ORÍ 3
‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run
1-3. (a) Sọ ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí àti ohun tó gbọ́. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Agbára wo ló mú kí Ìsíkíẹ́lì rí àwọn nǹkan yìí, ipa wo ló sì ní lórí rẹ̀?
ÌSÍKÍẸ́LÌ tẹjú mọ́ ọ̀ọ́kán, ó ń wo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú tí iyanrìn sì pọ̀ níbẹ̀. Ó kọ́kọ́ ṣe bíi pé ó fẹ́ pa ojú dé, àmọ́ ó wá lajú rekete. Ohun tó ń rí yà á lẹ́nu gan-an. Ó rí i tí ìjì líle ń kóra jọ. Àmọ́, kì í ṣe ìjì lásán. Bí atẹ́gùn líle tó ń fẹ́ wá láti àríwá ṣe ń fẹ́ irun àti aṣọ rẹ̀, ó rí ìkùukùu tó ṣú bolẹ̀ gan-an. Iná tó ń kọ mọ̀nà ń tan ìmọ́lẹ̀ nínú ìkùukùu náà, bó sì ṣe ń kọ mànà yẹn rán Ìsíkíẹ́lì létí bí àyọ́pọ̀ irin tó jẹ́ iyebíye ṣe máa ń rí.a Bí ìkùukùu náà ṣe ń rọ́ wá sọ́dọ̀ Ìsíkíẹ́lì, ó ń gbọ́ ohùn kan tó túbọ̀ ń ròkè, ohùn náà rinlẹ̀ bíi ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n ń kọjá lọ.—Ìsík. 1:4, 24.
2 Ọ̀dọ́kùnrin yìí ò ju ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún lọ nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ohun mánigbàgbé yìí. Ó rí “ọwọ́ Jèhófà” lára rẹ̀, agbára ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó kàmàmà. Ohun àgbàyanu ni ẹ̀mí yìí máa mú kó rí, tó sì máa gbọ́, ó máa jọni lójú gan-an, ó máa ju gbogbo àrà oríṣiríṣi tí wọ́n lè dá nínú àwọn fíìmù ìgbàlódé lọ. Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí máa mú kó dojú bolẹ̀, ẹnu sì máa yà á gidigidi.—Ìsík. 1:3, 28.
3 Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn fẹ́ fi ìran yìí dẹ́rù ba Ìsíkíẹ́lì. Bíi tàwọn ìran yòókù tó wà nínú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá yìí, ìran àkọ́kọ́ tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí ní ìtumọ̀ tó pọ̀ gan-an fún Ìsíkíẹ́lì fúnra rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí àti ohun tó gbọ́.
Bí Nǹkan Ṣe Rí Nígbà Yẹn
4, 5. Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran?
4 Ka Ìsíkíẹ́lì 1:1-3. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn. Ọdún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni lọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣẹlẹ̀. Bá a ṣe rí i ní orí tó ṣáájú, ìlú Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì wà nígbà yẹn, òun àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn ń gbé ní ìlú kan nítòsí odò Kébárì. Ẹ̀rí fi hàn pé ipa odò táwọn èèyàn gbẹ́ ni, ó ṣàn jáde látara odò Yúfírétì, ó sì ṣàn pa dà sínú odò náà.
5 Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti kó àwọn èèyàn náà lọ sígbèkùn, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) kìlómítà ló fi jìnnà sí Bábílónì.b Ìwà ìbàjẹ́ àti ìbọ̀rìṣà ló kún inú tẹ́ńpìlì tí bàbá Ìsíkíẹ́lì ti ṣiṣẹ́ àlùfáà. Ìtẹ́ ọba tó wà ní Jerúsálẹ́mù, èyí tí Dáfídì àti Sólómọ́nì lò nígbà tí wọ́n ń ṣàkóso nínú ọlá ńlá ti wá di ohun tó ń kó ìtìjú báni. Ọba Jèhóákínì tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run náà wà ní Bábílónì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn. Ọba burúkú ni Sedekáyà tó rọ́pò rẹ̀, àwọn míì ló sì ń darí rẹ̀.—2 Ọba 24:8-12, 17, 19.
6, 7. Kí nìdí tí Ìsíkíẹ́lì fi lè máa rò pé àsìkò tóun gbé yẹn ni àsìkò tí nǹkan le jù lọ?
