Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
MARCH 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 1-4
“Mo Wà Pẹ̀lú Rẹ Láti Dá Ọ Nídè”
Ta Ni Ìwọ Ń Ṣègbọràn Sí—Ọlọ́run Ni Tàbí Ènìyàn?
18 Ọlọ́run sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.” (Jeremáyà 1:8) Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dá wa nídè nígbà inúnibíni lóde òní? Ó lè lo adájọ́ tí kò lẹ́tanú bó ṣe lo Gàmálíẹ́lì. Ó sì tún lè rí sí i pé wọ́n yọ òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ tàbí alátakò nípò láìròtẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì fi òmíràn tó jẹ́ ọmọlúwàbí rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, Jèhófà lè máà dá inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn rẹ̀ dúró. (2 Tímótì 3:12) Bí Ọlọ́run bá gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa láyè, kò ní ṣàì fún wa lókun tá a ó fi lè fara dà á. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ohunkóhun tí Ọlọ́run bá sì ti gbà láyè, a mọ ohun tó máa yọrí sí dájúdájú, òun sì ni pé: Gbogbo àwọn tó ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run jà ń bá Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jà, àwọn tó bá sì ń bá Ọlọ́run jà kò ní borí láéláé.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
2:13, 18. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ ṣe ohun méjì tó burú jáì. Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, ẹni tó jẹ́ pé òun ni orísun ìbùkún, ìtọ́sọ́nà, àti ààbò. Wọ́n wá lọ gbẹ́ ìkùdu tiwọn fúnra wọn, tó túmọ̀ sí pé wọ́n lọ bá àwọn ọmọ ogún Íjíbítì àti Ásíríà pé kí wọ́n gba àwọn. Ní àkókò tiwa yìí, tẹ́nì kan bá fi Ọlọ́run tòótọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀kọ́ àti èrò ọmọ aráyé àti nítorí ìṣèlú ayé, ńṣe lonítọ̀hún fi “àwọn ìkùdu fífọ́” rọ́pò “orísun omi ààyè.”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
4:10; 15:18—Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà tan àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dàlẹ̀? Nígbà ayé Jeremáyà, àwọn wòlíì kan wà tí wọ́n máa ń sọ “àsọtẹ́lẹ̀ èké.” (Jeremáyà 5:31; 20:6; 23:16, 17, 25-28, 32) Jèhófà ò dá àwọn wòlíì wọ̀nyí dúró kí wọ́n má kéde àwọn ọ̀rọ̀ tó lè ṣi èèyàn lọ́nà.
MARCH 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 5-7
“Wọn Ò Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ Mọ́”
w88 4/1 11-12 ¶7-8
Jeremiah—Aláìgbajúmọ̀ Wolii Awọn Idajọ Ọlọrun
7 “Ṣugbọn wọn yoo ba ọ jà,” ni Jehofah kilọ, “wọn kì yoo sì lè bori rẹ.” (Jeremiah 1:19) Nísinsinyi eeṣe tí awọn Jew ati awọn oluṣakoso wọn fi fẹ́ bá wolii yii jà? Nitori pe ihin-iṣẹ rẹ̀ gbejako itẹlọrun-aibikita wọn ati àṣà afìdímúlẹ̀ ijọsin wọn. Jeremiah kò fẹ̀lẹ̀ debi fun wọn: “Sá wòó! ọrọ [Jehofah] di ẹgan sí wọn, wọn kò ní inudidun ninu rẹ̀. Lati kekere wọn titi dé nla wọn, gbogbo wọn ni ó fi araawọn fun ojukokoro, ati lati wolii titi dé alufaa [awọn ẹni gan-an tí ó yẹ kí wọn jẹ́ ẹṣọ awọn ohun iyebiye tẹmi ati ọnaiwahihu], gbogbo ní nṣe eke.”—Jeremáyà 6:10, 13.
8 Nitootọ, wọn nṣiwaju orilẹ-ede naa ninu ṣiṣe awọn irubọ. Wọn ndibọn ṣiṣe ijọsin tootọ, ṣugbọn awọn ọkan-aya wọn kò sí ninu rẹ̀. Aato ṣiṣe tumọsi ohun pupọ fun wọn ju iwa tí ó tọ́. Ní akoko kan-naa, awọn aṣaaju isin Jew nfi pẹ̀lẹ́tu mú orilẹ-ede naa rọlẹ̀ sinu imọlara ailewu eke kan, ni wiwipe, “Alaafia! Alaafia!” nigbati kò sí alaafia. (Jeremáyà 6:14; 8:11) Bẹẹni, wọn mú awọn eniyan naa huwa omugọ ninu gbigbagbọ pe wọn wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun. Wọn nimọlara pe kò sí ohunkohun lati ní wahala-ọkan lelori, nítori pe wọn jẹ́ awọn eniyan Jehofah tí a ti gbala, tí wọn ní ilu-nla mimọ naa ati temple rẹ̀ ní ìní. Ṣugbọn njẹ bẹẹ yẹn ni Jehofah ṣe bojuwo ipo-ọran naa bí?
