Àkópọ̀ Àwọn Àtúnṣe Tó Bá Òye Wa
Láti àwọn ọdún yìí wá ni ètò Ọlọ́run ti ń ṣàtúnṣe òye wa nípa àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, wọ́n sì ń gbé e jáde nínú Ilé Ìṣọ́. Àwọn àtúnṣe míì tún wà nínú ìwé yìí, Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò! Gbìyànjú bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí.
Kí ni ojú mẹ́rin tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ṣàpẹẹrẹ?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Ojú mẹ́rin tí àwọn ẹ̀dá alààyè tàbí àwọn kérúbù náà ní ṣàpẹẹrẹ ànímọ́ títayọ mẹ́rin tí Jèhófà ní.
Àtúnṣe: Òótọ́ ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ojú táwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ṣàpẹẹrẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan ànímọ́ títayọ mẹ́rin tí Jèhófà ní. Síbẹ̀, àpapọ̀ ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣàpẹẹrẹ gbogbo ànímọ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin táwọn ẹ̀dá alààyè náà ní jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé agbára àti ògo Jèhófà tóbi lọ́nà tí kò láfiwé.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nǹkan mẹ́rin sábà máa ń dúró fún ohun tí kò ṣẹ́ kù, tí ohun gbogbo wà nínú rẹ̀ tàbí tó pé pérépéré. Torí náà, tá a bá wo ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà lápapọ̀, wọ́n ṣàpẹẹrẹ ohun tó ju ànímọ́ mẹ́rin péré lọ, a máa rí i pé orí ànímọ́ mẹ́rin yìí ni àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà dá lé. Bákan náà, ojú kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti ẹ̀dá tó ta yọ, tó sì ní agbára àti okun. Ńṣe ni àwọn kérúbù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó ní ojú mẹ́rin yìí ń ṣojú fún gbogbo àwọn áńgẹ́lì alágbára tí Jèhófà dá, síbẹ̀ náà abẹ́ ìtẹ́ Jèhófà ni gbogbo wọn wà. Ìran yìí mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Tó Ga Jù Lọ.
Ta ni ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ ìyókù àwọn ẹni àmì òróró. Wọ́n ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn sàmì tó ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan síwájú orí àwọn tó di ara “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.”—Ìfi. 7:9.
Àtúnṣe: Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi. Ó máa sàmì sí ogunlọ́gọ̀ èèyàn ní ti pé á dá wọn láre nígbà “ìpọ́njú ńlá” pé wọ́n jẹ́ àgùntàn.—Mát. 24:21.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Jèhófà ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. (Jòh. 5:22, 23) Bó ṣe wà nínú Mátíù 25:31-33, Jésù ló máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, torí náà òun ló máa pinnu àwọn tó jẹ́ “àgùntàn” àtàwọn tó jẹ́ “ewúrẹ́.”
Ṣé òótọ́ ni pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tí wọ́n jẹ́ aṣẹ́wó, ìyẹn Òhólà àti Òhólíbà ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, pàápàá ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Èyí ẹ̀gbọ́n, ìyẹn Òhólà (Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì), ṣàpẹẹrẹ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Èyí àbúrò, Òhólíbà (Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà), ṣàpẹẹrẹ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ya kúrò lára Kátólíìkì.
Àtúnṣe: Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tí wọ́n jẹ́ aṣẹ́wó, ìyẹn Òhólà àti Òhólíbà kò ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn jẹ́ ká lóye bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà bí ẹnì kan tó ti ń fọkàn sìn ín tẹ́lẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè ẹ̀sìn. Ojú yìí kan náà ló fi ń wo gbogbo ẹ̀sìn èké.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Òhólà àti Òhólíbà ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Júdà ló dà bí olóòótọ́ ìyàwó fún Jèhófà, àmọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò fìgbà kankan wà nínú irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Bákan náà, bí Jèhófà ṣe fi àwọn èèyàn rẹ̀ tó di aláìṣòótọ́ wé aṣẹ́wó nínú Ìsíkíẹ́lì orí 16 àti 23 mú kó ṣe kedere pé nǹkan ṣì máa pa dà bọ̀ sípò fún wọn. Àmọ́ kò sí ìrètí bẹ́ẹ̀ fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tó jẹ́ apá kan Bábílónì Ńlá.
Ṣé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà ṣàpẹẹrẹ?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìlú Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà ṣàpẹẹrẹ. Torí náà, ìparun Jerúsálẹ́mù ṣàpẹẹrẹ ìparun tó máa wá sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.
