Ori 7
Dídá Messia, Ọba naa Mọ̀yàtọ̀
1. Eeṣe, lọna tí ó bamuwẹ́kú, tí Jehofa fi lò Danieli lati sọtẹlẹ nipa idiwọn akoko awọn iṣẹlẹ?
WOLII Danieli yoo jẹ́ ọ̀kan lára awọn wọnni tí a ó jí dide lati ṣajọpin ninu iṣeto Ijọba Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé. Bi oun ti ń pari igbesi-aye iṣẹ-isin gigun rẹ̀ si Jehofa ni a sọ fun un pe: “Iwọ yoo sì sinmi, iwọ yoo sì dide duro ní ipò rẹ ní ikẹhin ọjọ.” Danieli lọkan ifẹ jijinlẹ sí “àkókò opin” ati awọn “ohun iyanu” tí yoo ṣẹlẹ nigba naa, gan-an gẹgẹ bi awa ti lọkan ifẹ si i lonii. Nitori naa, ó baamu wẹ́kú pe Olupa Akoko mọ́ nla naa, Jehofa Ọlọrun, lò Danieli bi wolii rẹ̀ ní isopọ pẹlu itolẹsẹẹsẹ akoko rẹ̀ fun ‘dídé’ Ijọba naa.—Danieli 12:4, 6, 13; 11:27, 35; fiwe Amosi 3:7; Isaiah 46:9-11.
“ISỌDAHORO JERUSALEMU”
2. (a) Asọtẹlẹ Isaiah wo ni a muṣẹ lojiji ní 539 B.C.E., bawo sì ni? (b) Iṣẹ-iyanu wo ni a nilo fun Jeremiah 25:11, 12 lati ní imuṣẹ lakooko?
2 Ní ìlà pẹlu asọtẹlẹ Jehofa tí ó sọ ní ọpọ ọ̀rúndún ṣaaju, Ilẹ-ọba Babiloni ṣubu sọ́wọ́ awọn ọmọ-ogun Kirusi ará Persia ati Dariusi ará Media. (Isaiah 44:24, 27, 28; 45:1, 2) Dariusi di ọba lori ijọba Babiloni ti iṣaaju. Eyiini jẹ́ ní ọdun 539 B.C.E. Ọdun mejidinlaadọrin ti kọja nisinsinyi lati igba tí Nebukadnessari ti Babiloni ti run Jerusalemu ati tẹmpili rẹ̀, tí ó ti sọ ilẹ Juda di ahoro tí ó sì ti kó awọn Ju tí wọn laaja lọ si Babiloni. Nitori naa pẹlu ifojusọna mímúhánhán ni Danieli arugbo naa fi kọwe, ní ọdun kìn-ín-ní Dariusi pe: “Emi Danieli fiyesii, lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi tí ọ̀rọ̀ Oluwa tọ̀ Jeremiah wolii wá, pe aadọrin ọdun ni oun yoo mú pé lori idahoro Jerusalemu.” (Danieli 9:2; Jeremiah 25:11, 12) Nipasẹ iṣẹ-iyanu wo ni awọn Ju tí a kólẹ́rú, laaarin ọdun meji sii, fi lè padabọ ki wọn sì mú ijọsin Jehofa padabọsipo ní Jerusalemu?
3. Nitori naa, adura kíkankíkan wo ni Danieli gbà?
3 Danieli rawọ́ ẹ̀bẹ̀ kíkankíkan si Jehofa lorukọ awọn eniyan rẹ̀, ní jijẹwọ ẹṣẹ wọn ó képe Jehofa lati fi aanu hàn. Leke gbogbo rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ pe ki Jehofa mú ẹ̀gàn tí a ti kójọ pelemọ sori orukọ nla Rẹ̀ lati ọwọ awọn orilẹ-ede tí ó yí Israeli ká kuro. Ó pàrọwà si Ọlọrun rẹ̀ pe: “Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o sì ṣe; maṣe jáfara, nitori ti iwọ tikaraarẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ ni a fi ń pè ilu rẹ, ati awọn eniyan rẹ.”—Danieli 9:4-19.
4. Bawo ni Jehofa ṣe dahun adura naa?
4 Jehofa ha dahun adura yii bi? Ó ṣe bẹẹ nitootọ! Ní ṣiṣe bẹẹ, oun mú asọtẹlẹ rẹ̀ ṣẹ pẹlu. Ó mú ki Kirusi ti Persia, arọ́pò Dariusi, pa aṣẹ fun iyoku awọn ọmọ Israeli lati lọ si Jerusalemu ki wọn sì tún tẹmpili Jehofa kọ́. Bi “aadọrin ọdun” naa ti pari, ní 537 B.C.E., awọn Ju wọnni tí a mú padabọsipo tún bẹrẹsi rú ẹbọ si Jehofa lori pẹpẹ rẹ̀ tí a ti túnkọ́ ní Jerusalemu.—2 Kronika 36:17-23; Esra 3:1; Isaiah 44:28; 45:1.
