Orí Keje
Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
1. Báwo ni ipa tí ọ̀rọ̀ mẹ́rin tí a kọ sára ògiri nígbà pípẹ́ sẹ́yìn ní lórí àwọn ènìyàn ṣe rìn jìnnà tó?
Ọ̀RỌ̀ mẹ́rin lásán ni a kọ sára ògiri kan tí a rẹ́. Síbẹ̀, jìnnìjìnnì ọ̀rọ̀ mẹ́rin yẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ọba alágbára kan di ayírí. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kéde bí ọba méjì yóò ṣe kúrò lórí ìtẹ́, pé ọ̀kan nínú wọn yóò kú, agbára ayé alágbára kan yóò sì dópin. Ẹgbẹ́ ìsìn kan tí a bọ̀wọ̀ fún tipasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gbẹ̀tẹ́. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wọ́n gbé ìjọsìn mímọ́ gaara Jèhófà ga, wọ́n sì túbọ̀ jẹ́rìí sí jíjẹ́ ọba aláṣẹ rẹ̀ ní àkókò kan tí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ kò fi bẹ́ẹ̀ ka èyíkéyìí nínú méjèèjì sí. Kódà, àní ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn tún jẹ́ kí a lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé lónìí pàápàá! Báwo ni ọ̀rọ̀ mẹ́rin ṣe lè ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn ná? Ẹ jẹ́ kí a wò ó.
2. (a) Kí ní ṣẹlẹ̀ ní Bábílónì lẹ́yìn ikú Nebukadinésárì? (b) Alákòóso wo ni agbára wá wà lọ́wọ́ rẹ̀ báyìí?
2 Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ti kọjá lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní orí kẹrin ìwé Dáníẹ́lì. Ikú Nebukadinésárì Ọba agbéraga ní ọdún 582 ṣááju Sànmánì Tiwa fòpin sí ìṣàkóso rẹ̀, tí ó gùn tó ọdún mẹ́tàlélógójì ní Bábílónì. Ọ̀wọ́ àwọn arọ́pò ni wọ́n dìde wá láti ìlà ìdílé rẹ̀, ṣùgbọ́n ikú òjijì tàbí kí a yọ́ kẹ́lẹ́ pa òmíràn lára wọn ní ń fòpin sí ìjọba wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Níkẹyìn, ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Nábónídọ́sì gorí ìtẹ́ nípasẹ̀ ìdìtẹ̀. Ó dájú pé Nábónídọ́sì kò ti ìdílé ọba Bábílónì wá rárá nítorí pé ọmọ obìnrin kan tí ó jẹ́ àlùfáà àgbà fún Sin, ọlọ́run òṣùpá ni. Àwọn ògbógi kan dábàá pé ó fẹ́ ọmọbìnrin Nebukadinésárì ṣaya láti lè fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso múlẹ̀ lábẹ́ òfin, pé ó pin ìṣàkóso ṣe pẹ̀lú Bẹliṣásárì, ọmọ tí wọ́n bí, pé nígbà kan, ó tilẹ̀ fi Bábílónì síkàáwọ́ rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọmọ ọmọ Nebukadinésárì ni Bẹliṣásárì jẹ́. Ó ha ti tipasẹ̀ ìrírí baba rẹ̀ àgbà kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, tí ó lè tẹ́ ọba èyíkéyìí lógo bí? Bóyá ni!—Dáníẹ́lì 4:37.
ÀSÈ KAN DÌDÀKUDÀ
3. Báwo ni àsè Bẹliṣásárì ṣe rí?
3 Ọ̀rọ̀ àsè ńlá kan ni ó bẹ̀rẹ̀ orí karùn-ún ìwé Dáníẹ́lì. “Ní ti Bẹliṣásárì Ọba, ó se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, ó sì ń mu wáìnì ní iwájú àwọn ẹgbẹ̀rún náà.” (Dáníẹ́lì 5:1) Bí o bá fojú inú wò ó, gbọ̀ngàn tí yóò gba gbogbo àwọn ènìyàn yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn wáhàrí ọba àti àwọn aya rẹ̀ onípò kejì, ní láti gbòòrò gan-an ni. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Àsè àwọn ará Bábílónì máa ń fakíki gan-an ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìmutípara ni ó sábà máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. Wáìnì tí a kó wá láti ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ohun ìgbafẹ́ lónírúurú ni wọ́n máa ń kó kún orí tábìlì. Òórùn lọ́fíńdà a gba inú gbọ̀ngàn náà kan; àwọn akọrin àti àwọn tí ń lo ohun èlò ìkọrin a máa dá àwọn tí a pè wá síbi àsè lára yá.” Gẹ́gẹ́ bí alága àsè, Bẹliṣásárì wà níbi tí gbogbo ènìyàn ti lè rí i, ó ń mu wáìnì rẹ̀—ó sì mu, mu, mu.
4. (a) Èé ṣe tí ó fi lè dà bí pé ó ṣàjèjì lójú ẹni pé àwọn ará Bábílónì ń jàsè ní òru October 5 tàbí 6, ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Kí ni ó dà bí pé ó ki àwọn ará Bábílónì láyà lójú bí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ṣe dojú kọ wọ́n?