w88 4/1 12 ¶9-10
Jeremiah—Aláìgbajúmọ̀ Wolii Awọn Idajọ Ọlọrun
9 Jehofah pa á laṣẹ fun Jeremiah lati duro ní ipò-àyè kan ní ẹnu-ọna temple naa nibiti gbogbo eniyan yoo ti rí i kedere kí o sì sọ ihin-iṣe Rẹ̀ fun awọn olujọsin tí wọn nwo ibẹ. Oun nilati so fun wọn pe: “Ẹ maṣe gbẹkẹle ọrọ eke, wipe, ‘temple [Jehofah], temple [Jehofah], temple [Jehofah] ni eyi!’ . . . Kò ní èrè.” Awọn Jew nrin nipa riri, kii ṣe nipa igbagbọ, gẹgẹbi wọn ti nṣogo ninu temple wọn. Wọn ti gbagbe awọn ọrọ Jehofah ti npese iṣọra funni naa pé: “Ọrun ni itẹ mi [ilẹ̀-ayé] sì ni apoti itisẹ mi: nibo ni ile tí ẹ kọ́ fun mi gbé wà?” Jehofah, Oluwa Ọba Alaṣẹ agbaye salalu yii, dajujdaju, ni a kò kalọwọko sinu awọn isemọ temple wọn, laika bí ó ti wù kí ó jẹ́ ologo tó sí!—Jeremáyà 7:1-8; Isaiah 66:1.
10 Jeremiah nbaa-lọ lati maa bá ibawi-lilekoko itagbangba rẹ̀ tí njóni niṣo pe: “Kò ha ṣe pe ẹyin njale, ẹ npaniyan, ẹ nṣe panṣaga, ẹ nbura eke, ẹ nsun turari fun Baal, ẹ sì nrin tọ oriṣa tí ẹyin kò mọ̀, . . . ẹyin sì wipe, gbà wá; lati ṣe gbogbo irira wonyi?” Awọn Jew, gẹgẹbi ‘awọn eniyan ayanfẹ’ Ọlọrun, ronu pe oun yoo fàyè gba iru iwa eyikeyii, niwọnbi ó ba ti jẹ́ pe awọn mú awọn ẹbọ wọn wá sí temple. Bi ó ti wù kí ó rí, bí wọn bá woye rẹ̀ gẹgẹbi baba oloju-aanu omugọ kan tí ó ngẹ̀ ọmọ kanṣoṣo tí a ti bajẹ kan, wọn ti ṣetan lati niriiri ìtají ojiji ohun kan tí kò dunmọni.—Jeremáyà 7:9, 10; Exodus 19:5, 6.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
11 Ǹjẹ́ a máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí wa dáadáa? Ó dára ká máa sinmẹ̀dọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ká sì máa fi òótọ́ inú yẹ ara wa wò dáadáa. Gbé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ibẹ̀ kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ẹ dúró jẹ́ẹ́ ní ọ̀nà, kí ẹ sì rí, ẹ béèrè fún àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ibi tí ọ̀nà tí ó dára wà nísinsìnyí; ẹ sì máa rìn ín, kí ẹ sì rí ìdẹ̀rùn fún ọkàn yín.’ ” (Jeremáyà 6:16) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè rán wa létí arìnrìn-àjò kan tó dúró ní ìkòríta kan láti béèrè ọ̀nà. Ohun tó jọ èyí nípa tẹ̀mí ló yẹ káwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní Ísírẹ́lì ṣe. Ó yẹ kí wọ́n wá ọ̀nà tí wọ́n a fi padà sí “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” “Ọ̀nà tí ó dára” yẹn ni ọ̀nà táwọn baba ńlá wọn tó jẹ́ olóòótọ́ rìn, orílẹ̀-èdè náà sì ti rìn gbéregbère kúrò ní ọ̀nà náà nítorí ìwà òmùgọ̀ wọn. Ó dunni pé ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ń ṣagídí tí wọn ò tẹ̀lé ìránnilétí onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún wọn yìí. Ẹsẹ kan náà yẹn tún ń bá a lọ pé: “Ṣùgbọ́n wọ́n ń wí pé: ‘Àwa kì yóò rìn.’ ” Àmọ́, lóde òní, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yẹn.
w88 4/1 13 ¶15
Jeremiah—Aláìgbajúmọ̀ Wolii Awọn Idajọ Ọlọrun
Judah San Iye-Owo naa
15 Nigba tí ó fi maa di nǹkan bii 632 B.C.E., Assyria ti ṣubu sọ́wọ́ awọn ara Chaldea ati Medes, tí a sì din Egypt kù sí alagbara kekere kan ní iha guusu Judah. Ìhalẹ̀-mọ́ tootọ-gidi sí Judah yoo wá nipasẹ ipa-ọna iwọlegbogunti lati iha ariwa. Nipa bẹẹ, Jeremiah nilati fun awọn Jew ẹlẹgbẹ rẹ̀ ní awọn irohin buburu kan! “Sá wòó! Eniyan kan ti ilu ariwa wá . . . Onroro ni wọn, wọn kò ní aanu. . . . Wọn sì mura bí okunrin tí yoo jà ọ́ logun, iwọ ọmọbinrin Zion.” Agbara ayé ti ngoke-ipo-ọba naa ni akoko yẹn ni Babylon. Eyi ni yoo jẹ́ ohun-ilo-iṣẹ Ọlọrun fun fifi iya jẹ Judah alainigbagbọ.—Jeremáyà 6:22, 23; 25:8, 9.