6 Lójú ẹni tó nígbàgbọ́ bí Ìsíkíẹ́lì, àsìkò yìí ló máa fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àsìkò tí nǹkan le jù lọ. Àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn ti lè máa ronú pé: ‘Àbí Jèhófà ti fi wá sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé àwọn ará Bábílónì máa gbá ìjọsìn mímọ́ Jèhófà wọlẹ̀ ni? Àwọn tí wọ́n ń fi agbára wọn ṣìkà, táwọn òrìṣà wọn ò sì lóǹkà, ṣé wọ́n á wá fòpin sí àkóso Jèhófà láyé ni?’
7 Pẹ̀lú ohun tá a kà sílẹ̀ yìí, o ò ṣe kúkú ka ìràn àkọ́kọ́ tó ṣe kedere tí Ìsíkíẹ́lì rí, kó o fi bẹ̀rẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ lórí kókó yìí? (Ìsík. 1:4-28) Bó o ṣe ń kà á, máa fi ara rẹ sípò Ìsíkíẹ́lì, kó o máa wò ó bíi pé ò ń rí ohun tó rí àti pé ò ń gbọ́ ohun tó gbọ́.
Kẹ̀kẹ́ Tí Kò Láfiwé
8. Kí lohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, kí lohun náà sì ṣàpẹẹrẹ?
8 Tá a bá mú un lódindi, kí lohun tí Ìsíkíẹ́lì rí gan-an? Ohun tó rí dà bí ọkọ̀ gìrìwò kan tó ń bani lẹ́rù, èyí tá a mọ̀ sí kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ ńlá mẹ́rin, àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwọn áńgẹ́lì yìí la wá mọ̀ sí àwọn kérúbù. (Ìsík. 10:1) Ohun kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ bíi pèpéle tàbí òfúrufú wà lórí wọn, ó dà bíi yìnyín, orí rẹ̀ ni ìtẹ́ ògo Ọlọ́run wà níbi tí Jèhófà fúnra rẹ̀ gúnwà sí! Kí ni kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ṣàpẹẹrẹ? Ohun kan ṣoṣo ni ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣàpẹẹrẹ: ìyẹn sì ni apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Wo ohun mẹ́ta tó mú ká sọ bẹ́ẹ̀.
9. Báwo ni àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn tó dá sọ́run ṣe dà bíi wíwa ọkọ̀?
9 Àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn tó dá sọ́run. Kíyè sí i pé nínú ìran yìí, òkè àwọn kérúbù ni ìtẹ́ Jèhófà wà. Láwọn apá ibòmíì nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàpèjúwe Jèhófà pé ó gúnwà sórí àwọn kérúbù tàbí pé ó wà láàárín àwọn kérúbù rẹ̀. (Ka 2 Àwọn Ọba 19:15; Ẹ́kís. 25:22; Sm. 80:1) Kì í ṣe pé ó jókòó sórí àwọn kérúbù rẹ̀ ní tààràtà, bíi pé ó nílò kí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí máa gbé e kiri, bẹ́ẹ̀ ni kò nílò kó máa gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Àmọ́ àwọn kérúbù náà gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ, ó sì lè rán wọn lọ síbikíbi láyé àtọ̀run láti lọ jíṣẹ́ èyíkéyìí tó bá rán wọn. Bíi tàwọn áńgẹ́lì mímọ́ yòókù, òjíṣẹ́ tàbí aṣojú Ọlọ́run làwọn kérúbù, wọ́n sì máa ń ṣe ohun tí Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe. (Sm. 104:4) Lọ́nà yẹn, ó dà bí ìgbà tí Jèhófà ń “wà” wọ́n, bó ṣe ń fi àṣẹ rẹ̀ tí kò láàlà darí wọn bíi pé wọ́n jẹ́ ọkọ̀ gìrìwò kan tó so kọ́ra.
10. Kí ló fi hàn pé ohun tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run náà ń ṣàpẹẹrẹ ju àwọn kérúbù mẹ́rin yẹn lọ?
