá. (Diu. 30:19, 20; Jer. 19:9; Léf. 26:29) Àwọn kan lára wọn lè máa rò ó pé, ‘Ṣé irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ ṣá?’ Ó kúkú ṣẹlẹ̀, ìyẹn nígbà táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù, tí kò sì sóúnjẹ kankan fáwọn aráàlú láti jẹ mọ́. Jeremáyà sọ pé: “Àní ọwọ́ àwọn obìnrin oníyọ̀ọ́nú ti se àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ti dà bí oúnjẹ ìtùnú fúnni lákòókò ìwópalẹ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi.” (Ìdárò 4:10) Àjálù ńlá gbáà ni!
3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń rán àwọn wòlíì sáwọn èèyàn rẹ̀?
3 Àmọ́ ṣá, kì í ṣe torí àtimáa kéde ègbé tó ń bọ̀ nìkan ni Jèhófà ṣe ń yan àwọn wòlíì, irú bíi Jeremáyà. Ṣe ni Ọlọ́run ń fẹ́ káwọn èèyàn òun yí pa dà kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lọ́nà òdodo. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ń fẹ́ káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà. Ẹ́sírà sọ kókó yìí, ó ní: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sì ń ránṣẹ́ lòdì sí wọn ṣáá nípasẹ̀ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń ránṣẹ́ léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀.”—2 Kíró. 36:15; ka Jeremáyà 26:3, 12, 13.
4. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń kéde ṣe rí lára rẹ̀?
4 Jeremáyà náà ní ìyọ́nú sáwọn èèyàn rẹ̀, bíi ti Jèhófà. A lè rí ẹ̀rí èyí látinú ohun tó sọ ṣáájú kí Jerúsálẹ́mù tó pa run. Ọkàn rẹ̀ dà rú gan-an nítorí àjálù tó ń bọ̀ lórí wọn. Àjálù yẹn ì bá sì yẹ̀ lórí wọn o ká ní wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ Jeremáyà, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tó ń kéde fún wọn! Ìwọ fojú inú wo bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára Jeremáyà nígbà tó ń jíṣẹ́ Ọlọ́run fún wọn. Ó kérora pé: “Ìwọ ìfun mi, ìfun mi! Mo wà nínú ìrora mímúná nínú ògiri ọkàn-àyà mi. Ọkàn-àyà mi ń ru gùdù nínú mi. Èmi kò lè dákẹ́, nítorí ìró ìwo ni ohun tí ọkàn mi gbọ́, àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì ogun.” (Jer. 4:19) Jeremáyà kò lè panu mọ́ rárá o nípa ìyọnu tó ń bọ̀ náà.
KÍ LÓ JẸ́ KÓ DÁ A LÓJÚ TÓ BẸ́Ẹ̀?
5. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń kéde fi dá a lójú?
5 Kí nìdí tó fi dá Jeremáyà lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ tó ń sọ yóò ṣẹ? (Jer. 1:17; 7:30; 9:22) Ó jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an, àtẹni tó ka Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀ débi tó fi mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tó ń sàsọtẹ́lẹ̀ tí kì í yẹ̀. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn sì fi hàn lóòótọ́ pé Jèhófà lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tọ́mọ aráyé ò tiẹ̀ gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀, bí irú èyí tó sọ, pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gba ìdáǹdè kúrò lóko ẹrú Íjíbítì. Jeremáyà mọ ìtàn inú ìwé Ẹ́kísódù tó sọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò lóko ẹrú ilẹ̀ Íjíbítì yìí, ó sì tún ka ọ̀rọ̀ Jóṣúà tí ìtàn náà ṣojú rẹ̀. Jóṣúà rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣ. 23:14.
6, 7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà kéde? (b) Kí ló máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó ò ń wàásù dá ọ lójú?
6 Kí nìdí tó fi yẹ kó o túbọ̀ máa fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Jeremáyà rí ẹ̀rí tó dá a lójú pé Jèhófà máa mú gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ. Ìdí kejì ni pé àwọn kan lára ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ ti ń ṣẹ báyìí, àwọn míì sì ń bọ̀ wá ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Ìdí kẹta ni pé, bí ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà kéde lórúkọ Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe fìtara kéde wọn, fi hàn kedere pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Àní Jeremáyà fakọ yọ láwùjọ àwọn wòlíì pàápàá.” Ọlọ́run lo Jeremáyà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an láti ṣojú fóun láàárín àwọn Júù, débi pé, nígbà tí àwọn kan gbọ́rọ̀ Jésù wọ́n rò pé Jeremáyà ló ń bá àwọn sọ̀rọ̀.—Mát. 16:13, 14.
