Orí Kejìlá
“Ìyẹn Kì í Ha Ṣe Ọ̀ràn Mímọ̀ Mí Bí?”
1, 2. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kí Jèhóákímù dáwọ́ lé iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń ṣe?
JÈHÓÁKÍMÙ ỌBA ń kọ́ ilé kan, ajé-kú-ìjókòó ilé ni. Ilé oníyàrá gbàràmù gbaramu, olókè méjì ó kéré tán, ló ń kọ́. Àwọn fèrèsé gbígbòòrò tó máa ní yóò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn lè máa mọ́lẹ̀ wọlé rekete, ọba àtàwọn ará ilé rẹ̀ á sì tún máa rí atẹ́gùn tó ń fẹ́ lẹlẹ gbà sára. Igi kédárì olóòórùn dídùn láti Lẹ́bánónì, tí wọ́n gé pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ, ló fẹ́ fi ṣọ̀ṣọ́ sára ògiri ilé náà. Ọ̀dà aláwọ̀ pupa fòò, tí wọ́n ń kó wá láti ilẹ̀ òkèèrè, èyí táwọn ọlọ́lá àti alágbára ilẹ̀ òkèèrè yàn láàyò torí ẹwà rẹ̀, ló fẹ́ fi kun inú ilé náà.—Jer. 22:13, 14.
2 Owó kékeré kọ́ ni iṣẹ́ ilé náà máa ná an. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, lákòókò yẹn, ètò ààbò ilẹ̀ náà àti owó òde tí ilẹ̀ Íjíbítì bù lé wọn ti gbọ́n àpò orílẹ̀-èdè náà gbẹ. (2 Ọba 23:33-35) Àmọ́ Jèhóákímù wá ọgbọ́n dá láti rówó kọ́ ààfin tuntun rẹ̀. Lọ́nà wo? Ó kọ̀ kò sanwó fáwọn òṣìṣẹ́ tó ń bá a kọ́ ààfin yẹn! Ó ń lò wọ́n nílò ẹrú, pé kí wọ́n ka òógùn ojú wọn nídìí iṣẹ́ àṣekúdórógbó yẹn sí ojúṣe wọn sí ìjọba òun.
3. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Jèhóákímù àti baba rẹ̀, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
3 Ọlọ́run wá gbẹnu Jeremáyà dá Jèhóákímù lẹ́bi fún ìwà ìmọtara-ẹnì-nìkan rẹ̀ yẹn.a Ó rán ọba yẹn létí pé baba rẹ̀, Jòsáyà Ọba, ṣe inúure púpọ̀ gan-an sáwọn òṣìṣẹ́ orílẹ̀-èdè náà àtàwọn tálákà, ó sì lawọ́ sí wọn. Ó tiẹ̀ ń bá wọn gba ẹjọ́ wọn rò nílé ẹjọ́ pàápàá. Jèhófà sì wá pàfiyèsí Jèhóákímù sí bí Jòsáyà ṣe gba tàwọn aláìní rò, ó sì béèrè pé: “Ìyẹn kì í ha ṣe ọ̀ràn mímọ̀ mí bí?”—Ka Jeremáyà 22:15, 16.
4. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ mímọ Jèhófà?
4 Bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé Sátánì yìí, a nílò ìrànlọ́wọ́ àti ààbò Jèhófà, èyí tó máa ń wà fún àwọn tó bá mọ̀ ọ́n dunjú. Nítorí náà, ṣe ló yẹ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Ó yẹ ká sì tún máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ ká bàa lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà láṣeyọrí. Ṣùgbọ́n o lè wá máa rò ó pé, ‘Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè mọ Jèhófà dunjú bíi ti Jòsáyà Ọba?’
OHUN TÓ Ń FI HÀN PÉ ÈÈYÀN MỌ ỌLỌ́RUN
5, 6. (a) Ipa wo ni ìwà bàbá rere máa ń ní lórí àwọn ọmọ rẹ̀? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ti mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà, èyí tí Jèhóákímù kò ṣe?