10 Ohun tí kẹ̀kẹ́ náà ń ṣàpẹẹrẹ ju àwọn kérúbù yẹn lọ. Kérúbù mẹ́rin ni Ìsíkíẹ́lì rí. Bíbélì sábà máa ń lo nọ́ńbà yìí fún ohun tó dọ́gba tó sì pé pérépéré, tí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Torí náà, àwọn kérúbù mẹ́rin tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣojú fún gbogbo ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí adúróṣinṣin láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Tún kíyè sí pé àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ àtàwọn kérúbù náà ní ojú káàkiri, èyí sì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ ju àwọn mẹ́rin yìí lọ ló wà lójúfò, tí wọ́n sì ń ríran rekete. Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe kẹ̀kẹ́ náà fi hàn pé kẹ̀kẹ́ náà rí gìrìwò, èyí sì mú kó dà bíi pé àwọn kérúbù alágbára náà kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ìsík. 1:18, 22; 10:12) Bákan náà, apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà gbòòrò gan-an, àwọn tó wà níbẹ̀ sì pọ̀ ju àwọn kérúbù mẹ́rin yẹn lọ fíìfíì.
11. Ìran wo ni Dáníẹ́lì rí tó jọra pẹ̀lú ti Ìsíkíẹ́lì? Kí sì ni èyí mú ká parí èrò sí?
11 Dáníẹ́lì rí irú ìran kan náà nípa ọ̀run. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Dáníẹ́lì náà fi wà nígbèkùn ní Bábílónì, òun náà sì rí ìran nípa ọ̀run. Ó gbàfiyèsí pé, nínú ìran yẹn náà, ìtẹ́ Jèhófà ní àwọn àgbá kẹ̀kẹ́. Ìran tí Dáníẹ́lì rí dá lórí bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà nínú ìdílé Jèhófà ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ ní ọ̀run. Dáníẹ́lì rí ‘ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá’ àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n dúró síwájú Jèhófà. Wọ́n jókòó bíi Kọ́ọ̀tù ní ọ̀run, kálukú wà níbi tá a yàn án sí. (Dán. 7:9, 10, 13-18) Ẹ ò rí i pé, ó bọ́gbọ́n mu pé ká parí èrò sí pé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí àti ìran nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí tí wọ́n kóra jọ lọ́nà tó gbayì dúró fún ohun kan náà!
12. Kí nìdí tó fi máa ṣe wá láǹfààní tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, irú bí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run?
12 Jèhófà mọ̀ pé ó máa ṣe àwa èèyàn láǹfààní tá a bá ń fọkàn sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn ohun tí a kò rí.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Torí pé a jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara, “àwọn ohun tí à ń rí” la sábà máa ń ronú lé lórí jù, ìyẹn àwọn nǹkan tara tó ń jẹ wá lọ́kàn, tó sì máa ń wà fúngbà díẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:18.) Ìyẹn ni Sátánì sábà máa ń lò láti fi mú wa, ká lè máa ronú nípa nǹkan tara ṣáá. Kí Sátánì má bàa rí wa mú, Jèhófà máa ń fìfẹ́ fún wa ní àwọn ìránnilétí tó bọ́ sákòókò látinú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀kan lára ẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká rí bí ìdílé Jèhófà ní ọ̀run ṣe gbayì tó!
“Ẹ Gbéra, Ẹ̀yin Àgbá Kẹ̀kẹ́!”
13, 14. (a) Báwo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tó rí? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà ní àwọn àgbá kẹ̀kẹ́?
13 Àwọn kérúbù mẹ́rin ni Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní Orí 4 nínú ìwé yìí, a máa rí ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nípa Jèhófà lára àwọn ẹ̀dá alààyè yìí àti ìrísí wọn tó gbàfiyèsí. Àmọ́, Ìsíkíẹ́lì kíyè sí i pé àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ lọ́nà mẹ́rin, wọ́n sì wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. (Ka Ìsíkíẹ́lì 1:16-18.) Ó dà bí ohun tí wọ́n fi òkúta kírísóláítì ṣe, ìyẹn òkúta iyebíye tó mọ́ kedere tàbí téèyàn lè rí òdìkejì rẹ̀, ó máa ń ní àwọ̀ yẹ́lò tàbí àwọ̀ ewé. Ohun ẹlẹ́wà tí wọ́n fi ṣe àgbá kẹ̀kẹ́ náà ń tàn yòò.
