Dáníẹ́lì
10 Ní ọdún kẹta Kírúsì+ ọba Páṣíà, a ṣí ọ̀rọ̀ kan payá fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì;+ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó dá lórí ìjàkadì ńlá kan. Ọ̀rọ̀ náà yé e, a sì jẹ́ kí ohun tó rí yé e.
2 Nígbà yẹn, èmi Dáníẹ́lì ti ń ṣọ̀fọ̀+ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. 3 Mi ò jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, ẹran tàbí wáìnì kò kan ẹnu mi, mi ò sì fi òróró para rárá fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. 4 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kìíní, nígbà tí mo wà létí odò ńlá náà, ìyẹn Tígírísì,*+ 5 mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,*+ ó sì de àmùrè wúrà tó wá láti Úfásì mọ́ ìbàdí rẹ̀. 6 Ara rẹ̀ dà bíi kírísóláítì,+ ojú rẹ̀ rí bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ dà bí ògùṣọ̀ oníná, apá rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó ń dán,+ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dà bí ìró èrò púpọ̀. 7 Èmi Dáníẹ́lì nìkan ni mo rí ìran náà; àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ mi ò rí ìran náà.+ Síbẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sá lọ, wọ́n sì fara pa mọ́.
8 Ó wá ku èmi nìkan, nígbà tí mo sì rí ìran ńlá yìí, agbára kankan ò ṣẹ́ kù nínú mi, ojú mi tó fani mọ́ra tẹ́lẹ̀ yí pa dà, mi ò sì lókun mọ́ rárá.+ 9 Mo wá gbọ́ tó ń sọ̀rọ̀; àmọ́ nígbà tí mo gbọ́ tó ń sọ̀rọ̀, mo sùn lọ fọnfọn ní ìdojúbolẹ̀.+ 10 Ọwọ́ kan sì kàn mí,+ ó jí mi pé kí n dìde lórí ọwọ́ mi àti orúnkún mi. 11 Ó wá sọ fún mi pé:
“Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an,*+ fiyè sí ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ fún ọ. Ó yá, dìde níbi tí o wà, torí a ti rán mi sí ọ.”
Nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún mi, mo dìde, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n.
12 Ó wá sọ fún mi pé: “Má bẹ̀rù,+ ìwọ Dáníẹ́lì. A ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ láti ọjọ́ tí o ti kọ́kọ́ jẹ́ kí ọkàn rẹ lóye, tí o ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, torí ọ̀rọ̀ rẹ ni mo sì ṣe wá.+ 13 Àmọ́ olórí+ ilẹ̀ ọba Páṣíà dí mi lọ́nà fún ọjọ́ mọ́kànlélógún (21). Ṣùgbọ́n Máíkẹ́lì,*+ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ipò wọn ga jù* wá ràn mí lọ́wọ́; mo sì wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọba Páṣíà. 14 Mo wá láti jẹ́ kí o lóye ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ ní àkókò òpin,+ torí ìran ohun tó ṣì máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni.”+
15 Nígbà tó bá mi sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, mo dojú bolẹ̀, mi ò sì lè sọ̀rọ̀. 16 Ẹnì kan tó rí bí èèyàn wá fọwọ́ kan ètè mi,+ mo sì la ẹnu mi, mo sọ fún ẹni tó dúró níwájú mi pé: “Olúwa mi, ìran náà ń kó jìnnìjìnnì bá mi, mi ò sì lókun rárá.+ 17 Báwo ni ìránṣẹ́ olúwa mi ṣe wá fẹ́ bá olúwa mi sọ̀rọ̀?+ Mi ò lókun kankan báyìí, èémí kankan ò sì ṣẹ́ kù nínú mi.”+
18 Ẹni tó rí bí èèyàn náà tún fọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi lókun.+ 19 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Má bẹ̀rù,+ ìwọ ọkùnrin tó ṣeyebíye gan-an.*+ Kí o ní àlàáfíà.+ Jẹ́ alágbára, àní kí o jẹ́ alágbára.” Bó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo lókun, mo sì sọ pé: “Kí olúwa mi sọ̀rọ̀, torí o ti fún mi lókun.”
20 Ó wá sọ pé: “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi wá bá ọ? Ní báyìí, màá pa dà lọ bá olórí Páṣíà jà.+ Tí mo bá kúrò, olórí ilẹ̀ Gíríìsì máa wá. 21 Àmọ́, màá sọ àwọn nǹkan tí a kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. Kò sí ẹni tó ń tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá nínú àwọn nǹkan yìí, àfi Máíkẹ́lì,+ olórí yín.+