ORÍ 4
Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tá a rí kọ́ lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà
1, 2. Kí nìdí tí Jèhófà fi sábà máa ń lo àwọn ohun tá a lè fojú rí tó bá ń kọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
FOJÚ inú wo ìdílé kan tí wọ́n ní àwọn ọmọ kéékèèké, wọ́n jókòó pa pọ̀, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bàbá wọn fi àwọn àwòrán kan hàn wọ́n, kí àwọn ọmọ náà lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì. Inú àwọn ọmọ náà ń dùn, ara wọn sì ń yá gágá bí wọ́n ṣe ń dáhùn, èyí fi hàn pé ẹ̀kọ́ náà ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí bàbá yìí ṣe ń fi àwòrán ṣàlàyé ohun tó ń sọ, ó ń jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n má tètè lóye nípa Jèhófà.
2 Lọ́nà kan náà, Jèhófà lo àwọn ohun tó ṣeé fojú rí kí àwa èèyàn táa jẹ́ ọmọ rẹ̀ lè lóye àwọn ohun gidi tí a kò lè rí, tó sì lè má rọrùn fún wa láti lóye. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan tó jinlẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún Ìsíkíẹ́lì, ó fi ìran kan tó ní àwọn àwòrán tó gbàfiyèsí hàn án. Nínú orí tó ṣáájú èyí, a jíròrò ọ̀kan lára àwọn àwòrán náà. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò apá kan pàtàkì nínú ìran tó kàmàmà yẹn, ká sì wo bí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
“Mo Rí . . . Ohun Tó Dà Bí Ẹ̀dá Alààyè Mẹ́rin”
3. (a) Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 1:4, 5, kí ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí lo kíyè sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Ìsíkíẹ́lì fi ṣàlàyé ohun tó rí?
3 Ka Ìsíkíẹ́lì 1:4, 5. Ìsíkíẹ́lì ṣàpèjúwe “ohun tó dà bí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin” tí ìrísí rẹ̀ sì dà bíi ti áńgẹ́lì, èèyàn àti ẹranko. Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ìsíkíẹ́lì fi ṣàlàyé ohun tó rí, ó ní òun rí “ohun tó dà bí” àwọn ẹ̀dá alààyè. Bó o bá ṣe ń ka ìran tó wà ní Ìsíkíẹ́lì orí 1, wàá rí i pé wòlíì náà lo àwọn ọ̀rọ̀ kan léraléra, irú bíi “tó rí bí” àti “ó dà bí.” (Ìsík. 1:13, 24, 26) Ó ṣe kedere pé, Ìsíkíẹ́lì mọ̀ pé ohun tí òun rí wúlẹ̀ jẹ́ àwòrán tàbí ohun tó jọ àwọn ohun gidi tá ò lè rí tó wà lọ́run.
4. (a) Ipa wo ni ìran náà ní lórí Ìsíkíẹ́lì? (b) Kí ló dájú pé Ìsíkíẹ́lì mọ̀ nípa àwọn kérúbù?
4 Ó dájú pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà àti ohùn tó gbọ́ ti ní láti bà á lẹ́rù gan-an. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà rí bí “ẹyin iná tó ń jó.” Bí wọ́n sì ṣe ń yára lọ bọ̀ dà bíi ti “mànàmáná.” Àwọn ìyẹ́ wọn ń dún “bí ìró omi púpọ̀ tó ń rọ́ jáde,” bí wọ́n sì ṣe ń gbéra “dà bíi ti àwọn ọmọ ogun.” (Ìsík. 1:13, 14, 24-28; wo àpótí tá a pè ní ‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà.’) Nínú ìran míì tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó pe àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin yìí ní “kérúbù” tàbí àwọn áńgẹ́lì alágbára. (Ìsík. 10:2) Bó ṣe jẹ́ pé inú ìdílé àlùfáà ni Ìsíkíẹ́lì ti wá, ó dájú pé ó mọ̀ pé àwọn kérúbù ni àwọn ìránṣẹ́ tó máa ń wà níwájú Ọlọ́run, ibi tí Ọlọ́run bá sì wà ni wọ́n sábà máa ń wà.—1 Kíró. 28:18; Sm. 18:10.