4 Ó dà bí pé ó ṣàjèjì lójú ẹni pé àwọn ará Bábílónì ń ṣe irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ní òru yẹn—ní October 5 tàbí 6, ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Inú ogun ni orílẹ̀-èdè wọn wà, wọn ò sì rọ́wọ́ mú. Kò tíì pẹ́ tí àwọn ará Mídíà òun Páṣíà fẹ̀yìn Nábónídọ́sì balẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé Borsippa, ní apá gúúsù ìwọ̀-oòrùn Bábílónì ni ó sá lọ forí pa mọ́ sí. Àti pé, ní lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì pabùdó sí ẹ̀yìn òde ìlú Bábílónì gan-an. Síbẹ̀, kò dà bí pé ìdààmú kankan bá Bẹliṣásárì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn. Ó ṣe tán, Bábílónì, ìlú tí a kò lè borí láéláé sáà ni ìlú wọn! Àwòṣífìlà ni àwọn odi rẹ̀ kìǹbà kìǹbà, wọ́n sì ga fíofío lókè àwọn yàrà jíjìn, tí omi Odò Yúfírétì ńlá nì tí ń sàn gba inú ìlú ńlá náà sì kún àwọn yàrà náà dẹ́múdẹ́mú. Láti ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rún ọdún sí ìgbà yẹn, kò tíì sí ọ̀tá kankan tí ó tíì rọ́ lu Bábílónì lójijì. Nítorí náà, ti ìdààmú ti jẹ́? Bóyá Bẹliṣásárì ronú pé ariwo àríyá wọn yóò fi han àwọn ọ̀tá wọn tí ń gbọ́ ọ lóde pé àwọn ní ìdánilójú pé mìmì kan ò lè mi àwọn, tí ọwọ́ wọn yóò sì rọ.
5, 6. Kí ni Bẹliṣásárì ṣe nígbà tí wáìnì gùn ún, èé sì ti ṣe tí èyí fi jẹ́ ìtàbùkù ńláǹlà sí Jèhófà?
5 Kò pẹ́ púpọ̀ tí àmuyíràá ọtí fi bẹ̀rẹ̀ sí gun Bẹliṣásárì. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 20:1 ṣe wí, “afiniṣẹ̀sín ni wáìnì.” Nínú ọ̀ràn ti èyí, ó dájú pé wáìnì mú kí ọba hu ìwà aṣiwèrè tí ó burú jù lọ. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ohun èlò ọlọ́wọ̀, tí a kó wá láti inú tẹ́ńpìlì Jèhófà, wá síbi àsè náà. Àwọn ohun èlò wọ̀nyí, tí Nebukadinésárì kó gẹ́gẹ́ bí ìkógun nígbà tí ó ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ni a ní láti lò fún kìkì ìjọsìn mímọ́ gaara nìkan. Kódà, àwọn àlùfáà Júù tí a yọ̀ǹda fún láti lò wọ́n nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù tẹ́lẹ̀ rí ni a ti kìlọ̀ fún pé kí wọ́n para wọn mọ́ ní mímọ́.—Dáníẹ́lì 5:2; fi wé Aísáyà 52:11.
6 Ṣùgbọ́n, ìwà àfojúdi tí Bẹliṣásárì fẹ́ hù tún burú ju èyí lọ. “Ọba àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, àwọn wáhàrì rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀ onípò kejì . . . mu wáìnì, wọ́n sì yin àwọn ọlọ́run wúrà àti ti fàdákà, bàbà, irin, igi àti òkúta.” (Dáníẹ́lì 5:3, 4) À ṣé ńṣe ni Bẹliṣásárì fẹ́ gbé àwọn ọlọ́run rẹ̀ ga ju Jèhófà lọ! Ó dà bí pé ìwà yìí jẹ́ ìṣe àwọn ará Bábílónì. Ṣe ni wọ́n ń pẹ̀gàn àwọn Júù òǹdè wọn, tí wọ́n ń fi ìjọsìn wọn ṣẹ̀sín, wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí pé wọ́n ṣì lè padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ọ̀wọ́n. (Sáàmù 137:1-3; Aísáyà 14:16, 17) Bóyá ṣe ni ọba tí ó yó bìnàkò yìí rò pé títẹ́ àwọn ìgbèkùn wọ̀nyí àti títàbùkù sí Ọlọ́run wọn yóò mú orí àwọn obìnrin àti àwọn olóyè òun wú, tí ìyẹn yóò sì mú kí òun dà bí alágbára kan.a Àmọ́, ká tilẹ̀ ní Bẹliṣásárì rí ìwúrí gbà láti inú gígùn tí agbára gùn yìí, kò wà fún ìgbà pípẹ́ rárá.
ÌKỌ̀WÉ LÁRA ÒGIRI
7, 8. Báwo ni a ṣe dá àsè Bẹliṣásárì dúró, ipa wo sì ni èyí ní lórí ọba?
7 Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Ní ìṣẹ́jú yẹn, àwọn ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé ní iwájú ọ̀pá fìtílà sára ibi tí a rẹ́ lára ògiri ààfin ọba, ọba sì rí ẹ̀yìn ọwọ́ tí ó ń kọ̀wé.” (Dáníẹ́lì 5:5) Èèmọ̀ rèé o! Ọwọ́ ṣàdédé yọ láìmọ ibi tí ó ti wá, tí ó ń káàkiri lófuurufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí iná tàn sí dáadáa lára ògiri. Fojú inú wo bí ibi àsè náà ṣe máa dákẹ́ wẹ́lo bí àwọn tí a pè wá jàsè ṣe yíjú síbẹ̀ tí wọ́n sì ranjú mọ́ ọn. Ọwọ́ yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ àdììtú ìsọfúnni kan sára ibi tí a rẹ́ náà.b Àfihàn yìí jẹ́ abàmì gan-an, kó sì ṣeé gbàgbé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí àwọn ènìyàn fi ń lo gbólóhùn náà, “ìkọ̀wé lára ògiri,” títí di òní yìí, láti fi dọ́gbọ́n kìlọ̀ pé ewu ń bẹ níwájú.
