Orí Kẹta
A Dàn Wọn Wò—Ṣùgbọ́n Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Jèhófà!
1, 2. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ni a fi nasẹ̀ àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì?
ÌṢẸ̀LẸ̀ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu nínú ìwé alásọtẹ́lẹ̀ ti Dáníẹ́lì ní àkókò kan tí ìyípadà pàtàkì ń ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ásíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù Nínéfè olú-ìlú rẹ̀ ni. A ti sọ Íjíbítì di èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan mọ́ níhà gúúsù ilẹ̀ Júdà. Bábílónì sì ń yára kánkán gòkè gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ alágbára pàtàkì bí olúkúlùkù ti ń sapá láti jọba lé ayé lórí.
2 Ní ọdún 625 ṣááju Sànmánì Tiwa, Fáráò Nékò ti Íjíbítì gbé ìgbésẹ̀ ìkẹyìn láti dá gbígbilẹ̀ tí Bábílónì ń gbilẹ̀ lọ síhà gúúsù dúró. Nípa bẹ́ẹ̀, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Kákémíṣì, tí ó wà ní bèbè Odò Yúfírétì òkè. Ìjà ogun Kákémíṣì, bí a ṣe wá pè é, jẹ́ ogun àjàkágbá tí òkìkí rẹ̀ kàn. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì, tí Ọmọ Aládé náà, Nebukadinésárì, ṣe aṣáájú rẹ̀, fojú agbo ọmọ ogun Fáráò Nékò gbolẹ̀. (Jeremáyà 46:2) Ní yíyára lo àǹfààní ìṣẹ́gun rẹ̀ yìí, Nebukadinésárì bo Síríà òun Palẹ́sìnì mọ́lẹ̀, ó sì tipa báyìí fòpin sí àkóso Íjíbítì pátápátá ní àgbègbè yìí. Ikú Nabopolassar, baba rẹ̀, ni ó kàn dá jíjà tí ó ń ja ogun kiri dúró fún ìgbà díẹ̀.
3. Kí ni àbájáde ogun àkọ́kọ́ tí Nebukadinésárì gbé ja Jerúsálẹ́mù?
3 Lọ́dún tí ó tẹ̀ lé e, Nebukadinésárì—tí ó ti wá gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Bábílónì—tún yíjú sí gbígbé ogun ja Síríà òun Palẹ́sìnì lẹ́ẹ̀kan sí i. Àkókò yìí ni ó wá sí Jerúsálẹ́mù fún ìgbà àkọ́kọ́. Bíbélì ròyìn pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ni Nebukadinésárì ọba Bábílónì gòkè wá, bí Jèhóákímù sì ṣe di ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó yí padà, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i.”—2 Àwọn Ọba 24:1.
NEBUKADINÉSÁRÌ NÍ JERÚSÁLẸ́MÙ
4. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye gbólóhùn náà, “ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Jèhóákímù” nínú Dáníẹ́lì 1:1?
4 Gbólóhùn náà “fún ọdún mẹ́ta” fà wá lọ́kàn mọ́ra lọ́nà àkànṣe, nítorí pé ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú Dáníẹ́lì kà pé: “Ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Jèhóákímù ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga tì í.” (Dáníẹ́lì 1:1) Ní ọdún kẹta tí Jèhóákímù ti jọba, ẹni tí ó jọba ní ọdún 628 sí ọdún 618 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nebukadinésárì kò tíì di “ọba Bábílónì” ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ aládé. Ní ọdún 620 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nebukadinésárì sọ ọ́ di dandan fún Jèhóákímù láti san owó òde. Ṣùgbọ́n Jèhóákímù ṣọ̀tẹ̀ lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Nípa báyìí, ní ọdún 618 ṣááju Sànmánì Tiwa, tàbí nígbà ọdún kẹta tí Jèhóákímù jẹ ọba lábẹ́ àkóso Bábílónì, ni Nebukadinésárì Ọba wá sí Jerúsálẹ́mù lẹ́ẹ̀kejì, láti fìyà jẹ Jèhóákímù tí ó ṣọ̀tẹ̀.
5. Kí ni àbájáde ogun ẹ̀ẹ̀kejì tí Nebukadinésárì gbé ja Jerúsálẹ́mù?
5 Àbáyọrí ìgbóguntì náà ni pé “nígbà tí ó ṣe, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́ àti apá kan lára àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́.” (Dáníẹ́lì 1:2) Ó dà bí pé Jèhóákímù kú láàárín apá ìbẹ̀rẹ̀ ìgbóguntì náà yálà nípasẹ̀ ìyọ́kẹ́lẹ́pani tàbí nípasẹ̀ ìdìtẹ̀. (Jeremáyà 22:18, 19) Ní ọdún 618 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhóákínì ọmọkùnrin rẹ̀, ẹni ọdún 18, rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ṣùgbọ́n oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá péré ni ìṣàkóso rẹ̀ mọ, ó sì juwọ́ sílẹ̀ ní ọdún 617 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Fi wé 2 Àwọn Ọba 24:10-15.