7 Àkókò táwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì inú Bíbélì ń ṣẹ náà la wà yìí bíi ti ìgbà Jeremáyà. Ó sì yẹ kó dá ìwọ náà lójú bó ṣe dá Jeremáyà lójú, pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀ rárá. (2 Pét. 3:9-14) Báwo lo ṣe máa nírú ìdánilójú bẹ́ẹ̀? Ńṣe ni wàá túbọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ táá mú kó dá ọ lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í yẹ̀ lọ́nàkọnà. Nítorí náà, nínú orí kẹtàlá tá a wà yìí, a máa gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ tó sì ṣẹ níṣojú rẹ̀. A óò tún gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ míì tó ṣẹ lẹ́yìn ìgbà ayé rẹ̀ yẹ̀ wò. Àwọn míì lára àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kàn ọ́ ní tààràtà báyìí, wọ́n sì máa nípa lórí ọjọ́ ọ̀la rẹ. Jẹ́ kí àyẹ̀wò yìí mú kó o túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀, kó lè túbọ̀ dá ọ lójú pé Ọlọ́run yóò ṣe “ohun tí ó ní lọ́kàn.”—Ìdárò 2:17.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń yan àwọn wòlíì? Kí ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ìparun ń bọ̀ yóò ṣẹ?
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÍ JEREMÁYÀ SỌ TÓ SÌ ṢẸ NÍṢOJÚ RẸ̀
8, 9. Ọ̀nà kan wo ni Bíbélì gbà jẹ́ ìwé tó ta yọ?
8 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbìyànjú láti sọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ara irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, àwọn òṣèlú, àwọn abẹ́mìílò, àtàwọn awojú-ọjọ́. Níwọ̀n bí kò ti sọ́mọ èèyàn tó mọ ọ̀la, wàá ti rí i pé kì í rọrùn láti fọwọ́ sọ̀yà kó o sì sọ pé bí àwọn nǹkan ṣe máa rí ní ayé nìyí láàárín ọjọ́ mélòó kan tàbí ọ̀sẹ̀ mélòó kan kó sì rí bẹ́ẹ̀ láìyingin. Ní ti Bíbélì, ọ̀kan lára àwọn ohun tó mú kó ta yọ ni pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kì í yẹ̀ lọ́nàkọnà. (Aísá. 41:26; 42:9) Èyíkéyìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà kò yẹ̀ rárá, yálà èyí tó sọ nípa àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ tàbí èyí tó sọ nípa ọjọ́ iwájú tó jìnnà sí ìgbà ayé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ nípa àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan, òmíràn sì jẹ́ nípa àwọn orílẹ̀-èdè kan. Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àwọn díẹ̀ tó nímùúṣẹ nígbà ayé Jeremáyà.
9 Ẹ̀dá èèyàn wo lónìí ló lè sọ ipò tí ayé yìí máa wà ní ọdún kan tàbí ọdún méjì sí ìsinsìnyí? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a lè rí ọ̀mọ̀ràn kankan tó ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ń lọ lágbàáyé táá lè fọwọ́ sọ̀yà kó sì sọ bóyá agbára ìṣàkóso máa kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba kan bọ́ sọ́wọ́ òmíràn láàárín àkókò yẹn tàbí kò ní ṣẹlẹ̀? Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìjọba tó máa bọ́ sábẹ́ àkóso Bábílónì máa pọ̀ sí i. Ó ní Bábílónì ni “ife wúrà” tí Jèhófà máa lò láti fi da ìhónú rẹ̀ sórí Júdà àti sórí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú àtàwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àyíká ibẹ̀, yóò sì fipá máa kó wọn sìnrú. (Jer. 51:7) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ níṣojú Jeremáyà àtàwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ nìyẹn.—Fi wé Jeremáyà 25:15-29; 27:3-6; 46:13.
10. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Ọba Júdà mẹ́rin kan?
10 Jèhófà tún gbẹnu Jeremáyà sọ ibi tọ́rọ̀ àwọn ọba Júdà mẹ́rin kan máa já sí. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jèhóáhásì, ìyẹn Ṣálúmù, ọmọ Jòsáyà Ọba, pé yóò lọ sígbèkùn, kò sì ní pa dà sí Júdà mọ́ láéláé. (Jer. 22:11, 12) Ó sì rí bẹ́ẹ̀. (2 Ọba 23:31-34) Ọlọ́run tún sọ pé bí wọ́n “ṣe ń sin akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́” ni wọ́n ṣe máa sin Jèhóákímù tó jọba lẹ́yìn Jèhóáhásì. (Jer. 22:18, 19; 36:30) Bíbélì kò sọ irú ikú tó kú, kò sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òkú rẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìsàgatì Jerúsálẹ́mù ni Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ jọba dípò rẹ̀. Jeremáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhóákínì (tí wọ́n tún ń pè ní Konáyà tàbí Jekonáyà) yóò lọ sígbèkùn ní Bábílónì àti pé ibẹ̀ ló máa kú sí. (Jer. 22:24-27; 24:1) Ìyẹn náà ṣẹ. Sedekáyà Ọba tó jẹ kẹ́yìn ní Júdà náà ńkọ́? Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run máa fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, wọn ò sì ní fi ìyọ́nú hàn sí i. (Jer. 21:1-10) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Àwọn ọ̀tá yẹn mú un lóòótọ́. Wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ níṣojú rẹ̀, wọ́n fọ́ òun alára lójú, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì, níbi tó pa dà kú sí. (Jer. 52:8-11) Bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ pátá nìyẹn.
11. Ta ni Hananáyà, kí sì ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀?
11 A rí i kà ní orí kejìdínlọ́gbọ̀n ìwé Jeremáyà pé nígbà ìjọba Sedekáyà, wòlíì èké kan tó ń jẹ́ Hananáyà lọ ta ko ohun tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ nípa bí Bábílónì ṣe máa jẹ gàba lé Jerúsálẹ́mù lórí. Hananáyà ṣá ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tì, ó ní ṣe ni àjàgà ìsìnrú tí Nebukadinésárì gbé sọ́rùn Júdà àtàwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóò ṣẹ́ dà nù. Àmọ́ Jèhófà darí Jeremáyà láti já Hananáyà ní koro, àti láti tẹnu mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò ní láti sin àwọn ará Bábílónì àti pé wòlíì èké yẹn pàápàá kò ní la ọdún yẹn já. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn.—Ka Jeremáyà 28:10-17.
12. Kí lèrò ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà nípa olórí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an?
12 Àmọ́ ṣá, olórí iṣẹ́ tí Ọlọ́run dìídì fi rán Jeremáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù. Léraléra ni Jeremáyà ṣèkìlọ̀ pé wọ́n máa pa ìlú náà run àyàfi táwọn Júù bá jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, àìṣèdájọ́ òdodo àti ìwà ìkà wọn. (Jer. 4:1; 16:18; 19:3-5, 15) Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ló rò pé Jèhófà ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láéláé. Èrò ọkàn wọn ni pé ìlú Jerúsálẹ́mù ṣáà ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà. Báwo ni Ọlọ́run á ṣe wá gbà kí wọ́n pa irú ibi mímọ́ bẹ́ẹ̀ run? Wọ́n rò pé ìyẹn kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n o mọ̀ pé Jèhófà kì í parọ́. Ohun tí ó ní lọ́kàn gan-an ló sì ṣe.—Jer. 52:12-14.
13. (a) Kí ni ìgbà tiwa fi jọ ìgbà ayé Jeremáyà? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn kan nígbà ayé Jeremáyà?