8 Ipa wo ni ó ní lórí agbéraga ọba yìí tí ó gbìyànjú láti gbé ara rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ga ju Jèhófà lọ? “Ní àkókò yẹn, ní ti ọba, àwọ̀ ara rẹ̀ yí padà, ìrònú òun fúnra rẹ̀ sì kó jìnnìjìnnì bá a, àwọn oríkèé ìgbáròkó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀, àwọn eékún rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá ara wọn.” (Dáníẹ́lì 5:6) Ṣe ni Bẹliṣásárì fẹ́ gbé ara rẹ̀ sípò ẹni iyì, ọlọ́lá ńlá, níwájú àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó di ẹni tí a fi ń júwe bí jìnnìjìnnì ńláǹlà ṣe lè múni kú sára—àwọ̀ ojú rẹ̀ ṣì, ìgbáròkó rẹ̀ ń gbò yèpéyèpé, gbogbo ara rẹ̀ gbọ̀n rìrì gidigidi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn eékún rẹ̀ fi ń gbára. Ní tòótọ́, òtítọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì darí rẹ̀ sí Jèhófà nínú orin pé: “Ojú rẹ lòdì sí àwọn onírera, kí o lè rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.”—2 Sámúẹ́lì 22:1, 28; fi wé Òwe 18:12.
9. (a) Èé ṣe tí ìpayà Bẹliṣásárì kì í ṣe ti ìbẹ̀rù Ọlọ́run? (b) Kí ni ohun tí ọba nawọ́ rẹ̀ sí àwọn amòye Bábílónì?
9 Ẹ ṣàkíyèsí pé ìbẹ̀rù Bẹliṣásárì kì í ṣe ti ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn, ìbọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà, tí í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ gbogbo ọgbọ́n. (Òwe 9:10) Rárá o, ìpayà tí ń múni kí danidání ni, kò sì yọrí sí ọgbọ́n kankan rárá fún ọba tí ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ náà.c Kàkà tí ì bá fi máa bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ tàbùkù sí, ó ń ké kíkankíkan pé kí wọ́n mú “àwọn alálùpàyídà, àwọn ará Kálídíà àti àwọn awòràwọ̀” wá. Ó tilẹ̀ kéde pé: “Ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá ka ìkọ̀wé yìí, tí ó sì fi ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an hàn mí, a ó fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, a ó sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà yí ọrùn rẹ̀ ká, yóò sì ṣàkóso bí igbá-kẹta nínú ìjọba.” (Dáníẹ́lì 5:7) Ẹni ńlá gidigidi ni ẹni tí ń ṣàkóso bí igbá-kẹta nínú ìjọba yóò jẹ́, kìkì ọba méjèèjì tí ń ṣàkóso, tí í ṣe Nábónídọ́sì àti Bẹliṣásárì fúnra rẹ̀, ni yóò jù ú lọ. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, ọmọkùnrin Bẹliṣásárì tí ó bá dàgbà jú lọ ni ipò yẹn ì bá wà nílẹ̀ fún. Ẹ ò rí bí ọ̀ràn kí àlàyé ìhìn iṣẹ́ ìyanu yìí sáà wáyé lọ́nàkọnà ṣe ká ọba lára tó!
10. Báwo ni àwọn amòye náà ti ṣe sí lẹ́nu ìsapá wọn láti túmọ̀ ìkọ̀wé ara ògiri náà?
10 Àwọn amòye bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ wá sínú gbọ̀ngàn ńlá náà. Wìtìwìtì ni wọ́n ń ya lu ibẹ̀, nítorí ìlú tí ó rì sínú ẹ̀sìn èké gidigidi, tí àwọn tẹ́ńpìlì sì kún fọ́fọ́ ni Bábílónì jẹ́. Ó dájú pé pìtìmù ni ibẹ̀ kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn lè ṣàlàyé àwọn àpẹẹrẹ abàmì pé àwọn sì lè túmọ̀ àdììtú ìkọ̀wé. Àǹfààní tí ó wà níwájú àwọn amòye wọ̀nyí ti ní láti mú ara wọn yá gágá. Àǹfààní rèé fún wọn láti gbé iṣẹ́ ọwọ́ wọn yọ níwájú àwùjọ ẹni kàǹkà kàǹkà, kí ọba ṣe sàdáńkátà wọn, kí wọ́n sì di ẹni tí ipò agbára ńlá tẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, wọ́n kùnà gbáà! “Wọn kò kúnjú ìwọ̀n láti ka ìkọ̀wé náà tàbí láti sọ ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún ọba.”d—Dáníẹ́lì 5:8.