“Ọ̀kọ̀ọ̀kan Wọn Ní Ojú Mẹ́rin”
5. (a) Báwo ni àwọn kérúbù náà àti ojú wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà tóbi lọ́nà tí kò láfiwé àti pé ògo rẹ̀ kọyọyọ? (b) Kí ni apá tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìran yìí rán wa létí nípa orúkọ Ọlọ́run? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 Ka Ìsíkíẹ́lì 1:6, 10. Ìsíkíẹ́lì tún kíyè sí i pé kérúbù kọ̀ọ̀kan ní ojú mẹ́rin, ojú èèyàn, ojú kìnnìún, ojú akọ màlúù àti ojú ẹyẹ idì. Ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí ti ní láti tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọn lọ́kàn pé Jèhófà tóbi lọ́nà tí kò láfiwé, ògo rẹ̀ sì kọyọyọ. Kí nìdí? Ó jọni lójú gan-an pé ojú kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti ẹ̀dá tó ta yọ, tó sì ní agbára àti okun. Bí àpẹẹrẹ, kìnnìún jẹ́ ẹranko tí agbára rẹ̀ ta yọ, akọ màlúù jẹ́ ẹran ọ̀sìn tó tóbi tó sì lágbára, ẹyẹ idì pàápàá ta yọ láwùjọ àwọn ẹyẹ, èèyàn ló sì ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá sí ayé, òun ni olórí àwọn ẹ̀dá yòókù ní ayé. (Sm. 8:4-6) Síbẹ̀, Ìsíkíẹ́lì rí i nínú ìran yìí pé ìsàlẹ̀ ìtẹ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Tó Ga Jù Lọ, ni àwọn kérúbù tó ní ojú mẹ́rin tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹ̀dá alágbára náà wà, ojú wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń ṣojú fún àwọn ẹ̀dá yòókù. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu gan-an bí ìran yìí ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà pé ó lè lo àwọn ẹ̀dá rẹ̀ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ!a Bí onísáàmù náà ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí nípa Jèhófà, ó ní, “Iyì rẹ̀ ga ju ayé àti ọ̀run lọ.”—Sm. 148:13.
6. Kí ló ṣeé ṣe kó ran Ìsíkíẹ́lì lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ojú mẹ́rin náà dúró fún?
6 Lẹ́yìn tí àkókò díẹ̀ ti kọjá, tí Ìsíkíẹ́lì sì ti ronú lórí ohun tó rí, ó lè rántí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n wà ṣáájú òun ti lo àwọn ẹranko láti ṣe àfiwé. Bí àpẹẹrẹ, Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá fi Júdà ọmọ rẹ̀ wé kìnnìún, ó sì fi Bẹ́ńjámínì ọmọ rẹ̀ wé ìkookò. (Jẹ́n. 49:9, 27) Kí nìdí? Ìdí ni pé kìnnìún àti ìkookò ṣàpẹẹrẹ àwọn ìwà tàbí ànímọ́ tó máa ta yọ nínú ìwà àwọn ọkùnrin yìí. Àwọn àpẹẹrẹ tí Ọlọ́run mí sí Mósè láti kọ sílẹ̀ yìí ti ní láti mú kí Ìsíkíẹ́lì lóye pé ojú àwọn kérúbù náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ìwà tàbí ànímọ́ tó ta yọ. Àmọ́, àwọn ànímọ́ wo nìyẹn?
Àwọn Ànímọ́ Jèhófà àti Ìdílé Rẹ̀ Ọ̀run
7, 8. Àwọn ànímọ́ wo ni ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí àwọn kérúbù náà ní sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ?