5 Wo àwọn ọ̀nà tí ìwà bàbá rere kan lè gbà nípa lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Bí wọ́n bá ń rí i pé bàbá wọn lawọ́ sí àwọn tí kò ní, àwọn náà lè di ọ̀làwọ́. Bí wọ́n ṣe ń rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ ìyá wọn tó sì ń fọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n lè dẹni tó ń gba ti àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin bíi tiwọn tàbí obìnrin bíi tiwọn rò. Bí wọ́n bá sì ń gbọ́ pé bàbá àwọn jẹ́ olóòótọ́ àtẹni tó ṣeé fọkàn tán lórí ọ̀rọ̀ owó, àwọn náà lè di olóòótọ́ èèyàn àtẹni tó ṣeé fọkàn tán. Bó sì ṣe jẹ́ pé ẹní bíni làá jọ, bí àwọn ọmọ náà ṣe ń mọ ìwà àti ìṣe bàbá wọn sí àwọn èèyàn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fìwà jọ ọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.
6 Bákan náà, Kristẹni tó bá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi ti Jòsáyà, kò ní wulẹ̀ gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Á máa ka Bíbélì, èyí táá jẹ́ kó mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn ẹ̀dá rẹ̀ lò, á sì fẹ́ láti fìwà jọ Baba rẹ̀ ọ̀run. Ṣe lá máa fẹ́ràn Jèhófà sí i lójoojúmọ́ bó ṣe túbọ̀ ń kórìíra àwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra tó sì ń fẹ́ àwọn ohun tó fẹ́. Ṣùgbọ́n, tẹ́nì kan bá kẹ̀yìn sí àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run, tí kò jẹ́ kí Ọlọ́run darí ìgbésí ayé òun, kò lè mọ Ọlọ́run tòótọ́ rárá. Ṣe lonítọ̀hún máa dà bíi Jèhóákímù, tó kó ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jeremáyà kọ dà sínú iná.—Ka Jeremáyà 36:21-24.
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ Jèhófà bíi ti Jòsáyà Ọba?
7 Bá a bá máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, tá a sì máa wà lára àwọn tó máa gbé nínú ayé tuntun, a gbọ́dọ̀ mọ Jèhófà dunjú. (Jer. 9:24) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó hàn nínú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ. Bá a ó ṣe máa gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yìí yẹ̀ wò, máa wá ọ̀nà tí ìwọ alára lè gbà mọ Jèhófà kó o sì fìwà jọ ọ́ bíi ti Jòsáyà Ọba.
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jòsáyà Ọba mọ Jèhófà dunjú? Kí ni wàá máa ṣe tó o bá mọ Jèhófà bí Jòsáyà ṣe mọ̀ ọ́n?
“INÚ RERE RẸ̀ ONÍFẸ̀Ẹ́ WÀ FÚN ÀKÓKÒ TÍ Ó LỌ KÁNRIN!”
8. Ṣàlàyé ohun tí inú rere onífẹ̀ẹ́ jẹ́.
8 Ní ọ̀pọ̀ èdè, ó ṣòro láti rí ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ ṣókí tó lè ṣàkópọ̀ gbogbo ìtumọ̀ ohun tí wọ́n ń pe ànímọ́ Ọlọ́run kan lédè Hébérù, èyí tá a tú sí inú rere onífẹ̀ẹ́, tàbí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ohun tí ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì kan sọ ni pé, ńṣe lọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pe ànímọ́ Ọlọ́run yìí lédè Hébérù ń ṣàpèjúwe bí agbára, ìdúróṣinṣin àti ìfẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Ìwé yìí tún fi kún un pé: “Àlàyé èyíkéyìí tí kò bá ní nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nínú kò tíì gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn yọ dáadáa.” Èyí fi hàn pé ẹni tó bá ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ báni lò, ju ẹni tá a kàn lè pè ní ọmọlúwàbí èèyàn lọ. Nítorí aájò èèyàn tírú ẹni bẹ́ẹ̀ ní, ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lè bá ẹni tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ yanjú ìṣòro rẹ̀, pàápàá àwọn ohun tó bá jẹ mọ́ nǹkan tẹ̀mí. Ìdí pàtàkì tó sì fi ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ múnú Ọlọ́run Olódùmarè dùn.
