Àwọn Wo Ló Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run Lónìí?
“Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára.”—Ìṣípayá 4:11.
1, 2. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn ṣe ń wo ohun tó wà nínú ìṣẹ̀dá láti ṣe ohun tó jọ ọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ, kí sì ni ìdáhùn wọn?
LỌ́JỌ́ kan ni àwọn ọdún 1940, onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ ilẹ̀ Switzerland kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ George de Mestral mú ajá rẹ̀ rìn jáde lọ. Nígbà tó máa fi padà délé, ó ṣàkíyèsí pé èèmọ́ ti lẹ̀ mọ́ aṣọ òun àti irun ara ajá náà. Nítorí pé ó fẹ́ mọ ohun tí èèmọ́ yìí jẹ́, ó fi awò tó ń sọ ohun kékeré di ńlá wo àwọn èèmọ́ náà, inú rẹ̀ sì dùn gan-an nígbà tó rí àwọn nǹkan tín-tìn-tín tó wà lára èèmọ́ náà tó máa ń mú kó so mọ́ ohunkóhun tó bá lẹ̀ mọ́. Nígbà tó yá, ó wo bí èèmọ́ náà ṣe rí, ó wá ṣe ohun kan tó máa ń lẹ̀ mọ́ nǹkan. Àmọ́, De Mestral nìkan kọ́ ló ń wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá láti ṣe èyí tó jọ ọ́. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, lẹ́yìn táwọn ọmọkùnrin Wright ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹyẹ ńlá kan tó ń fò, wọ́n ṣe ọkọ̀ òfuurufú kan. Alexandre-Gustave Eiffel, onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ ilẹ̀ Faransé ya àwòrán tí wọ́n wò kọ́ ilé gogoro kan tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pè nílùú Paris. Onímọ̀ ẹ̀rọ yìí tẹ̀ lé ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe eegun inú itan tó ń gbé èèyàn ró.
2 Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn ṣe máa ń wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá tí wọ́n á sì ṣe èyí tó jọ ọ́. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá béèrè pé: Ẹ̀ẹ̀melòó làwọn tó ń hùmọ̀ nǹkan wọ̀nyí ń fi ògo fún Ẹni tó ṣe àwọn èèmọ́ kéékèèké, àwọn ẹyẹ ńlá, eegun tó wà nínú itan ọmọ èèyàn àti gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí àwọn tó ń hùmọ̀ nǹkan wò ṣe ohun tí wọ́n ṣe? Ohun tó bani nínú jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé, láyé òde òní, àwọn èèyàn kì í sábà fún Ọlọ́run ní ògo tó yẹ kí wọ́n fún un.
3, 4. Kí ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà “ògo” túmọ̀ sí, kí ló sì yẹ kó tọ́ka sí nígbà tá a bá lò ó fún Jèhófà?
3 Ó lè ya àwọn kan lẹ́nu, kí wọ́n sì wá máa béèrè pé, ‘Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ògo fún Ọlọ́run? Ṣebí Ọlọ́run ti ní ògo tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀? Òótọ́ ni pé Jèhófà ni Ẹni tó ní ògo jù lọ láyé lọ́run, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ẹ̀dá èèyàn ló gbà pé ó ní ògo yẹn. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ògo” ní èrò pé kí nǹkan “wúwo.” Ó tọ́ka sí ohun tó ń sọ èèyàn dẹni pàtàkì tàbí ẹni iyì lójú àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tá a bá sì fi ọ̀rọ̀ náà ṣàpèjúwe Ọlọ́run, ohun tó mú Ọlọ́run tóbi lọ́ba lójú àwọn èèyàn ló ń tọ́ka sí.