6. Kí ni Nebukadinésárì ṣe sí àwọn ohun èlò ọlọ́wọ̀ tí ó wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù?
6 Nebukadinésárì kó àwọn nǹkan èlò ọlọ́wọ̀ nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ìkógun, ó sì “kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì sí ilé ọlọ́run rẹ̀; àwọn nǹkan èlò náà ni ó sì kó wá sí ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀,” Mádọ́kì, tàbí Méródákì ní èdè Hébérù. (Dáníẹ́lì 1:2; Jeremáyà 50:2) A ṣàwárí ìkọ̀wé kan tí ó jẹ́ ti Bábílónì, nínú rẹ̀ a fi Nebukadinésárì hàn pé ó sọ nípa tẹ́ńpìlì Mádọ́kì pé: “Mo kó fàdákà àti wúrà àti òkúta iyebíye jọ sínú rẹ̀ . . . mo sì kó ìṣúra ilé ìjọba mi síbẹ̀.” A óò kà nípa àwọn nǹkan èlò ọlọ́wọ̀ wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà ọjọ́ Bẹliṣásárì Ọba.—Dáníẹ́lì 5:1-4.
ÀWỌN TÍ Ó ṢE ṢÁMÚṢÁMÚ LÁRA ÀWỌN ÈWE JERÚSÁLẸ́MÙ
7, 8. Kí ni a lè rí fàyọ láti inú Dáníẹ́lì 1:3, 4, àti 6, nípa ipò àtilẹ̀wá Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
7 Kì í ṣe àwọn nǹkan èlò inú tẹ́ńpìlì Jèhófà nìkan ni a kó wá sí Bábílónì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Lẹ́yìn náà ni ọba sọ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ rẹ̀ láàfin pé kí ó mú àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ ọba àti ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú wá, àwọn ọmọ tí kò ní àbùkù rárá, ṣùgbọ́n tí wọ́n dára ní ìrísí, tí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye nínú ọgbọ́n gbogbo, tí wọ́n ní ìmọ̀ gan-an, tí wọ́n sì ní ìfòyemọ̀ ohun tí a mọ̀, tí wọ́n sì tún ní agbára láti dúró ní ààfin ọba.”—Dáníẹ́lì 1:3, 4.
8 Àwọn wo ni a yàn? A sọ fún wa pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Júdà wà lára wọn, Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà.” (Dáníẹ́lì 1:6) Èyí ni ó jẹ́ kí a ní òye díẹ̀ nípa ipò àtilẹ̀wá ti Dáníẹ́lì àti ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí ó fara sin. Bí àpẹẹrẹ, a ṣàkíyèsí pé wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ Júdà,” láti ìdílé ọba. Yálà wọ́n ti ìlà tí ń jọba wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé, ó kéré tán inú ìdílé sàràkí-sàràkí tí ó lẹ́nu ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti wá. Yàtọ̀ sí pé èrò-inú wọn yè kooro tí ara wọn sì dá ṣáṣá, wọ́n tún ní ìjìnlẹ̀ òye, ọgbọ́n, ìmọ̀, àti ìfòyemọ̀—gbogbo èyí sì jẹ́ nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí tí a fi lè pè wọ́n ní “ọmọ,” bóyá ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba. Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti ní láti tayọ—àwọn tí ó ṣe ṣámúṣámú—láàárín àwọn èwe Jerúsálẹ́mù.
9. Èé ṣe tí ó fi dà bí pé ó dájú pé àwọn òbí tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní?
9 Àkọsílẹ̀ náà kò sọ àwọn tí ó jẹ́ òbí àwọn ọ̀dọ́mọdé wọ̀nyí fún wa. Àmọ́, ó jọ pé ó dájú pé wọ́n jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run tí ó fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí. Lójú bí ìwà rere àti ipò tẹ̀mí ṣe díbàjẹ́ tó ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn, pàápàá láàárín ‘àwọn ọmọ ọba àti ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú,’ ó ṣe kedere pé àwọn ànímọ́ títayọ tí a rí nínú Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kì í ṣe ohun àkọsẹ̀bá. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé yóò jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn gidigidi fún àwọn òbí wọn láti rí i pé a ń kó àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ jíjìnnà réré. Ì bá ṣe pé wọ́n ti mọ àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni, ẹ̀ wo bí ì bá ṣe mórí wọn yá gágá tó! Ó mà ṣe pàtàkì o, pé kí àwọn òbí tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà”!—Éfésù 6:4.
ÌJÀKADÌ LÁTI YÍ ỌKÀN WỌN PADÀ
10. Kí ni a fi kọ́ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù wọ̀nyẹn, kí sì ni ète èyí?
10 Lójú ẹ̀sẹ̀, ìjàkadì ti yíyí ọkàn ọmọdé ti àwọn ìgbèkùn wọ̀nyí padà bẹ̀rẹ̀. Láti rí i dájú pé a sọ àwọn ọ̀dọ́langba tí ó jẹ́ Hébérù wọ̀nyí di ẹni tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan ti àwọn ará Bábílónì, Nebukadinésárì pàṣẹ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ “kọ́ wọn ní ìkọ̀wé àti ahọ́n àwọn ará Kálídíà.” (Dáníẹ́lì 1:4) Èyí kì í ṣe ẹ̀kọ́ ṣákálá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia ṣàlàyé pé ó “ní nínú, kíkọ́ èdè Sumer, Ákádíánì, Árámáíkì . . . , àti àwọn èdè yòókù, àti àwọn ìwé rẹpẹtẹ tí a kọ ní èdè wọ̀nyẹn pẹ̀lú.” Ìwé ìtàn, ìṣirò, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àpapọ̀ “àwọn ìwé rẹpẹtẹ tí a kọ ní èdè wọ̀nyẹn.” Ṣùgbọ́n, “àyọkà ọ̀rọ̀ ìsìn tí ń bá a rìn, tí ó jẹ́ ti àwọn àpẹẹrẹ abàmì àti ti ìwòràwọ̀-sọtẹ́lẹ̀ . . . , ni ó kó ipa pàtàkì níbẹ̀.”
11. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni a gbé láti rí i dájú pé a mú kí ọ̀nà ìgbésí ayé ààfin Bábílónì mọ́ àwọn èwe Hébérù náà lára?
11 Kí àwọn ìṣe òun àṣà ààfin Bábílónì lè mọ́ àwọn èwe Hébérù wọ̀nyí lára, “ọba ṣètò ohun tí a yọ̀ǹda lójoojúmọ́ fún wọn láti inú àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba àti láti inú wáìnì tí ó ń mu, àní láti fi bọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta, kí wọ́n bàa lè dúró níwájú ọba ní òpin ọdún mẹ́ta náà.” (Dáníẹ́lì 1:5) Síwájú sí i, “sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin sì fún wọn ní orúkọ. Ó sì fún Dáníẹ́lì ní orúkọ náà Bẹliteṣásárì; ó fún Hananáyà ní Ṣádírákì; ó fún Míṣáẹ́lì ní Méṣákì; ó fún Asaráyà ní Àbẹ́dinígò.” (Dáníẹ́lì 1:7) Ní àwọn àkókò Bíbélì, àṣà tí ó wọ́pọ̀ ni pé kí a fún ènìyàn lórúkọ tuntun láti fi sàmì sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ní ìgbésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà yí orúkọ Ábúrámù àti Sáráì padà sí Ábúráhámù àti Sárà. (Jẹ́nẹ́sísì 17:5, 15, 16) Kí ènìyàn kan yí orúkọ ẹlòmíràn padà jẹ́ ẹ̀rí kedere pé ó láṣẹ tàbí àkóso lórí onítọ̀hún. Nígbà tí Jósẹ́fù di alábòójútó oúnjẹ ní Íjíbítì, Fáráò sọ ọ́ ní Safenati-pánéà.—Jẹ́nẹ́sísì 41:44, 45; fi wé 2 Àwọn Ọba 23:34; 24:17.
12, 13. Kí ni ìdí tí a fi lè sọ pé yíyí tí a yí orúkọ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù náà padà jẹ́ ìsapá láti bẹ́gi dínà ìgbàgbọ́ wọn?
12 Ní ti Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó jẹ́ Hébérù, àyípadà orúkọ yìí ṣe pàtàkì. Orúkọ tí àwọn òbí wọn sọ wọ́n wà níbàámu pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà. “Dáníẹ́lì” túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ni Onídàájọ́ Mi.” Ìtumọ̀ “Hananáyà” ni “Jèhófà Ti Fojú Rere Hàn.” Ó dà bí pé “Míṣáẹ́lì” túmọ̀ sí “Ta Ní Dà Bí Ọlọ́run?” “Asaráyà” túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.” Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ìrètí àwọn òbí wọn gidigidi pé kí àwọn ọmọ wọn dàgbà lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Jèhófà Ọlọ́run láti lè di ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ àti adúróṣinṣin.
13 Ṣùgbọ́n, orúkọ tuntun tí a fún àwọn Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni a so pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́run èké tímọ́tímọ́, ní dídọ́gbọ́n tọ́ka pé àwọn ọlọ́run àjúbàfún wọnnì ti borí Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ wo irú ìsapá alárekérekè ńláǹlà láti bẹ́gi dínà ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí tí èyí jẹ́!
14. Kí ni ìtumọ̀ àwọn orúkọ tuntun tí a fún Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
14 A yí orúkọ Dáníẹ́lì padà sí Bẹliteṣásárì, tí ó túmọ̀ sí “Dáàbò Bo Ìwàláàyè Ọba.” Dájúdájú, èyí jẹ́ ìkékúrú ọ̀rọ̀ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ kan sí Bélì, tàbí Mádọ́kì, olú ọlọ́run àwọn ará Bábílónì. Bóyá Nebukadinésárì lọ́wọ́ sí orúkọ tí a fún Dáníẹ́lì yìí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó fi ṣe ohun ìyangàn nígbà tí ó sọ pé ó jẹ́ “gẹ́gẹ́ bí orúkọ ọlọ́run [òun].” (Dáníẹ́lì 4:8) Wọ́n yí orúkọ Hananáyà padà sí Ṣádírákì, tí àwọn ògbógi kan gbà gbọ́ pé ó jẹ́ orúkọ alákànpọ̀-ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “Àṣẹ Aku.” Ẹ sì wá wò ó, Aku jẹ́ orúkọ ọlọ́run kan tí ó jẹ́ ti àwọn ará Sumer. Wọ́n pa orúkọ Míṣáẹ́lì dà sí Méṣákì (bóyá, Mi·sha·aku), tí ó jọ pé ó jẹ́ dídọ́gbọ́n yí “Ta Ní Dà Bí Ọlọ́run?” padà sí “Ta Ní Jẹ́ Ohun Tí Aku Jẹ́?” Orúkọ Bábílónì tí wọ́n fún Asaráyà ni Àbẹ́dinígò, bóyá tí ó túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Négò.” “Négò” sì jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti gbà pe “Nébò,” orúkọ ọlọ́run àjúbàfún tí a tún sábà máa fi ń pe ọ̀pọ̀ alákòóso ní Bábílónì.