7 Àwọn nǹkan wo làwọn tó kọ Bíbélì tí wọ́n wà ṣáájú Ìsíkíẹ́lì mọ̀ nípa kìnnìún, ẹyẹ idì àti akọ màlúù? Wo àwọn ohun tí Bíbélì sọ, irú bí: “Ọkùnrin tó láyà bíi kìnnìún.” (2 Sám. 17:10; Òwe 28:1) ‘Idì ń fò lọ sókè,’ àti pé “ojú rẹ̀ ń ríran jìnnà réré.” (Jóòbù 39:27, 29) “Agbára akọ màlúù máa ń mú kí ìkórè pọ̀.” (Òwe 14:4) Ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, bá a ṣe sábà máa ń ṣàlàyé rẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, jẹ́ ká mọ̀ pé ojú kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo tó gba ìgboyà; ojú ẹyẹ idì ṣàpẹẹrẹ ọgbọ́n tó ń ríran jìnnà réré; ojú akọ màlúù sì ń ṣàpẹẹrẹ agbára tó kàmàmà.
8 Àmọ́ kí ni “ojú èèyàn” ń ṣàpẹẹrẹ? (Ìsík. 10:14) Ó dájú pé kì í ṣe ìwà àti ìṣe àwọn ẹranko ló ń ṣàpẹẹrẹ, àmọ́ ó ń ṣàpẹẹrẹ ànímọ́ tí àwa èèyàn tí Ọlọ́run dá ní àwòrán ara rẹ̀ lè fi hàn. (Jẹ́n. 1:27) Ànímọ́ tí àwa èèyàn nìkan ní tó yàtọ̀ sí ti gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé ṣe kedere nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé: ‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ’ àti pé ‘kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ (Diu. 6:5; Léf. 19:18) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ, ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ Jèhófà là ń fi hàn yẹn. Bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ, “a nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:8, 19) Torí náà, ìfẹ́ ni “ojú èèyàn” ṣàpẹẹrẹ.
9. Àwọn ànímọ́ ta ni ojú àwọn kérúbù náà ń ṣàpẹẹrẹ?
9 Àmọ́ àwọn ànímọ́ ta ni à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Bó ṣe jẹ́ pé àwọn kérúbù yẹn ló ní àwọn ojú náà, àwọn ànímọ́ náà jẹ́ ti gbogbo ìdílé Jèhófà lọ́run tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì adúróṣinṣin. Àwọn ni àwọn kérúbù inú ìran náà ń ṣàpẹẹrẹ. (Ìfi. 5:11) Bákan náà, bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ni Orísun ìwàláàyè àwọn kérúbù yẹn, òun náà ni Orísun àwọn ànímọ́ wọn. (Sm. 36:9) Torí náà, ànímọ́ Jèhófà ni ojú àwọn kérúbù yẹn ń ṣàpẹẹrẹ. (Jóòbù 37:23; Sm. 99:4; Òwe 2:6; Míkà 7:18) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mélòó kan tí Jèhófà máa ń gbà fi àwọn ànímọ́ tó ta yọ yìí hàn.
10, 11. Àwọn ọ̀nà wo là ń gbà jàǹfààní àwọn ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì tó jẹ́ ti Jèhófà?
10 Ìdájọ́ òdodo. Bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run tó “nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo,” kì í “ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni.” (Sm. 37:28; Diu. 10:17) Torí náà, àǹfààní láti di ìránṣẹ́ Jèhófà àti láti gbádùn ìbùkún ayérayé wà fún gbogbo wa láìka irú ẹni tá a jẹ́ láwùjọ tàbí ibi tá a ti wá sí. Ọgbọ́n. Bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run “ọlọ́gbọ́n,” ó fún wa ní ìwé tí “ọgbọ́n tó gbéṣẹ́” kún inú rẹ̀. (Jóòbù 9:4; Òwe 2:7) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò, á ṣeé ṣe fún wa láti fara da àwọn ìṣòrò tó ń bá wa fínra lójoojúmọ́, ayé wa á sì nítumọ̀. Agbára. Torí pé Ọlọ́run tí ‘agbára rẹ̀ pọ̀’ ni Jèhófà, ó máa ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Èyí sì máa ń fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, bó ti wù kó le tó.—Náh. 1:3; 2 Kọ́r. 4:7; Sm. 46:1.