4 Lónìí, àwọn èèyàn díẹ̀ ló mọ ohun tó mú kí Ọlọ́run tóbi lọ́ba bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 10:4; 14:1) Àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn inú ayé, tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ́ pé àwọn gbà pé Ọlọ́run wà pàápàá, ti sún àwọn èèyàn láti fojú tẹ́ńbẹ́lú Ẹlẹ́dàá ológo tó dá ọ̀run òun ayé. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
“Wọn Kò Ní Àwíjàre”
5. Àríwísí wo làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ń ṣe nípa àwọn iṣẹ́ àrà tá à ń rí nínú ìṣẹ̀dá?
5 Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ń fi agídí rin kinkin mọ́ ọn pé kò sí Ọlọ́run. Àmọ́, ta ni wọ́n á sọ pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ àrà tá à ń rí nínú ìṣẹ̀dá, títí kan ẹ̀dá èèyàn? Wọ́n sọ pé àwọn iṣẹ́ àrà wọ̀nyí wáyé nípasẹ̀ ẹfolúṣọ̀n, ìyẹn agbára kan lásán tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n nì, Stephen Jay Gould, kọ̀wé pé: “Ìdí tá a fi wà níhìn-ín jẹ́ nítorí pé oríṣi àwọn ẹja àjèjì kan ní lẹbẹ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, lẹbẹ yìí ló ṣeé ṣe kó yí padà di ẹsẹ̀ táwọn ohun abẹ̀mí orí ilẹ̀ fi ń rìn . . . Bó ṣe wù ká yán hànhàn tó láti rí ìdáhùn ‘tó bọ́gbọ́n mu’ sí ìbéèrè náà,—síbẹ̀ inú òkùnkùn la ó ṣì wà.” Bákan náà, Richard E. Leakey àti Roger Lewin táwọn náà jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kọ̀wé pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àṣìṣe ńláǹlà kan ló fà á tí ìran ènìyàn fi wáyé.” Kódà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tí ẹ̀wà àti ọnà ìṣẹ̀dá máa ń jọ lójú pàápàá, kì í gbé ògo rẹ̀ fún Ọlọ́run.
6. Kí lohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́kàn kúrò nínú fífún Ọlọ́run ní ògo tó yẹ kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá?
6 Nígbà táwọn tó kàwé gan-an bá ń sọ pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé àwọn púrúǹtù nìkan ni kò gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Kí wá ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọkùnrin kan tó mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n dáadáa fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn kan tó fara mọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀hún. Ó sọ pé: “Ohun tí mo wá kíyè sí nípa ìdí táwọn tó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ fi gbà á gbọ́ jẹ́ nítorí pé àwọn kan sọ fún wọn pé gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, nígbà táwọn tó kàwé gan-an bá sọ ọ́ jáde pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, èyí máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́kàn wọn kúrò nínú fífún Ọlọ́run ní ògo tó yẹ kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá.—Òwe 14:15, 18.
7. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Róòmù 1:20 sọ, kí la lè rí nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀dá tá a lè fojú rí, kí sì nìdí rẹ̀?
7 Ǹjẹ́ ẹ̀rí tiẹ̀ wà tó mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n jóòótọ́? Rárá o! Àwọn nǹkan tó fẹ̀rí hàn pé Ẹlẹ́dàá wà pọ̀ yí wa ká. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé [aráyé] síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn [àwọn aláìgbàgbọ́] kò ní àwíjàre.” (Róòmù 1:20) A lè rí ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá wà lára àwọn nǹkan tó dá. Ohun tí Pọ́ọ̀lù wá ń sọ ni pé látìgbà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà lókè eèpẹ̀ ló ti ṣeé ṣe fún èèyàn láti tipasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀dá tá a lè fojú rí ‘fòye mọ’ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà. Ibo làwọn ẹ̀rí yìí wà?
8. (a) Báwo ni òfuurufú ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ní agbára àti ọgbọ́n? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹnì kan wà tó dá ayé òun ìsálú ọ̀run?