11. Kí ni kò fi ní lè jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àwọn amòye Bábílónì láti ka ìkọ̀wé náà?
11 Bóyá ṣe ni àwọn amòye Bábílónì kò rí ìkọ̀wé náà kà—ìyẹn àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ rẹ̀—kò dáni lójú. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fàlàlà fún àwọn ènìyàn kénìyàn yẹn láti kàn kà á bákan ṣá, bóyá lọ́nà kan tí yóò tilẹ̀ pọ́n ọba yẹn lé pàápàá. Ohun mìíràn tí ó tún ṣeé ṣe ni pé àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé kà dáadáa. Àmọ́, níwọ̀n bí àwọn èdè bí Árámáíkì àti Hébérù ti jẹ́ èyí tí a ń kọ láìsí fáwẹ́lì nínú rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ náà ni ó ṣeé ṣe láti fún ní àwọn ìtumọ̀ bí mélòó kan. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè má ṣeé ṣe fún àwọn amòye yẹn láti pinnu àwọn ọ̀rọ̀ wo gan-an ni ì bá jẹ́. Kódà bí wọ́n bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀, òye ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí kò ní yé wọn débi tí wọn yóò fi lè ṣàlàyé rẹ̀. Èyíwù ó jẹ́, ohun kan dájú: Àwọn amòye Bábílónì kùnà—wọ́n kùnà pátápátá!
12. Ìkùnà àwọn amòye wọ̀nyẹn fi ẹ̀rí kí ni hàn?
12 Bí àwọn amòye wọ̀nyẹn ṣe di ẹni tí a tú fó nìyẹn, pé ayédèrú ni wọ́n, pé ẹ̀tàn pátápátá ni ètò ẹ̀sìn wọn tí a bọ̀wọ̀ fún jẹ́. Ajánikulẹ̀ gbáà ni wọ́n! Bí Bẹliṣásárì ṣe rí i pé ìgbẹ́kẹ̀lé òun nínú àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyí ti wọmi, jìnnìjìnnì túbọ̀ bò ó sí i, àwọ̀ ara rẹ̀ sì túbọ̀ ń ṣì lára rẹ̀, kódà “ọkàn” àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn “dà rú.”e—Dáníẹ́lì 5:9.
A RÁNṢẸ́ PE ẸNÌ KAN TÍ Ó NÍ ÌJÌNLẸ̀ ÒYE
13. (a) Èé ṣe tí ayaba fi dábàá pé kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá? (b) Irú ìgbésí ayé wo ni Dáníẹ́lì ń gbé?
13 Ní àkókò tí ọ̀ràn le koko yìí, ayaba alára—bóyá òun ni ìyá ọba—wọnú gbọ̀ngàn àpèjẹ. Ó ti gbọ́ nípa rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ níbi àsè náà, ó sì mọ̀ nípa ẹnì kan tí ó lè ka ìkọ̀wé ara ògiri náà kí ó sì ṣàlàyé rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú, Nebukadinésárì baba rẹ̀ yan Dáníẹ́lì ṣe olórí gbogbo amòye rẹ̀. Ayaba rántí pé ó jẹ́ ẹni tí ó ní “ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ àti ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye.” Níwọ̀n bí ó ti jọ pé Bẹliṣásárì kò mọ Dáníẹ́lì, ó ṣeé ṣe kí ipò gíga tí wòlíì náà wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ikú Nebukadinésárì. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ gbajúmọ̀ kò já mọ́ nǹkan kan lójú Dáníẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé ní àádọ́rùn-ún ọdún ní ìgbà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣì ń fi ìṣòtítọ́ jọ́sìn Jèhófà nìṣó. Láìka nǹkan bí ọgọ́rin ọdún tí ó ti lò nígbèkùn ní Bábílónì sí, a ṣì fi orúkọ Hébérù rẹ̀ mọ̀ ọ́n. Àní ayaba pàápàá pè é ní Dáníẹ́lì, láìlo orúkọ Bábílónì tí a fún un nígbà kan rí. Ní ti gidi, ó rọ ọba pé: “Jẹ́ kí a pe Dáníẹ́lì, kí ó lè fi ìtumọ̀ náà gan-an hàn.”—Dáníẹ́lì 1:7; 5:10-12.
14. Ìṣòro wo ni Dáníẹ́lì kó sí bí ó ṣe rí ìkọ̀wé ara ògiri náà?
14 A ké sí Dáníẹ́lì, ó sì wọlé wá síwájú Bẹliṣásárì. Ó jẹ́ ìtìjú láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Júù yìí, tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run rẹ̀ ni ọba ṣẹ̀ṣẹ̀ tàbùkù sí. Síbẹ̀, Bẹliṣásárì gbìyànjú láti pọ́n Dáníẹ́lì, ní fífi èrè kan náà—igbá-kẹta nínú ìjọba—síwájú rẹ̀ bí ó bá lè ka àdììtú ọ̀rọ̀ náà kí ó sì ṣàlàyé rẹ̀. (Dáníẹ́lì 5:13-16) Dáníẹ́lì bá gbójú sókè wo ìkọ̀wé ara ògiri náà, ẹ̀mí mímọ́ sì jẹ́ kí ó lóye ìtumọ̀ rẹ̀. Ìhìn iṣẹ́ ègbé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run mà ni! Báwo wá ni Dáníẹ́lì yóò ṣe kéde ìhìn iṣẹ́ lílekoko tí a rán sí ọba tí ń fẹgẹ̀ yìí lójú rẹ̀ kòrókòró—ìyẹn sì tún jẹ́ níwájú àwọn aya rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn? Ìṣòro mà rèé fún Dáníẹ́lì! Pípọ́n tí ọba pọ́n ọn àti ọrọ̀ àti ipò olókìkí tí ó fi lọ̀ ọ́ ha gbà á lọ́kàn bí? Wòlíì yìí yóò ha ṣàbùlà ìkéde Jèhófà bí?
