Dáníẹ́lì
1 Ní ọdún kẹta àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàgọ́ tì í.+ 2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+
3 Ọba wá pàṣẹ fún Áṣípénásì olórí òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pé kó mú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wá, títí kan àwọn ọmọ ọba àti ọmọ àwọn èèyàn pàtàkì.+ 4 Kí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́* tí kò ní àbùkù kankan, tí ìrísí wọn dáa, tí wọ́n ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye,+ tí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba. Kí ó kọ́ wọn ní èdè àwọn ará Kálídíà àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé. 5 Bákan náà, ọba ní kí wọ́n máa fún wọn ní oúnjẹ lójoojúmọ́, lára oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ àti lára wáìnì tó ń mu. Wọ́n máa fi ọdún mẹ́ta dá wọn lẹ́kọ̀ọ́,* tí ọdún náà bá sì ti pé, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọba ṣiṣẹ́.
6 Àwọn kan wà lára wọn tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà* Júdà: Dáníẹ́lì,*+ Hananáyà,* Míṣáẹ́lì* àti Asaráyà.*+ 7 Àgbà òṣìṣẹ́ láàfin sì fún wọn ní orúkọ;* ó pe Dáníẹ́lì ní Bẹtiṣásárì,+ ó pe Hananáyà ní Ṣádírákì, ó pe Míṣáẹ́lì ní Méṣákì, ó sì pe Asaráyà ní Àbẹ́dínígò.+
8 Àmọ́ Dáníẹ́lì pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé òun ò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ àti wáìnì tó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Torí náà, ó ní kí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin gba òun láyè kí òun má bàa fi àwọn nǹkan yìí sọ ara òun di aláìmọ́. 9 Ọlọ́run tòótọ́ sì mú kí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin fi ojúure* àti àánú hàn sí Dáníẹ́lì.+ 10 Àmọ́ àgbà òṣìṣẹ́ láàfin sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ẹ̀rù olúwa mi ọba ń bà mí, ẹni tó ti ṣètò jíjẹ àti mímu yín. Tó bá wá rí i pé ìrísí yín burú ju ti àwọn ọ̀dọ́* yòókù tí ẹ jọ jẹ́ ojúgbà ńkọ́? Ẹ máa jẹ́ kí ọba dá mi* lẹ́bi.” 11 Àmọ́ Dáníẹ́lì sọ fún ẹni tí àgbà òṣìṣẹ́ láàfin yàn láti máa tọ́jú Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà pé: 12 “Jọ̀ọ́, fi ọjọ́ mẹ́wàá dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò, kí o máa fún wa ní nǹkan ọ̀gbìn jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi mu; 13 kí o wá fi ìrísí wa wé ti àwọn ọ̀dọ́* tó ń jẹ oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, lẹ́yìn náà, bí o bá ṣe rí àwa ìránṣẹ́ rẹ sí ni kí o ṣe sí wa.”
14 Ó wá gba ohun tí wọ́n sọ, ó sì fi ọjọ́ mẹ́wàá dán wọn wò. 15 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ìrísí wọn dáa, ara wọn sì le* ju ti gbogbo àwọn ọ̀dọ́* tó ń jẹ oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ. 16 Torí náà, ẹni tó ń tọ́jú wọn máa ń gbé oúnjẹ aládùn wọn àti wáìnì wọn kúrò, ó sì máa ń fún wọn ní nǹkan ọ̀gbìn. 17 Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọ̀dọ́* mẹ́rin yìí ní ìmọ̀ àti òye nínú oríṣiríṣi ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; ó sì fún Dáníẹ́lì ní òye láti túmọ̀ onírúurú ìran àti àlá.+
18 Nígbà tó tó àkókò tí ọba sọ pé kí wọ́n kó wọn wá,+ àgbà òṣìṣẹ́ láàfin kó wọn wá síwájú Nebukadinésárì. 19 Nígbà tí ọba bá wọn sọ̀rọ̀, kò sí ìkankan nínú wọn tó dà bíi Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà;+ wọ́n sì ń bá ọba ṣiṣẹ́. 20 Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba bi wọ́n, tó gba ọgbọ́n àti òye, ó rí i pé wọ́n fi ìlọ́po mẹ́wàá dáa ju gbogbo àwọn àlùfáà onídán àti àwọn pidánpidán+ tó wà ní gbogbo ibi tó jọba lé lórí. 21 Dáníẹ́lì sì wà níbẹ̀ títí di ọdún àkọ́kọ́ Ọba Kírúsì.+