11 Ìfẹ́. Torí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí ‘ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi,’ kì í fìgbà kankan pa àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn tì. (Sm. 103:8; 2 Sám. 22:26) Torí náà, tí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó ò bá jẹ́ ká lè ṣe tó ohun tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ọkàn wa máa ń balẹ̀ tá a bá rántí pé Jèhófà ò gbàgbé àwọn iṣẹ́ tá a ti ṣe torí ìfẹ́ tá a ní. (Héb. 6:10) Ó ṣe kedere pé à ń gbádùn bí Jèhófà ṣe ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tó ń lo ọgbọ́n, agbára àti ìfẹ́, àá sì túbọ̀ jàǹfààní àwọn ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì yìí lọ́jọ́ iwájú.
12. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa bá a ṣe lè lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà?
12 Àmọ́, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé ohun tí àwa èèyàn lè lóye nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà kò ju ‘bíńtín lára àwọn ọ̀nà rẹ̀.’ (Jóòbù 26:14) “Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè,” torí pé “àwámáridìí ni títóbi rẹ̀.” (Jóòbù 37:23; Sm. 145:3) A wá rí i pé àwọn ànímọ́ Jèhófà ò lóǹkà, a ò sì lè pín in sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. (Ka Róòmù 11:33, 34.) Kódà, ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run gbòòrò gan-an, kò sì níye. (Sm. 139:17, 18) Apá wo nínú ìran náà ló jẹ́ ká mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ pàtàkì yìí?
“Ojú Mẹ́rin . . . Ìyẹ́ Apá Mẹ́rin”
13, 14. Kí ni ojú mẹ́rin tí àwọn kérúbù náà ní ṣàpẹẹrẹ? Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
13 Ìsíkíẹ́lì rí i nínú ìran yẹn pé kì í ṣe ojú kan ṣoṣo làwọn kérúbù náà ní, àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ká má gbàgbé pé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nǹkan mẹ́rin sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó gún régé, tí ohun gbogbo pé sínú rẹ̀ tàbí tó pé pérépéré. (Àìsá. 11:12; Mát. 24:31; Ìfi. 7:1) Ó gbàfiyèsí pé nínú ìran yìí, ó tó ìgbà mọ́kànlá (11) tí Ìsíkíẹ́lì mẹ́nu ba nọ́ńbà náà mẹ́rin! (Ìsík. 1:5-18) Kí nìyẹn wá jẹ́ ká lóye? Bí àwọn kérúbù mẹ́rin náà ṣe ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ẹ̀dá yòókù tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú wọn mẹ́rin lápapọ̀ ṣàpẹẹrẹ gbogbo ànímọ́ Jèhófà.b
14 Ẹ jẹ́ ká fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgbà kẹ̀kẹ́ mẹ́rin tó wà nínú ìran yìí wéra láti ṣàpèjúwe ìdí tí ojú mẹ́rin tí àwọn kérúbù náà ní fi ṣàpẹẹrẹ ohun tó ju ànímọ́ mẹ́rin péré lọ. Àgbá kọ̀ọ̀kan ṣàrà ọ̀tọ̀, àmọ́ tá a bá wò wọ́n pa pọ̀, a máa rí ohun tó ju àgbá mẹ́rin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ, a máa rí i pé orí àwọn àgbá náà ni kẹ̀kẹ́ náà lódindi sinmi lé. Bákan náà, tá a bá wo ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pa pọ̀, a máa rí ju ànímọ́ mẹ́rin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ, a máa rí i pé orí ànímọ́ mẹ́rin yìí ni àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà dá lé.