15, 16. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Bẹliṣásárì kùnà láti kọ́ láti inú ìtàn, báwo sì ni ìkùnà yẹn ṣe wọ́pọ̀ tó lónìí?
15 Dáníẹ́lì fi ìgboyà sọ̀rọ̀ jáde, pé: “Kí ẹ̀bùn rẹ jẹ́ tìrẹ, sì fi ọrẹ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ ṣá o, èmi yóò ka ìkọ̀wé náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ fún un.” (Dáníẹ́lì 5:17) Lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì sọ nípa bí Nebukadinésárì ṣe tóbi lọ́lá tó, ọba kan tí ó lágbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, tí ó lè kọlu ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, tí ó lè gbé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ga, tí ó sì lè tẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́. Àmọ́, Dáníẹ́lì rán Bẹliṣásárì létí pé Jèhófà, “Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,” ni ó sọ Nebukadinésárì di ẹni ńlá. Jèhófà náà ni ó tẹ́ ọba alágbára náà lógo nígbà tí ó di onírera. Bẹ́ẹ̀ ni, Nebukadinésárì kẹ́kọ̀ọ́ tipátipá pé “Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń gbé ka orí rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 5:18-21.
16 Bẹliṣásárì “mọ gbogbo èyí.” Síbẹ̀, kò fi ìtàn kọ́gbọ́n. Ní ti gidi, ó ṣe ré kọjá ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga Nebukadinésárì, ó sì hu ìwà àfojúdi pátápátá sí Jèhófà. Dáníẹ́lì ka ẹ̀ṣẹ̀ ọba fún un. Síwájú sí i, ní iwájú àpéjọ àwọn abọ̀rìṣà yẹn, ó fi ìgboyà sọ fún Bẹliṣásárì pé àwọn ọlọ́run èké “kò rí nǹkan kan tàbí gbọ́ nǹkan kan tàbí mọ nǹkan kan.” Wòlíì Ọlọ́run, tí ó jẹ́ onígboyà, fi kún un pé ní òdì-kejì sí àwọn ọlọ́run tí kò wúlò wọ̀nyẹn, Jèhófà ni Ọlọ́run “ẹni tí èémí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀.” Di òní olónìí, àwọn ènìyàn ń sọ àwọn ohun aláìlẹ́mìí di ọlọ́run, wọn a sọ owó, iṣẹ́ ìgbésí ayé, ipò iyì, àní fàájì pàápàá, di òrìṣà. Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú ìwọ̀nyí tí ó lè fúnni ní ìwàláàyè. Jèhófà nìkan ni ẹni tí ìwàláàyè gbogbo wa ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí a gbára lé fún gbogbo èémí tí a ń mí sínú.—Dáníẹ́lì 5:22, 23; Ìṣe 17:24, 25.
A RÍ OJÚTÙÚ SÍ ÀDÌÌTÚ KAN!
17, 18. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́rin tí a kọ sára ògiri náà, kí sì ni ìtumọ̀ wọn ní ṣangiliti?
17 Wòlíì ọlọ́jọ́ lórí náà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó ti di ẹtì fún gbogbo amòye Bábílónì. Ó ka ọ̀rọ̀ tí a fọwọ́ kọ sára ògiri náà, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni: “MÉNÈ, MÉNÈ, TÉKÉLÍ, PÁRÁSÍNÌ.” (Dáníẹ́lì 5:24, 25) Kí ni wọ́n túmọ̀ sí?
18 Ní ṣangiliti, àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “mínà kan, mínà kan, ṣékélì kan, àti ààbọ̀ ṣékélì.” Gbólóhùn kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n iye owó kan, a sì tò wọ́n láti orí èyí tí ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ jù wá ìsàlẹ̀ sí èyí tí ó kéré jù. Ó mà kúkú ta kókó o! Ká tilẹ̀ ní ó ṣeé ṣe fún àwọn amòye Bábílónì láti mọ àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ náà, kò yani lẹ́nu pé wọn kò lè sọ ìtumọ̀ wọn.
19. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “MÉNÈ”?
19 Dáníẹ́lì ṣàlàyé lábẹ́ agbára ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run pé: “Èyí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà: MÉNÈ, Ọlọ́run ti ka iye ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 5:26) Àwọn kọ́ńsónáǹtì ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ yọ̀ǹda pé kí a pè é ní “mínà” tàbí kí a pè é ní ọ̀rọ̀ Árámáíkì kan báyìí tí ó túmọ̀ sí “kí a ṣírò rẹ̀,” tàbí kí a “kà á,” ní sísinmi lórí àwọn fáwẹ́lì tí òǹkàwé bá lò. Dáníẹ́lì mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ ìgbèkùn àwọn Júù ti ń parí lọ. Nínú àádọ́rin ọdún tí a sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò jẹ́ ní gígùn, ọdún méjìdínláàádọ́rin ti kọjá lọ. (Jeremáyà 29:10) Jèhófà, Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà, ti ka iye ọjọ́ ìṣàkóso Bábílónì gẹ́gẹ́ bí agbára ayé, òpin rẹ̀ sì sún mọ́lé ju bí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ níbi àsè Bẹliṣásárì ṣe rò lọ. Ní ti gidi, àkókò ti tán—kì í ṣe fún Bẹliṣásárì nìkan, ó ti tán fún Nábónídọ́sì baba rẹ̀ náà pẹ̀lú. Èyí lè jẹ́ ìdí tí a fi kọ gbólóhùn náà “MÉNÉ” lẹ́ẹ̀mejì—láti fi kéde òpin ipò ọba méjèèjì.