WỌ́N PINNU LÁTI MÁA BÁ A LỌ NÍ JÍJẸ́ OLÓÒÓTỌ́ SÍ JÈHÓFÀ
15, 16. Àwọn ewu wo ni ó wá dojú kọ Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe hùwà padà?
15 Orúkọ Bábílónì tí a fún wọn, ìtòlẹ́sẹẹsẹ fífi ẹ̀kọ́ tún wọn kọ́, àti àkànṣe oúnjẹ yẹn—gbogbo ìsapá wọ̀nyí kì í wulẹ̀ ṣe láti mú kí ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn ará Bábílónì mọ́ Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lára nìkan bí kò ṣe láti tún mú kí Jèhófà, Ọlọ́run tiwọn, àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn tí wọ́n ti gbà tẹ́lẹ̀ àti ipò àtilẹ̀wá wọn ṣàjèjì pátápátá sí wọn. Lójú gbogbo ìfi-nǹkan-rọni àti ìdẹwò tí ó dojú kọ wọ́n yìí, kí ni àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí yóò ṣe?
16 Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Dáníẹ́lì pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀ pé òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí nípasẹ̀ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba àti wáìnì tí ó ń mu.” (Dáníẹ́lì 1:8a) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáníẹ́lì nìkan ni a dárúkọ, ó hàn gbangba láti inú ohun tí ó tẹ̀ lé e pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ìpinnu rẹ̀ lẹ́yìn. Gbólóhùn náà “pinnu ní ọkàn àyà rẹ̀” fi hàn pé ìtọ́ni tí àwọn òbí Dáníẹ́lì àti àwọn mìíràn ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ fún un wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Láìsí iyèméjì, irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan náà ni ó darí àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yòókù nínú ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Ní kedere, èyí túbọ̀ fi ìníyelórí kíkọ́ àwọn ọmọ wa hàn, àní nígbà tí ó lè dà bí pé òye wọ́n ṣì kéré pàápàá.—Òwe 22:6; 2 Tímótì 3:14, 15.
17. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé oúnjẹ ojoojúmọ́ ọba nìkan ni Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kọ̀, tí wọn kò sì kọ àwọn ìṣètò yòókù?
17 Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́ Hébérù wọ̀nyí fi kọ kìkì àwọn oúnjẹ adùnyùngbà àti wáìnì ṣùgbọ́n tí wọn kò kọ àwọn ìṣètò yòókù? Àlàyé Dáníẹ́lì fi èyí hàn kedere pé: “Òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí.” Pé kí ènìyàn kọ́ “ìkọ̀wé àti ahọ́n àwọn ará Kálídíà” àti fífún tí a fúnni ní orúkọ Bábílónì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè lòdì, kò fi dandan sọni di eléèérí. Gbé àpẹẹrẹ ti Mósè, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fún un “ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” ó ṣì ń bá a lọ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ohun tí àwọn òbí rẹ̀ fi tọ́ ọ dàgbà fún un ní ìpìlẹ̀ tí ó lágbára. Nítorí náà, “nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.”—Ìṣe 7:22; Hébérù 11:24, 25.
18. Àwọn ọ̀nà wo ní ìpèsè ọba yóò gbà sọ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù náà di eléèérí?
18 Lọ́nà wo ni àwọn ìpèsè ọba Bábílónì yóò gbà sọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyẹn dìbàjẹ́? Àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn oúnjẹ tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ wà nínú àwọn oúnjẹ adùnyùngbà náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Bábílónì máa ń jẹ àwọn ẹran àìmọ́, tí a fi Òfin kà léèwọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Léfítíkù 11:1-31; 20:24-26; Diutarónómì 14:3-20) Ìkejì, àwọn ará Bábílónì kì í sábà ro ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n bá pa dànù kí wọ́n tó jẹran rẹ̀. Jíjẹ ẹran tí a kò ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dànù yóò jẹ́ rírú òfin Jèhófà nípa ẹ̀jẹ̀ ní tààràtà. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1, 3, 4; Léfítíkù 17:10-12; Diutarónómì 12:23-25) Ìkẹta, àwọn olùjọsìn àwọn ọlọ́run èké sábà máa ń fi oúnjẹ wọn rúbọ sí òrìṣà kí wọ́n tó jìjọ jẹ ẹ́ pa pọ̀. Ìránṣẹ́ Jèhófà kò jẹ́ gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀! (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 10:20-22.) Paríparí rẹ̀, ó ṣòro kí fífi oúnjẹ aládùn mìnrìngìndìn àti ọtí líle kẹ́ra lójoojúmọ́ tó lè jẹ́ ohun tí ó dára fún ènìyàn, ọjọ́ orí yòówù kí ó jẹ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọmọdé.