8 À ń rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà nínú àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Sáàmù 19:1 sọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run.” “Àwọn ọ̀run,” ìyẹn oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ń jẹ́rìí sí agbára Ọlọ́run àti ọgbọ́n rẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ lọ súà lójú ọ̀run ń mú ká gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Kì í sì í ṣe pé oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ kàn ń rìn gbéregbère lójú ọ̀run, àmọ́ ìlànà tá a ti ṣe fún ìrìn wọn ni wọ́n ń tẹ̀lé.a (Aísáyà 40:26) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kí ẹnì kan wá sọ pé ipá kan lásán ló ń darí wọn? Èyí tó tiẹ̀ wá yani lẹ́nu jù lọ nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló sọ pé ńṣe ni ayé òun ìsálú ọ̀run ṣàdédé bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn, ó kọ̀wé pé: “Àwọn tí ò gbà pé Ọlọ́run wà àtàwọn tó sọ pé Ọlọ́run ò ṣeé mọ̀ gbà pé láti ayérayé ni ayé òun ìsálú ọ̀run ti wà. Bákan náà, nígbà tí ayé òun ìsálú ọ̀run fi lè ní ìbẹ̀rẹ̀, á jẹ́ pé ẹnì kan ló dá wọn; ṣé adúrú gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn lè wá dá ara wọn láìjẹ́ pé ẹnì kan ló dá wọn ni?”
9. Báwo ni àwọn ohun abẹ̀mí ṣe fi ọgbọ́n Jèhófà hàn?
9 A tún lè rí àwọn ẹ̀rí lórí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run wà. Onísáàmù náà sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” (Sáàmù 104:24) Àwọn “àmújáde” Jèhófà, títí kan àwọn ẹranko jẹ́ ẹ̀rí pé ó ní ọgbọ́n. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ọnà ìṣẹ̀dá dára débi pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sábà máa ń fẹ́ ṣe ohun tó jọ ọ́. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ mìíràn yẹ̀ wò. Àwọn olùṣèwádìí ń ṣe àyẹ̀wò ìwo ẹtu nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe akoto tó túbọ̀ lágbára ju èyí tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀; wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò irú kòkòrò abìyẹ́ tó máa ń gbọ́ran dáadáa nítorí pé wọ́n fẹ́ mú kí nǹkan táwọn tí ò kì í gbọ́ran dáadáa fi ń gbọ́ràn túbọ̀ dára sí i; wọ́n tún ń ṣe àyẹ̀wò ìyẹ́ òwìwí kí wọ́n bàa lè ṣe ọkọ̀ òfuurufú kan téèyàn ò ní lè fi ẹ̀rọ mọ ibi tó wà. Àmọ́ bó ti wù kí ẹ̀dá èèyàn gbìyànjú tó, wọn ò lè ṣe é kó dà bí èyí tí Ọlọ́run dá gan-gan. Ìwé Biomimicry—Innovation Inspired by Nature sọ pé: “Gbogbo nǹkan tí ẹ̀dá èèyàn fẹ́ ṣe làwọn ohun alààyè ti ṣe láìsí pé wọ́n jo epo kankan tàbí kí wọ́n ba ilẹ̀ ayé òun ọjọ́ ọ̀la wọn jẹ́.” Ẹ ò ri pé ọgbọ́n ńláǹlà lèyí jẹ́!
10. Èé ṣe tí kò fi bọ́gbọ́n mú láti sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá? Ṣàpèjúwe.
10 Ì báà jẹ́ ojú ọ̀run ló wo tàbí o tẹjú mọ àwọn ìṣẹ̀dá tó wà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín, kedere ló máa rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. (Jeremáyà 10:12) Tọkàntọkàn ló yẹ ká fara mọ́ ohun táwọn ẹ̀dá tí ńbẹ lọ́run sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni kò lè fi ‘ojú ọkàn wọn’ rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n fi ojúyòójú wọn rí lè máa yà wọ́n lẹ́nu. (Éfésù 1:18) Àpèjúwe kan rèé: Tẹ́nì kan bá sọ pé ẹwà àti ọnà àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá wu òun àmọ́ tó lóun ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́nì kan bá sọ pé àwòrán mèremère kan wu òun àmọ́ tí ò gbà pé olùyàwòrán kan wà tó ya àwòrán náà. Ìdí níyì tá a fi sọ pe àwọn tó kọ̀ láti gbà pé Ọlọ́run wà ò ní “àwíjàre.”