20. Kí ni àlàyé ọ̀rọ̀ náà, “TÉKÉLÌ,” báwo ni ó sì ṣe kan Bẹliṣásárì?
20 Àmọ́, ẹ̀ẹ̀kan péré ni a kọ “TÉKÉLÌ” ní tirẹ̀, ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun kan ṣoṣo sì ni. Ìyẹn lè fi hàn pé Bẹliṣásárì ni a darí ìyẹn sí ní tààràtà. Èyí yóò sì bamu wẹ́kú, nítorí òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan hùwà àìbọ̀wọ̀fúnni tí ó burú jáì sí Jèhófà. “Ṣékélì” ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn kọ́ńsónáǹtì inú ọ̀rọ̀ yẹn tún jẹ́ kí a tún lè pè é ní “wọ̀n.” Nípa báyìí, Dáníẹ́lì sọ fún Bẹliṣásárì pé: “TÉKÉLÌ, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò kájú ìwọ̀n.” (Dáníẹ́lì 5:27) Lọ́dọ̀ Jèhófà, gbogbo orílẹ̀-èdè kò jámọ́ nǹkan kan gan-an bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ṣe jẹ́ lórí òṣùwọ̀n. (Aísáyà 40:15) Wọn kò ní agbára láti ké ète rẹ̀ nígbèrí rárá. Kí wá ni ọba kan ṣoṣo tí ń wú fùkẹ̀ fẹ́ jámọ́? Ọba Aláṣẹ àgbáyé ni Bẹliṣásárì gbìyànjú láti gbé ara rẹ̀ ga ré kọjá. Ènìyàn lásánlàsàn yìí tí dá a láṣà láti tàbùkù sí Jèhófà, ó sì fi ìjọsìn mímọ́ gaara ṣẹlẹ́yà ṣùgbọ́n a wá rí i pé “kò kájú ìwọ̀n.” Dájúdájú, ìdájọ́ tí ń bọ̀ kánkán yìí tọ́ sí Bẹliṣásárì gidi gan-an ni!
21. Báwo ni “PÁRÁSÍNÌ” ṣe jẹ́ ìlò ọ̀rọ̀ lọ́nà àrokò oníṣẹ̀ẹ́po mẹ́ta, kí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ náà fi hàn nípa ọjọ́ iwájú Bábílónì gẹ́gẹ́ bí agbára ayé?
21 Ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn lára ògiri yẹn ni “PÁRÁSÍNÌ.” Dáníẹ́lì pè é ní “PÉRÉSÌ,” tí ó jẹ́ ìpè ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun kan ṣoṣo, bóyá nítorí pé ọba kan ṣoṣo ni ó ń bá sọ̀rọ̀ ni níwọ̀n bí ìkejì kò ti sí níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí ni ó dé àdììtú ńlá Jèhófà ládé, èyí tí ó fi ìlò ọ̀rọ̀ lọ́nà àrokò oníṣẹ̀ẹ́po mẹ́ta gbé jáde. Ní ṣangiliti, “párásínì” túmọ̀ sí “ààbọ̀ ṣékélì.” Ṣùgbọ́n àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ kí ó lè ní ìtumọ̀ méjì mìíràn—“ìpínyà” àti “Páṣíà.” Nípa bẹ́ẹ̀ Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “PÉRÉSÌ, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.”—Dáníẹ́lì 5:28.
22. Kí ni ìṣarasíhùwà Bẹliṣásárì sí ojútùú àdììtú náà, kí sì ni ó lè máa retí pé yóò ṣẹlẹ̀?
22 Bí a ṣe rójútùú àdììtú náà nìyẹn. Bábílónì alágbára ńlá yóò ṣubú sọ́wọ́ agbo ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà láìpẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkéde ègbé yìí dorí Bẹliṣásárì kodò, ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ó mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ Dáníẹ́lì, kí wọ́n fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà ṣe ọrùn rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n sì kéde ní gbangba pé ó di igbá-kẹta olùṣàkóso nínú ìjọba. (Dáníẹ́lì 5:29) Dáníẹ́lì kò kọ ìbọláfúnni yìí, ní kíkà á sí pé wọ́n jẹ́ ọ̀nà láti gbà fi ọlá tí ó tọ́ sí Jèhófà hàn. Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kí Bẹliṣásárì retí pé kí ìdájọ́ Jèhófà rọjú bí òun bá bọlá fún wòlíì Rẹ̀. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀pa kò bóró mọ́.
ÌṢUBÚ BÁBÍLÓNÌ
23. Àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì wo ni ó ń ní ìmúṣẹ lọ lọ́wọ́ àní bí Bẹliṣásárì ṣe ń jàsè lọ́wọ́ pàápàá?