9. Kí ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò jẹ́ ká mọ̀?
9 Téèyàn bá fẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “inú rere onífẹ̀ẹ́” nínú Bíbélì, ọ̀nà tó dáa jù ni pé kéèyàn fara balẹ̀ wo bí Ọlọ́run ṣe ti ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò látayébáyé wá. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ogójì ọdún tí wọ́n lò ní aginjù, ó sì pèsè àtijẹ àtimu fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run tún yan àwọn onídàájọ́ fún wọn, tó ń gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, tó sì ń dá wọn pa dà sínú ìjọsìn tòótọ́. Torí pé Jèhófà dúró ti orílẹ̀-èdè náà gbágbáágbá nígbà dídùn àti nígbà kíkan jálẹ̀ ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ yẹn, ó lè sọ fún wọn pé: “Ìfẹ́ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni mo fi nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ìdí nìyẹn tí mo fi fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́.”—Jer. 31:3.b
10. Tá a bá wo àpẹẹrẹ tàwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì, báwo ni Jèhófà ṣe ń lo inú rere onífẹ̀ẹ́ nínú ọ̀nà tó gbà ń gbọ́ àdúrà?
10 Lóde òní, Ọlọ́run ṣì ń bá a nìṣó láti ṣe inú rere onífẹ̀ẹ́ lọ́nà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi ń jàǹfààní rẹ̀ ní tààràtà. Jẹ́ ká fi ti àdúrà gbígbà ṣe àpẹẹrẹ. Lóòótọ́ gbogbo àdúrà táwọn èèyàn bá gbà tọkàntọkàn ni Jèhófà máa ń ṣàkíyèsí, àmọ́ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ya ara wọn sí mímọ́ bá ń gbàdúrà, ṣe ló máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń gbàdúrà nípa àwọn ìṣòro kan tí kò lọ bọ̀rọ̀, àdúrà wa kì í dá Ọlọ́run lágara; bẹ́ẹ̀ ni àdúrà wa kì í sú u. Nígbà kan, Jèhófà ní kí Jeremáyà rán iṣẹ́ kan sí àwùjọ àwọn Júù kan tó ti dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì. Odindi ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà ni wọ́n wà sí ilẹ̀ Júdà níbi tí tẹ́ńpìlì wà, lọ́nà jíjìn réré sí ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àmọ́ ọ̀nà jíjìn tí wọ́n wà sí tẹ́ńpìlì ò ní kí Jèhófà má ṣe gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n ń bẹ̀ láti rí ojú rere rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń yìn ín. Sì wo bó ṣe máa jẹ́ ìtùnú tó fáwọn Júù nígbà tí wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Jeremáyà 29:10-12. (Kà á.) Bákan náà ni Jèhófà ṣe máa gbọ́ àdúrà àtọkànwá tó o bá gbà.
11, 12. (a) Kí ni Jèhófà ṣèlérí fáwọn ará Jerúsálẹ́mù? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà fẹ́nì kan tí wọ́n ti bá wí?
11 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jèhófà máa ń lo inú rere onífẹ̀ẹ́ ni bó ṣe máa ń mọ̀ pé ohun tó bà, kò tíì bà jẹ́. Bí ìparun Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé, táwọn èèyàn ibẹ̀ sì kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí, ibo lọ̀rọ̀ wọn máa já sí? Yálà kó jẹ́ pé ìyàn ló máa pa wọ́n tàbí kó jẹ́ pé ọmọ ogun Bábílónì láá fi idà pa wọ́n. Tí ìyẹn bá sì fò wọ́n ru, wọ́n lè dèrò ìgbèkùn fún àìmọye ọdún kí wọ́n wá kú sí ilẹ̀ òkèèrè. Síbẹ̀ náà, Jèhófà sọ “ọ̀rọ̀ rere” fún àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì yí pa dà. Ó ṣèlérí pé òun máa ‘yí àfiyèsí òun sí wọn.’ Ó lóun máa ‘mú wọn padà wá sí ibí yìí,’ ìyẹn sí ilẹ̀ wọn, láti iyànníyàn Bábílónì. (Jer. 27:22) Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè fi ìdùnnú kígbe pé: “Ẹ gbé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lárugẹ, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin!”—Jer. 33:10, 11.
12 Inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní, mú kó jẹ́ Orísun ìṣírí fáwọn tó dà bíi pé ọ̀rọ̀ wọn ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Lónìí, àwọn kan wà tí wọ́n ti fìgbà kan rí wà nínú ìjọ Ọlọ́run, àmọ́ tí wọ́n fún ní ìbáwí tó tọ́ sí wọn. Ojú lè gbà wọ́n tì gan-an nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn débi pé wọ́n á máa lọ́ tìkọ̀ láti tún pa dà sáàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Wọ́n lè máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà máa lè dárí jì àwọn láéláé, kó sì gba àwọn pa dà. Ọlọ́run Olódùmarè ní “ọ̀rọ̀ rere” fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ gbà, èyí táá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti yí ìwà àti èrò ọkàn wọn pa dà bó ṣe yẹ. Ohun tá a kà ní ìpínrọ̀ kọkànlá sì lè wá ṣẹ sí wọn lára lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ni pé, Jèhófà yóò “mú wọn padà bọ̀” sí àyè wọn láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ aláyọ̀.—Jer. 31:18-20.