Àwọn “Afọ́jú Afinimọ̀nà” Ń Ṣi Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lọ́nà
11, 12. Kí ni èrò tí wọ́n gbé ẹ̀kọ́ àyànmọ́ kà, kí ló sì fi hàn pé ẹ̀kọ́ yìí ò fi ògo fún Ọlọ́run?
11 Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló gbà tọkàntọkàn pé ìjọsìn àwọn ń fi ògo fún Ọlọ́run. (Róòmù 10:2, 3) Àmọ́, ẹ̀sìn lápapọ̀ wà lára ohun tó wà láyé yìí tí kò fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láǹfààní láti fi ògo fún Ọlọ́run. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà méjì tó gbà jẹ́ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.
12 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀sìn ń tipa àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn darí ògo tó yẹ kí wọ́n fún Ọlọ́run sí nǹkan míì. Àpẹẹrẹ kan ni ẹ̀kọ́ àyànmọ́. Wọ́n gbé ẹ̀kọ́ náà ka orí èrò náà pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti lágbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, wọ́n ní Ọlọ́run ti mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde gbogbo nǹkan. Ohun tí ẹ̀kọ́ àyànmọ́ wá ń sọ ni pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí olúkúlùkù èèyàn lẹ́yìnwá ọ̀la, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú. Gẹ́gẹ́ bí èrò yìí ṣe fi hàn, ńṣe ni wọ́n di gbogbo ẹ̀bi ìyà tó ń jẹ èèyàn àti ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù nínú ayé òde òní ru Ọlọ́run. Ó dájú pé kò fi ògo kankan fún Ọlọ́run nígbà táwọn èèyàn bá sọ pé òun ló lẹ̀bi tó yẹ kí wọ́n dì ru Sátánì, olórí Elénìní rẹ̀ tí Bíbélì pè ní “olùṣàkóso ayé”!—Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 5:19.
13. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mú kéèyàn máa rò pé Ọlọ́run ò ní lè kó ara rẹ̀ níjàánu tó bá di pé kó lo agbára tó fi ń mọ ọjọ́ ọ̀la? Ṣàpèjúwe.
13 Ẹ̀kọ́ àyànmọ́ kò sí nínú Ìwé Mímọ́, ó sì ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. Ẹ̀kọ́ náà ò tiẹ̀ jẹ́ kéèyàn mọ ohun tí Ọlọ́run lè ṣe àtohun tó dìídì ń ṣe. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lágbára tó lè fi mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. (Aísáyà 46:9, 10) Àmọ́, kò bọ́gbọ́n mu láti rò pé Ọlọ́run ò ní lè ko ara rẹ̀ níjàánu tó bá di pé kó lo agbára tó fi ń mọ ọjọ́ ọ̀la, kò sì bọ́gbọ́n mu láti rò pé òun ló fa gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Àpèjúwe kan rèé: Ká ní pé ó ní agbára ńlá kan. Ṣé gbogbo nǹkan tó wúwo tó o bá ti rí lá máa ṣe ọ́ bíi pé kó o gbé? Ó dájú pé kò ní máa ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀! Bákan náà, nítorí pé Ọlọ́run lágbára tó lè fi mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la kò túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ mọ gbogbo ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ tàbí kó kádàrá gbogbo nǹkan. Ó lójú nǹkan tó máa ń fi agbára tó fi ń mọ ọjọ́ ọ̀la mọ̀.b Dájúdájú, àwọn ẹ̀kọ́ èké títí kan ẹ̀kọ́ àyànmọ́, kò fi ògo fún Ọlọ́run.