13 Ipò tó jọ tàwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láyé ìgbà Jeremáyà làwọn èèyàn Ọlọ́run náà wà lóde òní. A mọ̀ pé Jèhófà máa tó mú àjálù bá gbogbo àwọn tó bá kọ etí ikún sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ìlérí tó ti ṣe nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa mú ká nírètí gẹ́gẹ́ bó ṣe mú kí àwọn Júù tí kò jáwọ́ nínú ìsìn mímọ́ nígbà ayé Jeremáyà ní ìrètí. Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Rékábù tó jẹ́ olóòótọ́ sí i, tí wọn kò sì tàpá sí àṣẹ baba ńlá wọn, pé wọ́n máa la ìparun Jerúsálẹ́mù já. Wọ́n sì la ìparun yẹn já lóòótọ́. A lè rí ẹ̀rí pé wọ́n là á já látinú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, pé “Málíkíjà ọmọkùnrin Rékábù” wà lára àwọn tó tún Jerúsálẹ́mù kọ́ nígbà tí Nehemáyà jẹ́ gómìnà. (Neh. 3:14; Jer. 35:18, 19) Jèhófà fi dá Ebedi-mélékì náà lójú pé ó máa la ìparun yẹn já torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé òun ó sì ti Jeremáyà lẹ́yìn. (Jer. 38:11-13; 39:15-18) Ọlọ́run sì tún ṣèlérí fún Bárúkù tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Jeremáyà pé yóò gba ‘ọkàn rẹ̀ bí ohun ìfiṣèjẹ.’ (Jer. 45:1, 5) Níwọ̀n bó o sì ti rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nímùúṣẹ, kí ni ìyẹn ń gbìn sí ìwọ náà lọ́kàn? Kí lo rò pé Jèhófà máa ṣe fún ìwọ náà tó o bá jẹ́ olóòótọ́?—Ka 2 Pétérù 2:9.
Ipa wo ni mímọ̀ tí Ebedi-mélékì, Bárúkù àtàwọn ọmọ Rékábù mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kì í yẹ̀ ní lórí wọn? Kí lèrò ọkàn rẹ nípa irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÓ ṢẸ LẸ́YÌN ÌGBÀ AYÉ JEREMÁYÀ
14. Kí ló mú kí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa Bábílónì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó ta yọ?
14 Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé yàtọ̀ sí pé Nebukadinésárì ọba Bábílónì máa ṣẹ́gun Júdà, yóò tún ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì. (Jer. 25:17-19) Ìyẹn lè dà bí àlá kan tí kò lè ṣẹ, torí pé orílẹ̀-èdè tó lágbára gidi ni Íjíbítì, kódà ó tún ń ṣàkóso Júdà pàápàá. (2 Ọba 23:29-35) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run, àwọn Júù tó ṣẹ́ kù gbìmọ̀ pọ̀ láti kúrò ní Júdà tó jẹ́ ilẹ̀ wọn láti lọ forí pa mọ́ sí Íjíbítì. Wọ́n fàáké kọ́rí pé àwọn máa lọ dandan bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má lọ, pé òun máa bù kún wọn tí wọ́n bá jókòó sí Júdà. Àmọ́, ó fi yé wọn pé tí wọ́n bá kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ òun, tí wọ́n pàpà sá lọ sí Íjíbítì, idà tí wọ́n torí ẹ̀ sá máa lé wọn bá níbẹ̀. (Jer. 42:10-16; 44:30) Òótọ́ ni pé Jeremáyà ò sọ nínú àwọn ìwé rẹ̀ bóyá ìṣojú rẹ̀ ni Bábílónì ṣe wá gbógun ja ilẹ̀ Íjíbítì. Ṣùgbọ́n ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣẹ sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó sá lọ sí Íjíbítì láti lọ forí pa mọ́, ìyẹn nígbà táwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Íjíbítì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Jer. 43:8-13.
15, 16. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe máa gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn ṣe ṣẹ?
15 Jeremáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa òpin Bábílónì tó ṣẹ́gun Íjíbítì pàápàá. Ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ni Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òjijì ni Bábílónì máa pa run, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run sọ pé àwọn omi tó fi ṣe odi ààbò rẹ̀ yóò ‘gbẹ táútáú’ àti pé àwọn alágbára ńlá rẹ̀ kò ní jà rárá. (Jer. 50:38; 51:30) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ látòkè délẹ̀ nígbà táwọn ará Mídíà àti Páṣíà darí Odò Yúfírétì gba ibòmíì, tí wọ́n wọ́dò kọjá ìwọ̀nba èyí tó ṣẹ́ kù, tí wọ́n sì wọnú ìlú Bábílónì, tí wọ́n lọ bá wọn lábo. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wàá rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà sọ, pé ìlú Bábílónì yóò di ahoro títí gbére tún ṣẹ. (Jer. 50:39; 51:26) Bí Bábílónì tó jẹ́ ìlú alágbára láyé ìgbà yẹn sì ṣe wà ní ahoro títí dòní jẹ́ ẹ̀rí pé èyíkéyìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kì í yẹ̀.