DÍDÍWỌ̀N AKOKO DÍDÉ MESSIA LÁKỌ̀Ọ́KỌ́
5. (a) Ki ni ohun tí ó tẹle e lẹsẹkẹsẹ? (b) Sáà akoko wo ni ó hàn ketekete ninu Danieli 9:24-27?
5 Abajade ojú-ẹsẹ̀ kan tẹle adura tí Danieli gbà yẹn pẹlu. Angẹli Gabrieli farahan niwaju rẹ̀ ní ìrí eniyan, ó sì bẹrẹsi bá a sọrọ. Ó tọkasi Danieli gẹgẹ bi “ayanfẹ gidigidi [sí Jehofa]” ó sì bẹ̀rẹ̀ síi fun un ní “òye” siwaju sii. (Danieli 9:20-23) Ohun tí ó ní lati sọ jẹ́ titun patapata, iṣipaya àkọ̀tun fun Danieli. Ó jẹ́ asọtẹlẹ yiyanilẹnu, eyi ti o ni ninu awọn iṣẹlẹ tí yoo kárí sáà àkókò kan, tí kii ṣe “aadọrin ọdun,” ṣugbọn “aadọrin ọsẹ.” Jọwọ kà á lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ ninu Danieli 9:24-27. Ki ni asọtẹlẹ naa tumọsi?
6. Bawo ni “aadọrin ọsẹ” naa ti gùn tó?
6 Ó sọ pe “aadọrin ọsẹ” ni a ti pinnu niti ifarahan “Messia Aṣaaju naa,” Ọba tí a ṣeleri lati inu ìlà Dafidi. Awọn wọnyi ha lè jẹ́ ọsẹ ṣákálá bi? Bẹẹkọ, nitori pe èkukáká ni gbogbo ohun tí a sọtẹlẹ fi lè ṣẹlẹ laaarin ọdun kan ati aabọ. Wọn fẹri han pe wọn jẹ́ “ọsẹ” ninu eyi tí ọjọ kan duro fun ọdun kan. (Fiwe Lefitiku 25:8.) Niti tootọ, awọn itumọ Bibeli melookan lò gbolohun ọ̀rọ̀ bii “aadọrin ọsẹ ti awọn ọdun” ninu Danieli 9:24. (An American Translation, Moffatt, Today’s English Version; tún wo alaye isalẹ ìwé ninu Rotherham, The New American Bible, The Jerusalem Bible.) Ní kedere “aadọrin ọsẹ” naa jẹ́ 490 ọdun gidi.
7, 8. (a) Eeṣe tí a kò bẹrẹsi kà “aadọrin ọsẹ” naa lati igba aṣẹ Kirusi? (b) Bawo ni a ṣe dahun adura Nehemiah? (c) Bawo ni awọn Ju ṣe dahun si “ọ̀rọ̀” ọba naa? (d) Nigba wo ni eyi ṣẹlẹ?
7 Nigba wo ni a bẹrẹsii kà “aadọrin ọsẹ” naa? Danieli 9:25 sọ fun wa pe: “Lati ijadelọ ọ̀rọ̀ naa lati tún Jerusalemu ṣe, ati lati tún un kọ́.” Bi ó ti wù ki ó rí, àṣẹ Kirusi kò ní iru “ọ̀rọ̀” bẹẹ ninu. A fi i mọ sí kìkì ‘títún ile Jehofa kọ́,’ eyi tí yoo ní pẹpẹ irubọ ninu. (Esra 1:1-4) Titi di eyi tí ó jù 80 ọdun lọ lẹhin naa, ilu-nla naa fúnraarẹ̀ wà ní “ahoro,” pẹlu awọn ogiri rẹ̀ tí ó wolulẹ. Ní akoko yẹn Ju oloootọ kan, Nehemiah, ni a gbàsíṣẹ́ gẹgẹ bi agbọ́tí fun Ọba Artasasta ti Persia, ní ile-olodi Ṣuṣani. Nigba tí ó gbọ́ nipa ipò oníwàhálà awọn Ju ní Jerusalemu, ó gbadura pe ki “ẹ̀gàn” ti o wà lori orukọ Jehofa lè di eyi tí a mú kuro.—Nehemiah 1:3, 11; 2:17.