Àtúnṣe: Ìwà àìṣòótọ́ táwọn èèyàn hù nílùú Jerúsálẹ́mù, títí kan ìbọ̀rìṣà àti ìwà ìbàjẹ́ tó gbilẹ̀ níbẹ̀ rán wa létí àwọn ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe lóde òní, àmọ́ a kì í tún sọ pé Jerúsálẹ́mù ìgbà yẹn ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé ìlú Jerúsálẹ́mù ṣàpẹẹrẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ìgbà kan wà tí Jerúsálẹ́mù jẹ́ ojúkò ìjọsìn mímọ́, àmọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò fìgbà kankan ṣe ìjọsìn mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà kan wà tí Jèhófà yọ́nú sí Jerúsálẹ́mù, tó sì dárí jì wọ́n. Àmọ́ Jèhófà ò fìgbà kankan yọ́nú sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, kò sì sí àmì pé á ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Báwo ni ìran àwọn egungun gbígbẹ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ṣe ṣẹ?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Lọ́dún 1918, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí lọ sígbèkùn Bábílónì Ńlá, ìyẹn sì mú kí wọ́n dà bí òkú tí kò lè ta pútú. Ìgbà kúkúrú ni wọ́n fi wà nígbèkùn yẹn torí pé lọ́dún 1919, Jèhófà mú kí wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ kíkéde Ìjọba Ọlọ́run.
Àtúnṣe: Ṣáájú ọdún 1918 làwọn èèyàn Jèhófà ti wà láìlè ta pútú nípa tẹ̀mí, ó sì pẹ́ gan-an kí wọ́n tó sọjí pa dà. Ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀, ó sì parí lọ́dún 1919 Sànmánì Kristẹni. Èyí bá àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn èpò àti àlìkámà mu nígbà tó sọ pé wọ́n máa dàgbà pọ̀ fún àkókò gígùn.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbèkùn, bẹ̀rẹ̀ látọdún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì fi hàn pé egungun àwọn òkú náà “gbẹ” tàbí pé wọ́n “gbẹ gidigidi,” tó fi hàn pé ó ti pẹ́ táwọn èèyàn náà ti kú. Yàtọ̀ síyẹn, Ìsíkíẹ́lì sọ pé díẹ̀díẹ̀ làwọn òkú náà ń wá sí ìyè, tó fi hàn pé ó máa gba àkókò.
Kí ló túmọ̀ sí pé wọ́n so igi méjì pọ̀ di ọ̀kan?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣọ̀kan láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́ lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, ìyẹn lọ́dún 1919, àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ pa dà wà níṣọ̀kan.
Àtúnṣe: Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tẹnu mọ́ bí Jèhófà ṣe máa mú káwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ wà níṣọ̀kan. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún lẹ́yìn ọdún 1919, àwọn èèyàn tó nírètí àtigbé láyé bẹ̀rẹ̀ sí í wá sínú ètò Jèhófà, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró. Àwùjọ méjèèjì sì ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ níṣọ̀kan.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ò sọ nípa igi kan tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ sí méjì tí wọ́n wá so pọ̀ di ẹyọ kan. Torí náà, àsọtẹ́lẹ̀ náà kò sọ nípa àwùjọ kan tó kọ́kọ́ pínyà tó sì pa dà wà níṣọ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni bí àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe di ọ̀kan.
Ta ni Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù lorúkọ tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Sátánì máa jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá lé e kúrò lọ́run.
Àtúnṣe: Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù ni àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí tó máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà ìpọ́njú ńlá.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ nípa Gọ́ọ̀gù fi hàn pé kò lè jẹ́ áńgẹ́lì. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé ó máa di ẹran ìjẹ fáwọn ẹyẹ àti pé ayé yìí nibi ìsìnkú rẹ̀ máa wà. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Dáníẹ́lì àti Ìfihàn sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn sì jọra pẹ̀lú ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ pé Gọ́ọ̀gù máa ṣe.—Dán. 11:40, 44, 45; Ìfi. 17:14; 19:19.
Ṣé tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran tó sì tún rìn yí ká rẹ̀ ni tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ nígbà tó yá?
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀: Ohun kan náà ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran àti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Àtúnṣe: Kì í ṣe tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó rí ni bí ìjọsìn tòótọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe lábẹ́ Òfin Mósè ṣe máa pa dà bọ̀ sípò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ìgbèkùn dé. Lọ́wọ́ kejì, iṣẹ́ ribiribi tí Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Tó Tóbi Jù gbé ṣe lọ́dún 29 sí 33 Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Nínú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, kò sí àlùfáà àgbà níbẹ̀. Nípa báyìí, ṣe ni ìran náà ń jẹ́ ká rí bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1919 Sànmánì Kristẹni. Torí náà, kò sídìí pé à ń wá ohun tí onírúurú nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ tàbí ohun tí ìwọ̀n kọ̀ọ̀kan ṣàpẹẹrẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wá lógún jù lohun tá a rí kọ́ nínú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, pàápàá bá a ṣe lè jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu.
Ohun tó mú ká ṣàtúnṣe: Àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tó mú kí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí yàtọ̀ sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fi ẹran rúbọ nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí. Àmọ́ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ẹbọ kan ṣoṣo ni wọ́n rú, ó sì jẹ́ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.” (Héb. 9:11, 12) Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó wá sáyé, kò tíì tó àkókò lójú Jèhófà láti ṣí òtítọ́ tó jinlẹ̀ nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí payá.