13. Kí nìdí tó fi yẹ kí dídúró tí Jèhófà dúró ti Jeremáyà jẹ́ ìṣírí fún ọ?
13 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run onínúure onífẹ̀ẹ́, gbágbáágbá ló máa ń dúró ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé Sátánì yìí, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà yóò máa pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó bá ń wá Ìjọba rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, yóò sì máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wọn. Rántí pé nígbà tó kù díẹ̀ náà kí Jerúsálẹ́mù pa run, ojú Jèhófà nìkan ṣoṣo ló kù tí Jeremáyà ń wò fún ìpèsè oúnjẹ àti ààbò. Ọlọ́run ò sì já wòlíì náà kulẹ̀. (Jer. 15:15; ka Ìdárò 3:55-57.) Ìṣòro yòówù kó dé bá ìwọ náà, bó ti wù kó le tó, máa rántí pé Jèhófà kò ní gbàgbé gbogbo bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sóun. Nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, yóò tì ọ́ lẹ́yìn débi pé ìṣòro èyíkéyìí kò ní lè borí rẹ.—Fi wé Ìdárò 3:22.
Èwo ló wù ọ́ jù nínú àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn? Kí nìdí tó fi wù ọ́?
“BÍ JÈHÓFÀ TI Ń BẸ LÁÀYÈ . . . NÍ ÌDÁJỌ́ ÒDODO!”
14. Àwọn ìwà ìrẹ́jẹ wo lo ti ṣàkíyèsí láìpẹ́ yìí?
14 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́wọ̀n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn ò ṣẹ̀ rárá. Kódà ó ti ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fẹ́nì kan tí wọ́n sì ti pa á kí wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí ẹ̀rí pé kò tiẹ̀ mọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yẹn. Láwọn orílẹ̀-èdè kan lóde òní, àìrí oúnjẹ jẹ ń sún àwọn òbí míì débi pé wọ́n ń ta ọmọ wọn sóko ẹrú kí ìdílé wọn lè rí oúnjẹ jẹ. Báwo ni irú ìwà ìrẹ́jẹ tó burú jáì bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá gbọ́ ọ? Báwo lo ṣe rò pé ó máa ń rí lára Jèhófà? Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ láti mú gbogbo ohun tó ń fa ìjìyà kúrò. Òun nìkan ṣoṣo ló sì lè ṣe é. Nítorí náà, kí àwọn tálákà àti àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ tó ń jìyà lónìí má ṣe bọkàn jẹ́. Jèhófà, Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo, ń ṣe nǹkan kan lórí bó ṣe máa yọ wọ́n nínú ìnira tí wọ́n wà.—Jer. 23:5, 6.
15, 16. (a) Òótọ́ pọ́ńbélé nípa Jèhófà wo ni Jeremáyà jẹ́ ká mọ̀? (b) Kí nìdí tó o fi lè gbára lé àwọn òfin àtàwọn ìlérí Ọlọ́run?
15 Nígbà ayé Jeremáyà, àwọn kan mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ni onídàájọ́ òdodo tó ga jù. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Jeremáyà sọ pé ó ṣeé ṣe kí Ísírẹ́lì ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n tiẹ̀ tún sọ ọ̀rọ̀ tó máa dà bí ẹ̀rí pé ọkàn wọn ti yí pa dà lóòótọ́, kí wọ́n ní: “Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè ní òtítọ́, ní ìdájọ́ òdodo àti ní òdodo!” (Jer. 4:1, 2) Òótọ́ sì ni ọ̀rọ̀ wọn yìí torí àìṣòdodo jìnnà sí gbogbo ọ̀nà Jèhófà pátápátá. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀rí míì tún wà tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ìdájọ́ òdodo gan-an ni.