8 Pẹlu oju kikoro, Nehemiah gbé ọtí wá fun ọba. Artasasta bi i léèrè pe: “Eeṣe tí ojú rẹ fi fàro? Iwọ kò sáà ṣaisan? Eyi kii ṣe ohun miiran bikoṣe ibanujẹ.” Nigba tí ó mọ̀ ohun tí ó fà á, lẹsẹkẹsẹ ni ọba fun Nehemiah ní itọni lati pada si Jerusalemu, ki ó baa lè kọ́ awọn “ogiri” ati “ẹnu-ọna” ilu-nla naa. Nigba tí Nehemiah dé ibẹ lati rohin nipa ojurere tí Ọlọrun fihan, ati lati jíṣẹ́ ọba “lati tún Jerusalemu ṣe ati lati tún un kọ́,” bawo ni awọn eniyan naa ṣe huwapada? “Wọn sì wi pe, Jẹ́ ki a dide, ki a sì mọ odi! Bẹẹ ni wọn gbà araawọn niyanju fun iṣẹ rere yii.” Gbogbo eyi ṣẹlẹ “ní ogún ọdun Artasasta ọba.”—Nehemiah 2:1-18.
9. Bawo ni a ṣe lè pinnu ogún ọdun Artasasta?
9 Ọdun wo ni eyi? Ẹ̀rí alagbara fihan pe Artasasta yii (tí a tún ń pè ní “Longimanus” nitori ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gígùn) gun ori ìtẹ́ Persia lẹhin iku Sasta baba rẹ̀. Ọdun kìn-ín-ní ijọba Artasasta yoo jẹ́ 474 B.C.E. Nipa bayii ogún ọdun ijọba rẹ̀ yoo jẹ́ 455 B.C.E.a
10. Bawo ni asọtẹlẹ naa nipa “ọsẹ meje” akọkọ ṣe ní imuṣẹ?
10 Bi ó bá rí bẹẹ, nigba naa, awọn “ọsẹ” ninu Danieli 9:25 yoo bẹrẹ kíkà lati 455 B.C.E. A kà pe:
“Nitori naa ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ̀ naa lati tún Jerusalemu ṣe, ati lati tun un kọ́, títí dé ìgbà [Messia Aṣaaju, NW] naa, yoo jẹ ọ̀sẹ̀ meje, ati ọ̀sẹ̀ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni ìgbà wahala.”
Ní kedere, “ọ̀sẹ̀ meje” akọkọ tabi 49 ọdun, kárí akoko tí a ń ṣe àtúnkọ́ ilu-nla naa, titi di 406 B.C.E. “Ìgbà wàhálà” naa tọkasi atako kíkorò tí ó kọlu iṣẹ àtúnkọ́ yii lati ọwọ awọn eniyan aládùúgbò. (Nehemiah 4:6-20) Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi itan ti fihan, Jerusalemu jẹ́ ilu-nla kan tí ó ní aásìkí ní opin ọ̀rúndún naa.b
11. Bawo ni “Messia Aṣaaju naa” ṣe farahan ní akoko?
11 Bi ó ti wù ki ó rí, rekọja eyi ni “ọ̀sẹ̀ mejilelọgọta” yoo fi wà—tí ó jẹ́ apapọ 69 ọsẹ ti ọdun, tabi 483 ọdun, lati 455 B.C.E. “titi dé ìgbà Messia Aṣaaju naa.” Awọn 483 ọdun wọnyi, tí ó ní kiki apakan 455 B.C.E. ninu ati apakan ọdun tí ó kẹhin, yoo nasẹ̀ dé 29 C.E. Messia naa ha farahan nigba naa bi? Luku 3:1-3 sọ pe “ní ọdun kẹẹdogun ijọba Tiberiu Kesari,” Johannu Arinibọmi “wá si gbogbo ilẹ ìhà Jordani, ó ń waasu baptismu.” Niwọn bi awọn opitan ti fidi rẹ̀ mulẹ pe Tiberiu di olú-ọba Romu ní August 17, 14 C.E. (kalẹnda Gregory), ó tumọsi pe iwaasu ati baptismu Johannu bẹrẹ lákòókò ọdun kẹẹdogun Tiberiu—ní igba iruwe 29 C.E. Ní igba ikore ọdun kan-naa—29 C.E.—a baptisi Jesu, ẹmi mimọ sì sọkalẹ lati ọrun wá lati fororoyan an gẹgẹ bi Messia. Nitootọ, ní akoko yiyẹ gan-an ní imuṣẹ asọtẹlẹ atọrunwa!—Luku 3:21, 22.