16 Jèhófà gbẹnu Jeremáyà kéde pé àwọn Júù máa sin àwọn ará Bábílónì fún àádọ́rin [70] ọdún. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run á wá mú àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà sí ilẹ̀ wọn. (Ka Jeremáyà 25:8-11; 29:10.) Ó dá Dáníẹ́lì lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ṣẹ, ó sì tún tipa àsọtẹ́lẹ̀ yẹn mọ ìgbà tí “ìparundahoro Jerúsálẹ́mù” máa dópin. (Dán. 9:2) Ẹ́sírà náà sì wá sọ pé, “Kí a lè mú ọ̀rọ̀ Jèhófà láti ẹnu Jeremáyà ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí,” ìyẹn ẹni tó ṣẹ́gun Bábílónì, tó fi jẹ́ pé ó dá àwọn Júù pa dà sí Júdà tó jẹ́ ilẹ̀ wọn. (Ẹ́sírà 1:1-4) Ìyẹn jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn tó pa dà wá sí Júdà lè fi ìdùnnú ké jáde nítorí àlàáfíà tó wà ní ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìsìn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀.—Jer. 30:8-10; 31:3, 11, 12; 32:37.
17. Ṣàlàyé bó ṣe lè jẹ́ pé ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà nípa “ẹkún” sísun ní Rámà nímùúṣẹ.
17 Jeremáyà sì tún ṣàkọsílẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé rẹ̀. Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní Rámà, a gbọ́ ohùn kan, ìdárò àti ẹkún kíkorò; Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gba ìtùnú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí pé wọn kò sí mọ́.’” (Jer. 31:15) Ó jọ pé lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tí wọ́n mú lóǹdè wà pa pọ̀ ní ìlú Rámà tó wà ní kìlómítà mẹ́jọ sí ìhà àríwá Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n pa àwọn kan lára àwọn tí wọ́n mú lóǹdè níbẹ̀, tó fi wá di pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́, nítorí ṣe ló máa dà bíi pé Rákélì ń sunkún nítorí àdánù “àwọn ọmọ” rẹ̀. Àmọ́ ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà náà, Hẹ́rọ́dù Ọba ní kí wọ́n pa gbogbo ọmọ ọwọ́ tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sì sọ pé Jeremáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìbànújẹ́ àwọn èèyàn ṣe máa pọ̀ tó nítorí ìpakúpa yẹn.—Mát. 2:16-18.
18. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run nípa Édómù ṣe ṣẹ?
18 Àsọtẹ́lẹ̀ míì tún nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Édómù wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí Bábílónì máa gbógun jà. (Jer. 25:15-17, 21; 27:1-7) Ọlọ́run sì tún sọ àwọn nǹkan míì tó máa ṣẹlẹ̀ sí Édómù. Ó ní Édómù yóò dà bí Sódómù àti Gòmórà. O mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ìyẹn ni pé kò ní séèyàn tó máa gbébẹ̀ mọ́ títí láé, tó fi hàn pé kò ní sí orílẹ̀-èdè náà mọ́. (Jer. 49:7-10, 17, 18) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ibo lo rò pé èèyàn ti lè rí ọ̀rọ̀ náà Édómù tàbí àwọn ará Édómù lóde òní? Ǹjẹ́ a lè rí i lórí ìwé àwòrán ilẹ̀ òde òní kankan? Ó tì o. Inú àwọn ìwé ìtàn nípa ayé àtijọ́ tàbí ìtàn Bíbélì tàbí ìwé àwòrán ilẹ̀ tó ń tọ́ka sí àwọn ibi tó wà láyé ìgbàanì la ti sábà máa ń rí i. Òpìtàn náà Flavius Josephus, sọ nínú ìwé rẹ̀ pé wọ́n fipá sọ àwọn ará Édómù di ẹlẹ́sìn Júù ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Látìgbà tí Jerúsálẹ́mù sì ti pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni ni gbogbo ìran Édómù ti pa rẹ́ mọ́ inú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yòókù.