16 Ọlọ́run kì í sọ̀rọ̀ kó yẹ̀ rárá, kì í sì í ṣe àgàbàgebè. Ọ̀rọ̀ tirẹ̀ kò dà bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń ṣèlérí tí wọn kì í mú un ṣẹ. Kódà àwọn òfin àdáyébá tí Ọlọ́run ṣe pé kó máa darí ayé àtọ̀run, èyí tá à ń jàǹfààní rẹ̀, kì í yẹ̀ rárá. (Jer. 31:35, 36) Bákan náà, a lè gbára lé àwọn ìlérí rẹ̀ àtàwọn ìdájọ́ rẹ̀, nítorí ìlérí tó dájú àti ìdájọ́ rere ni wọ́n máa ń jẹ́.—Ka Ìdárò 3:37, 38.
17. (a) Kí ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá ń ṣèdájọ́? (b) Kí nìdí tó o fi lè fọkàn tán àwọn alàgbà bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn ìṣòro tó bá yọjú nínú ìjọ? (Wo àpótí náà “Àwọn Onídàájọ́ Tó Ń Ṣojú fún Jèhófà,” lójú ìwé 148.)
17 Bí Jèhófà bá ń ṣèdájọ́, kì í fi ohun tó hàn sójútáyé lásán dájọ́. Ó máa ń kọ́kọ́ wo gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ délẹ̀ ná, láti lè róòótọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ó tún máa ń wo ohun tó sún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Lóde òní, àwọn dókítà ti ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn àkànṣe ẹ̀rọ kan tí wọ́n lè fi wo inú ọkàn èèyàn bó ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Wọ́n sì lè ṣàyẹ̀wò kíndìnrín èèyàn, èyí tó ń sẹ́ ìdọ̀tí kúrò nínú ẹ̀jẹ̀. Àmọ́ Jèhófà lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì. Ó máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, á fi wo ohun tó súnni ṣe nǹkan kan, á sì tún ṣàyẹ̀wò kíndìnrín ìṣàpẹẹrẹ, láti mọ bí nǹkan tónítọ̀hún ṣe ṣe rí lára rẹ̀ nínú lọ́hùn-ún. Yóò wá fìyẹn mọ ìdí tẹ́nì kan fi hùwà tó hù àti bí àwọn ohun tó ṣe yẹn ṣe rí lára rẹ̀. Bó sì ṣe wù kí kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan tí Olódùmarè rí látinú àyẹ̀wò fínnífínní tó ṣe ti pọ̀ tó, kì í kà á láyà. Níwọ̀n bí òye tirẹ̀ sì ti ta yọ ti adájọ́ tó ní ìjìnlẹ̀ òye jù láyé ńbí, ó máa ń lo gbogbo ìsọfúnni tó bá rí bó ṣe yẹ, láti fi pinnu irú ìdájọ́ tó tọ́ sí wa.—Ka Jeremáyà 12:1a; 20:12.
18, 19. Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ipa wo ló yẹ kí ìyẹn ní lórí wa?
18 Nítorí náà, ìdí pàtàkì wà fún ọ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àní tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá tiẹ̀ ń dà ọ́ láàmù nígbà míì nítorí àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn. Máa rántí pé Jèhófà kì í ṣe amòfin tó ń wonkoko mọ́ràn kó ṣáà lè rí nǹkan kan gbá mú láti fi jẹni níyà, kàkà bẹ́ẹ̀, aláàánú Adájọ́ tó ń fẹ́ láti ranni lọ́wọ́ ni Jèhófà. Tí ọkàn rẹ kò bá balẹ̀ nítorí ìwà kan tó o ti hù sẹ́yìn tàbí lórí ọ̀ràn kan tó wà láàárín ìwọ àti ẹlòmíì, bẹ Jèhófà pé kó jọ̀wọ́ ‘gba ìjà rẹ jà,’ ìyẹn ni pé kó rí sí ìdààmú ọkàn rẹ, kí ọkàn rẹ lè kúrò lórí ọ̀rọ̀ náà.c Ọlọ́run yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ débi tí wàá fi rí i pé ohun tó jẹ Ọlọ́run lógún ni pé kó o máa bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ò ń ṣe nìṣó.—Ka Ìdárò 3:58, 59.
19 Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé, Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo pípé, retí pé kí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ rí ojú rere òun máa ṣe ìdájọ́ òdodo. (Jer. 7:5-7; 22:3) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run nínú bó ṣe ń ṣe ìdájọ́ òdodo ni pé ká máa wàásù ìhìn rere láìṣe ojúsàájú. Tó o bá fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe lò ń gbé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run tó ga jù yọ lọ́nà tó ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní gidi. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé kí gbogbo èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Ìdárò 3:25, 26) O ò rí i pé àǹfààní ńlá lo ní láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, bó o ṣe ń gbé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yọ lẹ́nu iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yẹn!