14 Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí sọ púpọ̀ nípa àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìtẹ́ tó ní àgbá kẹ̀kẹ́! Ohun tó sábà máa ń wá sí wa lọ́kàn tá a bá ń ronú nípa ìtẹ́ ni pé ojú kan ló máa ń wà, bó sì ṣe máa ń rí nìyẹn fáwọn èèyàn tó ń jọba, ibi tí agbára wọn bá mọ ni àkóso wọn máa mọ. Àmọ́ àkóso Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí ti èèyàn. Ìsíkíẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ pé àkóso Jèhófà kò láàlà. (Neh. 9:6) Bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ ni pé kò síbi tí Ọba Aláṣẹ yìí ò ti lè lo agbára rẹ̀!
15. Kí ni Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe rí àti bí wọ́n ṣe tóbi tó?
15 Bí àwọn àgbà kẹ̀kẹ́ náà ṣe tóbi tó ya Ìsíkíẹ́lì lẹ́nu gan-an. Ó ní: “Àwọn àgbá náà ga débi pé wọ́n ń bani lẹ́rù.” A lè fojú inú wo bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń wòkè kó lè rí àwọn àgbá tó rí ràgàjì, tó ń tàn yòò, tó sì ga fíofío náà. Ó tún wá sọ nǹkan míì tó yani lẹ́nu, ó ní: “Ojú sì wà káàkiri ara àgbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.” Àmọ́ ohun tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ nínú ìran yìí ni bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe jẹ́ àrà-mérìíyìírí. Ó ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ ara wọn àti bí wọ́n ṣe rí dà bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
16, 17. (a) Báwo la ṣe lè ṣàlàyé bí kẹ̀kẹ́ náà ṣe ní àgbá kẹ̀kẹ́ kan nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì? (b) Kí ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ṣe lè yí pa dà bìrí?
16 Ó ṣe kedere pé àgbá méjì-méjì ló wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, wọ́n dábùú ara wọn, wọ́n sì wọnú ara wọn lókè àti nísàlẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn àgbá náà fi rí bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ pé: “Tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láì ṣẹ́rí pa dà.” Kí ni àwọn àgbá yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run tí Ìsíkíẹ́lì rí?
17 Ó dájú pé ibi tí àgbá tó ga fíofío báyìí máa yí dé tó bá yí po lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo máa lọ jìnnà gan-an. Kódà, ìran yìí fi hàn pé kẹ̀kẹ́ náà ń yára sáré bíi kíkọ mànàmáná! (Ìsík. 1:14) Yàtọ̀ síyẹn, bí àgbá náà ṣe kọjú síbi mẹ́rin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fi hàn pé bó ṣe máa yí pa dà bìrí kọjá ohun táwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ lè ṣe. Àgbá náà lè lọ síbikíbi ní ọ̀nà èyíkéyìí láìdẹwọ́ eré tó ń sá, tí kò sì ní ṣẹ́rí pa dà! Àmọ́ kì í gba ibi tó bá rí láìmọ ohun tó ń lọ. Àwọn ojú tó wà káàkiri àwọn àgbá náà fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé kẹ̀kẹ́ náà mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ̀, ní gbogbo ibi tó lè gbà.
18. Kí la rí kọ́ nínú bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe tóbi ràgàjì àti bí ojú ṣe pọ̀ lára wọn?
18 Ẹ̀kọ́ wo wá ni Jèhófà ń kọ́ Ìsíkíẹ́lì àti gbogbo àwọn olóòótọ́ èèyàn nípa apá ti ọ̀run lára ètò Rẹ̀? Ronú nípa àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò. Bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe tóbi àti bí ara wọn ṣe ń tàn yòò fi hàn pé ó ní ògo, ó sì ń bani lẹ́rù. Bí ojú ṣe wà káàkiri lára àwọn àgbá náà fi hàn pé ó mọ gbogbo ohun tó ń lọ. Ojú Jèhófà rí ohun gbogbo. (Òwe 15:3; Jer. 23:24) Yàtọ̀ síyẹn, ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì tó lè rán lọ síbikíbi láyé àtọ̀run, wọ́n máa ń fara balẹ̀ wo ohun tó ń lọ, wọ́n sì máa ń pa dà lọ jíṣẹ́ fún Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run.—Ka Hébérù 1:13, 14.
19. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà àti apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀ tá a bá ronú nípa bí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ṣe ń yára sáré tó sì ń yí pa dà bìrí?
