ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19
“Ọba Àríwá” Ní Àkókò Òpin Yìí
“Ní àkókò òpin, ọba gúúsù máa kọ lu [ọba àríwá].”—DÁN. 11:40.
ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀?
KÍ LÓ máa ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn Jèhófà láìpẹ́? Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kò ṣàjèjì sí wa. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó máa ṣẹlẹ̀ táá sì kàn wá. Àsọtẹ́lẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ohun táwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé máa ṣe. Inú Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11) ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí wà. Ó sọ nípa ọba méjì tí wọ́n ń bá ara wọn jà, ìyẹn ọba àríwá àti ọba gúúsù. Apá tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló ti nímùúṣẹ, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wa lójú pé apá tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀ náà máa ṣẹ láìsí tàbí ṣùgbọ́n.
2. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti Ìfihàn 11:7; 12:17, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì?
2 Ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11), ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ìjọba àtàwọn alákòóso tí wọ́n ní ohun kan pàtó tí wọ́n ṣe sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tó wà láyé, àwọn ni ìjọba ayé sábà máa ń dájú sọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun kan ṣoṣo tó gba Sátánì àti ayé burúkú yìí lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa run àwọn tó ń sin Jèhófà tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti Ìfihàn 11:7; 12:17.) Ohun míì tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó wà nínú Bíbélì mu. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ká tó lè ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, ó ṣe pàtàkì ká wo àwọn apá míì nínú Ìwé Mímọ́.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?
3 Pẹ̀lú àwọn kókó yìí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:25-39. A máa rí ẹni tí ọba àríwá àti ọba gúúsù jẹ́ láàárín ọdún 1870 sí 1991, àá sì rídìí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní tẹ́lẹ̀ nípa apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò Dáníẹ́lì 11:40–12:1, àá sì ṣàtúnṣe sí òye wa nípa ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1990 sí ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wàá jàǹfààní gan-an tó o bá ń wo àtẹ tá a pè ní “Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí.” Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pè ní ọba àríwá àti ọba gúúsù?
BÍ A ṢE LÈ DÁ ỌBA ÀRÍWÁ ÀTI ỌBA GÚÚSÙ MỌ̀
4. Àwọn kókó mẹ́ta wo ló máa jẹ́ ká lè dá ọba àríwá àti ọba gúúsù mọ̀?
4 Níbẹ̀rẹ̀, gbólóhùn náà “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” tọ́ka sí àwọn ọba tó ṣàkóso láwọn ilẹ̀ tó wà lápá àríwá àti gúúsù orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kíyè sí ohun tí áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán sí Dáníẹ́lì sọ, ó ní: “Mo wá láti jẹ́ kí o lóye ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ ní àkókò òpin.” (Dán. 10:14) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni àwọn èèyàn Ọlọ́run títí dìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ látìgbà yẹn wá, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ ni àwọn èèyàn òun. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni èyí tó pọ̀ jù lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì orí kọkànlá (11) kàn, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Ìṣe 2:1-4; Róòmù 9:6-8; Gál. 6:15, 16) Àmọ́ látìgbàdégbà ni ìyípadà ń bá àwọn tó jẹ́ ọba àríwá àti ọba gúúsù. Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan wà tí kò yí pa dà. Àkọ́kọ́, àwọn ọba yẹn ń ṣàkóso lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí tàbí kí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Ìkejì, bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run fi hàn pé wọ́n kórìíra Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Kókó kẹta ni pé àwọn ọba méjèèjì yìí máa ń bá ara wọn jà láti mọ ẹni tó jẹ́ ọ̀gá.
5. Ṣé ọba àríwá àti ọba gúúsù wà láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sí ọdún 1870? Ṣàlàyé.
5 Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn afàwọ̀rajà tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni rọ́ wọnú ìjọ, wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni dípò ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Látìgbà yẹn títí di ọdún 1870, kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà létòlétò tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èké Kristẹni ló gbòde kan bí ìgbà tí èpò bá gbalẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ṣòro láti mọ àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. (Mát. 13:36-43) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ kókó yìí? Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù kò kan àwọn alákòóso tàbí ìjọba tó wà nípò láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sí ọdún 1870. Kò sí àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ tí wọ́n lè gbógun tì.b Àmọ́, a lè retí pé kí ọba àríwá àti ọba gúúsù fara hàn lẹ́yìn ọdún 1870. Báwo la ṣe mọ̀?