19. Àwọn àwáwí wo ni àwọn èwe Hébérù náà ì bá ti ṣe, ṣùgbọ́n kí ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dórí ìpinnu tí ó tọ́?
19 Ọ̀tọ̀ ni kí a mọ ohun tí ó yẹ kí a ṣe, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ pátápátá ni kí a ní ìgboyà láti ṣe é nígbà tí a bá dojú kọ ìfi-nǹkan-rọni tàbí ìdẹwò. Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ì bá kàn rò ó pé níwọ̀n bí àwọn òbí àti ọ̀rẹ́ wọn ti wà lọ́nà jíjìn sí wọn, àwọn wọ̀nyẹn kò ní mọ ohun tí àwọn ṣe. Wọ́n tún lè wá àwáwí pé àṣẹ ọba ni, àti pé ó dà bí pé kò sí ọ̀nà mìíràn mọ́. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó dájú pé ṣe ni àwọn èwe yòókù yọ̀ mọ́ irú àwọn ìṣètò wọ̀nyẹn, wọ́n sì ka kíkópa nínú rẹ̀ sí àǹfààní dípò kíkà á sí ìnira. Ṣùgbọ́n ìrú ìrònú tí ó kù díẹ̀ káàtó bẹ́ẹ̀ lè fìrọ̀rùn súnni dẹ́ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀, tí ó jẹ́ ìdẹkùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́. Àwọn èwe Hébérù wọ̀nyí mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo” àti pé “Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” (Òwe 15:3; Oníwàásù 12:14) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ọ̀nà ìgbà hùwà àwọn ọ̀dọ́ olùṣòtítọ́ wọ̀nyí.
ÌGBOYÀ ÀTI ÌTẸPẸLẸMỌ́-NǸKAN MÚ ÈRÈ WÁ
20, 21. Ìgbésẹ̀ wo ni Dáníẹ́lì gbé, pẹ̀lú àbájáde wo sì ni?
20 Níwọ̀n bí Dáníẹ́lì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti dènà àwọn ohun tí ń sọni di eléèérí, ó tẹ̀ síwájú láti gbé ìgbésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìpinnu rẹ̀. “Ó . . . ń béèrè lọ́dọ̀ sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin, kí òun má bàa sọ ara òun di eléèérí.” (Dáníẹ́lì 1:8b) “Ó . . . ń béèrè”—ìyẹn jẹ́ gbólóhùn tí ó gbàfiyèsí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń béèrè kí a tẹpẹlẹ mọ́ ìsapá wa bí a óò bá retí láti ṣàṣeyọrí nínú gbígbéjàko àwọn ìdẹwò tàbí láti ṣẹ́pá àwọn àìlera kan.—Gálátíà 6:9.
21 Nínú ọ̀ràn ti Dáníẹ́lì, ìtẹpẹlẹmọ́-nǹkan mú èrè wá. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run tòótọ́ fi Dáníẹ́lì fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú níwájú sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin náà.” (Dáníẹ́lì 1:9) Kì í ṣe nítorí pé Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọmọlúwàbí àti onílàákàyè ni àwọn nǹkan fi yọrí sí rere fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbùkún Jèhófà ni. Ó dájú pé Dáníẹ́lì rántí òwe Hébérù náà pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yẹn mú èrè wá ní tòótọ́.
22. Àtakò tí ó tọ́ wo ni òṣìṣẹ́ láàfin náà gbé dìde?
22 Lákọ̀ọ́kọ́, sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin takò ó, ó sọ pé: “Mo bẹ̀rù olúwa mi ọba, ẹni tí ó ti ṣètò oúnjẹ yín àti ohun mímu yín. Kí wá ni ìdí tí yóò fi rí i pé ojú yín rẹ̀wẹ̀sì ní ìfiwéra pẹ̀lú ti àwọn ọmọ tí ẹ jọ jẹ́ ọjọ́ orí kan náà, èé sì ti ṣe tí ẹ óò fi sọ orí mi di ẹlẹ́bi lọ́dọ̀ ọba?” (Dáníẹ́lì 1:10) Wọ́n jẹ́ àtakò àti ìbẹ̀rù tí ó tọ́. Nebukadinésárì Ọba ṣòroó kọ ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu, sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin sì mọ̀ pé “orí” òun yóò wà nínú ewu bí òun bá ṣe lòdì sí àwọn ìtọ́ni ọba. Kí ni Dáníẹ́lì yóò ṣe?
23. Nípa ọ̀nà tí Dáníẹ́lì gbà hùwà, báwo ni ó ṣe fi ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n hàn?
23 Ibi tí òye inú àti ọgbọ́n ti wọnú ọ̀rọ̀ náà nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì ọ̀dọ́ rántí òwe náà pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Dípò tí Dáníẹ́lì ì bá fi ranrí pé dandan ni kí wọ́n ṣe ohun tí òun béèrè, bóyá kí ó tilẹ̀ sún àwọn mìíràn débi tí wọn yóò fi pa á bí ajẹ́rìíkú, ó fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ní àkókò tí ó tọ́, ó tọ “olùtọ́jú” lọ, ẹni tí ó dà bí pé ó túbọ̀ fẹ́ láti fún wọn ní ìyọ̀ǹda díẹ̀ nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ gan-an kọ́ ni ọba ti máa béèrè.—Dáníẹ́lì 1:11.