14. Ọ̀nà wo ni ètò ẹ̀sìn gbà ń bu ọlà Ọlọ́run kù?
14 Ọ̀nà kejì tí ètò ẹ̀sìn gbà ń bu ọlá Ọlọ́run kù jẹ́ nípa ìwà táwọn ọmọ ìjọ wọn ń hù. Ńṣe ló yẹ káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù. Lára nǹkan tí Jésù sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé, wọ́n ní láti ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì’ kí wọ́n má sì jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:12; 17:14-16) Àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì ńkọ́ o? Ǹjẹ́ wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn?
15. (a) Kí ni àwọn àlùfáà máa ń ṣe tó bá kan ọ̀ràn ogun táwọn orílẹ̀-èdè máa ń jà? (b) Ipa wo ni ìwà táwọn àlùfáà ń hù ní lórí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn?
15 Gbé ohun táwọn àlùfáà ti ṣe nípa ogun yẹ̀ wò. Wọ́n máa ń ti ogun lẹ́yìn, wọ́n ń gba ogun jíjà láyè, wọ́n tiẹ̀ tún mú ipò iwájú nínú ọ̀pọ̀ ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń jà. Wọ́n máa ń gbàdúrà fáwọn ológun, wọn ò sì gbà pé ó burú láti pààyàn. A ò wá ní ṣaláì béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ti wá sọ́kàn àwọn àlùfáà wọ̀nyí rí pé ohun tí wọ́n ń ṣe làwọn àlùfáà tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà tí wọ́n sì fẹ́ bá jagun ń ṣe?’ (Wo àpótí tó ní àkọlé náà “Ẹ̀yin Ta Ni Ọlọ́run Wà?”) Kì í ṣe ògo làwọn àlùfáà ń fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá ń sọ pé Ọlọ́run ló ń ti àwọn lẹ́yìn nínú ogun tí wọ́n ti ń ta ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn sílẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fi ògo fún un nígbà tí wọ́n bá sọ pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bágbà mu mọ́, tí wọ́n sì ń gba onírúurú ìṣekúṣe láyè. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ ká rántí àwọn aṣáájú ìsìn tí Jésù pè ní “oníṣẹ́ ìwà àìlófin,” àti “afọ́jú afinimọ̀nà”! (Mátíù 7:15-23; 15:14) Ìwà táwọn àlùfáà máa ń hù ti mú kí ìfẹ́ tí ọ̀kẹ́ àìmọye ní sí Ọlọ́run di tútù.—Mátíù 24:12.
Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Ní Tòótọ́?
16. Láti dáhùn ìbéèrè nípa àwọn tó ń fi ògo fún Ọlọ́run ní tòótọ́, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹ inú Bíbélì wò?
16 Tí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn àtàwọn sàràkí èèyàn inú ayé bá kùnà láti fi ògo fún Ọlọ́run, àwọn wo ló wá ń fi ògo fún un ní tòótọ́? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, a ní láti yẹ ohun tí Bíbélì sọ wò. Ó ṣe tán, Ọlọ́run láṣẹ láti sọ bó ṣe yẹ ká máa fi ògo fún òun, àwọn ìlànà nípa èyí sì wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Aísáyà 42:8) Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́tà tá a lè gbà máa fi ògo fún Ọlọ́run yẹ̀ wò, ní ibi kọ̀ọ̀kan tá a sì ti fẹ́ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, a ó dáhùn ìbéèrè nípa àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́ lónìí.
17. Báwo ni Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣe fi hàn pé fífi ògo fún orúkọ òun jẹ́ apá pàtàkì kan lára ìfẹ́ òun, àwọn wo sì ló ń yin orúkọ Ọlọ́run jákèjádò ayé lónìí?