Ọ̀nà wo ni ìdájọ́ òdodo tí Jèhófà ń ṣe lè gbà máa tù ọ́ nínú? Báwo lo ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run kó o lè máa tu àwọn èèyàn nínú?
“ÈMI KÌ YÓÒ MÁA FÌBÍNÚ HÀN FÚN ÀKÓKÒ TÍ Ó LỌ KÁNRIN”
20. (a) Kí ni Jeremáyà jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn lò? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń “pèrò dà” tó bá ti lè dárí ji àwọn èèyàn? (Wo àpótí náà “Báwo Ni Jèhófà Ṣe Máa Ń ‘Pèrò Dà’?”)
20 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kìkì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi bẹnu àtẹ́ lu ìwà ibi ló kún inú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò. Àmọ́, ńṣe làwọn tó rò bẹ́ẹ̀ gbójú fo gbogbo ibi tí Jèhófà ti ń fìfẹ́ sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ nínú ìwé méjèèjì pé òun ṣe tán láti dárí jì wọ́n. Jèhófà rọ àwọn Júù pé: “Kí olúkúlùkù jọ̀wọ́ yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere.” Jeremáyà náà tún rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere, ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí ó ti sọ lòdì sí yín.” (Jer. 18:11; 26:13) Lóde òní pẹ̀lú, Jèhófà máa ń dárí ji gbogbo àwọn tó bá ń kẹ́dùn tinútinú lórí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n sì jáwọ́ nínú rẹ̀.
21. Kí ni Jèhófà máa ń fẹ́ kó tún pa dà ṣẹlẹ̀ tó bá ti dárí ji ẹnì kan?
21 Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ ni ìdáríjì Jèhófà mọ sí o. Ó máa ń fi hàn nínú ìwà pé òun dárí jini. Jèhófà gbẹnu Jeremáyà rọ àwọn Júù pé: “Padà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ . . . Èmi kì yóò jẹ́ kí ojú mi sọ̀ kalẹ̀ tìbínú-tìbínú sórí yín . . . Èmi kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Jer. 3:12) Tí Ọlọ́run bá ti lè dárí ji èyíkéyìí nínú àwọn èèyàn rẹ̀, kì í tún gbin ọ̀rọ̀ náà sínú, ṣe ló máa ń tán pátápátá lọ́kàn rẹ̀. Òótọ́ ni pé onítọ̀hún ṣẹ̀ ẹ́, síbẹ̀ ó máa ń fẹ́ kí àárín òun àtẹni náà tún pa dà gún. Irú ẹ̀ṣẹ̀ yòówù kí ẹnì kan ṣẹ̀, tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, Jèhófà yóò ‘mú un padà wá’ kó lè tún máa rí ojú rere àti ìbùkún rẹ̀ gbà. (Jer. 15:19) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí fún àwọn tó bá ti rìn jìnnà sí Ọlọ́run tòótọ́ níṣìírí kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Láìsí àní-àní, wàá gbà pé bí Jèhófà ṣe ń dárí jini yìí ń fà wá sún mọ́ ọn.—Ka Ìdárò 5:21.
22, 23. Bó o ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà láti máa dárí jini, kí ló yẹ kó máa wà lọ́kàn rẹ?
22 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ṣẹ̀ ọ́ nítorí pé kò ronú dáadáa kó tó sọ̀rọ̀ tàbí kó tó ṣe nǹkan kan, ṣé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà? Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn Júù ayé ìgbàanì ni pé òun yóò ‘wẹ’ àwọn tóun ti dárí jì “mọ́ gaara.” (Ka Jeremáyà 33:8.) Ó lè wẹ àwọn tó bá dárí jì mọ́, tàbí kó nu ẹ̀ṣẹ̀ wọn dà nù, ní ti pé yóò mọ́kàn kúrò pátápátá lórí ohun tí wọ́n ṣe, á sì jẹ́ kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn òun lákọ̀tun. Àmọ́ ṣá, pé Ọlọ́run dárí ji ẹnì kan kò fi hàn pé onítọ̀hún ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ táwa èèyàn jogún, pé ó ti di ẹ̀dá pípé tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run sọ nípa bóun ṣe ń wẹ ẹ̀dá èèyàn mọ́ gaara. Ẹ̀kọ́ yẹn ni pé a lè mọ́kàn kúrò pátápátá lórí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ṣẹ̀ wá, tí yóò fi dà bí ẹni pé a wẹ ẹni náà mọ́ gaara lọ́kàn wa láìní máa fojú àbùkù wò ó mọ́. Báwo la ṣe máa ṣe é?