A DÁMỌ̀RÀN ÌDÁNWÒ ỌJỌ́ MẸ́WÀÁ
24. Ìdánwò wo ni Dáníẹ́lì dámọ̀ràn?
24 Dáníẹ́lì dámọ̀ràn ìdánwò kan fún olùtọ́jú náà, pé: “Jọ̀wọ́, dán àwọn ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, sì jẹ́ kí wọ́n fún wa ní àwọn ọ̀gbìn oko láti jẹ àti omi láti mu; sì jẹ́ kí ojú àwa àti ojú àwọn ọmọ tí wọ́n ń jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba fara hàn níwájú rẹ, kí o sì ṣe sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o bá rí.”—Dáníẹ́lì 1:12, 13.
25. Kí ni ó ṣeé ṣe kí ó wà nínú “ọ̀gbìn oko” tí a pèsè fún Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
25 Kí oúnjẹ wọn jẹ́ ‘ọ̀gbìn oko àti omi’ fún ọjọ́ mẹ́wàá—“ojú” wọn yóò ha “rẹ̀wẹ̀sì” ní ìfiwéra pẹ̀lú ti àwọn yòókù bí? Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí ó pilẹ̀ túmọ̀ sí “èso” ni a túmọ̀ sí “ọ̀gbìn oko.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan pè é ní “pulse” (ẹ̀wà), tí a sọ pé ó jẹ́ “èso wooro jíjẹ tí ó jẹ́ ti ohun ọ̀gbìn irú erèé lónírúurú (bí pòpòǹdó, erèé, tàbí ẹ̀wà lẹ́ńtìlì).” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan rò pé àyíká ọ̀rọ̀ náà tọ́ka pé oúnjẹ náà ju kìkì èso wooro jíjẹ. Ìwé atọ́ka kan sọ pé: “Ohun tí Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ń béèrè ni oúnjẹ ọ̀gbìn oko lónírúurú tí àwọn ènìyàn ń jẹ ní gbogbo gbòò dípò oúnjẹ ọba dídọ́ṣọ̀, tí ó kún fún ẹran.” Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀gbìn oko lè ní nínú àwọn oúnjẹ aṣaralóore tí a fi erèé, apálá, aáyù, ewébẹ̀ líìkì, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ẹ̀gúsí, àti àlùbọ́sà àti búrẹ́dì tí a bá fi onírúurú ọkà ṣe. Dájúdájú kò sí ẹni tí yóò ka ìyẹn sí oúnjẹ afebipani. Ó jọ pé olùtọ́jú náà lóye kókó yìí. “Níkẹyìn, ó fetí sí wọn lórí ọ̀ràn yìí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.” (Dáníẹ́lì 1:14) Kí ni àbájáde rẹ̀?
26. Kí ni àbájáde ìdánwò ọjọ́ mẹ́wàá náà, kí sì ni ìdí tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀?
26 “Ní òpin ọjọ́ mẹ́wàá, ojú wọn sì fara hàn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára sí i, tí wọ́n sì sanra sí i ní ẹran ara ju gbogbo àwọn ọmọ tí ń jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.” (Dáníẹ́lì 1:15) Èyí kì í ṣe ẹ̀rí pé oúnjẹ àwọn ajẹhun-ọ̀gbìn-nìkan dára ju oúnjẹ tí ó dọ́ṣọ̀, tí ó kún fún ẹran lọ. Ọjọ́ mẹ́wàá ti kúrú jù fún irú ààtò oúnjẹ èyíkéyìí láti lè mú àbájáde tí ó ṣe gúnmọ́ kan jáde, ṣùgbọ́n kò kúrú jù fún Jèhófà láti ṣàṣeparí ète rẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, kò sì fi wọ́n sílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Jésù Kristi wà fún ogójì ọjọ́ láìjẹun. Nípa ti èyí, ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Diutarónómì 8:3, tí ó kà pé: “Ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” Ní ti èyí, ìrírí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ kan.
ÌJÌNLẸ̀ ÒYE ÀTI ỌGBỌ́N DÍPÒ ÀWỌN OÚNJẸ ADÙNYÙNGBÀ ÀTI WÁÌNÌ
27, 28. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìṣètò oúnjẹ tí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ara wọn fún fi jẹ́ ọ̀nà láti gbà múra wọn sílẹ̀ de ohun ńlá tí ń bọ̀ níwájú?
27 Ọjọ́ mẹ́wàá náà wulẹ̀ jẹ́ fún ìdánwò, ṣùgbọ́n àwọn àbájáde rẹ̀ yíni lérò padà gan-an ni. “Nítorí náà, olùtọ́jú náà ń bá a nìṣó láti kó àwọn oúnjẹ adùnyùngbà àti wáìnì mímu tiwọn lọ, ó sì ń fún wọn ní ọ̀gbìn oko.” (Dáníẹ́lì 1:16) Kò ṣóro fúnni láti finú wòye ohun tí àwọn èwe yòókù tí wọ́n jọ ń fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan náà máa rò nípa Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni kíkọ̀ tí wọ́n kọ àsè ọba sílẹ̀ tí wọ́n sì lọ ń jẹ ọ̀gbìn oko lójoojúmọ́ máa jẹ́ lójú tiwọn. Ṣùgbọ́n ìdánwò àti àdánwò ńláǹlà ló fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán yìí, èyí yóò sì béèrè pé kí àwọn ọ̀dọ́ Hébérù náà lo gbogbo ìwàlójúfò àti ọgbọ́n inú wọn dé góńgó. Paríparí rẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà ni yóò mú kí wọ́n la àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn já.—Fi wé Jóṣúà 1:7.