23 Kódà, bí Bẹliṣásárì àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ ṣe ń mutí fún ìgbéga àwọn ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì ń tàbùkù sí Jèhófà, itú ńlá kan ni a ń pa lọ lọ́wọ́ nínú òkùnkùn lóde ààfin. Àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti sọ nípasẹ̀ Aísáyà ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì ṣáájú ti ń ní ìmúṣẹ. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì pé: “Gbogbo ìmí ẹ̀dùn nítorí rẹ̀ ni mo ti mú kí ó kásẹ̀ nílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo níni tí ìlú burúkú yẹn ń ni àwọn ènìyàn àyànfẹ́ Ọlọ́run lára yóò dópin. Nípasẹ̀ kí ni? Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kan náà sọ pé: “Gòkè lọ, ìwọ Élámù! Sàga tì, ìwọ Mídíà!” Ẹ̀yìn ọjọ́ wòlíì Aísáyà ni Élámù di apá kan Páṣíà. Ní ìgbà tí àsè Bẹliṣásárì ń lọ lọ́wọ́, tí a sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yẹn kan náà, Páṣíà àti Mídíà ti da agbo ọmọ ogun wọn pa pọ̀ ní tòótọ́, láti “gòkè lọ” láti lè “sàga” ti Bábílónì.—Aísáyà 21:1, 2, 5, 6.
24. Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo nípa ìṣubú Bábílónì ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀?
24 Kódà, a ti sọ orúkọ tí aṣáájú agbo ọmọ ogun yẹn pàápàá yóò jẹ́ tẹ́lẹ̀, a sì sọ àwọn ohun pàtàkì nínú ìwéwèé ogun jíjà tí yóò lò pẹ̀lú. Ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú, Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jèhófà yóò fòróró yan ẹnì kan tí ń jẹ́ Kírúsì láti wá bá Bábílónì jà. Bí ó ṣe ń jagun lọ, gbogbo ìdìgbòlù ni a óò mú di títẹ́jú níwájú rẹ̀. Omi Bábílónì yóò “gbẹ táútáú,” àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ńláńlá ni a óò ṣí kalẹ̀. (Aísáyà 44:27–45:3) Bí ó sì ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àwọn ọmọ ogun Kírúsì darí omi Odò Yúfírétì gba ibòmíràn, èyí mú kí omi rẹ̀ fà tí ó fi ṣeé ṣe fún wọn láti gba ìsàlẹ̀ odò náà kọjá. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tí kò bìkítà fi àwọn ilẹ̀kùn odi Bábílónì sílẹ̀ ní ṣíṣí. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ayé náà ṣe gbà, ìlú náà ni a kọlù nígbà tí àwọn olùgbé ibẹ́ ń ṣe àríyá aláriwo. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí àtakò kankan nígbà tí wọ́n gba Bábílónì. (Jeremáyà 51:30) Àmọ́ ṣá, ó kéré tán ẹnì kan kú, ó sì gbàfiyèsí. Dáníẹ́lì ròyìn pé: “Ní òru ọjọ́ yẹn gan-an, a pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà, Dáríúsì ará Mídíà sì gba ìjọba, ó jẹ́ ẹni nǹkan bí ọdún méjì-lé-lọ́gọ́ta.”—Dáníẹ́lì 5:30, 31.
KÍKỌ́ Ẹ̀KỌ́ LÁTI INÚ ÌKỌ̀WÉ ARA ÒGIRI
25. (a) Èé ṣe tí Bábílónì ìgbàanì fi jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó ṣe wẹ́kú fún ètò ìsìn èké kárí ayé lónìí? (b) Ní ọ̀nà wo ni ó fi jẹ́ pé a mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti òde òní lóǹdè ní Bábílónì?
25 Àkọsílẹ̀ onímìísí tí ó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, orí karùn-ún, ṣe pàtàkì gidigidi fún wa. Gẹ́gẹ́ bí ìkóríta àwọn àṣà ìsìn èké, Bábílónì ìgbàanì jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó ṣe wẹ́kú fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Àgbájọ ẹ̀tàn kárí ayé yìí, tí Ìṣípayá fi aṣẹ́wó tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ ṣàpẹẹrẹ, ni a pè ní “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣípayá 17:5) Ní ṣíṣàìka gbogbo ìkìlọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àṣà rẹ̀ tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run sí, ó ń ṣe inúnibíni sí àwọn tí ń wàásù òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí ti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti Júdà ìgbàanì, àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ ni a mú nígbèkùn sínú “Bábílónì Ńlá” ní ìgbà tí inúnibíni tí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà jẹ́ ògúnná gbòǹgbò rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ọdún 1918.
26. (a) Báwo ni “Bábílónì Ńlá” ṣe ṣubú ní ọdún 1919? (b) Ìkìlọ̀ wo ni ó yẹ kí àwa fúnra wa kọbi ara sí kí a sì ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?