12. (a) Ki ni pupọ ninu awọn Ju ń fojusọna fun nigba naa? (b) Eeṣe tí wọn fi tàsé koko pataki asọtẹlẹ naa? (c) Ṣugbọn bawo ni awa ṣe lè janfaani?
12 Ní awọn ọjọ wọnni, ọpọ awọn Ju ni wọn ń fojusọna fun dídé Messia, lápákan dajudaju nitori mímọ̀ tí wọn mọ̀ nipa “aadọrin ọsẹ” naa. (Luku 3:15; Johannu 1:19, 20) Ṣugbọn nitori líle ọkàn-àyà wọn, pupọ julọ tàsé koko asọtẹlẹ naa. (Matteu 15:7-9) Bi ó ti wù ki ó rí, awa lonii ni a lè fun igbagbọ wa lókun nipa fifiyesi irúfẹ́ gbogbo apá pataki ti “ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ” naa. (2 Peteru 1:19-21) Kii ṣe kiki pe “ọ̀rọ̀” naa fi Messia han yatọ ní kedere nikan ni, gẹgẹ bi a ti ṣalaye ninu ṣáàtì tí ó wà ní oju-iwe 67; ó tún tọka wa si awọn ibukun yiyanilẹnu tí a ó gbadun labẹ Ijọba “Messia Aṣaaju naa.”—Isaiah 9:6, 7.
A “KÉ” MESSIA ỌBA “KURO”
13, 14. Bawo ni ifarahan ati ipa-ọ̀nà Messia naa ṣe yatọ patapata si ohun tí awọn Ju ń reti?
13 Ifarahan “Messia Aṣaaju naa” ha yọrisi idande ojú-ẹsẹ̀ fun awọn Ju bi? Wọn reti pe ki ó jẹ́ jagunjagun alagbara, ọba alágbára gíga kan tí yoo gbà wọn silẹ lọwọ ìdè ìsìnrú rírorò labẹ Ilẹ-ọba Romu. (Johannu 6:14, 15) Bi ó ti wù ki ó rí, Baba rẹ̀, Jehofa, pete iru idande kan tí ó yatọ.
14 Ninu asọtẹlẹ “aadọrin ọsẹ” naa Gabrieli mú un ṣe kedere pe, dipo ki Messia naa jẹ́ olùṣàkóso olóṣèlú nla kan, a ó ‘ké e kuro, ki yoo sì sí ohunkohun fun un.’ Ó nilati kú iku ìtìjú kan laisi orukọ tabi ohun-ìní ti ara lati fi silẹ fun iran tí ń bọ̀ lẹhin. Ẹ wo bi imuṣẹ naa ti wọnilọ́kàn tó! Nigba tí a bọ́ aṣọ lara Jesu fun ìfìyà-ikú-jẹni, awọn ọmọ-ogun tilẹ ṣẹ́ kèké lé gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù fun un—ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀.—Danieli 9:26a; Matteu 27:35.
15. (a) Nigba wo ni a “ké” Messia “kuro”? (b) Bawo ni a ṣe fi ìdí ìpéye apá-ẹ̀ka akoko yii mulẹ?
15 Nigba wo ni ìfìyà-ikú-jẹni yii ṣẹlẹ? Gabrieli sọ pe yoo jẹ́ “ní ìdajì ọsẹ” ọdun tí ó kẹhin, eyiini ni, ní igba iruwe 33 C.E., ọdun mẹta ati aabọ lẹhin baptismu ati ìfòróróyàn Jesu. Gẹgẹ bi ẹ̀rí si ìpéye asọtẹlẹ naa, Ihinrere Johannu tọka pe Jesu nigba naa wà nibi Irekọja kẹrin tí ó tẹle baptismu rẹ̀.—Danieli 9:27b; Johannu 2:13; 5:1; 6:4; 13:1.
16, 17. (a) Bawo ni a ṣe mú awọn ọ̀rọ̀ siwaju sii ti Danieli 9:26 ṣẹ lọna ti o banininujẹ? (b) Bawo ni awọn ọmọlẹhin tootọ ti Messia nigba naa lọ́hùn-ún ṣe jẹ́ apẹẹrẹ fun wa?