6. Ìgbà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run tún bẹ̀rẹ̀ sí í wà létòlétò? Ṣàlàyé.
6 Látọdún 1870 lọ, àwọn èèyàn Ọlọ́run tún bẹ̀rẹ̀ sí í wà létòlétò. Ọdún yẹn ni Arákùnrin Charles T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dá àwùjọ tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀. Arákùnrin Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ló dà bí ìránṣẹ́ Jèhófà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa “tún ọ̀nà ṣe” ká tó fìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀. (Mál. 3:1) Ó ti wá ṣeé ṣe báyìí láti dá àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀! Ǹjẹ́ agbára ayé èyíkéyìí wà nígbà yẹn tó máa nípa lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
TA NI ỌBA GÚÚSÙ?
7. Ta ni ọba gúúsù láti ọdún 1870 títí dìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní?
7 Nígbà tó fi máa dọdún 1870, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣàkóso àwọn ilẹ̀ tó pọ̀ jù láyé, òun ló sì ní ẹgbẹ́ ológun tó lágbára jù lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ìwo kékeré kan tó ṣẹ́gun ìwo mẹ́ta míì. Ìwo kékeré yẹn ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà táwọn ìwo yòókù ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Faransé, orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Netherlands. (Dán. 7:7, 8) Òun ni ọba gúúsù títí dìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Láàárín àsìkò yìí kan náà, Amẹ́ríkà ni orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
8. Ta ni ọba gúúsù láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?
8 Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ pawọ́ pọ̀ ja ogun náà, ìyẹn sì mú kí wọ́n lágbára gan-an. Àsìkò yẹn ni wọ́n di ohun tá a mọ̀ lónìí sí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọba yìí ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tó lágbára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Dán. 11:25) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni ọba gúúsù.c Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni ọba àríwá?
ỌBA ÀRÍWÁ TÚN FARA HÀN
9. Ìgbà wo ni ọba àríwá tún fara hàn, báwo sì lọ̀rọ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:25 ṣe nímùúṣẹ?
9 Ní 1871, ìyẹn ọdún kan lẹ́yìn tí Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dá àwùjọ tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀, ọba àríwá tún fara hàn. Lọ́dún yẹn, Otto von Bismarck pa àwọn ìlú mélòó kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn pọ̀, ó sì pè é ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Ọba Wilhelm Kìíní tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Prussia ni olú ọba àkọ́kọ́, ó sì yan Bismarck ṣe olórí ìjọba àkọ́kọ́.d Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, orílẹ̀-èdè Jámánì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè míì ní Áfíríkà àtàwọn erékùṣù tó wà ní Òkun Pàsífíìkì, ó sì ń wá bó ṣe máa lágbára ju ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ. (Ka Dáníẹ́lì 11:25.) Ilẹ̀ Jámánì ní ẹgbẹ́ ológun tó lágbára, kódà òun ni orílẹ̀-èdè kejì táwọn ọmọ ogun ojú omi rẹ̀ pọ̀ jù lọ láyé. Àwọn ẹgbẹ́ ológun yìí ni Jámánì lò láti bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní.