26 Àmọ́, lójijì, “Bábílónì Ńlá” ṣubú! Óò, ìṣubú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ má mú ariwo kankan lọ́wọ́—gan-an bí ìṣubú Bábílónì ìgbàanì ṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ má mú ariwo kankan lọ́wọ́ ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, síbẹ̀ náà, ìṣubú rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ jẹ́ èyí tí ń fa ìparun. Ọdún 1919 Sànmánì Tiwa ni ó ṣẹlẹ̀, nígbà tí a dá àwọn ènìyàn Jèhófà sílẹ̀ lómìnira kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì tí a sì fi ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá jíǹkí wọn. Èyí fi òpin sí agbára “Bábílónì Ńlá” lórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì jẹ́ àmì pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí tú u fó pé ó jẹ́ ayédèrú kan tí kò ṣeé gbára lé. Ìṣubú yẹn jẹ́ èyí tí kò ní àtúnṣe, ìparun rẹ̀ pátápátá sì ti sún mọ́lé. Nípa báyìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń kéde ìkìlọ̀ náà lemọ́lemọ́ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:4) O ha ti kọbi ara sí ìkìlọ̀ yẹn bí? O ha ń ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bí?f
27, 28. (a) Òtítọ́ wo ni Dáníẹ́lì kò jẹ́ gbàgbé? (b) Ẹ̀rí wo ni a ní tí ó fi hàn pé Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ lórí ayé burúkú òde òní láìpẹ́?
27 Nítorí náà, ìkọ̀wé náà wà lára ògiri lónìí—àmọ́ kì í ṣe fún “Bábílónì Ńlá” nìkan. Rántí òtítọ́ kan tí ó jẹ́ kókó inú ìwé Dáníẹ́lì: Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé. Kìkì Òun nìkan ṣoṣo ni ó ní ẹ̀tọ́ láti fi olùṣàkóso jẹ lórí aráyé. (Dáníẹ́lì 4:17, 25; 5:21) Ohunkóhun tí ó bá fẹ́ dènà àwọn ète Jèhófà ni a óò mú kúrò. Kí àkókò sáà ti tó ni kí Jèhófà sì gbé ìgbésẹ̀. (Hábákúkù 2:3) Ní ti Dáníẹ́lì, irú àkókò yẹn tó níkẹyìn nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ lé ní àádọ́rùn-ún ọdún. Ó wá rí i pé Jèhófà mú agbára ayé kan kúrò—èyí tí ó ti ń tẹ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lórí ba láti ìgbà tí Dáníẹ́lì ti wà lọ́mọdékùnrin.
28 Ẹ̀rí tí a kò lè jáníkoro wà tí ó fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ti gbé Olùṣàkóso kan ka orí ìtẹ́ ní ọ̀run fún aráyé. Ní ti pé ayé ṣàìka Ọba yìí sí tí wọ́n sì tako ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí tí ó dájú pé Jèhófà yóò pa gbogbo àwọn alátakò ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ run láìpẹ́. (Sáàmù 2:1-11; 2 Pétérù 3:3-7) Ìwọ ha ń fi bí àkókò wa ṣe jẹ́ kánjúkánjú gbé ìgbésẹ̀, tí o sì ń gbẹ́kẹ̀ lé Ìjọba Ọlọ́run bí? Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ ńláǹlà ni o mà ti rí kọ́ nínú ìkọ̀wé ara ògiri yẹn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àkọsílẹ̀ fífín ìgbàanì kan, Kírúsì Ọba sọ nípa Bẹliṣásárì pé: “Olókùnrùn kan ni wọ́n fi jẹ alákòóso orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
b Kódà kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó dára yìí, láti inú àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì, jẹ́ èyí tí ó péye. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí pé àwọn ògiri ààfin Bábílónì ìgbàanì ni a fi bíríkì kọ́ tí a sì rẹ́.
c Ó ṣeé ṣe kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí àwọn ará Bábílónì ní túbọ̀ dá kún jìnnìjìnnì iṣẹ́ ìyanu yìí. Ìwé náà, Babylonian Life and History, sọ pé: “Ní àfikún sí ọ̀pọ̀ iye àwọn ọlọ́run tí àwọn ará Bábílónì ń jọ́sìn, a rí i pé wọ́n rì sínú ìgbàgbọ́ nínú àwọn iwin gidigidi, ó sì wọ̀ wọ́n lára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé àwọn àdúrà àti ọfọ̀ pé kí wọ́n má kàgbákò wọn ni ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn.”
d Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé: “Àwọn ògbógi Bábílónì kọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àpẹẹrẹ abàmì sílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. . . . Nígbà tí Bẹliṣásárì sọ pé dandan ni kí òun mọ ohun tí ìkọ̀wé ara ògiri náà jẹ́, ó dájú pé àwọn amòye Bábílónì wọ̀nyí yóò yíjú sí àwọn ìwé atúmọ̀ àwọn àmì wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n òfo ni wọ́n já sí.”
e Àwọn atúmọ̀ èdè sọ pé ọ̀rọ̀ tí a lò fún “ọkàn . . . dà rú” túmọ̀ sí rògbòdìyàn ńláǹlà, bí ìgbà tí rúkèrúdò bẹ́ sílẹ̀ láàárín àpéjọ náà.
f Wo ojú ìwé 205 sí 271 nínú ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
KÍ LO LÓYE?
• Báwo ni a ṣe dá àsè Bẹliṣásárì dúró ní òru October 5 tàbí 6, ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa?
• Kí ni ìtumọ̀ ìkọ̀wé ara ògiri náà?
• Àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ìṣubú Bábílónì ni ó ń ní ìmúṣẹ lọ́wọ́ bí àsè Bẹliṣásárì ṣe ń lọ lọ́wọ́?
• Kí ni ìtumọ̀ tí àkọsílẹ̀ ìkọ̀wé ara ògiri náà ní fún ọjọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 98]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 103]