16 Bẹẹni, ‘a ké Messia Aṣaaju naa kuro.’ Bawo ni ó ti banininujẹ tó pe awọn Ju kò mọyì ọba wọn! Ṣugbọn pupọ sii ń bọ̀. Isọdahoro yoo tún dé sori Jerusalemu lẹẹkan sii. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Danieli ti wí:
“Awọn ọmọ-aládé kan ti yoo wá ni yoo pa ilu naa ati ibi mímọ́ run; opin ẹni ti ń bọ̀ yoo si dabi ìkún-omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro.”—Danieli 9:26b.
17 Gan-an gẹgẹ bi asọtẹlẹ naa ti wi, akoko tí ó tẹle ‘ikekuro’ Messia ni ogun sami si “titi dé opin.” Nikẹhin, ní 70 C.E., ẹgbẹ ọmọ-ogun Romu rọ́gììrì dé bi ikun omi sinu Jerusalemu tí a gbogunti. Ilu-nla naa ati tẹmpili rẹ̀ ni a wópalẹ̀, ‘tí a mú wá sí ìparun wọn.’ Gẹgẹ bi opitan naa Josephus ti wí, 1,100,000 awọn Ju ni wọn ṣègbé ninu ìpakúpa naa. Lọna ti o dunmọni, awọn ọmọlẹhin tootọ ti Messia ti kọbiara sí “ami” tí ń ṣekilọ naa tí wọn sì salọ ni akoko yii si ibi aabo ní awọn oke-nla tí ó wà ní ìkọjá Jordani. (Matteu 24:3-16) Eyi sì tún tẹnumọ ọn pẹlu fun wa lonii bi ó ti ṣe pataki tó pe ki a fiyesi “ami” alasọtẹlẹ ti Ọlọrun ki Ijọba naa tó “dé” lati mú idajọ ṣẹ ní kíkún sori eto-igbekalẹ ayé buburu ti isinsinyi.—Luku 21:34-36.
MESSIA MÚ AWỌN ANFAANI WÁ
18. Ohun wo tí ó ní anfaani ni a ṣe ní aṣepari nigba wíwá Messia lakọọkọ?
18 Nigba naa, ki ni wíwá Messia nigba akọkọ yoo ṣe aṣepari rẹ̀? Gabrieli ti sọ fun Danieli pe:
“Aadọrin ọ̀sẹ̀ ni a pinnu sori awọn eniyan rẹ, ati sori ilu mímọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi èdìdí di ẹ̀ṣẹ̀, ati lati ṣe ìlàjà fun aiṣedeede ati lati mú ododo ainipẹkun wá.” (Danieli 9:24a)
Ṣaaju ati nipasẹ iku rẹ̀ “Messia Aṣaaju naa” yoo ṣaṣepari gbogbo eyi! Eyi ki yoo jẹ́ idande lọna iṣelu bikoṣe nipa tẹmi lọna agbayanu. Nipasẹ agbara irapada iwalaaye eniyan pípé rẹ̀, tí ó funni ninu irubọ, Jesu yoo mú abawọn ẹṣẹ ati irekọja kuro lara awọn wọnni tí yoo tẹwọgba á gẹgẹ bi Messia, yoo sì mú wọn wá sinu “majẹmu titun kan” gẹgẹ bi “Israeli Ọlọrun” ti ẹmi.—Galatia 6:16; Jeremiah 31:31, 33, 34.
19. Bawo ni Messia ṣe “dẹ́kun ẹbọ ati ọrẹ ẹbọ”?
19 Nitori naa ohun tí majẹmu Ofin tí Mose ṣe alarina rẹ̀ kò lè ṣe, lori ìpìlẹ̀ awọn irubọ rẹ̀ tí a fi ẹranko ṣe, ni majẹmu titun naa tí Messia ṣe alarina rẹ̀ yoo wá ṣe ní aṣepari nisinsinyi, lori ìpìlẹ̀ ẹbọ kanṣoṣo tí ó fi ara eniyan pípé rẹ̀ ṣe, tí a ṣe “laaarin ọsẹ naa.” Nipa bayii oun “yoo mú ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ,” niti pe awọn ẹbọ Ofin ki yoo ní iniyelori kankan mọ́. (Danieli 9:27) Gẹgẹ bi aposteli Paulu ti wí lẹhin naa: “Ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesii, wọn sì di titun. Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, ẹni tí ó sì ti ipasẹ̀ Jesu Kristi bá wà làjà sọdọ araarẹ̀, tí ó sì fi iṣẹ-iranṣẹ ìlàjà fun wa.”—2 Korinti 5:17, 18.