19. Kí ni ìwé Jeremáyà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe lágbára láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ?
19 Látinú àwọn àyẹ̀wò tá a ti ṣe yìí, wàá ti rí i pé ìwé Jeremáyà kún fún àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí nípa àwọn orílẹ̀-èdè kan. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló sì ti ṣẹ. Kókó yìí nìkan pàápàá tó ohun tó yẹ kó mú ọ gbé ìwé Jeremáyà kó o fara balẹ̀ kà á, torí á jẹ́ kí ohun kan túbọ̀ dá ọ lójú nípa Ọlọ́run rẹ tó tóbi lọ́ba. Ìyẹn sì ni pé Jèhófà ti ṣe ohun tó ní lọ́kàn, yóò sì tún ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ka Aísáyà 46:9-11.) Èyí á jẹ́ kó túbọ̀ dá ọ lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì máa ṣẹ. Àwọn kan tiẹ̀ wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà tí ìmúṣẹ wọn kàn ọ́ ní tààràtà, tó sì máa kan ọjọ́ ọ̀la rẹ. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nínú àwọn ìpínrọ̀ tó kù ní orí yìí.
Sọ díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó nímùúṣẹ lẹ́yìn tí Jeremáyà kú. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe pàtàkì sí ọ?
ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÓ KÀN Ọ́
20-22. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, títí kan àwọn kan nínú ìwé Jeremáyà, máa ń ṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ? Mú àpẹẹrẹ wá.
20 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì máa ń ṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ. Irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìdáhùn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹ lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé ó ṣì máa ṣẹ láwọn ọ̀nà kan nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ wá sorí gbogbo ètò nǹkan búburú yìí. Ìpọ́njú náà máa jẹ́ “irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mát. 24:21) A rí ohun tó jọ èyí nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà náà sọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé “Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀,” èyí tó kọ́kọ́ nímùúṣẹ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tó sì tún wá ní ìmúṣẹ nígbà pípẹ́ lẹ́yìn náà. (Jer. 31:15) Kódà, àwọn kan lára ohun tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ kan àkókò tiwa yìí, ìmúṣẹ wọn sì kan ìwọ gan-an alára.
21 O lè rí àpẹẹrẹ èyí látinú ìwé Ìṣípayá. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà sọ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Bábílónì lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nínú ìwé Ìṣípayá, a rí bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì láyé ìgbà yẹn ṣe jọra pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó gbòòrò gan-an lóde òní. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà tí Jòhánù tọ́ka sí tó ní ìmúṣẹ lóde òní ni ti ìṣubú ilẹ̀ ọba ńlá kan, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí í ṣe “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 14:8; 17:1, 2, 5; Jer. 50:2; 51:8) Àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ní láti “jáde kúrò nínú rẹ̀” bákan náà, kí wọ́n má bàa pín nínú ìparun rẹ̀. (Ìṣí. 18:2, 4; Jer. 51:6) Omi ìlú ńlá yẹn, tó dúró fún àwọn èèyàn rẹ̀, tàbí àwọn tó ń ṣèjọsìn níbẹ̀, máa dèyí tó “gbẹ ráúráú.”—Jer. 51:36; Ìṣí. 16:12.
22 Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣì máa nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa gbẹ̀san gbogbo àìdáa tí ẹ̀sìn èké ti ń ṣe sáwọn èèyàn òun lára rẹ̀. Jèhófà yóò “san án padà fún un gẹ́gẹ́ bí . . . gbogbo ohun tí ó ti ṣe.” (Jer. 50:29; 51:9; Ìṣí. 18:6) Gbogbo ibi tí ẹ̀sìn èké jọba lé lórí ni yóò di ahoro pátápátá.—Jer. 50:39, 40.