10. Báwo ni Dáníẹ́lì 11:25b, 26 ṣe nímùúṣẹ?
10 Dáníẹ́lì wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Jámánì àtàwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé ọba àríwá kò “ní dúró.” Kí nìdí? “Torí wọ́n máa gbèrò ibi sí i. Àwọn tó ń jẹ oúnjẹ aládùn rẹ̀ máa fa ìṣubú rẹ̀.” (Dán. 11:25b, 26a) Lásìkò tí Dáníẹ́lì gbáyé, lára àwọn tó ń jẹ “oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ” ni àwọn ìjòyè tó ń “bá ọba ṣiṣẹ́.” (Dán. 1:5) Àwọn wo gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tó wà nínú ìjọba ilẹ̀ Jámánì ni, títí kan àwọn olórí ogun àtàwọn agbaninímọ̀ràn ìjọba. Àwọn yìí ló fa ìṣubú ilẹ̀ ọba náà.e Yàtọ̀ sí pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ ohun tó máa fa ìṣubú ilẹ̀ ọba náà, ó tún sọ àbájáde ogun tó wáyé láàárín òun àti ọba gúúsù. Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa ọba àríwá ni pé: “Ní ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a máa gbá wọn lọ, a sì máa pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.” (Dán. 11:26b) Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ ló rí, àwọn ọ̀tá gbá àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì lọ, wọ́n sì “pa ọ̀pọ̀ nínú wọn run.” Tá a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ogun tó ti wáyé ṣáájú ìgbà yẹn, ogun yẹn ló tíì burú jù nínú ìtàn ẹ̀dá.
11. Kí ni ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe?
11 Nígbà tí Dáníẹ́lì 11:27, 28 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, ó sọ pé ọba àríwá àti ọba gúúsù “máa jókòó sídìí tábìlì kan náà, wọ́n á [sì] máa parọ́ fúnra wọn.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ pé ọba àríwá tún máa kó “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù” jọ. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn lóòótọ́. Ilẹ̀ Jámánì àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ ṣàdéhùn pé àlàáfíà máa wà, àmọ́ ogun tí wọ́n bára wọn jà lọ́dún 1914 fi hàn pé irọ́ ni wọ́n pa fúnra wọn. Láwọn ọdún tó ṣáájú 1914, ilẹ̀ Jámánì ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an, kódà òun ni orílẹ̀-èdè kejì tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé. Lẹ́yìn náà, kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 11:29 àti apá àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ 30 lè nímùúṣẹ, ilẹ̀ Jámánì bá ọba gúúsù jagun, àmọ́ ó fìdí rẹmi.
ÀWỌN ỌBA MÉJÈÈJÌ BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN JÀ
12. Kí ni ọba àríwá àti ọba gúúsù ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?
12 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914, ńṣe ni ogun táwọn ọba méjèèjì yìí ń bára wọn jà túbọ̀ ń gbóná, wọ́n sì ń dojú àtakò kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìjọba ilẹ̀ Jámánì àti ti Gẹ̀ẹ́sì ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run torí pé wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bákan náà, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ju àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run sẹ́wọ̀n. Èyí ló mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìfihàn 11:7-10 ṣẹ.
13. Kí ni ọba àríwá ṣe lẹ́yìn ọdún 1930 àti nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?
13 Nígbà tó yá, ìyẹn lẹ́yìn ọdún 1930, pàápàá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọba àríwá fayé ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú Násì gbàjọba lórílẹ̀-èdè Jámánì, Hitler àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ fòfin de iṣẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe. Àwọn ọ̀tá yìí pa àwọn bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún míì lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn torí ọba àríwá ‘sọ ibi mímọ́ di aláìmọ́, ó sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo kúrò’ ní ti pé ó jẹ́ kó nira fáwọn èèyàn Jèhófà láti máa yìn ín kí wọ́n sì máa kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba. (Dán. 11:30b, 31a) Kódà, Hitler tó jẹ́ aṣáájú ìjọba Násì lérí pé òun máa pa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà run ráúráú nílẹ̀ Jámánì.
ỌBA ÀRÍWÁ MÍÌ DÌDE
14. Ta ni ọba àríwá lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì? Ṣàlàyé.
14 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba Kọ́múníìsì ti Soviet Union ṣẹ́gun ilẹ̀ Jámánì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọba àríwá. Bíi ti àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ nígbà ìjọba Násì, ìjọba Soviet Union náà fayé ni àwọn èèyàn Jèhófà lára gan-an torí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tòótọ́ dípò kí wọ́n máa ṣègbọràn sí ìjọba èèyàn láìfi ti Ọlọ́run pè.