19 Bákan náà, a tún rí i pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ń yára sáré gan-an, ó sì lè yí pa dà bìrí. Ronú nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà àtàwọn ìjọba èèyàn pẹ̀lú àwọn àjọ tàbí ètò táwọn èèyàn gbé kalẹ̀! Ṣe ni wọ́n máa ń ṣe nǹkan báṣubàṣu, wọn kì í lè mú ara wọn bá àwọn ìyípadà tó ń dé mu, títí wọ́n á fi forí ṣánpọ́n tàbí kí wọ́n kógbá sílé. Àmọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà tó ń darí rẹ̀ yọ láìkù síbì kan pé ó jẹ́ Ọlọ́run tó ń fòye báni lò, tó sì máa ń mú ara rẹ̀ bá ohun tó bá ṣẹlẹ̀ mu. Bí ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí, ó lè di ohunkóhun tó bá yẹ kó lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Ẹ́kís. 3:13, 14) Bí àpẹẹrẹ, ó lè yára di Jagunjagun alágbára tó ń jà fún àwọn èèyàn rẹ̀, ó tún lè yí pa dà lójú ẹsẹ̀, kó sì di Aláàánú tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó ń tọ́jú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà torí ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára, tó sì ń mú wọn pa dà bọ̀ sípò.—Sm. 30:5; Àìsá. 66:13.
20. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìbẹ̀rù tó yẹ fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run náà?
20 Ó yẹ kí àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò nípa ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí mú ká bi ara wa pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo ní ìbẹ̀rù tó yẹ fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run yìí?’ Ó yẹ ká máa rántí pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí ń ṣojú fún ohun gidi kan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. A ò gbọ́dọ̀ ronú láé pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àtàwọn áńgẹ́lì kò rí àwọn ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ ṣàníyàn pé Ọlọ́run wa ò ní tètè fún wa ní àwọn ohun tá a nílò tàbí pé ètò rẹ̀ kò ní lè ṣe ìyípadà tó yẹ bí àwọn nǹkan tuntun ṣe ń rú yọ nínú ayé tí kò dúró sójú kan tá a wà yìí. Ká má ṣe gbàgbé pé ètò Jèhófà ò fìgbà kankan dáwọ́ iṣẹ́ dúró, ó ń tẹ̀ síwájú nígbà gbogbo. Kódà, Ìsíkíẹ́lì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tó ní: “Ẹ gbéra, ẹ̀yin àgbá kẹ̀kẹ́!” Ó ṣe kedere pé àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ni ohùn yẹn ń pàṣẹ fún pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. (Ìsík. 10:13) Ẹ wo bí ẹnu ṣe máa ń yà wá tó tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń mú kí ètò rẹ̀ tẹ̀ síwájú! Àmọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yẹ ká máa bẹ̀rù.
Ẹni Tó Ń Darí Rẹ̀
21, 22. Kí ló so àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà pọ̀? Ṣàlàyé.
21 Ìsíkíẹ́lì wá yíjú sí ohun tó wà lókè àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, ó rí ‘ohun kan tó tẹ́ lọ pẹrẹsẹ, tó ń dán bíi yìnyín tó mọ́ kedere.’ (Ìsík. 1:22) Ohun náà tẹ́ lọ pẹrẹsẹ, ó ń dán gbinrin lókè orí àwọn kérúbù náà lọ́hùn-ún. Bí ẹnì kan tó jẹ́ onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bá ka ìwé Ìsíkíẹ́lì dé ibí yìí, onírúurú ìbéèrè ló máa wá sí i lọ́kàn nípa kẹ̀kẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ló gbé ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lókè àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí dúró? Báwo ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láìsí irin tó so wọ́n pọ̀?’ Má gbàgbé pé àwọn òfin àdáyébá kọ́ ló ń darí kẹ̀kẹ́ náà, ṣe ló ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan, ó ń jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gangan nínú ọ̀run lọ́hùn-ún. Tún fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó yìí pé: “Ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà tún wà nínú àwọn àgbá náà.” (Ìsík. 1:20, 21) Ẹ̀mí wo ló ń darí àwọn kérúbù àtàwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí?
22 Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni, agbára tó ju gbogbo agbára lọ láyé àtọ̀run. Agbára tí kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró yìí ló so àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà pọ̀, tó ń mú kí wọ́n lagbára, tó sì ń mú kí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe máa bára mu délẹ̀délẹ̀. Ẹ jẹ́ ká fi kókó yẹn sọ́kàn, ká wá wo ibi tí Ìsíkíẹ́lì yíjú sí báyìí, ìyẹn ọ̀dọ̀ Ẹni tó ń darí kẹ̀kẹ́ náà.