23. Kí ni Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ní ọ̀rúndún ogún gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
23 O lè ti kíyè sí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń múni nírètí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremáyà sọ. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn tún máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn tòótọ́ lóde òní. Bí àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí ṣe rí ìdáǹdè gbà kúrò ní Bábílónì Ńlá lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run jọ tàwọn Júù tó wà nígbèkùn nígbàanì, tí wọ́n rí ìdáǹdè gbà kúrò ní ìlú Bábílónì. Ńṣe ni Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní nídè nípa tẹ̀mí, tó mú kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn mímọ́. Èyí sì jẹ́ kí wọ́n kún fún ọpẹ́ àti ayọ̀ yíyọ̀. Ó ti bù kún ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n wá sin Jèhófà, kí wọ́n sì dẹni tó ń jẹ àjẹyó nípa tẹ̀mí. (Ka Jeremáyà 30:18, 19.) Ìwọ náà sì tún mọ̀ láti inú ìrírí tìrẹ bí Jèhófà ṣe ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lóde òní, ìyẹn ìlérí tó ṣe pé òun máa fún àwọn èèyàn òun ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ìyẹn àwọn ọkùnrin tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí, tí wọ́n á máa fìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run tí wọ́n á sì máa dáàbò bò ó.—Jer. 3:15; 23:3, 4.
24. Àsọtẹ́lẹ̀ ńlá wo ni Jeremáyà sọ tí kò tíì nímùúṣẹ?
24 Bí Jeremáyà ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run ìgbàanì mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa fáwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ń kìlọ̀ fún wọn pé ìparun ń bọ̀ wá sórí àwọn tó bá kẹ̀yìn sí Jèhófà. Bọ́rọ̀ ṣe rí lóde òní náà nìyẹn. Kò sí nínú wa tí kò ní rí i pé ìkìlọ̀ tó jẹ́ kánjúkánjú hàn nínú ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ yìí, pé: “Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé. A kì yóò pohùn réré ẹkún nítorí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò kó wọn jọpọ̀ tàbí kí a sin wọ́n. Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà.”—Jer. 25:33.
25. Ojúṣe wo làwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti ṣe lóde òní?
25 Àkókò téèyàn ò gbọ́dọ̀ fi nǹkan falẹ̀ làwa náà ń gbé o, bíi ti ìgbà Jeremáyà. Bó ṣe rí nígbà tirẹ̀ náà ló rí lónìí, ní ti pé, ìhà táwọn èèyàn bá kọ sí iṣẹ́ Jèhófà tá à ń jẹ́ fún wọn ló máa pinnu bóyá wọ́n á yè tàbí wọ́n á pa run. Lóòótọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní kì í ṣe wòlíì, Jèhófà kò sì mí sí wa láti fi kún òótọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pípé tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, Ọlọ́run ti yàn wá pé ká máa wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí di ìparí ètò àwọn nǹkan. (Mát. 28:19, 20) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ‘jí ọ̀rọ̀ Jèhófà gbé lọ,’ ìyẹn ni pé ká bo ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ mọ́lẹ̀ láìsọ fáwọn èèyàn. (Ka Jeremáyà 23:30.) Ìpinnu wa ni pé a ò ní bomi la agbára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ò sì ní pẹ́ ẹ sọ. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà kéde ló ti ṣẹ. Ìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn tó kù kò ní ṣaláì ṣẹ. A gbọ́dọ̀ sọ fáwọn èèyàn pé, láìkùnà, Ọlọ́run yóò ‘ṣe ohun tí ó ní lọ́kàn àtàwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.’—Ìdárò 2:17.
26. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló kù tá a máa gbé yẹ̀ wò?
26 Àgbéyẹ̀wò wa nípa iṣẹ́ wòlíì tí Jeremáyà ṣe àtàwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kò ní kún rẹ́rẹ́ láìjẹ́ pé a ṣàyẹ̀wò àwọn ìlérí pàtàkì tí Jèhófà ṣe pé òun máa bá àwọn èèyàn dá “májẹ̀mú tuntun” kan, èyí tó jẹ́ pé òun máa kọ àwọn òfin rẹ̀ sí ọkàn wọn. (Jer. 31:31-33) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti bó ṣe nímùúṣẹ, èyí tó jẹ́ pé ó kàn ọ́ ní tààràtà, ni kókó tá a máa gbé yẹ̀ wò ní orí tó tẹ̀ lé èyí.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jeremáyà wo ló ti ṣẹ lóde òní? Kí lèrò rẹ nípa àwọn èyí tó kù tí kò tíì ṣẹ?