15. Kí ni ọba àríwá ṣe lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí?
15 Kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, Soviet Union tó jẹ́ ọba àríwá tuntun àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí Ìfihàn 12:15-17 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọba yìí fòfin de iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn lọ sí ìgbèkùn. Kódà, jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni ọba àríwá fi ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run bí ìgbà tí “odò” bá ya luni, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí.f
16. Báwo ni ìjọba Soviet Union ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 11:37-39 ṣẹ?
16 Ka Dáníẹ́lì 11:37-39. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ, ọba àríwá kò “ka Ọlọ́run àwọn bàbá rẹ̀ sí.” Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ìjọba Soviet Union wá bó ṣe máa pa gbogbo ẹ̀sìn run, torí náà ó fojú àwọn ẹlẹ́sìn rí màbo, ó sì gba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn. Kó lè mú ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ṣẹ, lọ́dún 1918 ìjọba Soviet Union ṣòfin kan tó mú kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé pé kò sí Ọlọ́run. Báwo ni ọba àríwá ṣe “yin ọlọ́run ibi ààbò lógo”? Ìjọba Soviet Union ná òbítíbitì owó láti mú kí àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ lágbára gan-an àti láti ṣe àwọn ohun ìjà runlérùnnà kí ìjọba rẹ̀ lè túbọ̀ lágbára. Bó ṣe di pé tọ̀tún-tòsì wọn, ìyẹn ọba àríwá àti ọba gúúsù to àwọn ohun ìjà jọ pelemọ nìyẹn, kódà àwọn ohun ìjà náà lágbára débi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pa gbogbo ayé run!
ÀWỌN ỌBA MÉJÈÈJÌ PAWỌ́ PỌ̀ ṢE OHUN KAN
17. Kí ni “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro”?
17 Ohun pàtàkì kan wà tí ọba àríwá ṣe ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọba gúúsù, ohun náà ni pé wọ́n “gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀.” (Dán. 11:31) Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni “ohun ìríra” náà.
18. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ohun ìríra”?
18 Bíbélì pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ohun ìríra” nítorí pé ó ṣèlérí pé òun máa mú àlàáfíà wá sáyé, bẹ́ẹ̀ sì rèé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àlàáfíà wá. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ pé ohun ìríra náà máa “fa ìsọdahoro” torí pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa dojú kọ gbogbo ìsìn èké, ó sì máa pa wọ́n run.—Wo àtẹ tá a pè ní “Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí.”
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MỌ OHUN TÁ A JÍRÒRÒ YÌÍ?
19-20. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ àwọn ohun tá a jíròrò yìí? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Ó yẹ ká mọ àwọn ohun tá a jíròrò tán yìí torí pé láàárín ọdún 1870 sí 1991, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa ọba àríwá àti ọba gúúsù ní ìmúṣẹ. Fún ìdí yìí, ó dá wa lójú pé àwọn apá tó kù nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà máa nímùúṣẹ.
20 Lọ́dún 1991, ìjọba Soviet Union wá sópin ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni ọba àríwá lásìkò wa yìí? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
a Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ṣì ń nímùúṣẹ. Kí ló mú kó dá wa lójú? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí?
b Pẹ̀lú àlàyé yìí, kò bá a mu láti pe Aurelian tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù (270-275 S.K.) ní “ọba àríwá” bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá a mu láti pe Ọbabìnrin Zenobia (267-272 S.K.) ní “ọba gúúsù.” Àtúnṣe lèyí jẹ́ sí àlàyé tá a ṣe ní orí 13 àti 14 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!
c Wo àpótí náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.”
d Lọ́dún 1890, Olú Ọba Wilhelm Kejì lé Bismarck kúrò lórí oyè.
e Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ṣe ló jẹ́ kí ilẹ̀ ọba náà tètè ṣubú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pa dà lẹ́yìn olú ọba náà, wọ́n tú àṣírí bí àwọn ṣe fẹ́ ja ogun yẹn fáwọn ọ̀tá, wọ́n sì fipá mú olú ọba náà láti fipò rẹ̀ sílẹ̀.
f Bó ṣe wà nínú Dáníẹ́lì 11:34, àwọn Kristẹni tó wà láwọn ilẹ̀ tí ọba àríwá ń ṣàkóso rí ìtura fúngbà díẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìjọba Soviet Union wá sópin tó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lọ́dún 1991.