23 Jẹ́ ká sọ pé o jogún àwo wúrà iyebíye kan. Tí ìdọ̀tí bá yí i lára tàbí tí àbàwọ́n kàn án, ṣé wàá kàn jù ú nù ni? Bóyá ni wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Àfàìmọ̀ lo ò ní sa gbogbo ipá rẹ láti fọ ìdọ̀tí náà kúrò pátápátá tàbí kó o rí i pé àbàwọ́n náà ṣí kúrò. Wàá fẹ́ rí i pé ẹwà rẹ̀ tún yọ gan-an, kó sì máa dán gológoló. Lọ́nà kan náà, ńṣe ni kó o sa gbogbo ipá rẹ láti fa ìbínú ohun tí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan ṣe sí ọ tu kúrò lọ́kàn pátápátá. Bí ọ̀rọ̀ tẹ́ni náà sọ tàbí ìwà tó hù tó ń dùn ọ́ bá fẹ́ máa pa dà wá sí ọ lọ́kàn, gbógun ti èrò náà kó o má ṣe gbà á láyè. Bí o ṣe mú gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn kúrò lọ́kàn, tó o gbàgbé ẹ̀, ńṣe lo wẹ irú ojú tó o fi ń wo ẹni tó o dárí jì náà àtohun tó ò ń rántí nípa rẹ̀ mọ́ lọ́kàn rẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yín lè ti fẹ́ di àjàtúká tẹ́lẹ̀, ìwọ àtẹni náà tún lè pa dà rẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i níwọ̀n bó ò ti ní nǹkan kan lọ́kàn sí i mọ́.
24, 25. Àwọn àǹfààní wo lo máa jẹ tó o bá mọ Jèhófà bíi ti Jòsáyà Ọba?
24 Díẹ̀ péré la tíì gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń báni lò tá a rí kọ́ bá a ṣe túbọ̀ ń mọ̀ ọ́n sí i. A ti wá rí i pé àwọn àǹfààní tá à ń rí nínú mímọ̀ tá a mọ Jèhófà dunjú máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sa gbogbo ipá wa láti sìn ín lọ́nà tó ń fẹ́. Tá a bá dẹni tó mọ Jèhófà dunjú bíi ti Jòsáyà Ọba, ìgbésí ayé aláyọ̀ la ó máa gbé, a sì mọ̀ pé ayọ̀ jẹ́ ara ànímọ́ Ọlọ́run.
25 Tá a bá mọ Jèhófà dáadáa, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn á túbọ̀ máa dára sí i. Bá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ ẹni tó ní inú rere onífẹ̀ẹ́, onídàájọ́ òdodo, àtẹni tó ń dárí jini bíi ti Jèhófà, ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú àwọn ará wa á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, àá sì di kòríkòsùn ara wa. Yàtọ̀ síyẹn, a ó dẹni tó túbọ̀ ń kọ́ni lọ́nà tó múná dóko nígbà ìpadàbẹ̀wò ní ìpínlẹ̀ wa, àtẹni tó ń ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú. Ìgbé ayé Kristẹni tí à ń gbé yóò túbọ̀ máa wu àwọn olùfìfẹ́hàn wa. Ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n dẹni tó ń sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa rìn ní “ọ̀nà tí ó dára.”—Jer. 6:16.
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú Ìdárò 5:21?
a Ní ti bí Jèhóákímù ṣe kàgbákò, wo Orí Kẹrin, ìpínrọ̀ kejìlá nínú ìwé yìí.
b Ọ̀nà tí Bíbélì The New English Bible gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí ni: “Àtayébáyé ni mo ti nífẹ̀ẹ́ rẹ gidigidi, àní títí di ìsinsìnyí mo ṣì ń tọ́jú rẹ lójú méjèèjì.”
c Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá lọ́wọ́ nínú ìwà tó ṣe kedere pé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ sọ fún àwọn alàgbà ìjọ kí wọ́n lè bójú tó ọ̀ràn náà kí wọ́n sì fi ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ ran ẹni náà lọ́wọ́.—Ják. 5:13-15.