Jèhófà Wà Nítòsí Gbogbo Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin
15. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Ìsíkíẹ́lì kọ́ nínú ìran tó kọ́kọ́ rí?
15 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí yìí, ó kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan tó fi í lọ́kàn balẹ̀ nípa àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn? Ó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì sọ pé òun wà ní “ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,” tó sì ń sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Ọwọ́ Jèhófà sì wá sórí rẹ̀ níbẹ̀.” (Ìsík. 1:3) Kíyè sí ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ, kò sọ pé Jerúsálẹ́mù ni òun ti rí ìran, àmọ́ ó ní níbẹ̀, ìyẹn ní Bábílónì.c Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo nìyẹn kọ́ Ìsíkíẹ́lì? Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé: Bí wọ́n tiẹ̀ mú un nígbèkùn kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì, wọn ò mú un kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà tàbí kúrò nínú ìjọsìn Rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe fara han Ìsíkíẹ́lì ní Bábílónì fi hàn pé èèyàn lè ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Ọlọ́run láìka ipò tàbí ibi tó wà sí. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ẹ̀mí tó fi ń ṣe é àti bó ṣe ń wù ú látọkàn wá pé kó sin Jèhófà.
16. (a) Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe tù wá nínú? (b) Kí ló ń mú kó o máa fi gbogbo ọkàn rẹ sin Jèhófà?
16 Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Ìsíkíẹ́lì kọ́ yìí fi tù wá nínú gan-an lóde òní? Ó fi dá wa lójú pé tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, kò ní fi wá sílẹ̀ rárá láìka ibi tí à ń gbé sí tàbí ìdààmú èyíkéyìí kó dé tàbí ipò yòówù ká ti bá ara wa. (Sm. 25:14; Ìṣe 17:27) Jèhófà máa ń ní sùúrù fún wa gan-an torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa pọ̀ gidigidi. (Ẹ́kís. 34:6) Torí náà, kò sígbà tá ò lè jọlá ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀. (Sm. 100:5; Róòmù 8:35-39) Bákan náà, ìran tó kàmàmà nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ àti agbára rẹ̀ tí kò láfiwé ń rán wa létí pé Jèhófà ni ìjọsìn wa tọ́ sí. (Ìfi. 4:9-11) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lo irú ìran yìí láti mú ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa ara rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀! Bá a ṣe túbọ̀ ń ní òye tó jinlẹ̀ nípa àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra tí Jèhófà ní, èyí ń fà wá sún mọ́ ọn, ó sì ń mú ká máa yìn ín, ká sì máa fi gbogbo ọkàn àti okun wa sìn ín.—Lúùkù 10:27.
17. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àwọn orí tó tẹ̀ lé èyí?
17 Síbẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n sọ ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Kí ni Jèhófà ṣe sí i? Ọ̀nà wo sì ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn gbà kàn wá lónìí? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn orí tó tẹ̀ lé èyí.
a Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀dá alààyè náà rán wa létí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, tá a gbà pé ó túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Bí apá kan ìtumọ̀ orúkọ náà ṣe jẹ́ ká mọ̀, Jèhófà lè mú kí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ di ohunkóhun tó bá pọn dandan kí ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ.—Wo Àfikún A4 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
b Àwọn ànímọ́ Jèhófà tá a ti jíròrò nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti àwọn ọdún yìí wá ti tó nǹkan bí àádọ́ta (50).—Wo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lábẹ́ “Jèhófà Ọlọ́run,” ní ìsọ̀rí “Àwọn Ànímọ́ Jèhófà.”
c Ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì sọ pé: Ọ̀rọ̀ yẹn “níbẹ̀” fi hàn “lọ́nà tó ṣe kedere jù lọ pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé . . . Ọlọ́run wà níbẹ̀ ní Bábílónì! Ìyẹn tuni nínú gan-an!”