MARCH 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 8-11
“Tá A Bá Ń Tẹ̀ Lé Ìtọ́sọ́nà Jèhófà Nìkan La Máa Ṣàṣeyọrí”
it-1 555
Apálá (Cucumber)
Wọ́n máa ń ri igi mọ́lẹ̀, tàbí kí wọ́n lo oríṣiríṣi ọ̀ná láti fi lé àwọn ẹran sá lóko. Jeremáyà fi ère táwọn abọ̀rìṣà ń ṣe wé igi “aṣọ́ko-másùn nínú oko apálá,” tí kò lè gbé ìṣísẹ̀ kankan.—Jer 10:5.
Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Lónìí?
10 Ì báà jẹ́ ojú ọ̀run ló wo tàbí o tẹjú mọ àwọn ìṣẹ̀dá tó wà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín, kedere ló máa rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. (Jeremáyà 10:12) Tọkàntọkàn ló yẹ ká fara mọ́ ohun táwọn ẹ̀dá tí ńbẹ lọ́run sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni kò lè fi ‘ojú ọkàn wọn’ rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n fi ojúyòójú wọn rí lè máa yà wọ́n lẹ́nu. (Éfésù 1:18) Àpèjúwe kan rèé: Tẹ́nì kan bá sọ pé ẹwà àti ọnà àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá wu òun àmọ́ tó lóun ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́nì kan bá sọ pé àwòrán mèremère kan wu òun àmọ́ tí ò gbà pé olùyàwòrán kan wà tó ya àwòrán náà. Ìdí níyì tá a fi sọ pe àwọn tó kọ̀ láti gbà pé Ọlọ́run wà ò ní “àwíjàre.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jeremáyà
3:11-22; 11:10-12, 17—Níwọ̀n bí àwọn ọ̀tá ti ṣẹ́gun Samáríà tí í ṣe olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kí nìdí tí Jeremáyà fi fi ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà kún àwọn tó kéde ìdájọ́ lé lórí? Ìdí ni pé ìparun tó wá sórí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ ìdájọ́ Jèhófà lórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀, kì í wulẹ̀ ṣe lórí Júdà nìkan. (Ìsíkíẹ́lì 9:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà, wọ́n ò gbàgbé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù nítorí pé àwọn wòlíì Ọlọ́run ṣì máa ń sọ̀rọ̀ wọn nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́.
MARCH 27–APRIL 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 12-16
“Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì”
it-1 1121 ¶2
Ìgbáròkó
Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà pé wọ́n dà bí ìgbànú tó lẹ̀ mọ́ ìgbáròkó rẹ̀, tó sì dè wọ́n mọ́ ara rẹ̀ pinpin kí wọ́n lè máa yìn ín, kí wọ́n sì jẹ́ ohun tó lẹ́wà lójú rẹ̀. (Jer 13:11) Jésù Kristi ni a sọ tẹ́lẹ̀ pé á máa ṣàkóso pẹ̀lú òdodo bí ìgbànú ní ìgbáròkó rẹ̀, tí á sì de ìṣòtítọ́ bí ìgbànú mọ́ abẹ́nú rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé Jésù ń fi gbogbo agbára rẹ̀ rọ̀ mọ́ ṣíṣe òtítọ́ àti òdodo, kò sì ní yí pa dà. Bí ìgbànú ṣe máa ń jẹ́ kí aṣọ dúró lára, bẹ́ẹ̀ ni òdodo ṣe ń fún Jésù lókun láti jẹ́ Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn.—Ais 11:1, 5.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ẹ Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà
Ẹ Jẹ́ Ká Ṣọ́ra Fáwọn Tá À Ń Bá Kẹ́gbẹ́
16 Jeremáyà sọ ohun mìíràn tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà. Ó sọ pé: “Èmi kò jókòó ní àwùjọ tímọ́tímọ́ àwọn tí ń ṣe àwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ ayọ̀ ńláǹlà. Nítorí ọwọ́ rẹ, ṣe ni mo dá jókòó ní èmi nìkan, nítorí o ti fi ìdálẹ́bi kún inú mi.” (Jeremáyà 15:17) Jeremáyà gbà kóun dá wà ju pé káwọn ọ̀rẹ́ burúkú wá kéèràn ran òun. Lónìí, bí àwa náà ṣe rí ọ̀rọ̀ náà nìyẹn. A ò gbàgbé ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́,” àní á bá ìwà rere tá a ti ń hù fún ọ̀pọ̀ ọdún jẹ́.—1 Kọ́ríǹtì 15:33.