20. Iwọ lè layọ nipa ifojusọna wo fun araye?
20 Nigba tí ó bá yá, awọn anfaani ẹbọ irapada Jesu yoo nasẹ̀ jinna rekọja Israeli tẹmi eyi tí Paulu jẹ́ apakan rẹ̀, nitori pe oun tẹsiwaju ní wiwi pe, nipasẹ Kristi, Ọlọrun “ń bá araye làjà sọdọ araarẹ̀, kò sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lọ́rùn.” (2 Korinti 5:19) Gẹgẹ bi apakan ayé araye, iwọ kò ha layọ pe awọn àṣìṣe rẹ tí o jẹ nitori àìpé eniyan ni a lè dariji lori ìpìlẹ̀ ẹbọ Ẹni naa tí ó bá ọ làjà pẹlu Ọlọrun?
21, 22. (a) Bawo ni ọsẹ aadọrin naa ṣe “fi èdìdí samisi iran ati wolii”? (Danieli 9:24) (b) Bawo ni a ṣe fòróróyan “Ibi Mímọ́ ninu awọn Ibi Mímọ́”?
21 Àmọ́ ṣáá o, kii ṣe kìkì pe ‘ọsẹ aadọrin’ yoo “mú ododo ainipẹkun wá” nikan ni. Pẹlupẹlu, yoo “fi èdìdí di iran ati wolii.” Gẹgẹ bi Ìfihàn 19:10 (NW), ti wi, “jijẹrii si Jesu ni ohun ti ń misi isọtẹlẹ.” Jesu, ní àkọ́wá rẹ̀ gẹgẹ bi Messia, niti gidi mú ọgọrọọrun asọjade alasọtẹlẹ ṣẹ ninu ohun tí ó ṣe ati ohun tí ó sọ. Eyi dabi fifi èdìdí aláìṣeéṣí kan dí awọn asọtẹlẹ wọnyẹn, ní fifihan pe wọn jẹ́ otitọ, pe wọn pé pérépéré tí wọn sì ní Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ gẹgẹ bi orisun wọn. Nisinsinyi, nipasẹ Messia naa, gbogbo ileri Ọlọrun fun bibukun awọn eniyan rẹ̀ ni a ó ṣàṣeparí rẹ̀. “Nitori pe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun ti pọ̀ tó, ninu rẹ̀”—Messia naa, Jesu—“ni bẹẹni.”—Danieli 9:24b; 2 Korinti 1:20.
22 Ohun tí a ó tún ṣaṣepari rẹ̀ nigba ‘ọsẹ aadọrin’ naa ni fífòróróyan “Ibi Mímọ́ ninu awọn Ibi Mímọ́.” (NW) “Ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́” ninu tẹmpili Jerusalemu kò tún ní ṣiṣẹ mọ́ fun ete Ọlọrun ti o nii ṣe pẹlu idariji ẹṣẹ. Ó wulẹ ti jẹ́ àwòkọ́ṣe ti eyi ti o jẹ gidi ninu iṣeto tẹmpili nla tẹmi tí a dasilẹ pẹlu ìfòróróyàn Messia ní 29 C.E. Nibẹ, tẹle iku ati ajinde rẹ̀, Kristi wọ̀ ọrun lọ “lẹẹkanṣoṣo” lati fi ìtóye ẹbọ eniyan rẹ̀ lelẹ niwaju Ọlọrun Fúnraarẹ̀. (Heberu 9:23-26) Ibugbe Ọlọrun ní ọrun nipa bayii ti ní irisi miiran. A ti fòróróyàn án gẹgẹ bi “Ibi Mímọ́ ninu awọn Ibi Mímọ́,” tí ó tipa bayii di ibi gidi tẹmi tí Ibi Mímọ́ Julọ ninu tẹmpili Jerusalemu ṣapẹẹrẹ rẹ̀. Nitori naa, bẹrẹ lati ọjọ Pentekosti, 33 C.E., ati titilọ dé opin ‘ọsẹ aadọrin’ naa, awọn Ju wọnni tí wọn tẹwọgba ipese Ọlọrun ní anfaani alailẹgbẹ kan. Lori ipilẹ ẹbọ Kristi tí a fi lelẹ ninu “Ibi Mímọ́ ninu awọn Ibi Mímọ́” yẹn, awọn, pẹlu, ni a fòróróyàn lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi awọn alufaa ọmọ-abẹ ninu tẹmpili Ọlọrun nipa tẹmi.
23. (a) Ní pataki bawo ni a ṣe ṣojurere sí awọn Ju ní ọsẹ aadọrin? (b) Bawo ni a ṣe ṣojurere sí awọn miiran lẹhin opin “aadọrin ọsẹ” naa?