17 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a lè fi ògo fún Ọlọ́run nípa yíyin orúkọ rẹ̀. Ohun tí Jèhófà sọ fún Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì lára ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tó ku ọjọ́ bíi mélòó kan kí Jésù kú, ó gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ohùn kan dá a lóhùn pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” (Jòhánù 12:28) Ó dájú pé Jèhófà lẹni tó dá a lóhùn. Ìdáhùn náà fi hàn kedere pé Ọlọ́run ò fojú kékeré wo fífi ògo fún òun. Nígbà náà, àwọn wo ló ń fi ògo fún Jèhófà lónìí nípa sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ àti nípa yíyin orúkọ rẹ̀ jákèjádò ayé? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè!—Sáàmù 86:11, 12.
18. Báwo la ṣe lè dá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run ní “òtítọ́” mọ̀, ẹgbẹ́ wo ló sì ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn?
18 Èkejì, a lè fi ògo fún Ọlọ́run nípa fífi òtítọ́ nípa rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn. Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ yóò máa “jọ́sìn [Ọlọ́run] ní . . . òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Báwo la ṣe lè dá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run ní “òtítọ́” mọ̀? Wọ́n ò gbọ́dọ̀ fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí ò sí nínú Bíbélì, tó sì tún ń parọ́ mọ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀. Dípò ìyẹn, òtítọ́ tó mọ́ gaara tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi kọ́ni, lára àwọn òtítọ́ náà sì ni pé: Jèhófà ni Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo, òun nìkan ló sì yẹ ká máa fi ògo ipò yìí fún (Sáàmù 83:18); Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run àti Olùṣàkóso tá a yàn lórí Ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run (1 Kọ́ríńtì 15:27, 28); Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, ìjọba náà yóò sì mú àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe sí ilẹ̀ ayé àti fún ìran èèyàn ṣẹ (Mátíù 6:9, 10); a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé pátá. (Mátíù 24:14) Láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún, àwùjọ kan ṣoṣo péré ló ń fi irú òtítọ́ ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn, àwùjọ náà sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
19, 20. (a) Báwo ni ìwà rere tí Kristẹni ń hù ṣe lè fi ògo fún Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn tó ń tipa ìwà rere wọn fi ògo fún Ọlọ́run lónìí?
19 Ìkẹta, a lè fi ògo fún Ọlọ́run nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pétérù 2:12) Ìwà tí Kristẹni kan bá ń hù máa ń jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe tó. Nígbà táwọn èèyàn bá sì wá rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀—ìyẹn nígbà táwọn èèyàn bá rí i pé ìgbàgbọ́ tí Kristẹni kan ní ló mú kó máa hu irú ìwà rere tó ń hù—èyí máa ń fi ògo fún Ọlọ́run.
20 Àwọn wo ló ń fi ògo fún Ọlọ́run nípa híhu ìwà tó dáa? Ìsìn wo ni ọ̀pọ̀ ìjọba máa ń yìn nítorí pé wọn kì í fa wàhálà, torí pé wọ́n máa ń pa òfin mọ́, tí wọ́n sì ń san owó orí wọn? (Róòmù 13:1, 3, 6, 7) Àwọn wo làwọn èèyàn mọ̀ jákèjádò ayé pé wọ́n wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́—ìyẹn ìṣọ̀kan tí kò jẹ́ kí wọ́n rántí pé ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè àti ìran wọn yàtọ̀ síra? (Sáàmù 133:1; Ìṣe 10:34, 35) Àwùjọ wo làwọn èèyàn mọ̀ jákèjádò ayé pé wọ́n ń fi Bíbélì kọ́ni, tí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ sì ń mú káwọn èèyàn máa pa òfin mọ́, kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà tó ń gbé ìdílé ró, kí wọ́n sì máa hu ìwà tí Bíbélì ní kéèyàn máa hù? Àwùjọ kan ṣoṣo ló wà tí ìwà rere tí wọ́n ń hù láwọn apá ibi tá a sọ yìí àti láwọn apá ibòmíràn jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀—àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni àwùjọ náà!
Ǹjẹ́ Ìwọ Alára Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run?
21. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa bóyá àwa fúnra wa ń fi ògo fún Jèhófà?