28 Ẹ̀rí pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ni a lè rí nínú ohun tí a sọ tẹ̀ lé e pé: “Ní ti àwọn ọmọ wọ̀nyí, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Ọlọ́run tòótọ́ fún wọn ní ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye nínú gbogbo ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; Dáníẹ́lì alára sì ní òye nínú gbogbo onírúurú ìran àti àlá.” (Dáníẹ́lì 1:17) Láti lè kojú hílàhílo tí ń bọ̀ wá bá wọn, ohun tí wọ́n nílò ju agbára ara-ìyára àti ìlera dídára lọ. “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú.” (Òwe 2:10-12) Ohun tí Jèhófà sì fún àwọn èwe olùṣòtítọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà gẹ́lẹ́ nìyẹn láti múra wọn sílẹ̀ de ohun tí ń bẹ níwájú.
29. Kí ní jẹ́ kí Dáníẹ́lì lè ‘ní òye gbogbo onírúurú ìran àti àlá’?
29 A sọ ọ́ pé Dáníẹ́lì “ní òye nínú gbogbo onírúurú ìran àti àlá.” Èyí kì í ṣe ní òye ti pé ó ti di arínúróde. Ó gbàfiyèsí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka Dáníẹ́lì sí ọ̀kan lára àwọn wòlíì Hébérù ńláńlá, a kò mí sí i rárá láti sọ ìpolongo bí “èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,” tàbí “èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Aísáyà 28:16; Jeremáyà 6:9) Síbẹ̀, lábẹ́ ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run nìkan ni Dáníẹ́lì ti lè lóye àwọn ìran àti àlá tí ń ṣí àwọn ète Jèhófà payá kí ó sì sọ ìtumọ̀ wọn.
ÌDÁNWÒ ṢÍṢE KÓKÓ DÉ NÍKẸYÌN
30, 31. Báwo ni ọ̀nà tí Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ yàn ṣe ṣàǹfààní fún wọn?
30 Ọdún mẹ́ta ti títúnni kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ àti mímúra ẹni sílẹ̀ náà parí. Ìdánwò ṣíṣe kókó dé wàyí—ọba fẹ́ fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. “Ní òpin àwọn ọjọ́ tí ọba sọ pé kí a mú wọn wá, sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin pẹ̀lú tẹ̀ síwájú láti mú wọn wá síwájú Nebukadinésárì.” (Dáníẹ́lì 1:18) Àkókò dé tí àwọn èwe mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà yóò fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn. Rírọ̀ mọ́ òfin Jèhófà dípò kíkó wọnú ọ̀nà àwọn ará Bábílónì yóò ha ṣàǹfààní fún wọn bí?
31 “Ọba . . . bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀, nínú gbogbo wọn, a kò rí ọ̀kankan bí Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà; wọ́n sì ń bá a lọ láti dúró níwájú ọba.” (Dáníẹ́lì 1:19) Ẹ wo bí èyí ṣe dá ìgbésẹ̀ wọn láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn láre pátápátá! Kì í ṣe ìwà aṣiwèrè ni wọ́n hù rárá nígbà tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìlànà oúnjẹ tí ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn wọn yàn. Nípa jíjẹ́ tí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó lè dà bí pé ó kéré jọjọ, a fi àwọn ohun tí ó tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ bù kún wọn. Ohun tí gbogbo ọ̀dọ́ tí ń bẹ nínú ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ń lépa ni pé kí àwọn ní àǹfààní “láti dúró níwájú ọba.” Bóyá kìkì àwọn èwe Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà nìkan ni a yàn ni o, Bíbélì kò sọ. Àmọ́ ṣá, ọ̀nà ìṣòtítọ́ tí wọ́n tọ̀ mú “èrè ńlá” wá fún wọn.—Sáàmù 19:11.
32. Kí ni ìdí tí a fi lè sọ pé Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà ní àǹfààní kan tí ó ga ju wíwà nínú ààfin ọba lọ?
32 Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí.” (Òwe 22:29) Bí Nebukadinésárì ṣe yan Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà nìyẹn láti máa dúró níwájú ọba, ìyẹn ni pé, kí wọ́n di ara ìgbìmọ̀ ààfin. Nínú gbogbo èyí, a lè rí i pé ọwọ́ Jèhófà ní ń darí àwọn ọ̀ràn náà kí a lè tipasẹ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí—ní pàtàkì nípasẹ̀ Dáníẹ́lì—sọ àwọn apá pàtàkì nínú ète Ọlọ́run di mímọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlá ni ó jẹ́ pé kí a yan ẹnì kan láti di ara ìgbìmọ̀ ààfin Nebukadinésárì, ọlá tí ó túbọ̀ ga ju bẹ́ẹ̀ lọ ni ó jẹ́ pé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, ń lò wọ́n ní irú ọ̀nà àgbàyanu kan bẹ́ẹ̀.