23 Nipa irúfẹ́ awọn Ju bẹẹ tí a ó mú wọ̀ inu Israeli tẹmi, asọtẹlẹ naa wi pe: “Oun yoo sì fi idi majẹmu naa mulẹ fun ọpọlọpọ níwọ̀n ọsẹ kan.” Eyi ni ‘ọsẹ awọn ọdun’ ti 29-36 C.E., ní akoko tí a ṣojurere ní pataki si awọn Ju nipa ti ara niti sisọ wọn dọmọ gẹgẹ bi apakan ‘iru-ọmọ Abrahamu’ nipa tẹmi. (Danieli 9:27a) Ṣugbọn nigba naa, pẹlu iwaasu tí Peteru ṣe fun Korneliu Keferi aláìkọlà naa, ọna ṣísílẹ̀ fun awọn eniyan aláìkọlà ninu awọn orilẹ-ede pẹlu lati mú wọn wọ̀ inu majẹmu Abrahamu. Nipa bayii, Paulu kọwe pe: “Nitori pe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo yin, nipa igbagbọ ninu Kristi Jesu. Nitori pe iye ẹyin tí a ti baptisi sinu Kristi, ti gbé Kristi wọ̀. Kò lè sí Ju tabi Griki, ẹrú tabi ominira, ọkunrin tabi obinrin: nitori pe ọ̀kan ni gbogbo yin jẹ́ ninu Kristi Jesu. Bi ẹyin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹyin ni iru-ọmọ Abrahamu, ati àròlé gẹgẹ bi ileri.”—Galatia 3:26-29; Iṣe 10:30-35, 44-48.
24. (a) Imudaniloju agbayanu wo ni ileri Abrahamu ní fun awọn miiran sibẹ? (b) Gẹgẹ bi Luku 9:23 ti fihan, bawo ni iwọ ṣe lè ṣajọpin?
24 Bi ó ti wù ki ó rí, nipa ti araye yooku ń kọ́—ọpọ billion tí a kò tíì kojọ lati di apakan “agbo kekere” naa tí ó ní ogún kan ní ọrun? Áà, ileri Abrahamu ní imudaniloju agbayanu kan fun awọn wọnyi, pẹlu, niti pe Ọlọrun wí nibẹ pe: “Ninu iru-ọmọ [ti Abrahamu] ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede ayé.” (Genesisi 22:18) Ó ha jẹ́ ifẹ-ọkan rẹ lati ṣajọpin ninu ibukun naa bi? Iwọ lè nípìn-ín ninu rẹ̀, ati nitori ìdí eyi iwọ gbọdọ gbadura fun ‘dídé ijọba Ọlọrun.’ Pẹlupẹlu, bi iwọ ti ń báa lọ ní wíwádìí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, iwọ yoo kẹkọọ bi o ṣe lè “sẹ́” araarẹ ninu iyasimimọ fun Ọlọrun ki o sì tẹle Messia Aṣaaju naa “ní ọjọ gbogbo.”—Luku 9:23.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wò Ilé-Ìsọ́nà, November 1, 1967, oju-iwe 348 si 349; Aid to Bible Understanding, oju-iwe 1473.
b Fun apẹẹrẹ, opitan ọ̀rúndún kẹrin B.C.E. naa Hecataeus ti Abdera ni Josephus ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Against Apion, Iwe I:22, ní kikọwe pe: “Awọn Ju ní ọpọlọpọ odi ati abúlé ní apa oriṣi orilẹ-ede naa, ṣugbọn kìkì ilu-nla olódi kanṣoṣo, tí ìwọ̀n gígùn rẹ̀ yípoyípo jẹ́ aadọta stades [nǹkan bii 33,000 ẹsẹ-bata] ati pẹlu nǹkan bii 120,000 awọn olùgbé; wọn ń pè é ní Jerusalemu.”