Ìsíkíẹ́lì ní láti wá ọ̀rọ̀ tó máa fi ṣàpèjúwe àwọn nǹkan àràmàǹdà tó rí
23. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Ìsíkíẹ́lì fi ṣàpèjúwe Jèhófà, kí sì nìdí?
23 Ka Ìsíkíẹ́lì 1:26-28. Ní gbogbo ibi tí Ìsíkíẹ́lì ti ń ṣàpèjúwe ohun tó rí nínú ìran yìí, ó sábà máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ohun tó rí bí,” “ó jọ pé” àti “ó dà bí.” Àmọ́, ó túbọ̀ lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí nínú àwọn ẹsẹ yìí. Ó jọ pé ṣe ni Ìsíkíẹ́lì ń wá ọ̀rọ̀ tó máa fi ṣàpèjúwe àwọn nǹkan àràmàǹdà tó rí. Ó rí “ohun tó rí bí òkúta sàfáyà . . . ó dà bí ìtẹ́.” Fojú inú wo ìtẹ́ tí wọ́n gbẹ́ látara òkúta sàfáyà ńlá kan tó ní àwọ̀ búlúù! Ẹnì kan gúnwà sórí ìtẹ́ náà. Ó sì “rí bí èèyàn.”
24, 25. (a) Kí ni òṣùmàrè tó yí ìtẹ́ Jèhófà ká ń rán wa létí rẹ̀? (b) Ipa wo ni irú ìran yìí máa ń ní lórí àwọn èèyàn tó nígbàgbọ́?
24 Ìsíkíẹ́lì ò lè sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun àgbàyanu tó rí, ìrísí náà lápapọ̀ nìkan ló lè sọ, torí ṣe ni ògo Jèhófà ń tàn yòò látibi ìbàdí sókè àti sísàlẹ̀. A lè fojú inú wo bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń ṣe bí ẹni fẹ́ pa ojú dé tó sì ń fọwọ́ bo ojú rẹ̀ bó ṣe ń wo ohun àgbàyanu náà. Ìsíkíẹ́lì tún wá sọ nǹkan míì tó fakíki tó rí, ó ní: “Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká bí òṣùmàrè tó yọ lójú ọ̀run lọ́jọ́ tí òjò rọ̀.” Ǹjẹ́ kì í múnú rẹ dùn tó o bá rí i tí òṣùmàrè yọ lójú ọ̀run? Èyí ń rán wa létí ní kedere nípa bí ògo Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ṣe ga lọ́lá tó! Àmì tó ní àwọ̀ mèremère tó tuni lára tó máa ń yọ lójú ọ̀run yìí lè rán wa létí májẹ̀mú àlàáfíà tí Jèhófà bá àwa èèyàn dá lẹ́yìn Ìkún Omi. (Jẹ́n. 9:11-16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Olódùmarè jẹ́ alágbára ńlá, Ọlọ́run àlàáfíà ni. (Héb. 13:20) Èrò àlàáfíà ló wà lọ́kàn rẹ̀, àlàáfíà yìí sì máa ń tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn.
25 Kí ni Ìsíkíẹ́lì ṣe nígbà tó rí ògo Jèhófà Ọlọ́run? Ìsíkíẹ́lì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀.” Ìyàlẹ́nu àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú kí Ìsíkíẹ́lì dojú bolẹ̀. Bó ṣe ṣe àwọn wòlíì yòókù náà nìyẹn nígbà tí wọ́n rí ìran látọ̀dọ̀ Jèhófà; ó dájú pé ohun tí wọ́n rí kà wọ́n láyà, ó sì mú kí wọ́n túbọ̀ rẹ ara wọn sílẹ̀. (Àìsá. 6:1-5; Dán. 10:8, 9; Ìfi. 1:12-17) Àmọ́ nígbà tó yá, ohun tí Jèhófà fi hàn wọ́n mú kí wọ́n pa dà lókun gan-an. Ó dájú pé Ìsíkíẹ́lì náà rí okun gbà. Tá a bá ń ka irú àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí, ipa wo ló yẹ kó ní lórí wa?
26. Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe máa fún un lókun?
26 Tí ipò táwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní Bábílónì bá ti ń mú kí Ìsíkíẹ́lì máa ṣiyèméjì tàbí kó máa dààmú, ó dájú pé ìran yìí máa fún un lókun gan-an. Ó ṣe kedere pé, ibi táwọn èèyàn Jèhófà wà kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, ì báà jẹ́ Jerúsálẹ́mù tàbí Bábílónì. Kò sígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò tí Jèhófà ń darí kò ní lè dé ọ̀dọ̀ wọn! Agbára wo látọ̀dọ̀ Sátánì ló máa ní òun tó bẹ́ẹ̀ láti dá Ọlọ́run tó ń darí ètò àgbàyanu tó wà lọ́run yìí dúró? (Ka Sáàmù 118:6.) Ìsíkíẹ́lì tún kíyè sí pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run náà ò jìnnà sí aráyé rárá. Abájọ tí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà fi máa ń kanlẹ̀! (Ìsík. 1:19) Torí náà, Jèhófà ò gbàgbé àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn rárá. Kò sígbà tí àbójútó Baba wọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn ò ní lè dé ọ̀dọ̀ wọn!
Bí Ìran Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Náà Ṣe Kàn Ẹ́
27. Àǹfààní wo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí lè ṣe fún wa lóde òní?
27 Ṣé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí lè ṣe wá láǹfààní lóde òní? Ó dájú pé ó lè ṣe wá láǹfààní! Má gbàgbé pé ṣe ni Sátánì túbọ̀ ń gbéjà ko ìjọsìn mímọ́ lónírúurú ọ̀nà. Ó máa ń fẹ́ ká máa ronú pé a dá wà, pé a ò ní alábàárò àti pé a ò lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run àti ètò rẹ̀. Má ṣe jẹ́ kó fi irú àwọn irọ́ yìí tàn ẹ́ jẹ! (Sm. 139:7-12) Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó mú kí àwa náà ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. A lè má dojú bolẹ̀ bíi ti Ìsíkíẹ́lì. Àmọ́ tá a bá ronú nípa bí apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà ṣe lágbára tó, bó ṣe ń yára kánkán tó, bó ṣe ń yí pa dà bìrí, bó ṣe ń mú ara rẹ̀ bá ipò èyíkéyìí mu àti bí ògo rẹ̀ tó ń tàn yòò kò ṣe láfiwé, ǹjẹ́ kò yẹ kó yà wá lẹ́nu, kó sì mú ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run?
28, 29. Kí làwọn ohun tó fi hàn pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ń tẹ̀ síwájú ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá?
28 Ó yẹ ká tún máa rántí pé bí ètò Jèhófà ṣe ní apá ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ náà ló ní apá ti orí ilẹ̀ ayé. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn aláìpé ló wà níbẹ̀. Àmọ́, jẹ́ ká ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe nínú ètò rẹ̀ apá ti orí ilẹ̀ ayé! Kárí ayé, Jèhófà ti fún àwọn èèyàn lágbára láti ṣe àwọn ohun tí wọn ò rò pé àwọn lè ṣe láṣeyọrí. (Jòh. 14:12) Tá a bá wo ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso! ó máa rán wa létí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń gbòòrò sí i ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. A tún lè rántí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú bí wọ́n ṣe ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ lẹ́kọ̀ọ́, bí ilé ẹjọ́ ṣe ń dá wa láre àti bá a ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run!
29 Tá a bá ronú nípa gbogbo ohun tá a ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí, á túbọ̀ ṣe kedere sí wa pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ń tẹ̀ síwájú. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ gbáà la ní láti wà nínú ètò yìí, tá a sì ń sin irú Ọba Aláṣẹ yìí!—Sm. 84:10.
30. Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?
30 Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tá a lè rí kọ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí. Nínú orí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ púpọ̀ sí i nípa àwọn “ẹ̀dá alààyè” mẹ́rin tàbí àwọn kérúbù tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà. Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n lè kọ́ wa nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Aláṣẹ wa tí ògo rẹ̀ ga lọ́lá?
a Ìsíkíẹ́lì sọ pé ó ń tàn yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà.
b Bí ọ̀nà yìí ṣe jìn tó nìyẹn, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà ibi tí àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn gbà fi ìlọ́po méjì ju ìyẹn lọ.