Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni wọ́n ṣe ń rí owó tí wọ́n ń ná sórí àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
▪ Owó orí ni wọ́n fi ń bójú tó oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì, ìdámẹ́wàá tó jẹ́ owó orí tó pọn dandan sì lò pọ̀ jù lára owó náà. Àmọ́, wọ́n tún máa ń lo àwọn owó orí míì pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà sọ fún Mósè pé kó gba ààbọ̀ ṣékélì fàdákà gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ fún Jèhófà,” lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí orúkọ wọ́n wà nínú àkọsílẹ̀.—Ẹ́kísódù 30:12-16.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe di ohun tí àwọn Júù wá ń ṣe nìyẹn, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń mú iye yìí wá lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí owó orí tẹ́ńpìlì. Owó orí yìí ni Jésù ní kí Pétérù fi owó ẹyọ tó rí lẹ́nu ẹja san.—Mátíù 17:24-27.
Láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n rí owó ẹyọ fàdákà méjì tí wọ́n fi ń san owó orí tẹ́ńpìlì. Ọdún 22 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe ọ̀kan lára owó ẹyọ náà ní ìlú Tírè, inú gọ́tà tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni wọ́n ti rí i. Wọ́n ya orí Melkart tàbí Báálì sí ojú àkọ́kọ́ owó ṣékélì náà, ìyẹn ọlọ́run tí wọ́n ń júbà fún jù lọ ní ìlú Tírè, wọ́n sì ya ẹyẹ igún tó bà sórí ọ̀pá ìtọ́kọ̀ òkun sí ojú kejì owó náà. Ọdún 66 sí 67 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún àkọ́kọ́ tí àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí Róòmù ni wọ́n ṣe owó ẹyọ kejì tí wọ́n rí nínú àwókù tẹ́ńpìlì. Àwòrán ife oníga àti àwòrán èso pómégíránétì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ yọ òdòdó pẹ̀lú àwòrán “Ààbọ̀ Ṣékélì” àti ti “Jerúsálẹ́mù Mímọ́” ló wà lára owó náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gabriel Barkay sọ nípa àwárí yìí, ó ní, owó ẹyọ náà ní “àmì pé iná ti bà á jẹ́, ó sì lè jẹ́ iná tí wọ́n fi sun Tẹ́ńpìlì Èkejì lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.”
Báwo ni ilé tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kọ́ ṣe tóbi lọ́lá tó?
▪ Ìwé Dáníẹ́lì inú Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Nebukadinésárì sọ, ó ní: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi?” (Dáníẹ́lì 4:30) Ṣé òótọ́ ni pé ìlú àtijọ́ yìí tóbi lọ́lá?
Àwọn òpìtàn sọ pé, Nebukadinésárì kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì, àwọn ààfin, àwọn ògiri ìlú àtàwọn ọgbà tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Ilé àwọn olùṣọ́ wà lórí tẹ́ńpìlì tó gbawájú jù lọ tó wà ní àárín ìlú Bábílónì, ó ṣeé ṣe kí ilé àwọn olùṣọ́ náà ga ju ilé alájà mẹ́tàlélógún [23] lọ. Àmọ́, ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìlú Bábílónì, ìyẹn ìwé Babylon—City of Wonders sọ pé, “Nǹkan ńlá tí àwọn èèyàn mọ̀ jù tí [Nebukadinésárì] ṣe ni Òpópónà Àwọn Aláyẹyẹ ní Bábílónì àti Ibodè Íṣítà.” Wọ́n yàwòrán àwọn kìnnìún tí wọ́n dà bíi pé wọ́n ń rìn sí ẹ̀gbẹ́ Òpópónà Àwọn Aláyẹyẹ ní Bábílónì, ọ̀nà yìí sì gba Ibodè Íṣítà kọjá. Nígbà tí ìwé kan náà yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ibodè tó gbàfiyèsí jù lọ tó wọ ìlú Bábílónì yìí, ó ní: “Bíríkì pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ aláwọ̀ búlúù ni wọ́n fi bò ó délẹ̀, wọ́n sì fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwòrán màlúù àti dírágónì ṣe ọ̀ṣọ́ sí i, ó dájú pé àwọn àlejò tó wá sí olú ìlú yẹn nígbà yẹn kò lè gbàgbé àwọn nǹkan tí wọ́n rí yìí.”
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún, àwọn awalẹ̀pìtàn hú ẹgbẹẹgbẹ̀rún nǹkan àwókù Òpópónà Àwọn Aláyẹyẹ ní Bábílónì àti Ibodè Íṣítà, wọ́n sì tún ọ̀pọ̀ irú rẹ̀ ṣe sí Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ní Pergamon, ní ìpínlẹ̀ Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bó ṣe rí gan-an nìyí
[Àwọn Credit Line]
Òkè: Clara Emit, Courtesy of Israel Antiquities Authority; ìsàlẹ̀: Zev Radovan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àtúnkọ́ ibodè Íṣítà