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 67]
AWỌN ASỌTẸLẸ TÍ A MUṢẸ NITI “MESSIA AṢAAJU NAA” NÍHÀ OPIN “AADỌRIN ỌSẸ”
ASỌTẸLẸ KÓKÓ INU RẸ̀ IMUṢẸ
Isaiah 40:3 Johannu Arinibọmi pese ọna silẹ Matteu 3:1-3
Mika 5:2 A bí Jesu ní Betlehemu Matteu 2:1-6
Genesisi 49:10 Lati inu ẹya Juda Luku 3:23-33
Isaiah 7:14 Lati ọwọ́ wundia kan Matteu 1:23-25
Isaiah 9:7 Atọmọdọmọ, ajogún Dafidi Matteu 1:1, 6-17
Jeremiah 31:15 A pa awọn ọmọ-ọwọ lẹhin ìbí Matteu 2:16-18
Hosea 11:1 A pè é jade lati Egipti (ibi-ìsádi) Matteu 2:14, 15
Danieli 9:25 Ó farahan lopin 69 “ọsẹ” Luku 3:1, 21, 22
Orin Dafidi 40:7, 8 Ó mú araarẹ̀ wá lati ṣe Matteu 3:13-15
ifẹ-inu Ọlọrun
Isaiah 61:1, 2 Ẹmi fòróróyàn án lati waasu Luku 4:16-21
Orin Dafidi 2:7 Jehofa kede Jesu ní ‘Ọmọkunrin’ Matteu 3:17
Isaiah 9:1, 2 Imọlẹ ní agbegbe Galili Matteu 4:13-16
Orin Dafidi 40:9 Ó fi àìṣojo waasu “ihinrere” Matteu 4:17, 23
Orin Dafidi 69:9 Ó ní itara fun ile Jehofa Johannu 2:13-17
Isaiah 53:1, 2 Awọn Ju kò gbà á gbọ́ Johannu 12:37, 38
Orin Dafidi 78:2 Ó sọrọ pẹlu akawe Matteu 13:34, 35
Sekariah 9:9 Ó wọ̀ ilu lori ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Matteu 21:1-9
Orin Dafidi 69:4 Wọn kórìíra rẹ̀ láìnídìí Johannu 15:24, 25
Isaiah 42:1-4 Ireti awọn orilẹ-ede; kò jà Matteu 12:14-21
Orin Dafidi 41:9 Ọ̀dàlẹ̀ aposteli dà á Johannu 13:18, 21-30
Sekariah 11:12 Fun 30 owó fàdákà Matteu 26:14-16
Orin Dafidi 2:1, 2 Awọn oluṣakoso gbégbèésẹ̀ lodisi Matteu 27:1, 2
ẹni-ami-ororo
Orin Dafidi 118:22 Wọn ṣá a tì, ṣugbọn Matteu 21:42, 43
ipilẹ tí ó daju ni
Isaiah 8:14, 15 Ó di okuta ìdìgbòlù Luku 20:18
Orin Dafidi 27:12 Awọn ẹlẹ́rìí eke lodi si i Matteu 26:59-61
Isaiah 53:7 O dákẹ́jẹ́ẹ́ niwaju awọn olùfisùn rẹ̀ Matteu 27:11-14
Orin Dafidi 22:16 Wọn kàn án ní ọwọ́ ati ẹsẹ̀ Johannu 20:25
Isaiah 53:12 Wọn kà á mọ́ awọn olùrékọjá Luku 22:36, 37
Orin Dafidi 22:7, 8 Wọn kẹ́gàn rẹ̀ lori òpó-igi Matteu 27:39-43
Orin Dafidi 69:21 Wọn fun un ní ọtí-waini Marku 15:23, 36
tí a fi òjíá sí
Sekariah 12:10 Wọn gún un ní ọ̀kọ̀ lori òpó-igi Johannu 19:34
Orin Dafidi 22:18 Wọn ṣẹ́ kèké lé aṣọ rẹ̀ Matteu 27:35
Orin Dafidi 34:20 Wọn kò fọ́ egungun rẹ̀ kankan Johannu 19:33, 36
Orin Dafidi 22:1 Ọlọrun kọ̀ ọ́ tì sápákan Matteu 27:46
fun awọn ọ̀tá
Danieli 9:26, 27 Wọn ké e kuro lẹhin 31/2 ọdunc Johannu 19:14-16
Sekariah 13:7 A kọlu oluṣọ-agutan, agbo túká Matteu 26:31, 56
Jeremiah 31:31 Majẹmu titun, a mú ẹṣẹ kuro Luku 22:20
Isaiah 53:11 Ó rù ẹṣẹ awọn ọpọlọpọ Matteu 20:28
Isaiah 53:4 Ó kó aisan araye lọ Matteu 8:16, 17
Isaiah 53:9 Ibojì pẹlu awọn ọlọ́rọ̀ Matteu 27:57-60
Orin Dafidi 16:10 A jí i dide ṣaaju idibajẹ Iṣe 2:24, 27
Jona 1:17 A jí i dide ní ọjọ kẹta Matteu 12:40
Orin Dafidi 110:1 A gbé e ga si ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun Iṣe 7:56
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Wo oju-iwe 61, 62 ninu ori yii.