21 Ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń fi ògo fún Jèhófà?’ Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Sáàmù 148 sọ, èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìṣẹ̀dá ló ń fi ògo fún Ọlọ́run. Àwọn áńgẹ́lì, òfuurufú, ilẹ̀ ayé, àti àwọn ẹranko—gbogbo wọn ló ń fi ògo fún Jèhófà. (Ẹsẹ 1-10) Ó mà báni nínú jẹ́ gan-an o pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn lónìí ni kì í fi ògo fún Ọlọ́run! Tó o bá ń gbé ìgbé ayé lọ́nà tó ń fi ògo fún Ọlọ́run, o wà lára àwọn ìṣẹ̀dá yòókù tí wọ́n ń yin Jèhófà lógo nìyẹn. (Ẹsẹ 11-13) Ọ̀nà tó dára jù lọ sì nìyẹn tó o lè gbà gbé ìgbé ayé rẹ.
22. Àwọn ọ̀nà wo lo gbà ń rí ìbùkún bó o ṣe ń fi ògo fún Jèhófà, kí sì ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu rẹ?
22 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà lo gbà ń jàǹfààní bó o ṣe ń fi ògo fún Jèhófà. Bó o ṣe ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, o padà bá Ọlọ́run rẹ́, o sì ní àjọṣe tó dára tó sì lérè pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. (Róòmù 5:10) Bó o ṣe ń ronú nípa àwọn ìdí tó fi yẹ kó o máa fi ògo fún Ọlọ́run, o túbọ̀ ń ní ẹ̀mí tó dára, o sì ń kún fún ìmoore. (Jeremáyà 31:12) Nígbà náà, wàá lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbé ìgbé ayé tó láyọ̀ tó sì dára, èyí yóò sì mú kí ayọ̀ ìwọ alára pọ̀ sí i. (Ìṣe 20:35) Àdúrà wa ni pé kó o wà lára àwọn tó pinnu láti máa fi ògo fún Ọlọ́run—nísinsìnyí àti títí láé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti lè rí ìsọfúnni tó pọ̀ sí i nípa bí òfuurufú ṣe ń gbé ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ yọ, wo orí 5 àti 17 nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
b Wo ìdìpọ̀ kìíní, ojú ìwé 853 nínú ìwé Insight on the Scriptures tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tá a lè fi sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa fi ògo fún Ọlọ́run?
• Àwọn ọ̀nà méjì wo ní ètò ẹ̀sìn ò fi jẹ́ káwọn èèyàn fi ògo fún Ọlọ́run?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fi ògo fún Ọlọ́run?
• Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú lórí bóyá ìwọ alára ń fi ògo fún Jèhófà?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
“Ẹ̀yìn Tá Ni Ọlọ́run Wà?”
Ọkùnrin kan tó wà lára Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Òfuurufú Ti Ilẹ̀ Jámánì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì àmọ́ tó ti wá di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní:
“Ohun tó bà mí nínú jẹ́ nígbà ogun yẹn . . . ni bí mo ṣe máa ń rí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì látinú gbogbo ẹ̀sìn—Kátólíìkì, àwọn ọmọlẹ́yìn Luther, Ìjọ Oníbíṣọ́ọ̀bù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—tí wọ́n ń gbàdúrà fún ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n fi ń jagun àti fún àwọn ológun kí wọ́n tó lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ pààyàn. Èrò tó sábà máa ń wá sí mi lọ́kàn ni pé, ‘Ẹ̀yìn Ta ni Ọlọ́run Wà?’
“Àwọn sójà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì máa ń de bẹ́líìtì kan tí wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ kan sí lára, ìyẹn Gott mit uns (Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa). Àmọ́, ó máa ń yà mí lẹ́nu pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi wà pẹ̀lú àwọn sójà tó wà lódìkejì tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà, tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run kan náà?’”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jákèjádò ayé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi ògo fún Ọlọ́run ní tòótọ́