33, 34. (a) Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́ Hébérù wọ̀nyẹn fi wú ọba lórí? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú ìrírí àwọn Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin?
33 Kò pẹ́ tí Nebukadinésárì fi ṣàwárí pé ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye tí Jèhófà fi fún àwọn èwe Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tayọ ré kọjá èyí tí gbogbo agbaninímọ̀ràn àti ọlọ́gbọ́n ààfin rẹ̀ ní. “Ní ti gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba wádìí lọ́wọ́ wọn, ó tilẹ̀ rí i pé wọ́n fi ìlọ́po mẹ́wàá sàn ju gbogbo àwọn àlùfáà pidánpidán àti alálùpàyídà tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 1:20) Kò ṣe ní rí bẹ́ẹ̀? Ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lásánlàsàn ti àwọn ará Bábílónì ni “àwọn àlùfáà pidánpidán” àti “àwọn alálùpàyídà” gbára lé, nígbà tí ó jẹ́ pé ọgbọ́n tí ó wá láti òkè ni Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé. Kò wulẹ̀ ṣeé fi wéra rárá ni—kò sí pé a ń díje rẹ̀ rárá!
34 Nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ látọdúnmọ́dún wá. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, nígbà tí ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ti àwọn Gíríìkì àti òfin Róòmù gbòde, a mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àlùmọ̀kọ́rọ́yí àwọn fúnra wọn.’ Àti pẹ̀lú: ‘Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.’ Nítorí bẹ́ẹ̀, kí ẹnì kankan má ṣe máa ṣògo nínú ènìyàn.” (1 Kọ́ríńtì 3:19-21) Lónìí, ó ń béèrè pé kí a rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ohun tí Jèhófà fi kọ́ wa, kí a má jẹ́ kí ayé jíjẹ àti afẹfẹyẹ̀yẹ̀ inú ayé, tí kìí tọ́jọ́, tètè ṣì wá lọ́nà.—1 Jòhánù 2:15-17.
WỌ́N JẸ́ OLÙṢÒTÍTỌ́ DÓPIN
35. Báwo ni ìsọfúnni tí a fún wa nípa àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe pọ̀ tó?
35 A ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àpèjúwe nípa ìgbàgbọ́ alágbára tí Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà ní nínú Dáníẹ́lì orí kẹta, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ère wúrà Nebukadinésárì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà àti ìdánwò iná ìléru. Láìsí àní-àní, àwọn Hébérù olùbẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyí jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà títí di ìgbà ikú wọn. A mọ èyí nítorí pé, ó dájú pé àwọn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń dọ́gbọ́n tọ́ka sí nígbà tí ó kọ̀wé nípa “àwọn tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ . . . wọ́n dá ipá iná dúró.” (Hébérù 11:33, 34) Wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, lọ́mọdé lágbà.
36. Iṣẹ́ ìgbésí ayé tí ó tayọ wo ni Dáníẹ́lì ṣe?
36 Ní ti Dáníẹ́lì 1:21, ẹsẹ tí ó gbẹ̀yìn ní orí kìíní sọ pé: “Dáníẹ́lì sì ń bá a lọ títí di ọdún àkọ́kọ́ Kírúsì Ọba.” Ìtàn fi hàn pé òru ọjọ́ kan ni Kírúsì fi ṣẹ́gun Bábílónì, ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ẹ̀rí fi hàn pé nítorí orúkọ rere àti ipò Dáníẹ́lì, ó ń bá a lọ láti sìn nínú ìgbìmọ̀ ààfin Kírúsì. Ní tòótọ́, Dáníẹ́lì 10:1 sọ fún wa pé “ní ọdún kẹta Kírúsì, ọba Páṣíà,” Jèhófà ṣí ọ̀ràn pàtàkì kan payá fún Dáníẹ́lì. Bí ó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́langba ni ó jẹ́ nígbà tí a mú un wá sí Bábílónì ní ọdún 617 ṣááju Sànmánì Tiwa, yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn ún ọdún nígbà tí ó gba ìran ìkẹyìn. Ẹ wo bí ìgbà tí ó lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe gùn tó àti bí a ṣe bù kún un tó!
37. Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú àgbéyẹ̀wò tí a ṣe nínú Dáníẹ́lì orí kìíní?
37 Ohun tí orí àkọ́kọ́ ìwé Dáníẹ́lì sọ fún wa ju ìtàn bí àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin ṣe kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí lọ. Ó fi bí Jèhófà ṣe lè lo ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti ṣàṣeparí ète rẹ̀ hàn wá. Àkọsílẹ̀ náà fi ẹ̀rí hàn pé bí Jèhófà bá ti fàyè gba nǹkan kan, bí ó tilẹ̀ dà bí àjálù ibi, ó lè ṣiṣẹ́ fún ète rere kan. Ó sì sọ fún wa pé jíjẹ́ olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun kéékèèké máa ń mú èrè ńlá wá.
KÍ LO LÓYE?
• Kí ni a lè sọ nípa ipò àtilẹ̀wá Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́?
• Báwo ni a ṣe dán ọ̀nà dídára tí a gbà tọ́ àwọn èwe Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà wò ní Bábílónì?
• Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún àwọn Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nítorí ìdúró onígboyà tí wọ́n mú?
• Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní lè kọ́ láti ọ̀dọ̀ Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]